url
stringlengths
37
41
id
stringlengths
1
5
text
stringlengths
2
134k
title
stringlengths
1
120
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2742
2742
Argẹntínà Argẹntínà Nínú ètò ìkànìyàn 1995, iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà (Argentiana) lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì àti àti ààbọ̀ (46 245 668). Èdè Pànyán-àn ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n tún ń sọ ní orílè-èdè yìí lé ní ogún. Lára àwọn ogún èdè yìí ni àwọn èdẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Àmẹ́rídíánà (Ameridian Languages) wà. Ara àwọn èdè. Àmérídíánà yìí ni ‘Guarani, Araucanian, Metaco àti Quechua’. Àwọn èdè tí ó tún wà lára ogún yìí ni èdè tí àwọn tí ó wá se àtìpó ń sọ. Lára wọn ni èdè Ítílì (Ìtahàn) àti Jámánì (Herman). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè fún òwò àgbáyé àti èdè àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wò wá sí ibẹ̀ (International trade and tourism). Wọ́n ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí pẹ̀lú èdè Pànyán-àn.
Argẹntínà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2743
2743
Èdè Árámáìkì Èdè Árámáìkì je ara èdè Sèmítíìkì (Semitic). Àwon tí ó ń so èdè yìí tó egbèrún lónà igba ní Ìráànù (Iran) àti Ìráàkì (Iraq) pèlú òpòlopò àwon mìíràn tí wón tún ń so ó ní Ààrin gbùngbùn ìlà-òòrùn àgbáyé (Middle tast). Láti séńtúrì kefà ni wón ti ń fi Árámáìkì àtijó (Classical Aramaic) ko nnkan sílè ní Ààrin gbingbein ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East). Hébéérù ni ó wá gba ipò rè gégé bí èdè tí àwon júù ń so. Èka-èdè ìwò-oòrùn èdè yìí (Western dialect) ni èdè tí Jéésù Kristì àti àwon omo èyìn rè ń so. Èka-èdè kán tí ó wá láti ara èka-èdè yìí ni wón sì ń so ní àwon abúlé kan ní ilè Síríà àti Lébánóònù. Ní nnkan bíi séńtúrì kéje ni èdè Lárúbáwá gba ipò èdè Árámáìkì. Èka-èdè apá ìwo-oòrùn èdè yìí tí a ń pè ní Síríàkì (Syricac) ni àwon ìjo Àgùdà ará fíríàkì (Syriac Catholic) ń lò. Álúfábéètì méjìlélógún ni èdè yìí ní. Èdè yìí sì se pàtàkì nítorí pé láti ara rè ni Hébéérù, Lárúbáwá àti àwon èdè mìíràn ti dìde.
Èdè Árámáìkì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2744
2744
Arabic
Arabic
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2745
2745
Èdè Lárúbáwá Èdè Lárúbáwá tabi ede Araabu Ara èdè Sẹ̀mítíìkì ni èdè Àrábíìkì (Arabic (Èdè Lárúbááwá)). Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíọ̀nù lọ́nà igba gẹ́gẹ́ bí èdè abíníbí ní àríwá Aáfíríkà àti ìlà-oòrùn-gúsù Eésíà (Asia). Àìmoye ènìyàn tí a kò lè fi ojú da iye wọn ni ó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì, ìyẹn èdè àkọ́kún-tẹni ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Mùsùlùmú ti gbilẹ̀. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní pàtàkì ní ilẹ̀ faransé náà máa ń sọ èdè yìí. Ibi tí àwọn tí ó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí ju ni Algeria, Egypt, Iraq, Morocco, Saudi Arabia, Sudan, Syria, Tunisia àti Yeman. Àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ kan wà tí ó jẹ́ ti apá ìwọ̀-oòrùn tí àwọn kan sì jẹ́ ti ìlà-oòrùn. Èdè tí a fi kọ kọ̀ráànù sílẹ̀ ni a ń pè ní ‘Classical’ tàbí ‘Literary Arabic’. Èdè mímọ́ ni gbogbo mùsùlùmú àgbáyé tí ó tó ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní àgbáyé (1, 100 million) nínú ètò ìkànìyàn 1995 ni ó mọ èdè ‘Classical Arabic’ yìí. Olórí ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá wà tí ó sún mọ́ èyí tí wọ́n fi kọ Kọ̀ráànù. Eléyìí ni wọ́n fi ń kọ nǹkan sílẹ̀. Òun náà ni wọ́n sì máa ń lo dípò àwọn ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ẹ̀ka-èdè lárúbáwá yìí ni wọ́n kò gbọ́ ara wọn ní àgbóyé. Méjìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Lárúbááwá. Apé ọ̀tún ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé wá sí apá òsù Yàtọ̀ sí álúfásẹ́ẹ̀tì ti Rómáànù, ti Lárúbáwá ni àwọn ènìyàn tún ń lò jù ní àgbáyé. A ti rí àpẹẹrẹ pé láti nǹkan bíi sẹ́ńtérì kẹ́ta ni a ti ń fi èdè Lárúbáwá kọ nǹkan sílẹ̀. Nígbà tí ẹ̀sìn mu`sùlùmí dé ní sẹ́ńtúrì kéje ni òkọsílẹ̀ èdè yìí wá gbájúgbajà. Wọ́n tún wá jí sí ètò ìkọsílè èdè yìí gan-an ní séńtúrì kọ́kàndínlógún nígbà tí ìkọsílẹ̀ èdè yìí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìwọ̀-oòrùn Úróòpù. Ní pele-ń-pele ni èdè yìí pín sí (ìyẹn ni pé eléyìí tí olówó ń sọ lè yàtọ̀ sí ti tálíkà tàbí kí ó jẹ́ pé eléyìí tí obìnrin ń lò lè yàtọ̀ sí ti ọkùnrin).
Èdè Lárúbáwá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2746
2746
Ántígúà àti Bàrbúdà Ántígúà àti Bàrbúdà (pípè /ænˌtiːgwə æti bɑːɹˈbjuːdə/; Spani fun "atijo" ati "onirungbon") je is a twin-orile-ede erekusu-meji larin Omi-okun Karibeani ati Okun Atlantiki. O ni erekusu meji ninla ti awon eniyan ungbe be, Ántígúà ati Bàrbúdà, pelu awon erekusu kekeke melo kan (bi awon Erekusu Great Bird, Green, Guinea, Long, Maiden ati York).
Ántígúà àti Bàrbúdà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2748
2748
Angola Àngólà, lóníbiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Àngólà (, ]; Kikongo, Kimbundu, Umbundu: Repubilika ya Ngola), jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ní apágúsù Áfríkà tó ní bodè mọ́ Namibia ní gúsù, Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò ní àríwá, àti Zambia ní ilàòrùn; ìwọ̀òrùn rẹ̀ bọ́ sí etí Òkun Atlántíkì. Luanda ni olúìlú rẹ̀. Ìgbèríko òde Kàbíndà ní bodè mọ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Kóngò àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò. Ìtàn. <ns>10</ns> <id>16733</id> <revision> <id>534273</id> <parentid>122075</parentid> <timestamp>2020-05-17T15:21:13Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Àngólà di ileamusin Portugal ni 1884 leyin Ipade Berlin. O gba ilominira ni odun 1975 leyin ogun itusile. Ko pe leyin ilominira ni ogun abele sele lati 1975 de 2002. Àngólà ni opo alumoni ati petroliomu, be sini okowo re ti ungbera soke pelu iwon eyoika meji lati odun 1990, agaga lateyin igba ti ogun abele wa sopin. Sibesibe opagun ijaye si kere gidigidi fun opo alabugbe, be sini ojo ori ati iye ọ̀fọ̀ ọmọwọ́ ni Angola je awon eyi to buru julo lagbaye. Jeografi. <ns>10</ns> <id>16733</id> <revision> <id>534273</id> <parentid>122075</parentid> <timestamp>2020-05-17T15:21:13Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format>
Angola
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2749
2749
Àndórà Àndórà tabi fun iseoba o je Ilẹ̀-Ọmọba Andorra, bakanna won tun mo si Ilẹ̀-Ọmọba àwọn Àfonífojì ilẹ̀ Àndórà (Principality of the Valleys of Andorra) je orílẹ̀-èdè aláfilẹ̀yíká ni apa guusuiwoorun Europe. Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn tí ó ń gbé Àndórà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì-dún-láàádọrin (68,000). Àwọn èdè tí ó jẹ́ ti ìