url
stringlengths
37
41
id
stringlengths
1
5
text
stringlengths
2
134k
title
stringlengths
1
120
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2163
2163
Orúkọ Àdúgbò ní Òndó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà Òndó ÒNDÓ. Ìtumọ̀:Ibi ti olóyè Ọ̀túnba kọ́ ilé sí tí ó n gbé ni à n pè ní òkè ọ̀túnba Ìtumọ̀: Ibi ti àwọn òyìnbó tó mú èsìn ìgbàgḅó wá, ilé ibi tí wón ń gbé tí ó wà lórú òkè tú wọ́n ń pè ni yádì ni àwọn so di òke àyàdí tí àdúgbò náà ń jé dòní. Ìtumọ̀:Ìsàlè òndó tí olóyè Ọjọmù kọ́lé sí ni wọn ń pè ni Odòjọ̀mù. Ìtumọ̀: Òrìsà kan tí wọ́n ń pè ní odòlúà ní ó tè àdúgbò yí dò, Ibìtí o wọlẹ̀ si ni à ń pè ni odòlúà. Ìtumọ̀: Òkè ibi ti ó kọ́lé sí tí ó ń gbé ti peka sí tí wọ́n ń pè ni íÒkèlísà. Lísà ni o wa ní àdúgbò ti a ń pè ni Òkèlísà. Ìtumọ̀:Ìdi igi kan ti ẹyẹ oge máa ń pọ̀sí ni wọ́n sọ di Ìdímògé ní ìlú Òndó. Ìtumọ̀: Igi kan wa ti wọ́n ń pè ní igi sin. Abẹ́ igi yíì fẹjú, ó tutu, ó sì gbòòrò tó bẹ́ẹ̀ tí o lè gba èèyàn púpọ̀ láti seré bíì ìjàkadì ayò ọpọ́n abbl. Béì tití ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé sí àyíká igi yi ti ó wá di ibi tí à ń pè ni idi isin di òní. Ìtumọ̀: ni àdúgbò ti àwọn onísòwò tí ó jẹ́ ìsòbò pọ̀ si wọn a sì máa se kárà kátà wọn ní àdúgbò náà idi nìyí tí Òndó ń fi ń pe àdúgbò náà ni Òkè ìsòwò ni wọ́n igbati ó jẹ́ wí pé òkè ni ó wà. Òkè ìsòwò yíì ni àwọn ìsòbò yíì se àsìse ni pípé rè tí wọ́n fi ń pè ní òkè ìròwò ti ó di òkèrówó títí di òní. Ìtumọ̀:Ó jẹ́ ibi ti Ògbóni ti bẹ̀rẹ̀ ti wọn n ko ìlédi wọn si, ti wọn bà si ń lọ wọn a mú Ogbó dani gẹ́gẹ́ bí àmìn ẹgbẹ́ wọn. Wọn á ma so wí pé à kìí wòó Àdúgbò yí ni wọn sọ di Ogbo-ti-a-kii-wò tì ò fi di Ògbònkowo lónìí Ìtumọ̀: Ọjọ́ ti Òndó ìbá dàrú tí Òndó ìbá túká nítorí awo nlá kan to sẹlẹ̀, ojú ibi tí wọn joko si pètù sọ́rọ̀ òhún. Ìtumọ̀: ìdí tí wọ́n fi ń pè wọ́n ni ọ̀kà ni pé àwọn ará Ọ̀kà Àkókó lo fi agbègbè yí se ibùgbé. Àwọn ará òkà yii si ti pẹ̀ ni Òndó to bee je ti won ti gbo èdè Òndó yinrinyirin se téwé bá pe lára ose a dose ìdí nì yen tí won ń fi pé won ní òkà Ondo ti o doruko àdúgbò won ti a mo si oka Ìtumọ̀: Ijoye nla kan lo nje yege, ibi to tedo di to n gbe bo si owo isale Òndó ìdí niyi ti won fi n pe won ni òdò yègè. Ìtumọ̀: Ojà ni won n pen i igele ni èdè Òndó. Tomodé tàgbà won ni o ma fi aro wọn lo oko ni agbèègbè ti a n soro bayii nigba ti o ba di owo, ale won a pate oja won si ita ile won, titi ti o fid i ojà ti won náà ni alale. Ìtumọ̀: Ó jé agbègbè ti okuta pos i agbegbe yin i àwon molé molé ti n ma wa ko okuta àwon ni o si so agbegbe naa di ibi-a-n-gbo-òkútà oun lo wa di ìgbònkúta lóní Ìtumọ̀:Ibi tí Ondo ati Bágbè ti pinya ni a npe ni ìtapín Ìtumọ̀: lósìnlá-là gbalá ni àpètán lósùlá ibè ni won ti kókó ń se osùn tí won ńrà osìn, tí won ńtà osìn ní Ondo. Ìtumọ̀: àwon òlàjú ti o kókó lo sí Èkó ti won tàjò dé ni won so agbegbe yin i sùrúlérè nigba ti won tàjò de lati ma fí rántí agbègbè tí won gbé ni Èkó Ìtumọ̀: Àwon òlàjú ti o koko lo sí Èkó ti won tajo dé ni won so agbègbè yin í Yaba nígbà tí won tàjò dé láti le ma fi rántí àgbègbè ti won gbé ní Èkó. Ìtumọ̀: O je akínkanjú okùnrin kan tí ó lòkíkí ti a wa fi orúko re so agbègbè tí ó ńgbé. Ìtumọ̀:Olóyè ló ń jé sokoti àdúgbò rè ni won wá so di idim-sòkòtí. Ìtumọ̀:Jé ìtà oba tí won ti ń ma pa olè àti òdaràn idà ni a fi ń pa won ibi tí a n tójú idà náà sí ni Ìsídà níwòn ìgbà tí ó si jé pé apá ìsàlè Ondo ló bó sí ni a fi ń pè ní Odòsíndà. Ìtumọ̀:Ibi tí àwon ará Ondó tí máa ń jo ibi tí ó téjú tí ó gba èrò púpò ni, ó sì bó sí àrín ìlú a sì ma ń se ìpàdé níbè náà pèlú agbègbè yíì ni won ń pè ní òde Ondó. Ìtumọ̀:Ibè ní agbèbbè tí a ma ńkò àwon omobìnrin tí kò tí mo Okunrin si fun Idabobo lowo isekuse ki won tó ní oko ní ayé àtijó agbègbè náà sì ni eré obìtun ti bèrè. Ìtumọ̀: O je agbègbè tí òkà ti ń pò ti àwon èèyàn ń rà tí won si ń tà. Ìdí nìyí ti won fi ń pè ní ibi-ìje-okà ti ó di ìjòkà lónìí. Ìtumọ̀: O je àdúgbò ti èèyàn kan tédó ni pe bayìí ti o so àdúgbò náà ni orúko Tèmídire: Tèmi-di-ire. Ìtumọ̀: Ó jé agbègbè tí babaláwo kan tí ó gbójú wa ni àtijó a sì máagbà èmí eniyan la pupo lowo iku. Igbàgbó sì ni wipe eni ti o bat i mikanlè lówó Iku lódò rè ko le rí ajínde mo idi niyi ti won fi ń pè ni odò-ìmí-kanlè tí àgékúrú rè wa di odòmíkàn. Ìtumọ̀: Eni tó ní ilé ni a ń pè ni ‘nuli’ ni èdè Òndó. Agbègbè yi si wa je agbègbè ti àwon oní ilé ń gbé idi niyi ti won fi n pe ni odò-núlí ti ó wá di odòlÍlí Ìtumọ̀: Orúko ìlagije akíkanjú kan ló ń jé béè. Agbègbè tí ó n gbe ni a fi orúko re so lati se aponle fún un. Ìtumọ̀: Baba kan wa ti o ni, irúfé, irúgbìn kan ti a mo si pakala ni ede Oǹdó. Ìtumọ̀: Àgbègbè tí àwon elésìn Kiriyó ti máa se ìsìn won fún ìgbalà okàn ni won pè ní òkè-ìgbàlà ti o wa di okegbala lónìí yíì.
Orúkọ Àdúgbò ní Òndó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2164
2164
Àdúgbò Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà Eko =+EKO-LAGOS= Ìtumò: Agbègbè yí jé ibi tí àwon ará ìlú orísirísi latí orílè èdè káàkiri gbé ní gbà a ayeye yí ní 1977 (Festival of Arts and culture). Ìtumò: Ibí yí jé agbègbè tí àown Ìbàrì bà ńgbé, nítorínáà ni wón fi pèé ní Ìyànà-Ibà. Ìtumò: Abúlé –Ìjèsà ni apá ibi tí àwon ìjèsà kókó pò sí ní èkó, èyí ni ìdí tí ó fi ńjé Abúlé-Ìjàshà. Ìtumò: Ìdí tí a fí só ní mile 2 nìípé máìlì méjì ni ókù láti ibè sí ìbi tó ńjé Tincan-Island. Ìtumò: Ibí ni ówà nínú Èkó, orúko yí ni orúko Oba Èkó níìgbà tó tipé, sùgbó orúko rè ni wón fi so agbègbè yí tí ó ńjé kòsókó road. Ìtumò: Orúko ènìyàn Tàfá Bàléwà, eni náà jé lára àwon tí ó ti jé ààre orílè wa, lé yìn ikú rè ni wón fi so ibè ní Tàfá Bàléwà “Square”. Ìtumò: Technology Road, ìdí tí wón fi só ní oruko yi nípé, Yaba Technology kò jìnà sí ibè rárá, ìdí náà ni wón fi soóní Technology Road. Ìtumò: Ní agbègbè yí enìkan péré ni óní kéké sùgbón nítorí èyí ni won fi so ibè ní kèké, sùgbón ní ìgbà tí àwon òyìnbó fid é ní wón só di kéké. Ìtumò: Orúko èyàn ni óún jé Herbert macanlay, eni yì jé okan lára àwon òyìbó tí wón wá sí orílè èdè yí, nítorí èyí ni wón fi só ní Herbert macaulay way. Ìtumò: Ní ìlú Èkó ìdí tí wón fi só ní Maryland nipé, orúko aya oba ìlú òyinbó ni Mary, ìdí èyí ni a fi só ní Maryland. Ìtumò: Èdè yí ni èdè àwon haúsá, ìtumò rè sì ni kíá-kíá, àwon Haúsá ni wón pò sí ibí yìí jù, ní-ìgbà tí wón tèdó tí bè wón kò mò bí wón áse bá àwon èèyàn sòrò, sùgbón nínú ìwònba ìgbà tí wón ń tajà èdè won ni másámásá, ìdí ètí ni wón fi só ní másámásá-kíá-kíá. Ìtumò: Ìdí tí wón fi só ní “coconut village” niípé omi pò ní ibè gan, àti cocoanut (àgbon). O wa ni agbègbè Ajégúnlè. Ìtumò: Ajégúnlè jé ibi tí wón ti ń ra jà àti ta jà ní Èkó, àti wípé ibè jé lára ibi tìí àwon èèyàn pòsí ní ìlú Èkó, ojà títà sì ń lo déédéé tí aje ati owó dè tińwolé nígbà náà, ìdí náà ni ófinjé Ajégúnlè. Ìtumò: Èyí jé orúko agbègbè kan ní ìlú Agége cinema ńlá kan ní ó wà ní ibè, tí wón pè ní PEN-CINEMA. Ìtumò: Ibí ni won sin àwon Ológun tí wón ti won ti kú, wón sìn o àre ńlá kan sí bè tí ó je sójà ológun. Ìtumò: Ilú yíì wà ní agbègbè Àpápá ní Èkó, ìlú ńkí jé ibi tí àwon èèyàn pò si, tí àwon sì gbèrò sí gan. Ìtumò: Ibì jé agbègbè tí àwon custom pò sí, ibè sì ni ibi tí àwon erù sì pò sí àti àwon kòntánà idí èyí ni wón fi pèéní Tincay-Island. Ìtumò: Agbègbè èyí ní Èkó ni ilé-isé ibi tí wón ti ń se àwon Okò Volkswagen. Ìtumò: Agbègbè yí ni ówà ní Dòpèmú ní ìlú Èkó, ibè ni àwon ohun ìkólé yìí pò sí (aluminum) ìdí náà ni wón fi ń pèé ní aluminum Ìtumò: Agbègbè yí ni wón ti má n já erù tí óún bò láti òkè-ògun àti èyí tí wón bá fé gbé jáde, ìdí èyí ni a fi ń pèé ní “port’ Ìtumò: Lékki jé ibi tí wón kó àwon eléwòn sí ìdí yìí ni wón fi ń pèéní Lékkí. Ìtumò: Abúlé òsun jé lára ibi tí àwon abò-òrìsà òsun pó sí ní ìlú Èkó èyí ni wón fi só ní Abúlé-òsu, àti pé omí pò ní bè lópòlópò. Ìtumò: Kiríkirì ni ibi tí àwon eléwòn má n gbéé kiríkirì sì jé lára, ilé èwèn tí ó tóbí jù, nítorí è ni wón fi ń péè agbègbè náà ní kiríkirì. Ìtumò: Abílé-Àdó jé lara ibi ti awon àlàdó pos i ni aiye atijo ni ilu Eko opolopo ni ko mo ibe nitori ise ti won nse ni ibe. Ìtumò: Eyi je ibi ti nkan alaworan yip o sin i ilu Eko, nkan ti ounje “satellite” nitori náà ni won fi pee ni “Satellite Town”. Ìtumò: saw mill jé lára àwon agbègbè tí ó tóbi jù tí wón ti máa n se ìtójú igi tí a fin kólé ìdí náà ni ó finjé saw-mill. Ìtumò: Ibi agbègbè ni ibi tí a ti má n rí àwon Haúsá tí wón pò sí jù ní agbègbè tàbí ìlú. Ìtumò: “Salvation Avenue” je ibi ti awon elesin Christi posi “choistians”, ibi ti awon elesin bas i posi igbala ni won ma n pariwo (salvation) idi ti won fi n pe ni “salvation Avenue” Ìtumò: Idi-Ararba yi je ibi ti idi araba po si lopolopo, agbegbe náà ko jina si mushin ni ìlu Eko. adugb bariga
Àdúgbò Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2165
2165
Gbólóhùn Yorùbá "'Gbólóhùn èdè Yorùbá" ni a lè pè ní odidi ọ̀rọ̀ tí ó pé, tí ó ní olùṣe ati abọ̀ nínú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lẹ́tà ńlá. Síńtáàsì ni èka kan nínú gírámà èdè tí ó níí sè pèlú bi a se ń so òrò pò tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Síntáàsì ní òfin ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yí yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun ti elédè so jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón eléyìi kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn làákàyè elédè sá féré bóyá látaàrí òhún jíje tàbí mįmu ti ó le máa mú elédè so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti opolo red bá padà sípò, yóò so òrò ti ó mógbón lówó. Òfin Síntáàsì. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan. Fún àpeere, eni tí ó bá gbó èdè Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà, (1) (a) Mo lo sí oko (b) Sí lo oko mo Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nipé ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò tí yóò first di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu. O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin bíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé ítéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé ìtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé. (2) (a) Àwon ti ó lo kò pò (b) Àwon ti wón lo kò pò Méjèèjì ni ó bófin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé ìtéwógbà, èkejì kò jé ìtéwógbà. Èyí kò ni ǹ kan se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófin mu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú jùlo. Èdè gégé bí àdámó. Ó ye kí á mò wípé òhún àdámó ni èdè jé. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó bí Wón tí ń so Èdè abínibí rè. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àdámó ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè abínibí, ó ti wà lára rè. Kò sí èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. (2) Òrò àti Àpólà: Òrò ti a ba tòó pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b). (3) (a) Olú gíga lo (b) Olú lo Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 3. Gírámà ti a ó lò: Gírámà ìyidà onídàro ti Chomsky ni a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye. Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere: (4) GB ---> APOR APIS Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5). (5) GB ---> APOR AF APIS Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí: (6) AF ---> AS, IB, M, IBM Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS
Gbólóhùn Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2175
2175
Èdè Abínibí Ede Abinibi
Èdè Abínibí
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2177
2177
Ìlú Òró Ilu Oro
Ìlú Òró
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2189
2189
Ede Abinibi
Ede Abinibi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2190
2190
Ilu Oro
Ilu Oro
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2220
2220
Aran Aran ==Awon Aràn== Sòbìà, Eépà, Áràn mùjèmùjè/Aràn Okèelè, Jèdíjèdí, Ejò inú, Tanmona, Ekóló.
Aran
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2222
2222
Àwọn Ẹyẹ Eye Àwon Eye. 1. Ògòǹgò 2. Pépéye 3. Adie 4. Àsá 5. Àwòdì 6. Odíderé 7. Igún/Igúnnugún 8. Eyelé 9. Tòlótòló 10. Òwìwí 11. Òkín 12. Ológosé 13. Eye Oba 14. Lékèélékèé 15. Wasowaso 16. Àdàbà 17. Tin-ín tin-ín 18. Èluulùú 19. Àparò 20. Ègà
Àwọn Ẹyẹ
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2223
2223
Àwọn Òdòdó Ododo Àwo n Òdòdó díè. 1Korotin 2Àkálífà 3Ìlá abilà 4Alámáńdà 5Kerebùjé 6Marigó 7Píńróòsì 8Róòsì 9Abóòrunyí 10Bó-giri-rìn 11Òdòdó 12Okán 13Yún-únyun 14Ìgbàlódó/Ìràwò ilè 15Ìdò 16Oró agogo/oró adétè
Àwọn Òdòdó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2224
2224
Àwọn Igi Igi Àwon Igi. 1. Afàrà 2. Ahùn 3. Idí 4. Gedú 5. Ìrókò 6. Ògánwó 7. Òmò 8. Òsè 9. Apá
Àwọn Igi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2230
2230
Adebáyò Faleti Adébáyọ̀ Àkàndé Fálétí (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá 1930) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Akéwì , Olùkọ̀tàn, àti eléré orí-Ìtàgé, bákan náà ni ó tún jẹ́ oǹgbufọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá, ó sìn tún jẹ́ Omíròyìn orí Ẹ̀rọ asoro-ma-gbesi Radio, Olóòtú ètò orí Tẹlifíṣọ̀n TV, àti Olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ Afíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Western Nigeria Television (WNTV). Adébáyọ̀ Fálétí náà ló ṣe ògbufọ̀ orin àmúyẹ orílẹ̀-èdè Naigerian National Anthem láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè abínibí Yorùbá. Bákan náà ni ó tún ṣe oǹgbufọ̀ fún ohun tí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí lásìkò Ológun, ìyẹn Ibrahim Babangida sọ, pẹ̀lú tí Ààrẹ-fìdíhẹ nígbà ayé Ológun kan rí Chief Ernest Shoneka, nípa lílo èdè Yorùbá tó gbámúṣé. Fálétí ti tẹ Ìwé-Atúmọ èdè Dictionary Yorùbá ní èyí tí ó ní àbùdá ògidì Yorùbá nínú. Adébáyọ̀ Fálétí ti gba onírúurú àmì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá oríṣiríṣi nílẹ̀ yìí àti lókè Òkun pẹ̀lú.
Adebáyò Faleti
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2232
2232
Ilé-Ifẹ̀ Ifẹ̀ (, tabi "Ilé-Ifẹ̀") jẹ́ orírun gbogbo ọmọ Oòduà ní ilẹ̀ Yorùbá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé-Ifẹ̀ wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ifẹ̀ sí ìlú Ìpínlẹ̀ Èkó je kilomita igba o le mejidinlogun (218) tí àwọn tí wọ́n jẹ́ olùgbé ibẹ̀ lápapọ̀ jẹ́ 509,813 níye. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, Ilé-Ifẹ̀ ni wọ́n dá sílẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Olódùmarè nígbà tí ó pàṣẹ fún Ọbàtálá kí ó wá láti dá ayé kí ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṇ́ fẹ̀ láti ibẹ̀ lọ káàkiri àgbáyé; ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe Ilé-Ifẹ̀ ní Ifẹ̀ Oòyè, ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wáyé. Àmọ́, Ifẹ̀ yí ni Ọbàtálá pàdánù rẹ̀ sọ́wó Odùduwà Atẹ̀wọ̀nrọ̀, èyí ni ó fàá tí fàá ká ja ṣe wà láàrín àwọn méjèèjì. Odùduwà ni ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba ní Ifẹ̀, ní èyí tí àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo náà sì di adarí àti olórí ìlú ní ẹlẹ́ka-ò-jẹ̀ka ibi tí wọ́n tẹ̀dó sí káàkiri orílẹ̀ Yorùbá lóní. Gẹ́gẹ́ bí a ti kàá nínú ìtàn, Ọọ̀ni àkọ́kọ́ tí yóò kọ́kọ́ jẹ ní Ifẹ̀ ni ó jẹ́ ọmọ bíbí inú Odùduwà tí ó jẹ́ ọ̀kànlélógójì òrìṣà fúnra rẹ̀, nígbà tí Ọọ̀ni tí ó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyí jẹ́ Ọọ̀ni Adéyẹyè Ẹnìtàn Ògúnwùsì Ọ̀jájá Kejì(II) tí wọ́n jẹ ní ọdún 2015. Bákan náà ni Ilé-Ifẹ̀ ní ọ̀kànlélúgba òrìṣà tí wọ́n ma ń bọ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yípo ọdún. Ilé-Ifè ìlú ńlá tí òkìkí rẹ̀ kàn jákè-jádò àgbáyé fún àwọn Iṣẹ́ ọnà wọn bíi ère orí Odùduwà àti àwọn ohun ọnà míràn tí wọ́n lààmì-laaka ní ǹkan bí ọdún 1200 àti 1400 A.D sẹ́yìn.
Ilé-Ifẹ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2242
2242
Kọ́lá Akínlàdé Kola Akinlade A bí Kọ́lá Akínlàdé ní ọdún 1924, ní ìlú Ayétòrò ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ ni Michel Akínlàdé àti Elizabeth Akínlàdé. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù mímọ́ ní Ayétòrò. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí ni ó kọjá sí Ìlaròó tí ó sì dá iṣẹ́ tẹ̀wétẹ̀wé sílẹ̀ ńbẹ̀ fúnrarẹ̀ ni ó ka ìwé gba ìwé-èrí G.C. E. ní ilé. Lẹ́yìn tí Kọ́lá Akínlàdé gba ìwé-ẹ̀rí yìí ni ó dá ìwé ìròyàn kan sílẹ̀ tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Ẹ̀gbádò Progressive Newspaper: Lẹ́yìn èyí ni ó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé ìjọba. Ó ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba ìpínlè ìwọ̀-oòrùn àtijọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Kị́lá Akínlàdé lọ kàwé ní Yunifásítì Ifẹ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ó sì tún padà sí ẹnu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ní ọdún 1976 ni Kọ́lá Akínlàdé fẹ̀yìn tì. Ní ọdún 1980, ó tún gba iṣẹ́ olùkọ́ sí ìbàdàn Boys High School, Ìbàdàn, Nàìjíríà. Ó wá fi ẹ̀yìn tì ní ọdún 1984. Kọ́lá Akínlàdé ní ìyàwó ó sì bí ọmọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ni Kọ́lá Akínlàdé ti kọ. Lára wọn ni Ajá to ń Lépa Ẹkùn, Ọ̣wọ̣̣́ Tẹ Amòokùnṣìkà, Àgbákò nílé Tẹ́tẹ́, Baṣọ̀run Olúyọ̀lé, Ajayi, the Bishop, Chaka, the Zulu, Esther, the Queen, Abraham, The…..Friend of God, Sheu Usman Dan fodio, Òwe àti Ìtumọ̀ rẹ̀, Sàǹgbá fọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún kópa nínú kíkọ Àsàyàn Ìtàn. 1. Ọmọ ilé-èkọ́ ni Dúró Orímóògùnjé. Ó ku Ọdún kan kí ó jáde ìwé mẹ́wàá. Ìyá rẹ̀ kú ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ìyẹ̀n ni pé ó kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Bàbá rẹ̀ nígbà tí ó kú. Ikú bàbá rẹ̀ tí ó gbọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ ni o gbé e wálé. Ìyàwó mẹ́rin ni Àkàndé Orímóògùnjẹ́ tí ó jẹ́ ìyá Dúró ti kú, ó ku mẹ́ta. Ọmọ márùn-un ni Àkàńgbé Orímóògùnjé bí Dúró sì ni àgbà gbogbo wọn. Òun ni àkọ́bí. Ìyaa folúké, ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó wọ̀nyí, ni ìríjú àkándé, Orímóògùnjẹ, ìyẹn ni pé òun ni ó fẹ́ran jù. Ìya fólúké yìí ni ó mú kọ́kọ́rọ́ séèfù jáde tí ó ṣí i tí wọn kò sì bá nǹkan kan ní ibẹ̀. Ìgbà tí Àkàndé mú owó kẹ́yìn nínú séèfù yìí kí ó tó kú, owó tí ó wà nínú rẹ̀ ju ẹgbàáta náírà (N30,000.00)lọ. Ọ̀gbẹ́ni Ajúṣefínní: Òun ní ó ra kòkó lówó Àkàngbé. Ó sanwo ní 10/2/80. Àṣàkẹ́: Òun ni ó jẹ́rìí sí owó kòkó ti Àkàngbé gbà. Ohun tí ó yani lẹ́nu ni pé Ogóje náírà (N140.00) péré ni wọ́n bá ní abẹ́ ìrọ̀rí Àkàngbé nígbà tí ó kú. Àdùnní: Òun ni ìyá Dúró Orímóògùnjé. Àdùnní ti di olóògbé, ìyẹn nip é ó ti kú. Ọ̀gbẹ́ni Túndé Atọ̀pinpin: Òun ló ní kí Dúró fi ọ̀rọ̀ owó tí ó sọnù lo Olófìn-íntótó. 2. Túnde Atọ̀pinpin náà kọ lẹ́tà sí Olófìn-íntótó. Ìdẹ̀ra ni orúkọ ilé-ẹ̀kọ́ àbúrò Túndé Atọ̀pinpin. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Dúró orímóògùnjẹ́. Ẹ̀gbọ́n Ilẹ́sanmí ni Àdùnní ìyá Dúró Orímóògùnjẹ́. Àgbẹ̀ oníkòkó ni Àkàngbé orímóògùnjẹ́, bàbá Dúró nígbà ayé rẹ̀. Túndé Atọ̀pinpin àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa ń sùn ní ilé Àkàngbé nígbà ti wọ́n bá ń lọ sí ìhà Odò Ọya. Dúró Orímóògùnjẹ́ nìkan ni ọmọ tí Àdùnní bé. Ará ìlú Àdùnní ni Olófìn-íntótó, ọmọ Adéṣínà. Túndé Atòpinpin máa ń lọ gbé ojà ní Èkó. Ọkọ̀ ojú omi ni ọjà yìí máa ń bá dé. 3. Olófìn-íntótó, ọmọ olusínà kọ̀wé sí Túndé Atọ̀pinpìn. Àròsọ ni Olófin-íntótó àti ilésanmí ti wokò. Dírẹ́bà wọn ń sáré gan-an ni. Fìlà Olófìn-íntótó tilẹ̀ sí sọ̀nù ní ọ̀nà. Ó dá mọ́tọ̀ dúró ni kí ó tó lọ mú un Nígbà tí wọ́n dé ojà, dírébà jẹ ẹ̀bà, ilésanmí jẹ iyán ó sì ra òòyà ní irinwó náírà (400.00) Ní ọjà, Olófìn-íntótó bá obìnrin kan pàdé. Ó ra ọtí fún un. Obìnrin yìí sì mu ìgò otí kan tán ó sì mu ìkejì dé ìdajì. Ó yẹ kí a sẹ àkíyèsí obìnrin yìí dáadáa nítorí pé òun nì a wá fi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jí owó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ jí ní iwájú. Nígbà ti Olófìn-íntótó àti Ilésanmí dé Ilé-Ifè tí wọn ń lọ, ọ̀dọ̀ Àlàó ni wọ́n dé sí. Ilé-Ifẹ̀ ni Àlàó ti ń ta ojà. Àlàó ra obì àti ọtí fún Olófìn-íntótó Olófìn-íntótó mu bíà mẹ́ta. Àlàó ń mu ẹmu lẹ́yìn tí ó jẹun tán Ilésanmú sì ń mu ògógóró. Ọlọ́fìn-íntótó gbádùn láti máà fi ọwọ́ pa túbọ̀mu rẹ̀. Irun tí ó hù sí orí ètè òkè ní ìsàlẹ̀ ibi tí imú wà ni ó ń jẹ́ túbọ̀mu. Àsàkẹ́: Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Gbajímọ̀ ènìyàn ni. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ṣùgbọ́n ó dàbí ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọ̀mọ̀wé ni. Yéwándé: Ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé ni òun náà. Kò kàwe ṣùgbọ́n o ní ọ̀yàyà ó sì máa ń ṣe àyẹ́sí ènìyàn. Àlàó: Òun ni Olófin-íntótó àti Ilésanmí dé sí ọdọ rẹ̀. Onígbàgbọ́n ni. Jọ̀ọ́nú ni orúkọ rẹ̀ mìíràn. Ó máa ń gbàdúrà ni alaalé kí ó tó sùn. Ọmọ mẹ́ta ni ó bí. Ní ọjọ́ tí àwọn Olófin-íntótó kọ́kọ́ dé ilé rẹ̀ tí wọ́n ń gbàdúrà ó ní kí gbgbo wọn kọ orin wá bá mì gbé olúwa. Àwọn ọmọ Àlàó kò bá wọn kọ ẹsẹ kejì tí ó sọ wí pé ‘Ọjọ́ ayéè mi ń sáré lọ sópin’. Àsàmú tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Àlàó ni ó ṣe àlàyé fún bàbá rẹ̀ ìdí tí wọn kò ṣe kọ ẹsẹ kejì orin náà. Ó ní orin àgbàlagbà ni. 4. Ilésanmí rọ́ àlà tí ó lá fún Akin Atọ̀pinpin ọmọ Olúṣínà. Ó ní nínú àlá tí òun lá, òún. Rí ẹni tí ó gbé owó ṣùgbọ́n òun kò rí ojú rẹ̀ tí òun fi ta jí. Ẹ jẹ́ kí á ṣe àkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n mẹ́nu bà ní orí yìí. Dúró – Òun ni àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Orímóògùnjẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Fólúkẹ́ - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni. Ó ṣẹṣẹ̀ wo kọ́lẹ́jì ni. Ọmọ́wùmí- Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni. Ilé-ẹ̀kọ́ kékeré ni ó wà. Ọládúpọ̀ - - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjé ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni. Ilé-ẹ̀kọ kékeré ni ó wà. Fólúkẹ́, Omówùmí àti Oládípọ̀ jẹ́ ọmọ Yẹ́wándé. Bándélé jẹ́ ọmọ odún méje. Àṣakẹ́ ni ó bíí Yàtọ̀ sí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́, Yéwándé nìkan ni ó tún máa ń mu owó nínú séèfù. Àìsàn Orímóògùnjẹ́ kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ tí ó fi kú. Ilé Orímóògùnjẹ́ kò ju ilé kẹ́rin lọ sí ilé Àlàó. Nígbà tí àwọn Olófìn-íntótó dé ilé Orímóògùnjẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí. Yéwándé ni ó mú wọn wọlé Kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù yìí kìí ya Orímóògùnjẹ́. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni ó wà nígbà tí ó ń ṣàìsàn. Kì í yọ kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù. Àṣàkẹ́ wọlé bá wọn níbi tí wọn ti ń sọ̀rọ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwádìí nílé Orímóògùnjẹ́. Wọ́n máa ń há ìlẹ̀kùn yàrá Orímóògùnjẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n máa ń fi kọ́kọ́rọ ibẹ̀ há orí ìtérígbà. Ẹnikẹ́ni ní inú ilé ni ó lè mú un ní ibẹ̀ kí ó sì fi sí ilẹ̀kùn Yéwándé ni ó máa ń tọ́jú Orímóògùnjẹ́ lóru nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. Àṣàkẹ́ máa ń ràn án lọ́wọ́. yéwándé àti àwọn ọmọ náà máa ń wá tọ́jú Orímóògùnjẹ́ nígbà ti ó ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí àìsàn rẹ̀ bá ń yọnu. Adékẹ́yẹ ni orúkọ bàbá yéwándé. Ọjà Ajégbémilékè ni Yéwándé fẹ́ lọ ní ọjọ́ tí ọkọ rẹ̀ kú. Àlàó ni ó kó ogóje náírà (N140.00) tí wọ́n bá níbi ìgbèré Orímóògùnjẹ́ fún Yéwándé láti tójú. Orúkọ mìíràn tí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ tún ń jẹ́ ni Bándélé. Ẹ rántí pé eléyìí yàtọ̀ sí Bándélé orúkọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ. Ọ̀sanyìnnínbí ni orúkọ oníṣèègùn Orímóògùnjẹ́. Ó ra páànù ìgàn méjìlá ní ọ̀dọ̀ kékeréowó. Èyí sì fẹ́ mí ìfura dání nítorí owó tí ó sonù. Àwọn kan rò pé bóyá òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ tí ó sọnù. Nílé Orímóògùnjẹ́ níbití wọ́n ti ń ṣe ìwádìí, Ọlọ́fìn-íntótó rí ẹ̀já òwú kan tí ó wà lára ọ̀kan nínú àwọn ojú kéékèèkéé inú séèfù ó sì mú un. Gbòngán ni fọláṣadé ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn Orímóògùnjẹ́ ń gbé. Ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún tàbí ọ̀sẹ̀ kan ní ifẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ kí ó tó padà sí Gbọ̀ngán. Kò bímọ kankan fún Orímóògùnjé. Ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí fọláṣadé dáadáa nítorí pé òun ni Olófìn-íntótó ra otí fún ní ọjà tíó mu ìgò ọtí kan àbò. Òun ni a sì rí ní òpin ìwé pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé. 5. Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ ní sítọ́ọ̀. Káyọ̀dé ni orúkọ akọ̀wé rẹ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́fà kí Akin Ọlọ́fín-íntótó ọmọ Olúṣínà àti Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ ti rí ara wọn mọ kí wọn tún tó rí ara wọn yìí. Àbúrò Orímóògùnjẹ́ ni Ilésanmí tí òun àti Olófìn-íntótó jọ wá ṣe ìwádìí ní ilé-Ifè. Ọ̀rẹ́ Orímóògùnjẹ́ ni Ajíṣefínní tí ó ń ta kòkó. Bíọlá ni orúkọ ẹni tí ó ń ta ọtí Lóòótọ́, oníṣèègùn ni Ọ̀sanyìnnínbí síbẹ̀, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn Oníṣèègùn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹgbẹ́ ìlera loògùn Ọrọ̀. Awóyẹmí ni orúkọ ẹni tí ó bá àwọn Ọlọ́fìn-íntótó níbi tí wọ́n ti ń gbádùn lọ́dọ̀ Ọmọtóṣọ̀ọ́. Ilésanmí àti Ọlọ́fin-íntótó sọ nípa ara wọn pé àwọn mọ ilẹ̀ tẹ̀ múyẹ́ (Ẹ rántí pé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀lmúyẹ́ ni wọ́n ń ṣe). Ajúṣefínní, ọ̀rẹ́ orímóògùnjẹ́ ni ó bá Orímóògùnjẹ́ ra ilẹ̀ tí ó ń kọ́ ilé sí. A ó rántí pé kòkó ní Ajíṣefínní ń tà. Ọwọ́ Òṣúnlékè ni wọ́n ti r ailẹ̀ tí Orímóògùnjẹ́ fi ń kólé náà. Ẹgbẹ̀ta náírà (N600.00) ni wọ́n ra ilẹ̀ náà. Káyòdé akòwé Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ sùn ní ẹnu iṣẹ́ Ìgbà tí wọ́n bi í pé kí ló dé tí ó fi sùn ni ó dáhùn pé olè ajẹ́rangbe tí àwọn ń lé ní òru ni kò jẹ́ kí àwọn sùn dáadáa. Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Oníṣèègùn Ọ̀sanyìnnínbí ni olórí àwọn olè ajẹ́rangbé yìí gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i kà ní iwájú. Ẹran tí ó ń jí gbé yìí wà lára ohun tí ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn fura sí Ọ̀sanyìnnínbí pé òun ló jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé níbi tí ó tí ń tọ́jú rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. Ẹran mẹ́ta ni wọ́n bá ní ilé àwọn olè wọ̀nyí nítorí pé wọ́n ti jí méjì tẹ́lẹ̀. Nítorí pé Ọ̀sanyìnnínbí jẹ́ ọ̀gá fún àwọn olè wọ̀nyí, wọ́n mú un lọ sí Àgọ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Morèmi ní ilé-Ifè. 6. Nígbà ti Ọlọ́fìn-íntótó gbọ́ pé wọ́n mú Ọ̀sanyìnnínbí sí àgọ́ ọlọ́pàá Morèmi, òun àti Ilésanmí lọ́ sí ibẹ̀. Aago mẹ́fà sí mẹ́jọ ni ọ̀gá ọlọ́pàá máa ń rí ènìyàn ṣùgbọ́n ó gbà láti rí Akin àti Ilésanmí lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rí káàdì Akin. Pópóọlá ni orúkọ ọ̀gá ọlọ́pàá yìí. Ọ̀rẹ́ Akin Olófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà ni. Àbéòkúta ni Pópóọlá wà tẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tí wá gbé e wá sí Morèmi ní Ifẹ̀ níbi tí ó ti jẹ́ ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá ibẹ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́ta tí ó ti rí Akìn mọ. Pópóọlá bèèrè Túndé Atọ̀pinpin lọ́wọ́ Akin. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tí wọ́n ti ṣè àlàyé pé ọ̀rọ́ Ọ̀sanyìnnínbí tí wọ́n mú ni ó gbé àwọn wa ni wọ́n ṣe àlàye pé tí ó bá jẹ́ pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́, yóò ti ná tó ẹgbẹ̀jọ náírà (N1,600.00) nínú owó náà. Ẹran ti Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé ni ó jẹ́ kí wọ́n ní àǹfààní láti yẹ ilé rẹ̀ wo. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí àwọn ènìyàn sọ ní orú yìí tí ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí. Ilésanmí ni ó kọrin pé, ‘Iyán lóunjẹ.’ Akin ni ó sọ pé, Ajímutí kìí tí’ Akin náà ni ó sọ pé, ‘Ẹni fojú di Pópó á gba póńpó lórí…’. Orúko Pópíọlá ni ó fi ń ṣeré níbí yìí. Pópóọlá sọ pé, ‘Ẹni tí ó pe tóró, Á ṣẹnu tọ́ńtọ́..’ Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Àlàó ni oríkì Pópóọlá. Eléyìí yàtò sí Àlàó tí ó tójú àwọn Olófìn-íntótó tí a ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ ṣáájú. Nígbà tí wọ́n ló yẹ ilé Ọ̀sanyìnnínbí wò, owó tí wọ́n bá ní ibẹ̀ jẹ́ ọgọ́sàn-án náírà (N180.00) Níní orí yìí, a ó rí òwe, ‘Àfàgò kẹ́yin àparò…’ Ohun tí ó fa òwe yìí ni ẹran tí Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé àti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ní yóò lọ tí ìyàwó rẹ̀ yóò sì ti bímọ kí ó tó dé. Àpatán òwe yìí ni, ‘Afàgò kẹ́yin àparò, ohun ojú ń wá lojú ń rí. 7. Akin Olúṣínà àti Ilésanmí lọ sí ilé Ọ̀sanyìnnínbí. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, òògùn ni Ọ̀sanyìnnínbí wá ṣe. Orí yìí ni a ti mọ ìdí tí Ọ̀sanyìnnínbí fi fẹ́ràn Orímóògùnjẹ́. Ìdí tí ó fi fẹ́ràn rẹ̀ nip é nígbà tí Ọ̀sanyìnnínbí ń ṣe òkú ìyá rẹ̀, ó fún un ní ọgọ́rùn-ún náírà (N100.00) níbi tí kò ti sí ẹni tí ó tún fún un ju náírà márùn-ún lọ. Àlàó tí ó tọ́jú Akin àti Ilésanmí nígbà tí wọ́n dé Ifẹ̀ kò fẹ́ran oògùn ìbílẹ̀ Ọ̀sanyìnnínbí sọ pé Orímóògùnjẹ́ kì í finú tan Àlàó yìí Àwọn ohun tí ó tún yẹ kí á ṣe àkíyèsí ní orí yìí ni ìwọ̀nyí: Awódélé wá kí Ọ̀sanyìnnínbí Àkànbí, àbúrò Aríyìíbí, tí Ọ̀sanyìnnínbí nígbà tí ó ń ṣàìṣàn ní ó dúró fún Ọ̀sanyìnnínbí ní àgọ́ ọlọ́pàá (Ìyẹn ni pé Àkàbí tí Ọ̀sanyìnnínbí wòsàn ni ó dúró fún òun náà) Ní ọjọ́ tí àwọn Ọ̀fíntótó wá sí ilé Ọ̀sanyìnnínbí, nǹkan bí agogo mókànlá ni ó wọlé àwọn Òfíntótó sì dé ilé rẹ̀ ní aago méjì kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Nígbà tí Akin Olúṣínà àti Ilésanmí dé ọ̀dọ̀ Ọ̀sanyìnnínbí tí ó rò pé oògùn ni wọ́n wá ṣe ní ọ̀dọ̀ òun, àwọn ẹbọ tí ó kà fún wọn ni ìyá ewúrẹ́ kan, ẹgbẹ̀rún náírà ìgò epo kan, iṣu mẹ́ta àti ìgàn aṣọfunfun kan. Akin Olúsínà mu ẹmu ní ilé Ọ̀sanyìnnínbí Ajéwọlé ni ó ra kòkó lówọ́ Ọ̀sanyìnnínbí. Ẹgbẹ̀fà náírà (N200.00) ni ó gbà ní owó kòkó náà. 8. Àwọn ohun tí ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí ní orí yìí ni ìwọ̀nyí: Láti lè mọ iye tí Ọ̀sanyìnnínbí gbà fún kòkó tí ó tà fún Ajéwọlé, ọgbọ́n ni wọ́n fi tan Ọ̀sanyìnnínbí. Wọ́n sọ fún un pé ẹnì kan ń rọbí àti pé yóò nílò oníṣèẹ̀gùn. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Oládiípọ̀. Òun sì ni àbíkẹ́yìn Yéwándé Bándélé jẹ́ ọmọ odún mẹ́jọ. Ọmọ Àṣàkẹ́ ni Jayéjayé kan ni Àṣàkẹ́ máa ń wọ àdìrẹ tàbí borokéèdì ó sì máa ń wọ súwẹ́ta nígbà òtútù. Fawọlé: Ó wà lára àwọn ẹni tí ó wá wo Orímóògùnjẹ́ nígbà tí ara rè kò yá. Nígbà tí Akin Olúsínà ṣe ìwádìí nípa rẹ̀, èsì tí ó rí gbọ́ ni ìwọ̀nyí: Wọ́n ní ìhà sáábó ni Fáwọlé máa ń gbe Tinúkẹ́ ni orúkọ ọmọ rẹ̀. Nípa aṣọ tí ó wọ̀ ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́, ẹni kan sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú aṣọ òfì ni ó wọ̀. Ẹni kan sọ pé sán-ányán ni aṣọ tí ó wọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ́dé kìí tètè gbàgbé nǹkan, Akin Olúṣínà ní kí awọ́n bèèrè ìbéèrè nípá Fáwọlé lọ́wọ̀ Fólúkẹ́ àti Bándélé. Fólúkẹ́ sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì ni ó wọ̀. Ó ní ó dé filà sán-ányán, ó wọ́ bàtà aláwọ̀ funfun ràkọ̀ràkọ̀ Bándélé ni ó bomi fún Fáwọlé ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́. Folúkẹ́ ní ojoojúmọ́ ni Ọ̀sányìnnínbí máa ń wá sọ́dọ̀ Orímóògùnjẹ́ nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń sàìsàn ó sì máa ń dúró di ìgbà tí wọ́n bá ń pèrun alẹ́ kí ó tó kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Folúkẹ́ ní òun rí nǹkan kan bí ológbò ní àpò rẹ̀ ni ọjọ́ kan. Àlàó kò gbọ́ nípa ẹni tí ó ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò nítorí pé ó lọ sí ibì òkú ìyá Báyọ̀ ní ọjọ́ náà. Ìyá Bándélé ni ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dan séèfù wò náà Orímóògùnjẹ́ kò sọ ọ̀rọ̀ eni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò yìí fún Àlàó. Yéwándé náà kò sọ fún un. 9. Igba náírà (N200.00) ni wọ́n bá ní ilé Àṣàkẹ́, ìyẹn ìyá Bándélé nígbà tí àwọn Akin Ọlọ́fìn-íntótó yẹ ilé rẹ̀ wò. Ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè ni Àṣàkẹ́ ìyá Bándélé. folúkẹ́ ni ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé Àṣàké ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò. Àṣàkẹ́ máa ń kanra mọ́ ọmọdé. Aṣọ òfì ni Yéwándé wọ̀ nígbà tó wọ́n ń ṣe ìwádìí yìí torí òtútù. Ọjọ́ kejì ọjà Ajágbénulékè ni Àṣàkẹ́ rí kọ́kọ́rọ́ tí ó fi dán séèfù wò nínú yàrá rẹ̀. Àlàá, Àkin àti Ilésanmí fi kọ́kọ́rọ́ náà dán séèfù wò, kò sí i. Lẹ́yìn ìwádìí ti ọjọ́ yìí, Akin Ọlọ́fìn-íntótó àti ilésanmí padà sí Ìbàdàn. Ní ibi tí Akin ti dá mọ́lò dúró nígbà tí o fẹ́ ẹran ìgbẹ́ ni bàbá alágbẹ̀dẹ kan ti sọ fún ọmọ kan pé kí ó wò ọkọ̀ náà. Kọ́lá ni orúkọ ọmọ yìí. Orí yìí ní wọ́n ti wá mọ orúkọ ọmọge tí Akin Olúṣínà ra ọtí fún nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ifẹ̀ tí a ti mẹ́nu bà ṣáájú. Orúkọ ọmọge yìí ni fìlísíà Olówólàgbà. A ó rí i ní iwájú pé filísíà Olówólàgbà yìí ni orúkọ mìíràn fún ìyàwo Orímóògùnjẹ́ tí ó jí owó Orímóògùnjé gbé. Akin àti Ilésanmí wá filísíà yìí lọ sí pètéèsì aláwò pupa rúsúsúsú. Kọ́lá ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ilé yìí. Akin àti Ilésanmí sun ọ̀dọ Fìlísíà mọ́jú. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí Pópóọlá. Ó gbé wọn dé màpó. 10. Akin lọ gbowó ní bàǹkì. Òun àti Ilésanmí ni wọ́n jọ lọ. Ní báǹkì, wọ́n pàdé Kọ́lá. Ẹnu rẹ̀ ni wọ́n ti gbọ́ pé Bínpé àbúrò fìlísíà fẹ́ ṣe ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngán. Pópóọlá gbé Akin, Ilésanmí àti Kọ́lá. Ní ọ̀nà, ní ibi tí alágbẹ̀dẹ́ ti fi Kọ́lá sí ọkọ̀ ní ìjelòó, wọ́n rí àwọn méjì tí wọ́n ń jà Ògúndélé ni orúkọ alágbẹ̀dẹ yìi. Òun ni ó ń bá Jìnádù jà. Wọ́n gbá Adénlé tí ó fẹ́ là là wọ́n ní ẹ̀sẹ̀ nínú. Pópóọlá tí ó jẹ́ ọlọ́pàá ni ó pàṣẹ pé kí wọn dá ọwọ́ ìjà dúró tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí ó fa ìjà tí Ògúndélé àti Jinádù ń jà ni pé Ògúndélé tí ó jé alágbẹ̀dẹ rọ kọ́kọ́rọ́ kan fún jìnádù ní múrí mẹ́ta (#60), Jìnádù san Múrí kan (#20) níbẹ̀ ó ku múrí méjì (#40). Ògúndélé bínú nítorí pé Jìnádù kò tètè san múrí méjì tí ó kì. Jìnádù bínú nítorí pé ó sọ pé Ògúndélé sin òun ní owó ní àárí àwùjọ. Jìnádù sọ pé Ògúndélé fi òrùkọ ẹ̀rẹ na òun. Nígbà tí Kọ́là sọ̀ kalẹ̀ tí ó ń lọ, ó gbàgbé àpò rẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n dá a padà fún un. Nígbà tí Ain àti Ilésanmí ti Ìbàdàn tí wọ́n ti ń bọ̀ dé Ilé-Ifẹ̀, wọ́n lọ sí ilé fáwọlé Nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí fọláṣadé 9tí àwa tún mọ̀ sí fìlísíà) wá sí Ifẹ̀, ó lò tó ọjọ́ mẹ́ta dípò méjì tí ó máa ń lò tẹ́lẹ̀. Ìpàdé ọmọlẹ́bí tí wọ́n fẹ́ ṣe gan-an ni ó tèlè mú un padà. Yàtọ̀ sí ìgbà tí ìnáwó pàjáwùrù bá wà ọjọ́ karùn-ún kànùn-ún ni Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ nígbà tí ó wà láyé. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Yéwándé máa ń bá Orímóògùnjẹ́ mú owó nínú séèfù rẹ̀ ṣùgbọ́n ó tó oṣù kan sí ìgbà tí Orímóògùnjẹ́ tó kú tí ó ti rán an mú owó nínú rẹ̀ gbèyìn. Ọjọ́ ọjà ni ọjọ́ tí Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ máa ń bọ́ sí. Ọjọ́ kẹ́rin tí Orímóògùnjẹ́ mú owó kẹ́yìn nínú séèfù rẹ̀ ni ó kú. Ìyẹn ni pé ọjà dọ̀la ni ó kú Orímóògùnjẹ́ máa ń fún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní owó-ìná tí ó bá ti mówó. Níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwadìí yìí, Akin Olúṣínà ń fi ataare jobì. Túndé Atọ̀pinpin ní kí àwọn yẹ yàrá Fọláṣadé wò. 11. Ìsòrí kọkànlá yìí ni ó ti hàn gbangba pé Fọláṣadé, ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Orímóògùn ni ó jí owó rẹ̀ gbé. Ó ní ìdí tí òun fi jí owó náà gbé nip é òun kò bímọ fún Orímóògùnjẹ́ òun kò sì fẹ́ kì tòun ó gbé sílé rẹ̀ nítorí pé ọmọ tì obìnrin bá bí fún ọkọ ni wọ́n fi máa ń pín ogún ọkọ náà ní ilẹ̀ Yorùbá. Fọláṣadé ni ó yí orúkọ padà tí ó di fìlísíà. Òun náà ni ó lọ rọ kọ́kọ́rọ́ lọ́dọ̀ bàbá àgbẹ̀dẹ tí Àṣàkẹ́ fi dán séèfù wò. Akin Olúṣínà: Òun ni wọ́n máa ń pè ní Akin Ọlófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà. Òun ni ó ṣe ìwádìí owó tí ó sọnù. Àròsọ ni ó ti wọkọ̀ lọ sí Ifẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí owó náà. Fìlà rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀ nínú mọ́tò tí ó wọ̀. Dírẹ́bà ọkọ̀ yìí kò mọ ọkọ̀ wà dáadáa. Akin Olúṣíná fẹ́ràn ẹran ìgbẹ́. Ó máa ń mutí. Ó máa ń jobì tó fi ataa sínú rẹ̀. Ó ní túbọ̀mu ó sì máa ń fi ọwọ́ pa á. Ó ṣe wàhálà púpọ̀ kí ó tó mọ̀ pé Fọláṣadé tí ó tún ń jẹ́ filísíà nì ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó. Foláṣádé: Òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó. Kò bímọ fún Orímóògùnjẹ́. Ìdí nì yí tí ó fi jí owó rẹ̀ gbé. Ó ní kí ti òun má bàa jẹ́ òfo nílé Orímóògùnjẹ́ ni ó jẹ́ kí òun jí owó rẹ̀ gbé. Fọláṣadé náà ni ó yí orúkọ padà sí fìlísíà Olówálàgbà. Orúkọ yìí ni ó si fi lọ fi owó pamọ́ sí báǹkì. Gbòngán ni ó ń gbé ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, ó ní ilé sí Ibadan. Gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, Ọ̀gá ni ó jẹ́ fún Kọ́lá Òwú ara súwẹ́tà rẹ̀ tí ó já bọ́ síbi séèfù wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́ láti rí i mú. Ìwé ìfowópamọ́ rẹ̀ tí Akin Olúṣínà rí lọ́wọ́ Kọ́lá náà tún wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́. Fọláṣadé wà lára àwọn tí wọ́n bí séèfù lójú rẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ tí wọn kò bá nǹkan kan níbẹ̀. Kò sì jẹ́wọ́ pé òun ni òun kó owó tí ó wà níbẹ̀. Ó máa ń ti Gbọ̀ngán wá sí Ifẹ̀. Òun ni ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn foún Orímóògùnjẹ́. Tí ó bá wá láti Gbọ̀ngán, ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún ní Ifẹ̀ tàbí ọ̀sẹ̀ kan. Ilé oúnjẹ ni Akin àti Ilésanmí ti kọ́kọ́ pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó jiyán tán ní ilé olóúnjẹ yìí, ó mu ìgò otí kan àti àbọ̀ nínú ọtí tí Akin Olúṣínà rà. Àkàngbé Ọrímóògùnjẹ́: Òun ni wọ́n jí owó rẹ̀ gbé tí Akin Olúṣínà wá ṣe ìwádìí rẹ̀. Àìsàn tí ó ṣe é tí ó fi kú kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù rẹ̀ máa ń wà. Inú séèfù yìí nì ó máa ń kó owó sí. Kìí yọ àwọn kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù yìí. Tí wọ́n bá ti ilèkùn yàrá rẹ̀, wọ́n máa ń fi kọ́kọrọ́ há orí àtérígbà níbi tí ẹnikẹ́ni ti lè mú un. Orúkọ múràn tí ó ń jẹ́ ni Bándélé. Ogóje náírà (#140), péré ni wọ́n bá nígbà tí ó kú tán. Kí ó tó kú ó ti ra ilẹ̀ tí yóò fi kọ́lè. Ajíṣafínní ni ó bá a dá sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tí ó rà náà. Owó Òṣúnlékè ni ó ti rà á. Ẹgbàáta náírà (#6,000) ni ó ra ilẹ̀ náà. Dúró: Dúró ni àkọ́bí ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Ilé-ẹ̀kọ́ girama ni ó wà. Ọdún kan ni ó kù kí ó jáde. Òun ni ó kọ ìwé sí Akin Olúṣínà pé kí ó wá bá òun wádìí owó bàbá òun tí wọn kò rí mọ́. Àdùnní ni orúkọ ìyá rẹ̀ òun nìkan ni ó sì bí fún bàbá rẹ̀. Àdùnní yìí tí kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) nì Dúró. Àbúrò mẹ́rin ni ó ní. Àwọn náà ni Àdùkẹ́, Ọmọ́wùmí, Oládípò àti Bándélé. Àdùnní: Àdùnní ni ìyàwó tí Orímóògùnjẹ́ kọ́kọ́ fẹ́. Ó kú ní ọdún mẹ́ta sáájú ọkọ rẹ̀. Òun ni ó bí Dúró fún Orímóògùnjẹ́. Ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún Ilésanmí. Ọmọ ìlú kan náà nì òun àti Akin Olúṣínà.
Kọ́lá Akínlàdé
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2251
2251
Ìṣẹ̀-Èkìtì Ise-Ekiti Iṣẹ́ yìí dá lórí àyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka-èdè tí à ń sọ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì. Láti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ yìí, tíọ́rì onídàrọ́ ni a lò. Ìpín mẹ́rin ni a pín iṣẹ́ yìí sí. Ní orí kìn-ín-ní ni a ti sọ ìtàn orírun Ìṣẹ̀-Èkìtì. A sọ èrèdí iṣẹ́ yìí, ọgbọ́n ìwádìí tí a lò àti àyẹ̀wò iṣẹ́ tí ó wà nílẹ̀. Bákan náà, a sọ tíọ́rì tí a lò fún iṣẹ́ yìí. Ní orí kejì ni a ti ṣe àlàyé lórí àwọn ìró inú ẹ̀ka-èdè ìṣẹ̀-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. Bíi ìró kónsónáǹtì, ìró fáwẹ́lì, ìró ohùn, iṣẹ́ ohùn, sílébù àti oríṣiríṣi. sílébù tí a lè rí nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. Ní orí kẹ́ta àpilẹ̀ko yìí ni a ti ṣàyẹ̀wo nípa ìgbésẹ̣̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. A wo ìpàrójẹ, àrànmọ́ àti àǹkóò fáwẹ́lì. Ní orí kẹ́rin iṣẹ́ yìí ni a ti gbìyànjú láti wo àwọn ìyàtọ̀ àti ìjọra tí ó wà láàrin fonọ́lọ́ji ẹ̀ka-èdè Ìsè-Èkìtì àti ti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Àgbálọgbábọ̀ iṣẹ́ yìí dá lé àwọn tuntun tí ó jáde nínú ìwádìí ti a ṣe a si tọ́ka sí àwọn ibi tí a lérò pé iṣẹ́ kù sí.
Ìṣẹ̀-Èkìtì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2276
2276
Àkúrẹ́ Akure je ilu ni Naijiria ati oluilu ipinle Ondo ni apa iwo oorun. A kò le sọ pàtó ọdún tàbí àkókò tí wọn tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Arífálò (1991) ṣe wòye, ó ní Àkúrẹ́ fẹ́rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí ó pẹ́ tí wọn ti tẹ̀dó ni ilẹ̀ Yorùbá Akurẹ is probably lone of the oldest towns in Yorubaland. (Arífálò 1991; o,1.2) Ìtàn sọ fún wa pé, Aga, ẹni tí a tún wá mọ orúkọ rọ̀ bí Alákùnrẹ́ ni ó kọ́kọ́ tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó. Orúkọ̀ bàbá rẹ̀ ni ìyàngèdè. Ìtàn sọ fún wa pé, Ẹ̀pé, ní ẹ̀bá ìlú Òǹdó ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ibùgbé lẹ́yìn tí wọn kúrò ní Ilé-Ifẹ̀. Alákùnrẹ́ tẹ̀ síwájú láti dá ibùgbé tirẹ̀ ní. Ní àsìkò yìí, ohun ọ̀ṣọ́ ọwọ́ rẹ̀ tí á ń pè ní ‘Àkún’ gé. Ó pe ibẹ̀ ní ‘Àkún rẹ́’ nítorí ìtumọ̀ ‘gé’ ni ‘rẹ́’ ní èdè Àkúrẹ́. Eléyìí ni ó wá di ‘Àkúrẹ́’ títí dòní yìí. Alákùnrẹ́ sì jókòó gẹ́gẹ́ bí olórí ìlú. A kì í pè é ní ọba ní àsìkò yẹn bí kò ṣe ‘Ọmọlójù’. Ó lo ipò rẹ̀ bí olórí ìlú àti ọmọ Odùduwà ní ìlú Àkúrẹ́. Ní àsìkò yìí ni àwọn ọmọ Odùduwà ń jẹ ọba káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. A gbọ́ pé, Àjàpadá Aṣọdẹ́bọ̀yèdé tí o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Odùduwà kúrò ní ìlú Òṣú, ó sì dúró sí ìlú kan tí wọn ń pè ní ‘Òyè’nítòsí Ẹ̀fọ̀n-Alààyè. Rògbòdìyàn, Ìṣòro, ogun àti àìfọkànbalẹ̀ kọ lu ìgbé – ayé Àjàpadá pẹ̀lú ara ìlú ‘Òyè’ náà. Ó wá di dandan fún Àjàpadá láti kúrò ní ìlú ‘Òyè’fún ààbò. Òun àti àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ dórí kọ ilẹ̀ àìmọ̀rí fún ibùgbé. Àjàpadá gbáradì, ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí akíkanjú àti ògbójú ọdẹ. wọ́n rìn títí tí wọn fi dé igbó Àkúrẹ́, ibí ni wọ́n ti bá wọn pa erin. Erin tí Àjàpadá pa fún àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ fún àwọn ará ìlú ní ìwúrí àti ìbẹ̀rù, nítorí pé, ọdẹ tí ó bá pa erin jẹ́ ọdẹ abàmì àti akíkanjú ọdẹ. Àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ wá gba Àjàpadà gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọdẹ tí yóò lè ní agbára láti gba ará ìlú rẹ̀ ní ọjọ́ mìíràn tí ogun tàbí ọ̀tẹ̀ bá dé. Àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ fún Àjàpadá ní orúkọ ‘Aṣọdẹbóyèdé’. Àjàpadá tí à ń pè ní Aṣọdẹbóyèdé wá ní iyì gidi tí àwọn ará ìlú sì fẹ́ràn rẹ gan-an. Àwọn ará ìlú wá gbé Àjàpadá ga ju Alákùnrẹ́ tí o kọ́kọ́ dé ìlú Àkúrẹ́ lọ. Alákùnrẹ́ náà ṣàkíyèsí pé, àwọn ará ìlú fẹ́ràn Àjàpadá ju òun lọ, ó wa dàbí ẹni pé wọ́n rí ‘ọkọ́ tuntun gbé àlòkù èṣí dànù’. Alákùnrẹ́ wá já ọwọ́ rẹ̀ nínú irọ́kẹ̀kẹ̀ àti akitiyan láti jẹ́ ọba fún ìlú Àkúrẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun gan-an ni ẹni kìíní tí ó kọ́kọ́ tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó. Itàn sọ fún wa pé Alákùnrẹ́ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kúrò fún Àjàpadá Aṣọdẹbóyèdé. Àjàpadá Aṣọdẹbóyèdé wá jẹ́ ọba ìlú Àkúrẹ́ kìíní, gbogbo ayé gbọ́, ọ̀run sì mọ̀. Iwádìí fi hàn wá pé, Àjàpadá yìí jẹ́ ọmọ Ẹkùn, Ẹkùn sì jẹ́ ọmọ Òdùduwà1. Òdùduwà tí ó jẹ́ bàba Ẹkùn ni ó tọ́jú Àjàpadá dàgbà nítorí Ẹkùn tètè kú. Àjàpadé jẹ́ ọmọ rere, ó sì fẹ́ràn láti máa ṣeré káàkiri ààfin Òdùduwà, àwọn ènìyàn a sì máa pè é ní ‘Àjàpadá Ọmọ Ẹkùn. A gbọ́ pé Odùduwà fún Àjàpadá ní ẹ̀wù oògùn kan tí wọn ń pè ní ‘Ẹ̀wù Ogele’ tí Òduduwà fúnra rẹ̀ fi ń ṣe ọdẹ, nígbà tí Àjàpadá pinnu láti dá ibùgbé tirẹ̀ ní. 1. Oríṣiríṣi èrò ni ó wà nípa orúkọ àti iye ọmọ Òdùduwà. Wo: T. A. Ládélé a.y. Àkòjọpọ̀ Iwádìí Ìjìnlẹ̀ Àsà Yorùbá. Ibadan’, Macmillan Nigeria Publishers Ltd. 1986, o.i. 1-2. Ohun méjì ni ó mú kí Òdùduwà ṣe èyí, èkínní ni ìwà akíkanjú tí Àjàpadá fi hàn nígbà tí o fi ‘Àjà’1 kékeré pa eku ẹdá nínú ilé àìlujú nígbà èwè rẹ. Èkejì ni ìfẹ́ tí Òdùduwà ní sí Ẹkùn tí ó jẹ́ bàbá fún Àjàpadá. Ẹkùn sì tètè kú, ‘Ọmọ́rẹ̀mílẹ́kún’ ni Àjàpadá jẹ́ sí Odùduwà. Ẹ̀bùn ẹ̀wù yìí nìkan kò tẹ́ Àjàpadá lọ́rùn, ó bẹ Odùduwà fún àwọn ohun ọrọ̀ míràn, èyí wá jẹ́ kí Òdùduwà tún rob í baba Àjàpadá ti jẹ́, ó sì wọ ilé lọ, nígbà tí o máa jáde, ó jáde pẹ̀lú ẹwà iwà mímọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó gbé adé kan lọ́wọ́, ó súre fún Àjàpadá, ó sì sọ fún Àjàpadá pé, ‘mo fi adé yìí jì ọ́’ Mo fi adé jì ọ́, ni ó wá di ‘Déjì’tí o jẹ́ orúkọ oyè ọba ìlú Àkúrẹ́, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Òdùduwà fi adé jì2. Adé yìí jẹ ìtọ́kasí pé ọmọ ọba ni Àjàpadá. 1. Ohun èlò ọdẹ ti wọn fi irin ṣe ni o ń jẹ́ ‘Àjà’. Ibi náà ni orúkọ Àjàpadá tí ṣúyọ tí o túmọ̀ sí ‘A fi ajà pá ẹdá (Àjàpadá) 2. Èyí tí ó túmọ̀ sí pé, mo fi adé yìí fún ọ láéláé. Àjàpadá ọmọ Ẹkùn Aṣọdẹbóyèdé, Déjì kìíní ní ìlú Àkúrẹ́ jẹ́ akínkanjú ògbójú ọdẹ ni gbogbo ìgbésì ayé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Weir (1934)1 ogójì ọba ni ó ti jẹ ní ìlú Àkúrẹ́ láti ìgbà tí ìtàn ti bẹ̀rẹ̀. Ọba mẹrìn sì ti jẹ lẹ́yìn àkókò tí Weir ṣe ìwádìí tirẹ̀. Àpapọ̀ ọba tí ó ti jẹ ní Àkúrẹ́ jẹ́ mẹ́rìnlélógójì2. À rí igbọ́ pé obìnrin méjì ni ó wà nínú wọn.3 Obìnrin kìínì ni Èyé – Aró ti ó jẹ ọba ní ọdún 1393 títí di ọdún 1419 A.D. Ohun tí o fà á tí oyè fi kan obìnrin yìí nip é, òun nìkan ni ifá rẹ fọ rere láàrin àwọn tí wọn dárúkọ fún ifá rẹ fọ rere láàrin àwọn tí wọn dárúkọ fún Ifá. Àwọn Àkúrẹ́ sì fẹ́ tẹ̀ lé ohun tí Ifá sọ nítorí pé wọn ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba jẹ tí wọn kò pẹ lórí oyè. Ifá sọ pé obìnrin yìí yóò pẹ́ lórí oyè àti pé àsìkò rẹ̀ yóò tuba tùṣẹ. Obìnrin kejì tí ó jẹ ọba ní Èyémọhin, ó wà lórí oyè ni ọdún 1705 títí di ọdún 1735. A gbọ́ pé nígbà tí wọn tún dá ifá ní àsìkò yìí, ifá kò mú ọmọkùnrin ọmọ-ọba kọọkan, bí kò ṣe ọmọ-ọba-bìnrin yìí. Eléyìí ni ó mú kí àwọn ará Àkúrẹ́ fi ọmọ-ọba-bìnrin yìí jẹ ọba. 1. Wo: N.A. C. Weir 1934 Akurẹ District Intelligence Report. Filo 41, 30014 Nigerian National Archives Ìbàdàn. 2. Wo Àfikún ‘I’ fún orúkọ àwọn ọba tí ó ti jẹ ní ìlú Àkúrọ́. Ọba Adéṣidá Afúnbíowó ni a gbọ́ pé, ó pẹ́ láyé jù gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú Àkúrẹ́. Ó lo bí ọgọ́ta ọdún láyé (1897 -1957.) Àkíyèsí: A ko iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́mè ti F.A Àjàkáyé A.F Àjàkáyé (1998) ‘Ìlò Orin Láwùjọ Àkúrẹ́ Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria. Àṣamọ̀ Èròngbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣe ìwádìí sí ohun tí àwọn ará Àkúrẹ́ máa ń lo orin fún ní àwùjọ wọn. Ó jẹ́ ọ̀nà láti ṣẹ̀dámọ̀ àwọn orin àwùjọ Àkúrẹ́, láti ṣàlàyé ìṣẹ̀ṣe àwọn orin wọn àti láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn kókó tí orin máa ń dá lé. Ìlò orin ní àwùjọ Àkúrẹ́ tí iṣẹ́ ìwádìí yìí dá lé ni èròngbà láti sí ọ̀nà titun sílẹ̀ fún àtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ lọ́nà láti mú kí àwọn orin wọ̀nyí yé ni dáradára. Ó tún jẹ́ ọ̀nà láti ṣí ọ̀nà titun sílẹ̀ fún ìwádìí lórí lítíréṣọ̀ alohùn pàápàá ti àwùjọ Àkúrẹ́ tí ó jẹ́ pé iṣẹ́ ìwádìí kò ì tí pọ̀ lórí rẹ̀. À ṣe àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò láti ọdọ̀ àwọn ọ̀kọrin. Apohùn ìṣẹ̀nbáyé àti àwọn abínà-ìmọ̀. A ṣe àdàkọ àwọn orin tí a gbà jọ, a sì ṣe àgbéyẹwò àwọn iṣẹ́ tí wọn ti wà nílẹ̀ lórí orin ní àwọn agbègbè mìíràn. A ka àwọn ìwá tí ọwọ́ wa tẹ̀ ní agbègbè náà, a sì rí ọ̀kọ́ tó wúlò fún wa lórí orí ọ̀rọ̀ tí iṣẹ́ wa yìí dá lé. Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé àkọ́jinlẹ̀ orin nípa síṣe àtúpalẹ̀ kókó ohun tí à ń lo orin fún pọn dandan kí a tó le ní òye iṣẹ́ ọnà àti Ìtumọ̀ orin ní àpapọ̀. Ìṣẹ́ yìí tún jẹ́ kí ń ní ìmọ̀ nípa ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀, ẹ̀sìn àti ètò ìṣèlú àwọn ará Àkúrẹ́. Iṣẹ́ yìí tún fi hàn pé ẹ̀sìn ní o máa ń bí àwọn orin ẹ̀sìn ní àwùjọ Àkúrẹ́ àti pé àṣà àti ìṣe àwùjọ ni ó máa ń ṣe okùnfà fún àwọn orin aláìjọmẹ́sìn. Ojú Ìwé: Oókàn-dín-láàádọ́ọ̀sàn-án Alámòjútó: Ọ̀mọ̀wé A. Akínyẹmí.
Àkúrẹ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2277
2277
Eégún Eegun Ìtàn tí n ó sọ nípa bí eégún ̣ṣe délé ayé yìí, mo gbọ́ ọ láti ẹnu baba babaà mi ni kí ó tó di pé wọ́n jẹ́ ìpè Olódùmarà ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́hìn. Ìdí pàtàkì tí ó jẹ́ kí n fi ara mọ́ ìtàn náà ni pé ó fi ara jọ ìtàn tí mo kà lórí nǹkan kan náà ìwé Òmọ̀wé J.A. Adédèjì1. Ìdí mìíràn tí ó jẹ́ kí n fi ara ḿọ́ ìtàn náà yàtọ̀ sí òmíràn nip é ẹnu àwọn tí mo ṣe ìwadìí lọ́wọ́ wọn kò kò lóŕi ọ̀rọ̀ náà. Ó dà bí ẹni pé olúkálukú ni ó fẹ́ fi bu iyi kún ìlú tirẹ̀ pé ní ìĺú tòun ni awo Iségún ti bẹ̀rẹ̀. Ògbẹ́ni Táyélolú Ṣáṣálọlá tí ó ń gbé ni ìlú Oǹd́ó tilẹ̀ sọ f́ún mi pé ní ìlú Ọ̀fà ni Eégun ti ṣẹ̀. Nígbà tí mo sì fi ọ̀rọ̀ wá a lénu wò, mo rí i pé ọmọ Ọ̀fà ni baba rẹ̀. Ọmọ Iwékọṣẹ́ tún sọ fún mí pé ó dá òun lójú pé ní ìlú Òkè-igbó lẹ́bàá Oǹd́ó ni Eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Nínú Ìdàrúdàpọ̀ yìí ni mo wá rò ó pé bí ènìyàn bá fẹ́ẹ́ mọ òtítọ́ tí ó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà, àfi bí ènìyàn bá tọ Ifá lọ nítorí pé If́a kò ní í gbè sẹ́hìn ẹnìkẹ́ni. Orísìí ìtàn méjì ni mo sì wá rí ńinú Ifá. Ṣùgbọ́n ìtàn kéjì ni mo fi ara mọ́. Ìdí tí mo sì ṣe fi ara mọ́ ọn náà nip é ó jọ ìtàn tí mo ti gbọ́ lẹ́nu baba babaà mi. Èyí nìkan kọ́: mo fi ara mọ́ 1. Adédèjì J.A. The Alárìnjó Theatre: The Study of a Yorúbà theatrical Art form its Origin to the Present Times. Ph.D. Thesis (University of Ibadan), 1969, pp. 20-90. Ìtàn kejì yìí nítorí pé ó tún là wá lọ́yẹ lórí bí orúkọ náà, “Eégún”, ti ṣe bẹ̀rẹ̀. Ìtàn àkọ́kọ́ yìí wà nínú Odù Èjì ogbè, Ẹsẹ̀ Èkejì. Ìbéjì ni wọ́n fi Eẹgún bí. Ọ̀kán kú èkejì sì wà láàyè. Èyí tí ó wà láàyè si wá ́n sunkún ṣá. Wọ́n wá dọ́gbọ́n, wọ́n dáṣọ̣ Eégún. Wọ́n mú èyí tí ó wà ẹnìkan lórí. Ẹni tí ó gbé Eégún náà ń pe ẹni tí ó wà láàyè pé: “Mọ́ tí ì wá o, Ìhín ò rọ̀ o ò.” Ẹsẹ Ifá náà lọ báyìí: “Ńí ọjọ́ tí Éégún dé ayé, Ìbejì ni wọ́n bí i. Ọ̀kan kú, ọ̀kan wà láàyè. Èyí tí ó wà láàyè wáá sunkún títí, Ni wọ́n bá dọ́gbọ́n, Wọ́n dáṣọ Eégún. Wọ́n mú èyí tí ó wà láàyè lọ sínú igbó. Wọ́n gbé aṣọ Eégún náà bọ ẹnìkan lórí. Ẹni tí ó gbé Eégún náà ń pé Èyí tí ó wà láàyè pé: Mọ tíì wá o, Ìh́in ò rọ̀ o ó. Èyí tí ó wà láàyè bẹ̀rẹ̀ síí sunkún, 1. Abimbọ́la Wandé, Awọn Odù Mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndímlógún. (memio), pp. 3-4. Eégún náà yára wọ inú igbó lọ. Aṣọ tí a dà bo alààyè lórí Ni à ń pè ní ẹ̀kú Eégún. Ẹ̀kú ayé o, Ẹ̀kú ọ̀run, N à ń pè ní èjìgbèdè ẹ̀kù.” Ìtàn ke jì wà nínú ìwé Ọ̀mọ́wé J.A. Adédèjì tí mo ti tọ́ka sí tẹ́lẹ̀. Ńińu Odù Ọ̀wọ́nrínsẹ̀ ni ó wà. Ìtàn náà lọ báyìí: Nígbà TÌ Ọ̀wọ́nrín tí ọ́ ń gbé ní Ìsányín dolóògbé, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta - Arúkú, Arùḱu àti Aròḱu-rọja-má-tà kò ní owó lọ́wọ́ lati fi ṣe òkú bàbáa wọn. Ìrònú ọ̀ràn náà pọ̀ dé bi pé èyí Arúkú tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún gbogbo wọn fi ìlú sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èyí àtẹ̀lé rẹ̀, Arùkú, mú ìmọ̀ràn wá pé kí àwọn ó ta òkú náà1. Èyí àbúrò wọn, Aròkú-rọja-má-tà, bá kiri òkú náà lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ti kiri fún ìgbà díẹ̀ tí kò ti rí ẹni ra òkú náà ni ó ti sú u, ó sì wọ́ òkú náà jùnù sínú igbó; ó bá tirẹ̀ lọ. Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, èyí ẹ̀gbọ́n di baálé ilé, ó sì gba ipò bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ológbìín. Gẹ́gẹ́ bí ipò rẹ̀ òun ni ó sì wá di Ológbo2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abuké ni, Aláàfin fún un ní ìyàwó kan, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìyá Mòsè. Ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọd́un, Mòsè kò gbọ́ mokòó 1. Wọn a máa ta òkú láyé àtijọ́ fún àwọn olóògùn tí wọn fẹ́ lo ẹ̀ya ara òkú náà. 2. Akígbe tí ́o sì máa ń ru ọ̀pá oyè Aláàfin. rárá; ó kàn ń fọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ ni. Èyí ni ó mú kí ọkọ rẹ̀ Ológbìín tọ Ọ̀rúnmìlà lọ. Nígbà tí ó débà tí ó débẹ̀, ó ńi “emi ló dé tí ìyàwó òun fi rọ́mọ lẹ́hìn adìẹ tó bú púrú sẹ́kún?” Ọ̀rúnmìlà sì sọ fún un pé àfi tí ó bá lè ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún baba rẹ̀ tí ó ti kú kí ìyàwó rẹ̀ ó tó lè bímọ. Ní àkókò yìí, Ìyá Mòsè ti lọ́ sọ́dọ̀ Amúsan láti lọ ṣe ìwádìí ohun tí ó fa sábàbí. Bí Ìyá Mòsè ti ń bọ̀ láti odò Asà níjọ̀ kan ni elégbèdè kan jáde sí i láti inu igbó tí ó sì bá a lòpọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ìyá Mosè ṣe bẹ́ẹ̀ lóyún. Mòsè kò sì lè jẹ́wọ̀ bí ó ṣe lóyún fún ọkọ rẹ̀. Ó sì fọ̀n ọ́n ó di ọ̀dọ̀ Ọlọ́pọndà tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Ìyá Mòsè. Níbẹ̀ ni ó ti bí ìjímèrè. Ìtìjú a máa pa gbajúmọ̀. Nígbà tíìtìjú pọ̀ fún Mòsè, ó tún fọn ọ́n, ó di ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Bí ó sì ti ń lọ lọ́nà ni ó ju ìjímèrè sínú igbó. Ṣé ọkọ rẹ̀ kò kúkú mọ nǹ̀̀kan tí ó bí. Nígbà tí ó dijọ̀ keje ni Ato tí ó jẹ́ ìyàwó Ògògó tí ó jẹ́ ọmọ Ìgbórí rí ìjímèrè igbó. Ní àkókò tí a ń wí yìí. Ológbìín ti gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Ó ti lọ sí ọ̀dọ̀ Ọ̀rúnmìlà, Ifá sì ti sọ fún un pé sùúrù lẹbọ. Ifá ní kí Ológbìín máa tọ́jú abàmì ọmọ náà, ṣùgbọ́n kí ó tún ṣe ẹ̀yẹ ìkọhìn fún baba rẹ̀ nìpa lílọ sí igbó níbi tí wọ́n ti rí abàmì ọmọ náà láti lọ ya eégún baba rẹ̀. Àwọn ohun tí Ifá pa láṣẹ ètùtù náà ni ẹgbẹ̀rin àkàrà, ẹgbẹ̀rin ẹ̀kọ, ẹgbẹ̀rin pàsán àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹmu. Igbó tí wọn ti ṣe ètùtù náà ni a mọ̀ sí igbó ìgbàlẹ̀ di òní olónìí. Aláràn-án òfí tí ó jẹ́ ìyekan Ológbìín ni ó gbé aṣọ òdòdó tí baba Ológbìín tí ó ti kú ń lò nígbà ayé rẹ̀ bora, tí ó sì tún gbé abàmì ọmọ náà pọ̀n sẹ́hìn, tí ó sì ń jó bọ̀ wá sí àárín ìlú láti inú igbó náà pẹ̀lú ìlù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́hìn rẹ̀. Ológbìín ti fi lọ̀ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún baba òun tí ó ti kú nítorí náà nígbà tí wọ́n rí Aláràn-án Òrí nínú aṣọ òdòdó, wọ́n ṣe bí Ológbìín tí ó ti kú ni, pàápàá tí abàmì ọmọ tí ó pọ̀n dà bí iké ẹ̀hìn rẹ̀. Àwọn ènìyàn ń sún mọ́ ọn láti wò ó dáadáa ṣùgbọ́n pàṣán tí wọ́n fi ń nà wọ́n kò jẹ́ kí wọn sì wọ ilé baba Ológbìín tí ó ti kú lọ. Bí àwọn ènìyàn ti ń wò ó ni wọ́n wí pé: “Ẹ wo begun ẹni tó kú ti gún tó! Egungun náà gún lóòótọ́! Egungún gún! Egungún gún!” Báyìí ni àrá ọ̀run náà ṣe ṣe káàkiri ìlú tí ó sì ń súre fún àwọn ènìyàn. Nígbà tí ó sì ṣe ó wọ káà lọ. Wọ́n sì pe Ato kí ó máa tọ́jú abàmì ọmọ náà. Wọ́n sì ń pe abàmì ọmọ náà níOlúgbẹ̀rẹ́ Àgan. Nínú káà yìí ni Ògògó tí ó jẹ́ ọkọ Ato, ti ń wo ọmọ náà nígbàkúùgbà. Àwọn ènìyàn inú ilé a sì máa pe Ògògó ní Alàgbọ̀ọ́-wá1. Alágbọ̀ọ́-wá yìí ni ó sì di Alágbàá (baba Maríwo) títí di òní olónìí. Odù Òwọ́nrínsẹ̀ náà nìyí: “Arúkí, Arùkú, Aròkú-rọjà-má-tà. Òkú tá a gbé rọjà tí ò tà; 1. Ìtumọ̀ èyí ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó wá. La gbé sọ sígbó. Òun la tún gbé wálé, Tá a daṣọ bò, Tá a ń pè léégún. A dÌfá fún Ọ̀wọ́nrín Ìsányín Tó kú tí àwọn ọmọ rẹ̀ Kò rówó sin ín.1 Bí a bá sì tún wo oríkì eégún, ọ̀rọ̀ nípa bí eégún ṣe kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ yóò túbọ̀ tún yé wa sí i. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀, oríkì ni ọ̀rọ̀ tí ó júwe ìwà, ìṣe2 àti Ìtàn ìbí àwọn òrìṣà, ènìyàn àti àwọn nǹkan mìíràn. Oríkì Egúngún náà lọ báyìí: “Egúngún Ajùwọ́n, Lùkùlùkù gbúù-gbúù! A-rágọ̀ gbálẹ̀, Egúngún kìkì egungun T’Ògògó! Òkú yìí gbérí! Ẹni ará kan Tí ń jí jó awo. 1. Adédèjì, J.A. The Alárinjó Theatre. The Study of a Yorùbá theatrical Art from its Origin to the Present Times. Ph.D. Thesis (University of Ibadan 1969). Pp. 60-88. 2. Babalọlá, A Àwọn Oríkì Orílẹ̀, pp. 11. Ọ̀ṣọ̀ràn lokùn ń dè lÁgburè. Ìgbà tí n kò ṣòràn okùn, Kí lẹ mókùn so mí lápá sí? Ọmọ kẹ́kẹ́ mo ṣá, Mo mú ṣèwe lÁgburè. Gọ̀ǹbọ̀ ni mo wà, Mo mú ṣèwe nIgbórí1 ‘Torí Ìgbórí mi lỌ̀yọ́ Mọ̀kọ. Baba Arúkú, Baba Arùkú, Baba Aròkú-rọjà-ma-tà. Òkú tá a gbé rọjà Tá ò tà, Òun la dáṣọ fún Tá à ń pè léégún. Ikú ‘i lÓdò. Ọmọ atòkú jẹun, Ọmọ atáyé solẹ̀ nÍgbàlẹ̀. Baba Ato kékeré A-bẹnu wẹ́jewẹ́jẹ.2 Báyìí a ti mọ̀ bí eégún ṣe kọ́kọ́ dé inú ayé nígbà ìwáṣẹ̀. 1. Àwọn Tápà ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. 2. Adédèjì, J.A. The Alárìnjó Theatre; (The Study of a Yorùbá Theatrical Art from its Origin to the Present Times.) Ph.D. Thesis (University of Ibadan 1969). Pp. 60.88. Ṣùgbọ́n láyé òde òní ń kọ́? Báwo ni a ṣe ń ‘ṣẹ́’ eégún? Ó ṣòroó sọ pàtó pé kò níí sí ìyàtọ̀ díẹ̀ láti ìlú dé ìlú lórí ọ̀rọ̀ bí a ṣe ń ‘ṣẹ́’ eégún. Ṣùgbọ́n bí ìyàtọ̀ kàn tilẹ̀ wà náà, kò pọ̀ rárá. Mo léèrò wí pé àwọn obìnrin kò ní í mọ ìdí abájọ. Obìn in a sì máa mọ awo, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá tilẹ̀ mọ ọ́n, wọn kò gbọdọ̀ wí. Àgbàlagbà Ọ̀jẹ̀ nikan ni wọ́n ń ‘sẹ́’ eégún rẹ̀ bí ó bá kú. Bí a bá ti fẹ́ ‘ṣẹ́’ eégún ẹni tí ó ti kù yìí, a ó wá pàsán1 mẹ́ta, a ó wá aṣọ fúnfún tí ó tóbi, a ó tún wá ẹni tí kò sé kò yẹ̀ gíga ẹni tí a fẹ́ ‘ṣẹ́’ eégún rẹ̀ náà. Ìtàn sọ fún mi pé láyé àtìjọ́, tí wọ́n bá pe òkú Òjẹ̀ nígbà tí wọn kò bá tíì sin ín, pé ó maa ń dáhùn tí yóò sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n eke ti dáyé, aáṣà ti dÁpòmù, nǹkan ò rí bí í ti í rí mọ́ nítorí pé a kò lè ṣe é bí a ti í ṣe é tẹ́lẹ̀. Bí àwọn èròjà tí a kà sílẹ̀ wọ̀nyí bá ti dé ọwọ́ àwọn àgbà Òjẹ̀, a ó mú ọkùnrin tí kò sé kò yẹ̀ gíga òkú Òjẹ̀ náà lọ sínú igbó ìgbàlẹ̀. Àwọn àgbà Ọ̀jẹ̀ nìkan ni wọ́n lè mọ ẹni náà. Lẹ́hìn èyí, àwọn Òjẹ̀ yókù àti àwọn ènìyàn yóò máa lu ìlù eégún ní ibi tí wọn ti pa pẹrẹu lẹ́bàá igbó ìgbàlẹ̀ náà. Ọ̀wẹ́wẹ́2 ni ìlù tí a ń wí yìí. Tí wọ́n bá ti ń lu ìlù báyìí, àgbà Ọ̀jẹ̀ kan yóò máa mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú pàṣán yẹn, yóò 1. Òpá àtòrì tí a fi irin gbígbóná ṣe ọnà sí lára tí àwọn tí ó máa ń tẹ̀lé eégún lọ sóde fi ń na ènìyàn. 2. Aparun tàbí igi tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, tí a sì ṣe é pelẹbẹ pẹlẹbẹ̀. Sì máa fin a ilẹ̀ lẹ́ẹ́mẹ́ta mẹ́ta. Bí ó bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni yóò máa pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà tí a sì fẹ́ ‘sẹ́’ eégún rẹ̀ yìí. Nígbà tí ó bá ti fi pàṣán kẹta na ilẹ̀ lẹ́ẹ́kẹ́ta tí ó sì tún pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà, ẹni tí ó ti wà nínú igbó ìgbàlẹ̀ yóò dáùn, yóò sì máa bọ̀ pẹ̀lú aṣọ fúnfún báláú lọ́rí rẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò sì máa yọ̀ pé baba àwọn dáhùn, pé kò tilẹ̀ kú rárá. Bí babá bá ti jáde báyìí ni àwọn ènìyàn yóò máa béèrè oríṣìíríṣìí nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, tí baba náà yóò sì máa dá wọn lóhùn. Nígbà tí ó bá ti jó dáadáa fún ìgbà díẹ̀, yóò súre fún àwọn ènìyàn kí ó tó padà bá inú igbó ìgbàlẹ̀ lọ. Bí eégún ṣe ń jáde lóde òní nìyí ní ìlú Oǹdó. BÍ EÉGÚN ÀTI ÒGBÉRÈ EÉGÚN ṢE DÉ ÌLÚ OǸDÓ Gẹ́gẹ́ bí yóò ti hàn níwájú, kì í ṣe èdè tí àwọn ará Oǹdó ń fọ̀ lẹ́nu ni wọ́n fi ń kógbèérè: èdè Ọ̀yọ́ ni wọ́n ń lò. Èyí jẹ́ ìtọ́kasí kan láti fi hàn pé láti Ọ̀yọ́ ni eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ kí ó tó tàn ká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá. Ní ayé àtijọ́, nígbà tí ogun àti ọ̀tẹ̀ pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ogún kó láti ìlú kan dé òmíràn. Àwọn mìíràn lè ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kí wọn ó sì padà sílé nígbà tí wọn bá ti ra ara. Àwọn mìíràn a tilẹ̀ kúkú jókòó sí ìlú náà wọn a sì fẹ́ Ìyàwó níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ àṣà kò ṣeé fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò gbàgbé ẹ̀sìn wọn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé e
Eégún
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2281
2281
Rárà Rárà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ewì àbáláyè ni ilẹ́ ẹ̀ Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí mo tí ṣe ṣe àlàyé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, agbègbè Ìbàdàn àti Ọ̀yọ́ ni irú ewì báyìí tí wọ́pọ̀. Òun ni ọ̀kan nínú àwọn ewì `tí a máa ń fi ń yin ẹnikẹ́ni tí a bá ń sun ún fún yálà ní ìgbà tí ó bá ń ṣe ìnáwó tàbí àríyá kan. Bí ó ti jẹ́ ohun tí a fí ń yin ènìyàn náà ni ó tún jẹ́ ohun tí a lè fi pe àkíyèsí ènìyàn sí ìwà àléébù tí ó ń hù. Bákan náà, rárà jẹ́ ọ̀nà kan tí a fi máa ń ṣe àpọ́nlé ènìyàn ju bí ó tí yẹ lọ, nígbà tí a bá sọ pé ó ṣe ohun tí ó dà bí ẹni pé ó ju agbára rẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ ni a máa ń bá pàdé nínú un rárà ó sì dà bí ẹni pé àwọn orúkọ wọ̀nyí jẹ́ orúkọ àwọn ẹni àtijọ́ tí ó jẹ́ bí i baba ńlá ènìyàn tí ó ṣẹni sílẹ̀. Nítorí pé ọ̀rọ̀ iyìn àti ẹ̀pọ́n la máa ń bá pàdé nínú un rárà, èyí máa ń mú inú àwọn ènìyàn tí ó bá ń gbọ́ rárà náà dùn, orí a sì máa wu. Ní ààrin orí wíwú àti yíyá báyìí ni àwọn ènìyàn tí à ń sun rárà fún yíò tí máa fún àwọn asunrárà náà ní ẹ̀bùn tí wọn bá rò pé ó tọ́ sí wọn. Rárà sísun báyìí pé oriṣI méjì tàbí mẹ́ta ni agbègbè ibi tí wọn ti ń suún. OríṣI kan ni àwọn èyí tí obìnrin-ilé máa ń sun. tí àwọn obìnrin ilé wọ̀nyí kò ń ṣe gbogbo ìgbà. Ìgbà tí ọmọ-ilé kan ọkùnrin tàbí ọmọ-osu, tàbí ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó ilé bá ń ṣe ìnáwó ni wọn tóó sun ti wọn. OríṣI kejì nit i àwọn ọkùnrin tí ó máa ń lu ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn ẹni kẹta ni àwọn ọkùnrin tí kò ń lú sí tiwọn. II. ÌGBÀ TÍ A MÁA Ǹ SUN RÁRÀ Jákèjádò ilẹ̀ ẹ Yorùbá, ó ní ìgbà tí a máa ń sába ń kéwì. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ àti bí òwe àwọn Yorùbá tí ó sọ wí pé “Ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán”, bákan náà ni fún rárà, a kì í déédé sun rárà láìjẹ́ pé ó ni nǹkankan pàtàkì tí à ń ṣe. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i àti bí a ṣe gbọ́ láti ẹnu àwọn asunrárà tí a wádìí lọ́dọ̀ ọ wọ́n, àwọn àsìkò tí a máa ń sun rárà jẹ àsìkò ti a bá ń ṣe àríyá tàbí àjọyọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn asunrárà Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́ tí wo, ó jẹ́ ìwá àti ìṣe wọn láti máa lọ̀ ọ́ sun rárà fún Aláafìn ní àǹfin rẹ̀. Lẹ́hìn ti ààfin sísun fún yìí, wọn a tún máa sún tẹ̀lé ọba yìí bí ó bá ńlọ sí ìdálẹ̀ kan. Wọ́n ń ṣe èyí kí àwọn ẹni tí ọba náà kọjá ni ìlú u wọn lè mọ́ ẹni tí ń kọjá lọ. Ní ìlú Ọ̀yọ́ àti Ìbàdàn, ó dà bí ẹni pé a ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún rárà sísun yìí. Ọjọ́ yìí ní à ń pè ní ọjọ́ ọ Jímọ́ọ̀ Ọlóyin. Ọjọ́ yìí máa ń pé ní ọjọ kọkàndílọ́gbọ̀n sí ara wọn. Ọjọ́ yìí ni á gbọ́ pé ó ṣe pàtàkì nínú ìkà oṣù àwọn Yorùbá. Ọjọ́ yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé wá sí ààrin ìlú láti oko tí wọ́n ń gbé yálà láti wá ṣo ìpàdé e mọ̀lẹ́bí tàbí láti wá ṣe ohun pàtàkì míràn. Ní ọjọ́ yìí, àwọn ènìyàn máa ń pọ̀ nínú ìlú jú bí ó ṣe máa ń wà tẹ́lẹ̀ lọ. Ní Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ Jímọ́ọ̀ Olóyin yìí, àwọn asunrárà náà yíò máa káàkiri ilé awọn Ọ̀yọ́ Mèsì àti àwọn ìjoyé ìlú yókù. Lẹ́hìn ti èyí wọn ó padà sí àafin láti wá jókòó sí ojú aganjú. Níhìín ni wọn yíò tí máa sun rárà kí gbogbo àwọn àlejò tí ó bá ń lọ kí Aláàfin. Wọ́n ń ṣe èyí láti lè rí ẹ̀bùn gbà lọ́wọ́ àwọn àlejò náà; àti láti lè jẹ́ kí Aláàfin mọ irú àlejò tí ń bò. Bákan náà a gbọ́ pé ní ayé àtijọ́ ní ìgbà tí ogun wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, àwọn jagunjagun máa ń ní asunrárà tí í máa sun rárà tẹ̀ lé wọn bí wọn bá ńlọ sí ogun1. Mo rò pé wọ́n ń ṣe èyí láti lé fún àwọn jagunjagun náà ní ìṣírí. Bákan náà wọ́n a tún máa sọ fún wọn bí ó ti ṣe yẹ kí wọ́n ṣe lójú ogun. Lẹ́hìn ti kí a sún rárà fún àwọn ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí a tún ń sun rárà jẹ́ àwọn àsìkò ìnáwó tàbí àríyá. Ni ìgbà tí ènìyàn bá ń ṣe Ìgbéyàwó àwọn onírárà a máa sun rárà fún onínàwó náà. Fún àpẹẹrẹ ni ibi ìyàwó tí àwọn obìnrin bá ń sun rárà fún ẹni tí ń gbé Ìyàwó náà wọn ó máa wí báyìí: Ẹ mọ̀mọ̀ ṣeun mì o Torí ẹni tó ṣúpó Opó laá póṣú Èèyàn tó gbẹ̀gbà, Aá pé n bẹ́gbà ló gbà. Ògo dodo nìyàwó alẹ́ àná, Ọmọ ‘Bísí Adé. Ọmọ lójúu Lájùnmọ̀kẹ́, Ọmọ Gẹ́gẹ́ọlá, Abiamọ ọ̀ mi Àjàmú, Ẹní gbé ‘yàwó ṣògo dodo”, Ìgbà tí a tún máa ń sun rárà ni ibi ìnáwó ìsọmọ lórúkọ. Irú ìsọmọlórúkọ yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a ṣe tìlù tìfọn. Bákan náà bí a bá ń sin òkú àgbàlagbà ó lè jẹ́ ìyá, bàbá, tàbí ẹ̀gbọ́n ẹni. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ibi tí a bá gbé ń ṣe nǹkan tí ó lè mú ìdùnnú lọwọ, yálà ilé ṣíṣí ní tàbí ìwuyè ni a ti i máa ń rí àwọn asunrárà. Ní ayé ìsin yìí a tún máa ń rí àwọn asunrárà nì ìgbà tí àwọn ènìyàn bá ń ṣe ọdún. Nínú ọdún iléyá ti àwọn mùsùlùmí tàbí ọdún un kérésìmesì tí àwọn onígbàgbọ́, àwọn onírárà a máa káàkiri ilé àwọn ẹlẹ́sìn wọ̀nyi, láti kí wọn kú ọdún nípa rárà sisun. Àwọn ọlọ́dún wọǹyí yìò sì máa fún àwọn asunrárà náà lẹ́bùn. Àwọn asunrárà ọkùnrin tí ó máa ń fi rárà ṣe iṣẹ́ ṣe ni wọ́n máa ń ya ilé kiri láti sun rárà.
Rárà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2284
2284
Apiiri Apiiri E.I. Oso E.I. Ọ̀ṣọ́ (1979), ‘Àpíìrì’, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria. Eré àpíìrì jẹ́ ohun tí ó ní orin, ìlù àti ijó nínú. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, erée pelebe ni ó di àpíìrì níwọ̀n ìrínwó ọdún sẹ́hìn. Ìjerò-Èkìtì ni eré àpíìrì yìí ti bẹ̀rẹ̀. Ìtàn fi yé wa pé wọn mọ̀ ọ́n fúnra wọn ni, kì í ṣe wí pé wọ́n mú un wá láti Ilé-Ifẹ̀ tí ó jẹ́ orírun Yorùbá. Eré yìí bẹ̀rẹ̀ ní àkókó tí àwọn ará Ìjerò mú Alákeji jọba dípò ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ó jẹ́ ọba. Ìtàn fi yé wa pé nígbà tí ogun àti ọ̀tẹ̀ yí ìlú Ìjerò ká, ẹ̀gbọ́n Alákeji tí ó jẹ́ ọba wá gbéra láti lọ wá ọ̀nà tí wọn yíò fi ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn ká. Nígbà tí àwọn ará ìlú kò tètè rí i, wọ́n gbèrò láti fi àbúrò rẹ̀ Alákeji jọba. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n Alájeji wá padà, ó rí i pé wọ́n ti mú àbúrò òun jọba. Ó ka gbogbo ètùtù tí wọ́n ní kí ará ìlú ṣe láti lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn káàkiri. Ìtàn yìí náà ni ó fi yé wa pé kò torí èyí bínú kúrò ní ìlú. Ó sọ fún àwọn ará ìlú pé kí wọn máa ṣe eégún fún òun lákòókò ọdún Ògún fún ìrántí òun, kí wọn sì máa ṣeré àpíìrì tí egúngún yìí bá jáde. Lẹ́hìn èyí ni eré àpíìrì ti bẹ́rẹ̀ ní ìlú Ìjerò-Èkìtì. Àwọn alápìíìrì tí ó ti dolóògbèé ni Ọ̀gbẹ́ni Àṣàkẹ́ Ìwénifá, Ajórùbú, Àjàlá, Olóyè Ọsọ́lọ̀ Òkunlọlá, Afọlábí Ọ̀jẹ̀gẹ̀lé. Àwọn eléré àpíìrì tí ó tì ń ṣeré ní Ìjerò báyìí ni Èyéọwá Ọmọyẹyè, S.O. Fómilúsì tí ó sọ ìtàn bí eré àpíìrì ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Ìjerò-Èkìtì. Gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹnu bà á ní ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, ìbágbé pọ̀ àwọn èèyàn ni ó mú eré àpíìrì tàn kálẹ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì. Èèyàn méjọ sí mẹ́wàá ni ó sábà máa ń ṣeré àpíìrì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn mẹ́rin péré ni í máa ń lu ìlù. Ohùn méjì pàtàkì ni a ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. Èkíní ni ohùn pàtàkì ni a ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. Èkíní ni ohùn alámọ̀, tó sábà máa ń jáde lẹ́nu nígbà tí eléré àpíìrì bá fẹ́ salámọ̀. Èyìí fẹ́ jọ ohùn arò. Ohùn orin ni èkejì tí a máa ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. Lítíréṣọ̀ aláfohùnpè ni eré àpíìrì. Eré yìí sábà máa ń ní olórí tí yíò máa dá orin, tí àwọn yòókù yíò máa gbè ti ìlù bá ń lọ lọ́wọ́. Ẹni tí ń lé orin yìí lè ṣe ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tàbí ènìyàn méjì lápapọ̀ láti lè fi ohùn dárà nínú orin lílé. Nígbà míràn, ó lè ṣe ẹni tí ń dá orin náà ni yíò máa salámọ̀ láàrin eré, ó sì tún lè jẹ́ ènìyàn méjì yàtọ̀ sí àwọn tí ń dárin. Kíkọ́ ni mímọ̀ ni ọ̀rọ̀ eré yìí. Ẹni tí kò kọ́ ìlù eré àpíìrì tàbí orin rẹ̀ kò lè mọ̀ ọ́n. Àwọn eléré àpíìrì máa ń ronú láti lè mú kí wọn mú oríṣìíríṣìí ìrírí wọn lò nínú orin wọn. Èyí fi ìdàgbàsókè ti ń dé bá eré àpìírì hàn. Ní àtijọ́ ọdún Ògún ni eré àpíìrì wà fún, ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé yíyí ni ayé ń yi, àwọn òṣèré náà wá ń báyé yí nípa pé kí wọn ṣẹ̀dá orin àpíìrì fún onírúurú àṣeyẹ tí a ó mẹ́nu bà níwáju. Eré àpíìrì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ àti òye tí ó fi ọgbọ́n, ìrònú, àkíyèsí, èrò, èèwò àti ìgbàgbọ́ àwa Yorùbá hàn. Àwọn ohun tí ó ya eré àpíìrì sọ́tọ̀ sí eré ìbílẹ̀ míràn ni, irúfẹ́ ìlù tí a ń lò fún eré yìí, ọ̀nà tí a ń gbà kọ orin àpíìrì àti bí ìlù tí a ń lò ṣe ń dún létí. Nǹkan mìíràn tí ó tún ya eré yìí sọ́tọ̀ sí òmíràn nip é agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì nìkan ni a ti ń ṣe irú eré yìí ní gbogbo ilẹ̀ káàárọ̀-oò-jíire. Àwọn ohun tí a ń lò bí ìlù nínú eré àpíìrì láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá ni agbè tí ajé wà lára rẹ̀. Agbè àti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ jẹ́ ohun èlò ìlù lílù àti ijó jíjó tí a dá sílẹ̀ ní àkókò Ẹ́mpáyà Bìní. Àwọn Ẹ̀gùn àti Pópó ni ó dá a sílẹ̀ ní àkókò ọba Oníṣílè. Agogo náà tún jẹ́ ọ̀kan nínú ohun èlò eré àpíìrì. Àwọn agbè tàbí ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ̀nyí máa ń tóbi jura wọn, kí dídún wọn bàá lè yàtọ̀ síra. Orúkọ tí a ń pe ajé tàbí agbè wọ̀nyí ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì ni, Èyé ajé tàbí Èyé ùlù, kugú, ọ̀pẹẹẹrẹ àti agogo. Bí àwọn agbè wọ̀nyí ṣe tóbi sí ni a ṣe fún wọn lórúkọ. Wọn máa ń lo ìrùkẹ̀rẹ̀ láti jó ijó àpíìrì. Ìdàgbàsókè tí ń dé bá ohun èlò eré àpíìrì. Ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn. Àwọn Yorùbá ló ń pà á lówe pé, ‘báyé bá ń yí ká báyé yí, bígbà bá ń yí ká bá ìgbà yí, ìgbà laṣọ, ìgbà lẹ̀wù, ìgbà sì ni òdèré ikókò nílè Ìlọrin.’ Nísìsíìyí, arábìnrin Adépèjì Afọlábí tí ó jẹ́ eléré àpíìrì ní Ìdó-Èkìtì ti mú ìlù Bẹ̀mbẹ́ àti àkúbà mọ́ agbè àti agogo tí a ń lò tẹ́lẹ̀ nínú eré àpíìrì. Àwọn olùgbọ́ kó ipa pàtàkì nínú eré àpíìrì tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú Lítíréṣọ̀ aláfohùnpè. Àwọn olùgbọ́ máa ń gbe orin pẹ̀lú àwọn òṣèré. Wọn a máa jó, wọn a sì máa pa àtẹ́wọ́ tí erá bá ti wọ̀ wọ́n lára. Irú ìtẹ́wẹ́gbà báyìí sì máa ń mú kí ọ̀sèré túbọ̀ ṣe eré tí ó dára lójú agbo. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí mo ṣe ṣáájú, ọ̀nà tí àwọn alápíììrì ń gbà ṣe eré wọn ni kí olórí eré máa lé orin fún àwọn elégbè tí yíò máa gbe orin tí ó bá dá. Olórí lè kọ́kọ́ kọrin kí alámọ̀ tẹ̀lé e tàbí kí ó kọ́kọ́ salámọ̀ kí ó tó kọrin. Kò sí bátànì kan pàtó tí alápìíìrì gbọ́dọ̀ tẹ̀lé nínú eré nítorí pé bí ó bá ṣe wuni ni a ṣe ń ṣèmọ̀le ẹni Ní àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí, alámọ̀ ni eléré àpíìrì yìí fi bẹ̀rẹ̀ erée rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wò ó. Lílé (Alámọ̀) – Ò rì polóó ùdín ria Ọ̀bà ǹ bá e mú, kán an síì Mú un titun barun ùn Láiún ùgbín rẹ̀ pẹgbẹ̀fà An máiun rẹ̀ pegbèje lúléè mi, Ọ karee o, Mè í múléè ni, Mẹ́ mọ̀ búyà kànkàn í rè
Apiiri
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2286
2286
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà Ìjèbú-Jèṣà je ilu ni ile Naijiria ati oluilu agbegbe ijoba ibile Oriade ni Ipinle Osun. Oríṣìíríṣìí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a ti gbọ́ nípa ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé yóò dín. Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn náà sọ pé: Ọwà Iléṣà kìíní Ajíbógun àti Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kìíni, Agírgírì jẹ́ tẹ̀gbọ́n tábúrò. Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni ẹ̀gbọ́n tí Ọwá sì jẹ́ àbúrò. Bákan náà, tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni ìyá tí ó bí wọn. Láti ọmọomún ni ìyá Ajíbógun Ọwá Iléṣà ti kú Ìyá Agígírì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ló wò ó dàgbà, ọmún rẹ̀ ló sì mún dàgbà. Nípa bẹ́ẹ̀ Ọwá Ajíbógun àti Agígírì jọ dàgbà pọ̀. Èyí ló mú kí wọn di kòrí-kòsùn ara wọn láti kékeré wá, wọn kí í sì í yara wọn bí ó ti wú kí ó rí. Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji-Agígírì àti ajíbogun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọn wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣa láti dó sí kí wọn lè ni àyè ijọba tiwọn. Ajíbogun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónìí yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírì rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbùrò òun kò mọ̀ wí pé nǹkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín. Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbúrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọdọ̀ jìnná sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé aginjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pè ibi tí òun ti rìn ti nàsẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí. Kì wọn tó kùrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fún un ní ọgbọn nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọn, òun lè dáàbò bo ara òun, ò sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé; “Ijẹ̀ṣà ọgbọ̀n Ijẹ̀bú ogún É sìí bó ṣe a rí Kógún a parẹ́ mọ́gbọ̀n lára” Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírì àti Ajíbógun ni Ilé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lè ríran padà ó lọ, Ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohun ìní bàbá wọn líifi nǹkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran. Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀) bàbá rẹ̀. ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fun un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú irin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lórí àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀. Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyà yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrò pọ̀ láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn sì wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn. Itán sọ pé Ibòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọna Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà sì gba Ilékéte lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ si Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró: Agóró yìí ló dúró sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan patàki nínú àwọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sì iwájú díẹ̀ kí ó lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ràn Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Igbà ti Agígírì kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fun ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lonìí yìí. Iyàlẹnu ńlánlà lọ́ jẹ́ fún Agígírì láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lù àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí ti ibẹ̀ dùn mọ́ on fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọdẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì a sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n isàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkònísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayó”. Agbo ilée Bajimọn ní Òkè -Ọjà ni Agígírì sọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́jìn èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gbà òtẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè Agígírì kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ilédè náà ní ibi tí Aàfin Ọba Ijẹ̀bú-jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí wọ́n múra láti ibé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Nikẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. “Ojú iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu tí ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ́ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n. Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ijẹ̀bù-Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bí-Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbà tí wón dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n pẹ̀rẹ̀sì í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mù ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n Igbà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ láti máa tọ́jú ogbà náà, wọ́n sì dúró pẹ́ dìẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wọ́n fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ìbẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilé. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn –Agígírì sọ ibẹ̀ ni IJẸLÚ nítorí pe ÌJẸ̀ ni Ìjẹ̀sà máa ń pe Ẹ̀JẸ̀. Nigbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ̀bú tí wọ́n ti ń pè tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní. Ṣùgbọ́n Ijẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́. Ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa. A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bu ti Ìjẹ̀bù –Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè má sí láàárin wọn nígbà kan ti rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu Ògbóni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú-Òde lọ. Ibẹ̀ ló gi mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó. Nínú àwọn ìtàn òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ijẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfẹ́ èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ijẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mi díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ògbóni. Itán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀. Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, Ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ ọ̀ọ́tó jù lọ nínú wọn. Nipa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ojọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nǹkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a sẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì kan náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti ajá tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárìn wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ìlẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nǹkán kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn. Tí Ọwá bá fẹ́ fi ènìyàn bọrẹ̀ láyé àtijọ́, Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀. Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilẹ̀ṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bu-Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Ilẹ́ṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Ilẹ́ṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọ̀n ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀. Idí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé; “Kàí bi an kọlíjẹ̀bú Níbi an tọ̀nà Ìjẹ̀sàá bọ̀ Ọtáforíjọja ọ̀nà ni an kọlijẹ̀bú Ọmọ Egbùrùkòyàkẹ̀” Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sì n jẹ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà a rí Ògbóni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara Ìwàrẹ̀fà mẹfà ni ògbóní méjèejì yí a ni Iléṣà ṣùgbọ́n ògbóni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. A rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà. Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí ti orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún apẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní ìléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú jèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ́lù. Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, àdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ. Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán. Tí ọ̀kan nínú wọn bá sì wàjà, ón ni ogún ti wọ́n máa ń jẹ lọ́dọ̀ ara wọn bí aya, ẹrú àti ẹrù. Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀nà tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. Nígbà tí ilẹ̀ Ilèṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́ún, àrìmọ-kùnrin Ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bù-Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójù ráyè, kí ó tó tùbà tùṣẹ. Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọbà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá àti Ògbóni Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn” Alaye sọ́kí lórí ìlú àti àwọn ènìyàn ìjẹ̀bù-jẹ̀ṣà Ìlù Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ ìlú kan pàtàkì ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yị́ ní Nàìjéríà. Apá ìwọ́ oòrùn ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ilẹ̀ Yorùbá tàbí káàárọ́ - oò- jíire. Ìlú Ilẹ́ṣà ti ó jẹ́ olú ìlú fun gbogbo ilẹ̀ jẹ̀ṣà jẹ́ nǹkan ibùsọ̀ mẹ́rìnléláàádọ́rin sí ìlú Ìbàdàn tí jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlú Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì tó nǹkan bí ibùsọ̀ mẹ́fà sí Iléṣà ní apá àríwá ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Ní títóbi, ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ó pọwọ́lé ìlú Iléṣà ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, òun si ni olú ìlú fún ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun ọ́un kí wọn tó tún un pín sí ọ̀nà mẹ́rin; síbẹ̀ náà òun ni olú ìlú fún ìjọba ìbìlẹ́ ààrin gùngùn obòkun. Àdúgbò márùnún pàtàkì ni wọ́n pín ìlú yìí sí kí bà lè rọrùn fún ètò ìjọ̀ba síṣe àti fúniṣẹ́ Ìlọ́rọ̀, Ọ̀kènísà àti Òdògo. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àdúgbò yí ló ní Olórí ọmọ tàbí lóógun kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ aṣáájú fún ọmọ àdúgbò rẹ̀ òun ní aṣáájú fún iṣẹ́kíṣẹ́ àti tí ó bá délẹ̀ láti ṣe ni àdúgbó, bẹ́ẹ̀ ni, ó sì tún jẹ́ aṣojú ọba fún àwọn ọmọ àdúgbò rẹ̀. Òdògo nìkan ni kò fi ara mọ́ èlò yí tó bẹ́ẹ̀ nítorí ìtàn tó bí i fi hàn pé ìlú ọ̀tọ̀ gédégédé ni òun. Àwọn ènìyàn ọ̀gbọ́n náà ń fẹ́ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbà ìwásẹ̀ ti fi hàn wí pé wọn kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Lòde òní, nǹkan ti ń yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nítorí pé àjọṣẹ tí ó péye ti ń wàyé láàárín ọ̀gbọ́n náà àti àwọn ọ̀gbọ́n yòókù. Ẹ̀rí tí ó fi hàn gbegbe pé àwọn Ìjẹ̀ṣà gba ìlù Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bi ìlú ti ó tẹ̀ lé Iléṣà ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni pé ìjókòó àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá ìlẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń yàn àn lé. Síwájú sí i, nípa ti ìlànà oyè jíjẹ, ó ní iye ọjọ́ tí Ọwá tuntun gbọ́dọ̀ lò ní Ijẹ̀bù - Jẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni ó máa ń gbé Ọwá lésẹ̀ tí ó sì máa ń ṣúre fún un kí wọn tó gbà á gẹ́gẹ́ bí ọwá àti olóri gbogbo ọba ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà. Láti túnbọ̀ fi pàtàkì ìlú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà hàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú ìtàn ìwásẹ̀, ti Ọwá bá fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún ọ̀daràn apànìyàn kan, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbódọ̀ wà níjòkó, bí èyí kò bà rí bẹ́ẹ̀, Ọwá gbódọ̀ sùn irú igbẹ́jọ́ tábi ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ sí ọjọ́ iwájú. Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe máa ń sọ pé “Ọwa ràà dáni í pa K Ìjẹ̀bu -Jẹ̀ṣà mọ mọ̀n Kọ́wá bá a pani Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà á gbọ́” Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ń ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó jẹ́ àgbẹ̀ alárojẹ, bẹ́ẹ̀ ni a tún rí àwọn tó mú àgbẹ̀ àrojẹ mọ́ àgbẹ̀ agbinrúgbìn tó ń mówó wọlé lọ́dọ́ọdún àti láti ìgbàdégbà. Àwọn irúgbìn tí wọ́n ń gbìn fún àrojẹ ni, iṣu, ẹ̀gẹ́ (gbáàgúdá) ikókó, ìrẹsì, àgbàdo, kọfí, òwù àti obì sì jẹ́ àwọn irù-gbìn tó ń mówó wálé fún wọn. A rí àwọn oniṣẹ-ọwọ́ bíi, alágbẹ̀dẹ, onílù. agbẹ́gilére, àwọn mọlémọlé àti àwọn kanlékanlé. Àwọn obìnrin wọn náà a máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́-ọwọ́, lára wọn ni aró dídá, apẹ ati ìkòkò mímọ àti aṣọ híhun pẹ̀lú. Bákan náà, wọ́n tún jẹ́ oníṣowò gidi. Ọmọ ìyá ni ẹlẹ́dẹ̀ àti ìmọ̀dò, bẹ́ẹ̀ náà sì ni inàki àti ọ̀bọ, gbogbo ibi tí a bá ti dárúkọ Ìjẹ̀ṣà ni a á ti máa fi ojú oníṣòwo gidi wò wọ́n. Elèyìí ni a fi ń pè wọ́n ní “Òṣómàáló” nítorí kò sí ibi tí a kó ti lè rí Ìjẹ̀ṣà ti ọ̀rọ̀ ìṣòwò bá délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí irúfẹ́ owo tí wọn kò lè ṣe, ohun tí ó kó wọn ni irìnra ni olé àti ọ̀lẹ. “Alápà má ṣiṣẹ́” ni àwọn Ìjẹ̀ṣà máa ń pe àwọn ti kò bá lè ṣiṣẹ́ gidi. Wọn ko sì fẹ́ràn irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ràrá. Ìjẹ̀ṣà kò kọ̀ láti kọ ọmọ wọn lọ́mọ tí ó bá jalè tàbí tí kò níṣẹ́ kan pàtàkì lọ́wọ́. Wọ̀n á sí máa fi ọmọ wọn tí ó bá jẹ́ akíkanjú tàbí alágbára yangàn láwùjọ. “Òkóbò nìkan ni kìí bímọ sí tòsí, a ní ọmọ òun wà ní òkè-òkun” Bákan náà ni pé “arúgbó nìkan ni ó lè parọ́ ti a kò lè já a nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ti kú tán” Purọ́ n níyì, ẹ̀tẹ́ ní ń mú wá, bi irọ́ ni, bí òótọ́ ni pé àwọn Ìjèṣà jẹ́ akíkanjú, ẹ wo jagunjagun Ògèdèngbé “Agbógungbórò” Ọ̀gbóni Agúnsóyè, “Ologun abèyìngọgọú, ó pẹ̀fọ̀n tán, ó wojú ìdó kọ̀rọ̀, Ọ̀dọ̀fin Arówóbùsóyè, Ọ̀gbọ́kọ̀ọ́ǹdọ̀ lérí odi kípàyẹ́ bì yẹ̀ẹ̀yẹ̀ẹ̀ séyìn” Ológun Arímọrọ̀ àti àwọn Olórúkọ ńláńlá ni ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Tí a bá tún wo àwọn oníṣòwò ńláńlá lóde òní nílẹ̀ Yorùbá jákèjádò, “Ọkan ni ṣànpọ̀nná kó láwùjọ èpè” ni ọ̀rọ̀ ti Ìjẹ̀ṣà. Nínú wọn ni a ti rí Àjànàkú, Erinmi lókun, Ọmọ́le Àmúùgbàǹgba bíu ẹkùn, S.B. Bákàrè Olóye méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àti Onìbọnòjé àtàri àjànàkù tí kì í ṣẹrù ọmọdé. Mé loòó la ó kà lẹ́hín Adépèlé ni ọ̀rọ̀ wọn. Àwọn ọmọ Ìjèbú -Jẹ̀ṣà jẹ́ aláfẹ́ púpọ̀ pàápàá nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Àwọn ènìyàn ti o fẹ́ràn àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ láàárin onílé àti àlejò sì ni wọ́n pẹ̀lú. Wọn máa ń pín ara wọn sí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìlú láti jọ kẹ́gbẹ́ àjùmọ̀ṣe lẹ́nu iṣẹ́ àti oríṣìíríṣìí ayẹyẹ nílùú pẹ̀lú. “Àjèjé ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dóri” àjùmọ̀ṣè wọn yìí mú ìlọsíwájú wá fún ìlú náà lọ́pọ̀lọ́pọ̀ “Abiyamọ kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kò má tatí were” ni ti àwọn ọmọ Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà sí ohunkóhun tí wọ́n bá gbọ́ nípa ìlú wọn. Bí ọ̀rọ̀ kan bá délẹ̀ nípa iṣẹ́ ìlú, wọn máa ń rúnpá-rúnsẹ̀ sí i, wọ́n á sì mú sòkòtò wọn wọ̀ láti yanjú irú ọ̀rọ̀ náà. Ọmọ ọkọ ni àwọn ọmọ ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ní tòótọ̀. Síwájú sí i, oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó bá òde òní mu ni wọ́n ti là sí àárín ilú láìní ọwọ́ ìjọba kankan nínú fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìlú wọn. Fún àpẹẹrẹ Ilé - Ẹ̀kọ́ gíga (Grammar Schoo) méji tí ó wà ní ilú náà, òógùn ojú wọn ni wọ́n fi kọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Modern School wọn. Ọjà ilú, ilé-ìfìwé rànṣẹ́ àti gbàngàn ìlú ti o nà wọn tó àádọ́ta àbọ̀ ọ̀kẹ́ naira: Àwọn ọ̀nà títí tí wọ́n bójú mu tí wọ́n sì bá ti òde òní mu náà ni wọ́n ti fi òógùn ojú wọn là láìsí ìrànlọ́wọ́ ìjọba kankan.
Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2291
2291
Ẹfọ̀n-Alààyè Nínú àwọn ìwé ti mo yẹ̀ wò. kò sí èyí tó sọ pàtó ìgbà tàbí àkókò tí a dá ìlú Ẹ̀fọ̀m-Aláayè sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àbúdá ìtàn ìwáṣẹ̀. púpọ̀ nínú ìtàn yìí ló máa ń rújú pàápàá tó bá jẹ́ ìtàn ìtẹ̀lúdó ni ìlẹ Yorùbá. (Akínyẹmí 1991:121) Ìlànà ìtàn àròsọ ìwásẹ̀ ní a gbé ìtàn wọ̀nyí lé. Ní ìgbà ìwáṣè kò sí pé a ń kọ nǹkan sílẹ̀. Nítorí àìkọ sílẹ̀ ìtàn yìí, kò jẹ́ kì a rí àkọsílẹ̀ gidi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ibi tí ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ti jé ọ̀kan nínú awọn ìlú bẹ́ẹ̀. Ìtàn ti a rí jójọ kò kọjá ìtàn atẹnúdẹnu. ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayé kò yàtọ̀ sí èyí. Oríṣìí òpìtàn ni a rí, ìtàn wọn máa ń yàtọ̀ sí ara wọn, bí kò ní àfikún yóò ni àyọkúro ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí àwọn òpìtàn ti ṣiṣẹ́ lé lórí nípa ìtàn ilẹ̀ Aáfíríkà ni ìyànjú wọn lati wo ìtàn ìwáṣẹ̀, kí wọ́n tó lè fa òótọ́ yọ jáde. Ṣàṣà ni onímọ̀ kan tó ṣiṣẹ́ lórí ìtàn ìlú kan tàbí àdúgbò kan tí kò mú ìlànà ìtàn ìwáṣẹ̀ ló láti ṣàlàyé to bojumu nípa orírun ìlú kan (Johnson 1921;3). Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ilẹ̀ Yorùbá, àwọ òpìtàn ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayè gbà pé ọ̀dọ̀ odùduwà ni wọ́n tí ṣẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀. Lára àwọn òpìtàn yìí tilẹ̀ lérò pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó rọ̀ lati ojú ọ̀run sílé ayé. Ìlú tó sọ̀kalẹ̀ sí ní Ilé-Ifẹ̀ tó jẹ́ orírun àwọn Yorùbá. Ìtàn yìí ṣòro láti gbàgbọ́, nítorí kò ri ìdí múlẹ̀. Kò tí ì sí ẹni tí a rí tó wọ̀ láti ojú ọ̀run rí. Nínú ìtàn ìwáṣẹ̀, òrìṣà àti odù mẹ́rìndínlógún ni a gbọ́ pé wọ́n rọ̀ láti ìsálọ̀run wá sí ìsálayé (Abimbọla, W. 1968:15). Awọn òpìtàn yìí lè rò pé bóyá nítorí tí a ti ń pe àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá ni ìgbákejì òrìṣà ni àwọn náà ṣe rò pé Aláayè àkọ́kọ́ rọ̀ sílẹ́ ayé lati ọ̀run. ‘Ọmọ ọwá, ọmọ ẹkún Ọmọ òkìrìkìsì Ọmọ ọ̀ tójú ọ̀run á yé’ Nínu ìtàn ìwáṣẹ̀ mìíràn, a gbọ́ pé Ọbàlùfọ̀n Aláyémore ni ọba àkọ́kọ́ ti o tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó. Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ yìí jẹ́ ọmọ Ọbàlùfọ̀n Ogbógbódirin tí í ṣe àkọ́bí Odùduwà tí ó jẹ́ Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ ni àkókó ìgbà kan. Lẹ́yìn Ikú rẹ̀, Ọ̀rànmíyàn lò yẹ kí ó jẹ ọba ní Ilé-Ifẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti lọ sílùú àwọn ọmọ rẹ̀, Eweka ni Eìní ati Aláàfin ni Ọ̀yọ́. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ti jẹ oyè Ọọ̀ni kí Ọ̀rànmíyàn tó dé. Nígbà tí Ọ̀rànmíyàn dé, Aláyẹ́mọrẹ sá kúrò lórí oyè nítorí pé ní ayé àtijọ́ wọn kì í fi ẹni ìṣááju sílẹ̀ láti fi àbúrò joyè. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ rìn títí ó fi dé orí òkè kan. Wọn pe ibẹ̀ ni Ọba-òkè. Èyí ni ọba tó tẹ̀dó sorí òkè ṣùgbọ́n lónìí ọ̀bàkè ni wọn ń pe ibẹ̀. Ni orí òkè yìí, Ọbàlùfọ̀n ṣe àkíyèsí pé ẹranko búburú pọ̀ ní agbègbè tó tẹ̀dó sí, èyí tó pọ̀jù ni ẹfọ̀n. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ẹfọ̀n yìí ni àparun. Awọn ẹfọ̀n kékeré níbẹ̀ ni wọn kójọ sínu ọgbà, ti wọn so wọn mọ́lẹ̀ títí wọ́n fi kú. Ọmọdé tó bá lọ sì igbó ibi tí wọ́n kó ẹfọ̀n kékeré sí, ni awọn òbí wọn a ké pé: ‘Kọ́ ọ̀ yàá ṣe lúgbó ẹfọ̀n alaayè’ Nibi yìí ni Ẹ̀fọ̀n ti kún orúkọ Ọbalufọn Aláyémọrẹ. Lára Aláyémọrẹ ni wọn tí yọ Aláayè to fid i: Ẹ̀fọ̀n-Aláayè títí dí òní. Nígbà tí ó ṣe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ránṣẹ́ sí Ọ̀rànmíyàn kí o fi nǹkan ìtẹ̀lúdó ṣọwọ́ sí òun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi nǹkan yìí ránṣẹ́ sí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ; kò pẹ́ ti Ọ̀rànmíyàn kú. Àwọn ará Ilé-Ifẹ̀ wá ránṣẹ́ si Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ láti wá jọba lẹ́ẹ̀kejì. Kí o tó lọ, ó fí ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀. Ìyàwó mẹ́ta ni Aláyémọrẹ ni kí ó tó kúrò ní Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Àwọn ni Adúdú Ọ̀ránkú tí ì ṣe ìran àwọn Obólógun; Aparapára ọ̀run ìran awọn Aṣemọjọ, ẹ̀ẹ̀kẹta ni Èsùmòrè-gbé-ojú-ọ̀run-sàgá-ìjà. Ìtàn sọ pé lásìkò tí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ padà sí Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni, bọ́ sí àkókò ti Ọba Dàda Aláàfin Ọ̀yọ́ wá lórí oyè ni nǹkan bí 1200-1300AD. Bí ìtàn ìwáṣẹ̀ yìí ìbá ṣe rọrún tó láti gbàgbọ́ awọn àskìyèsí kan ní a rí tọ́ka sí tí ó jẹ́ kí ìtàn náà rú ènìyàn lójú. Nínú ìtàn yìí, wọn sọ pé Ọbàlùfọ̀n Ògbógbódirin ni àkọ́bí Odùduwa, èyí tó tako ìtàn tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa Odùduwa. Ọ̀kànbí ni àkọ́bí Odùduwa. Bó bá tilẹ̀ ṣe orúkọ ló yípadà, àwọn ọmọ Ọkànbí ni ọba méje pàtàkì ni ilẹ̀ Yorùbá tí kò sí Ọbàlùfọ̀n nínú wọn. Ohun tí òpìtàn ìbá sọ fun wa nip é ìran Odùduwà ni Ọbàlùfọ̀n jẹ́. Àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ rú ni lójú púpọ̀. Nínú ìtàn yìí a ri i pe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ mọ àsìkò ti Ọ̀rànmíyàn wà láyé. A rí i pé ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ni wọn. Kó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó jẹ ọmọ àti bàbá. Lóòótọ́ ni Ọ̀rànmíyàn jẹ ọba ni Òkò, tó tún wá sí Ilé-Ifẹ̀. Àwọn ará Ọ̀y;ọ ló fi Àjàká jẹ ọba sí Òkò. Aláàfin Dada tí òpìtàn fẹnu bà pé ó jẹ ọba ní Ọ̀yọ́ da ìtàn rú. Johnson (1921:144) gbà pé Àjàká ló wá lórí oyè gẹ́gẹ́ bí Aláàfin Ọ̀yọ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn kú. Tó bá jẹ́ òtítọ́ ní Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ tún wa jọba lẹ́ẹ̀kejì ní Ilé-Ifẹ̀ a jẹ́ pé àsìkò Aláàfin Àjàkáló jẹ ọba. Awọn òtìtọ́ kọ̀ọ̀kan farahàn nínú ìtàn yìí. Lóòótọ́ ni Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ kan wá ni Ilé-Ifẹ̀. Títí dí oní ọ̀gbọ́n Ọbàlùfọ̀n wa ní Ilé-Ifẹ̀. Àdúgbò Aláayè si wa ní Ilé-Ifẹ̀ títí dí òní. Kò sí irọ́ níbẹ̀ pé Ẹ̀fọ̀n Aláayè bá Ilé-Ifẹ̀ tan. Nínú ìtàn mìíràn, a gbọ pé àwọn oríṣìí ènìyàn bí i mẹ́fà ni wọ́n tẹ̀dó lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Nínú ìtàn yìí, a gbọ́ pé Èkúwì ló kọ́kọ́ dé sílùú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, igbó-àbá ni Èkúwì tẹ̀dó sí. Ọdẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oríkin náà tẹ̀dó sí Igbó àayè. Lọ́jọ́ kan, lásìkò tí oríkin tẹ̀dó, ó rí iná tó ń rú ni Igbó-Àbá. Ó ṣe ọ̀dẹ lọ sí igbó yìí. Oríkin rọ àwọn tó wa ni Igbó àbá kí wọn jọ má gbé ní Igbó-Àayè. Wọ́n gbà bẹ́ẹ̀. Lásìkò tí wọn jọ ń gbé ni wọn fí Ọbàlùfọ̀n jẹ ọba. Igbákejì Ọbàlùfọ̀n tí wọ́n jọ wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní wọn fi jẹ igbákejì ọba tí a mọ̀ sí Ọbańlá. Bàbá Igbó Àbá ọjọ́sí ni wọn fi jẹ baba ọlọ́jà tí a mọ sí Ọbalọ́jà. Ọbàlùfọ̀n àti Ọbalọ́jà jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nígbà náà. Bí ọba ṣe ń pàṣẹ fún àayè ní Ọbalọ́jà ṣe n pàṣẹ ní Ọ̀bàlú láyé ìgbà náà. Lónìí, Ọbalọ́jà jẹ Olóyè pàtàkì ní ìlú Ẹ̀fọ̀n. Ọbalọ́jù ní olórí àwọn Ọ̀bàlú. Àjọṣe wá láàrìn Ọba àti Ọbalọ́jà. Bí ọba kan bá wàjà ní ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, iwájú ilé ọba-ọlọ́ja ni wọn yóò kó ọjà lọ. Nínú ìtàn mìíran a gbọ́ pé ààfin Odùduwà ni wọ́n bí Aláayè sí. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọba obinrin ló bii. O jẹ́ arẹwà okùnrin ti ènìyàn púpọ̀ fẹ́ràn rẹ̀ pàápàá àwọn babaláwo tó ń wá sí ààfin. Ìtàn yìí tẹ̀síwájú pé ọkùnrin yìí ní aáwọ̀ ni ààfin, èyí ló mú kí Odùduwà ṣe fún Aláayè ní ilẹ̀ sí ìráyè tí a mọ̀ sì Modákẹ́kẹ́ lónìí. Odùduwà fún un ni adé tó sì n jẹ́ Ọba Láayè. Nínú ìtẹ̀sìwájú, Ìtàn mìíràn tó fara jọ ìtàn òkè yìí, a gbọ́ pé àwọn ọmọọba méjì ló fẹ́ lọ tẹ ìlú dó. Bó ba rí bẹ́ẹ̀ á jẹ́ pé ìlú Ẹ̀fọ̀n tí wá kí Modákẹ́kẹ́ tó dáyé. Àtàdá ati Johnson tilẹ̀ maa ń to Aré àti Ẹ̀fọ̀n tẹ̀lé ara wọn. Ni pàtàkì, ogun kò ṣẹgún Ẹ̀fọ̀ Aláayè rí àyàfi Ogun Ọdẹ́rinlọ (1852-54). Ọdẹ́rìnlọ jẹ ọmọ Ìrágberí, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ni ìrágberí ti kúrò. A le sọ pe ọmọ bíbi Ẹ̀fọ̀n ló kó Ẹ̀fọ̀n-Aláayè kì í ṣe ọ̀tá nítorí òkè to yí wọ́n ká jẹ ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ fún ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, ó sì jẹ wàhálà fun ọ̀tá. Àwọn ọ̀tá to fẹ jà wọn lógun nígbó Òòyè, wọn ṣe lásán ni. Ogun yìí fà á ti Aláayè kì í fi jẹ osun ògògó titi dòní. Ohun àrífàyọ nínú ìtàn yìí nip é ọdẹ ló tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n dó gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú mìíran ni ilẹ̀ Yorùbá. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn mìíràn ń tẹ̀lé e wá sí ibi ìtẹ̀dó. Ó ṣe é ṣe bẹ́ẹ̀ nitori ibi ti ọdẹ máa ń tẹ̀dó sí kò ní jìnnà sí omit i ń sàn; àtipé yóò ti kó àwọn ẹran rẹ̀ jọ sí ojú ibi ìdáná. Ọja ló ṣéyọ láti ibẹ̀. A tún rí i pé ẹni tó jẹ ọba Ẹ̀fọ̀n gbé adé rẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀; ṣùgbọ́n àsìkò tó dé sí ibùdó yìí ni a kò mọ̀. Lóòótọ́, ẹni tó bá jẹ́ alágbára láyé àtijọ, tó sì ní àmúyẹ ni wọn fi i jọba, lẹ́yìn ti Ifá bá ti fọre. Kò yá wá lẹ́nu pé wọ́n fi ẹni tí adé ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ jẹ ọba nítorí àwọn ohun àmúyẹ ọba wà ni sàkání rẹ̀. Ní ìparí, Finnegan (1970:368) sọ nínú ọrọ rẹ pé: …they (myths) depict the deeds of human rather then supernatural heroes and deal with or allude to, events such as migrations, war, or the establishment of ruling dynasties. Èyí ni pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ti pẹ́, ó ń sọ nípa ènìyàn akọni àti awọn nǹkan to yi i ka bí ìrìnàjò láti ibi kan sí èkejì, ogun jíjà ati bí wọn ṣe tẹ ìlú dó. Encyclopaedia Britanica (1960:54) ṣàlàyé pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ìtàn nípa àṣà tí ó ń ṣàlàyé nípa ènìyàn, ẹranko, òrìṣà àti ẹ̀mí àìrí. Irú ìtàn yìí kì í sọ àkókò gan-an tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹ́ ṣùgbọ́n wọn jẹ́ kí ìtàn ní kókó àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò lò rí nínú ìtàn lásán. Ìtàn ìwáṣẹ̀ máa ń jẹ ọ̀nà kan pàtàkì láti ṣàlàyé ìgbé ayé tó ti kọjá. Ò máa ń sọ nípa bí àwọn ènìyàn ṣe dé sí ilẹ̀ kan ati ìdí tí àwọn kan fi jẹ gàba lórí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Volume Library (267) tilẹ̀ sọ pé o yẹ kí ìgbàgbọ́ wa rọ̀ mọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ nítorí ó jẹ́ mọ́ àṣà bí o tilẹ jẹ́ pé kò sí ẹni tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ohun ti a mọ̀ nip é ìtàn ìwáṣẹ̀ ti wáyé lásìkò tó ti pẹ́. A kò lè fọ́wọ́ rọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlí Ẹ̀fọ̀n-Alàayè ṣẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú àwọn ìtàn tí àwọn òpìtàn sọ fún wa, ìdáṣọró okùn-ìtàn wà níbẹ̀ ṣùgbọ́n nǹkan tó ṣe pàtàkì ní pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n Alàayè dó wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní àsìkò ìgbà kan tí a kò mọ̀. Ìlú ibi ti wọ́n tẹ̀dó sí tù wọn lára, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí dí òní. Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè I.A. Ologunleko.
Ẹfọ̀n-Alààyè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2292
2292
Ponna J.A. Ogunwale Ogunwale Itumo Ponna Itumo ponna J.A Ògúnwálé (1992), ‘Àyẹ̀wò Àwọn Afọ̀ Onítumọ̀ Pọ́n-na nínú Àwọn Ìwé kan nínú Èdè Yorùbá.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyé Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria. AṢÀMỌ̀ Pọ́n-na inú àwọn àṣàyàn ìwé Yorùbá kan ni kókó ohun tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí. Iṣẹ́ yìí tún ṣe àlàyé lórí àjọṣepọ̀ ààrin Ṣàkání-Ìtumọ̀, afọ̀ àti ìtumọ̀ nítorí pé bí atọ́nà ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Bákan náà ni a pín àwọn Pọ́n-na tí a rí nínú àwọn ìwé Yorùbá díẹ̀ sí ìsọ̀rí. Ẹ̀yìn èyí ni a wá ṣe àfiwé pọ́n-na pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Ìtumọ̀ mìíràn tó ń bá a ṣé orogún. A fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọ Yorùbá tó ń lo èdè náà lẹ́nu wò kí ìtumọ̀ tí a ń fún afọ̀ tí àwa kà sí pọ́n-na má baà dà bí àtorírò tiwa lásán. A wo àwọn ìwé tí ó jẹ mọ́ ewì, ọ̀rọ̀ geere àti eré onítàn kí a lè baà kó gbogbo ẹ̀yà ìwé Yorùbá já. Orí òṣùwọ̀n àjùmọ̀ṣe Kress àti Odell lórí ìṣẹ̀dà òye-ọ̀rọ̀ ni a gbé iṣẹ́ yìí kà. A kíyèsí I wí pé àwọn àkíyèsí tí ó jẹ mọ́ ti gírámà àti sẹ̀máńtììkì máa ń pa ìtumọ̀ afọ̀ kan dà. A sì tún kíyèsí i wí pé ìlò àfikún ẹ̀yán wà lára aáyan elédè láti pèsè ṣàkání-ìtumọ̀. Iṣẹ́ yìí tún pín pọ́n-na sí ìsọ̀rí. Òṣùwọ̀n tí a lò ni àyè tí a bá àwọn ibùba pọ́n-na, Ìrísí Ṣàkání-ìtumọ̀, Ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ àti àbùdá odo ìtumọ̀ onípọ́n-na. a rí i wí pé àbùdá pọ́n-na kì í ṣe ohun tó yé tawo-tọ̀gbẹ̀rì, a wá fi wé àwọn oríṣìí ẹ̀yà-ìtumọ̀ mìíràn bíi gbólóhùn aláìlárògún, ẹ̀dà òye-ọ̀rọ̀, ààrọ̀ àti gbólóhùn aláìnítumọ̀-pàtó. Iṣẹ́ yìí rí i wí pé ara àbùdá èdè ni àwọn pọ́n-na kan jẹ́, ó lè má jẹ́ àmì àìgbédè-tó olùsọ̀rọ̀. Èyí mú kí a tọ́ka àkọtọ́ tó péye, Ìṣẹ̀dà òyè ọ̀rọ̀ àti ìlò ṣàkání-ìtumọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ìyọní-pọ́n-na. A fi orí iṣẹ́ yìí tì si ibi wí pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni pọ́n-na máa ń jẹ́ àkómẹ́rẹ̀ fún àsọyé àti àgbọ́yé. Èyí ló sún wa dé ibi pé kí a ṣe àlàyé díẹ̀ lórí ìlò tí a ń lo pọ́n-na láwùjọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú àwọn ìwé tí a ṣàyàn
Ponna
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2294
2294
Ifẹ̀wàrà Ìfẹ̀wàrà jẹ́ ìlú kékeré kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni Nàìjíríà Gẹ́gẹ́ bí a sọ ṣaájú, ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí dé Ìjọba Ìbílẹ̀ Àtàkúmọ̀sà tí ó ní ibùjókòó rẹ̀ ní Òṣú. Ní ìjọba ìbìlẹ̀ yìí, gbogbo àwọn ìlú àti abúlèko tí ó wà ní ibẹ̀ ló jẹ́ ti Ìjẹ̀ṣà. Ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀ṣà ni wọ́n sì ń sọ àfi Ifẹ̀wàrà tí ó jẹ́ ẹ̀yà ẹ̀kà-èdè Ifẹ̀ ni wọ́n ń sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn tí gbọ́, Ifẹ̀ ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà ti ṣí lọ sí ìlú náà láti agboolé Arùbíìdì ní òkè Mọ̀rìṣà ní Ilé-Ifẹ̀1 . Ìwádìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ oyè ló dá ìjà sílẹ̀ ní ààrin tẹ̀gbọ́ntàbúrò. Ẹ̀gbọ́n fẹ́ jẹ oyè, àbúrò náà sì ń fẹ́ jẹ oyè náà. Ọ̀rọ̀ yìí dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ ní ààrin wọn. Lórí ìjà oyè yìí ni wọ́n w`atí ẹ̀gbọ́n fi lọ sí oko. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀gbọ́n tó ti oko dé, ipè láti jẹ oyè dún. Àbúrò tí ó wà ní ilé ní àsìkò náà ló jẹ́ 1. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú arábìnrin Julianah aya ni 17/6/92. 2. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Olóyè Fákówàjọ ni 17/6/92. Ipé náà. Ipè ti sé ẹ̀gbọ́n mọ́ oko. Èyí bí ẹ̀gbọ́n nínú nígbà tí ó gbọ́ pé àbúrò òun ti jẹ òyé, ó sì kọ̀ láti padà wá sí ilé nítorí pé kò lè fi orí balẹ̀ fún àbúrò rẹ̀ tí ó ti jẹ oyè. Ọ̀rọ̀ yìí di ohun tí wọn ń gbé ogun ja ara wọn sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n yìí wá ń gbé ogun ja àbúrò rẹ̀ ní Ifẹ̀ lemọ́lemọ́, ni àwọn Ifẹ̀ bá fi ẹ̀pà ṣe oògùn sí ẹnu odi ìlú ní Ìlódè. Wọ́n sì fi màrìwò ṣe àmì sì ọ̀gangan ibi tí wọ́n ṣe oògùn náà sí. Láti ìgbà yìí ni ogun ẹ̀gbọ́n kò ti lè wọ Ifẹ̀ mọ. Àwọn Ìjẹ̀ṣà ní ó ni kí ẹ̀gbọ́n tí ó ń bínú yìí lọ tẹ̀dó sí Ìwàrà. Nígbà tí wọ́n dé Ìwàrà, wọ́n fi mọ̀rìwò ọ̀pẹ gún ilẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́ mọ̀rìwò kọ̀ọ̀kan ti di igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan.Ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀lẹ̀, wọ́n sì pinnu pé àwọn kò níí lè bá àwọn àlejò náà gbé nítorí pé olóògùn ni wọn. Èyí ló mú kí àwọn ara Ìwàrà lé àwọn àlejò náà sí iwájú. Ibi tí àwọn àlejò náà tẹ̀dó sí lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Ìwàrà ni a mọ̀ sí Ifẹ̀wàrà lónìí. Lóòótọ́ orí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ifẹ̀wàrà wà ṣùgbọ́n kò sí àjọṣepọ̀ kan dàbí alárà láàrin Ifẹ̀wàrà, Iléṣà àti Ìwàrà títí di òní pàápàá nípa ẹ̀ka-èdè tí wọn ń sọ. Àkíyèsí fi hàn pé gbogbo orúkọ àdúgbò tí ó wà ní Ifẹ̀ náà ni ó wà ní Ifẹ̀wàrà. A rí agboolé bí Arùbíìdì, Mọ̀ọ̀rẹ̀, Òkèrèwè, Lókòrẹ́ àti Èyindi ní Ifẹ̀wàrà. Bákan náà ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ nì wọ́n ń sọ ní Ifẹ̀wàrà. Àsìkò tí wọ́n bá sì ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ ní Ifẹ̀ náà ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà máa ń ṣe tiwọn. Ìwádìí nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ìlú tí iṣẹ́ yìí dé fi hàn gbangba pé mọ̀lẹ́bí ni Ifẹ̀, Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó pẹ̀lú Òkè-Igbo, àti Ifẹ̀wàrà. Wọ́n jọra nínú ìṣesí wọn. Ẹ̀ka-èdè wọn dọ́gba, orúkọ àdúgbò wọn tún bára mu, bákan náà ni ẹ̀sìn wọn tún dọ́gba. Àkókó tí wọ́n ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ kò yàtọ̀ sí ara wọn. Bí ẹrú bá sì jọra, ó dájú pé ilé kan náà ni wọ́n ti jáde.
Ifẹ̀wàrà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2295
2295
Ife Ife C.O. Odejobi Ifẹ̀ láti ọwọ́ C.O. Ọdẹ́jọbí, DALL, OAU, IFẸ̀ Nigeria. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣiwájú nínú ìmọ̀ ni wọ́n ti sọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ifẹ̀. Bákan náà Johnson1, Gugler, àti Flanagan2 tó fi mọ́ Fáṣọgbọ́n3 sọ ìtàn Ifẹ̀ nínú iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, ọ̀nà méjì ni ìtàn Ifẹ̀ pín sí. Èkíní jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ nípa pé láti ìpilẹ̀sẹ̀ ni Ifẹ̀ ti wà. Ìtàn kejì ni èyí tí ó sun jáde láti ara Odùduwà1. Ìtàn àkọ́kọ́ ni ti Ifẹ̀ Oòdáyé2 Ìtàn ìwásẹ̀ náà sọ pé Olódùmarè pe àwọn Òrìṣà láti lọ wo ilé ayé wá nígbà ti ó fẹ́ dá ayé. Ó fún wọn ní èèpẹ̀ tí ó wà nínú ìkarahun ìgbín, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún, àti ọ̀ga. Nígbà tí wọ́n dé ilé ayé, wọ́n rí i pé omi ní ó kún gbogbo rẹ̀, àwọn òrìṣà da eèpẹ̀ tí Ooódùmarè fún wọn sí orí omi náà, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún sì tàn án. Bí adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún ṣe ń tan ilẹ̀ yìí bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ ń fẹ̀ sí i èyí náà ló bí orúkọ Ifẹ̀. Ìtàn kejì ni pé láti ìlú mẹ́kà ni Lámurúdu tí ó jẹ́ baba Odùduwà ti wá sí Ifẹ̀. Ogun Mohammed tí ó jà láàrin kèfèrí àti mùsùlùmí ìgbà náà ló ká Lámúrúdu mọ́. Èyí ti Lámurúdu ìbá fi gbà, ó fi ìlú Mẹ́kà sílẹ̀, ó sì tẹ Ifẹ̀ dó.3 Lẹ́yìn ikú Lámurúdu ni Odùduwà gba Ipò. Ilé Ọ̀rúntọ́ ti wà ní Ifẹ̀ kí Lámurúdu tó dé. àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ ni ó gba Lámurúdu àti Odùduwà ní àlejò4. Àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ gbà fún Odùduwà láti jẹ́ olórì wọn nítorì pé alágbára ni. Ìtàn ti akọkọ yìí ló sọ bí Olódùmarè ṣe ran àwọn oriṣa láti wá dá ayé. Lẹ́yìn tí àwọn oriṣa dá ayé tan, ti wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ ni Odùduwà tó wá sí Ile-Ifẹ̀ láti ìlú Mẹka. Abẹ́nà ìmọ̀ itan kejì yìí tilẹ̀ fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Lámurúdu àti Odùduwà bá àwọn kan ni Ilé-Ifẹ̀ nígbà ti wọ́n dé Ifẹ̀. Ohun tí èyí èyí ń fi yé wa nip é nibi tí ìtàn akọkọ parí si ni ìtàn kejì ti bẹrẹ. Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ Ẹ́meè C.O. Ọdẹ́jọbí .
Ife
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2296
2296
Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó Ifetedo C.O. Odejobi Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó àti Òkè-Igbó Láti ọwọ́ C.O. Ọdẹ́jọbí DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria. Dérìn Ọlọ́gbẹ́ńlá nì orúkọ ẹnì tí ó tẹ Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó dó1. Ọmọ ìlú Ifẹ̀ nì Ọlọ́gbẹ́ńlá, ó sì jẹ́ akíkanjú àti alágbára ènìyàn. Ìwádìí fi hàn pe, ọba Òṣemọ̀wé Oǹdó ló ránṣẹ́ sí Ọọ̀nì Abewéelá pé, kí ó rán àwọn ọmọ-ogun wá, kí wọ́n lè ran òun lọ́wọ́ latí ṣẹ́gun àwọn tí ó ń bá òun jà. Ọdún 1845 ni ọba Abewéelá rán Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ jẹ́ ìpè ọba Òṣemọ̀wé ti Oǹdó2 Wọ́n sì tẹ̀dó sí Òkè-Igbó. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ní ọdún 1845 yìí kan náà, Ọlọ́gbẹ́ńlá kò padà sí Ifẹ̀ mọ́, ó kúkú fi Òkè-Igbó ṣe ibùjókòó rẹ̀. Gbogbo aáyan àwọn Ifẹ̀ láti mú kí Ọlọ́gbẹ́ńlá padà sí Ifẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti ṣẹ́gun ní Oǹdó ló já sí pàbó. Ní ọdún 1880 ní wọn fi jẹ Ọba èyí ni Ọọ̀ni ti Ifẹ̀, ṣùgbọ́n kò wá sí Ifẹ̀ wá ṣe àwọn ètùtù tí ó rọ̀ mọ́ ayẹyẹ ìgbádé ọba, Òkè-Igbó ni ó jókòó sí1 Òkè-Igbó yìí ní ó wà tí ọlọ́jọ́ fi dé bá a ní ọdún 18922. Ní ọdún 1982 ni àwọn ara Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó kan fi ibinu ya kúrò lára Òkè-Igbó3, nítorí ọ̀rọ̀ ìlẹ̀. Oko-àrojẹ àwọn Òǹdó ni Òkè-Igbó kí ó tó dip é Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi ibẹ̀ ṣe ibùjókòó wọn4. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé lórí ilẹ̀ Òǹdó ni Òkè-igbó wà ṣùgbọ́n àwọn Ifẹ̀ ni ó ń gbé ìlú náà. Nígbà tí àwọn Òyìnbó ń pín ilẹ̀ Yorùbá sí ẹlẹ́kùnjẹkùn, wọ́n pín Òkè-Igbó mọ́ Òǹdó. Ohun tí ó ṣẹ́lẹ̀ lẹ̀yín náà nip è àwọn Òǹdó ń fẹ kí àwọn tí ó wà lórì ilẹ̀ àwọn ní Òkè-Igbó máa san owó-orì wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Oǹdó. Bákan náà ni àwọn Ifẹ̀ ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó wà ní Òkè-Igbó san owó-orí wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Ifẹ̀ nítorí pé Ifẹ̀ ni wọ́n1. Yàtọ̀ sí àríyànjiyàn tí ó wà lórí ibi tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn Òkè-Igbó san owó-orí sí, àwọn akọ̀wé agbowó-orí tún máa ń ṣe màgòmágó sí iye owó-orí tí àwọn èniyàn bá san2. Èyí ni pé ọ̀tọ̀ ni iye owó tí ó máa wà ní ojú rìsíìtì tí àwọn akọ̀wé agbowó-orí ń fún àwọn tí ó san owó-orí, ọ̀tọ̀ ni iye tí wọ́n máa kó jíṣẹ́. Gbogbo èyí ló dá wàhálà sílẹ̀ ní Òkè-Igbó ní àkókò náà. Ọba Ọọ̀ni Adérẹ̀mí ni ó pa iná ìjà náà nígbà tí ó pàṣẹ ni oḍún 1932 pé kí ẹni tí ó bá mọ̀ pé Ifẹ̀ ni òun, kúrò ní Òkè-Igbó, kí ó fo odò Ọọ̀ni padà sẹ́yìn kí ó tó dúró. Àwọn tí ó padà sí òdìkejì odò Ọọ̀ni ní oḍún 1928 ati ọdún 1932 ni a mọ̀ sí Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó lónìí. Ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, àwọn àdúgbò wọ̀nyí ló wà níbẹ̀: Ilé Badà, Oríyangí, Kúwólé, Aṣípa-Afolúmọdi, Mọ̀ọrẹ̀, balágbè, Fáró, Ìta-Akíndé, Odò-Odi, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, Òkèèsodà, Olú-Òjá àti Ọdọ́. Díẹ̀ lára àwọn àdúgbò wọ̀nyí wà ní Ifẹ̀, fún àpẹrẹ, Oríyangí, Mòọ̀rẹ̀, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, àti Òkèèsodà. Bákan náà ló jẹ́ pé gbobgo ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Ifẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó. Bí a bá tún wo ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni. Nítorí náà a gba orin èébú ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó. Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ Ẹ́meè C.O. Ọdẹ́jọbí
Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2297
2297
Ìgbómìnà Igbomina Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà jẹ́ ẹ̀yà èdè Yorùbá tí àwọn Ìgbómìnà ń sọ. Ní ilẹ̀ Yorùbá lóde òní, àwọn Ìgbómìnà wà ní ìpìnlẹ̀ Ọṣun àti Kwara. Àwọn ìlú tí wọn tí ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣùn ní ìlá Ọ̀ràngún Òkè-Ìlá àti Ọ̀rà. Ní ìpínlẹ̀ Kwara, àwọn ìlú yìí pọ̀ jut i Ọ̀ṣun lọ. Ìjọba Ìbílẹ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọn ti ń sọ Ìgbominà. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Ìfẹlodun, Ìrẹ́pọdun, Òkè-Ẹ̀rọ́ àti Isis. Ìlú tí wọ́n ti n sọ èka-èdè Igbómìnà ni ìjọba Ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódun ni Ìgbàjà, Òkèyá, Òkè-Ọdẹ, Babáńlá, Ṣàárẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní Ìjọba ìbílẹ̀ Irẹpọ̀dun, lára àwọn Ìlú tí wọ́n ti ń sọ ẹ̀kà-èdè Igbómìnà ni Àjàṣẹ́, Òró, Òmù-Àrán, Àrán-Ọ̀rin. Ní ìjọba ìbílẹ̀ Òkè-Ẹ̀rọ̀ ẹ̀wẹ̀, wọn a máa sọ Ìgbómìnà ni Ìdọ̀fin. Ní ti ìjọba Ìbílẹ̀ Isis, a rí ìlú bíì Òkè-Onigbin-in, Òwù-Isis, Èdìdi, Ìjárá, Ọwá kájọlà, Ìsánlú-Isis, Ọ̀là àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Olúmuyiwa (1994:2) wòye pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀ka-èdè ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ní ẹ̀yà. Èyí náà rí bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà. Lóòótọ́, àwọn ìlú tí a dárúkọ bí ìlú tí a ti ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà máa ń gbọ́ ara wọn ni àgbọ́yé bí wọ́n ba ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀ oríṣiríṣI ni ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ láti ìlú kan sí èkejì. Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà Òrò sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ ni ẹkùn Òrò. Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú Àpilẹ̀kọ Ẹ́meè A. F. Bámidélé.
Ìgbómìnà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2305
2305
Fíìmù Fíìmu Ìwà Ọ̀daràn C.O. Odéjobí C. O. Ọdẹjọbi (2004), ‘Àyẹ̀wò Ìgbékalẹ̀ Ìwà Ọ̀daràn nínú fíìmù Àgbéléwò Yorùbá’., Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria. ÀṢAMỌ̀ Iṣẹ́ yìí ṣe àyẹwò sí bí isẹlẹ inú àwùjo se jé òpákùtèlè ìwà òdaràn nínú ìsòwó àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá kan, b.a. ‘Ogun Àjàyè’, ‘Owọ́ Blow’, ‘Aṣéwó Kánò’, ‘Agbo Ọ̀dájú’, ‘Ṣaworoidẹ’, ‘Ìdè’, abbl. Àlàyé wáyé lórí ọ̀nà ìgbékalè ọ̀ràn nínú fíìmù àgbéléwò Yorùbá, bákan náa ni a sì tún se àyèwò ipa tí fíìmù àgbéléwò ajemọ́ ọ̀ràn dídá ń ní lórí àwọn òǹwòran, òsèré lọ́kùnrin-lóbìnrin àti àwùjo lápapọ̀. Iṣẹ́ yìí ṣe àyèwò ohun tó ń mú kí àwọn asefíìmù ó máa ṣe àgbéjáde fíìmù Yorùbá ajemó òràn dídá tó lu ìgboro pa báyìí, a sì tún wo orísirísi ìjìyà tí àwọn ọ̀daràn máa ń gbà. Tíọ́rì ìmò ìfojú ìbára-eni-gbépò ni a lò kí a lè fi òràn dídá inú fíìmù wé tí ojú ayé. Ìfọ̀rọ̀ wá àwọn aṣefíìmù lénu wò wáyé láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń gbé fíìmù ajẹmó òràn dídá jáde. A tún fi ọ̀rọ̀ wá àṣàyàn àwọn òṣèré lókùnrin àti lóbìnrin àti ònwòran lénu wò láti mo ìhà tí wón ko sí fíìmù ajemó òràn dídá àti ipa tí wíwo irúfé fíìmù béè lè ní lórí àwọn ènìyàn nínú àwùjo. Àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó jẹ mọ́ iṣẹ́ yìí ni a wò tí a sì tú palè. Ní àfikún. Olùwádìí tún lọ sí ilé ìkàwé láti ka ọ̀pọ̀ ìwé bíi jọ́nà, átíkù, ìwé iṣé àbò-ìwádìí láti lè mo àwọn isé tó ti wà nílè. Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé ìyàgàn àti àìní tó je mó owó, ipò, obìnrin àti àwọn nǹkan mìíràn tí ẹ̀dà lépa ló ń ti àwon ènìyàn sínú ìwà ọ̀daràn. Iṣẹ́ yìí se àkíyèsí pé lára àwọn tó ń lówó nínú ìwà ọ̀daràn ni a ti rí òré, ebí àti àwọn agbófinró. Bákan náà ni isẹ́ yìí tún se àfihàn onírúurú ọ̀nà tí àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ń gbà dá ọ̀ràn. Ní ìparí. iṣé yìí gbà pé àwọn ìwà ọ̀daràn tó ń ṣelè ni a lè kà sí ọ̀kan lára ohun tí ìsẹ̀lẹ̀ àwùjọ bí àti pé ìjìyà ti a ń fún ọ̀daràn máa ń ní ipa nínú ẹbí wọn nígbà mìíràn. Alábòójútó Kìíní: Ọ̀jọ́gbọ́n T.M. Ilésanmí Alábòójútó Kejì: Ọ̀jọ̀gbọ́n B. Àjùwọ̀n Ojú Ìwé: 249 ì
Fíìmù
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2354
2354
Ìlú Ìrèlè Ilu Irele Akinyomade (2002), ‘Ìlú Ìrèlè’, láti inú ‘Ipa Obìnrin nínú Ọdún Èje ní Ìlú Ìrèlè.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwe 3-12. ÀPÈJÚWE ÌLÚ ÌRÈLÈ. Ìlú Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì àti èyí tí ó tóbi jù nínú Ìkálẹ̀ Mẹ̀sàn-án (Ìrèlè, Àjàgbà, Ọ̀mi, Ìdèpé-Òkìtipupa, Aye, Ìkọ̀yà, Ìlú tuntun, Ijudò àti Ijùkè, Erínjẹ, Gbodìgò-Ìgbòdan Líṣà). Ìlú yìí wà ní ìlà-oòrùn gúṣù Yorùbá (SEY) gẹ́gẹ́ bí ìpínsí-ìsọ̀rí Oyelaran (1967), Ó sì jẹ ibìjókòó ìjọba ìbílẹ̀ Ìrèlè. Ìlú yìí jẹ́ ọkan lára àwọn ìlú tí ó ti wà ní ìgbà láéláé, àwọn olùgbé ìlú yìí yòó máa súnmọ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbàá. Ní apá ìlà-oòrun, wọ́n bá ilú Sàbọmì àti Igbotu pààlà, ní apá ìwọ̀-oòrùn ìlú Ọ̀rẹ̀ àti Odìgbó pààlà, ní àriwá tí wọ́n sì ba ìlú Okìtìpupa-Ìdèpé àti Ìgbòbíní pààlà nígbà tí gusu wọ́n bá ìlú Ọ̀mì pààlà. Ìrèlè jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó sórí yanrìn, tí òjò sì máa ń rọ̀ ní àkókò rẹ̀ dáradára. Eléyìí ni ó jẹ́ kì àwọn olùgbé inú ìlú yìí yan iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ ẹja pípa ní àyò gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òòjọ́ wọ́n ṣé wọ́n ní oko lèrè àgbẹ̀. Ohun tí wọ́n sábà máa ń gbìn ni ọ̀pẹ, obì tí ó lè máa mú owó wọlé fún wọn. Wọ́n tún máa ń gbin iṣu, ẹ̀gẹ́ kókò, kúkúǹdùkú àti ewébẹ̀ sínú oko àrojẹ wọn. Nígbà tí ó dip é ilẹ̀ wọn kò tó, tí ó sì tún ń ṣá, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i, àwọn mìíràn fi ìlú sílẹ̀ láti lọ mú oko ní ìlú mìíràn. Ìdí èyí ló fi jẹ́ pé àwọn ará ìlú yìí fi fi oko ṣe ilé ju ìlú wọn lọ. Lára oko wọn yìí ni a ti ri Kìdímọ̀, Lítòtó, Líkànran, Òfò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀làjú dé, àwọn ará ìlú yìí kò fi iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ẹja pípa nìkan ṣe iṣẹ́ mọ́, àwọn náà ti ń ṣe iṣẹ́ ayàwòrán, télọ̀, bíríkìlà, awakọ̀, wọ́n sì ń dá iṣẹ́ sílẹ̀. Wọ́n ní ọjọ́ tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kónyè tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kóyè tí wọn máa ń ná ní ọrọọrín sira wọn. Àwọn olùsìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ pọ̀ ni Ìrèlè. Wọ́n máa ń bọ odò, Ayélála, Arẹdẹ-lẹ́rọ̀n bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń ṣe ọdún egúngún, Ṣàngó, Ògún, Ọrẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀sìn àjòjì dé wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ń yi padà lati inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọ́n sí ẹ̀sìn mùsùmùmí àti ẹ̀sìn kirisitẹni. Bí ojú ṣe ń là si náà ni ìdàgbàsókè ń bá ìlú yìí. Oríṣìíríṣìí ohun amúlúdùn ni ó wà ní ìlú Ìrèlè, bíi iná mọ̀nà-mọ́ná, omi-ẹ̀rọ, ọ̀dà oju popo, ile ìfowópamọ́, ilé ìfiwé-ránṣẹ́, ilé-ìwé gígá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. ÌTÀN ÌLÙ ÌRÈLÈ. Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ilẹ̀ Yorùbá tí m bẹ ni ìha “Òǹdó Province” ó sì tún jẹ́ ọ̀kan kókó nínú àwọn ilẹ̀ mẹ́ta pàtàkì tí ń bẹ ni “Ọ̀kìtìpupa Division” tàbí tí a tún ń pè ní ìdàkeji gẹ́gẹ́ Ẹsẹ̀ Odò tí ọwọ́ òwúrò ilẹ̀ Yorùbá. Ìwádìí fí yé wa wí pé ọmọ ọba Benin tó jọba sí ìlú Ugbò1 tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ Olúgbò-amẹ̀tọ́2 bí Gbáǹgbá àti Àjànà. Gbáǹgbá jẹ́ àbúrò Àjànà ṣùgbọ́n nígbà tí Olúgbò-amẹ̀tọ́ wàjà, àwọn afọbajẹ gbìmọ̀pọ̀ lati fi Gbáǹgbà jẹ ọba èyí mú kí Àjànà bínú kuro ní ìlú, ó sì lọ tẹ ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́3 pẹ̀lú Gbógùnrọ́n arakunrin rẹ̀. Láti ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́ ní Àjànà tí lọ sí ìlú Benin, ò sí rojọ́ fún Ọba Uforami4 bí wọ́n ṣe fí àbúrò oùn jọba, àti pé bí oùn náà ṣe tẹ ibikan dó. Oùn yóò sì jẹ Ọba “Olú Orófun”5 sí ìbẹ. Ọba Uforami sì fún Àjànà ní adé, Àjànà padà sí Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ó bí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Ògèyìnbó, ọkùnrin sì ni àwọn mejeeji. Kò pẹ́, kò sí jìnà, Àjànà wàjà. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji lọ si Benin lati jọba. Ògèyìnbó lọ sí Benin lati jọba. Ó dúró sí ọ̀dọ̀ Oba Benin pé baba òun tí wàjà, òun yóò sí jọba. Ọ̀rúnbẹ̀mékún náà lọ sí ọ̀dọ̀ Ìyá Ọba Benin pé òun náà fẹ jọba nígbà tí baba òun ti kú. Ọba Benin ń ṣe orò ọba fún Ògèyìnbó nígba tí Ìyá ọba ń ṣe orò fún Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún. Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún mu Olóbímítán ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí akọ́dà Ọba Benin tí yóò wà gbé oúnjẹ fún Ìyá Ọba, rí í wí pé ọrọ̀ tí ọba ń ṣe fún alejo ọdọ̀ rẹ̀ náà ní Ìyá ọba ń ṣe fún ẹni yìí. Èyí mú kí akọ́dá ọba fi ọ̀rọ̀ náà tó kabiyesi létí. Ní ọba ni ọmọ kì í bí ṣáájú iyaa rẹ, ó pe Ògèyìnbò kó wá máa lọ. Nígbà tí àwọn méjèéjì fí lọ sí Benin, Gbógùnrọ̀n tí gbe “Àgbá Malokun”6 pamọ́ nítorí ó tí fura pé wọn kò ní ba inú dídùn wá. Ògèyìnbó dé Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, kò rí Àgbá Malòkun mọ́, ó wa gbé Ùfùrà, ó wọ inú ọkọ ojú omi, o sí tẹ isalẹ̀ omi lọ, oùn ní ó tẹ ìlú Erínjẹ dó. Ní àkókò tí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún fí wà ní ìlú Benin, Òlóbímitán, ọmọ rẹ̀ máa lọ wẹ̀ lódò Ìpòba7 àwọn ẹrú ọba sí màa ń ja lati fẹ èyí ló fá ìpèdè yìí “Olóbímitán máa lọ wẹ̀ lódì kí ẹru ọba meji máa ba jìjà ku tori ẹ”. Èyí ní wọ́n fi ń ṣe ọdún Ìjègbé ní ìlú Benin. Ní ìgbà tí ó ṣe Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Olóbímitán padà sí ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ṣùgbọ́n Gbógùnrọ̀n sọ fún wí pe àbúrò rẹ̀ (Ògèyìnbó) i ba ibi jẹ́ kò sì dára fún wọn lati gbé, wọ́n kọja sí òkè omi wọn fi de Ọ̀tún Ugbotu8, wọn sọkalẹ, Olóbímitán ní òun…àbàtà wọ́n wá tẹ́ igi tẹ́ẹ́rẹ́ lorí rẹ̀ fún, èyí ní wọn fí ń kí oríkì wọn báyìí: “Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún a hénà gòkè” . Àgbá Malòkun tí gbógùnrọ̀n gbé pa mọ́ kò le wọ inú ọkọ́ ojú omi, wọn sọ ọ́ sínú omi, títí dì òní yìí tí wọ́n bá ti ń sọdún Malòkun ní ìlú Ìrèlè, a máa ń gbọ́ ìró ìlù náà ní ọ̀gangan ibi wọ́n gbé sọ ọ́ somi. Wọ́n tẹ̀dó sí odó Ohúmọ. Oríṣìíríṣìí ogun ló jà wọ́n ní odí Ohúmọ, lára wọn ní Ogun Osòkòlò10, Ogun Ùjọ́11, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Olumisokun ọmọ ọba Benin, ìyàwò rẹ̀ kò bímọ nígbà tó dé Ìrèlè ó pa àgọ́ sí ibikan, ibẹ̀ ní wọn tí ń bọ Malokun ni ìlú Ìrèlè. Lúmúrè wá dò ní ìlú Ìrèlè, ó fẹ Olóbímitán ṣùgbọ́n Olóbímitán kò bímọ fún un èyí mú kí ó pàdà wa si ọdọ baba rẹ̀, Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún, olúmísokùn wá fẹ Olóbímitán ní odó Ohúmọ. Wọ́n bí Jagbójú àti Oyènúsì, ogun tó jà wọn ní ní odó Ohúmọ pa Oyènúsì èyí mú kí Jagbójú sọ pé “oun relé baba mi”. Mo relé. Bí orúkọ àwọn to kọ́kọ́ jọba ni ìlú Ìrèlè ṣe tẹ̀lé ara wọn nì yìí: Odú Ifá tó tẹ Ìrèlè dó. "Ègúntán Ọ̀bàrà Ègùntán á ṣẹ Ọ̀bàrà á ṣẹ A díá fún Ìyá túrèké Wọ́n ni kó lọ ra ewurẹ́ wá lọ́jà Owó ẹyọ kan ní wọn fún Ègùntán ní ìyá òun yóò ra ewúrẹ́ méjì Ọ̀bàrà ni ìyà òun yóò ra ewúrẹ́ kan Túrèké ra ewúrẹ́ kan Ṣùgbọ́n ó lóyún Kí ó tó délé ewúrẹ́ bí mọ" . ORÍKÌ ÌLÚ ÌRÈLÈ. " Ìrèlè ẹgùn, Ibi owó ń gbé so, Tí a rí nǹkan fi kan Ìrèlè ẹgùn, Ó gbẹ́ja ńlá bọfá, Èṣù gbagada ojú ọ̀run Ó jókòó ṣòwò ọlà Malòkun ò gbólú Ọba-mi-jọ̀ba òkè. Àtètè-Olókun Iwá òkun, òkun ni Ẹ̀yìn òkun, òkun ni A kì í rídìí òkun A kìí rídìí Ọlọ́sà Ọmọ Ìrèlè kò ní opin Ìdí ìgbálẹ̀ kì í ṣẹ́ Aṣọ funfun tí Malòkun Ọpẹ ni ti Malòkun" . ÌTỌSẸ̀ Ọ̀RỌ̀. 1 Ugbò = Orúkọ ìlú kan ní ìlú Ìlàjẹ ní jẹ́ bẹ́ẹ̀. 2 Olúgbò-amẹ́tọ̀ = Orukọ ọba ìlú Ugbò nígbà náà. 3 Gbáǹgbà àti Àjànà = Orukọ ènìyàn. 4 Ìgbẹ́kẹ̀bọ́ = ìlú kan ní jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìpílẹ̀ Ìlàjẹ 5 Ọba Ùfóràmí = Orúkọ Ọba Benin. 6 Olú Orófun = Orúkọ oyé ọba ìlú Ìrèlè. 7 Àgbá Malòkun = Orúkọ ìlù kan ni tí wọ́n ń lù ní ọjọ́ ọdún Malòkun. 8 Ìpòbà = Orúkọ omi kan ní ìlú Benin 9 Ugbotu = Orukọ ìlú àwọn Ìlàjẹ kan ni. 10 Ohúmọ = Orúkọ omi kan ni. 11 Ogun Òsòkòlò = Orúkọ ìlú kan tó kó ogun ja ìlú Ìrèlè. 12 Ùjọ́ = Orúkọ àwọn ẹ̀ya ènìyàn kan ni
Ìlú Ìrèlè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2357
2357
Bámijí Òjó Bamiji Ojo (20 October, 1939) je olukowe omo ile Naijiria. Itàn Ìgbésíayé Bámijí Òjó. A bí Bámijì Òjó ní ogúnjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1939 ní ìlú ìlọ́ràá, ní ìjọba ìbílẹ̀ Afijió ní ìpínlẹ̀ Ọ̀jọ́. Orúkọ àwọn òbí rẹ̀ ni Jacob Òjó àti Abímbọ́lá Àjọkẹ́ Òjó. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn òbí rẹ̀ ń ṣe. Ojú ti ń là díẹ̀ nígbà náà, ẹni tí ó bá mú ọmọ lọ sí ilé-ìwé ní ìgbà náà, bí ìgbà tí ó fi ọmọ sọ̀fà tí ó mú ọmọ lọ fún òyìnbó ni. Ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ pa ìmọ̀ pọ̀ wọ́n fi sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ìjọ onítẹ̀bọmi ti First Baptist Day School ìlú Ìlọràá ni ọdún 1946. O ṣe àṣeyẹrí nínú ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́fà, tí ó kà jáde ni ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Nígbà náà wọ́n ti ń dá ilé ẹ̀kọ́ gíga Mọ́dà (Modern School) sílẹ̀. Bámijí Òjó ṣe ìdánwò bọ́ sí ilé-ìwé Local Authority Modern School ní ìlú Fìdítì, ó wà ní ibẹ̀ fún ọdún mẹ́ta (1956-1959). Lẹ́yìn èyí nínú ọdún 1960, Bámijí Òjó ṣe iṣẹ́ díẹ̀ láti fi kówó jọ. Nítorí pé kò sí owó lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ láti tọ́ ọ kọjá ìwé mẹ́jọ. Lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ tí ó sì kówó jọ fún ọdún kan pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí “Modern School”, ó tún tíraka láti tẹ̀síwájú lẹ́nu ìwé rẹ̀. Ó lọ sí ilé-ìwé ti àwọn olùkọ́ni ti “Local Authority Teacher Training College” ní ìlú Ọ̀yọ́ láti inú ọdún 1961 di ọdún 1962. Ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe iṣẹ́ tí ó wù ú lọ́kàn gan-an láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni iṣẹ́ tíṣà. Ó ṣe iṣẹ́ tíṣà káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ bí i Ṣakí, Edé, Ahá. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìròyìn ni ó múmú ní ọkàn rẹ̀. Bámijí Òjó wà lára àwọn méjìlá àkókó tí wọ́n gbà ní ọdún 1969 láti kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì Èkó. Nígbà náà ojú ọ̀lẹ ni wọ́n fi máa ń wo ẹni tí ó bá lọ kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni wọ́n gba Bámijí Òjó sí ilé iṣẹ́ ìròyìn ní ọdún 1970, Àlhàájì Lateef Jákàńdè ni ó gbà á sí iṣẹ́ ìròyìn ní ilé-iṣẹ́ “Tribune”ní ìlú Èkó, gẹ́gẹ́ bí igbá kejì olóòtú Ìròyìn Yorùbá. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó tin í ìyàwó nílé nígbà náà wọ́n gbé e padà sí Ìbàdàn. Ilé-iṣẹ́ wọn wà ní Adẹ́ọ̀yọ́. Ní àsìkò yìí kan náà ni Bámijí Òjó ronú pé iṣẹ́ ìròyìn ti orí Rédíò Sáá ní ó wu òun. Ó wá ń bá wọn ṣiṣẹ́ aáyan ògbufọ̀ ni ilé-iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Èyí ni ó ń ṣe tí ó fi ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ “Tribune” àti nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Ní ọdún 1971 ni wọ́n gba Bámijí Òjó gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Ìròyìn ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Àwọn tí wọ́n jìjọ ṣiṣẹ́ ìròyìn nígbà náà ni Alàgbà Ọláòlú Olúmìídé tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀, Olóògbé Àlhàájì Sàká Ṣíkágbọ́ àti Olóògbé Akíntúndé Ògúnṣínà àti bàbá Omídèyí. Nítorí ìtara ọkàn tí Bámijí Òjó ní láti ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Tẹlifíṣàn ó kúrò ní “Radio Nigeria”, ó lọ sí “Western Nigerian Broadcastint Service” àti “Western Nigerian Televeision Station” WNBS/WNTV tó wà ní Agodi Ìbàdàn, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1973. Ni ibẹ̀ ni ọkà rẹ̀ ti balẹ̀ tí àyè sì ti gbà á láti lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti gbé èdè, àṣà àti lítíréṣọ̀ Yorùbá lárugẹ. Ìràwọ̀ rẹ̀ si bẹ̀rẹ̀ sí í tàn gidigidi lẹ́nu iṣẹ́ ìròyìn. Nígbà ti Bámijí Òjó wà ní “Radio Nigeria” kí ó tó lọ sí “Western Nigerian Television Station (WNTV)” ni wọ́n ti kọ́kọ́ ran àwọn oníṣẹ́ ibẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Rédíò. Ilé iṣẹ́ Rédíò ní Ìkòyí ni wọn ti gba idánilẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ìdí nip é tí ènìyàn bá máa sọ̀rọ̀ nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”nígbà náà ó gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́. Lára àwọn ètò tó máa ń ṣe lórí ẹ̀rọ Tẹlifísàn ni “Káàárọ̀-oò-jíire” àti “Tiwa-n-tiwa” túbọ̀sún Ọládàpọ̀, Láoyè Bégúnjọbí àti àwọn mìíràn ni wọ́n jọ wà níbi iṣẹ́ nígbà náà. Gbogbo akitiyan yìí mú kí ìrírí Bámijí gbòòrò si nípa iṣẹ́ ìròyìn àti ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn inú rẹ̀. Ní ọdún 1976 ni Bámijí Òjó lọ fún ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ ní Òkè Òkun, ní orílẹ̀ èdè kenyà níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí “Certificate Course In Mass Communication” (Ìlànà Ìgbétèkalẹ̀ lórí afẹ́fẹ́). Nígbà tí ó di oṣù kẹwàá ọdún 1976, ni wọ́n dá àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ta sílẹ̀, Ọ̀yọ́, Òndó àti Ògùn, Bámijí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó kúrò ni ilé iṣẹ́ “Western Nigerian Broadcasting Services” àti “Western Nigerian Television Station (WNBS/WNTV) tí ó lọ dá Rédíò Ọ̀yọ́ sílẹ̀. Engineer Olúwọlé Dáre ni ó kó wọn lọ nígbà náà, Kúnlé Adélékè, Adébáyọ̀ ni wọ́n jìjọ dá ilé iṣẹ́ Rédíò sí lẹ̀ ni October 1976, wọ́n kó ilé iṣẹ́ wọn lọ sí Oríta Baṣọ̀run Ìbàdàn. Nínú ọdún 1981 ni Bámijì Òjó tún pa iṣẹ́ tì, tí ó tún lọ fún ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ Rédíò ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó jẹ́ gbajúgbajà ní àgbáyé tí wọn ń pè ní “British Broadcasting Co-operation (BBC) London fún Certificate Course. Ní ọdún 1983 ni ó lọ sí orílẹ̀ èdè Germany fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Olóṣù mẹ́ta ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí à ń pè ni “Voice of Germany”. Níbẹ̀ ló ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ Rédíò àti Móhùnmáwòrán. Ìgbà tí Bámijì Òjó dé ni ó jókòó ti iṣẹ́ tí ó yìn láàyò. Èyí ni ó ń ṣe títí tí wọ́n tún fi pín Ọ̀yọ́ sí méjì tí àwọn Ọ̀ṣun lọ, èyí mú kí àǹfààní wà láti tẹ̀ síwájú. Oríṣìíríṣìí ìgbéga ni ó wáyé nígbà náà ṣùgbọ́n ìgbéga tí ó gbẹ̀yìn nínú iṣẹ́ oníròyìn ni “Director of Programmes’ tí wọ́n fún Bámijí Òjó nínú oṣù kẹsàn-án, ọdún 1991, Ó sì wà lẹ́nu iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn ẹ̀ka tí ó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ títí di ọdún 1994. Ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1994 ni ó fẹ̀yìn tì. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé, nínú oṣù kìíní ọdún 1995 ni Bámijì Òjó dá ilé iṣẹ́ tirẹ̀ náà sílẹ̀. Èyí tí ó pa orúkọ rẹ̀ ní ‘Bámijí Òjó Communicatio Center’. Bámijì Òjó tin í iyàwó bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run sì ti fi ọmọ márùn-ún dá a lọ́lá. Oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn móríyá àti ìkansáárásí ni Bámijí Òjó gbà nígbà tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ijọba. Fún orí pí pé àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀ tí ó fi hàn ní ilẹ̀ Germany. Ó gba onírúurú ẹ̀bùn fún àṣeyọrí àti àṣeyege ní òpin ẹ̀kọ́ náà. Pẹ̀lú ìrírí àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ ní ‘London’ àti ‘Germany’ó di ọmọ ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí ‘Overseas Broadcasters’ Association’. Ní ọdún 1990 ni ọ̀gágun Abudul Kareem Àdìsá fún Bámijí Òjó ní ẹ̀bùn ìkansáárá sí, èyí ni ‘Ọ̀yọ́ State Merit Award for the best producer or the year’. Fún ìmọ rírì ètò tí ó ń ṣe ní orí ‘Television Broadcasting Co-operation Ọ̀yọ́ State (BCOS)’ Ṣó Dáa Bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń jé àǹfààní rẹ̀, Aláyélúwà Ọba Emmanuel Adégbóyèga Adéyẹmọ Ọ̀pẹ́rìndé 1. ni ó fi oyè Májẹ̀óbà jẹ́ ti ilú Ìbàdàn dá a lọ́lá, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1994. 1.5 Bámijì Òjó Gẹ́gẹ́ Bi Ònkọ̀wé Ìwé Ìtàn Àròsọ Yorùbá Ìwé kíkọ jẹ ohun ti Bámijì Òjó nífẹ̀ẹ́ sí. Ọba Adìkúta jẹ́ ọ̀ken lára ìwé méjì sí mẹ́ta tí ó ti kọ jáde. Ìwé àkọ́kọ́ tí Bámijì Òjó kọ jáde ni Mẹ́numọ́. Ìwé yìí jáde ni ọdún 1989. Lẹ́yìn èyí ni Bámijì Òjó kọ ìwé rẹ̀ kejì. Ọba Adìkúta tí ó jáde nínú oṣù kẹta ọdún 1995. Nígbà tí Bámijì Òjó wà ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria” ni ó ti kọ́kọ́ kọ ìwé kan tí ó pè ní Àṣà Àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ìwé yìí wà lọ́dọ̀ àwọn atẹ̀wétà tí ó gbàgbé sí wọn lọ́dọ̀ tí kò sì jáde di òní olónìí. Bámijì Òjó gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí ó ní ìtara ọkàn. ó tún ní àwọn ìwé méjì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí yóò jáde ní àìpẹ́. Àkọ́kọ́ ni Ṣódaa Bẹ́ẹ̀. Ìwé yìí jẹ́ àbájáde ètò kan tí ó ṣe pàtàkì lórí Rédíò. Òmíràn ni ètò Èyí Àrà. Bámijí Òjó ni ó dá ètò náà sílẹ̀¸ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin ọdún 1984. Ní ilẹ̀ Yorùbá pàápàá jù lọ “South West”, òun ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kò sí ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó síwájú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ètò yìí “Phone In” Èyí Àrà.
Bámijí Òjó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2358
2358
Ọ̀gbàgì Ìlú Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú pàtàkì tó wà ní agbègbè àríwá Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìlú yìí wà láàárín Ìkàrẹ́ àti Ìrùn tó jẹ́ ààlà àríwá Àkókó àti Èkìtì. Ìlú Ọ̀gbàgì wà ní ojú ọ̀nà tó wá láti Adó-Èkìtì sí Ìkàrẹ́-Àkókó ó sì jẹ́ kìlómítà mẹ́rìnláá sí ìlú Ìkàrẹ́. Láti Ìkàrẹ́, ìlú Ọ̀gbàgì wà ní apá ìwọ̀ oòrùn tí ó sì jẹ́ pé títì tí a yọ́ ọ̀dà sí ló so ó pọ̀ mọ́ ìlú Ìkàrẹ́ tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Àkókó. Ìlú Ọ̀gbàgì kò jìnnà sí àwọn ìlú ńlá mìíràn ní agbègbè rẹ̀. Ní ìlà oòrùn Ọ̀gbàgì, a lè rí ìlú bí i Ìkàrẹ́ àti Arigidi àti ní ìwọ̀ oòrùn ìlú yìí ni ìlú Ìrùn wà ní ọ̀nà tó lọ sí Adó-Èkìtì. Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú mẹ́fà tí ó tóbi jùlọ ní agbègbè àríwá Àkókó nírorí ìwádìí sọ fún wa pé gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn, ti ọdún `963, àwọn ènìyàn ìlú yìí ju Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ nígbà náà ṣùgbọ́n èyí yóò tit ó ìlọ́po méjì rẹ̀ lóde òní. Ìlú yìí jẹ́ ìlú ti a tẹ̀dó sí ibi tí ó tẹ́jú ṣùgbọ́n tí òkè yí i po, lára àwọn òkè wọ̀nyí sì ni a ti rí òkè Oròkè tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ojýbọ Òrìṣà Òkè Ọ̀gbàgì. ` Ojú ọ̀nà wọ ìlú yìí láti àwọn ìlú tó yí i pot í ó sì jẹ́ pé èyí mú ìrìnnjò láti Ọ̀gbàgì sí ìlúkílùú ní Ìpinlẹ̀ Oǹdó rọrùn. Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí mú un rọrùn láti máa kó àwọn irè oko wọ̀lú láti gbogbo ìgbèríko tó yí ìlú Ọ̀gbàgì ká. Gẹ́gẹ́ bi ó ti jẹ́ pé oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ àti lóde òní, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè rí i ní ìlú Ọ̀gbàgì níbi tó jẹ́ pé púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá ni wọn ń ṣe. Iṣẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ pàtàkì iṣẹ́ àwọn Yorùbá ló rí àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Iṣẹ́ àwọn ọkùnrin ni ẹmu-dídá tó tún ṣe pàtàkì tẹ̀lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Òwò ṣíṣe, oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tàbí iṣẹ́ ọwọ́ bí i agbọ̀n híhun, irun gígẹ̀, iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ, ilé mímọ àti iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Iṣẹ́ àwọn obìrin sì ni aṣọ híhun, irun dídì, òwò ṣíṣe àti àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìjọba ti ọkùnrin àti obìnrin ń ṣe. Nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ tí wọn ń ṣe, púpọ̀ nínú oúnjẹ wọn ló wá láti ìlú yìí tí ó sì jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ ni oúnjẹ tí a ń kó wọ̀lú. Iṣẹ́ ẹmu-dídá pàápàá ti fẹ́ ẹ̀ borí iṣẹ́ mìíràn gbogbo nítorí èrè púpọ̀ ni àwọn tó ń dá a ń rí lórí rẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé àwọn àgbẹ̀ oníkòkó kò lè fọwọ́ rọ́ àwọn adẹ́mu sẹ́hìn nítorí ẹmu-dídá kò ní àsìkò kan pàtó, yípo ọdún ni wọ́n ń dá a. Iṣẹ́ ẹmu-dídá yìí ṣe pàtàkì nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ògùrọ̀ ni a lè rí ní ìlú yìí àti ní gbogbo oko wọn. Àwọn adẹ́mu wọ̀nyí máa ń gbin igi ògùrọ̀ sí àwọn bèbè odò bí àwọn àgbẹ̀ oníkòkó ṣe máa ń gbin kòkó wọn. Èyí ló sì mú kí àwọn tó ń ta ẹmu ní Ìkàrẹ́, Arigidi, Ugbẹ̀, Ìrùn àti Ìkáràm máa wá sí ìlú Ọ̀gbàgì wá ra ẹmu ní ojoojúmọ́. Bí a ti rí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọna ti iṣẹ́ ń gbé wá sí ìlú Ọ̀gbàgì náà ni a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Ọ̀gbàgì tí iṣẹ́ ìjọba gbé lọ sí ibòmíràn, nítorí náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ìbá wà láàárín ìlú yìí ni wọ́n wà lẹ́hìn odi. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí a lè rí ní àárín ìlú náà ni àwọn olùkọ́ àwọn ọlọ́pàá, ọ̀sìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́, òṣìṣẹ́ ilé ìfìwéránṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀. Idí tí a fir í àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wọ̀nyí ni àwọn àǹfààní tí ìjọba mú dé ìlú yìí bí i kíkọ́ ilé ìgbẹ̀bí àti ìgboògùn, ilé ìdájọ́ ìbílẹ̀, ilé ìfìwéránṣẹ́, ilé ìfowópamọ́, ọjà kíkọ́, ilé ọlọ́pàá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gíga àti ilé-ẹ̀kọ́ kéékèèkéé. Nípa ti ẹ̀sìn, àwọn oríṣìí ẹ̀sìn mẹ́ta pàtàkì tí a lè rí lóde òní ní ilẹ̀ Yorùbá náà ló wà ní Ọ̀gbàgì. Fún àpẹẹrẹ, a lè rí ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àti àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé tó jẹ́ ẹ̀sìn kirisitẹẹni àti ẹ̀sìn mùsùlùmí. Nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a ti rí oríṣìíríṣìí àwọn òrìṣà tí wọn ń sìn, èyí tí òrìṣà òkè Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tó wà fún gbogbo ìlú Ọ̀gbàgì. Bí a ti rí àwọn tó jẹ́ pé wọn kò ní ẹ̀sìn méjì ju ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a rí àwọn mìíràn tó wà nínú àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé wọ̀nyí síbẹ̀ tí wọn tún ń nípa nínú bíbọ àwọn òrìṣà inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀. Eléyìí lè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn ìdílé tàbí àwọn àwòrò òrìṣà tó jẹ́ dandan fún wọn láti jẹ oyè àwòrò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn mìíràn ni wọ́n nítorí ìdílé wọn ló ń jẹ oyè náà. Ẹ̀sìn ìbílẹ̀ kò jẹ́ alátakò fún ẹ̀sìnkẹsìn ni wọ̀ngbà tí ẹ̀sìn náà bá lé mú ire bá àwọn olùsìn. Àpèjúwe mi yìí kò ní kún tó tí mo bá fẹnu ba gbogbo nǹkan láìsọ ẹ̀yà èdè tí ìlú Ọ̀gbàgì ń sọ. Ní agbègbè Àkókó, oríṣìíríṣìí èdè àdùgbò tó jẹ́ ara ẹ̀yà èdè Yorùbá ni a lè rí, nítorí ìdí èyí, ó ṣe é ṣe kí ọmọ ìlú kan máà gbọ́ èdè ìlú kejì tí kò ju kìlómítà méjì sí ara wọn. Nítorí náà, ó dàbí ẹni pé iye ìlú tí a lẹ̀ rí ní agbègbè àríwá Àkókó tàbí ní Àkókó ní àpapọ̀ ní iye ẹ̀yà èdè tí a lè rí. Ṣùgbọ́n a rí àwọn ìlú díẹ̀ tí wọn gbọ́ èdè ara wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà díẹ̀díẹ̀ nínú wọn. Ó ṣe é ṣe kí irú ìyàtọ̀-sára èdè yìí ṣẹlẹ̀ nípa oríṣìíríṣìí ogun abẹ́lé tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ nítorí èyí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tẹ̀dó sí agbègbè yìí tí ó sì fa sísọ oníruurú èdè tó yàtọ̀ sí ara wọn nítorí agbègbè yìí jẹ́ ààlà láàárín Ìpínlẹ̀ Oǹdó, Kwara àti Bendel lóde òní. Nítorí ìdí èyí, èdè Ọ̀gbàgì jẹ́ àdàpọ̀ èdè Èkìtì àti ti Àkókó ṣùgbọ́n èdè Èkìtì ló fara mọ́ jùlọ nítorí ìwọ̀nba ni àwọn ìyàtọ̀ tó wà nínú èdè Ọ̀gbàgì àti ti Èkìtì gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú àwọn orin àti ewì tí mo gbà sílẹ̀. Fún ìdí èyí, kò ní ṣòro rárá fún ẹni tó wá láti Èkìtì láti gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì tàbí láti sọ èdè Ọ̀gbàgì ṣùgbọ́n ìṣòro ni fún ẹni tó wá láti ìlú mìíràn ní Àkókó láti gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì tàbí láti sọ ọ́ yàtọ̀ sí àwọn ìlú díẹ̀ ní àkókó tí wọn tún ń sọ ẹ̀yà èdè Èkìtì bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ìlú Ìrùn, Àfìn, Eṣé àti Ìrọ̀ ti wọn wà ní agbègbè kan náà pẹ̀lú Ọ̀gbàgì lè sọ tàbí gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Bí ó ti wù kí ìṣòro gbígbọ́ èdè yìí pọ̀ tó, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun fún àǹfààní tí mo ní láti ṣiṣẹ́ láàárín àwọn ará ìlú yìí fún ọdún márùn ún tí ó mú kí ń lè gbọ́ díẹ̀ nínú èdè Ọ̀gbàgì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lè sọ ọ́ ṣùgbọ́n mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Olóyè Odù tó jẹ́ olùtọ́nisọ́nà àti olùrànlọ́wọ́ mi tó jẹ́ ọmọ Ọ̀gbàgì tó sì gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá láti ṣe àlàyé lórí àwọn nǹkan tó ta kókó èyí tí ó sì mú kí iṣẹ́ ìwádìí yìí rọrùn láti ṣe.
Ọ̀gbàgì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2359
2359
Ìrè-Èkìtì Ire-Ekiti F.I. Ibitoye Ogun F.I. Ibitoye (1981), ‘Ìlú Ìrè-Èkìtì’, láti inú ‘Òrìṣà Ògún ní ìlú Ìrè-Èkìtì.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwé 1-3. Ìrè-Èkìtì jẹ́ ìlú kan ní agbègbè àríwá Èkìtì ní ìpínlẹ̀ Oǹdó; èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ bíbí inú ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn àtijọ́. Tí ènìyàn bá gba ojú títì ọlọ́dà wọ ìlú Ìrè, ó rí bi kìlómítà márùndínlógójì sí Ìkọ̀lé-Èkìtì tí í ṣe olú ìlú fún gbogbo agbègbè àríwá Èkìtì. Ṣùgbọ́n ó fi díẹ̀ lé ni ogóje kìlómítà láti Ilé-Ifẹ̀. Èyiini tí a bá gba ọ̀nà Adó-Èkìtì. Nígbà tí a bá gba ọ̀nà yìí, lẹ́hìn tí a dé Ìlúpéjú-Èkìtì ni a óò wá yà kúrò ní títí ọlọ́dà sí apá ọ̀tún. Ọ̀nà apá ọ̀tún yẹn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe ni a óò wá tọ̀ dé Ìrè-Èkìtì, kìlómítà márùn-ún ibi tí a ti máa yà jẹ́ sí ìlú Ìrè-Èkìtì. Ara ẹ̀yà ilẹ̀ Yorùbá náà ní ilú Ìrè-Èkìtì wà. Àwọn gan-an pàápàá sì tilẹ̀ fi ọwọ́ sọ àyà pé láti Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ti wá. Wọ́n tún tẹnu mọ́ ọ dáradára pé ibẹ̀ ni àwọn ti gbé adé ọba wọn wa. Nítorí náà, títí di òní olónìí, Onírè ti Ìlù Ìre-Èkìtì jẹ́ ògbóǹtagi kan nínú àwọn ọba Aládé tí ó wà ní Èkìtì. Gẹ́gẹ́ bí n óò ti ṣe àlàyẹ́ ní orí kejì ìwé àpilẹ̀kọ yìí, “Oní-èrè” ni ìtàn sọ fún wa pé wọ́n gé kúrú sí “Onírè” ti ìsìnyìí. Alàyẹ́ Samuel Johnson nínú The History of The Yoruba. sì ti fi yé wa pé nítorí oríṣìíríṣìí òkè tí ó yi gbogbo ẹ̀yà Yorùbá tí à ń pe ní Èkìtì ká, ni a ṣe ń pè wọ́n bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, orúkọ àjùmọ jẹ́ ní “Èkìtì”. Ìtàn sí tún fi yé mi pé ìlú kékeré kan tí ó ń jẹ́ “Igbó Ìrùn” ni àwọn ará Ìrè-Èkìtì ti ṣí wá sí ibi tí wọ́n wà báyìí; àìsàn kan ló sì lé wọn kúrò níbẹ̀. “Igbó Ìrùn” ti di igbó ní ìsinyìí, ṣùgbọn apá àríwá Ìrè-Èkìtì ló wà. Mo fi èyí hàn nínú àwòrán ìlú náà. Ìṣesí àwọn ará Ìrè-Èkìtì kò yàtọ̀ sí tí àwọn ìlú Yorùbá yòókù, yálà nípa aṣọ wíwọ̀ tàbí àṣà mìíràn. Àrùn tí í sìí ṣe Àbọ́yadé, gbogbo Ọya níí ṣe. Àwọn náà kò kẹ̀rẹ̀ nípa gbígba ẹ̀sìn Òkèèrè mọ́ra nígbà tí gbogbo ilẹ̀ Yorùbá mìíràn ń ṣe èyí. Ẹsìn Ìjọ Páàdi àti ti Lárúbáwá ni a gbọ́ pé wọ́n gbárùkù mọ́ jù. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì ń ráyẹ̀ gbọ́ ti ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá, bí ọ́ tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ ó ní àwọn àdúgbò tí èyí múmú láyà wọn jù. Fún àpẹrẹ, mo tọka sí àwọn àdúgbò tí wọn ti mọ̀ nípa Òrìṣà Ògún dáadáa nínú àwòrán. Èdè Èkìtì nì òdè Àdúgbọ̀ wọn. Nítorí náà, ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin èdè Èkìtì àti ti Yorùbá káríayé náà ló wà ní tiwọn. Fún àpẹẹrẹ wọn a máa pa àwọn kóńsónàntì kan bíi ‘w’ jẹ. Wọn a pe “owó,” ‘Òwírọ̀’ “Àwòrò” ni “eó”, “ọ̀úrọ̀”, “Àòrò”. Wọ́n tún lè pa ‘h’ gan-an jẹ; kí wọ́n pe “Ahéré”ní “Aéré. Nítorí náà “Aéré eó” yóò dípò “Ahéré owó” Nígbà mìíràn pàápàá, wọn a fi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan dípò òmíràn, fún àpẹẹrẹ: ira yóò dípò ará erú yóò dípò erú èyé yóò dípò ìyá. àbá yóò dípò bàbá ijọ́ yóò dípò ọjọ́ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ, àwọn náà tún máa ń fi fáwẹ́lì ‘u’ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Fún àpẹẹrẹ: Ulé dípò Ilé Ùrè dípò Ìrè Ufẹ̀ dípò Ifẹ̀ Ukú dípò Ikú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni èdè yìí fi yàtọ̀ si ti Yorùbá káríayé. Nítorí náà, mo kàn ṣì ń ṣe àlàyé rẹ̀ léréfèé ni, n óò tún máa mẹ́nu bá wọ́n nígbà tí a bá ń ṣe àtúpayá èdè orin Ògún. Ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀ ni.
Ìrè-Èkìtì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2362
2362
Ọ̀ra Ìgbómínà Ọ̀ra Ìgbómínà Agbègbè Ìlá-Ọ̀ràngún ni Ọ̀ra-Ìgbómìnà wà. Ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà ló dúró bí afárá tí a lè gùn kọjá sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ípínlẹ̀ Ondó, àti ìpínlẹ́ Kwara. Ìkóríta ìpínlẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni Ọ̀ra-ìgbómìnà wà, ṣùgbọ́n ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní wọ́ ṣírò rẹ̀ mọ́. Kilómítà mẹ́tàlá ni Ọ̀ra-Ìgbómìnà sí Ìlá-Ọ̀ràngún tó wá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Kílómítà mẹ́ta péré ni Ọ̀ra sí Àránọ̀rin tó wà ní ìpínlẹ́ Kwara, ó sì jẹ́ Kìlómítà kan péré sí Ọ̀sàn Èkìtì tó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ilé-Ifẹ̀ ni àwọm Ọ̀ra ti wá ní òórọ̀ ọjọ́. Ìtàn àtẹnudẹ́nu fi yẹ́ ni pé kì í ṣe Ọ̀ra àkọ́kọ́ ni wọ́n wà báyìí. Ní ǹkan bí ọ̀rìnlé-lẹ́ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́hìn ni wọ́n tẹ ibi tí wọ́n wà báyìí dó. Ọra-Ìgbómìnà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú tí ogun dààmú-púpọ̀ ní ayé àtijọ́. Nínú àwọn ogun tí ìtàn sọ fún ni pọ́ dààmú Ọ̀ra ni – ogun Ìyápọ̀ (ìyàápọ̀), ogun Jálumi, Èkìtì Parapọ̀, àti ògun Ògbórí-ẹfọ̀n. Ní àkókò náà, àwọn akọni pọ́ ní Ọ̀ra lábẹ́ àkóso Akẹsin ọba wọn. Àwọn ògbógi olórí ogun nígbà náà ni ‘Eésinkin Ajagunmọ́rùkú àti Eníkọ̀tún Lámọdi ti Òkè-Ópó àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun mìíràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fí ìbẹ̀rù-bójo sá kúrò ní ìlú ní àkókò ogun. Nígbà tí ogun rọlẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ nínú àwọn to ti ságun ló pádá wá sí Ọ̀ra ṣùgbọ́n àwọn mìíràn kò padà mọ́ títí di òní olónìí. Àwọn Òkèèwù tó jẹ́ aládùúgbò Ọra náà ṣí kúrò ní Kèságbé ìlú wọn, wọ́n sì wá sí Ọ̀ra. Nínú àwọn tí kò pádà sí Ọ̀ra mọ́, a rí àwọ́n tọ́ wá ní Rorẹ́, Òmù-àrán, Ìlọfà àti Ibàdàn. Àwọn ìran wọn wà níbẹ́ títí dì òní olónìí. Ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí, ìlú méjì ló papọ̀ tí a ń pè ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà - Ọ̀ra àti Òkèèwù, ìlú ọlọ́ba sin i méjèèjì. B. ÌṢẸ̀DÁ ÌLÚ Ọ̀RA-ÌGBÓMÌNÀ Nítorí pẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ìṣẹ̀dá àwọn ìlú Yorùbá jẹ́ àtẹnudẹ́nu, ó máa ń sòro láti sọ ní pàtó pé báyìí-báyìí ni ìlú kan ṣe ṣẹ̀. Nígbà míràn a lè gbọ́ tọ́ bí ìtàn méjì, mẹ́ta, tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ nípa bí ìlú kan ṣe ṣẹ́. Báyìí gan-an nit i ìṣẹ̀dá ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà rí. Ohun tí a gbọ́ ni a kọ sílẹ̀ ní éréfẹ̀ẹ́ nítorí kì í kúkú ṣe orí ìtàn ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà gan-an ni mo ń kọ ìwé lé, ṣùgbọ́n bí òǹkàwé bá mọ díẹ̀ nínú ìtàn tó jẹ mọ́ ìṣẹ̀dá ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà, yóò lè gbádùn gbogbo ohún tí a bá sọ nípa Ọdún Òrìṣà Ẹlẹ́fọ̀n ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà tí mo ń kọ Ìwé nípa rẹ̀. Ìtàn kan sọ pé àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀ra Ìgbómìnà kì í ṣe ọ̀kan náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá. Irú wá, ògìrì wá ni ọ̀rọ̀ ìlú Ọ̀ra. Àwọn ọmọ alápà wá láti Ilé-Ifẹ̀. Àwọn Ìjásíọ̀ wá látio Ifọ́n. Awọn Òkè-Òpó àti Okè kanga wá láti Ọ̀yọ́ Ilé, àwọn mìíràn sí wá láti Ẹpẹ̀ àti ilẹ̀ Tápà. Kò sí ẹni tó lè sọ pé àwọn ilé báyìí-báyìí ló kọ́kọ́ dé ṣùgbọ́n gbogbo àwọn agbolé náà parapọ̀ sábẹ́ àkóso Akẹsìn tó jẹ́ ọmọ Alápà-merì láti Ilé Ọ̀rámifẹ̀ ní Ilé-Ifẹ̀. Orúkọ ibi tí àwọn ọmọ Alápà ti ṣí wá sí Ọ̀ra-Ìgbómìnà náà ni wọ́n fi sọ ìlú Ọ̀ra títí di Òní-Ọ̀ra Oríjà ni wọ́n ti ṣí wá, wọ́n sì sọ íbi tí wọn dó sí ní Ọ̀ra. (Èdè Ìgbómìnà tí wọ́n ń sọ ni wọ́n ṣe ń pe ìlú wọn ní Ọra-Ìgbómìnà). Àkókò ogun jíjà ni àkókò náà, gbogbo wọn sì máa ń pa ra pọ̀ jagún ni Àwọn-jagunjagun pọ̀ nínú wọn. Jagúnjagun gan-an sì ni Akẹsin tó jẹ́ olórí wọn. Àwọn méjì nínú àwọn olórí ogun wọn ni Eésinkin Ajagun-má-rùkú àti Eníkọ̀tún tí wọ́n pe àpèjà rẹ̀ ní Lámọdi. Eésinkin Ajagun-má-rùkú ló wa yàrà yí gbogbo ìlú Ọ̀ra po. Eníkọ̀tún Lámọdi ló lé ogun Èkìtì-Parapọ̀ títí dé òdò kan tí wọn ń pè ní Àrìgbárá. Àwọn tí ọwọ rẹ̀ sì tẹ̀, wọ́n mọ wọ́n mọ́ odi láàyè ni ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń ki àwọn ọmọ Òkè-Òpó ní oríkì- “Ọmọ Eníkọ̀tún ṣàbi Ọmọ Lámọdi Ọmọ Àyánwọ́nyanwọ̀n - ọkùnrin Ọmọ Àràpo ni ti ìbẹ̀tẹ́ Ọ́mọ́ Álẹ́kàn d’Arìghárá Ọmọ Alégun dé Sanmọr Baba yín ló pè èjì Ẹ̀kàn Lọ́jọ́ Ọjọ́ra Kọ́la.” Lẹ́hìn ogun ìyápọ̀ àti ogun ògbórí-ẹfọ̀n, àwọn aládùúgbò wọn kan tó ti wà ní Kèságbé lábẹ́ àkóso ọba wọn Aṣáọ̀ni bá Akẹsìn sọ ọ́ kí ó lè fún òun nílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (Akẹsìn) kí wọn lè jọ máa parapọ̀ jagun bí ogun bá tún dé. Akẹsìn bá àwọn ìjòyè rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì gbà. Wọ́n fún Aṣáọ̀ni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ilẹ̀ ní Ọ̀ra. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà tí lọ, obìnrin kan tó ṣe àtakò pé kí wọn má fún àwọn ọmọ Aṣáọ̀ni tí wọ́n ń pe ní Òkèèwù láàyè, wọ́n dá a dọ̀ọ̀bálẹ̀ wọ́n sì tẹ́ ẹ́ pa lẹ́ẹ̀kẹsẹ̀. Báyìí ni ọba ṣe di méjì ní ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà. Ṣùgbọ́n wọ́n jọ ní àdéhùn, wọ́n sì gbà pé Akẹsìn ló nilẹ̀. Ìyáàfin Bojúwoyè (Òkè-Òpó) ẹni àádọ́rin ọdún àti ìyáàgba Dégbénlé (Ìjásíọ̀) ẹni àádọ́rùnún ọdún ó lé mẹ́fà tí wọ́n sọ itàn yìí fún mi kò ta ko ara wọn rárá, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe àkókò kan náà ni mo ṣe ìwádìí ìtàn lẹ́nu àwọn méjèèjì. Àwọn méjèèjì ló wà láyé ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. Ìran Lámọdi ọmọ Òpómúléró tó wá láti ilé Alápínni ní Ọ̀yọ́ ilé ni ìyáàfin Bojúwoye ìran Enífọ́n sì ni ìyáàgbà Dégbénlé. Àwọn méjèèjì ló wà láyé ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. Ìtàn kejì tí mo gbà sílẹ̀ lẹnu ìyá àgbà Adégbénlé (Iyá-Ìlá) ti ìjásíọ̀ sọ fún wa pé ìlú méjì ló parapọ̀ di Ọ̀ra bí a ti mọ̀ ọ́n lónìí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, ìlú Ọ̀ra ti wà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kí ogun ‘iyápọ̀’ ati ogun ‘Èkìtìparapọ̀’ tó dé. Ìlú kan sí wà létí Ọ̀ra tó ń jẹ́ Òkèwù. Àwọn ìlú méjèèjì yí pààlà ni. Igi ìrókò méjì ló dúró bí ààlà ìlú méjèèjì. Igi ìrokò kan ń bẹ ní ìgberí Ọ̀ra, ìyẹn ni wọ́n ń pè ní ìrókò Agóló, ọ̀kan sì ń bẹ ní ìgberí Òkẹ̀wù, ìyẹn ni wọn ń pè ní irókò Mọ́jápa (Èmi pàápàá gbọ́njú mọ igi ìrókò mejèèjì; ìrókò mọ́jápa nìkan ni wọ́n ti gé ní àkókò tí mo ń kọ̀wé yìí; ìrókò Agólò sì wà níbẹ̀) Nítorí àwọn igi ìrókò méjèèjì tó1 Ọ́ra àti òkèwù láàárín yìí, àwọn òkèwù tí ìlú tiwọn ń jẹ́ Kò-sá-gbé’ máa ń ki ara wọn ní oríkì-orílẹ̀ báyìí: “Ọmọ ìrókò kan tẹ́ẹ́rẹ́ tí ń bẹ nígbèrí Ọ̀ra Ọmọ ìrókò kan gàǹgà tí ń bẹ nígberí Òkèwù Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣè ‘ọn Ọ̀ra Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣe ‘ọn Òkèwù Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣe ‘ọn Àtẹ́-ńlẹ́-ọdẹ́ Ọmọ Ọ́dẹ́-mojì, ma a sin’mọ gágá relé ọkọ Àpè-joògùn má bì l’Okèwù”. Ìtàn kẹta jẹ́ èyí tí baba mí gan-an sọ fún mi kí títán tó dé sí i ní dún 1966. Ẹni ọgọ́fa ọdún ni baba mi Olóyè Fabiyi Àyàndá Òpó, mọjàlekan, Aláànì Akẹsìn, nígbà tó tẹ́rí gbaṣọ. Bába mi fi yé mi pé àwọn ojúlé tí wa ní Ọ̀ra nígbà òun gbọ́njú ni Ìperin, Ìjásíọ̀, Òkè-Òpọ́, Òkèágbalá, ilé atè, Odò àbàtà, Òkè-akànangi, Okèkàngá, Òkèọ́jà, odìda, odòò mìjá, Òkèwugbó, Ilé Ásánlú, ilé Akòoyi, ilé sansanran, odònóíṣà ilé ọba-jòkò, ilé Eésinkin-Ọ̀ra ilé ìyá Ọ̀ra, ilẹ́ ọ̀dogun, ilé ọ̀gbara, ilé Olúpo, kereèjà, àti ilé Jégbádò . Gbogbo àwọn ojúlé wọ̀nyí ló wà lábẹ́ àkóso ọba Akẹsìn ṣùgbọ́n àwọn ìwàrẹ̀fà àti àwọn Ẹtalà2 ló ń pàṣẹ ìlú. Ìdí nìyẹn tí wọn ṣe máa ń we pé – “Péú lAkẹ́sìn ń wỌ̀ra”. Akẹsìn kàn jẹ́ ọba Ọ̀ra ni ohun tí àwọn ògbóni tó wà nínú ìgbìmọ̀ - Ìwàrẹ̀fa àti Ẹ̀tàlá bá fi ọ́wọ́ sí ni òun náà yóò fi ọwọ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, àwọn ojúlé wọ̀nyí ni àwọn tí kò parun bí ogun ti dààmú ìlú Ọ̀ra tó. Baba mi tún sọ síwájú sí i pé Òrùlé tó ń bẹ ní Ọ̀ra nígba tí òun gbonjú kò ju ọgbọ̀n lọ, àti pé ṣe ni wọn fa àgbàlá láti Òkè-Òpó dé Òkèkàngá. Bí eégún bá sì jáde ní Òkèòpó, títí yóò fi dé Òkèkàngá ẹnì kan kan lè má rí i bí kò bá fẹ́ kí ènìyàn rí òun. Baba mi wá ṣàlayé pé Aláfà baba ti òun pa á nítàn pé àwọn Okèwù tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ Ọ̀ra, Ọ̀ra sì fún wọn láàyè lórí ìlẹ̀ àwọn ìjásíọ̀ àti Òkè Akànangi. Nígbà tí ibi tí a fún wọ́n kò gba wọ́n, wọ́n tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí Aláfa ní Òkè-Òpó. Nígbà tí awọ́n Òkèwú wá jòkó pẹ̀sẹ̀ tán, àwọn ọmọ íyá wọn tó wà ní Òró àti Agbọnda wá ṣí bá wọ́n. Oníṣòwò ni àwọn tó wá láti Òró wọ̀nyí. Iṣu ànamọ́ li wọn máa ń rù wá sí Ọ̀ra fún tità. Ọ̀nà Àránọ̀rin ni wọ́n máa ń gbà wọ ìlú. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, obìnrin kan tí ara rẹ̀ kò dá máa ń jòkó ní abẹ́ igi kan ní ẹ̀bá ọ̀nà. Ibi tí igi náà wà nígbà náà ni a ń pè ní Arárọ̀mí lónìí. Baba mi so pàtó pé òun mọ obìnrin tí a ń wí yìí àti pé Àdidì ni wọ́n ń pè é. Ìgbà-kìgbà tí àwọn oníṣòwò wọ̀nyí bá ti ń ru iṣu ànàmọ́ ti Ọ̀ró bọ̀, tí wọn bá sì ti dé ọ̀dọ̀ Àdìdì, wọn a sọ ẹrù wọn kalẹ̀, wọn sì sinmi tẹ́rùn. Kí wọn tó kúrò ní ọ̀dọ̀ Àdìdì, wọn á ju iṣu ànàmọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. Báyìí ni àwọn Òkèwù bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i ní Ọ̀ra-Ìgbómínà. Nígbà tó yá, Arójọ̀yójè tó jẹ Aṣáọ̀ni (Ọba ti àwọn okèwú) nígbà náà tọrọ ilẹ̀ díẹ̀ sí i lọ́wọ́ Aláfà òkè-òkó (baba mi àgbà) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́, Aláfà fún un ní ilẹ̀ nítorí àwọn Òke-òpó ní ilẹ̀ ilé púpọ̀. Ilẹ̀ oko nikan ni wọn kò ní ní ọ̀nà. Ní ibi tí Aláfà yọ̀ọ̀da fún Arójòjoyè yìí, akọ-iṣu àtí tábà ni àwọn Òkè-òpó ti máa ń gbìn síbẹ̀ rí. Ibẹ̀ náà ni olọ́ọ̀gbẹ́ Ìgè kọ́ ilẹ́ rẹ̀ sí. Ilẹ́ náà wà níbẹ̀ ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Òkèwù tó rí ààyè kólé sí ṣe ń ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ìyá wọn tó wà ní ẹkùn Òrò àti Agbọndà nìyẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló tún wá láti Èsìẹ́, Ílúdùn, Ìpetu (Kwara), Rorẹ́ àti Òmu-àrán. Báyìí, àwọn ìtàn mìíràn tí àwọn baba ńlá wa kò pa rí ti ń dìde. Nígba tí ọ̀rọ̀ adé gbé ìjà sílẹ̀ ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà láìpẹ́ yìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti wádìí ìtàn Ọ̀ra. Àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ náa wà nínú ìwé ìkéde Gómìná ìpinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olóyè Bọ́lá Ìge tí ní orí ẹrọ asọ̀rọ mágbesí nínú oṣu kẹwàá ọdún 1980 a tún gbọ́ nínú ìkẹ́de yẹn ni pé Òkèwù ló tẹ ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà dó àti pé àwọn ló sọ orúkọ ìlú náà ní Ọ̀ra (A ó ra tán) Ohun tó da àwa lójú ni pẹ́ ìlú méjì ló papọ̀ tí wọn so Ọ̀ra-Ìgbómìnà ró báyìí. Ìlú ọba Aládé sì ni ìlú méjèèjì Ọ̀ra àti Òkèwù. D. ÀWỌN ÈNÌYÀN ÌLÚ Ọ̀RA, IṢẸ́ OÚNJẸ ÀTI ÈDÈ WỌN Ẹ̀yà Yorùbá kan náà ni gbogbo àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà àti Òkèwù. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀kan náà ni wọ́n ní òórọ̀ ọjọ́ bí a ti sọ ṣáájú. Àwọn ará Ọ̀yọ́ wà ní Ọ̀ra, àwọn árá Ilé-Ifẹ̀ sì wà ní Ọ̀ra pẹ̀lú. Àwọn kan tán sí Èkìtì, àwọn mìíràn si tan sí ìpínlẹ̀ Kwárà. Àwọn tó ti ilẹ̀ Tápà wá ń bẹ ní Ọ̀ra, àwọn tó ti Kàbbà wá sì ń bẹ níbẹ̀ báyìí- àwọn ni ọmọ, Olújùmú. Àwọn Hausá pàápàá wà ní ìlú Ọ̀ra báyìí, ṣùgbọ́n èdè Ìgbómìnà ni èdè tí ó gbégbá oróke láàrin wọn. Iṣẹ́ àgbẹ̀ aroko-jẹun ni iṣẹ Ọ̀ra láti ilẹ̀ wà. Wọ́n ń gbin iṣu, àgbado, àti ẹ̀gẹ́. Àwọn ohun ọ̀gbìn tí wọ́n fi ń ṣowó ni tábà ọ̀pẹ, áko, erèé òwú, obì àbàtà àti ìgbá tí wọ́n fi ń ṣe ìyere fún irú tí wọ́n fi ń ṣe ọbẹ̀.
Ọ̀ra Ìgbómínà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2363
2363
Ìjẹ̀bú-Òde Ìjẹ̀bú-Òde jẹ́ ìlú tó gbajúmọ̀ nílẹ̀ Yorùbá ní Ìpínlẹ̀ Ògùn lápá ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.. Ọba Awùjalẹ̀ ni orúkọ Ọba alạ́dé tí wọ́n fi ń jẹ ní Ìjẹ̀bú-Òde. Ọba Sikiru Kayode Adetona ni ó wà lórí ìtẹ́ lọ́wọ́ ní ìlú Ìjẹ̀bú-Òde. Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀bú-Òde. Orísìírísìí ni ìtàn tí à ń gbó nípa ìsèdá ìjèbú Òde. Sùgbón èyí tí ó wó pò jù nínú àwon ìtàn náà ni mo ménu bà yìí; Alárè fi omobìnrin rè kan Gbórowó, fún Odùduwà láti fi se aya. Léhìn èyí, ó gba ònà Ìseri dé Ìbesè, títí ó fi dúró ní Ìjèbú-Òde. Ajèbú àti Olóde jé lára àwon àtèlé Alárè. Fún isé ribiribi won fún ìlú ni a se so Ibùdó náà lórúko won - Ajèbú-Olóde. Àpèjá orúko yìí ni ó di Ìjèbú-Òde lónìí yìí. Léhìn Alárè ni Lúwà (OLÙ-ÌWÀ) náà dé. Òun náà gba ònà Ilé-Ifè, ó sì yà kí Odùduwà. Lúwà àti Àlárẹ̀ bí ọmọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Osi ni ọmọ Lúwà; Eginrin sì ni ọmọ Alárẹ̀. Ní àsìkò yìí. Ọṣìn tàbí Ọlọ́jà ni à ń pe Olórí Ìjẹ̀bú-Òde. Èdè àìyédè bẹ́ sílẹ̀ láàárín Alárẹ̀ àti Lúwà lórí, i ẹni tí yóò jẹ ọlọ́jà. Nígbà tí wọ́n tọ Ìfá lọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó fí yé wọn pé ẹni tí yóò jẹ olórí kòì tíì dè!. Kò pẹ́ kò jìnnà, lẹ́hìn ikú Alárẹ̀ àti Lúwà, ni àjèjì kan tí o múrá pàpà-rẹrẹ wọ̀lú. Ọ̀nà Oǹdó ni àjèji yíí gbà wọ ìlú. Kò pẹ́, ìròhìn ti tàn ká pé àjìji kán fẹ́ gbọ́gun wọ̀lú. Èyí ni ó mú Apèbí (Olóyè pàtàkì kan ní ibùdó yìí) lọ báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótọ́. Àjèjì yìí kò fèsì lọ báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótọ́. Àjèjì yìí kò fèsì ju pé “Ìjà dà?. láti fi hàn pé òun kò bá ogun wá. Àjèjì náà fi yé wọ́n pé Ògbòrògánńdá-Ajogun ni orúkọ òun. Ó jẹ́ ọmọ Gbórówó tí í ṣe ọmọbìnrin Alárẹ̀ tí ó fún Odùduwà fẹ́ ní Ilé-Ifẹ̀, Ipasẹ̀ àwọn ẹbí ìyáa rẹ̀ ni Ògbòrògánńdà tọ̀ wá, lẹ́hìn ikú bàbá rẹ̀. Títí di òní, àdúgbò tí Apèbí tí pàdé Ògbòrògánńdà ni à ń pè ní ÌJÀDÀ. Àpàbí lọ fi tó olóyè àgbà Jaginrìn tí ó rán an níṣẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀rọ̀ ni àjèjì náà mú wá. Nígbà tí Jaginrìn bi Apèbí ibi tí àjèjì náà wà, Apèbí dáhùn pé “Ọba-ńníta” (Ọba wà ní ìta) nítorí ipò Ọ́ba ni ó rí i pé ó yẹ ẹni pàtàkì bí i tí Ògbòrògbánnńdà-Ajogun. Láti ìgbà yìí ni a tí mọ Ògbòrògánńdà ní Ọbańníta, tí àjápè rẹ̀ di Ọbańta di òní. Agbègbè tí Ọníṣeémù ti lẹ́ ọ̀sà lọ tí a fún Ògbòrògánńdà láti máa gbé ni ó júwe pé” ó tóó ró”- (Ibí yìí) tó láti dúró sí) ni à ń pè ní Ìtóòró di òní. Àdúgbò yìí ni a ṣe ọ̀wọ́n kan sí ní ìrántí Ọbańta, nítorí a kò mọ bí ó ṣe kú. Inú igbó kan ni tòsí Orù-Àwà ni a gbọ́ pé ó rá sí. Ògbórògbánńdá Ajogun (Ọbańta) gbé Winniadé, ọmọ Osi níyàwó. Ósi yìí, bí a ti mọ̀ ṣáájú jẹ́ ọmọ Lúwà. Ọbáńta sì jẹ́ ọmọ-ọmọ Alárẹ̀. Wọ́n bí ọmọkùnrin kan tí ó ń jẹ Mọnigbùwà. Síbẹ̀ aáwọ́ tí ó wà láàárín Lúwà àti Alárẹ̀ nípa óyè jíjẹ kò í tán láàárín àwọ́n ẹbí méjèèjì. Láti fi òpin sí aáwọ̀ yìí, àwọn ará ìlú ní kí Monigbùwà, ọmọ Ọbańta, jáde rẹ̀ ti ṣe ní ọjọ́ kìíní. ‘Mọnigbùwà gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lọ sí ìletò kan tí a mọ̀ sí Òdo, láti ibẹ̀ ní ó sì ti padà wọ ìlú pẹ̀lú ìfọn àti orin. Ọjọ́ yìí ni a gbé adé fún Mọnígbùwà. Oùn ni ó jẹ́ ẹni àkókó ti ó jẹ oyè Awùjalẹ̀ - ‘A-mu-ìjà-ilẹ̀’-èyí ni ẹni tí ó parí ìjá tí ó bá nílẹ̀. Àpápè oyè yìí ni ó di Awùjalẹ̀ dòní yìí. Títí di òní yìí ni ẹnikẹ́ni tí a bá yàn gẹ́gẹ́ bí ọba tuntun gbọ́dọ̀ jáde ní ìlú lọ sí Òdo, kí ó sì wọ ìlú padà gẹ́gẹ́ bí i Mọnigbùwà àti Ọbańta kí ó tó ó gbadé. Lára àwọn olóyè pàtàkì-pàtàkì ní Ìjẹ̀bú-Òde ni Olísà Ẹgbọ̀, Àgbọ̀n, Kakaǹfò, Jaginrìn àti Lápòẹkùn, tí wọ́n jẹ́ óyè ìdílé. Àwọn oyè bí i Ọ̀gbẹ́ni Ọjà kìí ṣe oyè ìdílé. Àwùjalẹ̀ kọkànléláàádọ́ta ni a gbọ́ pé ó wà lórí oyè báyìí. Àwọn Ìjẹ̀bú fẹ́ràn láti máa jẹ kókò àti ọ̀jọ̀jọ̀. Wọ́n tún fẹ́ràn lati máa fi ògìrì sí obẹ̀ àti oúnjẹ wọn mìíràn bíi ikọ́kọrẹ́ láti fún un ní adùn àjẹpọ́nmulá. Ẹ̀sin. Ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ni àwọn ènìyàn Ijẹ̀bú Òde ní ìgbà láíláí. Wọ́n máa ń bọ oríṣiríṣi òrìṣà tí a ń bọ ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bí i Ògún, Ifá, Èsù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òrìṣà ìbílẹ̀ bíi Agẹmọ, Òrò, àti Obìnrin-Òjòwú wà pẹ̀lú. Lode oní àwọn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọ̀nyí kò fi bẹ́ẹ̀ ranlẹ̀ bíi ti àtijọ́ mọ́, síbẹ̀ wọ́n ṣì ń bọ wọ́n lójú méjèèjì. Ẹ̀sìn Mùsùlùmí ni ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn Ìjẹ̀bú-Òde ń ṣe báyìí. Mọṣáláṣí kan wà ní àdúgbò Òyìngbò tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú mọ́ṣáláṣí tí ó tóbi jù ni apá ìwọ́ oòrùn Afríka. Àwọn ẹlẹ́sìn àtẹ̀lé Krístì Lóríṣiríṣi náà kò gbẹ́hìn. Àwọn náà pọ̀ ní ìwọ̀nba tiwọn. Àwọn ìjọ Àgùdà tilẹ̀ fi Ìjẹ̀bú Òde ṣe ibùjúkóó fún dáyósíìsì ti ẹkùn Ìjẹ̀bú. Àwọn Àdúgbò. 1. Àdúgbò: Itaolówájodá Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni àwon ìjòyè Oba ìlú yìí tí a ń pè ni olówá tè dí, ti won si ń se ìjoba lórí àwon ènìyàn tó wà ládùgbó yìí 2. Àdúgbò: Olíwòro Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà alá wà tétètélè, Àwon àwòrò òrìsà yìí ni ó te àdúgbò yìí dó. 3. Àdúgbò: Ìdóbì Ìtùmò: Igi obì púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí bá nígbà ti wón fé te ìbè dó. 4. Àdúgbò: Ìtaòsù Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà òsù wa. ni tori pe ibí yìí ni wón ti ń bo òrìsà yìí ni wón se ń pe e ni ìta òsù. 5. Àdúgbò: Imèpè Ìtùmò: Igi òpe púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí ban i ibi yìí nígbà tí wón fé te ibè dó 6. Àdúgbò: Ayegun Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni òkan lára àwon akoni ode to máa ń ye ojó ogun ti awon olóde yòókù bá ti dá síwájú tè dó ìdí niyìí tí won fi ń pe àdúgbò yìí ni Ayegun. 7. Àdúgbò: Ìtalápò Ìtùmò: Awon ounje orisirisi tí a dì sínú àpò bii àgbàdo, ìyo, ni àwon ara àgbègbè máà ń gbé wá si àdúgbò yìí wá lati tà kí ó tó di àdúgbò. Wón si máà ń na ojà ni àdúgbò yìí títí di òní yìí . 8. Àdúgbò: Ìsasà Ìtùmò: Isé ìkokò mímo ni isé àwon to té àdúgbò yìí dó. Díè lára àwon omo omo won si ń se ìsé yìí 9. Àdúgbò: Ìta Òsùgbó Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni àwon Olósùgbó ti máà ń se ìpàdé. Níbè ni ilé ìpàdé wón wa, kí ó tó di pé won te ibè dó. 10. Àdúgbò: Ìsesí Ìtùmò: Ibí yìí ni ójúbo osi esi wà télètélè kí o to di pé won te ibè do tí o si dí àdúgbò ojúbo osi yìí si wa níbè títí dònìí. 11. Àdúgbò: Ìta Opó Ìtùmò: Àwon Opó ni won máà ń na ojà yìí ni alaalé. Òríta ti wón ń náà yìí ni o di adúgbò, ti wón si ń pe ni ìtà opó. Wón si máà ń ná ojà alé ni àdúgbò yìí títí dònìí 12. Àdúgbò: Molípáà Ìtùmò: Okunrin kan tó mú opà dání ló te apá ibí yìí dó. Ìtàn so fún wa pé àpá ase Oba ìlú ibòmíìràn ló mu dàni nígbà tí o ń bo, àwon kan tilè so pé Àremo oba ìlú náà ni. Nígbà tí o, fé te àdúgbò náà do ó mú òpá yìí dá ni, Ìdí niyìí tó fi je pé won ń je oba ni àdúgbò náà títí di òní yìí 13. Àdúgbò: Ìtóòrò Ìtùmò: Ìtàn so fún wa pé omi nigbogbo àdúgbò yìí teletélè kí ó to dí pe wón te ibè do. Okunrin akoni ti a ń pè ni òró ni o pé ofò tí ó sì le omi náà lo. Ìdí nìyìí ti a fi ń pé àdúgbò náà ni Ìtóòró. 14. Àdúgbò: Olóde Ìtùmò: Ibí yìí ni òkan lára àwon akoni tó te ìlú yii dó kokó dúró si kó tó dip é ó wo àárin ìlú lo. Nígbà ti ijà dé láàrin òun àti àwon tí wón fo wo ìlú yìí, o bínú pàdà si ibi yìí o si wolè. Ìdí niyìí tí wón fi ń pe àdúgbò naa ni Olóde. Oórì okùnrin yìí si wà níbè títí dòníì. 15. Àdúgbò: Odò Èsà Ìtùmò: Eégún kan ti won ń pè ni obrinrin ojòwú ní o te ibí yìí dó. Èégún Odoodún ni eégún máà ń jáde ni àdúgbò yìí títí donii. Ìdí igi ìrókò ni won fi se ojúbo eégún yìí Igi ìrókò yii wà níbè títí dónì yìí. 16. Àdúgbò: Ìdépo Ìtùmò: Isé epo ni àwon to te àdúgbò yìí yàn láàyò léyìn tí wón ti dó síbè. Bí o tilè jé pé won kò se ise epó níbè mó, won si ń ná ojà epo níbè titi dò níí. 17. Àdúgbò: Fìdípòtè Ìtùmò: Lára àwon ìjòyè oba Gbélébùwà àkókó tí won kò fara mo on pé kí wón pa Oba náà ni won wa te àdúgbò yìí dó léyìn ti wón kúrò ni ààfún. 18. Àdúgbò: Apèbi Ìtùmò: Oríta yìí ni àwon ìjoyè Oba Gbétebùwá àkókó péjo sí láti bi ara won ohun ti o ye kí àwon se fún oba náà. 19. Àdúgbò: Ìdéwòn Ìtùmò: Ìtàn so gún wa pé nígbà tí wín fe te ibí yìí dó, wón bá òrìsà kan níbè tó dé adé sórí tó sì fi èwòn onírin se ileke owó àti tí esè. Ìdí ni yìí ti à fi máà ń yan Oba láti ìdílé enití ó te àdúgbò náà dó. Ìdílè yìí náà tílè ni ààfún tí a ń pè ni ààfin Òba ìdéwon. 20. Àdúgbò: Ìta Àfín Ìtùmò: Ìtàn so fún wa pé bí ó tilè jé pé èrúktí o té àdúgbò yìí do kii se àfín, sùgbón gbogbo àwon omo tí won bi láti ìdílè enití o te àdúgbò náà do je àfín. Nígbà ti won lo bi ifá wo, Ifá ni ki won máà bo Obàtálá ni ìdílé náà, láti ìgbà náà lo ni won ti ń bo Obàtálá ni ìdílè yìí. Ti o bad i àsìkò odún òrìsà yìí, àríyá ni fún gbogbo àwon omo àdúgbò yìí àti fún ìlú pàápàá.
Ìjẹ̀bú-Òde
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2397
2397
Ọba Ìséyìn Oba Iseyin ORÌKÌ OBA ÌSÉYÌN. OBA ADÉYERÍ LÁTI ENU (PA) ÁLÍMÌ AJÉYEMÍ ILÉ ALUSÈKÈRÈ NÍ ÌLÚ ÒYÓ Adéyerí omo Alájogun Adéyerí omo wúràólá Adéyerí omo wúràólá Ìyàndá a-báni-sòrò-má-tannìje Adéyerí omo Alájogun À n bó’bo, òbó hun Adéyerí omo alájogun Òbo kìkì are rè. A à féná à ní ò jò A féná tán Oníkálukú n gbénu ú sá kiri Àká baba ìrókò Asawo lode ò febè paní Adéyení omo Alájogun ònà ìbàdàn la ò gbodò rìn O n káà koko Adéyení omo Alájogun Òjò pa kòkò rè gbìn-gbìn-gbìn Òjò tí ì bá pa tápà A dòtúbáté Adéyení omo Alájogun Elébùrú ìké Omo Alájogun Òbo kìkí are rè. N ó k’aséyìn oba àrànse Oyinbó omo Èjìdé àgbé Gbógun léye Àsoba jagun Oyinlolá Oláwóore Peranborí Peran bofá Oláwóore a bèyìn àrò gele-mò-gelé-mò. Kò se é mú ròdá Ò se é mú Gbógunléye Àsobajagun Nlé Oláwóore Baba enìkan ò gbin yánrin Baba enìkan ò gbin gbòrò Omo èjìdé Àgbé Fúnra rè lóhù Aséyìn Oba àrànse Oyinlolá Oláwóore A gbó onísé Oba má mà dúró Omo èjìdé àgbé tí í gbónísé onjò Tí í tún fìlà se ge-ge-ge Oyinlolá Oláwóore Àsán-àn-jòmì-eye Oláwóore Ekùn-abi-làà-làà-ìjà-layà Láwóore ekun-abi-làà-làà ìjà-layà Agbógbe má gbóyàn Oba Àyínde Oyinlolá Láwóore Àbe Afàdàmò-ragun-jànyìn-jànyìn Oyinlolá omo Èjìde Àgbé Dákun má gbéná Oba àrànse ohinlolá Láwóore Nígbà tí ò sí mó Aséyìn ò ti è parun Oyinlolá Oláwóore O kan Adégbìté Sùkú-séré Adégbìté Omo alálè-òrun A-jó-kí-de-ó-ró Baba ori dagogo Àrán kún lé Baba odún sàrìnnàkò ààlà yìgì Ààlà yìgì baba ò dé títí dodún Omo afòkú sòwò Àrèmú Arówólóyè Àbíkú oníjànmón Baba ládépé N-n-gb ó gbinrin lówó òtún Sùkú-mì-séré Mo se bálágbède òrun ní n lurin A-jó-kí-de-ó-ró Baba orí dagogo, n-n-gbó gbinrin Lówó òsì, Adégbìte Mo se bálágbèdè-òrun ló n lurin. A-jó-kíde-á-ró baba orí dagogo Èmi-ò-tetè-mo-pówó-fá-gùn-má-ràjà-gún-gbe Arówólóyè Àbíkú oni jànmó Baba ládépé O dèèkínní onísé ìbàdàn dé wón lógun jà ni Mókín ilé Arówólóyè Oba èse Wón ní mo kí séríkí Mo kí Balógun Mo kótùn-ún Mo kósì O dèèkejì èwèwè Onísé ará ìbàdàn dé Wón lógun jà ni mòkín ilé Arówólóyè Wón ní wón ó kí séríkí dáadáa Wón ó kótùn-ún Wón ó kósì ìbàdàn O dèèketa èwèwè Onísé ará ìbàdàn dé Wón lógun jà ni Mòkín ilé Arówólóyè Oba èse Wón lógun le fún séríkí Ogún le fún Balógun Ogun le fótun-ún Ogun le fósì Kóso kó kí e má le è kó won A-jó-kí-dé-ó-ró Baba orí dagogo Sèkèrè kó ní e má le è sétè Tètè kò pé e má le è kójèbú Arówólóyè Abíkú onijànmó Baba ládépé Járun-járun Kó máa jáwon lo Jósèèké jósèèké Kó pé e má le è kójèbú Arówólóyè Abíkú oníjànmó Baba ládépé O kan Olúgbilé Ìgbà tí ò sí mó Aséyìn ò ti è parun Olúgbilé Eléwu oyè Òmùdún kókò Oba asàwòlòlò Oní jànmó alátise Olúgbilé Aberan nílé bí ode aperin Afàlùkò-jèjèè Jejèé-nílé-oníjànmó Jejèé-lóde Olugbile tó tó baba Láwóore re i se Aborí esin báá-báá lónà komu Abìrù esin tìkòtìkò Lónà ababja Sèrùbàwón baba Àjíà Ológòdo ègi Olúgbilé Aberun nlé bí ode aperin Rèwó-rèwó ní e má ti è rèwó mó Ológòdo egi Olúgbilé ni bá a bá lo Emi ni í máa se ní wàye Mo ní jà mo jùlo N-n-jù-tòsun-lo Òmùwè tí n wè lódò òsà Kó múra kó lè wèé já Iba mi olúgbilé aláwòye Òmùdún kókò oba asàwòlòlò Ìfòròwánilénwò lóri àwon òrò tó ta kókó Ìbéère: kín ni ìtumò gbólóhùn yìí “A à féná, à ní kò jò? Ìdáhùn: ìtumò rè ni pé nígbà ti ìnà kò ì jò ni à n dúró, tí iná bá ràn tán ènìyàn ó ho. Ìbéèrè: kinni ìtúmò omo Alájogun. Ìdáhùn: omo jagun jagun Ìbéèrè: kín ló fa ‘ona ìbàdàn la ò gbodò rìn? Ìdáhùn: Nítorí pé ológun jo ni wón. Ìbéèrè: Abèyìn àrò gelemò-gelemò nkó? Ìdáhùn: ó jé eni tí í máa n ni eran nílé ní gbogbo ìgbà tí ó sì máa n fi í se àlejò. Ìbéèrè: kínni ìtumò Ekùn abi làà-làà ìjà layà? Ìdáhùn: Jagun-jagun tí ó le ni à n pè béè. Ìbéèrè: ìdí tí e fi n pè é ni Oba àrànse? Ìdáhùn: Onírànlówó ènìyàn ni ó n jé béè. Ó n ran ènìyàn lówó. Ìbéèrè: Omo aláte-òrun nkó? Ìdáhùn: Eégún baba won ni aláte-òrun tí a fi n pè é béè. Ìbéèrè: kin ni ìtumò àbíkú oni janmo? Ìdáhùn: E ni tí n dákú. Ìbéèrè: kín ni ìdí tí a fi so pé ó se ori esin báá-báá Lónà kòmu? Ìdáhùn: ìdí ni pé kòmu ni oko rè. Ìbéèrè: òmùdún kókò a sàwòlòlò nkó? Ìdáhùn: Oba tí ara tè ndán ni eléyìní.
Ọba Ìséyìn
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2400
2400
Ọba Ìkòyí Oba Ikoyi ORÍKÌ OBA ÌKÒYÍ. LÁTI ENU ALÀGBÀ OYEKALE ALADE OMO ISÉ FÓYÁNMU) Ùn n lo ilé wa lóhun ò ò ò ò Nílé ìkòyí omo erù ofà Olóòótó omo gbáà, omo gbèdu Yánbínlólú omo Arágáláká kee fikú pogun 1 Àrònì gbonra jìgì dagi erù oògùn nù Omo gbélé Omo gbégbèé Omo gbé ijù, gbébi Ò-gbódi-gbé-yàrá O gbebadan ò kè pé, o gbákínmòórìn, o gbáawé Ò-gbé-fìdítì-gbewàré O gbákínelé, o gbéléefón run O gbélé kúata, òtè ò tán e e bibì làá dé si Kú fúnwon rérìn-ín Olóyè n ni baba mi Ó níbi táa bá gbé, ibe nilé eni Jagunjagun lèrò ìkòyí jé, omo oba a jò lápó wòròwòrò Ogun ló bámi ni gbo Mo dolú igbó N lé mi lóhùnún ma dòsó esin Bí bá n rogun Èrò òdàn bamii lódan mo dèrò òdàn Ogun ló bámi pàlàpálá mee dòpá à bon Àsé Olú nìkòyi jé omo eèru Ofa Témi bá n lo sónà ihè mo mo on lé wa Olúkòyí àfeji, àfeji n lo bí onikoye àfòjò àfòjò Olúkòyí àfòjò àfòjò, un lo wa bí Olúkòyí èèrùn gan gan gan 2 Olúkòyí èèrun gang an gan N ló bí Olúkòyí ìrìwòwò Olúkòyí ìrì wòwò, un ló bi Oníkòyí òdá gbágbá Olúkòyí òdá gbá gba, un ló bi Oníkòyí ò koko Un ba won tó pón kángun síkoto níjóhun Témi bá n sónà bè mo monú ilé wa, Eléyun nì taa lóbí, taa lóbí ? Un ló bí òkéré lèrù gan gang an Òkéré-lèrù gan gan gan gàgbon n baba won àgbà took tó kori òde ìsálayé N lé ìkòòòyí omo eerù ofà Olóòtó omo gbáà omo gbèdu Yánbíniólú omo arágálá efikú pogun Témi bá n lo sónà be mo molé wa Omo Oba ìjí peké-peké N lé ìkòòyí omo erù ofà Àwon ni, àwon lomo Oba ìjí pokùn-pokùn Ìjí mó pokùn mó Igi àtòrì ni ko yá mó on pa Ìji mó pagi àtòrì mó Igi àtòrì òun nigi àse 3 Igi àtòrì òun nigi òrìsà òwójì Láwòójì n be nlé owínsí dara Omírìn dara lóri ofa òòò Ota rìn dara lóri omi ò ò ò Làwa n pèkòyì omo eerú ofà Olóòtó ègi yánbinlolu omo arágálá e fikú pogun. Àrònì gbonra jìgì dagun erùù oògùn nù N lé ìkòòyí omo eerù ofà Àlà e wà bí, inú ilé gbogbo kààà sí nkan kan nítiwa Omo sírò n togun Omo gbàro n togun Omo jìgan n tode Omo jìgan-jìgan láà rùkú alaigbodoràn mote serù bòtè Mo letí mo fi n gbóràn láyé òòò Enikéni kó mó rúmí gbajú òde baba mi lo olórí ogun Àwa lomo òsèsè ‘kòyí Tí mo réèrín gán án ni kú Tú kí n dérin, elégbà ni mo di pèle níjó tí mo fi lo gán án ni ogun ìlànlá omo èrù oofà Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa Ìkòyí omo eerù ooofà 4 Olóòtó omo gbáà, omo gbèdu Èyin obìnrin ìkòyí e mó pagbòn lágbòn mó Gbogbo obìnrin ìkòyí tí bá n pagbòn lágbòn wón n rán oko won léti ogun ni Lóòotó ni béè ni òdòdò on yùn Àkà kè wà bí, inú ilé gbogbo káà sí n kan ní tiwa ìlànlá omo gbáà erù ooofà Olóòtó omo gbáà omo gbèdu yánbínlólú omo arágálá omo e fi kú pogun Orin: Eruwa nil é omo agbòn, ta n níkòyí ò nílé Omo agbon ? Ègbè: Eruwa ni lé omo a Lílé: Ta n ni kòyí ò ni lé omo agbòn Ègbè: Èrùwà nilé omo agbòn Lílé: Ta n níkòyí ò nílé omo agbon? Ègbè: Èrùwà nilé omo agbòn on on. Ìrìn mi gbèrè ó dilé wa lóhùn ún òòò Àdesítèé oníkòyí òòò Ìkòyí omo eerù oofà Adésítèé loba tí nbe lé kòyí omo agbàawà 5 Olóòtó omo gbáà, omo gbèdu, yánbímilólú omo arágálá e fikú pogun, Àrònì gbonra jìgì dabo erù oògùn nù Okùnrin gbon gbon gbon bí ojó kanrí Adésítèé, Okùnrin gbòn gbòn gbòn bí eni fìbon tì Ìsépo méjì omokùnrin Adésítèé mo o bá tòde baba a re lo Ìkòyí omo gbáà, omo gbedu yánínlólú omo arágálá e fi kú pogun Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa Orin: Tapó tapó ;à á bómo ogun Tapó tapó là á bomo ogun Ìgbà ìkòyì ò tó déedé Ègbè: Tapó là á bómo ogun Lílé: Èsò kòyí ò rìkú sá Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun Lílé: Àgbà à kòyì ò ríkú sá Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun Lílé: Àgbà kòyí ò ríkú sá Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun Lílé: Àgbàà kòyì ò ríkú sá Ègbè: Taapó taapó làá bómo ogun un. ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ NÍNÚ OBA ÌKÒYÍ 1 Olúkòyi je jagunngagun tí kì í gbélé kò se inú ìgbé. Ìdì nìyi to wón fi máa n so pé èrùwà nilé omo agbòn.
Ọba Ìkòyí
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2401
2401
Ọba Ògbómọ̀ṣọ́ Oba Ogbomoso ORÍKÌ OBA ÒGBÓMÒSÓ. LÁTI ENU ALÀGBÀ OYÈKALÈ ÀLÀDÉ Ògbómòsó òle ò gbé Ògbómòsó òle ò gbé, eni ó bá lágbárá ni gbébe 1 Lóótó ni béèni Òdodo ni Ògbómòsó ‘mo ajekà ká tó mùko yangan Ògbómòsó ‘mo a jòrépo-tú-yì Àlà e wà bí o ? Inú ilé gbogbo kàà sì n kan an ní tíwa. Ògúnlola lorúko sòún àkókó je Soun kéìtán iwin lábérinjo Àísá Òkin onígùru-gùrù kéta Adàdá mówù moja àpà Oba tóbá onígògòngò jagun àlùsì àpà Eléyun ni ni oòòò Òun loba tó kókó tèlú ògbómòsó òòòòòò Un lókó tèlú Ògbómòsó dó Lóòtó ni, béèni òdodo ni kì gbogbo Oba kí won ó tó mó on je N gbà tí ò dè si eléyun nì mó o Ògbómòsá òle ò gbé eni ó lágbára ní gbébe Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilée wa Èyi loríkì ti ògbómòsó ajílété Béè náà ni Oba ajísegírí niilé wa E dáké Ògbómòsó òle ò gbé Eni ó lagbara ni gbebe. Ògbómòsó, Ogbomojúgun Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa Báàbá bára wa tan, a fògbó kògbó nnú lé Àlà e wà bí ò ò ò 2. Inú ilé gbogbo kàà sí n kan ní ti waaa kótó wá kàjàyí-Olú-Ògídí oníkànga àjí pon Aíléwólá agidingbi lójú Ogun Àtilé atona ni baba mi Àrèmi fi sá nka ìjà á sí Béènáàni Aíléwólá agidingbi lójú ogun O lájá ti n be nínú ilé méì wulè gboni, Ènìyàn Àjàyí té e rí ò gbodò ya só o mó lásán Béè náà ni omo aráyé nì n kóba lóro Ìgbà ti ò dè si eléyùn nì mó o N ló wa kan Oba Ajagunbádé Témi bá n lo sónà ibè mo mo on mi ilé wa Ìbísùnmí, Lákanngbò, oko aràgan Ajagungbádé Onídugbe Àráráriri, Gbángbóyè ìrèlè baba òkè Kójú ó torì, kóràn ó dòrìsà Òrìsà mo kaàbá Bábà bá yè Ajagungbádé Jánjanjan ní mo ón dunni Ajírèrín Òkeke Àdàgbàlagbà Sinyan àgbìgbò nìwòn Ìbísùnmí ní n tósàgbònìwòn té e dékun èrín rín Tobá segúnnugún a kowo móri eyin Nnkan to sàjààsá té e délé ìbàdàn Tóbá solówó erú ni, à bá ti rérú è mó pátápátá 3 Atìbàdàn wá joyè bí omo jógíoró Okùnrin pon pon pon bí ìbon ògodo Gbongbòn janran baba mi ìbisùnmí tó wúwo bí àte àdí Aja-n-gba-da-gírì-jagi Ò-jebòlò jegi ìdi rè Sara-sara làá kina bolé Òjò pàà pàà ti tújà Abomo on mú sànpònná kàrà-kàrà nìgbà osàn Ó yi éyìn osè, o pomo òsú lékún O sìkà osumí ògódó ó kanga oní kanga Báni bù ú wò omo òkèèbàdàn Àlá ó ba bùú, ó ní iyán lémo Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mo òòòò N ló wá kàlàbí Òyéwùmí Oyèwùmí Ládiméjì, Ládèjo Afolábí omo Tinúuwin Ajíkobi Dèjì omo iwin ìgbàlè Dèjì omo Àsààkún eni tó bá wolodumare ní dá lólá Òkìkí ò posù, ariwo ò ní pojó 4 òkìkí ò nó somo onílè ni n kankan Ojo ò tòòjó, ojó ò tojò Ojó táwon kenimoni gbórí àbíkú kale lójàajagun Eni tó kúrú n wón n tiro Ènìyàn tó gùn n bèrè Àlàbí ò gùn béè ni ò kúrú Ó dúró gbangba, óbálábòsí wijo Níwájú òyìnbó ajélèèèè o jàree abínú eni Orí ewúré sunwòn itú ló bí Tàgùtàn sin àn ó bí yàgbò Ìpàdéolá abesin gbórùlé jìgbàró Orí baba Láléye sin àn tó bárá Ìbàdàn tan A rí bí won tí n sojú oko Olúgbódi Àrán inú àpóti oko Efúntádé Àrìnjó káàkótó oko ògboyà Méèle nìkàn sùn, méèle nìkàn dájí Nílé làlàbí òkín lóti málàké ròòde Témi bá n ko sónà ‘bè mo monú ilé wa Agbe tori omo rè dáró Àlùpò dùdù tori omo rè kosùn Lèkélèké gbàràndá ó torí omo rè déwù aso funfun 5 Torí Àbáké lo fi ránmo láyédé Torí Àbáké lo fi lo o kóògùn aremo Àsoba sàrìnjó tí n gbonílù tí fi gbèwù àrán Oyèwùmí Àlàbí n ní gbomo Ológbàó tí fí wé gèlè genga Eléyelé ìyàwó, oko jólásún Ará ilé Àdùnní, OLókan aya bale ajísomo Dèjì Àlàbí oko látúndùn Oyèwùmí Àlàbí ló fi Ládùnní rópò ara rè tó dip ó térí gbaso Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa Òun loládùnnúnní Àkànó Oba tí n be lógbomòsó òòòò Oba ògbómòsó tí n be lórí oyè ní ìsinsin in Témi bá n lo sónà ibè mo on lé wa Ìbà baba mi Àkànó Oládùnúnní òòò Oládùnúnní Oba tó rojó ilè tó jàreee Bémi bá n lo sónà ibè mo monú ílé waaa O jàre gbogbo àwon ìjòyè tí n be lórí ilè náà Àlàa`fíà ke wà bí o Témi bá n lo sónà bè mo molé wa Eléyelé ìyàwó òko Lárónké òòò Ará ilé Àbìó ò ò ò Oyèwùmí Àlààbí 6 Oyèwùmí Àlàbí Oládùnní Ajagungbádé kan Olá òkan ò jòkan aya Bale ajísomo Dèjì Àlàbí Oko Túndùn Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé won *Àwon lomo Ìbàrùbá niwón elégùn esè Ìbàrùbá niwon elégùn esè Olàyankú omo ode bárán eti oya Omo Abérisé Omo Agbònkájù Omo Ajijoperin Ìbàrùbá omo olójà n lìkì Ìbàrùbá mojà lójà Ilé yìí, ilé àwon baba mi Mo bá e dó kááda oníkáadé Oníkáda won ò sì ní gbèsab àwò ò ní tánmo lórùn n lìkì Omo pákí nimi, mé je sìgo Omo nàmù-námú, erú ò joòrì Omo kékeré Ìbàrìbá téerì ò gbodo jáwé apá sié lánlán Ìbàrùbá Olákòndórò, Oláyínnkú, omo ode bare eti oya Omo abérinsé, omo agbònkájù, omo ajíjóperin Looto ni béèni òdodo ni Ìbàrùbá won èé sunlé àjà Won a ní e bámi wéké yógùn nanana ki ni róhun kólé 7 Ìbàrùbá onílè lìkì Ìbàrùbá won è é pèkùlù Won a ní e kálo o lé lóhunún ká lo rèé kédò erin Ìbàrùbá Olákòndórò Oláyankú Omo amérin wá á mòlú, omo aréfòndiyàyà Àrá abowó òjà lálálá Baba mi ògìdán tí fowó ìjà ralè Óní bí elérèé ò bá réni Tí ìjèsà ò bá tajà láwìn A kòí molésà lásán Òyíìrí lápó Oládòkun èjè ti ti ti lénu esin Tayérunwón, Tègbésòrun Agbesin lówó Olúpaje Aare akòta sùsùsù ofà Sòún abiléfà n wájú Kéètán abilé ofà léyìn Dáùsí abilé ofà láàrin Baba wa ló soró kan bí agogo A fìbènbé ooró kù bi òjò Eléyun ni nú ò ò ò Àwon Oba tó tògbómòsó o Jógioró akandehunso, àpáti Olúmokò tí kogun lójú tòsán tòòru 8 léfá wolé, lóòsà wolè kò jé ki elénpe bòdé mó o gbesin lówó Olúgbaja, ààre a-ko-ta-sù sù ofà témi bá n lo sónà bè mo monú ilé wa Ìgbà ti ò dè sí eléyùn nì mó ò ò ò ti jógioró kú ò Eranko orí ráre tii dún mònnàhun-mònnàhun Témi bá n lo sónà bè mo mole wa N ló wá kan Ik’’umóyèdé Àjàsá alátò oyè lábé Oba lábé bánbóba bánbóba Oba tóláya márùn-ún táwon márààrún ti an bímo oyè Wórókòòkan Oba ni wón je Témi bá n ló sónà ibè mo mo on nú ilé wa Eléyun nì óòòò` Taa lóbí, taa lóbí òòò? Òun ni baba Àjàjí Olú ògidí òòò Olúwùsì Àjàyí Lóòtó ni béè ni òdodo ni Olúwùsì Àjàyí Onísòro sègì òpónrororo, baba mi akòtòpò iyùn Òbá jègbè ìlèkè Àjàyí ebí láàrin lòbá mó on gbé Ailéwólá o yanjú Olá gandangbon Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó ò ò ò Taa lóbí, ta a lóbí ò ò ò ? N lókàndòwú bólántà a wùwón 9 ìdòwú Bólántà a wuwòn on bólá bá dojúdé a súwon súwon Àkèyìn sí olá kì í rò Ìdòwú Olóde Àgbánká Fárónbi abesi kan kúro lójú ogun Gúdúgúdú abojú légbèé Àlùkojú órun àpinti Adáso mó fágírí, oko ògúnyìnmí Agbinni mó gbinsè, oko Ajíbólá Ògòngò gongo nírìhànló Oko òjíbù ti jájolá Ayìndòwú nibon kò kú, a tomo jógíoro lóra o mú gbogbo e je Ògbó dì ofà tii semú wìlìkí O ní kòsí oya òòòò Ogun a kólé e rá òòò Bí ò sí olùfòn ogun a jà lérìn Tí ò bá síi lákidófà Ìdòwú Ogun ni jòsogbo Ó gòkè òrá, o seré nà fún gàmbàrí Ò se rebee níjó dósogbo Ògbèkè n gbekè, rábesè gbékèlé Ó fàtògòrò, ó súwon lóòrógàn títí Ó gbójúlé lé jagun níjó ogun níjó ode Èdù òkin ti fóhnn sà Témi bá n lo sónà bè molé wa Ìgbà tí ò dè si eléyun nì mó ò ò ò 10 lówá kan Akíntúndé òwè ìsòlá Tí jówólè Oòni Akíntúndé Apébu Apéébu wóló, atìdí yògòlò Amúlé gbolófófó Àwa la múlé gbelé aseni Ilé aseni won ò jìnnà ó jà Àbá molé olórò ni, a ò sì molé aseni Àbá mole aseni, òràn won a tètè tán N lèmi pogunlabí Òwè ò jejò kínní o feran ejò se lénu Yàkàtà yakata kò jé a rí ìdí ìsápá Ìbíkúnlé ìbàdàn, won ò je á sodún arò ní nkankan Ìgbì tí n gbìkúnlé A jade tòun tòbùrù gege bi elégbára ègbè léyìn gbogbo àgbà Bàdàn. Òháhá ilé lógundégèlé ò eruku esin lofi légún Déyemo Awon ará Òòyì, àwon n won ò gbón Àwon n won ò mònràn Won ò mò pérúukú lòwò o báwí 11 Ogunlabí kójúmó tó mo lo kó gbogbo won lóóde Òlémo gbó Àsàmú baba Àb áàsì Ìgbà ti ò dè sí eleyun nì ìn mó òòòò` N mí Oba márun òòòò Lóòtó ni béè ni òdodo ni in Temi bá n lo sónà bè mo monlé wa Ó wa kàbàrí Olúòyó, ebìíyà Àbàrí OlúÒyó, Oyèédòjun, Látiri abólugun-Oba Oba táaké ké ti ò juke Oba táa gègè tí ò jugè Òrìsà tí ò jugè, ojú pópó ní gbé Dúdú fílàní n lomo lákan lé fi modi Pupa re ní sàatà, ìdùkúrùkú Témi bá n lo sónà bè, mo monú ilé won Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mó ò Témi bá n lo sónà ibè mo mo on lé e wa a In ló wá kàlàó, Onísòrosègi Àlàó témi bá n lo sona Òun ni baba Àtàndá Ògúnwèndé òòò Àlàó táa wí yìí, òun ni baba Àtàndá Ògúnwèmdé òòò Òun ni baba Láoyè tíí jórumogegege 12 Apásánlá abaralómú, lómú omo kélébe Ààre asòkò senbe àbàjà Sòún dáìsí Oláoyè ni baba ònpetu Bàbá lelébùrú àásáká Oláoyè abìlé gbogbo lóógunlóógun Odán nigi àwúre Òpè nigi ìràdà Àgbà ti n féni láfèé lólé Iwo nlá ni fólúwa re je Té lésin, bàà lésin Òkètè n ketè, a mò ón gùn jomo àgbè Àtùké bóun àsá baba lágbéndé pinpin pin lórí esin Òpòló tóo yírò òo se é to Oláoyè okólé baba re lóbá kan kórí Alùfáà a pàkòi, Oúnlé orí omo kélebe Témi bá n lo sónà be momolée wa Ìgbà ti ò dè si eléyun nì ìn mó o N ló wá kàntá Olóndé omo Omídélé òòò Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa Bá à kègbón taní kàbúrò Mo kókó fe e lo sílé baba itabiyi Témi bá kó n lo sónà bè mole wa 13 òjó aburúmoku ò ò ò ò Témi ba n lo sónà bè mo monlé wa Kékeré àsá omo ajùújù bala Àgbàlagbà àsá omo ajùújù bala Kékeré làdàbà subu táwon tí n je láàrin òtá Olóumí kékée lo ti n soko won nílé Kekere lo ti n soko won lóki Kékeé lòjó ti n soko won lóna ijù Oníyòówón, Inásírù, Ibasòrun Kínyodé Iba tíí begun wolé e rémo lo Iba tí n bá n bò, a kòdi órun Òfesè mejeèjì gungi òbobò Eléyun nì ní ò ò ò Òun ni baba ìtá Olóndé omo Omídélé ò ò ò Òré ò sí, Olórun Oba dada Ináwolé baba kóta Ó ní Ifá firipò nínú igbó Òpèlè firipò laàtàn Òrìsà ké kè firipò lágbède agodi Ináwolé baba kóta 14 Témi bá n lo sónà bè nmo monlé wa Tí ún bá n lo sónà tòkun, òkun lolórí omi Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó ò ò ò ò N lówá koláyodé ò ò ò Adékúnkèé, Adégòkè oko pàte Oláyodé omo egúngún oko Àrà n baba mi Àatàndá Adégòkè omo iwin ìgàlè Lékèélékèé eléwù akese Ahan ran mòjàngbòn, eléwù pànpànkusà Ògbómòsó ní wón gbé, won ó mo lòó sàyonuso, sí Láyodé omo egúngún oko Ò-déyìn-ìlèkùn-di-baba-àgbàlagbà Òmìmyín-mìnyín té e rí ò le è meyín erin Èfúùfùlèlè n won ò leè mi òkun Won ò sì leè mi òsà Ìse tí èfúùfùlèlè táwon n se sókè lorùn Àtàndá Òkín Olóun Oba nu ò joke ó wó Àsá n ta, kò leè tagba raso Àwòdì wón n rà, won ò le e rewin ìgbàlè Títí tí àwòdì òkè tée gbélé ò ile mò pé ojú eye oko a mó on ri íri-íri Ìse ègbón, n wón n pe àbúrò Àbúrò ìba sègbónm ojú won n pón 15 Àbúrò ìba sègbón, ojú won a pón kankan bí oju alala, orùn won a wò pèrè-pèrè bí èwù àgbàlagbà Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa Ó wa kan Ajíbnólá, Adogun Eléèpo àrán Ajíbólá Oba to kobi sóyi Témi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa Ajíbólá Oba tó kobi sóyi sógun Àlà e wà bí, gbénkan dùgbè-dùgbè Un ní pé Olóun Oba gbàmi Oba séríkí, in ní gbani lóhun tótóbi ní nla tóbi Sòkòtò èfà mi ò òn balè Adìgún ni kásá paà lówó lówó Táa bá ti lówó lówó gbogbo e níí tóní Àlà e wà bí ò, inú ilé gbogbo kàà si nkan nítiwa. Agbà ti ò dè sí eléyun nì mó o Ó wa kòkò lánipèkun 16 Témi bá n lò sónà an bè, mo mo on nú ilé wa aa Àlàáfìà ke wà bí o ? Òkè Olánipèkun? Òkè kéé kèè ké, mó on jólè rè sánpónná Kóniyangí kó mó on jélégbáa Òkè tó lo sóòwu òbò Eléèé tó lo sóowu ò dé Adéowó dáké mo joke kóòwu jojololá omo Bádéjéorúko Òkè ni ò ri powó awon èlèdà Àlà e wà bi, inú ilé gbogbo kàà si n kan nít iwa Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó o In ló wa kan Olátúnjí Eléèpo àrán Olátúnji omo gbángbéfun Àrágada sí bààmú lójú oko Oyèládùn Kòlù-kòlù mó kolùmi Olátúnji ò ò ò Eni Olátúnjí Àlàó Àlàó bá kolù yó febo jura Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o N ló wá kolágidé, Olágíde Àjàgbé òkin baba Lúfójè Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé waaa 17 Òyìnbó funfun ò doable fóba láàfin sòún ri o Níjó títáláyé ti dáyé ò ò ò Béè náà ni, níwájú omo Odérónké ti n wó tuuru Níjó tó fòyìnbó párì joyè Àlà e wà bí inú gbogbo kàà si n kan ni tiwa a Àjàgbé Òkin baba ìlúróyè Tí ùn n bá tún lo sónà bè mo mo mole wa Ìgbà tí ò dè si eléyin ni mó ò Ó wá korímádégún àjààgbé Òkin, Tí ùn bá n lo sónà an be mo nú ilé wa Salami Àjàgbé, omo ìtá Olónjó, omo Omídélé Òré Òsú, Olóun Oba dàda Ináwole baba kóta Gbogbo won pata-pátá táa wí yí òòò Orílè ti wón ti wá Gbogbo won lomo ìbààrú onílè lìkì Oláyankú omo ode báré etí oya Ìbàrùbá won è é sunlé àlà Won a ni e bami wéké yógùn nanana kí n róhun kole adodo 18 ìbàrùbá oonílè lìkì Ìbàrùbá niwon eledin ese, omo ode báré eti oya Òun ni baba tó se gbogbo wón lè pátápátá pogodo Nílé è bààrú onílèe lìkì. ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ NÍNÚ ORÍKÌ OBA ÒGBÓMÒSO 1. Ìran ìbàrùbá ni sòún ògúnlolá, ode ni ó se dé ibi ti a mò só Ògbómosò lónìí yìí. Sòún Ògúnlolá àwon kan pàdé nínú igbo, gégé bí ìtàn ti so, èéfìn iná ni wón fi mò pé àwon kan tún wà nínú igbó nàá. Lára àwon kan tún Ògúnlolá bá pàdé ni Aálè èyí tí ó jé bale Òkèelérin, òbé ti ó jé bale Ìjérù, ìran Ègbá ni Òbé jé, nígbà tí Aálè jé ìran Tápà, gbogbo won jo n se ìpàdé ní òdò Sòún Ògúnlola, wón sì fi se alága. 2 Ìtumò Ògbó mòsó: Ìyàwó Sòún Ògúnlólá jé eni tí n pon Otí tà, orúkootí náà ni oti ewe. Ìyàwó Ògúnlolá je bábá ìjèsà kan ní Owo, nibi ti wón ti jo n sòrò lówó ni Sòún Ògúnlolá wolé, èdè àìyedè dé láàrin Ògúnlolá àti baba náà, Sòún si lu bàbá náà pa. wón fún Sòún Ògúnlolá ni àrokò pé kí ó lo fun Aláàrin, bí ó ti débè, ó so fún Oba pé òun yóò bá won ségun elémòsó ti n pa ará Òyó. Ògúnlolá bá elémòsó jà ó sì paá ni ó bá gé ori rè, o sì gbe fún Aláàfin. Ògbórí elémòsó ni o di gbomoso. Akínkanjú ti Ògúnlolá jé yìí ni o jé kí ó jé Olórí fún àwon Oba aládé tí ó wà ní agbègbè Ògbómòsó. Lára àwon Oba aládé náà ni Oba Arèsà, Oba Ònpetu abbl. 3 Ìtumò Otí ewe: Otí erèé ni à n pè ní otí ewé .
Ọba Ògbómọ̀ṣọ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2402
2402
Ọba Ònpetu Oba Onpetu ORÌKÌ OBA ÒNPETU ÒJÉ. ÀLÀDÉ(OMO ISÉ FOYÁNMU) Ó dilé wa lóhùn-ún òòò Témi bá n lo sónà token òkun lolórí omi, in Mo fé lolé Oba bí adé ò mèedi òjé aa dígò sorò 1 Lótùú olójà lodòjé ilé Omo afínjú eye tíí mumi lágbada tòdò tí mo n bà lonà èbì, Òró gangan ni wón fomo odó fún odó òòò, N lé ni lóhùn ú nose okúmorò lónpetu, Lóòró gangan gan táwo todò lónpetu Ìda kàlà n baba mi àgbà kan ó tó mùko àdò mònyàn Ìyá ò dámi ní àgbalè rí, n dúró gangan le fi múmi ní omo Obí n jesu kò wale írí, Mo bá tòde baba mi lo, Omo obí tàlùpò lówó won ò wasà, Obí, obí te túkùú ò gba toríigi keke Omo Oba gbélo, gbébò lebì. Mo pàdé egún kan lókè lààká o Ojó ò t òòjó, oojó ò tojò, Tí mo pàdé egún kan lókè lààká o, Mo rò pé were ò tètè dami mo pemi ni in, Témi b á n lo sónà be mo monlé e wa, Ó ní banyan ò gòkè, tó dòkè kó mo on rókè, kómó on bo á sísàlè èè 2 Ó ni ò ní bóun dé pálò baba òun Mo ní n bo ni in? Olóun lomo èbì òjé a dígò soorò Mo bèèrè, mo bèèrè lówóo láyèwú n jósí òòò Ólólúefón leni tó kókó joba lójèé O lólú eyìn ló tèle Mo níró loo pa Mo ní àwon lomo Oba mínrin, Àwon lomo Oba mìnrin Omo Oba òmìnrìn mínrín tolú òmínrín tó kókó tile-ifè wá jònpetu, Eléyun nì baba tó bi Obandí, Obándé un ló bí ògánndolè Ògándolè un lóbí Ona dede Obadede un lóbí ifátólú Ifátólú un baba Àsàmú Atóèbí eni tó kókó degbó òòjé tó ò parun Àsàmú òhún un ló sore onílè À sore onílé Un ló sore Olóólà Un ló dìyekan won 3 Tí an bá pónko olóólà òhún tí jé Olóólà ohun nííjé abú-bí ekùn-mo-pani-je Aké kaaka kí olórò ó gbo baba òtún àgòrò Òtún àgòrò, kó tó kolúdé, òkìkí amúlè bí ìbon Òkè léyìn pòrò Akìí kamo fónbí, un ó bi t`mi pòpò Oba mèdì òjé maa dígò sorò Lókùú Olójà lodòjé ilé Omo afínjú eye tí í mumi lágbada Témi bá n lo sónà bè mo mo on lée waaa Ojó ò tójó Ojo òò tojò Ìyàwó Olúòjé ó lo sí àwon ona èyìnkùlé Ó lo rèé sègbònsè O rógun lókèè odò loogun bá sú dededee Un ló bá sáré wolé Ó ni baálé wa, òlóòdè e wa Ó ni wá wogun lókè odò, ogun sú dededee N baálé re bá kápó, ó kórun Olúòjé ó kófà N ló bá sòló Ó wàgbo sòló N ló bá lógun lo 4 Ìgbà tó di ni sègbè eléèkejì yi èwèwè wè, Ìyàwó lo sí ònà àwon èyìnkùlé n N ló bá rógun lókè odò n logun bá su de de de, Ó ní baálé wa, olóòdè wa O ní wá wogun lókè odò ogun sú de dè dee, N ní baálé re, n lo ba kápó, N ló bá kórun Olúòjé ba wàgbo sàlàà, n lo ba wàgbo sòló, n lóbá lógun lo Lóòtó ní, béè ni, òdodo ni Ìgbà tó di ní sègbè eléèketa yí èwè wèwè Lóòtó ni béèni òdodo ni Baálè, ìyàwó bá lo sónà oja N ló bá rógun lókè odò, N logun bá sú de de de N ló bá sáré wolé wá Ó ni baálé won, òlóòdè wa O ní wáá wogun lékùlé re ogun dé dan dan dan an 5 N ló bá w’`agbo sàlà, o wàgbo sòló N ló bá kápó N ló bá kórun N ni ún bá n lógun ún lo Ó lógun ti ti ti Owó re ò bógun O lógun tí tí tí, lówó re ò bógun Ìgbà tó lógun tí tí tí ogun jìnnà N logun bá polúòjé ò ò ò Ó polúòjé so sáàrin ììgbé òo Won retí Olúòjé tí tí tí, won ò ri Ìgbà tó dojó èkejì Ni wón bá fín wá Obi á kiri Igbà ti an waja Obi ti an fi woba kiri títí Wón bá koba láàrin ìgbé òo Níbi tógún paá si ò ò ò ò, In wón bá kàn-án níhòhò Kò sáso kankan lára re Wón léèse, Èétirí enìkan kìíri, enìkan kìí rùkú oolójà nihòhò, N wón bá mája Oba 6 N wón bá pa á Ni wón bá bó awo re Ni wón bá fi bo Oba Ni wón bá n pé àbáà dáso epínrín lé epínrín, Kòtíì táso òjé mu ròrun aso aláso ni, Èbáà dáso kókò lagbàlá alé Kòtíì táso táwon òjé mú ròrun aso alaso ni, Kée dáso kókò láàrán Kèè táso tólúòjé múròrun aso aláso ni Awo ajá pélénjá pèlènjà pélénjá N laso òjé é mú pèkun Moparun yékété etí I yemetu Ìrà mokò un o sòkùn fún won lónà tèbì Omo gbálújobi, 7 Mo sùsú lódò kan oso ti í je weru Sùsú lelénmò bínú, eléruku jámò Akìí bèèrè àgbà nílé Olúòjé mo olórí adé ò ò ò N jé nú lé lóhùn-ún san àbi ò san Bí ò bá san mó, baba anìnùn ló dà hun un Témi bá n lo sónà an bè è, mo mo on le e wa aa Àlàfià ke wàà bí o ? Àjàmú ní n be lólúòjé níhà hin ò, Àjàmú ní n be lólúòjé mó on gbórò enu mi Tí ùn n bá n lo sónà be mo monlée wa Bóri gbeni gbeni bá gbeni, Àtàrí gbènyàn gbènyàn tí an ba n gbàwon ènìyàn Oò póríi taa ní ó mo gbè è o o o ? Lóòtó ni béè ni òdodo ni, Òri sàlàkó, oníìlí ò fé ó tú Agbara-bi-awú abáni gbélé ní se bée Òjúòjú elérù gbérù Ó tì lójú elégàn mo rèé tamó baárú Sàlàkó, ni kúrú níhìn-ín, lóhùn-ún 8 Lèkùn òjòwú, wón tìgbásè gbó tútú Aso pami un kú in ní lu kára bí ajere O láì wíni loran kó sìì di teni Oníkálùkù kó yáa senu ti è láàbò Bóri gbeni gbeni báa’gbeni, Atari gbènyàn, bí won bá gbawon ènìyàn, Oò póríi taa ni ó mo on gbèè ó o ? Àjàmú mó on gbórò enu mi Abídoyè Àjàmú tí n be lólúòjé lòò ni o, Òò pórí taa ní ó mo gbèè o o ? Lóòtó ni, béè ni òdodo ni, Oríi Bóládé, bí ó ti mo on gbè ó tòó pin ni Àwon omo Atóbatélè kó tó wáá joba Bémi bá n lo sónà bè mo molé wa aa Àjàa`mú àró afúgò sorò Àjàmú àró okúmorò lónpetu mo aparun jékété etíi yemetu ìlá mokò un ò sokùn tún won lónà an tèbì Témi bá n lo sónà be, mo monú ilé waa 9 Oò pori ta ní ó mo gbe ó ò ò ò ò ? Orí Adéolé bí ó ti mó on gbèè ó ótóópin in in Ò póri ta ni ó mo gbèè ó o ? Orí òsékùnmólá, bí ó ti mó on gbè e o tóò pin ni, Ò pórí ta ni ó mo gbèè ó o ? Orí Atóyèbí bí ó ti mó on gbè è o tóò pin ni in Ó póri ta ni ó mo gbèè ó o ? Orí Atóyèbí atówúrà sabàjà Atóyèbí Alárìnje è baaka, abi kété kété babaáje ní tako tabo Ìbaaka bàbà sojú òtún ní kànnà kànna kànna O ní, kì í se pésin baba enìkan màrà Kìí jé pésin baba enìkan mo òn jó Sùgbón esin Atóyèbí N lo mò ón jó ju taráyòókù lo Abi kété kété baba á jó wariwo ojú ogun Àbénté ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo Àbèntè ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo káloolé lónìí mo jákàn mo on jììgan bìbaaka bàbá soojú òtún kànnà O pori ta ní ó mo gbè ó ò ò ò ò ? 10 Orí Àmódù, bí ó ti mo on gbè ó tó ò pin ni, Eja ló nibú, bí ó ti mó on gbè ó tó ò pin ni O pórí ta ní ó mo gbè o ? Adédoyin, Àgbàkiri Òsùn sí, N wón n yoko Efúndélé lénu O fárí kondoro o fiyawo kan, babaa lúfóyè Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóòpin ni in Témi bá n lo sónà bè mo mo on le e waa Ò póríi ta ni ó mo gbèè ó o Témi gbogbo Oba sónà bè mo mo on le wa Bórí gbogbo Oba wònwònyi dááko bórí won ó ti mó on gbèè o tóò pin ni Témi bá n lo sónà bè mo mo on le wa aa Àlà e wà bi ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ní tiwaaa? 11 Tí ùn n bá n lo sónà tòòkun, nkun lolórí omi Ojàre òsà làbábi níyìn yò Àjeku, a jèkàà làbá lókèrè Èmi náà làbá bi lókì orin mi Orin láwèéréke, orin àwérèke Orin asínsínndada, asìnsínndada Bàtá ògèdè Saworo Òkótó Atiro ò yàrìnjó Àrìnjó ò yeni ti n tiro E kilo fún mo lárìnjó Ki molárìnjó mó on mésè rè le le le Témi bá n lo sónà be mo mo on lé e e wa a a Omo Oba n mínni Omo Oba minni Omo Oba òmìnnì mínní tolú òmínní to kókó tile-Ifè wa jònpetuu Témi bá n lo sónà an bè mo mo on lé e wa aa Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóò pin ni in Tí un bá n lo sónà bè mo mo on lé e wa aa 12 Àlà e wà bí òòò? Inú ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ni tiwaa, Èbì òjèé a bidò sorò Lótùnún Olójà lodoje ilé, Omo afinjú eye tíí muni inú agbada Orin: Àlùfáà ni ò ya ní wá Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo Lílé: Àlùfáà ni ò yà ní wa Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo Lílé: Àlùfáà ni ò yà níí wa Ègbè: Bódún dé áá fòkó sebo Lilé: Àlùùfáà ni ò yà nííu wa Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo o o o . ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KOKO NÍUN ORÍKÌ OBA ÒNPETU 1 Omo Odùduwà ni ònpetu kí ó tó wá je Oba ni Òjé Ilé. 2 Oríkì Òrànányàn Òrànmíyàn Akòtún Akin nílé Akin lógun Òràn ni mo yàn, un ò yankú Òràn mo yan, un ò yàrùn Baba ni á yènà àyèbá Ó ní a yenú òwú, a rook abé re.
Ọba Ònpetu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2406
2406
Ọba Ìrágbìjí Oba Iragbiji ORIKI OBA ÌRÁGBÌJÍ. Kábíyésí Oba Oba tótó Oba ìrágbìjí Àbíyèsí Oba Oba mo fé pè n kò ní mu emu Oba ni mo fé pè n kò mu gòrò Àbè togún ràlú onmo ará lósìn Téní wíjó ará lóbòkun sá loba ìrágbìjí n jé. Ònkókóló omo oníyán kónkólóyo Omo bárígídí níyán ògún Omo arílù mó lulu fún ìrà Àrílá ílànkí mo gbé òkè je nàmùn Gbéléwadé mo gbélé se bí Oba Omo Òké gbélé wùsì lónà tòrà Anal mo kéde jègbe Ará mú lege ará òkun esè kè Omo òkan ti yí lulè Ó kù okan Omo olórò kan òrò kàn Èyí tí fáwù lógànjó yányán Gódógódó Ilé won kò gbodò sowó odó poro Béè ni alògì kan won kò gbodò solo ògì sàrà Omo kékèké Ilé won o gbodò sunkún omú Èyì tí ò bá sunkún mo lórò ni yoo mo gbe lo. Omo òkè kékéké ni yíkè yíkè yí láyé. Àbè togún ràlú omo arà lósìn Téní wíjò ìjèsà kò rídìí ìsáná Ilé loní Owá ti mú iná roko Àbè togún ràlú omo arà lósìn. Mo tún yí yun tì kédéngbé Ònyín mo tún lo re dé òkè àgbò. Oba tótó mo lémi kò perí Oba Oba won n perí e ní Sókótó Oba ni wón n perí rè ní Sàbàrà Oba ni wón n perí rè nílè ìrágbìjí Oba olókùn esin Ará Ilé mi abi ìrù esin mi tìèmì A gbún esin ní késé à ló mò jó édòko Gbogbo ara esin wón wá koná sasa Oba kólérán tí n retí eni tí yoo tè fun. Oba n náà ní í be lónà ti òkè àgbò. Àbè togún ràlú omo arà lósìn Téni wíjó ará lódó kánkán Èyin lomo olóyè nílé omo olóyè lóde. Oyè náà won kò ní pare mó yin lówó. Orí àpéré yoo gbé yín dòyè baba èyin Èyí tó n be níbè won kò ní kú mo yin lówó Oba tótó àágbìgí mo lémi kò perí oba Oba ni n be lónà ti ìjèsà àbè Ìjèsà àbè togún ràlú omo arà lósìn Téní wíjó ará lódò kánkán. Mo onípokítí Ide Ikú kò ni pa Oyàdókùn wa Ìjèsà ìsèrè onílè obi Omo ojú rábe sá mó gbódó pea be lórúko. Omo ojú réjò ata wàrà Sòbòrò la bí ìgbín kò fi abe kan ara. Àwon ni omo olóbìkan òbìkàn Èyí tí ó kò bá fé won ní wò sílé Èyí tí ò kò bá fé won a wò síjù Eranko igbó á mu soko je A kì ki Ìjèsà kí a má je Obi tógbó. Tí e kò bá rí obì tógbó Kí e wá gba Obì lówó mi Àwon lomo olódò kan òdò kan Tósàn wéréke tó sàn wèrè ke. Tí ó dé èyìn èkùlé osólò tó di àbàtà Èyin lomo tí e bá jáwé kan Eègbá kan ni Bí e bá já méjì Eègbá méjì ni. Tí e bá já méta Eègbá méta ni Ò pé pep e aso won lóde ìgbájo Elégbòdò ni aso àwon ìjèsà Èyí tí e bá ri lójà ni kí e rà nfún wá Kí n ró jó Olóye lo Torí a kà jò olóye dun ìran baba yin Àbè togún ràlú omo arà lósìn Mo bá àágbìjí relé Mo bá àágbìjí relé.
Ọba Ìrágbìjí
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2417
2417
Alókò ti Ìlokò-ìjèsà ORIKI OBA ALÓKÒ TI ÌLOKÒ. Omo ògbágbà sami sile Àgbágbá Ilé ria se é sun Kí an fònìyàn le ki an mérèé dú Omo òréré kóni níjanu Omo àgbágbá sami sílé Àgbágbá ilé ria see sun Mesi oko ri wa A kìí bani jeku kan abàyà suésùé A kìí báni in sisré òjá finfin nílokò Oso ìgbà mo fi gbígbin n sèye òkè ilokò Wón nit ó bá gbin níbòmíràn won a ni ogun ló dé Ogun ò mò dé Àgùntan ni Àgùntàn oke bàbá lashosre ló n joko nígbà náà Omo olórò kan òrò kan Tí won fi n se lóròlórò ìbà tetè Ilórò agba aiku ile wa nílokò Èje ló bí fún wa Omo òréré ko ni nijami Ko dàíjù kó dá ni ní kòró boko Omo oréré o pojú wode ìjèsà míbò O ni ti won kò bá poju wò ó À remo nílé re Omo agbagba sami síle lo sélé yà ònà ìlokò Àgbágbá Ilé ria se é sun Ibi ti won feniyan sile ti won gberee ru omo olójà àlténí fún Àwon to bójà ni be ki ni won o se O ni bi mo boja ki ni màá se nítèmi Se ni n bá ro pòsí ide Ti n bá ròyìyà iyùn Se ni a ba gbóità kalé ki an to ru ìlokò ka lo gba’run Omo ògúnyán baba ba lérí ota kólórun bùje nígbórò Éyin lómògbà lómógba rí yèyé ria nígbó òsé Se ni méwàá ní fobi aperiri wò mí Obì aperiri Ilé gbara oso ùsì ònà Ìlokò Obi apèrírí lúpaa ra nólè kale Omo olóro a fii gbágùnmòkèkè kalè Omo olórò an fi í sori èsí wonin nígó òké Èsí Ilémi ko bàmí àbàyè ni e rè Kó bá ti la ba omo elomirin ke wa je èsí Esi pajá je o fegbe laa seun ni mùrè ògègè ria Omo olórò un fi i se hóròhórò ìbàtetè Iloro a bolórò a remo nílé re Iloro agba aiku ria nílokò èje lo bí kò á Omo olorere kó ni níjanu ‘ O daiju kí an dá ni ni kòró bo ko Iba mi kára oní mure Agege a Baba mi kare oní mùrè àgègè o Ajagun si òtè wonrin wónrin Òjagbáríigba òkè Ìlokò Omo oboko jà padìye oko je I be si ti sájí oko àgbò n ba gbà N ba gbagbo tó sàmù rederede N ba gbòbídìye bàyà péke Omo olúygbó aré o Asébi gbodidi emi Èlúsémusé Elufagba sile ka ma ba silé yà o Agba gòkè bèrè mole Kómo alókò mó baà nà toto lórí omi Àgbágba òkè nawó kanlè é mú ohun oni í je Oní mùrè àgègè n lé Bàbá mí káre onimùrè àgègè o Me mo roni kebì a pè run òní Obi o peru ni para e jólè kíká Omo asoro de mèkun kèkun Omo olórò a fi í kun olójà lóta e fun Omo olórò a fi í kun hóròhòrò ìbà tetè Horo a boyún Hóró a remo Hórò a gànyìn bì meje lo bi n Ilòkò Onìmùrè agegé nlé Bàbá mi káre onimùrè àgègè o Omo obóko já padiye oko je O ni bi ko si ti saji oko agbo n bá gbà N bá gbagba kò í bàmú rederede N bá gbòbídìye bàyà péke Mo ra gbagiri o Olugbo are o Asebi gbogogo okun Asebi gbodidi eni Elusemuse Elu fògbàgbà o sami súlé Ka ma ba sulé ya o Onímùrè agege nle Bàbá mi káre onímùrè agege o Omo oloro a fi pa hórò hórò ìbàtetè Hórò á boyún horo á remo Horo a gànyìn bí meje lóbí Onímùrè àgègè nlé Bàbá mi káre onimùrè àgègè o Omo Ajagun sia ko omo ló reni Àjàgúnsi lo lereja to fi wa bogun níjèsà obokun Owá mò ni n jíle ní ogboní lásòrè Baba mi káre oni mure Àgègè o. Omo okeinísà Ategboro esu Ki mo ro poke inias nisu tii ta Mé ra méwùrà dé bè. Tori kísu mo baà tàtawòde Kí mo jògèdè aigbo loko Ki me ba ti jalè Se ni a jo a jígbo Omo Alágádá kilo fólè Àgádá farumo Ó fa rùmò Eni bá ti pé loko nijo náà A je wí pé ó ni ohun tí n se Alákàtàkì á kilo fólè Selége tìrege légbòrò Òrò sí bá yèpè Ó tun fi báyín erinlá Ó wá fi mu okuta látìbà Oloro lo làtìbà Ogboni oge lo lodò agidi Àgbàrá atiba gbómo paroko sórí òsé Ara ojúgboro ò gbó Èrò àtìbà ò mò Omo arí herehere enu gbéde yàde Oníjukùn so agogo mo ìrókò Àgbà iwoye so agogo mó kun Eran yòkòkò mù Omo ògbùrùkù yàkè Ogbùrú yàkè o dabi kò papò somijè Oníjùkù àgbé Omo abìdèdè ònà omi Obi ko wò ó séun eni Yè é é hò sénu eni Kó hò síjù Omo eranko á fije Omo olobi yèé ó ho Kó petu nígbó àgbó Tòótó lobi hò Tòótó letu kú nílé ni Irin kí mía rin Kí màa bóba relé ògún àlròtélè Oba dirù sílè Ojú roni koro koro bi uwo Omo bàtá kumirin babe gèru nílé ògbóni oyé Loro lo latiba Ogboni lo lodo agigi nílé mi Omo elékùn ònà kí an kàn fide se nílé ògbòni Omo elékùn ìgbòrò àwíhò Èkùn ònà kóó fòó san ni bí òyìyè Bàbá mi káre onímùrè àgègé o
Alókò ti Ìlokò-ìjèsà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2420
2420
Àtáọ́ja Òṣogbo osogbo jé oba ìlú ayé àtijó ilè Òsogbo ní ìpínlè Òsun ATAOJA OSOGBO. A kì í joyin ká gbàgbé adùn. Enu àgò bàbá ìbà o. Oòmulè o. Àjàní Òkín. Mo juba baba à mi. Pópóolá omo Adédoyin Àjàní Òkín. Mo fé kí oba ìlú òsogbo. Morónkólá omo òkè bí Oba aláyélúwà. ‘Ládiméjì omoàkógbé. Àlàmú ÒKín, Làdiméjì Lálékan. Ìranolá Morónkólá a bi baba joba. Taani ì bá lóba méjì tí ò fáyé lójú. Àlàmú Òkín lóba méjì O tún n sènìyàn rere. Morónkólá Oba Olóríire. A bà gbàlá tó kokò sáré. Àgbàlá Àlàmú ju Oko baba elòmíràn lo. Omo ìjèsà tó gun làlú. Morónkólá Oba Olóríire. Elégòdòmì aso ìgbájo. Elégòdòmì aso ìyèlà. Èyí tó dùn ni e rà fún mi wá. Kí n ró n jó ló yè ìjèsà Ò sere adé eléní ewá. Béwùúlè o má so bora. Omo Ajólówu. E wòó nílé ìré. E wòó nílé Olórò níjèsà abé. A ríléwó ní mòkun. A bèdè kirimì ní ìjèsà. Láì jé mo ro Àlàmú. Láì ro Morónkólá. A bi baba je Oba A bile gbágà léyìn. Àlàmú Òkín. A bilé gbágà láàrin. Ojó ojó kan ò dùn. Ni ojó a fé yan omo oyè ní Òsogbo. Gbogbo omo Oba dúró gégé bí Ogun. Jagun Akínsòwòn di aláfèyìn tì. Ìyìolá Morónkólá. A bi baba jóba. Akogun Òsogbo àgbàlagbà oyè Omo Folásodé Lólá. Salátìléyìn Oba Morónkólá. A bi baba j’oba. Òsà Àkàndé lalátìléyìn Oba. Morónkólá a bi baba j’Oba Ìyálóde Òsogbo . Omo Adélékè. N náà ló salátìléyìn Oba. Morónkólá a bi baba j’Oba. Àti awo àti Ògbèrì. Won ò tètè mò pé. Jagun Akínsòwón sòtító. Pé Lápàdé lobá kàn. Omo Aládéyófin. Àlàmú Òkín j’Oba ìlú tòrò kin kin. Morónkólá Oba Olóríire. Àlàmú omo Mátànmí lósogbo. Mótànmí aní Kanngúndù Omo àkógbé alágbàborò. Mufúolájé baba Mówunní. Amúgbùrùwá fúo. Baba Olúgbèjà. Láyànféélé baba Oyin dà. Olá aláyélúwà j’Oba káyé ó leè rójú. Ò joyè lógun omo Oba. Ò joyè tán fará è módò. Ará níu gbe ni. Egbàá ò gbe ni. Àtélewó kì í pé Lájobí. Lójó Mátànmí n fò de sòkan. Baba béeni àtànpàkò kò yara è lótò o. Òde gbangba kò sé dààsè sí. Lásojú ìlú kan diè-lójú òde. Àwìrì omo selé oko owó e dan. Àwìrì tanwì oko owo e dan. Ò gbó èlùbó Òsèlú orí emo oko Arinkékànbi. Alátise ò rómo róye. Ò rómo róye baba Olúgbèjà. Oba ò rómo ìlekò. Aláyélúwà baba ‘Lábímtán. Ò joyè jogún omo Oba. O joyè tán fará è módò. Ará ní n gbe ni. Egbàá ò gbe ni. B’Oobásùn bóobá jí. Àlàmú Òkín, Móojúbà baba à re. Àjànà kan ó mó pefòn léjó mó. Oláa baba kálukún ni kálukú n je. Àlàmú n je Oláa Mátànmí láàfin. Morónkólá abí baba j’Oba. A bi àgbàlá tó ìkookò sáré. Àgbàlá Àlàmú ju oko baba elòmíràn lo. Èmòilègùnlè baba Gbógbéjó. A dàgbà Ládìgbéjó. Baba Ládàpò. Bàbá à mi Àlàmú. A à mo ibi tí yó mo ilé yìí dé. Omo Mopé. Àlàmú Òkín. Bó parí òkanmòkan. Morónkólá abi baba j’Oba . Kábíyèsaí Oba Òsogbo Oba to léducátìon. Tó lógbón lórí. Kábíyèsí Oba Òsogbo. Iyìolá omo Mákànjúolá. Kábíyèsí Oba Òsogbo. Oba tó léducátìon. Tó lógbón lórí. Kábíyèsí Oba Òsogbo. Iyìolá omo Ládéjobi. Kábíyèsí Oba Òsogbo.
Àtáọ́ja Òṣogbo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2421
2421
Tìmì tí Èdè Timi ti Ede Timi Ede Ede Toyese Laoye TIMI EDE. A à ní joyin, ká tún gbàgbé adùn. Òrúmo gégé láoyè ako ekùn akùnyùngbà. Gbóyè ólá Àkànjí ì mi Láoyè tó tóyèse. Àgbàdá tolómù omo kélébe . Àre lágbà lóyè bí ògèdè. Àkànjí omo Àjénjù Àyà mi kò pé méjì, n bá fi òkan fún omo Ojo. Àgbàdá ta lómù omo kélébé. Ò ránmo ní isé fàyàtí. Àkànjí ì jí lo . A ò rí okùnrin Ogun. Àgbàdá talómù omo kélébé. Ìgbà tí ò sí láyé mó tó kú. Fólórunsó, Ajífòní baba Baba Bólánlé Oláníyì Ajítòní Ajàgbé. Olá à re ì ‘dèra ni Fólórunsó omo lórí demo Àjàgbé omo Béllò Àjítòní aran ee deyin. Béèni àgbo o won A sì ti àn ti ròrò ti ròrò Ajítòní Ajàgbé. Síyán ti e dé pinnu ara. Fólórunsó omo lórí demo . Fólórunsó. Orí Oba ni ó bi wón. Eni tí n bá Obá á je . Tí n sòrò Oba léyìn . Ori Oba ni ó bi wón . Fólórunsó Àjàgbé Oládòkun. Orí Oba ni ó bi wón. Eni tí n bá Oba á je. Tí n bá Oba á mú. Orí Oba ni ó bi wón . Ajítòni Fólórunsó. Àjàgbé mo gbà fún Oládòkun. Tìmì Oba Ede O kú mèye ìbàdàn . Ajítòní baba wa. O kú mèye Òsogbo. Fólórunsó omo Béllò Kò sí ibi owó ìjà erin ò mà mà tó. Owó tó Sókótó. Owó tó ìlorin. Owó tó ìmèsí olójà òkè. Àjàgbé owó tó ìlú Èbó. Oláníyì ìwo lomo Eégúnjobí . A ó lese tàì leè kó . Bée bá dé ilée wa lóhùú. A ó le se tàì le kose kó o A ó lese Fólórunsó lerí yen. Àlaré aláwàdà. Àjàgbé lerí yen. Àlaré aláwàdà. Àjàgbé lerí yen. Àwàdà laré yìí. Aremo n be lówó o e e e e Aremo n be lówó. Àwàdà laré yìí o . Aremo n be lóó o eeeee Aremo n be lóla. Ikúmóruwá Olórun ló lóògùn. Kò mò sónísègùn tó ju Olórun lo. Olórun lo lóògùn Ikúmoruwá, Àjàgbé Oladokun. Iró, Iró. Iró ni wón n pa. èké, èké ni won n sa. Iró enìkan kì í bá Oba á jà, iró. È báà pa àgùntàn, àgùntàn È báà pa tòló tòló olórí eye. Omo tí Olórun yó se, ó ti sé. Àjàgbé Oládòkun. Ìyá àjé kú è n yò sèsè Omo tí àjé fi sílè, ó lè pani je. Àjàgbé Oládòkun. A wí, wí, wí wón ò fé. Won ò fé. Won ó fé. A fò fò, fò, won ò gbà. A bólù sílè a fi enu wí. Àpótí alákàrà ká bí á wó. Abánise mó sì bánise mo. A jìnnà sátákètè kété kété. Ojú ti babaláwo yín. Ibi e gbé ojú lé ònà ò gba ibè lo. Ojú ti babaláwo yín. Ikúnrúwá, Àjàgbé Oládòkun. Kùkùté ò mira jìgì. Kùkùté ò mira jìgì. Ení mi kùkùté ara è lómì o. Kùkùté ò mira jìgì, Fólórunsó Àjàgbé Oládòkun Kùkùté ò mira jìgì. Kùkùté ò mira jìgi. Eni ó mi kùkùté ara è lónìmo. Kùkùté ò mira jìgì. Fólórunsó Ajàgbé Oládòkun. Orí Oba ni ó bi yín. Orí Oba ni ó bi yín. Eni tí n bá Oba á je Ti n bá Oba léyìn. Ajitòni. Orí Oba ni ó bí yín. Ikúnrúwá, Àjàgbé Oládòkun. Orí Oba ni ó bi yín. Eni tí n bá Oba á je. Ti n bá Oba á mu. Tí n sòrò Oba léyìn. Orí Oba ni ó bi yín.
Tìmì tí Èdè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2423
2423
Olókukù ti Òkukù Olokuku OLÓKUKÙ TI ÒKUKÙ. –OBA ABÍÓYÈ OLÚRÓNKÉ TI LÁTI OWÓ RÁFÁTÙ OYÈTÓÚN –ILÉ OLÓKUKÙ Olúrónké Abíóyè sèsó ará ìbá làlúké Olúrónké omo orunkunkun tí n jé ó sán ngbáa Mo dàgbà n ò tí fòrò loyè Àkànní eníjà mo tòsín mo mú raso Mo tà kòrò mo sìn sosìn sòrò loyè Èmí wá teléfe rà kókó Omo Olúrónké mo teja nlá Mo mú rerú were sókun Omo Olúrónké Àbìrókò gogongo nínú oko Babaà mi Abìrókò kò ní yòyòyò Elékùlé à á pàdé Olúrónké abilé kere níwájú ebu Ibájáde ò tún nlé Abasó gbé kóko hánu Abìrìn aso jèntièlè Elékùlé ànpàdé omo ‘Mówálé Abilé kere níwájú ebu Ìsájáde ò tán n lé omo Olúrónké Abí bó bá máso dúdú a mú pupa A fèyí wìnìwìnì bora sùn Ará odò kòsi Ará odò kòbìnìyàn Mo tólá bí eni tóyin énu Eníjá mo tàsín mo mú raso Mo tà kòrò mo sín sosìn sorà loyè Èmí wá telébe rà kókó Mo teja n lá mo mú rerú were Wón bú mi lárùpè nìjàbé osólú Éràn oyè mo délé mo su kún sí baba wa Ìsèsó ará ìbálà lúké Mo wá délé mo súré telé N ó rè bá gògo lómo àgògo mi sòsò layè mokò lotìn Eni ó kìjàsé tí ò kiwi E máa bá mi ségi gangan lóri olúwa re Eríja mo tàsín mo mú rase Mo tà kòrò yofà loyè Èmi teléèbé ràkókó Mo teja nlá mo mú rerú were lóko Òtònpòrò mí yodà loyè Obukun wá n bá mí relé ìbálàmoko Omo alárá ti n gesín mawo Eèkí eríjà mo tàsín mo mú raso Mo ta kóró mo sìn sosìn sorà loyè Èmí wá telébe rà kókó Igi mélòó ní sowó níran babà re Áwé wón n sowó àràbà kàn mà soyùn Nípópó oníjàbé mo ró o Áwé n sowó o Àràbà mà soyùn nípópó oníjàbé mo ró o Ìsèsó alárá mi won ò ní jewe Mo loòràn òwè jálè nìlàkùn N ò jé polódòó yò símo Omi kúnkún tí n yayaba lénu Ìsèsó ará odò kòbini Ìsèsó ará odò kòbìyàn Ìsèsó ará odò Mòtólání Njó àwéré wón n sòwón lòwó n nú ilé wa Owó wá sun gbeere wa sì tiè lòtìn Njó àwèrè àwèrè wón pàd;e jà n jàbé osólú Eéràn oyè mo teja dúdú mo mú rerú were Mo tà kòrò mo sìn sosìn sorà loyè Èmí wá telébe rà kókó Eéràn oyè mo teja nlá mo mu rerú were Àwé wón sowó o Àràbà kán mà soyùn Áwé sowó ará ìbálàmoko Omo alárá ti n gesin mawo E bá n kárelé ará ìbálàlúké E bá n kárélé omo omifunfun tí n yayaba lénu Ìsèsú tí mo kówè n ò kójó tí mo wá kójó tán tíjó n yo mí lénu Omo Olúrónké omo Òtínkànle Omo Mádòlótìn Ó wá gbòtìn kan kan kan Ìsèsú ará odò orò Ará odò mòtòlénú bí eni tóyin émi Pí tí wón kése sùbú Oba Babà mi àlà agemo òjó gèlè àsò Omo bó di gigùn ó gùn Olúrónké Obá ni bó di gíga ó ga Omo kòga ò bèrè lòkùnrìn kún Omo arógangan gún kèsewà nìyá tó bí mi lómo Ìsèsú ará odò mòtólárí o Aásìn-n nì won ò gbe nílé Oba gòdògògò won ò dé n léràn-án sè Ebúkú wá n sé síin lénu Àbálàlúké omo arunkunkun tí wón n jósán agbáa Ìsèsú ará odò orò E bá n kárelé ará ìbálàwóko Omoalárá tí n gesín mawo Omo alias eníwèé òye Baba mi oòsà won ò gbohùn odì títí òsà sé pàyá ìkókó Mo síbá olá lómo ode a máa súngi so Baba mi Àdìsá lásáré mi èkan kìí se lásán Bí baba ò bá ti lé nìkan Nkan ní baba lo Ará ibú aró ará àgbón ìgbe Ará omi kúnkún tí yayaba lénu Ìrókò tété modé ò gbodò sa Eníjó orí òrìlé baba Oyéédùn Kì í logun ó mó mérú wálé Láganjú à n gbó à n té é n gbopa bí ò lèrin E bá n ká relé o Ìsèsù bí mo kówè lotìn E bá n ká relé o Ará ìbálàmóto E bá n kárelé ìbálàmóko Omo orunkúnkún tí jósán gbáa Mo dàgbà n è tíì bòrò loyè Omo èkè ò jé wí felékèé nòdí Babà mi èsìkà won ò pera è níkà Sápé lode èké n jó Omo won n jó wón n bá ní kòyi Èké ò tètè mò pé tòun là n wi Baba Lápéri Àrèmú Oyèuemí Babà mi Àrèmú enisànpònná se léwà lajàsé Tálájogún wá n wó bí ení gbón ni Ègùn Àjàsé wá n tirí wó tònà Ó ní bárèmú ò bá kú ló tán Baba Lápérí E bá n kárelé ará odò kòbini É bá n kárelé ará odò kòbìyàn É bá n kárelé ará odò mòtólání Omo oríaré àdé sùnyàn ni wón máa n poba Babà mi àgbàlagbà lajò Ònjó àbú bànté Orí aré arókó po wá bì ságbàdo lára babà mi abàgbàdo sòsò legàn Elékùlé ànpàdé Ó ti took Omówálé se Omo ajímá sé n sé sègí babà mi ò jiníkìtùkùtù se hùn Ò sùn jáláte sùn mójúmó Mójúmó sìn bá yowó dúdú á yowó pupa Omo òwàrà Àlàdé tó ti fón sègo dà á gbó Ajímosìn-in nítorí aséwé nítorí aségi Ó ni nótorí ìlàpá ti won n wògbè sùà sùà E bá n kárelé o Ìsèsún ará odò orò E bá n kárelé o Lérìn koko babà mi mòrìwò sara Ògún jìè Olúrónke abilé kiri mò níbòkun Babà mi abòlè kiri mò nílè jèsà Ìbá mómo è rè Jèsà nímòkun nì bá kú sí Oko Lálété Ará ibú aró ará àgbón ìgbe Ará omo kúnkún tí yayaba lénu Ìsèsó ará odò orò Omo p’ptí wón kesè sùsú Oba Babà mi àlà agemo òtó gèlè àsà Omo bó di gúngùn ógùn Olúrónké Obá ní bó di giga ó ga Omo à pè á joyè ogun ará ibú aró o Ará ibú aró ará àgbón ìgbe Níbo nilé yín o Ìsèsún tí mo kómè n ò kójó tí mo wá kójó tán tójó wá n yomí lénu Odò Òtìn le mò E ò mo bú aró o Ibú aró n be Òkóyè kólé Odò Otìn le mò E ò ma bú owó o Ibú owó n be Òkóyè kólá Eníkòyí omo agbònyìn Eníkòyí omo agbòn ti è rikú sá Yánbídolú omo alérí ikú kangun Òsèsèkòyí omo agbonyìn Yánbídolú lóòtó ègin Omo awí bée bógun lo Èsó wón n rode rèé kólé Nígba tó níkòyí é fid é olè kólé è lo Omo akú omo oru Omo akú bi ó dí Omo akú bi ti tèntèré eye ò gbodò dé Omo akú tán gurí è gún sòyìn Òsèsèkòyí eníkòyí dìde Yánbìdolú ogún tó lo Òsèsèkòyí wón n rode rèé kólé Nígbà ti Èníkòyí é ti dé olè kólé è lo Yánbídolú omo a kú tapó torun Òsèsèkòyí omo agbònyìn Eníkòyí o ì dìde Omo a wí bée bógun lo Òsèsèkòyì omo akúmó yànyìn kórí Yánbídoyí olóòótó ègímo Alérí ikú kangan Òsèsèkòyí omo agbònyín Eníkòyí dìde Yánbídolú ogún wá ti lo Òsèsèkòyí omo agbòntíè ríkú sá Eníkòyí dìde ogún tó lo ogún tó lo Èsó ò délé pé ogún tó lo Èsó ò fara rogi Òsèsèkòyí gbapó gbofà tán ogún wá le Eniíkòyí wo ló ti ì le ogún tó lo Ìdí òyélù a ròkún Ìdi oyélù a ròsà Ìdí oyélù a rèkòyi ilé Onikoyi ò í dìde ogun Oba tó lo Òsèsèkòyí omo àgbonyìn Yánbídoyí olóòótó èyin Omo awí lée bógun lo.
Olókukù ti Òkukù
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2426
2426
Síńtáàsì Yorùbá SÍNTÁÀSÌ YORÙBÁ (1) Kí ni Sińtáàsì? Síńtáàsì ni èka kan gírámà èdè tí ó níí sè pèlú bi a se ń so òrò pò tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Nínú ìdánilékòó yìi, a ó máa mú enu ba ohun ti a pè ni òfin. Ìtumò òfin gégé bí a se lò ó ní ìyín ni àwon ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yii yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun ti elédè so jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón eléyìi kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn lè mu emu yó ti yóò máa so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti otí bá dá ní ojú rè, yóò so òrò ti ó mógbón lówó. Nínú ìdánilékòó yìí, a ó ménuba ohun tí a ó pè ní ofin. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan. Fún àpeere, eni tí ó bá gbó Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà, (1) (a) Mo lo sí oko (b) Sí lo oko mo Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nip é ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu. O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin tíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé àtéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé àtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé. (2) (a) Àwon ti ó lo kò pò (b) Àwon ti wón lo kò pò Méjèèjì ni ó bófin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé àtéwógbà, èkejì kò jé àtéwógbà. Èyé kò ni nǹken kan án se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófinmu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú ìdánilékòó yìí. Ó ye kí á tún pe àkíyèsí wa sí tip é àbínibí ni èdè o. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó ọ. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àbínibí ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè, ó ti wà lára re. Kò sì si èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. (2) Òrò àti Àpólà: Òrò ti a bat ò pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b). (3) (a) Olú gíga lo (b) Olú lo Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 3. Gírámà ti a ó lò: Gírámà ìyidà onídàro ti Chomsky ni a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye. Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere: (4) GB APOR APIS Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5). (5) GB APOR AF APIS Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí: (6) AF AS, IB, M, IBM Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS. (4) APOR: Èyí ni eni ti ó kópa nínú ohun ti òrò-ìse ń so. OR tàbí arópò-orúko (AR) ni ó máa ń jé olórí fún/APOR. Ohun tí a máa ń pè ní olórí fún àpólà kan ni òrò kan soso tí ó bá è dúró fún àpólà yen. Fún àpeere omo ni olórí fún (7a) àti (7b) àpólà orúko sì ni méjèèjì. Mo ni olórí fún àpólà orúko olùwà ní (7d), arópò-orúko sì ni mo yìí. (7) (a) Omo pupa (b) Omo (d) Mo lo A lè bá àpólà orúko ni ipò olùwà (èyí ni a fa ìlà sí ní ìdí ni (8a), ipò àbò (òun ni a fa ìlà sì ní ìdí ni (8b) àti ní i`po àbò fún atókùn nínú gbólóhùn (wo òrò tí a fa ìlà sí ní ìdi ní (8d)). (8) (a) Aso pupa ti ya (b) O ti ya aso pupa (d) Ó rí Olú ni ilé òfin ìhun gbólóhùn tí a fi lè tún APOR ko ni: (9) APOR ---> OR APAJ Àpólà àpèjúwe ni APAJ dúró fún. Láti fi hàn pé OR ni ó se pàtàkì jù nínú APOR, a lè ko òfin ìhun gbólóhùn wa báyìí. (10) APOR ---> OR (APAJ) Àmì yìí “( )” dúró fún pé ohun tí ó wà nínú rè kò pon dandan. Àkámó ni a ń pe àmì yìí. Níbi tí a kò bá ti lo àmì yìí, gbogbo ìsòrí òrò tí ó tèlé àmì ofà yen ni ó pon dandan nìyàn. A lè fi àwòrán-atóka igi fi èyí hàn báyìí. (11) nìkan ni a lé rì nínú (9); Àwòrán-atóka igi (11) ní èka, ti (12) kò ní. Aróp-orúko náà lè dúró gégé bí APOR. Òfin ìhun gbólóhùn (13) fi èyí hàn. (13) APOR --> AR Nìgbàkúùgbà tí a bá tin i a rópò-orúko gégé bi APOR, arópò-orúko náà kì í ní èyán nítorí a kì í fi òrò mìíràn yán arópò-orúko ní èdè Yorùbá béè ni a kì í fi arópò-orúko Yorùbá yán òrò mìíràn. Àwòrán-atóka igi bíi ti (12) náà ni a ó lò fún òfin ìhun gbólóhùn (13). Ìyàtò tí ó kàn níbè kò ju pé dípò OR, a ó lo AR. A lè so gbogbo òfin ìhun gbólóhùn APOR ti a ti ń ko láti òni (wo (9), (10) àti (13)) di eyo kan. Àkámó onídodo ni a ń pe àmì yìí “ ” . Ohun tí ó ń fi hàn nip é a ó mú òkan nínú AR àti OR (APAJ). A ti so télè pé ohun tí kò pon dandan ni àmì yìí “( )” ń fi hàn. (17) (a) Mo lo (b) Olú lo (d) Omo pupa lo (e) Omo pupa tí ó ga lo Òfin ìhun gbólóhùn tí ó gbé (17e) jáde ni (18) tí a lè rí ni (16) Àfikún ni ohun tí a pè ní AFK nínú àwòrán yìí. Ohun tí ó dúró fún ni àwon òrò bíi tí (Omo ti ó lo), pé (Ó so pé ó lo) abbl tí a ń pè ní atíka gbólóhùn. Ohun tí tirayáńgù tí ó wà ní (19) dúró fún ni pé a kò fé fó ohun tí ó wà ní abé rè sí wéwé nítorí pé kò se pàtàkì fún ohun tí a ń so lówó. Sé e mò pé a tì lè fó GB sí APOR, AF àti APIS, a kò se èyí nítorí pé kò je wá lógún nínú ohun tí a ń so lówó. A lè so APOR mó APOR lábé APOR. Òfin ìhun gbólóhùn tí a fi lè fi èyí hàn ni (20); (21) sì ni àwòrán-atóka igi rè. (20) APOR ---> AS APOR Òrò-àso ni AS dúrú fún 5 APIS Òrò-ìse (IS) ni olórí fún àpólà ìse (APIS). APIS ni a máà ni a máa ń pò ní kókó gbólóhùn nínú àwon ìwé tètèdé onígírámà nítorí pé ó ní òrò-ìse nínú. Òrò-ìse ni ó máa ń so ohun tí APOR se nínú gbólóhùn. Gégé bí olórí fún APIS, ó pon dandan kí òrò-ìse wà nínú gbólóhùn yálà pèlú àwon emèwà rè tàbí ní òun nìkan. 5i. ÌGBÀBÒ TÀBÍ ÀÌGBÀBÒ: Òfin ìhun gbólóhùn tí a fi máa ń tú APIS pale ni (22) APIS ---> IS X “X” jé bí àfikún fún òrò-ìse nínú APIS. Àfikún yìí lè dúró fún ìsòrí òrò kan tàbí àpólà. Ó ye kí á tètè se àlàyé síwájú sí i nípa ìgbàgbò tàbí àìgbàbò òrò-ìse. Òrò-ìse tí ó gbàbò ni òrò-ìse tí ó bá ní APOR gégé bí àfikún. Èyí tí kò bá ní APOR gégé bí àfikún ni òrò-ìse àìgbàbò. Ohun a ń so nip é òrò-ìse lè ní àfikún nínú gbólóhùn sine kí á pè é ní òrò-àìgbàbò. E wo (23) àti (24). (23) Olú lo kíákíá (24) Olú ra aso Lóòótó (23) àti (24) ni ó ni àfikún fún òrò-ìse sùgbón sùgbón (24) nìkan ni lè so pé òrò-ise rè gba àbo. Ohun tí ó fá èyí ni wí pé APOR ni àfikún fún òrò-ìse (23) sùgbón àpólà àpónlé (APAP) ni àfikún fún òrò-ìse (24). A lè fi òfin gbé àlàyé àtúnpín sísòrí òrò-ìse tí a sese sàlàyé rè tán jáde báyìí. (25) (a) ISagb + [---APOR] (b) ISaigb + [ ---0] A lè pa òfin méjèèjì yìí pò báyìí (26) IS + [ ------------ (APOR)] Yàtò si APOR àti APAP, IS tún lè rí àwon àfikún mìíràn. Àwon náà ni àpólà atókùn (APAT) àti gbólóhùn onípele (GB). A lè se àtúnpínsòrí IS pelú gbogbo won báyìí, (27) (a) rí : IS; + [----- APOR] Mo rí Olú (b) wá: IS; + [-----APAT ] Mo wá sí ilé (d) rà IS; + [-----APOR (APAT)] Mo ra aso ní ojà (e) dàbí: IS; +[--------GB] Ó dàbí kí ó má lo Ohun tí òfin (27) yìí ń so nip é tí a bá rí òrò-ìse kan, gégé bí elédè, a ó mo sàkáání ibi tí a ti lè bá a. Fún àpeere, (27a) ń so pé rí jé òrò-ìse tí ó máa ń gba APOR gégé bí àfikún. (27b) náà so pé wá jé òrò-ìse tí ó máa ń gba APAT gégé àfikún. Kìí se pé àwon òrò-ìse wònyí kò lè yan àfikún mìíràn sùgbón àtúnpínsòrí tí a bá fún òrò kan ni a gbódò tèlé bí béè kó, gbólóhùn tí ó ti je yo kò ní í bófin mú. Yàtò sí àtúnpínsísòrí tí a menu bà yìí, a tún lè fi òfin ìhun gbólóhùn sàlàyé APIS. (28) (a) APIS ---> IS (b) APIS ---> IS APOR A lè pa méjèèjì pò báyìí: (29) APIS ---> IS (APOR) Lóòótó, o dàbí ìgbà pé àwòrán-atóka igi yé ènìyàn ju àkámó asàmìsí lo sùgbón à kò lè so pé òkan dára ju èkejì lo tí a bá fi ojú tíórì wò ó. E se àkíyèsi pé àayè tí àwòrán-atóka igi gbà jut i àkámó asàmì sí lo. Níwòn ìgbà tí ó jé wí pé àwon méjèèjì ni a ó máa bá pàdé nínú ìwé, ó ye kí á mò wón. (5ii) Òrò-ìse Àsínpò: Lóòótó àwon tètèdé onígíràmà ti máa ń fún gbólóhùn abódé ní oríkì pé òun ni àkójopò òrò tí ó òrò-ìse kan nínú. Èyí kò wolé mó nítorí a ti rí gbólóhùn abode tí ó ní ju òrò-ìse kan lo. Àpeere irú gbólóhùn abode báyìí ni gbólóhùn alásínpò ìse. Gbólóhùn yìí máa ń ní olùwà kan sùgbón àwon òrò-ìse yìí mó ara won. Òfin ìhun gbólóhùn ti a máa ń lò fún àpólà-ìse inú gbólóhùn alásínpò ise ni. (32) APIS ---> APIS (APISn ) Oun tí “n” yìí ń so nip é APIS yìí lè máà níye. E jé kí á wo gbólóhùn kan tí ó ní irú òrò-ìsè yìí. (34) Adé gbé ògèdè mi fún eran je (6) Àfòmó: Ní àárín àpólà ìse àti àpólà orúko ni ìsòrí tí a ń pè ní àfòmó wà. Òpòlopò òrò ni ó wà ní abé ìsòrú yìí. Gbogbo won ni ó sì ní àbùdá òrò-ìse. Ìsòrí yìí ni àwon tètèdé onígírámà ń pè ní asèrànwó-ise. Àwon ohun tí a ń bá lábé ìsòrí yìi ni àsìkò, ibá, múùdù àti ìbámu. Ìdí tí a fi ń pe ìsòrí yìí ní àfòmó nip é púpò nínú àwon ohun tí ó máa ń je yo lábé rè, àfòmó ni wón máa ń jé nínú òpòlopò èdè àgbáyé. Gbogbo èdè ni ó ní àfòmó yìí sùgbón ònà tí èdè kòòkan fi máa ń mú un lò yàtò sí ara won. Gbogbo àwon òrò tí ó wà lábé ìsòrí yìí ní èdè Yorùbá ni ó lè dá dúrò, ìyen ni pé won kì í se mófíìmù àfarahe. Fún àpeere, abé ìsòrí yìí ni a ti máa rí àwon òrò bíi gbódò, lè, máa, ta, ń abll. Pèlú àfòmó tí a ti menu bà yìí, òfin ìhun gbólóhùn tí a ó máa ló ni (35), 936) ni gbólóhùn tí ó lè ti inú rè jáde, (35) GB ---> APOR AF APIS (36) Olú gbódò lo 7. Àpólà Atókùn àti Àpólà Àpónlé: A ti menu bà APOR àti APIS. A ti sòrò díè nípa àpólà àpèjúwe àti àfòmó. Àpólà méjì tí ó kù tí a ó menu bà sí i ni àpólà atókùn àti àpólà àpónlé. Òrò atókùn àti APOR ni a máa ń bá nínú àpólà atókùn ni a fa igi sí ní ìdí ní (38). Òfin ìhun gbólóhùn rè ni (38) (a) Adé lo sí ilé (b) Mo rí Olú ní ojà (d) Òjó ti ilé lo sí oko (39) APAT ---> AT APOR Òrò àpóné ni a máa ń bá nínú àpólà àpónlé. Òrò àpónlé yìí seé se kí ó ju eyo kan lo ó sì lè jé eyo kan. (41) ni òfin ìhun gbólóhùn àpólà àpónlé Ní (42), a fa igi sí ìdí àpólà àpónlé a sì ya àwòrán-atóka igi fún un ní (43). (41) APAP ---> AP APAP (42) Adé lo kíákíá rí AF---> AS, IB, M, IBM. (8) Orísìí Gbóóhùn Yorùbá: Orísìí gbólóhùn méta ni ó wà ni èdè Yorùbá- (i) gbólóhùn abode, (ii) gbólóhùn oníbò àti (iii) gbólóhùn alákànpò. (i) Gbólóhùn abode: Púpò nínú àwon àpeere tí a ti ń lò láti ìbèrè ìwé ìléwó yìí ni ó jé gbólóhùn abode. Oríkì tí a lè fún gbólóhùn abode ni gbólóhùn tí ó ní kókó gbólóhùn kan. Ohun tí ó jé kí á lo kókó gbólóhún dipò òrò-ìse ni pé a rí gbólóhùn abode tí ó ní ju òrò-ìse kan lo sùgbón tí ó jé pé kókó gbólóhùn kan soso ni ó ní . Àpeere irú ìyí ni gbólóhùn alásínpò ìse tí a ti sòrò nípa rè sáájú. Òfin ìhun gbólóhùn tí a ń lò fún gbólóhùn abode ni (44); (45) ni àpeere gbólóhùn abódé. (44) GB ---> APOR AF APIS (45) Mo ra isu (ii) Gbólóhùn Oníbò: Gbólóhùn oníbò ni gbólóhùn tí ó ní olórí gbólóhùn àti gbólóhùn àfibò. Olórí gbólóhùn yìí lè dá dúró sùgbón gbólóhùn àfibò kò lè dá dúró. GB ---> ATAF GB Òfin gbólóhùn (52) lè gbà wá láàyè láti sèdá. (53) (a) Olú dé (b) Ade ra aso (d) Omo tí ó lo dé Sùgbón a kò lè sèdá òkankan nínú (54) nípa lílo òfin (52). (54) (a) Ǹjé Olú dé? (b) Sé Adé ra aso? (d) Omo tí ó lo dé bí? Síbè a ó se àkíyèsí pé àwon gbólóhùn (53) ní nǹkan se pèlú (54). Gírámà tí a pè ní gírámà ìyídà onídàro yìí ní gbára láti se àlàyé ìbásepò tí ó wà láàrin àwon gbólóhùn wònyí. Sùgbón kí a tó menu ba bí yóò se se àlàyé yìí, e jé kí a wo àwon ohun tí a lè bá pàdé nínú gírámà yìí. 10. Gírámà Ìyídà Onídàro: Ònà méta ni a lè pín gìrámà yìí sí àwon náà ni ìhun ìsàlè, gbé aifa àti ìhun òkè. Àwon èka méjì mìíràn tún wà tí kò ní í je wá lógún púpò nínú ìdánilékòó yìí: àwon náà ni èka fonólójì àti èka ìlárògún (ìní àrògún). A ó wá yè wón won í òkòòkan. (i) ìhun Ìsàlè: Gbogbo gbólóhùn ni ó máa ń ní ìhun ìsàlè. Ó wá seé se kí ìhun ìsàlè gbólóhùn kan bá ti òkè mu; ó sì seé se kí ó máà bá a mu. Àwon ohun tí a máa ń pá pàdé nínú ìhun ìsàlè ni aká òrò, òfin òrò, òfin gbólóhùn, àttúnpínsìsòrí, òfin ìsòrí òrò, ìyanra (ìyan ara). (ii) Gbé alfa: Ìtumò gbé alfa ni pé kí á gbé nǹkan kan láti ibì kan lo sí ibòmíràn nínú gbólóhùn. (iii) Ìhun Òkè: Àwon ohun tí a máa ń bá pàdé nínú ìhun òkè ni ìsòrí kòòfo, gbólóhùn tí a ti da ètò rè rú, ìse lámì kanùn (1ise ní àmì kan ùn) asé. (iv) Èka Fonólójì: Òkan nínú àwon èka méjì tí kò níí je wá lógún púpò tí a máa ń bá nínú gírámà ìyídà onídàro ni èka fonólòjì. Èka yìí nib í a se ń pe òrò jáde lénu je lógún. (v) Èka Ìlárògún: Èka yìí náà kò ní í je wá lógún tó béè tàbí jù béè lo nínú ìdánilékòó yìí. Èka yìí ní ó se pèlú àrògún. Òfin síńtáásì lè gba àwon gbólóhùn kan láàyè tí ó jé pé èka yìí ni yóò so pé irú gbólóhùn béè kò ni àrògún. Àwòrán (57) ní ó fi àwon èka wònyí hàn wá dáradára. E jé kí á wá wo bí gírámà yìí se ń sisé. (11) Gbólóhùn Ìbéèrè béè-ni-béè-kó: Àwon ìbéèrè kan wà tí ó jé pé béè ni tàbí béè kó ni ìdáhùn máa ń jé. Fún àpeere, tí a bá so pé: (55) Ǹjé Olú lo? A lè dáhùn wí pé: (56) Béè ni, Olú lo tàbí béè kó, Olú kò lo (57) Ìhun Ìsàlè/ìpìlè aká òrò òfin òrò òfin ìsòrí àtúnpínsìsòrí ìyanra òfin ìhun gbólóhùn Gbé Alfa Ìhun Òkè Ìsòrí kòòfo Gbólóhùn tí a dà ètò rè rú Ìse lámì kan-ùn asé Ẹ̀ká Fonọ́lọ́jì Ẹ̀ka àrògún Gégé bí a se so télè, o rorùn láti láti lo òfi ìhun gbólóhùn láti sèdá gbólóhùn bíi (58) sùgbón a kò lè lo òfin ìhun gbólóhùn láti sèdá (55). (58) Olú lo Síbè a gbódò lè sàlàyé bí (55) se wáyé. Ohun tí gírámà tí a ń lò nínú ìdánilékòó yìí so ni pé (58) ni ìpìlò (55), ìyen ni pé ní ìhun ìpìlè, (58) nìkan ni a ní. Ìhun òkè ni (55). Ohun tí ó selè nip é léyìn ìgbà tí a ti fi òfin ìhun gbólóhùn sèdá (58) tán ni a wá so atóka ìbéèrè mó on. Bí àwòrán-atóka igi won se rí nìyi. Àrótì ni AROTI dúró fún. Àwon ìbéèrè mìíràn tí ó bá eléyìí mu tí a sì gbódò sàlàyé won bákan náà ni (61). (61) (a) Sé Olú lo? (b) Olú lo bí? E ó se àkíyèsí wí pé ń se ni àrótì sáájú gbólóhùn nínú Ǹjé Olú lo? Sùgbón nínú Olú lo bí? àrótì yóò tèlé gbólóhùn ni. (12) Ìbéèrè tí kì í ní ìdáhùn béè ni béè kó: Àwon ìbéèrè kan wà ti ìdáhùn won kì í se béè ni tàbí béè kó. Àpeere irú ìbéèrè béè ni (63) (a) Ta ni Olú rí? (b) Kí ni Olú se? Ònà tí a ń gbà se àlàyé àwon ìbéèrè eléyìí yàtò sí ti béè ni béè kó. A ó rántí pé àrótì, ìyen àwomó ni a lò láti sàlàyé bí ìbéèrè béè ni béè kó se wáyé. Gbé alfa ni a ó fi sàlàyé eléyìí. Nígbà tí a ń sòrò nípa àtúnpínsísòrí òrò-ìse, a sàlàyé pé àwon òrò-ìse bíi: rí àti se gbódò ní APOR gégé bí àbò nínú gbólóhùn tí a bá ti lò wón. Ìyen ni a fi ń rí. (64) (a) Olú se isé (b) Adé rí Òjó Tí (56) kò sì bófin mu (65) (a) *Adé rí (b) *Olú se Sùgbón tí a bá wo (63), a o rí i wí pé APOR kankan kò tèlé rí àti se gégé bi àbò síbè àwon méjèèjì bá òfin mu. Àlàyé tí a rí se ni pé kì í se pé won kò ní APOR gégé bú àbò, won ní ní ìhun ìpìlè. Ìhun òkè ni ó ti dàbí ìgbà pé won kò ní nítorí pé a ti gbé APOR àbò tí wón ní kúrò láàyè won. E se àkíyèsí pé tí a bá ń se ìbéèrè alápèpadà, a máa ń so (66). (66) (a) Olú se kí ni? (b) Adé rí tan i? Nínú gbólóhùn (66), a ò lè so pé se àti rí kò ní APOR àbò nítorí ta àti kí ni ó jé àbò fún òkòòkan won, òrò-orúko sì ni ta àti kí yìí. Àwon òrò yìí ni a gbé kúrò láàyè tí wón wà ní ìhun ìpìlè lo sí ibòíràn kí wón tó dé ìhun òkè. Èyí ló fi dàbí ìgbà pé won kò ní àbò. Ìgbà tí a gbé àwon òrò wònyí kúrò láàyè tí wón wà ní (66) lo sí iwájú ni a ní (63). Kòòfo ni KF dúró fún. Àwon atóka ìbéèrè kan wà tí òrò-ìse kì í se àtúnpínsísòrí fún won. Àpeere irú won ni: (68) (a) Níbo ni Olú ti ra aso (b) Báwo ni Dàda se mú Olu A ó se àkíyèsi pé àwon òrò-ìse rà àti mú sì ní APOR àbò tí ó ye kí wón ní. Síbè e ó se àkíyèsí pé a lè se àwon ìbéèrè alápèpadà wònyí: (69) (a) Olú ra aso, níbo? (b) Dàda mú Olú, báwo? Ohun tí eléyìí ń fi hàn ni pé (69) náà ni ìpìlè fún (68) sùgbón nǹkan tí ó selè nip é àbé àpólà-ìse kó ni àwon atóka ìbéèrè báwo àti níbo wà. Abé ìsòrí tí wón wà ni a ń pè ní àrótì. Bí àwóràn-atóka igi ti won se rí nì yí. Tí a bá lo atóka ìbéèrè tan i tàbí kí ni láti bèèrè ìbéèrè nípa òrò-orúko olùwà, ààyè olùwà yìí kò ní í jé kòòfo. A ó fi arópò orúko kan sí ààyè yìí. Béè náà nit í a bá bèèrè ìbéèrè nípa òrò-orúko tí ó ń yán òrò-orúko mìíràn. Àpeere. (71) (a) Olú gbé ìwé Adé (b) Ta ni ó gbé ìwé Adé? (d) Ta ni Olú gbé ìwé rè 13. Awé gbólóhùn Asàpèjúwe: Gbólóhùn tí a tún máa ń gbé alfa nínú rè ni awé gbólóhùn asàpèjúwe. Àbùdá Awé gbólóhùn Asapèjúwe: i. A rí APOR tí awé gbólóhùn oní-tí tèlé ii. APOR tí ó saájú awé gbólóhùn oní-tí yìí ni olórí fún gbogbo awé gbólóhùn yìí. iii. Àlàfo kan wà nínú gbólóhùn àfibò inú awé gbólóhùn yìí. iv. Kò sí ibi tí a kò ti lè rí àlàfo tí a menu bà ní (iii) yìí. AGBA dúró fún awé gbólóhùn asàpèjúwe. (vi) Àlàfo tí a menu ní III gbódò ní àmì kan náà pèlú atíka awé gbólóhùn asàpèjúwe. (vii) Àwon kan wà nínú àwon awé gbólóhùn asàpèjúwe tí kì í ní àlàfo. Àwon yìí ni ìgbà tí a bá se àpèjúwe fún APOR olùwà àti OR tí ó bá yán OR mìíran. (viii) Ó pon dandan kí APOR méjì bá ara mu nínú awé gbólóhùn asàpèjúwe. Àwòrán-atóka igi tí ó sàlàyé awé gbólóhùn yìí nì yí ní sí-sè-n-tèlé GB gbódò ní APOR tí ó bá ti iwájú rè dógbà nínú Àmì yìí I ń fi hàn pé àwon APOR méjèèjì bá ara mu. A ó so APOR; kejì di ti a ó gbé e wá sí abé àfikún. Omo ni a ó gbé wá sí abé àfikún tí yóò di ti. (14) Òrò-Ìse aláìléni: A ó se àkíyèsí pé gbogbo nǹkan tí a ti ń gbé, apá òtún ni a ti ń gbé won wá sí apa òsì. Ìbéèrè wá nip é sé apá òsì nìkan ni a máa ń gbé nǹkan wa. Ìyen ni pé se apá òsì nìkan ni a máa ń gbé ‘alfa’ wa ni? Kì í se apá òsì nìkan. Àpeere tí a ó fún wa báyìí yóò fi èyí hàn. Àpeere náà ni gbólóhùn tí ó bá ní òrò-ìse aláìléni nínú. Irú gbólóhùn béè ni: (76) Kí á pa àgó méta dára, dára tí ó wà nínú gbólóhùn yìi ni a pè ní òrò-ìse aláìléni. Àwon òrò-ìse mìíràn tí ó tún wà lábé ìsòrí yìí ni burú, dájú, dùn, wù abbl. E ó se àkíyèsi pé ìtumò kan náà ni (76) àti (77) ni. (77) ó dára kí á pa àgó méta. Níwòn ìgbà tí wón tin í ìtumò kan náà tí òrò inú won sì férè bára mu tán, ó ye kí á lè topa ìpìlè won dé ibì kan náà. (76) ni ó jé ìpìlè fún (77). Ohun tí ó selè ni pé a gbé kú á pa àgó méta lo sí èyìn dára. Nígbà tí a se eléyìí, ààyè ibi tí kí á pa àgó méta wà télè wá sòfo. Ààyè olùwà ni ààyè yìí. Níwòn ìgbà tí ààyè olùwà kò sì gbódò sófo, a wá fi ó tí kò tóka sí enikéni sí ààyè náà. Báyìí ni a se rí (77) láti ara (76). Àyè kòòfo (KF) yìí ni a ó wá fi ó aláìléni sí. Apá òsì ni a ti gbé nǹkan lo sí apá òtún. Àpeere àwon gbólóhùn tí ó se báyìí wáyé ni: (80) (a) (i) Kí á jalè kò dára (ii) Kò dára kí á jalè (b) (i) Pé mo pé dùn mí (ii) Ó dùn mí pé mo pé (15) Gbólóhùn Àse: Kì í se gbogbo ìyídà ni ó máa ń ní gbé ‘alfa’. Ìyen ni pé kì í se gbogbo ìyídà ni a máa ń gbé nǹkan láti ibì kan lo sí ibòmíràn. Àpeere gbólóhùn tí a sèdá láìgbé nǹkan kan lo sí ibòmíràn ni gbólóhùn àse. Àpeere gbólóhùn àse ni: (18) (i) wá (ii) jókòó (iii) Dìde Gbólóhùn ni àwon wònyí sùgbón wón jo APIS lásán. Òhun tí ó selè ni pé a ti pa APOR olùwa won je. APOR olùwà ti a sì pa je ni iwo. Ohun tí a fi mò pé ìwo ni a pa je ni pé a máa n lò ó nínú gbólóhùn àkésí. (82) Ìwo, wá Àwon èrí mìíràn tí ó fi ìdí rè mule pé enikejì eyo ni a pe je ni ìwònyí. Nínú gbólóhùn alátapadà, eni nínú APOR àbò gbódò bá eni nínú APOR olùwà mu. Ìyen nip é tí APOR olùwá bá jé eni kìíní eyo, béè náà ni APOR àbò gbódò jé. Fún àpeere, ibì tí àwon gbólóhùn alátapadà (b) ti wa ni (a) (83) (a) *Òjó féràn Òjó (b) Òjó féràn ara rè (a) *Èmi féràn èmi (b) Èmi féràn ara mi Òjó àti ara rè jé eni kéta eyo. Èmi àti ara mi náà sì jé eni kìíní eyo. E jé kí á wá wo gbólóhùn àse. (84) Ìhun ìpìlè: *Ìwo gbádùn ìwo Alátapada: Ìwo gbádùn ara re Yíyo Olùwà: Gbádùn ara re Bí òfin yìí se sísé ní sísè-n-telé ni eléyìí. Èrí kejì nit i orísìí ìbéèrè kan tí a lè se lórí gbólóhùn àse. Ìbéèrè yìí fi hàn gbangba pé eni kejì eyo ni a pe je. (85) (a) Mú owó bò lóla / Sé o gbó? (b) Wá sí ilé wa o / Sé o gbó? Ìbéèrè yìí fi hàn pé èni kejì eyò ni a ń tóka sí. (16) Òté tí ó de Gbe ‘alfa’: A ti sàlàyé pé ìtumò gbé ‘alfa’ ni pé ki a gbe nǹkan tí ó bá wù wá láti ibi kan lo sí ibòmíràn. Òté wà tí ó de nǹkan ti a lè gbé. (1) A kò lè gbé òrò kankan láti inú gbólóhùn tí ó bá jé pé APOR tí o ní olórí ni ó je gàba lé e lórí. Fún àpeere, láti inú àwon àpólà tí a fa ìlà sí ní ìdí yìi, a kò lè gbé òrò kankan. (87) (i) (a) Ìròyìn pá Nàìjirià gba góòlù dùn mó mi (b) *Kí ni ìròyìn pé Nàìjíríà gbà – dùn mó mi? (ii) (a) Olú se ìlérí pé òun yóò fún un ní ìwé (b) *Kí ni Olú se – pé oun yóò fún un ní ìwé? (iii) Tí olùwà gbólóhùn bá jé gbólóhùn, a kò lè gbé nǹkan kan láti inú rè. A kò lè gbé nǹka láti inú gbólóhùn tí a fa igi sí ní ìdí wònyí. (89) (a) (i) Síse ìdáwò mérin ni ojó kan dára (ii) *Kin i síse ____ ni ojó kan dára? (b) (i) Kí á pa àgó méta wù mí (ii) Kí ni kí a pa ¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬___ wù mí? A kò lè gbé nǹkan kan láti inú àpólà tàbí gbólóhùn àso. A kò lè gbé eyo nǹkan láti inú àpólà ti a fi ìlà sí ní ìdí yìí. (91) (i) Mo ri Òjó àti Adé (ii) *Ta ni mo rí Òjó àti Adé (iii) * Ta ni mo rí _________ àti Adé? Tí a bá máa gbé nǹkan kan, méjèèjì ni a ó gbé papò. (92) Ta ni mo rí _____________?
Síńtáàsì Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2439
2439
Ṣàngó Ṣàngó Olukoso, Oko Oya. Òrìṣà Ṣàngó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òrìṣà tí àwọn Yorùbá ń bọ. Ṣàngó jẹ́ òrìsà takuntakun kan láàárín àwon òrìsà tókù ní ilẹ̀ Yorùbá. Ó jẹ́ orisà tí ìran rẹ̀ kún fún ìbẹ̀rù, Ìrísí, ìṣe àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ pàápàá kún fún ìbẹ̀rù nígbàtí ó wà láyé nítorípé ènìyàn la gbọ́ pé Ṣàngó jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí ó tó di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Ìtàn sọ wí pé ọmọ Ọ̀rányàn ni ṣàngó ń ṣe àti pé Ọya, Ọ̀ṣun àti Ọbà ni wọ́njẹ́ ìyàwó rẹ̀. Ìhùwàsí búburú ati dídá wàhalá ati ìkọlura pẹ̀lú ìjayé fàmílétè-kí-n-tutọ́ pọ̀ lọ́wọ́ ṣàngó g̣ẹ́gẹ́ bí Ọba tó bẹ́ẹ̀ títí ó fi di ọ̀tẹ́yímiká, èyí jásí wí pé tọmọdé tàgbà dìtẹ̀ mọ́ ọ. Wọ́n fi ayé ni í lára. Ó sì fi ìlú Ọ̀yọ́ sílẹ̀ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ó pokùnso sí ìdí igi àyàn kan lẹ́bà ọ̀nà nítòsí Ọ̀yọ́ nígbàtí Ọya: Ìyàwó rẹ̀ kan tókù náà sì di odò. Ọgbọ́n tí àwọn ènìyàn ṣàngó tókù dá láti fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà nípa títi iná bọlé wọn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sọ ṣàngó di òrìṣà tí wọ́n ń bọ títí dòní tí wọ́n sì ńfi ẹnu wọn túúbá wí pé ṣàngó kò so: Ọba koso. Àwọn orúkọ tí Ṣàngó ń jẹ́. Oríṣiríṣi orúkọ ni a mọ ṣàngó sí nínú èyí tí gbogbo wọn sì ní ìtumọ̀ tàbí ìdí kan pàtó ti a fi ńpè wọ́n bẹ́ẹ̀. Àwọn orúkọ bíi ìwọ̀nyìí:
Ṣàngó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2458
2458
Gírámà Yorùbá Gírámà èdè Yorùbá Gírámà ni ìmò nípa bí a ṣe ń lọ àwọn ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ètò àti ìlànà ni èdè Yorùbá Ìsòrí gírámà ni wọn yìí (a) Ọ̀rọ̀ orúkọ (b) Ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ orúkọ (d) Ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ afarajorúkọ (e) Ọ̀rọ̀ ìṣe (ẹ) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe (f) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé (g) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn (gb) Ọ̀rọ̀ àsopọ̀. Oju-iwe Kiini. Girama Yoruba Kí ni Sińtáàsì? Síńtáàsì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀ka gírámà èdè tí ó ní í sè pèlú bi a se ń so òrò pọ̀ tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Nínú ìdánilékòó yìi, a ó máa m ẹ́nu ba ohun tí a ń pè ni òfin. Ìtumò òfin gégé bí a se lò ó ni àwon ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yii yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun tí elédè sọ jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón èyí kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn lè mu emu yó ti yóò máa so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti otí bá dá ní ojú rè, yóò sọ òrò ti ó mógbón lówó. Nínú ìdánilékòó yìí, a ó ménuba ohun tí a ó pè ní ofin. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan.bí àpẹẹrẹ re, eni tí ó bá gbó Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà, (1) (a) Mo lo sí oko (b) Sí lo oko mo Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nipé ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu. O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin tíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé àtéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé àtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé. (2) (a) Àwon ti ó lo kò pò (b) Àwon ti wón lo kò pò Méjèèjì ni ó bá òfin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé àtéwógbà, èkejì kò jé àtéwógbà. Èyé kò ni nǹken kan án se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófinmu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú ìdánilékòó yìí. Ó ye kí á tún pe àkíyèsí wa sí tip é àbínibí ni èdè o. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó ọ. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àbínibí ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè, ó ti wà lára re. Kò sì si èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. (2) Òrò àti Àpólà: Òrò ti a bat ò pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b). (3) (a) Olú gíga lo (b) Olú lo Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 3. Gírámà ti a ó lò: Gírámà ìyidà onídàro ti Chomsky ni a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye. Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere: (4) GB ---> APOR APIS Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5). (5) GB ---> APOR AF APIS Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí: (6) AF ---> AS, IB, M, IBM Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS Ojú-ìwé kejì. Ayọ Bámgbóṣé Gìrámà Fonoloji ati Girama Yoruba Ayọ̀ Bámgbóṣé (1990), fonọ́lọ́jí àti Gírámà Yorùbá. Ìbàdàn, Nigeria: University Press Limited. ISBN 978 249155 1. 239 pp. Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Láti ìgbà tí Ìgbìmọ̀ Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀kọ́ (N.E.R.C.) ti gbé ìlànà ẹ̀kọ́ Yorúbá fún ìlò -ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì jáde ni ó ti di dandan láti wá ìwé tí yó ṣe àlàyé yékéyéké lórí àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ yọ nínú ìlànà ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ìrírí wa nipé àti akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ni ó máa ń ni ìṣòro lórí iṣẹ́ tí ó bá èdè yàtọ̀ sí lítíréṣọ̀. lọ Ìdí nìyí tí a fi ṣe ìwé yìí lórí èdè, tí a sì lo ìmọ̀ ẹ̀dà-èdè láti fi ṣàlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ fonọ́lọ́jì àti gíràmà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì àti ti olùkọ́ni, láìmẹ́nuba àwọn olùkọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, ni wọ́n ti ń lo ìwé Èdè Ìperí Yorùbá tí N.E.R.C. tẹ̀ jáde ní ọdún 1984, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Bámgbóṣé sì ṣe olótùú rẹ̀. ìwé Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ kejì lórí lílo èdè-ìperí Yorùbá nítorí pé a ṣe àlàyé àwọn èdè-ìperí tí ó bá ẹ̀dá-èdè lọ dáadáa; a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìtumọ̀ wọn hàn kedere. Nípa lílo ìwé yìí, èdè-ìperí á kúrò ní àkọ́sórí nìkan: kódà, á á di ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ mọ̀ dénú, tí wọ́n sì lè ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹlòmíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi tí mo ṣe Olóòtú ìwé Èdè-Ìperí Yorùbá náà ni mo kọ ìwé tuntun yìí. Mo sì kọ ọ́ ní ọ̀nà tí yó rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ láti kà nítorí pé nípa ìrírí púpọ̀ tí mo tin í nípa kíkọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀dá-èdè Yorùbá, mo mọ ọgbọ́n tí a lè fi ṣe àlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ tí ó díjú lọ́nà tí yó lè fi tètè yé ni. A dá ìwé yìí sí ọ̀nà mẹ́ta. Apá kìíni ni Fonọ́lọ́jì, Apá kejì ni Gírámà. Apá kẹta sì ni Ìdánwò Èwonìdáhùn. Nínú apé kìíní àti apá kejì, a pín àwọn orí-ọ̀rọ̀ sí abẹ́ orí kọ̀ọ̀kan nínú èyí tí a ṣe àlàyé àti ìtúpalẹ̀ orí-ọ̀rọ̀, tí a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìdí ìtúpalẹ̀ náà gúnlẹ̀ dàadáa. Lẹ́yìn èyí ni a fi ìdánrawò kádìí orí kọ̀ọ̀kan. Orí mẹ́rìnlá ni ó wà ní abẹ́ Fonọ́lọ́jì, tí méjìdínlógún sì wà lábẹ̀ Gírámà. Ó ṣeé ṣe fún olùkọ́ láti fa ẹ̀kọ́ méjì mẹ́ta yọ láti ara ori kọ̀ọ̀kan. A sì tún lè lo orí kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àtúnyẹ̀wò iṣẹ́ tí a ti ṣe kọjá lorí orí-ọ̀rọ̀. Ní apá kẹta ìwé yìí, a fi ìdánwò èwonìdáhùn mẹ́rin nínú èyí tí ìbéèrè méẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wà nínú ìkọ̀ọ̀ken ṣe àpẹẹrẹ irú ibéèrè ti a lè ṣe fún gírámà àti fonọ́lọ́jì Yorùbá. Irú àpẹẹrẹ ìdánwò báyìí yóò wúlò fún àwọn tí ó ń sẹ́ẹ̀tì ìdánwò àti fún àwọn olùkọ́ pẹ̀lú. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pàápàá yó lè lo ìdánwò yìí gẹ́gẹ́ bí àfikún fún ìdánrawò tí ó wà lẹ́yìn orí kọ̀ọ̀kan. Mo ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ láti ran ara wọn lọ́wọ́ nínú ẹ̀kó Yorùbá. Ọ̀nà tí wọ́n sì lè fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọn lo ìwé tí yó mú kí ẹ̀kọ́ Yorùbá rọrùn fún wọn láti kọ́. Ìwé tí ó lè ṣe èyí ni ìwé tuntun yìí. Ìwé náà sì lè fún wọn ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún ẹ̀kọ́ Yorùbá ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga.
Gírámà Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2462
2462
Sádíìkì Chadic (Sádíìkì) Omo ebi kan ni eleyii je fun ebi ede ile Aafirika kan ti oruko re n je Afro-Asiatic (Afuro-Esiatiiki). Awon ede ti o wa ninu Chadic yii to ogojo (160) awon ti o si n so awon ede wonyi to ogbon milionu. Awon ti o n so o bere lati iha ariwa Ghana (Gana) titi de aarin gbungbun Aafirika. Hausa ni gbajumo ju ninu awon ede ti o wa ni abe ipin Chadic. Oun nikan ni o wa ninu ipin yii ti o ni akosile ti o peye. Lara awon ede miiran ti o wa ni ipin yii a ti ri Anga, Kotoko ati Mubi.
Sádíìkì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2463
2463
Àkólì Acholi tabi Akoli jẹ́ èyà kan ní apá àríwá ilẹ̀ Uganda àti ní apá gúúsù ilẹ̀ Sudan. Èdè wọn ni Èdè Akoli.
Àkólì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2497
2497
Elédùmàrè Elédùmarè Yorùbá gbàgbọ́ wípé elédùmàrè ni ó dá ayé àti ọ̀run pẹ̀lú gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn. Yorùbá sì gbàgbọ́ wí pé kò sí ohun tí elédùmarè kò lẹ se, òhun ni wọ́n fí ń ki elédùmarè wí pé "ọba àìkú, Ọba àtíyìn, aláyé gbẹlẹgbẹlẹ bí ẹni láyin, Ọba atẹ́lẹ̀ bi ẹni tẹ́ní, Ọba atẹ́ sánmọ bí ẹni tẹ́sọ, àlọrun-làye-alàye-lọrùn, olọwọ́ gbọgbọ ti yọ ọmọ rẹ̀ nínú ọ̀fìn atẹrẹrẹ káríayé." Bí a bá ti ojú inú wò ó á ri wí pé àwọn oríkì yìí fib í olódùmarè se jẹ́ hàn láwùjọ Yorùbá. Ohun tí a ń so ni wí pé ọ̀pọ̀ ìtàn iwásẹ̀ ló sọ wípé bi olódùmarè se dá ayé àti ọ̀run. Èrò Yorùbá ni pé kọ̀ síohun ti a lẹ̀ fi wé elédùmarè nitorí àwọn àwòmọ́ tàbí àbùdá rẹ̀ tó tayọ awari ẹ̀dá. Fún àpẹẹrẹ, ẹlédàá, àlẹ̀mí, oun ló ni ọsán àti òru, ọlọ́jọ́ òní, òní ọmọ ọlọ́rin ọ̀la ọmọ ọlọ́run ọ̀tunla ọmọ ọlọrin, ìrèmi ọmọ ọlọrin, òrún ni ọmọ ọlọ́rin. Yorùbá máa ń sọ wí pé iṣẹ́ ọlọ́run tóbi tàbí àwámárídì ni iṣẹ́ olódùmarè. ọ̀rúnmìlà lọ́ fẹ̀yìntì, ó wo títítítí ó ní ẹ̀yin èrò òkun, ero ọ̀sà ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ wí pé iṣẹ́ elédùmarè tòbí. Olódùmarè gẹ́gẹ́ bí alágbaára láyé àti lọ́run a dùn ń se bí ohun tí elédùmarè lọ́wọ́ sí a sòro se bí ohun tí elédùmarè kò lọ́wọ́ sí, a lèwí lese, asèkanmákù, ohun tí Yorùbá rò nípa elédùmarè ni wí pé kò sí nǹkan tí kò le se àti wí pé ohunkíhun tí ó bá lọ́wọ́ sí ó di dandan kí ó jẹ́ àseyọrí àti àseyege. Ní ọ̀nà míràn Yorùbá tún gbàgbọ́ wí pé ọlọ́run nìkan ni ó gbọ́n, ìdí ni ìyí tí Yorùbá fi máa ń sọ ọmọ wọn ní Ọlọ́rungbọn elédùmarè rí óhun gbogbo, ó sì mọ ohun gbogbo arínúríde, olùmọ̀ràn ọkàn. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ojú ọlọ́run ni sánmọ̀ Yorùbá sọ wí pé amùokùn sìkà bí ọba ayé kòrí o, Ọba ọ̀rùn ń wò ọ́, ki ni ẹ̀ ń se ní kọ̀kọ̀ tí ojú ọba ọ̀run kò tó. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé elédùmarè ni olùdájọ́ ìyẹ ni wí pé elédùmarè ni adájọ́ tó ga jù láyé àtọ̀run, òun ni ọba adákẹ́ dájọ́, àwọn òrìṣà ló, máa ń jẹ àwọn orúfin níyà ṣùgbọ́n ọlọrun ló ń dájọ́. Bí àpẹẹrẹ ní ìgbnà kan láyé ọjọ́un àwọn òrìṣà fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú elédùmarè, lẹ́yìn tí tọ̀tún tòsì wọn rojọ́ tán elédùmarè dá ọ̀runmìlà láre. Odù ifá kan ọ báyìí wí pé Ọ̀kánjúà kìí jẹ́ kí á mọ nǹkanán-pín, adíá rún odù mẹ́rìndínlógún níjọ́ tí wọ́n ń jìjà àgbà lọ ilé elédùmarè, nìgbà tí àwọn ọmọ irúnmọlẹ̀ mẹ́rìndínlógún ń jìjà tani ẹ̀gbọ́n tan i àbúrò, wọ́n kí ẹjọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ elédùmarè, níkẹyìn elédùmarè dájọ̀ wí pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn Odù yókù. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé onídájọ́ ododo ni elédùmarè ìdí nì yí tí Yorùbá fi máa ń sọ wí pé ọlọ́run mún-un tàbí ó wa lábẹ́. Pàsán ẹlẹ́dùmarè Ní ọ̀nà míràn Yorùbá gbàgbọ́ wípé ọta àìkú ni elédùmarẹ̀ Yorùbá máa ń sọ wípé rẹ̀rẹ̀kufẹ̀ a kì í gbọ́ ikú elédùmarè. Ẹsẹ ifá kan ìyẹn ni ogbè ìyẹ̀fún sọ fún wa wí pé: - Rèròfo awo àjà ilẹ̀ Ló dífá fún elédùmarè Tí ó sọ wí pé wọn ò ní gbọ́ ikú rẹ laalaa. Ní àkótán Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ọba tó mọ́ Ọba tí je ni èérí ni elédùmarè ń se. Òun ni àwọn Yorùbá ń pè ní alálàfunfun ọ̀kàn àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé bí àwọn ángẹ́lù ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ọ̀rùn bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òrìṣà jẹ́ orùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ayé. Awọn òrìṣà wọ̀nyí sì ni wọ́n jẹ́ alágbàwí fún àwọn ènìyàn lọ́dẹ̀ elédùmarè.
Elédùmàrè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2506
2506
Àwùjọ Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Kò sí ẹ̀dá alààyè tó dá wà láì ní Olùbátan tàbí alájogbé. Orísirísi ènìyàn ló parapọ̀ di àwùjọ-bàbá, ìyá, ará, ọ̀rẹ́, olùbátan ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ìyá ṣe ń bí ọmọ, tí bàbá ń wo ọmọ àti bí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ṣe ń báni gbé, bẹ́ẹ̀ ni ìbá gbépọ̀ ẹ̀dá n gbòòrò si. Gbogbo àwọn wọ̀nyí náà ló parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. Àti ẹ̀ni tí a bá tan, àti ẹni tí a kò tan mọ́, gbogbo wa náà la parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. Ní ilẹ̀ Yorùbá ati níbi gbogbo ti ẹ̀dá ènìyàn ń gbé, ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣe pàtàkì púpọ̀. Bí ẹnìkan bá ní òun ò bá ẹnikẹ́ni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlọ. Ṣùgbọ́n, àwa ènìyàn lápapọ̀ mọ ìwúlò ìbágbépọ̀. Orísirísi àǹfàní ni ó wà nínú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá n gbé papọ̀, ó rọrùn lati jọ parapọ̀ dojú kọ ogun tàbí ọ̀tẹ́ tí ó bá fẹ́ wá láti ibikíbi. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àjòjì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù dórí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló ṣe rí fún àwùjọ-ẹ̀dá. Gbígbé papọ̀ yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbẹ̀rù dání nítorí bí òṣùṣù ọwọ̀ ṣe le láti ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwùjọ tó fohùn ṣọ̀kan. Èyí jẹ́ oun pàtàkì lára ànfàní tó wa nínú ìṣọ̀kan nínú àwùjọ-ẹ̀dá. Nídà kejì, bí ọ̀rọ̀ àwùjọ-ẹ̀dá ba jẹ́ kónkó-jabele, ẹ̀tẹ́ àti wàhálà ni ojú ọmọ ènìyàn yóó máa rí. Nítorí náà, ó dára kí ìṣọ̀kan jọba ni àwujọ-ẹ̀dá. Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjọ kò sẹ̀yìn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bí àti ránmú un gángan ò ti sẹ̀yìn èékánná. Ó yẹ kí á mò pé nítorí ìdàgbàsókè ni ẹ̀dá fi ń gbé papọ̀. Bí igi kan ò ṣe lè dágbó ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnìkan ò lè dálùúgbé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló máa ń dá Ọgbọ́n jọ fún ìdàgbàsókè ìlú. Bí Ọgbọ́n kan kò bá parí iṣẹ́, Ọgbọ́n mìíràn yóó gbè é lẹ́yìn. Níbi tí orísirísi ọgbọ́n bá ti parapọ̀, ìlọsíwájú kò ní jìnnà si irú agbègbè bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ànfàní tó wà ní àwùjọ-ẹ̀dá tí kò sì ṣe é fi sílẹ̀ láì mẹ́nu bà. Nínú ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá, a tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Kò ṣe é ṣe kó máa sì wàhálà láwùjọ ènìyàn. A kò lè ronú lọ́nà kan ṣoṣo, nítorí náà, ìjà àti asọ̀ máa ń jẹ́ àwọn nǹkan tí a kò lè ṣàì má rì í níbi ti àwọn ènìyàn bá ń gbé. Wàhálà máa ń fa ọ̀tẹ̀, ọ̀tẹ̀ ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá sòfò. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ara àwọn ìṣòro tó n kojú àwùjọ-ẹ̀dá. Kò sí bí ìlú tàbí orílè-èdè kan kò se ní ní ọ̀kan nínú àwọn àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, a gbódò mọ̀ wí pé awọn ànfàní àti awọn ìṣòro wọ̀nyí ti wà láti ìgbà pípé wá. Tí a bá wo àwọn ìtàn àtijọ gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwọn nǹkan wònyí kò jẹ́ tuntun. Ọgbọ́n ọmọ ènìyàn ni ó fi ṣe ọkọ̀ orí-ìlẹ, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rọrùn. Àwùjọ-ẹ̀dá ti ṣe àwọn nǹkan dáradára báyìí náà ni wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ó lè pa ènìyàn lára. Fún àpẹẹrẹ, ìbọn àti àdó-olóró. Àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ni wọ́n lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní Odun 1914 sí 1918 àti ti èkejì ní odún 1939 sí 1945. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ti wà tí ó sì tún wà síbè di òní. Lákòótán, ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ tó lárinrin. Ohun kan tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ nip é, kò ṣe é ṣe kí ẹ̀dá máa gbe ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ìdí ni pé gbígbé papọ̀ pẹ̀lú ìsọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló lè mú ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbà-sókè wá
Àwùjọ
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2513
2513
Edee Yoruba
Edee Yoruba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2531
2531
Ìwó Ìlú Ìwó je ilu ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni Naijiria.
Ìwó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2533
2533
Ògbómọ̀ṣọ́ Ògbómọ̀ṣọ́ jẹ́ ìlú kan tó gbajúmọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀-èdè Naijiria. ìtàn nípa Ìlú Ògbómọ̀ṣọ́. Ogunlọlá jẹ ọdẹ, ògbótari, tí ó mọ̀n nípa ọdẹẹ síse ó féràn láti máa lọ sísẹ́ Ọdẹ nínú igbó ti a máa ni ìlú Ògbómòsọ́ tí à pè ní igbó ìgbàlè, ṣùgbọ́n ọkùnrin yii ti o jẹ ogunlọlá ṣe Baale àdúgbọ̀ tí ó Ogunlọlá gbé nígbà nàá. Baale o ríi wí pe Ogunlọlá gbé àdùtú àrokò náà lọ sí ọ̀dọ̀ Aláàfin. Aláàfín àti àwọn emẹ̀wà rẹ̀ yìí àrokọ̀ náà títí, wọ́n sì mọ̀ ọ́ tì. Pẹ̀lú líhàhílo, ìfòyà, aibalẹ ọkàn nípa OGUN Ọ̀GBÒRỌ̀ tí ń bẹ ló de Ọ̀yọ́, kò mú wọn ṣe ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ Ogunlọlá, wọ́n si fi í pamọ́ si ilé olósì títí wọn yóò fi ri ìtumọ̀ sí àrokò náà. Ní ọjọ́ kan, Ogunlọlá ń sẹ ọdẹ nínú igbó ìgbàlè-àdúgbò i bi tí Gbọ̀ngàn ìlú ògbímòṣọ́ wà lonìí. Igbó yìí, igbó kìjikìji ni, ó ṣòro dojúkọ̀ kí jẹ́ pé ọdẹ ní ènìyàn, kó dà títí di ìgbà tí ojú tí là sí i bí ọdun 1935, ẹ̀rù jẹ́jẹ́ l’o tún jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú láti wọ̀ ọ́ ńitorí wí pé onírúurú àwọn ẹnranko búburú l’ó kún ibẹ̀. Àní ni ọdún 1959, ikooko já wo Ile Ògúnjẹ́ ńlé ni ìsàlè-Àfọ́n gẹ́gẹ́ bi ìròyìn, ikooko já náà jáde láti inú igbó ìgbàlè yìí ni àwọn ALÁGỌ̀ (àwọn Baálè tí wọ́n ti kú jẹ rí ní ògbómọ̀ṣọ́, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹsin-ìbílẹ̀) máà ń gbé jáde nígbà tí ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń ṣe ọdun Ọ̀LẸ̀LẸ̀. Láti pa á mọ́ gẹ́gẹ́ bi òpẹ títí di òní, nínú Gbọ̀ngàn Ògbómòṣọ́ ní àwọn Alágà náà ń ti jáde níwọ̀n ìfbà tí ó jẹ́ wí pé ara àwọn igbí ìgbàlè náà ní ó jẹ́. Ogunlọlá kó tí í tin jìnnà láti ìdí igi Àjàbon (ó wá di òní) tí ó fi ń ri èéfín. Èéfín yìí jẹ́ ohun tí ó yá à lẹ́nu nítorí kò mọ̀ wí pé iru nǹkan bẹ́ẹ̀ wà ní itòsí rẹ̀ Ogunlọlá pinnu láti tọ paṣẹ̀ èéfín náà ká má bá òpò lọ sílé Olórò, àwọn ògbójú ọdẹ náà rí ara wọn, inú swọn sí dùn wí pé àwọn jẹ pàdé. Orukọ àwọn tí wọ́n jẹ pàdé awa wọn náà ní:- AALE, OHUNSILE àti ORISATOLU. Lẹ̀yìn tí wọn ri ara wọn tan, ti wọn si mọ ara wọn; wọ́n gbìdánwò láti mọ ibi tí Olukaluku dó sí ibùdó wọn. Nínú gbogbo wọn Ogunlọla níkan l’ó ni ìyàwó. Wọ́n sì fi ìbùdó Ogunlọlá ṣe ibi inaju lẹ́yìn iṣe oojọ wọn. Lọ́rùn-ún-gbẹkun ń ṣe ẹ̀wà tà, ó sí tún ń pọn otí ká pẹ̀lú; ìdí niyìí tí o fi rọrun fún àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ Lọ́rùn-un-gbẹ́kún láti máa taku-rọ̀sọ àti lati máa bá ara wọn dámọ̀ràn. Bayíí, wọ́n fí Ogunlọla pamọ́ sí ọ̀dọ̀ Olósì. Ìtàn fi yé wa wí pé Ọba Aláàfin tí ó wà nígbà náà ni AJÁGBÓ. Rògbò dèyàn àti aápọn sì wà ní àkókò ti Ogunlọlá gbé aro ko náà lọ si Ààfin Ọba; Ogun ni, Ogun t’ó sì gbóná girigiri ni pẹ̀lú-Orúkọ Ogun ni, Ogun náà ni OGUN Ọ̀GBỌ̀RỌ̀. Nínú ilé tí a fi Ogunlọla. sí, ni ó ti ráńṣe sí Aláàfìn wí pé bí wọ́n bá le gba òun láàyè òun ní ìfẹ́ sí bí bá wọn ní pa nínú Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Ẹni tí a fi tì, pàrọwà fún Ogunlọla nítorí wí pé Ogun náà le púpọ̀ àti wí pé kò sí bí ènìyàn tilẹ́ lé è ní agbára tó tí ó le ṣégun ọlọ̀fè náà. Wọn kò lée ṣe àpèjúwe ọ̀lọ̀té náà; wọ́n sá mọ̀ wí pé ó ń pa kúkúrú, ó sí ń pa gigun ni. Aláàfin fún Ogunlọlá láṣẹ láti rán rán òun lọ́wọ́ nípa Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Aláàfín ka Ogunlọlá sí ẹni tí a fẹ́ sun jẹ, tí ó fi epọ ra ara tí o tún sún si ìdìí ààro, ó mú isẹ́ẹ sísun Yá ni. Alaafin súre fún Ogunlọlá. iré yìí ni Ogunlọla bà lé. Ogunlọlá dójú Ogun, ó pitu meje tí ọdẹ pa nínú igbo ó sẹ gudugudu meje Yààyà mẹ́fà. Àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ fi ibi ọta gunwa sí lórí igin han atamatane Ogunlọlá, Ogunlọá sì “gán-án-ní” rẹ̀. Nibi ti ọta Alaafin yìí tí ń gbiyanju láti yọ ojú síta láti ṣe àwọn jagun-jagun lọ́sé sé ọfà tó sì loro ni ọlọ̀tẹ̀ yìí ń ló; mó kẹ̀jẹ̀ ní Olọ̀tẹ̀ kò tí ì mórí bọ́ sínú tí ọrun fi yo lọ́wọ́ Ogunlọlá; lọrun ló sí ti bá Olọ̀tẹ̀; gbirigidi la gbọ to Ọlọ̀tè ré lulẹ lógìdo. Inú gbogbo àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ sì dún wọ́n yọ sẹ̀sẹ̀ bí ọmọdé tí seé yọ̀ mọ̀ ẹyẹ. Ogunlọlá o gbé e, o di ọ̀dọ̀ Aláàfin; nígbà yìí ni Aláàfin to mo wí pé Ẹlẹ́mọ̀sọ̀ ni ń ṣe alèṣà lẹ́yìn àwọn ènìyàn òun. Bayìí ni Ogunlọlá ṣe àseyorí ohun ti ó ti èrù jẹ̀jẹ̀ sí ọkan àyà àwọn ara ilu ọ̀yọ́. Aláàfin gbé Oṣiba fún Ogunlọlá fún iṣé takun-takun tí ó ṣe, o si rọ̀ ó kìí ó dúró nítòsi òun; ṣùgbọ́n Ogunlọlá bẹ̀bẹ̀ kí òun pasà sí ibùdó òun kí ó ó máa rańsẹ sí òun. Báyìí Aláàfin tú Ogunlọlá sílẹ̀ láàfín nínú ìgbèkùn tí a fii sí kò ní jẹ́ àwáwí rárá láti sọ wí pé nínú ìlàkàkà àti láálàà tí Ogunlọlá ṣe ri ẹ̀yín Ẹlẹ́mọsọ ni kò jọ́ sí pàbó tí ó sí mú orukọ ÒGBÓMỌ̀SỌ́ jade. Erédì rẹ nìyìí Gbara tí a tú Ogunlọla sílẹ̀ tán pẹ̀lu asẹ Alaafin tí ó sì padà si ibùdó rẹ̀ nì ìdí igi Àjàgbọn ni bí èrò bá ń lọ́ tí wọn ń bọ́, wọn yóò máa se àpèjuwe ibudo Ogunlọlá gẹ́gẹ́ bíí Bùdó ò-gbé-orí-Ẹlẹmọsọ; nígbà tí ó tún ṣe ó di Ògbórí-Ẹlẹmọ̀ṣọ́ kó tó wà di Ògbẹ́lẹ́mọ̀sọ́; ṣùgbọ́n lónìí pẹ̀lú Ọ̀làjú ó di ÒGBÓMỌ̀SÓ Iselu ni Ogbomoso. Baálẹ̀ ni Olórí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́. Nínú ìlànà ètò ìjọba, agbára rẹ̀ kò jut i ìgbìmọ̀ àwọn ìjòyè ìlú rẹ̀ lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti ṣe àlàyé wipe irú ètò báyìí wà láti rí pé Baálẹ̀ tàbí Ọba kò tàpá sí àwọn ìgbìmọ̀ ìjòyè kí gbogbo nǹkan lè máa lọ déédéé ni ìlú. Irú ètò yìí yàtọ púpọ̀ sí ìlànà ètò Ìjọba àwọn ìlú aláwọ̀-funfun ninú eyi ti àṣẹ láti ṣe òfin wà lọ́wọ́ ilé aṣòfin, tí ètò ìdájọ́ wà lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ ìjọba. Ẹkìínní kò gbọ́dọ yọ ẹnu sí iṣẹ́ èkejì, oníkálukú ló ni àyè tirẹ̀. Ní ti ètò ìjọba Yorùbá, Ọba atì àwọn ìjòyè ńfi àga gbá’ga ni nínú èyí tí ó jọ pé ìjà le ṣẹlẹ̀ láàrin wọn bi ọ̀kan bá tayọ díẹ̀ sí èyí. Ohun tí ó mu un yàtọ̀ ni wípé Ṣọ̀ún, baba ńlá ìdílé àwọn Baálẹ̀, dé sí ibi tí ó di Ògbómọ̀ṣọ́ lónìí lẹ́hìn tí àwọn mẹ́ta ti ṣaájú rẹ̀ dé ibẹ̀. Nipa akíkanjúu rẹ̀ ló fi gba ipò aṣíwájú lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ yókù. Akẹ́hìndé sì di ẹ̀gbọ́n lati igba yi lọ títí di òní, àwọn baálẹ ti a ti jẹ ní Ògbómọ̀ṣọ́ kò jẹ́ kí àwọn ìdílé ẹni mẹ́ta ti o ṣaáju Ṣọ̀ún dé ìlú jẹ oyè pàtàkì kan. Ẹ̀rù mbà wọ́n pé ìkan nínú àwọn ọmọ ẹni mẹ́ta yìí lè sọ wípé òun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe Olórí ìlú. Nitorina ni o fi jẹ́ pé àwọn ìjòyè ìlú tí o mbá Baálẹ̀ dámọ̀ràn láàrin àwọn ẹni tí ó dé sí ìlú lẹ́hìn Ṣọhún ní a ti yan wọ́n. Síbẹ̀ náà, Baálẹ̀ kan kò gbọdọ̀ tàpá si ìmọ̀ràn àwọn ìjòyè ìlú, pàápàá nínú àwọn ọrọ tí ó jẹ mọ iṣẹ̀dálẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì jù ní nǹkan ọgọ́rùn ọdún sí àkókò ti a ńsọ nípa rẹ̀ yìí. Àwọn ópìtàn ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ sọ pé gbogbo àwọn Baálẹ̀ ti wọn tàpá si ìmọ̀ràn ìjòyè ìlú ni Aláàfin rọ̀ lóyè. Abẹ́ Aláàfin ni Ògbómọ̀ṣọ́ wà ní ìgbà náà... Àtòjọ orúkọ àwọn olórí ìṣájú. Olùṣèdásílẹ̀ Ogbomoso ni Soun Olabanjo Ogunlola Ogundiran. Òun ni Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ̀ àkọ́kọ́. Ó ní ọmọ márùn-ún, orúkọ wọn ni, Lakale, Kekere Esuo, Eiye àti Jogioro. Ọmọ àbígbẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn Erinbaba Alamu Jogioro ló gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀, òun sì ni Sọ̀ún ẹlẹ́ẹ̀kejì. Àwọn ìdílé máràràrún tí wọ́n ṣèjọba ní Ògbómọ̀ṣọ̀ wá láti ìran àwọn ọmọ márùn-ún tí Soun Ikomeyede, èyí tó jé Sọ̀un kẹta ti Ògbómọ̀ṣọ́ (àti ọmọ Jogioro), àwon ọmọ náà ni Toyeje, Oluwusi, Baiyewu, Bolanta Adigun, àti Ogunlabi Odunaro. Oyè Soun fìgbà kan jẹ́ oyè Baale (èyí tó jẹ́ olóyè kékeré) nítorí Ògbómọ̀ṣọ̀ fìgbà kan jẹ́ ìlú kékeré láàárín Ọ̀yọ́. Ní ọdún 1952, oyè náà yí padà sí Ṣọ̀ún, ó sì jẹ́ oyè tí gbogbo ènìyàn mọ̀ títí dọ̀ní. Èyí ni àtòjọ orúkọ àwọn olórí ìṣáájú: Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, 02 of September, 2023, wọ́n yan Ṣọ̀ún ìmíì sípò, òun sì ni Prince Afolabi Ghandi Olaoye, ẹni tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde rẹ̀. Ètò-ẹ̀kọ́. Ogbomosho ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga mẹ́rin tí ń fúnní ní oyè ẹ̀kọ́ àti àmì-ẹ̀yẹ ìgbẹ̀kọ́. Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH) jẹ́ èyí tí wọ́n fi orúkọ ọmọ Ogbomosho soọrí, tí ó sì gbajúmọ̀ ní apá Ìwọ̀-oòrùnilẹ̀ Nàìjíríà, órúkọ rẹ̀ ni Samuel Ladoke Akintola (SLA). Wọ́n fi LAUTECH ṣáájú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tó gbòkè bọ̀ ní Nàìjíríà. Ó ń ṣètò oyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ science, engineering, technology àti èkọ́ ìsègùn (medicine). Ilé-ẹ̀kọ́ gíga yìí ní ilé-ìwòsàn tí wọ́n sọ ní orúkọ rẹ̀, ìyẹn Lautech Teaching Hospital. Nigerian Baptist Theological Seminary (NBTS), jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tó pè jù ní Nàìjíríà, ó sí jẹ́ ilé-èkọ́ gíga àkọ́kọ́ tí wọ́n ti gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn bíi theology, sociology àti philosophy. Ilé-ẹ̀kọ́ yìí wá̀ lábẹ́ Baptist Church in Nigeria, The Nigerian Baptist Convention (NBC), tó máa ń wáyé bákan náà ní Ibadan, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Bowen University Teaching Hospital Ogbomoso- (BUTH) tó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ tí àwọn Kìrìsìtẹ́ẹ́nì fún àwọn tó fé gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ ìṣègùn, jẹ́ èyí tí wọ́n dásílẹ̀ ní March 1907, ó sì di ilé-ẹ̀kọ́ tí wọ́n ́ kọ́ nípa ètò ìṣègún ní 2009. BUTH ní orí-ìbùsùn 400, òṣìṣẹ́ tó ju 800 lọ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, pẹ̀lú àwọn ohun àmúyẹ lóríṣiríṣi. Lára àwọn oyè ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì ń fúnni ni B.Sc. Anatomy, B.Sc. Physiology àti MB/BS. Ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ-èdẹ̀ Nàjíríà ti fòǹtẹ̀ lu ìdásílẹ̀ Federal Polytechnic, Ayede, tó wà ní ìlú kékeré kan ní Ògbómọ̀ṣọ́. Ìgbẹ̀kọ́ àti iṣẹ́-ìwádìí á tó bẹ̀rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí láìpẹ́. Bákan náà,ilé-ìwé ti ìjọba àpapọ̀ eyí tí ń ṣe Federal Government College, Ogbomosho àti Nigerian Navy Secondary School, Ogbomosho wà ní ìlú náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé aládàáni ló wà ní ìlú náà bí i Pine Valley High School, Faith Academy, Smith International Baptist Academy, Gomal Baptist College, George Green Baptist College, Zoe Schools, Maryland Catholic High School, Lautech International College, Royal International College, Zion Christian Academy, àti Command Secondary School, Gambari.
Ògbómọ̀ṣọ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2540
2540
Òmuò-Òkè-Èkìtì Ìlú Òmùò-Òkè Èkìtì jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní apá Ìlà oòrùn Èkìtì ni Òmùò òkè wà. Ìjọba ìbílẹ̀ ìlà Oòrùn ni ìpínlẹ̀ Èkìtì ni Òmùò-òkè tẹ̀dó sí. Òmùò-òkè tó kìlómítà méjìlélọ́gọ́ọ̀rin sí Adó-Èkìtì tí ó jé olú-ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì. Òmùò-òkè ni ìpínlẹ̀ Èkìtì parí sí kí a tó máa- lọ sí ìpìnlẹ̀ Kogi. Ìdí nìyí tí ó fi bá àwọn ìlú bí i, Yàgbà, Ìjùmú, Ìyàmoyè pààlà. Bákan náà ni ó tún bá Erítí Àkókó pààlà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìwádìí fihàn wí pé àwọn ìlú bí Ejurín, Ìlíṣà, Ìṣàyà, Ìgbèṣí, Àhàn, Ìlúdọ̀fin, Orújú, Ìwòrò, Ìráfún ni ó parapọ̀ di Òmùò òkè, Ọláitan àti Ọládiípò (2002:3) Iṣẹ́ òòjọ́ wọn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò ṣíṣe. Ìdí ti wọn fi ń ṣe iṣẹ́ òwò ni wí pé, Òmùò òkè ni wọn ti máa ń kò ẹrù lọ sí òkè ọya. Ẹ̀ka èdè Òmùò-òkè yàtọ̀ sí Òmùò kọta Òmùò Ọbádóore. Òmùò Èkìtì jẹ́ àpapọ̀ ìlú mẹ́ta. Èdè Òmùò-òkè farapẹ́ èdè Kàbbà, Ìgbàgún àti Yàgbàgún ni ìpinlẹ̀ Kogi. O ṣe é ṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Òmùò-òkè ló bá ìpínlẹ̀ Kogí pààlà. Bákan náà ni àwọn ènìyàn Òmùò-òkè máa ń sọ olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pàápàá àwọn tó mọ̀ọ̀kọ̀-mọ̀ọ́kà. Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀. Ìtàn àgbọ́sọ ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú Òmùò-òkè gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ni àwọn ilẹ̀ Yorùbá káàkiri. Ilé-Ifẹ̀ ni orírun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí ní Òmùò-òkè. Olúmoyà pinnu láti sá kúró ni Ifẹ̀ nítorí kò faramọ́ ìyà ti wọn fi ń jẹ́ ẹ́ ni Ifẹ̀. Kí ó tó kúró ni Ilé-Ifẹ̀, ó lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Ifá. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe yìí fihàn wí pé yóò rí àwọn àmì mẹ́ta pàtàkì kan ni ibi ti ó máa tẹ̀dó sí. Ibi tí ó ti rí àwọn àmì mẹ́ta yìí ni kí ó tẹ̀dó síbẹ̀. Àwọn àmì àmì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rìn títítí ni ó wà dé ibi ti ifá ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un. Nígbà ti ó rí odò, ó kígba pé “Omi o” ibi ni orúkọ ìlú náà “Òmùwò” ti jáde. Òmùwò yìí ni ó di Òmùò-òkè títí di òní. Olúmoyà rìn síwájú díẹ̀ kúró níbí odó yìí pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó dé ibìkan, ibi yìí ni òun àti àwọn tí ó ń tẹ̀le kọ́ ilé si. Ibi ti ó kọ́ ilé sí yìí ni ó pè ni “Ìlẹ́mọ” Orúkọ ilé yìí “Ìlẹ́mọ” wà ni Òmùò òkè títí di òní. Olúmoyà gbọ́rọ̀ sí ifá lẹ́nu, ó sọ odò náà ni “Odò-Igbó” àti ibi ti ó ti rí ẹsẹ̀ erin ni “Erínjó”. Akíkanjú àti alágbára ọkùnrin ni Olúmoyà ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ. ó kọ ilẹ òrìṣà kan tí ó pè orúkọ òrìṣà yìí ni “Ipara ẹ̀rà”. Ibi yìí ni wọn ti máa ń jáwé oyè lé ọba ìlú náà. Báyìí ni Olúmoyà di olómùwò àkọ́kọ́ ti ìlú Òmùwò tí a mọ̀ sí Òmùò-òkè ní òní. Àwọn Itọ́kasí. Ìtàn yí ò kì ńṣe ìtàn ìlú Omuo òkè ní ẹkùn rẹ rẹ. Ìlú Omuo òkè ni o jẹ ìlú kan tí wọn lé kúrò ní orí ilé tiwọn tẹ̀dó sì ni agbegbe iyagba ni Ìpínlẹ̀ Kogi. Lílé tí wọn le wọn yí ni ó ṣokùnfà bí wọn ṣe wá si'lu Omuo Ekiti nígbà náà. Èyí lomu ki wọn tán ọba tí ó wà lórí ìtẹ́ nígbà náà àti àwọn ìjòyè Omuo Ekiti. Bayi ni àwọn ìgbìmò wọ̀nyí fún àwọn ará ìyá yí ni ilẹ̀ tí o kọ́ gun sí ìlú ilamoye ni ìpínlè Kogi (ibiyi ni Omuo npeni igun {Edge}). Olomuo igbana ni o sọ fún wọn pé Omuo Oke níwọ̀n ó máa jẹ. SÍHÀBÀ ni orúkọ oyè tí Olomuo ìgbàanì fún ẹni tí yio dúró gẹ́gẹ́ bíi olórí fún wọn. Àdúgbò (Quarters) ni Omuo Oke je n'ilu Omuo. Àwọn Àdúgbo tí ó wà n'ilu Omuo Ekiti ni; Ilisa, Iworo, Ijero, Ahan, Edugbe, Ekurugbe, Omodowa, Ehuta, Ìloro, Oruju, Oya, Kota, Oda odò, Araromi, Ahan Ayegunle, Òmùò-òkè.
Òmuò-Òkè-Èkìtì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2542
2542
Èdè Yorùbá Èdè Yorùbá Ni èdè tí ó ṣàkójọpọ̀ gbogbo ọmọ káàárọ̀-oò-jíire bí, ní apá Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní Ìwọ̀-Oòrùn aláwọ̀-dúdú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ bi èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn olùsọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà ni Ìpínlẹ̀ Ẹdó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ìpínlẹ̀ Èkó, àti Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ẹ̀wẹ̀ a tún rí àwọn orílẹ̀-èdè míràn bí Tógò apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, Ghana, Sierra Leone,United Kingdom àti Trinidad, gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ. Èdè Yorùbá jẹ́ èdè kan ti ó gbalẹ̀ tí ó sì wuyì káàkiri àgbáyé. Ìtàn sọ fún wa pé ìbátan Kwa ní èdè Yorùbá jé, kwa jẹ́ ẹ̀yà kan ní apá Niger-Congo. A lè sọ pé àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lé ní Ọgbọ̀n mílíọ̀nùn tàbì jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀nà tí èdè Yorùbá pín sí. Èdè Yorùbá gbajú-gbájà ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti káàkiri àgbánlá ayé lápapọ̀. Àwọn nǹkan tí ó ń gbé èdè Yorùbá níyì tí ó fi di àrí má leè lọ àti àwòpadà sẹ́yìn nìwọ̀yín: Òwe. Òwe ni ọ̀kan lára àwọn ọnà-èdè tí àwọn Yorùbá mán ń gbà láti kó ẹwà bá ohùn ènu wọn. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni a le gbà pa òwe: (a) A le pa òwe gẹ́gẹ́ bí àwọn elédè ti ń pa á tàbí bí gbogbo ènìyàn ti ń pá gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Àíyá bẹ́ sílẹ̀ ó bé áré, (igi ọ̀ún ni kò ga). (b) À lè pa òwe dà, bí àpẹẹrẹ: Ojú kìí ti eégún kí ọmọ alágbàá ma kọrí sóko. (i) Ojú kì í ti eégún nínú aṣọ (ii) Ohun tí n tán lọdún eégún, ọmọ alágbàá a kọri sóko. 2. Akànlò èdè 3. Lílò àmìn ohùn (´-`). Ìlò-èdè Yorùbá. Lára àwọn èròngbà kan gbòógì tí ìlò èdè Yorùbá yíì ni pé mo fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ èdè Yorùbá lo dáradára nítorí náà a wo ìjúba ni awùjọ Yorùbá, a wo ààtò, Ìtúmọ̀, ìlò, àti àgbéyẹ̀wò àwọn òwe, àkànlò èdè àti ọ̀rọ̀ àmúlò mííràn. A wo èdè àmúlò nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ àti igba ti a ba kọ èdè Yorùbá silẹ. A wo ẹ̀bùn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. A sí wo ìlànà ati òté tó de sísọ̀rọ̀ ni àwùjọ Yorùbá. A wo ìwúrẹ láwùjọ Yorùbá. A wo aáyan àròkọ kikọ. Lábẹ́ àròkọ, a wo arokọ wọ̀nyí: alapejuwe, ajemọroyin, alalaye, alariiyan, ìsòròǹgbèsì, onisiipaya, ajẹmọ́-ìsonísókí-ìwé ati arokọ onileta. A wo bi a ṣe n se agbekale isẹ to da le girama, iwe atumọ, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ, àbọ̀ ìpàdé, ìjábọ̀ ìwádìí, ìwé ìkéde pélébé àti eyí ti a fi n se ìpolongo ti a máa ń tẹ̀ mọ́ ara ògiri. Èdè Yorùbá ni ibamu pẹlu asa obínibí Yorùbá. Ó yẹ kí a mọ ọ̀rọ̀ í dá sí. Ó yẹ ki a mọ ọ̀rọ̀ sọ, ki á si mọ ọ̀rọ̀ ọ́ kọ sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà ti a bá ka ìwé kékeré yìí. Bí èdè Yorùbá ṣe di kíkọ sílẹ̀. Kí àwọn òyìnbó tó gòkè odò dé, kò sí ètò kíkọ ati kíka èdè Yorùbá. Gbogbo ọ̀rọ̀ àbáláyé tí ó ti di àko sílẹ̀ lóde òní,nínú ọpọlọ́ àwọn baba ńlá wa ni wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Irú àwọn ọ̀rọ̀ àbáláyé báyìí a máa súyọ nínú orin, ewì àti ìtàn àwọn baba wa. Nígbà tí a kọ́ ń pe gbogbo àwọn ẹ̀yà tí èdè wọ́n papọ̀ yìí ní Yorùbá tàbí Yóòbá, wọn kò fi tara tara fẹ́ èyí nítorí pé àwọn ẹ̀yà Yorùbá ìyókù gbà pé àwọn Ọ̀yọ́ nìkan ni Yorùbá. Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run aláwọ̀ funfun tó wá wàásù nípa kírísítì ṣe àkiyèṣí pé èdè wọ́n bá ara wọn mu ni wọ́n bá pè wọ́n ní Yorúbà tàbí Yóòba. Àwọn Yorùbá ti a ko l’éní lo si ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí a sì wá dá padà sí sàró lẹ́hìn tí òwò ẹrú tí tán ni àwọn òyìnbó Ìjọ C.M.S. kọ́kọ́ sọ di onígbàgbọ́. Àbùdá èdè Yorùbá. Àbùdá èdè Yorùbá ni ó máa jẹ́ kí á mọ ohun tí èdè jẹ́ gan-an. Orísirísi ni àwọn àbùdá tí èdè Yorùbá ní. Èdè Yorùbá kógo àbùdá wọ̀nyí já. (1) Ohun tí a bá pè ní mi gba to aobdubdi lnfjbfi gibh knjèdè gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a fí ìró èdè gbé jáde. Ìró yìí ni a le pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa. A ó ṣe àkíyèsí pé èyí yàtọ̀ sí pípòòyì, ijó ọlọ́bọ̀ùnbọ̀un, dídún tàbí fífò tata tàbí jíjuwó alákàn sí ara wọn. (2) Èdè nílò kíkọ́ ọ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó le sọ ọ́. Ó ti di bárakú tàbí àṣà fún wa pé a gbọ́dọ̀ kọ́ ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni èdè. Àkiyèsí àti ìwádìí yìí ni àwọn eléde gẹ̀ẹ́sì ń gọ́ka sí nígbà tí àwọ́n ba sọ pé “Language is Culturally transmitted”. Ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣè bí tí a kò kọ́ ní èdè, àti àwùjọ jẹ́ kòríkòsùn. (3) Ìhun ni èdè ènìyàn gùn lé tàbí dálé. Bí a ṣe hun ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú gbólóhùn ṣe pàtàkì kíkà iye ìró èdè nínú gbólóhùn kò fi ibi kankan ní ìtúmọ̀. A lè sọ pé ìyàndá ṣubú ìyàndá ẹlẹ́mu ṣubú Ó ṣubú Ìyàndá tí a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣubú. Ìyípadà orírsirísi ló le wáyé sí gbólóhùn wọ̀nyí tí yóò sì da ètò wọn ní, síbẹ̀síbẹ̀, yóò ní ìtumọ̀. Irú àbùdá yìí ni onímọ̀ ẹ̀dá-èdè ń pè ní “Structure dependence”. (4) Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí a ń pè ní (Fóníìmù {phonemes}). Foniimu yìí sún mọ́ ti àwọn ẹranko ṣùgbọ́n ó sì tún rọ̀ jut i ẹranko lọ. Ó yàtọ̀ láti èdè kan sì òmíràn. Bí a bá mú fóníìmù yìí lọ́kọ̀ọ̀kan. kì í dá ìtumọ̀ ní kó wúlò ìgbà tí a bá kàn án pọ̀ mọ́ fóníìmù mìíràn gan-an ló máa ṣìṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ:- ìró èdè /a/ /b/ /d/ /e/ /ẹ/ kò dá ìtumọ̀ ní, àfi tí abá kàn wọ́n papọ̀ lọ́nà orísirísi. A lè se àkànpọ̀ kí á ri ọ̀rọ̀ bí : abẹ, baba, adé, alẹ́ abbl. Irúfẹ́ àkiyèsí àti ìwádìí yí ni àwọn onímọ̀ ẹ̀dà-èdè ń pe gẹ̀ẹ́sì rè ní “duality” tàbí “double articulation” ìwádìí fihàn pé àwọn ẹyẹ àti ẹranko tí wọ́n ní ìró èdè kò pò, iye èdè tí òkọ̀ọ̀kan ní kò pọ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ adìyẹ ní ìró èdè bí ogún, ti mààlúù jẹ́ mẹ́wàá ṣùgbọ́n kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ọgbọ̀n. (5) Èdè jẹ́ ohun ètò tí a máa ń lò láti ṣe àròyinlẹ̀.
Èdè Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2543
2543
Àṣà Yorùbá Àṣà Yorùbá jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà [Yorùbá] ń lò láti fi gbé èrò, ìmọ̀, àti ìṣe wọn kalẹ̀ tí ó sì bá àwùjọ wọn mu ọ́nà tí ó gun gẹ́gẹ́. Tàbí kí á sọ wípé Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn ènìyàn kan, ní àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́-ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n kó'ra jọ pọ̀ ń jẹ́ àṣà. Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá, a ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a ń mú enu bà ni ìhùwàsí àti ìrísí wa láàrín àwùjọ. Nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan pàtàkì ni' " Àṣà ìkíní" nílẹ̀ Yorùbá. Èyí jẹ́ ohun tí gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ó kú ní agbáyé fi ma ń ṣàdáyanrí ọmọ káàrọ̀-o kò-jíire bí tòótọ́ ní gbogbo ayé tí wọ́n bá dé Ẹ jẹ́ kí a jọ gbé e yèwò, kí a jọ yàn-àn-nàá rẹ̀. Ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àkọ́kọ́ ni: Àṣà ìkíni nílẹ̀ Yorùbá. Àṣà ìkíni jẹ́ àṣà tí ó gbajúgbajà nílẹ̀ Yorùbá, àṣà yí sì ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà àti àkókò. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí ó ń sẹlẹ̀ ní déédé àsìkò náà. Bí Yorùbá bá jí láàárọ̀, ọmọdé tí ó bá jẹ́ ọkùnrin, yóò wà lórí ìdọ̀bálẹ̀, nígbà tí èyí tí ó bá jẹ́ obìnrin yóò wà lórí ìkúnlẹ̀, wọn a sì kí àwọn òbí wọn tàbí ẹni tí ó bá ti jùwọ́n lọ ní gbogbo ọ̀nà, wọn á máa wípé: "Ẹ kú àárọ̀/Ẹkáàárọ̀, ẹni tí wọ́n ń kí náà á sì dá wọn lóhùn wí pé: "Káàárọ̀ ọmọ mí, ṣé dáadáa ni o jí? /aàjíırebí?" Bí ó bá jẹ́ ọ̀sán, wọn á ṣe bákannáà, wọn á sọ wí pé: "Ẹ kú ọ̀sán/Ẹkásàn-án" ẹni tí wọ́n ń kí náà á sì dá wọn lóhùn wí pé: "Kú òsán/Kásàn-án" bí ó bá jẹ́ ìgbà iṣé, "Ẹ kú iṣẹ́" ni à ń kí'ni. Bí ó sì jẹ́ àṣálẹ́, "Ẹ kú alẹ́/Ẹkáalẹ́" ni à ń kí'ni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nílẹ̀ Yorùbá, gbogbo àsìkò ni ó ní ìkíni tirẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọdé ni ó kọ́kọ́ máa ń kí àgbà. Èyí tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní wí pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀kọ́ tàbí, wọ́n kọ́ ọ ní'lé, kò gbà ni. Bí ó bá jẹ́ ìgbà ayẹ̣yẹ bíi ìsìnkú àgbà, nítorí Yorùbá kì í ṣe òkú ọ̀dọ́, ẹhìnkùnlé ni wọ́n máa ń sin òkú ọ̀dọ́ sí. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé, òfò ni ó jẹ́ fún àwọn òbí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wàyí, bí ó bá jẹ́ òkú àgbà, wọn á ní, "Ẹ kú ọ̀fọ̀, ẹ kú ìsìnkú, Olórun yóò mú ọjọ́ jìnnà sí'ra o." Bí ó bá jẹ́ ayẹyẹ Ìkómojáde/Ìsọmọlórúkọ, wọn á ní, "Ẹ kú ọwọ́lómi o." Bákan náà, oríṣiríṣì àkókò ni ó wà nínú odún. Àkókó òfìnkìn, Àkókò ọyẹ́, Àkókò oòrùn (Summer), Àkókò òjò, gbogbo wọ̀nyí sì ni àwọn Yorùbá ní bí a ṣe ń kí'ni fún. Ẹ jẹ́ kí á gbẹ́ àṣà ìsìnkú yẹ̀wò. Àṣà ìsìnkú nílẹ̀ Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú wípé ó ní àwọn òkú tí Yorùbá máa ń ṣe ayẹyẹ fún, àwọn bíi òkú àgbà, nítorí wọ́n gbà wí pé, olóògbé lọ sinmi ni, àti wí pé, wọ́n lọ'lé. Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọjà ni ayé, ṣùgbọ́n ọ̀run ni ilé. Bí ó bá jẹ́ òkú ọ̀dọ́ tàbí ọmọdé, òkú ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́ ló jẹ́. Wọ́n á gbà wí pé, àsìkò rẹ̀ kò tíì tó. Yorùbá máa ń ná owó àti ara sí ìsìnkú àgbà, pàápàá bí olóògbé náà bá jẹ́ ẹni tí ó ní ipò àti ọlá nígbà tí ó wà láyé, tí ó sì tún bí ọmọ. Ìsìnkú àwọn wọ̀nyí máa ń lárinrin, ayé á gbọ́, òrun á sì tún mọ̀ pẹ̀lú. Ní ayé àtijọ́, bí aláwo bá kú, àwọn àwọn Olúwo ní ń sìnkú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wọn á pa adìyẹ ìrànà, wọn á sì máa tu ìyẹ́ rẹ bí wọ́n ṣe ń gbé òkú rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí wọn bá sin òkú tán, àwọn aláwo náà á sun adìye náà jẹ. Ìdí rèé tí Yoòbá fi máa ń sọ wí pè, "Adìyẹ ìrànà kì í ṣ'ọhun à jẹ gbé." Nítorí pé, kò sí ẹni tí kò ní kú. Ọ̀fọ̀ ni ó máa ń jẹ́ tí ìyàwó ilé bá sáájú ọkọ rẹ̀ kú. Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọkọ ló máa ń sáájú aya rẹ̀ kú, kí ìyàwó máa bójú tó àwọn ọmọ. Fún ìdí èyí, bí okùnrin bá kú, àwọn ìyàwó irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ṣe opó pẹ̀lú ìlànà àti àṣà Yorùbá. Ogójì ọjọ́ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń fi ṣe opó. Lẹ́yìn ìsìnkú, àwọn àgbà ilé ni wọ́n máa pín ogún olóògbé fún àwọn ọmọ rẹ̀, bí ó bá jẹ́ òkú olọ́mọ. Àmọ́ tí kò bá bí’mọ, àwọn ẹbí rẹ̀, ní pátàkì jùlọ, àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ tí ó jù ú lọ ní wọ́n máa pín ogún náà láàárín ara wọn. Ó tún jẹ́ àṣà Yorùbá òmíì kí wọn máa ṣú opó olóògbé fún àwọn àbúrò rẹ̀, láti fi ṣe aya. Ohun tí ó jẹ́ orírun àṣà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú. Ìpolówó Èkìtì – iyán rere, ọbẹ̀ rere; Ìpolówó Oǹdó Ẹ̀gi – (dípò Iyán) ẹ̀bà gbọn fẹẹ. Àṣà Oǹdó ni kí wọ́n máa pe iyán ní ẹ̀bà, nítorí pé èèwọ̀ wọn ni, wọn kò gbọdọ̀ polówó iyán ní àárín ìlú. Àwọn ohun tí ó kórá jọ di àṣà. Àṣà jẹ mọ́ ìgbàgbọ́, bí àpẹẹrẹ; Olódùmarè,àbíkú, àkúdàáyà, iṣẹ́-ọnà tí a lè fojú rí tàbí fẹnu sọ. Ìsọ̀rí Àṣà. A lè pín àṣà sí ìsọ̀rí mẹ́ta, èyí tí ó jẹ mọ́: (a) Ọgbọ́n ìmọ̀, ète, tàbí ètò tí à ń gbà ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ: (b) Iṣẹ́-ọnà. Àpẹẹrẹ: (d) Bí a ṣe ń darí ìhùwàsí àwọn ẹgbẹ́ tàbí ẹ̀yà kan. Àbùdá Àṣà. Lára àbùdá àṣà ni pé: (a) Kò lè è súyọ láìsí ènìyàn, ìdí ni wípé ẹ̀mí àṣà gùn ju ti ènìyàn lọ. (b) Ó jẹ mọ́ ohun tí a lè fojú rí; (d) Àṣà kọ̀ọ̀kan ló ní ìdí kan pàtó. Àlàyé nípa Àṣà. (a) Àṣà lè jẹyọ nínú oúnjẹ: Òkèlè wọ́pọ̀ nínú oúnjẹ wa. Àkókó kúndùn ẹ̀bà, Ìlàjẹ fẹ́ràn púpurú, Igbó ọrà kìí sì í fi láfún òṣèré. (b) Àṣà lè jẹyọ nínú ìtọ́jú oyún, aláìsà,òkú; ètò ẹbí, àjọṣepọ̀; ètò ìṣàkóso àdúgbò, abúlé tàbí ara dídá nípa iṣẹ́-ọnà. Aáyẹ tí ó de bá àṣà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè abínibí wa kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. Àwọn ọ̀nà tí àṣà máa ń gbà yípadà. (a) Bí àṣà tó wà nílẹ̀ bá lágbára ju èyí tó jẹ́ tuntun lọ, èyí tó wà tẹ́lẹ̀ yóò borí tuntun. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ wíwọ̀. (b) Àyípadà lè wáyé bí àṣà tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ bá dógba pẹ̀lú àṣà tuntun, wọ́n lè jọ rìn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àṣà ìgbéyàwó. (d) Bí àṣà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, yóò sọ àṣà ti àtẹ̀hìnwá di ohun ìgbàgbé. Bí àpẹẹrẹ, bí a ṣe ń kọ́'lé. Tí a bá wá wò ó fínnífínní, à á ri wí pé, àṣà, lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà máa ń dá lé: (a) Ìmọ̀ ìṣe sáyẹ́ǹsì (b) Ìṣe jẹun wa (d) Ìsọwọ́ kọ́lé (e) Iṣẹ́ ọwọ́ ní síṣe ÀKÍYÈSI:. Èdè àwọn ènìyàn jẹ́ kókó kan pàtàkì nínú àṣà wọn. Kò sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò nínú àṣà àti èdè. Ìbejì ni wọ́n. Ọjọ́ kan náà ni wọ́n délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fẹ́ sọ nípa àṣà, tí kì í ṣe pé èdè ni a ó fi gbé e kalẹ̀. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa àṣà yọ. A lè fi èdè Yorùbá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni, a lè fi kọrin, a lè fi kéwì, a lè fi jọ́sìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láti ara àwọn nǹkan tí à ń sọ jáde lẹ́nu wọ̀nyí ni àṣà wa ti ń jẹyọ. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwọn àkànlò-èdè gbogbo wà. A lè fa púpọ̀ nínú àwọn àṣà wa yọ láti ara òwe àti àkànlò èdè. Nítorí náà, èdè ni ó jẹ́ òpómúléró fún àṣà Yorùbá. Àti wí pé, òun ni ó fà á tí ó fi jẹ́ pé, bí àwọn ọmọ Odùduwà ṣe tàn kálẹ̀, orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n, èdè kan náà ni wọ́n ń sọ níbikíbi tí wọ́n lè wà. Ìṣesí, ìhùwàsí, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀. Fún ìdí èyí, láìsí ènìyàn, kò le è sí àṣà rárá.àsà jẹ́ nnkan gbòógì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ṣùgbọ́n àwọn yorùbá mu ní ọ̀kúnkúndùn kí gbogbo wa sì gbe lárugẹ Àwọn Ìtọ́kasí. 1. Adeoye C.L. (1979) Àṣà àti iṣe Yorùbá Oxford University Press Limited 2. J.A. Atanda (1980) An introduction to Yoruba History Ibadan University Press Limited 3. Adeomola Fasiku (1995) Igbajo and its People Printed by Writers Press Limited 4. G.O. Olusanya (1983) Studies in Yorùbá History and Culture Ibadan University Press Limited. 5. Rev. Samuel Johnson (1921) The History of the Yorubas A divisional of CSS Limited.
Àṣà Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2547
2547
Ìnáwó Sé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “Se bó o ti mọ ẹlẹ́wàà sàpọ́n. Ìwọ̀n eku nìwọ̀n ìtẹ́.” Wọn a sì tún máa pa á lówe pé “ìmọ̀ ìwọ̀n ara ẹni ni ìlékè ọgbọ́n nítorí pé ohun ọwọ́ mi ò tó ma fi gọ̀gọ̀ fà á, í í já lu olúwarẹ̀ mọ́lẹ̀ ni” áyé òde òní, àwọn ọ̀dọ́ tilẹ̀ máa ń dáṣà báyìí pé “dẹ̀ẹ́dẹ̀ẹ́ rẹ, ìgbéraga ni ìgbérasán lẹ̀.” Wọ́n máa ń sọ èyí fún ẹni tí ó bá ń kọjá ààyè rẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ ọgbọ́n kan se wí pé “ni àtètékọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ wà,” bẹ́ẹ̀ náà ni ètò ti wà fún ohun gbogbo láti ìpilẹ̀sẹ̀ wá. Ètò ní í mú kóhun gbogbo rí rẹ́mú. Ọlọrun ọ̀gá ògo to da ayé. Ó fi ẹranko sígbó {àwọn olóró}. Ó tún fi ẹja síbú. Ó fi àwọn ẹyẹ kan sígbó. Ó fi àwọn mìíràn sílé. Àdìmúlà bàbá tó ju bàbá lọ tún fi ààlà sáààrin ilẹ̀, omi òkun, àti sánmọ̀. Ohun gbogbo ń lọ ní mẹ̀lọ̀-mẹ̀lọ. Bàbá dá àwa ọmọnìyàn kò fi ojú wa sí ìpàkọ́. Kò fi ẹsẹ̀ wa sórí kí orí wá wà lẹ́sẹ̀. Elétò lỌlọ́run gan-an. Kíni ètò? Ètò jẹ̣́ ọ̀nà tí à ń gbà láti sàgbékalẹ̀ ohun kan tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan lójúnà àti mú kí ó se é wò tàbí kó se é rí tàbí kó dùn ún gbọ́ sétí. A sẹ̀dá orúkọ yìí gan-an ni. Ohun tí a tò ní í jẹ́ ètò. Ẹ̀wẹ̀, ìnáwó ni ọ̀nà tàbí ìwà wa lórí bí a se ń náwó. Ohun pàtàkì ni láti sètòo bí a óò se máa ná àwọn owó tó bá wọlé fún wa. Ní àkọ́kọ́ ná, èyí yóò jẹ́ kí á mọ ìsirò oye owó tó ń wọlé fún wa yálà lọ́sẹ̀ ni o tàbí lósù, bí ó sì se lọ́dún gan-an ni. Bákan náà, yóò tún mú kó rọrùn fún wa láti mọ àwọn ọ̀nà tí owó náà ń bá lọ. Síwájú síi, ètò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti le ní ìkọ́ra-ẹni-níjàánu lórí bí a se ń náwó wa. Bí a bá ti mú ìsàkọ̀tún tán, tí a tún mú ìsàkòsì náà, ìsàkusà ni yóò kù nilẹ̀. Tí a bá yọ ti ètò kúrò nínú ojúse ìjọba pàápàá sí ará ìlú, eré ọmọdé ni ìyókù yóò jẹ́. Gbogbo àwọn ẹka ìjọba pátá-porongodo ló máa ń ní àgbẹ́kalẹ̀ ìlànà tí wọn yóò tẹ̀lé lati mọ oye owó ti wọn n reti ati eyi ti wọn óò na bóyá fún odidi ọdún kan ni o tàbí fún osù díẹ̀. Èyí ni wọ́n ǹ pé ní ‘ÈTÒ ÌSÚNÁ’ Ìdí nìyí tó fi se pàtàkì fún gbogbo tolórí-tẹlẹ́mù, tòǹga-tòǹbẹ̀rẹ̀ ki kúlukú ní ètò kan gbòógì lọ́nà bí yóò se máa náwó rẹ̀. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “eku tó bá ti ní òpó nílẹ̀, kì í si aré sá. Bí a bá ti se àlàkalẹ̀ bí a óò se náwo wa yóò dín ìnákùùná kù láwùjọ wa. Ìnáwó àbàadì pàápàá yóò sì máa gbẹ́nú ìgbẹ́ wo wá láwùjọ wa. Mo ti sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀kan nípa àwọn ẹka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀tà orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n máa ń sètò ìnáwó wọn. Àwọn wo ló tún yẹ kó máa sètò ìnáwó? Àwọn náà ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn oníṣòwò, àwọn ọmọ ilé-ìwé, níbi àsẹyẹ. Àwọn òsìsẹ́ ìjọba gbọdọ̀ sètò ìnáwó wọn kó sì gún régé. Ìdí ni pé, èyí ni yóò jẹ́ kí owó osù wọn tó í ná. Ẹni tó ń gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lósù tí kò sì fi òdiwọ̀n sí ìnáwó rẹ̀ nípa títò wọ́n lésẹẹsẹ le máa rówó sohun tó yẹ láàákò tó yẹ nígbà tí ó bá ti náwó rẹ̀ sí àwọn ohun mìíràn tó seése kó nítumọ̀ ṣùgbọ́n tí kì í se fún àkókò náà. Irú wọn á wá má ráhàn owó tósù bá ti dá sí méjì tàbí kí wọ́n jẹ gbèsè de owó osù mìíràn. Síwájú sí i, àwọn oníṣòwò gbọ́dọ̀ máa sètò to jíire lórí ìnáwó wọn. Nípa ṣíṣe èyí, wọn óò ni àǹfààní láti mọ̀ bọ́yá Ọláńrewájú ni iṣẹ́ wọn tàbí Ọláńrẹ̀yìn. Níbi tí àtúnṣe bá sì ti pọn dandan, “a kì í fòdù ọ̀yà sùn ká tó í nà án ládàá,” wọn kò nì í bèsù bẹ̀gbà, wọn óò sì se àtúnṣe ní wéréwéré. Àwọn ọmọ ilé-ìwé gan-an gbọdọ̀ mọ̀ pé ká sètò ìnáwó ẹni kì í sohun tó burúkú bí ti í wù kó mọ. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ẹ̀kó gíga, béèyàn bá gbowó fún àwọn orísirísi ìnáwó láti ilé lórí ẹ̀kọ́ ẹni, ó seése kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ná ìná-àpà tó bá dé ààrin àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀. Irú wọn ló máa ń pe ọ̀sẹ̀ tí wọ́n bá ti ilé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn dé ní ‘Ọṣẹ ìgbéraga’ Èyí kò yẹ ọmọlúàbí pàápàá. Ó sì ń pè fún àtúnṣe. Ṣíṣe ètò tó gúnmọ́ lórí ọ̀nà tí à ń gbà náwó kò pin sí àwọn ọ̀nà tí mo sàlàyé rẹ̀ sókè yìí. Mo fẹ́ kó ye wá pé a le sètò ìnáwó wa níbi àwọn orísisi ayẹyẹ bí ìsọmọlórúkọ [tàbí ìkọ́mọ́jáde], ìgbéyàwó, oyè jíjẹ, ìṣílé, àti ìsìnkú àgbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi bí a se tó hàn wá ká le mọ ohun tí a óò dágbá lé níbi irúfẹ́ àṣeyẹ tí a bá fẹ́ í ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀ a ò ní í sí nínú àwọn tó máa ń pa òwe tó máa ń mú kí wọn kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Òwe wọn ni, “rán aṣọ rẹ bí o bá se ga mọ.” Èyí tí wọn ì bá fi wí pé “rán aṣọ rẹ bí o bá se lówóo rẹ̀ sí.” Bí ẹni tó ga bá rán aṣọ rẹ̀ ní ‘bóńfò’ bó se lówó mọ ni, kò sì fẹ́ í sàsejù. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ le ti mọ̀ pé alásejù pẹ́rẹ́ ní í tẹ́. Bí a bá wá fẹ́ láti sètò ìnáwó wa, ó yẹ ká mọ̀ pé ìtòṣẹ̀ ló lỌ̀yọ̀ọ́, Oníbodè lo làààfin, ẹnìkan kì í fi kẹ̀kẹ́ síwájú ẹsin. Iwájú lojúgun í gbé. Ìnáwó tó bá ṣe kókó jùlọ tó sì ń bèèrè fún ìdásí ní kíákíá ló yẹ ká fi síwájú bí a se ń tò ó ní ẹsẹẹsẹ. Bí a bá wá kíyèsí pé ètò tí a là sílẹ̀ ti ju agbára wa lọ, ẹ jẹ́ ká fura nítorí pé akéwì kan wí pé: “Ẹ fura óò! Ẹ fura óò! Páńsá ò fura Páńsá jááná Àjà ò fura Àjá jìn Ońlè tí ò bá fura Olè ní ó ko o…”
Ìnáwó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2551
2551
Ètò ajé Eto Oro Aje Oro Aje Ajibola, Olaniyi Olabode AJIBOLA OLANIYI OLABODE ÈTỌ̀ ORO AJÉ Yorùbá tọ̀ wọ́n ní kí la ó jẹ làgba kí la ó ṣe, abálájọ tí ètò ajé fi mumú láyà gbobgo orílẹ̀ èdè àgbáyé tóó bẹ̀. Gbàrà tí ọ̀nà káràkátà oní-pà ṣí pààrọ̀ tayé ọjọ́ tun ti dotun ìgbàgbé ni ètò ajé ti dotun tó gbòòrò síwájú sí. Awọn ènìyàn wáá bẹ̀rẹ̀ síí ní lo àwọn ohun èlò bíi wúrà àti jàdákà láti máa fii se pàṣípààrọ̀ àwọn ohun tí wọ́n nílò. Eléyìí mú kí káràkátà láàrín-ín ìlú àti orílẹ̀ èdè tún gbináyá síi nígbà tí àwọn kù dìẹ̀ ku diẹ tí ń fa ìdílọ́wọ́ nínú káràkátà onípàṣípàrọ̀ ti kúrò ní bẹ̀. Tí abá kọ́kọ́ gbé ètò ayé ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú yẹ̀ wò fínní fínní, aórìí pe ohun erè oko ló jẹ́ lájorí ọrọ̀ ajé àwọn ènìyàn yìí. Àwọn erè oko wọ̀nyí ni wọ́n si ń fi ń ṣe pàṣípàrọ̀ láti tán àìní ara wọn ṣááju alábàápàbé wọn pẹ̀lú àwọn aláwọ̀ funfun. Ṣíṣa lábàápàdé àwọn aláwọ̀ funfun yìí mú kí àwọn aláwọ̀ dúdú ní àǹfàní àti ṣàmúlò àwọn ohun èlò míràn bíi: Jígí ìwojú, Iyọ̀, ọti líle àti àwọn ohun míràn bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àti ibí yìí ni wọ́n ti kọ́ àṣà lílo àwọn ohun èlò táati dárúkọ ṣáájú yìí dípò pà sí pààrọ̀ tó mú ọ̀pọ̀ wàhálà lọ́ iwọ́. kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀, ìlànà àti máa lo owó wá sí ojútáyé, tí ètò ọrọ̀ ajé sì wá búrẹ́kẹ́. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìbúrẹ́kẹ́ ọrọ̀ ajé yìí, ìyípadà díẹ̀ ló dé bá ipò ò ṣì tí àwọn aláwò dúdú yìí ti wà tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ́rí. Èyí tó pọ̀jù nínú èrè ọrọ̀ ayé ìgbà ló dé yìó lóńlọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun. Kàyéfì ńlá ló jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí tí ń pọ̀ sin i òṣì túbọ̀ ń bá àwọn aláwọ̀ dúdú fínra sí. Kàyéfì ọ̀rọ̀ yìí ò sẹ̀yìn ìwà imúni sìn adáni lóró tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí fimú àwọn gìrìpá tó yẹ kó fi gbogbo ọpọlọ àti agbára wọn ṣiṣẹ́ láti mú ayé ìrọ̀rùn wáá bá ilẹ̀ wọn àti àwọn ènìyàn wọn. Nígbà tó yẹ kí àwọn gìrìpá aláwọ̀ dúdú máa ṣiṣẹ́ idàgbàsókè ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìlẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun ni wọ́n wà tí wọ́n ń bá àwọn ènìyàn yìí ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ńlo àwọn aláwọ̀ dúdú láti tún orílẹ̀ èdè ti wọn se, àti láti pilẹ̀ ọrọ̀ ajé tó lààmì láka. Gbogbo ìgbà tí ìmúni lẹ́rú yìí n lọ lọ́wọ́, tí ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí sì ń tẹ̀ síwájú, kò sí ẹyọ iṣẹ́ ìdàgbàsókè kan ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú. Ìgbà tí ìmúnilẹ́rú dáwọ́ dúró, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ti gòkè àgbà díẹ̀ ń se ni wọ́n tún yára gba ètò ìṣàkóso ìjọba lọ́wọ́ àwọn àláwọ̀ dúdú, tí wọ́n sì sọ pé, ọ̀làjú ni àwọn fẹ́ẹ́ fi wọ àwọn aláwọ̀ dúdú yìí tí ẹ̀wù ìdí nìyí tí àwọn fi tẹ wọ́n lóríba tí àwọn sì fi pá gba ijọba wọn. Òtítọ́ tó dájú nip é, àwọn aláwọ̀ funfun yìí ríi pé ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú dára fún àwọn iṣé ọ̀gbìn erè oko kan bíi: kòkó rọ́bà, ẹ̀pà, àti kọfí èyí tí ó wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ohun èlò àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ti dá sílẹ̀. Wọ́n wá fi tì pá tì kúùkù sọ̀ ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú di oko Ọ̀gbìn àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò tí àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ti wọn. Ipò Ìṣẹ́ àti Ìmúni sìn yìí ni àwọn aláwọ̀ dúdú wà tí tí fi di ìgbà tí wọ́n sọ pé àwọn funfun wọn ní òmìnira. Ipò òṣì àti àre tí àwọn aláwọ̀ funfun fi àwọn ènìyàn yìí sí kò jẹ́ kí wọ́n ó lè dá dúró, kí wọ́n sì dáńgbájíá láti máage àwọn ohun ti wọ́n nílò ní ilé iṣẹ́ ìgbàlódé ti wọn fún raa wọn. Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ló sì wá ń dá iye owó tí ohun erè oko tó ń wá láti ilè àwọn aláwọ̀ dúdú yíò jẹ́, èyí ti ó ń túmọ̀ sí pé, ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí ni dídọ lọ́rọ̀ àti òdìkejì àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú wà. Ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí ni ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé wà, tó bá sì ṣe wùn wọ́n ni wọ́n ń lò ó. Abálájọ tó fi jẹ́ owó tí wọ́n ń ná nílùú wọn fińṣe ìdíwọ̀n pàṣípàrọ̀ ọjà ní ọjà àgbàyé. Kódà, àwọn orílẹ̀ èdè kan tó ní àwọn ohun àmúṣọrọ̀ kan tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ò fi bẹ́ẹ̀ ní, bíi epo rọ̀bì ò he è dá ohun kan ṣe lórí ohun àmúṣọrọ̀wọn yìí láì sí ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí níbẹ̀. Abálájọ tó fi ṣòro láti rí orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú kankan nínú àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà. Ọ̀wọ́ àwọn aláwọ̀ funfun ni agbára ètò ọrọ̀ ajẹ́ àgbéyé wà, àwọn ló sì ń pàṣe fún àwọn orílẹ̀ èdè tó kù ní pa ọnà tí wọn yíò gbà ṣe ìjọba àti ọ̀nà tí wọn yíò gbé ọrọ̀ ajé wọn gbà, tí wọ́n bá fẹ́ àjọ ṣepọ̀ dídán mọ́rán pẹ̀lú àwọn.
Ètò ajé
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2552
2552
Ìṣèlú Ìṣèlú tabi òṣèlú ni igbese bi awon idipo eniyan kan se n sepinnu. Oro yi je mimulo si iwuwa ninu awon ìjọba abele. ÌSÈLÚ NILE YORUBA. Ní àwùjọ Yorùbá, á ní àwọn ọ̀nà ìsèlú tiwa tí ó dá wa yàtọ̀ sí ẹ̀yà tàbí ìran mìíràn. Kí àwọn Òyìnbó tó dé ní àwa Yorùbá ti ni ètò ìsèlú tiwa tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀. Tí ó sì wà láàárin ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Yàtọ̀ sí tí àwọn ẹ̀yà bí i ti ìgbò tí ó jẹ́ wí pé àjọrò ni wọn n fi ìjọba tiwọn ṣe (acephalous) tàbí ti Hausa níbi tí àsẹ pípa wà lọ́wọ́ ẹnìkan (centralization). Ètò òsèlú Yorùbá bẹ̀rẹ̀ láti inú ilé. Eyi si fi ipá tí àwọn òbí ń kò nínú ilé ṣe ìpìlẹ̀ ètò òsèlú wa. Yorùbá bọ̀ wọn ní, “ilé là á tí kó èsọ́ ròdé”. Baba tí ó jẹ́ olórí ilé ni ó jẹ́ olùdarí àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèlú wa. Gbogbo ẹ̀kọ́ tó yẹ fún ọmọ láti inú ilé ni yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. Bí i àwọn ẹ̀kọ́ ọmọlúàbí. Tí èdèàiyèdè bá sẹlẹ̀ nínú ile, bàbá ni yóò kọ́kọ́ parí rẹ̀. tí kò bá rí i yanjú ni yóò tó gbé e lọ sí ọ̀dọ̀ mọ́gàjí agbo-ilé. Agbo-ilé ni ìdílé bíi mẹ́rin lọ sókè tó wà papọ̀ ni ojú kan náà. Wọn kó ilé wọn papọ̀ ní ààrin kan náà. Tí mógàjí bá mọ̀ ọ́n tì, ó di ọdọ olóyè àdúgbò. Olóyè yìí ni ó wà lórí àdúgbò. Àdúgbò ni àwọn agbo-ilé oríṣìíríṣìí tí ó wà papọ̀ ní ojúkan. A tún máa ń rí àwọn Baálè ìletò pàápàá tí wọ́n jẹ́ asojú fún ọba ìlú ní agbègbè wọn. Àwọn ni ọ̀pá ìsàkóso abúlé yìí wà ní ọwọ́ wọn. Ẹjọ́ tí wọn kò bá rí ojúùtú sí ni wọ́n máa ń gbé lọ sí ọdọ ọba ìlú. Ọba ni ó lágbára ju nínú àkàsọ̀ ìsàkóso ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn Yorùbá ka àwọn Ọba wọn sí òrìṣa Ìdí nìyí tí wọn fí máa ń sọ pé: Ọ̀kan tí ó lé nínú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ òkànlénú tàbí ọ̀kàn-lé-ní-rinwó (401), àwọn ọba ni. Wọn a ní. KÁBÌYÈSÍ ALÁṢẸ. ÈKEJÌ ÒRÌṢÀ. Ọba yìí ní àwọn ìjòyè tí wọn jọ ń ṣèlú. Ẹjọ́ tí ọba bá dá ni òpin. Ààfin ọba ni ilé ẹjọ́ tó ga jù. Ọba a máa dájọ́ ikú. Ọba si le è gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó tàbí ohun ìní ẹlòmíì. Wọ́n a ní: Ọba kì í mùjẹ̀ Ìyì ni ọba ń fi orí bíbẹ́ ṣe. A rí àwọn olóyè bí ìwàrèfà, ní òyọ́ ni a ti ń pè wọ́n ní Ọ̀yọ́-mèsì. Ìjòyè mẹ́fà tàbí méje ni wọn. Àwọn ni afọbajẹ. A rí àwọn ìjòyè àdúgbò tàbí abúlé pàápàá tí ó máa ń bá ọba ṣe àpérò tàbí láti jábọ̀ ìlọsíwájú agbègbè wọn fún un. A tún ń àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó ń dáàbò bo ọba àti ìlú. Àwọn ni wọn ń kojú ogun. Àwọn ni o n lọ gba isakọlẹ fọ́ba. A tún ní àwọn onífá, Babaláwo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò òsèlú wa tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ yìí ni ó mú kí ó sòro fún àwọn òyìnbọ́ láti gàba tààrà lórí wa (Indirect rule). Àwọn ọba àti ìjòyè wa náà ni wọn ń lò láti ṣèjọba lórí wa. Ó pẹ̀ díẹ̀ kí wọ́n tó rí wa wọ.
Ìṣèlú
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2556
2556
Adamawa-Ubangi
Adamawa-Ubangi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2562
2562
Mosovce
Mosovce
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2563
2563
Mošovce [[Mosofuki] Mošovce (1380 olùgbéonílùú) - pàtàkìtóbilárí [[ìletòabúlé]] nínú láarínlágbedeméjì [[Slofákíà]] pëlúàtilôdöbáfidání púpõ ti íwé itan [[ìbòjiohun ìrántí]], ati ìlú àbínibíìbí ìbí çni of a olókìkítóbiñlápö Slovak [[poet]], [[Ján Kollár]]. Gallery. Commons:Mošovce [[Ẹ̀ka:Slofákíà]]
Mošovce
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2567
2567
Èdè Abkhaz Èdè kan ni eléyìí lára àwọn èdè tí a ń pè ní Abkhazo-Adyghian tí àwọn wọ̀nyí tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ fún àkójọpọ̀ èdè tí a ń pè ní caucasian (Kọ̀kọ́síànù). Àwọn tí ó ń sọ Abkhaz tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ènìyàn ní ìpínlẹ̀ tí a ń pè ní Abkhaz ní Georgia. Ó wà lára àwọn èdè ti ìjọba ń lò níbẹ̀. Wọ́n tún ń sọ èdè yìí ní apá kan ilẹ̀ Tọ́kì (Turkey). àkọtọ́ Cyrillic (Sìríhìkì) ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀.
Èdè Abkhaz
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2576
2576
Àṣínììsì Aṣineesi Achinese (Àṣínììsì) Èdè àwọn Malayic (Maláyíìkì) kan ni eléyìí tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ fún àwọn èdè tí wọ́n ń pè ní Austronesian (èdè tí wọ́n ń sọ ní ilẹ̀ Australia, New Zealand àti Asia). Àwọn ènìyàn bú mílíonù mẹ́ta ni ó ń sọ èdè Àsíníìsì ní apá kan ilẹ̀ Sumatra àti Indonesia. Wọ́n tún máa ń pe èdè yìí ní Achehnese àti Atjehnese. Àkọtọ́ Rómáànù ni wọ́n fi ko èdè yìí sílẹ̀.
Àṣínììsì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2578
2578
Afghanístàn Afghanístàn (; Pashto/Dari: , Pashto: [avɣɒnisˈtɒn, ab-], Dari: ), àlòṣiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira Onímàle ilẹ̀ Afghanístàn, ni is a orílẹ̀-èdè onílẹ̀bodè ní Gúúsù àti Àrin Ásíà. Afghanístàn ní bodè mọ́ Pakistan ní ìlà-òrùn àti ní gúúsù; mọ́ Iran ní ìwọ̀-òrùn; mọ́ Turkmenistan, Uzbekistan, àti Tajikistan ní àríwá; àti mọ́ Ṣáínà ní àríwá-ìlàòrùn. Gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀ fẹ̀ tó , orílẹ̀-èdè olókè ní tó ní ilẹ̀ pẹpẹ ní apá àríwá àti gúúsù-ilàòrùn. Kabul ni olúìlú àti ilú tótóbijùlọ níbẹ̀. Iye aráàlú ibẹ̀ fẹ́ ẹ̀ pọ̀ tó 32 mílíọ́nù, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà àwọn Pashtun, Tajik, Hazara àti Uzbek. Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé ó wà ní ìlú yìí lé díẹ̀ ní mílíònù mọ́kànlélógún (21,017.000). Èdè tí wọ́n ń sọ ní ìlú yìí tó àádọ́ta ṣùgbọ́n ìlàjì nínú àwọn tí ó wà ní ìlú náà ni ó ń sọ páṣítọ̀ (Pashto) tí òun àti Dárì jọ jẹ èdè ìjọba (official language). Dárì (Dari) yìí nì orúkọ tí wọ́n ń pe Persian (Pásíà) ní Afuganísítàànù. Dárí yìí ṣe pàtàkì gan-an ni gẹ́gẹ́ bí èdè tí ìjọba ń lò (lingua franca). Fún ti òwò tí ó jẹ mọ gbogbo àgbáyé, èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i. Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n ń sọ ní ìlú yìí ni Tadzhik, Uzbek, Turkmen, baluchi, Brachic àti pashayi
Afghanístàn
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2579
2579
Africa
Africa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2580
2580
Èdè Gẹ̀ẹ́sì Áfríkà Amẹ́ríkà Àpèjá AAVE duro fun African-American Vernacular English, ìyẹn ni, ede Geesi tí àwọn ọmọ Afrika Amerika n so ni ile Amerika. Ọ̀kan nínú àwọn èdè àdúgbò ni. Àwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n tún ń pe èdè yìí ni Black English Vernacular (BEV), Afro-American English àti Black English. Àwọn àmì ìdámò èdè yìí ni pé wọn kì í lo ‘s’ tí ó jẹ́ àtọ́ka ẹni kẹ́ta ẹyọ, bí àpẹẹrẹ, "She walk" , wọn kìí lo be, bí àpẹẹrẹ, "They real fine". wọ́n sì máa ń lo be láti tọ́ka ibá atẹ́rẹrẹ bárakú, bí àpẹẹrẹ, "Sometime they be walking round here". A kò le so pàtò ibi tí èdè yìí ti sẹ̀. Àwọn kan sọ pé láti ara kirio ("Creole") ni ṣùgbọ́n àbùdá rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí a ń ṣe àkíyèsí rẹ̀ lára èdè Gẹ̀ẹ́si tí wọn ń sọ ní gusu Àmẹ́ríkà jẹ́ kí àwọn kan gbà pé láti ara èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ó ti wáyé. Èdè yìí wá ní àbùdá tirẹ̀ nígbà tí àwọn dúdú kọjá sí àwọn ìlú ńláńlá. wọ́n wá ń lo èdè yìí gẹ́gẹ́ bí àmì àdámọ̀ fún ara wọn. Ọmọ Afrika Amerika
Èdè Gẹ̀ẹ́sì Áfríkà Amẹ́ríkà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2581
2581
Èdè Áfríkáánì Èdè ìwọ̀ oòrùn Jámìnì (a West Germany language) tí ó wáyé láti ara Dọ́ọ̀jì (Dutuh) ni eléyìí tí wọ́n ń sọ ní Gúsù Aáfíríkà. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó míhíọ̀nù mẹ́fà. Wọ́n ń sọ ọ́ ní Nàmíbíà, màláwì, Zambia àti Zimbabwe. Àwọn kan tí ó sì ti ṣe àtìpó lọ sí ilẹ̀ Australia àti Canada náà ń sọ èdè náà. Wọ́n tún máa ń pa èdè yìí ni kéépú Dọọ̀jì (lapa Dutch). Èdè àwọn tí ó wá tẹ ilẹ̀ Gúsù Aáfíríkà dó ní ṣẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún (17th century) ni ṣùgbọ́n ó ti wá yàtọ̀ sí èdè Dọ́ọ̀jì (Dutch) ti ilẹ̀ Úroòpù (Europe) báyìí nítorí èdè àdúgbò kọ̀ọ̀kan ti ń wọ inú rẹ̀. Èdè yìí ni èdè tí ó lé ní ìdajì àwọn funfun tí ó dó sí Gúsù Aáfíríkà ń sọ. Ìdá àádọ́sà n-án àwọn tí òbí wọn jẹ́ ẹ̀yà méjì ni ó sì ń sọ èdè yìí pẹ̀lú. Láti ọdún 1925 ni wọn ti ń lo èdè yìí pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí èdè ìjọba. Èdè yìí tin í lítírésọ̀. Àkọtọ́ Rómáànù ni wọ́n fi ń kọ ọ́.
Èdè Áfríkáánì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2593
2593
Èdè Ainu Èdè Ainu Èdè kan tí ó dá dúró ní òun nìkan ni èdè yìí. A kò mọ iye ẹni tí ó ń sọ ọ ṣùgbọ́n ètò ìkànìyàn ọdún 1996 so pe márùndínlógún ni wọ́n. Hokkaido, Japan àti ní Sakhalin àti Erékùsù Kuril. Ní ìbẹ̀rẹ̀ sẹ́ńtúrì ogún, púpọ̀ núnú àwọn ohun tí ó se pàtàkì nínú èdè àti àṣa Ainu ni Jepaníìsì ti gba ipò wọn
Èdè Ainu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2594
2594
Akaanu ! style="background-color: #b0c4de" | Èdè Various Akan dialects ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀sìn Christianity, African traditional religion, Islam ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀yà abínibí bíbátan Akan Akaanu, Akan Àwọn ènìyàn bíi mílíọ̀nù méjè ni ó ń sọ èdè yìí ní pàtàkì ní orílẹ̀-èdè Ghana. Wọ́n tún ń sọ èdè yìí ní Cote d’lvoire àti Tógò. A máa ń lo Akan fún àwọn èdè tí ó fara pera wọ̀nyí Ashante, fante àti iwì tí àwọn tó ń sọ wọ́n gbọ́ ara wọn ní àgbóyé dáàyè kan ṣùgbọ́n tí wọ́n kà sí èdè òtọ̀ọ̀lọ̀ nítorí àṣà àti ọ̀nà ìgbà kọ nǹkan sílẹ̀ wọn tí kò bára mu. Èdè ìṣèjọba Àkọtọ́ Rómáànù ni wọ́n lò láti kọ ọ́ sílè.
Akaanu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2595
2595
Akadianu Akadianu Akkadian Èdè sẹ̀mítíìkì kan ni eléyìí tí wọ́n ń sọ ní ilè Mesopotámà láàárín sẹ́ńtúrù 2300 sí 500 sáájú ìbí kírísítì (c2300 to c500). A tún máa ń pe èdè yìí ní Accadian. Ìgbà mìíràn a tún máa ń pè é ní Assyro-Babylonian. A mú orúkọ tí ó gbèyìn yìí láti ara àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ̀ méjèèjì (Assyrian àti Babylonian). Èdè yìí ni ó rọ́pò Sumerian tí wọ́n ti ń sọ ní ìpínlẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀. Ẹ̀ka-èdè Babylonian ni wọ́n ti ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ìfiṣejọbí (lingua france) láti ìbẹ̀rẹ̀ pèpẹ̀ láti nǹkan bíi mìlẹ́níọ̀nù kìíní sáájú ìbí kírísítì (1st millennium B.C) ṣùgbọ́n láàárín sẹ́ńtúrì díẹ̀ èdè Aramaic ti gba ipò rẹ̀ síbẹ̀ Babylonian sì tì jẹ́ èdè tí wọ́n ń lò fún ìwé kíkọ àti kíkà tí di mìléníọ̀nù kìíní lẹ́yìn ikú kírísítì (1st Millenium A.D). Àkọtọ́ kúnífọ́ọ̀mù (Cuineform script) ni wọ́n fi kọ Akkadian sílẹ̀. Sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún (19th century) ni wọ́n tú u palẹ̀ (decipher) sí èdè tó yé tawo-tọ̀gbèrì.
Akadianu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2596
2596
Alibéníà Alibéníà ( , , Gheg Albanian: "Shqipnia"/"Shqypnia"), lonibise bi Orileominira ilẹ̀ Alibéníà (, pipe ; Gheg Albanian: "Republika e Shqipnísë"), je orile-ede ni Guusuilaorun Europe, ni agbegbe awon Balkani. O ni bode mo Montenegro ni ariwailaorun, Kosovo[a] ni riwailaorun, Orileominira ile Makedonia ni ilaorun ati Girisi ni gusu ati gusuilaorun. O ni eti-omi ni egbe Omi-okun Adriatiki ni iwoorun, ati legbe Omi-okun Ionia ni gusiiworun. O fi iye to din ni jinna si Italy, nikoja Strait of Otranto to ja Adriatic Sea po mo Ionian Sea. Albáníà je omo egbe UN, NATO, Agbajo fun Abo ati Ifowosowopo ni Europe, Igbimo ile Europe, Agbajo Owo Agbaye, Agbajo Ipade Onimale be sini omo egbe lati ibere Isokan fun Mediteraneani. Albania ti fe di omo egbe Isokan Europe lati January 2003, be sini o ti toro lati di omo egbe lati 28 April 2009. Albáníà je oseluarailu onileasofin pelu itokowo toun yipada. Oluilu Albáníà, Tirana, je ile fun awon eniyan bi 600,000 ninu awon eniyan 3,000,000 to wa lorile-ede na. Atunse oja alominira ti si orile-ede sile fun inawo idagbasoke latokere, agaga fun idagbasoke okun ati eto irinna.
Alibéníà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2598
2598
Àlgéríà Àlgéríà (Arabiki: , "al-Gazā’ir"), fun onibise Orílẹ̀-èdè Olómìnira Òṣèlú àwọn Ènìyàn ilẹ̀ Àlgéríà, je orile-ede ni Àríwá Áfríkà. Ile re ni ti orile-ede ti o tobijulo ni Okun Mediterraneani, ekeji totobijulo ni orile Áfríkà leyin Sudan, ati ikokanla totobijulo lagbaye. Àlgéríà i bode ni ariwailaorun mo pelu Tùnísíà, ni ilaorun pelu Libya, ni iwoorun pelu Moroko, ni guusuiwoorun pelu Apaiwoorun Sahara, Mauritania, ati Mali, ni guusuilaorun pelu Niger, ati ni ariwa pelu Okun Mediterraneani Sea. Titobi re fe je , be si ni iye awon eniyan re je 35,700,000 ni January 2010. The capital of Algeria is Algiers. Àlgéríà je omo egbe Iparapo awon Orile-ede, Isokan Afrika, ati OPEC. Bakanna o tun kopa ninu dida ikoenu owo Isokan Maghreb.
Àlgéríà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2600
2600
Àwọn èdè Altaic Awon ede Altaic Àkójọpọ̀ èdè tí ó tó ọgọ́ta tí nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-dínlọ́gọ́fà ènìyàn ń sọ ni a ń pè ní ‘Altaic’. Wọ́n ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí ní Penisula Balkan (Balkan Penisula) ní ìlà-oòrùn àríwá ilẹ̀ Asia. Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹgbẹ́ Turkic, Mongolian àti Manchus-Tungus. Àkọsílẹ̀ lórí ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè àwọn èdè yìí kò pọ̀. Àkọsílẹ̀ lórí Turkic wà ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹ́jọ (8th Century) ṣùgbọ́n a kọ̀ mọ nǹkan kan nípa Mongolian ṣáájú sẹ́ńtúrì kẹtàlá (13th Century). Ó tó sẹ́ńtúrì kẹtàdúnlógún (17th Century) kí a tó rí àkọsílẹ̀ kanka nípa Manchu. Ní sẹ́ńtúrì ogún (20th Century), ìgbìyànjú tó ga wáyé láti sọ àwọn èdè yìí di èdè òde òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí ó wuyì ni ó ń jáde tí a fi àwọn èdè àdúgbò kọ, bí àpẹẹrẹ, Uzbek. Wọ́n tún ṣe àtúnse sí àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀, bí àpẹẹrẹ Turkish
Àwọn èdè Altaic
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2603
2603
Sàmóà Amẹ́ríkà Orílẹ̀-èdè kan ni ó ń jẹ́ American Samoa. Ètò ìkànìyàn 1995 sọ pé àwọn ènìyàn ibè jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ojójì ó lé mẹ́ta (43, 000). Èdè Gèésì ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba. Ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ibẹ̀ ni ó ń sọ Samoan. Àwọn kan tún ń sọ Tongan àti Tokelau
Sàmóà Amẹ́ríkà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2657
2657
Orúkọ Yorùbá Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn Yorùbá ń lò jákè-jádò gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Yorùbá bí Ìbíní, Tógò àti Nàìjíríà. Nípaṣe ìṣe àwọn baba ńlá baba àwọ́n Yorùbá, wọ́n ń fún ọmọ wọn lórúkọ níbi ayẹyẹ tí ó máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀jọ lẹ́yìn ìbímọ. Àwọn orúkọ àwọn ọmọ jẹ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nípa ifá dídá tí ọ̀pọ̀ Babaláwo bá dá, ṣùgbọ́n ní ayé òde-òní, orúkọ ọmọ tún lè wá láti ọ̀dọ àwọn tí ó bá ní ipò tóga nínú ẹbí pẹ̀lú bàbá, ìyá, òbí àwọn òbí méjéèjì tàbí ẹni tí ó súnmọ́ wọn gbágbá. Ìyá àti bàbá, àti alásùn-ún-mọ́ wọn lè fún ọmọ tàbí àwọn ọmọ ní orúkọ tóbá wù wọ́n. Orúkọ ọmọ sábà máa ń wá láti ọ̀dọ àwọn òbí méjéèjì ìyá àti bàbá ọmọ àti àwọn obí tó bí òbí méjéèjì yí wọ́n bí ọmọ tí wọ́n fẹ́ sọ lórúkọ. Orúkọ ìbílẹ̀ tí a dífá fún láti ọ̀dọ Babaláwo ń ṣe àfihàn òrìṣà tó ń ṣe atọ́nà ọmọ náà wá sáyé, yálà ọmọ náà jẹ́ àtúnbí oònilẹ̀ àti pé kádàrá ọmọ àti nípa ti ẹ̀mí tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí, tí ó máa ran ọmọ lọ́wọ́ láti lè jẹ́ kí ó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ayẹyẹ ìkọ̀kọ̀ àkọ́kọ́ kan tún wà fún ìyá àti bàbá ọmọ nìkan níbi tí orúkọ àti èèwọ̀ yóò ti máa jẹ́ fífún ọmọ àti òbí rẹ̀, àti àbá lórí ohun tí ọmọ náà máa nílò láti fi ṣe àṣeyọrí. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìnáwó àwùjọ tí àsè àti àríyá ti wáyé tí ẹbí àti ojúlùmọ̀ sì ti jẹ́ ìpè àwọn obí ọmọ láti wá báwọn ṣàjọyọ̀ ìbí ọmọ náà. Àròkọ àti ìwúlò orúkọ. Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun tí ènìyàn máa ń sáábà kíyèsí láàrin ọ̀sẹ̀ sáájú ayẹyẹ ìṣọmọ-lórúkọ gẹ́gẹ́ bí i àbójútó ńlá tí ó wà lórí gbígbé e lórí i yíyan orúkọ kan tí kò ní ìrísí lórí èyíkéyìí ìwà tó lòdì tàbí ìwà búburú láàrín àwùjọ̀,ní ọìgbà mííràn yíyan orúkọ tí ó ti ọ̀daràn kan tẹ́lẹ̀ fún ọmọ Yorùbá kan kìí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí èrò ọlọ́gbọ́n (gẹ́gẹ́ bí i ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èrò Yorùbá) lè mú kí ọmọ náà ó di olè tàbí ọ̀daràn lọ́jọ́ iwájú. Ìpín sí ìsọ̀rí orúkọ Yorùbá. Orúkọ àyànmọ́. Èyí ni a tún mọ̀ sí orúko àmútọ̀runwá, (orúkọ tí a gbà wí pé àti ọ̀run ni a ti gbé e wá tàbí tí a tí jẹ bọ̀ láti) àpẹẹrẹ ni Àìná, Ìgè, Òjó, Yéwándé, Abọ́ṣẹ̀dé, Taiwo, Kẹ́hìndé, Ìdòwú, Àlàbá, Babatúndé, Jọ́ọ̀ọ́dá, Ájàyí, Abíọ́nà, Dàda, ìdògbé, Yéwándé. Orúkọ àbísọ. Èyí ni (orúkọ tí a fún ọmọ ní ọjọ́ tí ań ṣàjọyọ̀ ìbí rẹ̀, yálà látẹnu àwọn òbí rẹ̀ ni tàbí àwọn alásùn-ún-mọ́ fún un) ni a tún ń pè ní orúkọ àbisọ. Èyí sábà máa ń jẹ mọ́ ipò tí ẹbí tábí àwọn òbí ọmọ náà wà ní àwùjọ. ìwọ̀nyí ni: Ọmọtáyọ̀, Ìbílọlá, Adéyínká, Ọláwùmí, Ọládọ̀tun, ìbídàpọ̀, Ọládàpọ̀, ọlárìndé, Adérónkẹ́, Ajíbọ́lá, Ìbíyẹmí, Morẹ́nikẹ́, Mojísọ́lá, Fọláwiyọ́, Ayọ̀délé, Àríyọ̀, Oyèlẹ́yẹ, Ọmọ́táyọ̀, Fadérera. Orúkọ oríkì. Àwọn orúkọ yìí ni: Àyìnlá, Àjíkẹ́, Àlàó, Àdìó, Àkànmí, Àmọ̀ó, Àríkẹ́, Àgbékẹ́, Àjìún, Àlàkẹ̀, Àwẹ̀ró, Àbẹ̀bí, Àrẹ̀mú, Àlàní, Àyìnké. Orúkọ àbíkú. Èyí ń ṣàfihàn ìmọ̀sílára àwọn Yorùbá àti ìgbàgbọ́ wọn nípa ẹ̀mí àìrì, ikú àti àkúdàáyà. Àpẹẹrẹ orúkọ àbíkú ni: Málọmọ́, Kòsọ́kọ́, Dúrósinmí, Ikúkọ̀yí, Bíòbákú, Kòkúmọ́, Ikúdàísí, Ìgbẹ́kọ̀yí, Àńdùú, Kásìmáawòó, Ọmọ́túndé, Dúrójayé, Kalẹ̀jayé. Orúkọ ìnagijẹ. Orúkọ ìnagijẹ ni orúkó tí wọ́n ma ń fúnni látàrí ìhùwà sí, ìrísí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àpẹẹrẹ ni Eyínfúnjowó, Eyínafẹ́, Ajíláran, Ajíṣafẹ́, Ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, Arikúyẹrí, Agbọ́tikúyọ̀, Awẹ́lẹ́wà, ìbàdíàrán àti bẹ̀ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Méjì nínú orúkọ àmútọ̀runwá Yorùbá tó gbajúmọ̀ jù ni Táíwò (tàbí Táyé) àti Kẹ́hìndé tí wọ́n fún àwọn ìbejì ní pàtàkì. Ó jẹ́ ìgbàgbọ́ pé àkọ́kọ́ nínú ìbejì ni Táíwò (tàbí Táyé) tí ó gbèrò láti kọ́kọ́ jáde wá sáyé láti finmú fínlẹ̀ bóyá agbègbè ibi tí wọ́n fẹ́ wọ̀ dára tàbí kò dára láti wà sínú ẹ̀. Tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn á tẹ́wọ́ gba ìkejí rẹ̀ Kẹ́hìndé (nígbà mííràn á dá kẹ́hìndé padà) kó ní kó má a bọ̀. Òmíràn pẹ̀lú ẹ̀sìn àbáláyé: àpẹẹrẹ ni Ifáṣọlá-Ifá ṣe àṣeyọrí. Ó ṣeéṣe fífún ọmọ tí wọ́n máa kọ́ gẹ́gẹ́ bí i babaláwo àti iṣẹ́ ifá máa jẹ́ kí ó dọlọ́rọ̀ àti aláṣeyọrí. Àwọn obí onígbàgbọ́ ìgbàlódé fún ìṣe kí wọ́n máa lo orúkọ àbáláyé fún pípáàrọ̀ orúkọ òrìsà fún OLÚ tàbí OLÚWA, ìtumọ̀ olúwa tàbí olúwa mi tí ó ń tọ́ka sí èròǹgbà onígbàgbọ́ nípa ỌLỌ́RUN àti Jésù kírísítì. Fún àpẹẹrẹ Olúwatiṣé-olúwa ti ṣé,àwọn òbí gbàdúrà fún ọmọ olúwa náà sì fún wọn níkan. Àwọn òbí Mùsùlùmí máa ń fẹ́ fẹ́ fún ọmọ wọn ní orúkọ Lárúbáwá nígbà mííràn pẹ̀lú pípè Yorùbá, Ràfíáh di Ràfíátù. Orúkọ ipaṣẹ̀ tún lè ṣàkàwé ipò tí ìdílé náà wà láwùjọ (àpẹẹrẹ "Adéwálé" orúkọ ìdílé ọba àtàtà) Ó tún lè ṣàkàwé iṣẹ́ abínibí ìdílé kan (àpẹẹrẹ "àgbẹ̀dẹ", àwọn Alágbẹ̀dẹ). Yorùbá tún ní oríkì irú èyí tí àwọn akọ́ríkì máa ń lò láti tẹpẹlẹ mọ́ àṣeyọrí aṣáájú ti oríṣìíríṣìí ìdílé. Oríkì tún lè jẹ́ ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀ bì i "Àdúnní"tàbí kí ó jẹ́ ẹṣẹ̀ ìwé tàbí jáǹtìrẹrẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé kì í ṣe ipa àtàtà ni ó ń kó nínú orúkọ gidi, oríkì máa ń sábà jẹ́ lílò ní ẹ̀gbẹ́ kan, ó máa ń sábà jẹ́ ohun tí gbogbogbò mọ̀ mọ̀ọ̀yàn ní àkókò kan. Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ni àwọn ará ìlú mìíràn lè dámọ̀ kódà ìdílé wọn nípa lílo oríkì okùn ìrandíran won. Iṣẹ́ kékeré ni yíyan orúkọ nísìn yìí, nítorí kò sí àkójọpọ̀ orúkọ Yorùbá tó pé. Síbẹ̀síbẹ̀ iṣẹ́ àgbéṣe titun látọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣe gbogbo orúkọ Yorùbá sí kíkọ sílẹ̀ sínú ìwé arídìí ní ti ìlànà onírúurú ọ̀nà ìgbàròyìn. Oruko Yoruba naa ni iwe yii da le. O soro nipa jije oruko, eto ikomojade, oruko amutorunwa, oruko abiso ati oruko mti won n fun abiku, iyato laarin oruko ati alaje ki o to wa fi orile pari re. Ibeere wa ni opin iwe fun idanrawo. Awon itumo awon oro ti ta koko naa si wa pelu.
Orúkọ Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2660
2660
Asiteeki-Tanoanu Asiteeki-Tanoanu Aztec-Tanoan Ẹgbẹ́ èdè kan tí ó ní ọgbọ̀n èdè nínú ni a ń pè ní Azter-Tanoan. Wọ́n ń sọ ọ ní ìwọ̀-òorùn àti gúsù ìwọ̀-oòrùn Àmẹ́ríkà (USA). Wọ́n tún ń sọ ní ìwò-oòrùn mexico. Àwọn tí ó ń sọ àwọn èdè yìí kò pọ̀. Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹgbẹ́ yìí ni Comanche, Paiute Shoshone àti Hopi. Èdè ilẹ̀ Mixico mẹ́ta ni wọ́n ń sọ jù. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni Nahuat (tí wọ́n tún ń pè ní Aztec; ó ní ẹ̀yà púpọ̀. Àwọn tí ó ń sọ wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àbọ̀ 1.4. million). Èkejì ni Tarahumar (bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì). Papágo-Pima tí ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn ń sọ ni ẹ̀kẹ́ta. Gbogbo àwọn èdè yìí ni ó ń lo àkọsílẹ̀ Rómáànù (Roman alphabet)
Asiteeki-Tanoanu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2661
2661
Àwọn Azore Azores Ètò ìkànìyàn 1995 sọ pé ẹgbẹ̀rún lónà ogójì lé ní igba ènìyàn ló ń gbé Azores. Èdè Potokí (Portuguese) ni èdè ìṣe ìjọba ibẹ̀. Wọ́n ti ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì báyìí sí i sá fún èdè ìgbafẹ́ (tourism).
Àwọn Azore
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2662
2662
Èdè Azerbaijani Èdè Azerbaijani Ọmọ ẹgbẹ́ ni èdè yìí jẹ́ fún ẹgbẹ́ èdè tí a ń pè ní Turkic. Ẹgbẹ́ èdè Turkic yìí jẹ́ ọmọ ẹbí Altaic. Àwọn tí ó ń sọ Azerbaijani tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlá ní Azerbaijan ní ibi tí wọ́n ti ń lò ó gẹ́gẹ́ bí èdè ìṣe ìjọbi. Wọ́n tún ń sọ èdè yìí ní Turkey, Syria àti Afgloanistan. Wọ́n tún máa ń pe èdè yìí ni Azeri. Àkọtọ́ Cyrillic ni wọ́n fi ń kọ ọ́ sílẹ̀ ní Azerbaijan ṣùgbọ́n àkọtọ́ Arabic ni wọ́n fi ń kọ ọ́ sílẹ̀ ní Iran. Wọ́n fi ojú èdá èdè pín wọn sí Swuthern Azerbaijani) àti Northern Azerbaijani tí mílíọ̀nù méje ènìyàn ń sọ.
Èdè Azerbaijani
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2663
2663
Azerbaijan Aserbaijan Ní ètò ìkànìyàn 1995, àwọn tí ó ń sọ èdè yìí jẹ́ mílíọ̀nù méjè àbọ̀. Òun ni ó jẹ́ èdè ìjọba fún Aserbaijani níbi tí àwọn ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ ti ń sọ ọ́. Àwọn ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Rọ́sía ni ó ń sọ èdè yìí. Àwọn èdè bú méjìlà mìíràn tún wà èyí tí Avar àti Armerican wà lára wọn.
Azerbaijan
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2664
2664
Aymara Aymara Omo egbé Quechumaran ni Aymara. Quechumaran fúnrarè náà jé omo egbé fún àwon èdè Andea-Equatorial. Àwon tí ó ń so àwon èdè wònyí lé díè ní mílíònù méjì (2.2.million). Púpò nínú àwon tí ó ń so wón wà ní Bolivia (1.8 million) ó dín díè ní mílíònù méjì. Wón tún ń so àwon èdè wònyí ní Peru àti apá kan Argentina. Àkótó Rómáànù ni wón fi ń ko ó sílè. Ní ìgbà kan rí, Aymara jé èdè kan tí ó se pàtàkì ní ààrin gbùngbùn Andes tí wón jé apá kan Énípáyà Inca (Inca Empire)
Aymara
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2665
2665
Èdè Afaaru Afaaru Avar Ọmọ ẹgbẹ́ àwọn èdè tí wọ́n ń pè ní Dagestanian ni eléyìí. Dangestanian yìí tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ fún àwọn èdè tí wọ́n ń pè ní Caucasian. Àwọn tí ó ń sọ Caucasian yìí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀tà ní Caucasus ní pàtàkì ní ìpínlẹ̀ Dagestan ní Rọ́síà àti Azerbaijan. Àkọtọ́ Cyrillic ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà ní àdúgbò yìí ni wọ́n ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí èdè ìṣèjọba. Àwọn Andi àti Dido náà wà lára àwọn ẹ̀yà tí ó ń lò wọ́n.
Èdè Afaaru
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2666
2666
Austronesian
Austronesian
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2667
2667
Ositiro-Esiatiiki Ositiro-Esiatiiki Austro-Asiatic Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹbí èdè yìí tó àádọ́sàn-án. Àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin. Gúsù ìlà-oòrùn Asia ní pàtàkì ní China àti Indonesia ni wọ́n ti ń sọ wọ́n jù. Àwọn kan sì tún ń sọ wọ́n ní apá ìwọ̀-oòrùn àríwá India àti ní Erékùsù Nicobar (Nicobar Island). Àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ẹbí èdè yìí tí ó ṣe pàtàkì ni Mon-Khmer (tí ó jẹ́ pé nínú rẹ̀ ni àwọn èdè pọ̀ sí jù), Munda àti nicobarese. Àwọn méjèèjì tó gbẹ̀yìn yìí ni wọ́n ń sọ ní ìwọ̀-oòrùn àdúgbò Mon-khmer. Láti fi ìmọ̀ ẹ̀dá èdè pín àwọn èdè yìí sòro díẹ̀ nítorí pé díẹ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó ní àkọsílẹ̀ àti pé ìbáṣepọ̀ tí ó wà ní àárín àwọn ẹbí èdè yìí àti àwọn ẹbí èdè mìíràn kò yé èèyàn tó.
Ositiro-Esiatiiki
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2668
2668
Austria
Austria
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2669
2669
Austrálíà Austrálíà (, or ), fun ibise bi Orílẹ̀-èdè Àjọni ilẹ̀ Austrálíà, je orile-ede ni Southern Hemisphere to ni gbogbo ile orile Ostralia (to kere julo laye), erekusu Tasmania, ati opolopo awon erekusu kekeke ni inu okun India ati Pasifiki.N4 Awon orile-ede to ni bode pelu ni Indonesia, East Timor, ati Papua New Guinea ni ariwa, Solomon Islands, Vanuatu, ati New Caledonia ni ariwa-ilaorun, ati New Zealand ni guusuilaorun.
Austrálíà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2670
2670
Australian Osirelianu Austrolian Austrolian ni a orúkọ fún ẹgbẹ́ àwọn èdè kan tí àwọn aborigine ń sọ. Àwọn èdè yìí fi bí obọ̀n lé ní igba (230) síbè àwọn tí ó ń sọ wọ́n kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n lọ. Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹbí bí ọgbọ̀n ó dún méjì nítorí wí pé wọ́n ní wọ́n bá ara wọn tan. Gbogbo àwọn èdè wọ̀nyí, yàtọ̀ sí ọ̀kan nínú wọn ni ó wà ní àríwá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Australia àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá (Northern Territory) àti Queensland. Gbogbo ilẹ̀ tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kò ju ìdá mẹ́jọ ilẹ̀ Austrolia lọ. Ṣùgbọ́n èdè tí a ń pe ẹbí rẹ̀ ní Pama-Nyunga ni ó gba gbogbo ilẹ̀ yòókú ní Austrolia. Àwọn èdè tí ó wà nínú ebí yìí tó àádọ́ta tí àwọn ènìyàn sì ń lò wọ́n dáadáa. Àwọn èdè tí àwọn ènìyàn ń sọ jù ni twi, Wapiri, Aranda, Mabuyng àti Western Desert. Àwọn tí ó ń sọ òkọ̀ọ̀kan wọn lé tàbí kí ó dún díẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún. Láti nǹkan búséńtúrì kejìdúnlógún àwọn èdè tí ó ní àwọn tí ó ń sọ wọ́n ti ń dínkù jọjọ. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó sẹ́kì yìí ti ń parẹ́. Kò sí ẹni tí ó lè sọ bí ọjọ́ iwájú àwọn èdè aborigine yìí yóò ṣe rí ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti ń ṣiṣẹ́ gidigidi lórí wọn báyìí láti nǹkan bí ọdún 1960 tí àwọn kan ti dìde láti jà fún fífún gbogbo ènìyàn ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin. Púpọ̀ nínú àwọn èdè wọ̀nyí ni ó ti ń ní àkọsílẹ̀ tí wọ́n fi àkọtọ́ Rómáànù (Roman alphabet) kọ. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ sì ti ń lo èdè méjì., èdè mìíràn àti èdè mìíràn.
Australian
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2673
2673
Ẹ̀sìn Islam Ẹ̀sìn Ìmàle tabi Ẹ̀sìn Islàm (Lárúbáwá: ‎ "al-’islām," ]) jẹ́ ẹ̀sìn àlááfíà,ìrọ̀rùn àti ìjupá-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́run aṣẹ̀dá gbogbo ayé nípa ṣ́iṣe ìfẹ́ àti títèlé àṣẹ rẹ̀ yálà o tẹ́ ọ lọ́rùn tàbí kò tẹ́ ọ lọ́rùn. Ó tún jẹ́ ẹ̀sin tí Ọlọ́run tún fi ránṣẹ́ sí gbogbo ayé látọwọ́ àwọn òjíṣ̣́e rẹ̀ tó ti rán wá ṣáájú ànọ́bì Muhammad ọmọ Abdullah (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun ó ma bá a). Òun sì ni ẹ̀sìn òtítọ tí ẹ̀sìn mìíràn kò lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gb̀a ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun (Allah) yàtò sí òun nìkan. Ọlọ́hun (Allah) sì ti ṣe é ní ẹ̀sìn ìrọ̀rùn tí kò sí ìṣòro kankan tàbí wàhálà níbẹ̀. Kò si ohun tí ó kọjá agbára wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìjẹni nípá fún àwọn tí wọ́n gba èsìn náà. Bẹ́è sì tún ni ẹ̀sìn náà kò la ohun tí ó kọjá agbára wọn bọ̀ wọ́n lọ́rùn. Ìsìlámù ni ẹ̀sìn tí ó ṣe pé ìmọ̀-Ọlọ́hun ni (al- Taoheed) ní ìpìl̀ẹ rè, òdodo ni òpó rẹ̀, ó dá lórí déédé,otito. Òhun sì ni ẹ̀sìn tí ó gbópọn tí ó jẹ́ pé ó ń darí gbogbo ẹ̀dá sí ibi gbogbo ohun tí yó̀o jẹ́ ànfààní fún wọn ní ọ̀run àti ayé wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì tún ń kì wọ́n nílọ̀ nípa gbogbo ohun tí yó̀o ṣaburú fún wọn yálà láyé ni tàbí ọ̀run. Òhun ni ẹ̀sìn tí Ọlọ́hun (Allah) fi ṣe àtúnṣe àwọn àdì-ọ́kàn àti àwọn ìwà àìdáa kan. Òhun náà ni Ó fi ṣe àtúnṣe ìsẹ̀mí ayé àti ti ọ̀run. Òun ni Ọlọ́hun (Allah) fi ṣe ìrẹ́pọ̀ láàrin àwọn ọkàn tí ó kẹ̀yìn sí ara wọn àti àwọn ojúkòkòrò tí ó fọ́nká. Nípasẹ̀ èyí ni Ó fi yọ àwọn ohun tí a kà sí iwájú yìí nínú òkùnkùn biribiri ìró, tí Ó sì ṣe ìfinimọ̀nà rẹ̀ lọ sí ibi òtítọ́, tí Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà lọ sí ibi ọ̀nà tí ó yè kooro. Ẹ̀sìn Islam Ní Ṣókí. ISLAM ni esin ti o duro to, eyi ti a gbe kale ni ona ti o dara de opin ninu gbogbo awon iro ti o muwa ati ninu gbogbo awon idajo re pata.Ko si iroyin kankan ninu re ayafi otito ati ododo be e si ni ko si idajo kankan ninu re ayafi rere ati deede. Ninu re ni a o ti ri awon adisokan ti o ni alaafia, awon ise ti o duro to ,awon iwa ti o dara pari pelu awon eko ti o ye kooro.. Ni soki, ise ISLAM wa lati se aseyori awon ohun ti o n bo wonyii: Ni akotan, a lee rokirika awon ohun ti esin islam pe ni lo si ibe ninu awon koko ti o n bo wonyii: IKINNI: Adisokan (akiidah). Eleyin da lori igbagbo pelu awon origun igbagbo mefeefa: (1) Gbigba Olohun (Allah) gbo. Eyi le e je be e pelu awon nikan ti o n bo wonyii: (2) Nini igbagbo ninu awon molaaika. Awon molaaika ni awon eru Olohun kan ti won je eni aponle gegebi won ti je eda Olohun (Allah). Bakannaa, won je oluse ibaada (ijosin) fun Olohun de oju ami won si tun je atele ase re ni perepere. Olohun (Allah) fi awon ise (ojuse) orisirisii fun okookan won. Ninu won ni Jibiriilu eni ti a se afiti ise mimo ti o ba n waye lati odo Olohun (Allah) si odo eni ti O ba fe ninu awon anabi Re ati awon ojise Re ti si. Ara won si tun ni Miikailu eni ti o wa fun alaamori riro ojo ati awon koriko ti n hu. Bee naa ni ara won ni Isiraafiilu eni ti o wa fun fifon fere ni asiko ti Olohun (Allah) ba fe ki gbogbo eda o sun oorun asun- fonfon- n-tefon ti yoo kase ile aye nile ati nigba ti o ba tun fe ki won dide (lati jabo nipa igbesi aye won). Ara won si tun ni molaaika iku eni ti ojuse re je gbigba awon emi ni asiko ti Olohun (Allah) ba ti ni asiko re to. (3) Nini igbagbo si awon iwe mimo Olohun (tira). Olohun (Allah), Oba ti o tobi ti o si gbon-un -gbon julo so awon iwe kale fun awon ojise Re eyi ti ona mimo, rere ati daradara wa ninu re. Awon ti gbedeke re waye ninu awon tira yii ni wonyii: (4) Nini igbagbo si awon ojise Olohun pata laiko da enikan si. Olohun (Allah) ti ran awon ojise kan si awon eda Re. Eni akoko ninu awon ojise naa ni anabi Nuhu nigbati anabi Muhmmad (ki ike ati ola Olohun o ma a baa ati gbogbo awon ojise ti o siwaju re)si je olupinnu won. Gbogbo awon ojise Olohun pata -ti o fi mo anabi Isa- je eda abara ti ko si nkankan ninu jije Olohun ni ara won. Awon paapaa je eru Olohun (Allah) gegebi awon eda yoku naa ti je eru Olohun sugbon ti Adeda won se aponle fun won pelu riran won ni ise mimo si awon eda abara yoku. Ni akotan, Olohun (Allah) ti pari gbogbo ise ti o fe ran si aye pelu ise-imona ti o fi ran anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa).O si ti ran an si gbogbo eniyan laiko da enikan si. Nitori naa, ko si anabi kankan mo leyin anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa). (5) Nini igbagbo nipa ojo ikehin. Ojo agbehinde ni ojo ikehin ti ko ni si ojo kankan leyin ojo naa mo. Ojo naa ni Olohun (Allah) yoo gbe gbogbo eniyan dide ni aaye pada lati seku titi ayeraye ninu ile onidera (alujonna)tabi ninu ile iya (ina) atanijoni. Ninu igbagbo si ojo ikehin jasi nini igbagbo si gbogbo ohun ti yoo sele leyin iku ni eyi ti o ko ibeere (fitino) saaree ati idera pelu ijiya re sinu. Ati ohun ti yoo tun sele leyin eleyii gegebi agbehinde, iseripadabo si odo Olohun ati isiro ise ti eda gbe aye se. Leyinwa-igba-naa, ni imorile ile ibugbe ayeraye eyi ti i se alujonna tabi ina. (6) Nini igbagbo si kadara(akoole). Ohun ti oun n je kadara ni nini igbagbo pe Olohun (Allah) ni O pebubu gbogbo ohun ti n be, Ohun ni O si da gbogbo eda ni ona ti mimo Re ti siwaju re ti ariwoye Re si fe bee. Gbogbo awon alaamori ni o ti je mimo ni o si ti wa ni akoole ni odo Re. Olohun (Allah) fe gbogbo ohun ti n sele ni o je ki o maa sele bee, Oun paapaa ni o si daa. IKEJI: Awon òpó Ẹsin Imale. Esin ISLAM je ohun ti a mo lori awon origun marun kan to je pe eniyan ko lee je musulumi tooto ayafi ti o ba ni igbagbo ninu awon origun naa ti o si n se okookan ninu re. Awon origun naa ni wonyi : Ijeri. Ijeri (igba-tokantokan) pe Olohun (Allah) nikan ni Oba (ti a a josin fun) ati pe ojise Olohun ni anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) i se. Ijeri yii ni kokoro ISLAM ati ipilese re ti gbogbo eka yoku duro le lori. Itumo a i si oba miran leyin Olohun (Allah) ni pe ko si eni ti o leto pe ki a ma a se ijosin fun ju oun nikan lo.Oun nikan ni apesin tooto. Gbogbo elomiran ti a ba n dari ijosin si odo re yato si Oun je iwa ibaje ti ko si lese nile bi o ti wu ki o mo. Ohun ti o n je Olohun Oba ninu agboye awa musulumi ni eni ti a a josin fun. Itumo ijeri (ifaramo) pe anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) je ojise Olohun ni gbigba a ni ododo ninu gbogbo ohun ti o fun ni ni labare re, titele e ninu gbogbo oun ti o pa lase ati jijinna si gbogbo ohun ti o ko fun ni lati se ti o si jagbe mo a i fe be e. Irun kiki. Eyi ni awon irun ti a ma a n paara kiki re ni eemarun lojumo. Olohun (Allah) se e ni ofin lati lee je ifun Olohun ni iwo o Re lori awon eru Re, idupe fu Un lori ideraa Re ati okun idapo laarin musulumi ati Olohun Adeda re. Eyi ti yoo ma a ba A ni gbolohun ninu re ti yoo si ma a gbadura si I ninu re. Ti awon irun yii yo o si je akininlo fun un nipa sise ibaje ati sise aburu. Olohun (Allah) si ti se imudaniloju daradara esin, igunrege igbagbo ati laada aye ati ti orun fun eni ti o ba n ki irun wakati maraarun daadaa. Ni ipase awon irun yii ni ibale-okan ati ibale-ara ti yoo je okunfa orire aye ati ti orun yoo fi sele fun eni ti o ba n kii deede. Itore aanu (Saka). Eyi ni ore atinuwa kan ti eni ti o ba ni owo ti o ti wo gbedeke ti ilana ISLAM se afilele re yoo ma a san ni odoodun fun awon eni ti o leto si gbigba re ninu awon alaini ati awon miran. A ni lati mo daju gbangba pe itore aanu yi i ko je dandan fun alaini ti ko si gbedeke owo yii ni owo re. Eni ti o je dandan fun ni awon oloro ti yoo je pipe fun esin won ati ifaramo ISLAM won .Ti yoo si tun mu ilosiwaju ba iwasi won ati ihuwasi won pelu. Eyi si tun je ona kan pataki lati mu iyonusi ati iyojuran aye kuro lara won ati lara dukia won. Ati lati se afomo fun won kuro nibi aburu pelu lati se ikunlowo fun awon talaka ati awon alaini lawujo ati lati se igbeduro ohun ti yoo mu nkan tubatuse fun awon gan an alara paapaa. Paripari gbogbo re, oore aanu yii ko koja ebubu kan kinkinni ninu ohun ti Olohun (Allah) se fun won ninu owo ati ije- imu. Aawe gbigba. Eleyi yoo ma a je ohun ti yoo ma a sele ninu osu kan soso lodoodun. Osu yen si ni osu Ramadan alaponle, eyi ti se osu kesan an ninu osu odun hijira (odun ti a n fi osupa mu ka). Ninu osu yii ni gbogbo awon musulumi yoo se ara won ni osusu-owo ti won yoo si kora duro nibii kosee-mase-kosee-mato won gegebi i jije, mimu ati wiwole to aya eni ni asiko osan. Iyen ni pe kikoraduro yo o wa lati asiko idaji hai (yiyo alufajari) titi di irole pata (asiko wiwo oorun). Olohun (Allah) yoo wa a fi pipe esin won ati igbagbo ati amojukuro nibi laifi won jiro ikoraduro yii fun won. Bee si ni pipe won yoo si lekun gegebi nkan daradara miran yoo ti je tiwon ninu awon oore lantilanti ti o ti pa lese sile fun eleyii ni ile aye nihaayin ati ni orun. Irinajo si ile mimo (haji). Ohun naa ni imura giri lo si ile Olohun (Allah) Olowo lati lo josin fun Un ni asiko kan pato gegebi o tise wa ninu ilana Islam. Olohun (Allah) ti see ni oranyan fun eni ti o ba ni ikapa bee ni igba isemi ni eekan soso. Ninu asiko haji yii ni gbogbo musulumi jakejado aye yoo kojo si aaye ti o loore julo lori ile, ti gbogbo won yoo maa se ijosin fun Olohun kan soso nibe ,ti won yoo si gbe ewu orisikan - naa wo. Ko ni i si iyato laarin olori ati ara ilu, olowo aye ati mekunnu pelu funfun ati dudu ninu won. Gbogbo won yo o ma a se awon ise ijosin mimo kan ti o ti ni akosile. Eyi ti o se koko julo ninu re je kikaraduro ni aaye ti a mo si Arafa ati rirokirika ile Oluwa (Kaaba) abiyi ti o je adojuko gbogbo Musulumi ni asiko ijosin won pelu ilosoke-losodo laarin oke Safa ati Moriwa. Awon anfaani aye ati orun olokan -o - jokan ti ko se e ka tan ni o wa ninu re. IKETA : IHSAN. Eleyi tumo si pe ki Musulumi maa sin Olohun re pelu igbagbo ati esin ododo gegebi eni-wipe o n wo Olohun Adedaa lojukoroju, bi o tile je pe ire kori I dajudaju Oun n ri o. Bakanaa, ki o rii daju wipe oun se ohun kohun ni ibamu pelu ilana (Sunnah) ojise e Re; annabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun ki o baa). Bakan- naa ni ISLAM tun feto si igbesi aye awon eni ti o gba a lesin yala ni iwasi won ni eyo kookan ni o tabi nigbati won ba wa nijonijo ni ona ti oriire aye ati torun yo o fi je tiwon. Nitori idi eyi ni o fi se fife iyawo ni eto fun awon atele re ti o si se won lojukokoro lo sibe. O si se sina sise ati iwa pansaga ni eewo fun won ati awon isesi-i-laabi miran. Bee ni o si se dida ibi po ati sisaanu awon alaini ati talika ni oranyan pelu amojuto won. Gegebi o ti senilojukokoro lo si ibi gbogbo iwa to dara ti o si se e ni oranyan, bee gege ti o si kininilo nipa gbogbo iwa buruku ti o si se e ni eewo. Siwaju sii, o se kiko oro jo lona mimo gegebii owo sise tabi yiyafunnilo ati ohun ti o fara pe eleyii ni eto. Ni idakeji ewe, o se owo ele (riba) ati gbogbo owokowo ati ohun ti o ba ti ni modaru ati awuruju ninu ni eewo. Alaiye Ipari Nipa Esin Islam Ni Soki. Yato si ohun ti a ka siwaju yii, ISLAM se akiyesi aidogba awon eniyan ninu diduroto si oju ona ilana re ati siso eto awon eniyan miran. Nitori-idi-eyi ni o fi gbe awon ijiya amunisakuro-nibi-ese kale fun awon itayo -aala ti o ba waye ninu awon iwo Olohun (Allah ) Mimo; gegebii kikoomo (pipada sinu keferi leyin igba ti a ti gba ISLAM), sise sina, mimu oti ati bee bee lo.Gege bee naa ni o gbe awon ijiya adanilekun kale fun titase agere lori awon eto awon eniyan gegebii pipaayan, ole jija, piparo agbere mo elomiran, titayo aala nipa lilu elomiran tabi si see ni suta ati bee bee lo. O se pataki lati fi rinle pe awon ijiya kookan ti o fi lele yii se weku irunfin kookan la i si aseju tabi aseeto nibe. ISLAM tun seto, o si tun fi ala si ibasepo ti o wa laarin awon ara ilu ati awon adari won. O si se titele awon adari ni dandan fun awon ara ilu ninu gbogbo ohun ti ko ba si sise Olohun (Allah) ninu re. O si se yiyapa si ase won ati aigbo- aigba fun won ni eewo nitori ohun ti o le tara eyi jade ninu aapon ati rukerudo fun terutomo. Ni akotan , a le e fowogbaya re pe ISLAM ti kakoja mimo asepo ti o yanran-un-tan ati ise ti o ye kooro laarin eru Olohun (eda) ati Adeda re ni abala kan, ati laarin omo eda eniyan ati awujo ti o n gbe nibe ninu gbogbo alaamori re ni abala miran. Ko si rere kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti se ifinimona awon atele re sibe ti o si se won lojukokoro nipa diduro tii gboin -gboin. Bee si ni ko aburu kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti ki won nilo gidigidi nipa atimasunmo o ti o si ko o fun won. Eyi ni o fi wa n han wa gedegbe pe esin ti ko labujeku kankan ni ISLAM je, esin ti o si dara ni pelu ti a ba gbe yiri wo ni gbogbo ona.
Ẹ̀sìn Islam
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2708
2708
Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje Irinkerindo ninu Igbo Elegbeje ni oruko iwe ti D.O. Fagunwa ko. Ìrìnkèrindò ni ìwé ìtàn-àròsọ yìí dá lé lórí. Ìwé yìí ni D. O. Fagunwa pè ní Apá Kẹ́ta Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀. Nínú Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje, a ìbẹ̀rẹ̀ ìrììnàjò sí òkè ìrònú, alábàá pàdé ẹlẹ́gbára, ìtàn òmùgọ́diméjì àti Òmùgọ́dimẹ́ta ìtàn wèrédìran àti ìgbéyàwó Ìrìnkèrindò Irinkerindo wọle de Ojú-Ìwé 1-15. Aiyé kún fún ibùgbé ìyanu, ọba bí Ọlọ́rûn kò sí, Olódùmarè ní ńṣe alákǒso ohun gbogbo tí ńbẹ ní òde aiyé àti òde ọ̀run, ìyanu ní aiyé pàápàá jẹ́: aiyé kún fún ènìà ẹlẹ́sẹ̀ méji ati eranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin,ejò afàiyàfà àti ẹja tí ńkákìiri inú omi, ẹiyẹ tí nkọrin bí fèrè àti alágẹmọ tí Olódùmarè wọ̀ ní onírúnrú asọ.Òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, oòrùn àti òsùpá, àwọ̀sánmọ̀ àti erùpẹ̀ ilẹ̀,gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ìyanu.Bákannáà ní ọ̀rọ̀ sìsọ lásán yìí jẹ́ ìyanu, èyítí, mo sì gbọ́ ní ìjọ́sí ni mo ní kí nbá yín sọ lónǐ, ẹ̀nyin ọmọ ènìà.. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò sí òkè ìrònú tí mbẹ nínú igbó ẹlẹ́gbẹ́jẹ̀ Ojú-Ìwé 16-30. Ní òwúrọ̀ ọjọ keji, ko pẹ púpò ti mò lọ kí àlejò wà yi tán tí nóẉn fi wí fún mi pé onjẹ tí ṣetán, gbogbo wà lọ sí tábílì, a jẹun. Ìyàlẹ́nu l’o jẹ fún mi pe bi o tilẹ̀ ti jẹ́ pé nkò sọ fún púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi nípa okùnrin na tó wọnni, síbẹ̀ ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹ̀nìà l’o ti gbọ́ nípa okùnrin na, kí o sí tó di pe a jẹun àrọ̀ tán lọ́jọ́ na àwọn ẹ̀nìà tí rọ́ de ilé wa. Bí a tí jẹun tán ní mò ko àwọn ohun ìkọ̀wé jáde tí mò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, on na sí bẹ̀rẹ̀sí ọ̀rọ̀ ísọ ní: ... Alabapade ẹlẹgbara Ojú-Ìwé 31-37. “Lẹhin eyi, a kọju si ọn Igbo Elegbeje, a nlọ. A ko ri nkan abami kan ti o ṣe pataki fun ọjọ diẹ o to bi ọjọ mẹta ti a ti sin Gọngọṣutakiti ki o to dip e nkan miran tun de ba ni, bayi ni: “Bi a ti de ibi kan bayi ti o tẹju diẹ ti a duro ti a jẹun tan ni a dede gbọ ariwo ogunlọgọ awọn ọmọde ni apa ọna ibiti a nlọ ti ẉon nke bọ lapa ọdọ wa. Aiya mi ja pupọ nitori igbe yi nitori mo nbẹru ki ó má ba jẹ iwin buruku ti okiki rẹ̀ ti kan jakejado ode aiye ti a npe ni Ẹlẹgbara. Iwin buruku ni, bi ò ba nbọ awọn ọmọ rẹ̀ ti a npe ni ọmọ Ẹlẹgbara ni o ma nṣaju ti noẉn ma nkede bibọ̀ rẹ̀ fun gbogbo ohun alaye. ... Ilu awọn èdìdàrẹ́ ni ibiti omugọdimeji ti nṣe ọba wọn Ojú-Ìwé 38-48. “Nigbati a kuro ni ibiti awọn ẹranko wọnyi wà ti a tubọ rin diẹ siwaju a ri ọna kekere kan bayi ti o yà ba apa osi lọ, Nwọn kọ àkọlé kan si ìyànà na, nkan ti ẉon si kọ ni eyi: ‘Ilu awọn Èdìdàrẹ́ nibiti Omugọdimeji ti nṣe ọba wọn.’ “Akọle yi yà wa lẹnu a si yà si ọna na ki a ba lọ wo bi ibẹ ti ri. Nigbati a rin si iwaju diẹ, a bẹrẹsi wo ilu na ni ọkankan ṣugbọn ọna ti a ntọ̀ lọ tubọ ndi kekere si i afi bi ẹni pe enia ko ngbe ilu na ni, nigbati o sa pẹ ṣa, a yọ si ilu yi... Omugọdimẹta g’ori oye ṣọpọnna gbe omugọdimeji lọ Ojú-Ìwé 49-54. Ibiti alejo mi sọrọ na fun mi mọ lọjọ ti a tun nkọwe na ni eyi, a ba da ọwọ duro lọjọ na, a ki awọn ti o wa gbọ ọrọ w ape ki noẉn ma lọ sile ki nwọn tun pada lọjọ keji. Ko pẹ pupọ ti ilẹ ọjọ keji si mọ ti gbogbo enia tun fi nrọ wọ ile mi, igbati awa na si jẹun tan, alejo mi tun bẹrẹ o nba itan na lọ o ni: “Ẹnyin ọrẹ mi, ibiti mo ba irohin na de lana ni iku Omugọdimeji. ... Ẹbọra igberaga-ibanujẹ ati ahọndiwura iyawo rẹ̀ Ojú-Ìwé 55-59. “A kuro ní ilu awọn Edidarẹ lẹhin ti a ti gbe eti ibẹ fun odidi oṣu mẹta gbako, a kọ ori si ọna wa. Ẹ má jẹki eyi yà yin lẹnu pe a pẹ tobẹ̀ ni ilu kan ti a ko lọ si ibiti nwọ́n ran wa. Ọba papa ti fun wa ni aṣẹ bẹ ki a to kuro ni ile, o ti wi fun w ape bi a ba de ibikibi ti a ri i pe ohun ti a nfẹ ṣe yio gba ni to oṣu mẹfa tabi ju bẹ lọ ki a maṣe kanju, ki a ṣe e dada... A fi oju wa ri ọrun apadi Ojú-Ìwé 60-70. “Bí a ti de ibikan ti o dakẹ minimini bayi, ti igbo ibẹ di ti o dudu mirinmirin ni a ri iwin kan ti o nbọ, o dabi ọba gan, igbati a si kọ ri i, a ke ‘Kabiyesi’, a ti gbagbe pe Aginju Baba-loriṣa ni wà, bẹni ko si ibiti ẹbọra na fi yatọ si ọba. Fila ori rẹ̀ dabi ade, bata ẹsẹ rẹ̀ dabi bata ẹsẹ awọn alagbara, bẹni ẹwu ọrun rẹ̀ ko yatọ si ti ọba ti o ti gba ade lati ọwọ Oduduwa, ọpọlọpọ awọn iwin miran ni ó tẹle e, ọkan ninu awọn iwin na si gbe apoti kan le ori, o nri ù tẹle e. Igbati gbogbo awa ọdẹ dọbalẹ ti a ki iwin pataki yi, o dahun o nì... Wèrédìran ti ngbe ile òmùgọ̀parapọ̀ Ojú-Ìwé 71-75. “A kọju si ọna wa, a nlọ, a ko si ri nkankan ju bẹ lọ titi o fi di owurọ ọjọ kan bayi, ni nkan bi agogo mẹwa, ti a ri ọna kan ti o yà baa pa ọtun lọ. A ri akọle yi, o tọka si ọna na: ‘Eleyi ni ilu awọn Alaṣeju nibiti Ọba Alaiyeluwa Aláṣeté ti nṣe ọba wọn.’ “Orukọ ilu yi ko fa ni mọra, ṣugbọn bi ko ti fa ni mọra to yin a, a fẹ lati lọ mọ ibẹ, nitori a le lọ de ibẹ ki a ri ọgbọn diẹ kọ. ... Igbeyawo Irinkerindo pẹlu aburo olókun iwin inu omi Ojú-Ìwé 76-100. “Ṣugbọn kini kan ko ni ṣai ya yin lẹnu nipa emi papa ẹ kò bi mi nkan na dan? On ni wipe lati igbati a ti kuro ni ibiti Ẹlẹgbara ti le wa, ọkan mi ko kuro lara obinrin ti o ṣe itọju mi nigbati Ẹlẹgbara fi le mi kọja oke odò. Gẹ́gẹ́ bi mo ti sọ ṣaju, nko fẹran obinrin ṣaju akoko na, nwọn tilẹ nma rùn si mi ni, nko si mọ ohun ti o fa ti fifẹ ti mo dede wa fẹran obinrin na ju ti itọju mi ti o ṣe nigbana lọ, ṣugbọn ki a má sa fa a gun lọ titi, gongo ori ẹmi mi ni ọmọ na duro le, ọrọ rẹ̀ ki isi ikuro lẹnu mi tobẹ ti o jẹ pe awọn ẹnikeji mi ma nfi mi ṣe yẹ̀yẹ́ ṣa ni... Ilu itanjẹ-enia Ojú-Ìwé 101-108. “Ọpọlọpọ nkan ni a fi oju ri nigbati a kuro ni ilu yi tan ṣugbọn ko si aye nisisiyi lati sọ gbogbo wọn. Sibẹsibẹ na, nko gbọdọ ṣai sọ nkan ti o ṣẹlẹ si mi ni ilu ti a npe ni Itanjẹ-enia. “Ko si ẹniti o wà ni ode aiye yi ti ko ni agbelebu tireẹ̀ Agbelebu ki isi itilẹ fi ibi nkan rere silẹ. Mo ni agbelebu kan ninu irinajo yi, agbelebu na si ni igba kemi mi, Aiyédèrú-ẹ̀dá. Mo ro pe ẹ o ranti iru ọrọ buruku ti ó sọ niwaju Omugọdimeji ọba ilu awọn Edidarẹ, ẹ o si ṣakiyesi pe ọrọ rẹ̀ kò ju ati fi wa oju Omugọdimeji mọra lọ. ... Ogun ibode igbo elegbeje Ojú-Ìwé 109-117. “Bayi ni ọkunrin na wi, mo si nfẹ ba a sọrọ ki ntúbọ wadi nipa nkan ti o sọ, ṣugbọn, were l’ó kọja, ko duro mọ. “Igbati o ṣe, a yọ si Igbo Elegbeje. Nkan ti a kọ ṣe akiyesi ni ọwọ̀n nla kan ti ó ba oju ọrun lọ, ti ó duro ni ẹnu ọna igbo na. Igbati ó ba ṣe ti a ba wo oke ọwọ̀n yi, a dabi oju enia. Ti o bat un ṣe, a dabi oju kiniun, igbati ó tun ṣe, a dabi oju ẹkùn. Bi ó ba sit un yi pada a dabi ori ejo nla, a ma yọ ahọn jade bérébéré lẹnu...
Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2709
2709
Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀ Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀ jẹ́ ìwé ìtàn-àròsọ tí ọ̀mọ̀wé D.O. Fagunwa kọ ní ọdún 1938. Ó jẹ́ ìwé ìtàn-àròsọ tí a kọ́kọ́ kọ ní èdè Yorùbá, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ìwé ìtàn tí a má a kọ́kọ́ kọ ní èdè Àfíríkà . Ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbòkègbodò ògbójú Ọdẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Àkàràògùn", àti ohun tí ojú rẹ̀ rí lóríṣiríṣi nínú ìrìn-àjò rẹ̀ nínú igbó. Àwọn nkan bí idán, iwin, ẹbọra àti àwọn òòṣà orísirísi ṣe fìtínà rẹ̀ nínú igbó tí òǹkọ̀wé pè ní igbó irúnmọlẹ̀. Ó jẹ́ ìwé ìtàn-àròsọ méèrirí tí a ka ní èdè Yorùbá. Ìwé ìtàn àròsọ tí ó tẹ̀lẹ́ ìwé yí láti ọwọ́ònkọ̀wé kan náà ni Ìgbó Olódùmarè. Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Sóyinká ṣe ògbufọ̀ ìwé ìtàn àròsọ Ògbójú Ọdẹ nínú Igbo Olódùmarè sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Like "Igbo Olodumare", it was adapted for the stage, in both English and Yoruba.
Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2710
2710
Igbó Olódùmarè Igbo Olodumare ni oruko iwe ti D.O. Fagunwa ko. Eléyìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìtàn àròso tí D.O. Fagunwa kọ. Ó sọ ìtàn Olówó-ayé àti ìrìnàjò rẹ̀ ní Igbó olódùmarè. Ó sọ bí ó ṣe dé ọ̀dọ̀ bàbá-onírùngbọ̀n yẹnkẹ àti bí ó ṣe rí òpin Òjòlá-ìbínú
Igbó Olódùmarè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2729
2729
Emere Emere Olatinwo Adeagbo Adeagbo Ọlátìńwò Adéagbo Fátokí (1991) Emèrè. Ìbàdán, Nigeria: Heineman Educational Books Nig. PLC. ISBN 978-129-234-2. Ojú-ìwé 53. Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ Ohun tó gbé mi dé ìdí à ń kọ ìwé yìí ni ìgbàgbọ́ àti ihà tí àwọn ènìyàn kọ sí àwọn ọmọ tí à ń pè ní Emèrè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rí àwọn ọmọ wọ̀nyìí gẹ́gẹ́ bí Àbíkú, Ẹlẹ́gbẹ́, Ọ̀gbáńje, Ọmọ Ìyanu, Abáfẹ́fẹ́rìn-ọmọ Ẹlẹ́mìíkẹ́mìí-ọmọ àti Adíwọ̀n-ọmọ. Àwọn orúkọ wọ̀nyìí fi hàn pé ìṣòro ńlá wà láti dá Emèrè mọ̀. Lọ́wọ̀ọ́ ìgbà tó sì jẹ́ pé a ko le fi Ògún rẹ̀ gbárí pé Emèrè nìyìi, mo wá lọ sí Àròjinlẹ̀ ọkàn, mo pe kọ́lọ́fín ọpọlọ jáde, mo wá rí i pé Emèrè jẹ́ Àjíǹde-òkú tó ń pọ́n ọ̀bẹ sùn, tó tún fapò rọrí. Gbogbo ara ni wọ́n fi ṣe agbára. Ẹ̀mí àìrí tó sì ń bá wọn lò jẹ́ èyí tó ṣòro láti ṣàpèjúwe. Ọmọ kàyéfì ni Emèrè. À ní Àdánwò-ọmọ ni wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dúró fún tibi-tire tó bá bá àwọn lọ́kọláyà tó bá lùgbàdì wọn. Ní ti agbára, wọ́n ní agbára ju Àjẹ́ àti Oṣó lọ. Ẹ̀yìn Ìyà mi, apani-má-hàá-Ogún, ìbà! Pẹ̀lú fàájì ni Emèrè ṣe ń wọ inú obìnrin-kóbìnrin. Taa ni yóò yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò? Wọ́n ní agbára láti yí padà tàbí taari ọmọ inú aboyún jáde nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lo ààyè ibẹ̀. …
Emere
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2733
2733
Báháráìnì Bahrain tabi Ile-Oba Bahrain Ní ọdún 1995, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé orílẹ̀-èdè yìí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta àti ààbọ̀ (555,000). Èdè Lárúbááwá (Arabic) ni èdè ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè kan tún wà tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Àwọn èdè náà ni fáàsì (farsi) tí àwọn tí ó ń sọ ó ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́ta (48, 000); Úúdù (Urdu) tí àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) àti àwọn èdè fílípíìnì (Phillipine) mìíràn tí àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbayì ní ilẹ̀ yìí sí i gẹ́gẹ́ bí èdè òwò àti èdè ìṣe àbẹ̀wò sí ìlú (tourism).
Báháráìnì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2734
2734
Àwọn Bàhámà Àwọn Bàhámà (pípè /ðə bəˈhɑːməz/) tabi lonibise bi Orílẹ̀-èdè Àjọni ilẹ̀ awọn Bàhámà, je orile-ede elede Geesi to ni awon erekusu 29, 661 cays, ati 2,387 erekusu kekere 2,387 (apata). O budo si inu Okun Atlantiki ni ariwa Kuba ati Hispaniola (Dominiki Olominira ati Haiti), ariwaiwoorun awon Erekusu Turks ati Caicos, ati guusuilaorun orile-ede Awon Ipinle Aparapo ile Amerika (nitosi ipinle Florida). Apapo iye aala ile re je 13,939 km2 (5,382 sq. mi.), pelu idiye olugbe to to 330,000. Oluilu re ni Nassau. Bi jeografi, awon Bahama wa ni asopo erekusu kanna bi Kuba, Hispaniola (Dominiki Olominira ati Haiti) ati Awon Erekusu Turks ati Caicos. Awon onibudo ibe tele ni awon Taino ti Arawaka, awon Bahama ni ibi ti Columbus koko gunle si ni Ile Aye Tuntun ni 1492. Botilejepe awon ara Spein ko se amunisin awon Bahama, won ko awon Lucaya abinibi ibe (eyi ni oruko ti awon Taino Bahama unpe ara won) lo si oko eru ni Hispaniola. Lati 1513 de 1650 enikankan ko gbe ori awon erekusu yi, ko to di pe awon olumunisin ara Britani lati Bermuda tedo si erekusu Eleuthera.
Àwọn Bàhámà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2735
2735
Bálíníìsì Bátíníìsì Balinese Ọmọ ẹgbẹ́ ẹbí èdè Austronesian ni èdè yìí. Àwọn tí ó n sọ ọ́ fẹ́rẹ́ẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́rin (3.8 million) ní erékùsù Báálì (Bali) ní In-indoníísíà (Indonesia). Àkọtọ́ Bálíníìsì àti ti Rómáànù (Balinese and Roman alphabet)ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀.
Bálíníìsì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2736
2736
Èdè Bàlóṣì Ọmọ ẹgbẹ́ èdè tí a ń pé ní Iranian ni Bàlúṣì. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tọ́ mílíọ̀nù márùn-ún. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ọ́ yìí ni ó wà ní Pakísítáánì (Pakistan) ní Bàlúṣísítáànì (Baluchistan). Baluclistan yìí ni ìpínlẹ̀ (province) tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn jùní pakcstan. Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí ní Baluchistan tó mílíọ̀nù (Iran), Afuganíísítáànù (Afghanistan) àti In-índíà (India). Àkọtọ́ Lárúbáwá (Arabic) ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àjọ kan wà tí wọ́n ń pè ní Baluchi Academy tí ó ń ń sí pé àkọsílẹ̀ èdè yìí páye.
Èdè Bàlóṣì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2737
2737
Bàlúṣì Bàlúṣì tàbí Bàlóṣì Baluchi or Balochi Ọmọ ẹgbẹ́ èdè tí a ń pé ní Iranian ni Bàlúṣì. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tọ́ mílíọ̀nù márùn-ún. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ọ́ yìí ni ó wà ní Pakísítáánì (Pakistan) ní Bàlúṣísítáànì (Baluchistan). Baluclistan yìí ni ìpínlẹ̀ (province) tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn jùní pakcstan. Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí ní Baluchistan tó múlíọ̀nù (Iran), Afuganíísítáànù (Afghanistan) àti In-índíà (India). Àkọtọ́ Lárúbáwá (Arabic) ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àjọ kan wà tí wọ́n ń pè ní Baluchi Academy tí ó ń ń sí pé àkọsílẹ̀ èdè yìí páye.
Bàlúṣì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2738
2738
Àwọn èdè Balto-Sílàfù Awon ede Balto-Slavic Ẹgbẹ́ àwọn èdè tí wọ́n ní Baltic ati Slavic ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n wá ń pe àwọn méjèèjì papọ̀ ní Balto-Slavic. Ọmọ ẹgbẹ́ ni àwọn èdè wọ̀nyí jẹ́ fún àwọn ẹ̀yà èdè (branch) tí a ń pè ní Indo-European (In-indo-Yùrópíànù). Àwọn tí ó ń sọ Baluto-Sìláfíìkì yìí tí mílíọ̀nù lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn (300 million people). Eléyìí tí ó ju ìlàjì lọ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ó ń sọ èdè Rọ́síà (Russian) Èdè àìyedè díẹ̀ wà lórí pé bíyá ibi kan náà ni gbogbo àwọn èdè yìí ti ṣẹ̀ tàbí pé nítorí pé wọ́n jọ wà pọ̀ tí wọ́n sì jọ ń ṣe pọ̀ ló jẹ́ kí ìjọra wà láàrin wọn.
Àwọn èdè Balto-Sílàfù
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2739
2739
Asamiisi Assamese Asamiisi Ara ẹgbẹ́ ti ìlà-oòrùn àwọn èdè Indo-Aryan (Indo-Aryan languages ni Assamese. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ to mílíọ̀nù mẹ́rìnlá àbọ̀ (14.5 million). Orílẹ̀-èdè Asam ni wọ́n ti ń sọ èdè yìí jù. Ìlà-oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè India ni Asam wà. Àwọn tí ó ń sọ èdè Assamese yìí tún wà ní Bhutan àti Bangladesh. Àkọtọ́ Bengah ni wọ́n fi ń kọ Assamese sílẹ̀. Ìbátan sì ni òun àti èdè Bengah:
Asamiisi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2740
2740
Èdè Arméníà Èdè Arméníà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Indo-European (Indo-Ùrópóàànù) kan ni eléyìí. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíònù méje. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ ní orílẹ̀-èdè Armenia jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (3.6 million). Wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Turkish Armenia. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní Europe (Úróòpù), Àmẹ́ríkà (USA) àti ààrin gbungbun ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East) náà ń sọ èdè náà. Èdè Armenia àtijọ́ (Classical Armenian tí wọ́n ń pè ní Grabar ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ lítíréṣọ̀ sílẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Wọ́n kọ ọ́ ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì karùn-ún lẹ́yìn ikú Jésù Kírísítì Èdè Grabar yìí ni wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ẹ̀sìn fún àwọn ijọ ilẹ̀ Armenia òde òní, Lẹ́tà álúfábẹ́ẹ̀tì méjìdínlógòjì ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀. St Mesrop ni ó ṣẹ̀dá álúfábẹ́ẹ̀tì yìí. Oríṣìí méjì ni ẹ̀yà èdè yìí ni ayé òde òní. Ọ̀kan nit i apá Ìlà oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní, ìpínlẹ̀ Yeravan. Òun ni wọ́n ń lò ní orílẹ̀-èdè Armenia. Èkejì nit i Ìwọ̀-oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Islanbul. Eléyìí ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Turkey.
Èdè Arméníà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2741
2741
Arméníà Arméníà (; Arméníà: , siso "Hayastan", ]), fún iṣẹ́ọba bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Arméníà (Հայաստանի Հանրապետություն, "Hayastani Hanrapetut’yun", ]), je orile-ede oke-ile ti ile yika ni agbegbe Kafkasu ni Eurasia. O budo si oritameta Apaiwoorun Asia ati Apailaorun Europe, o ni bode mo Turki ni iwoorun, Georgia ni ariwa, "de facto" Nagorno-Karabakh Republic alominira ati Azerbaijan ni ilaorun, ati Iran ati ile Azerbaijani Nakhchivan ni guusu.
Arméníà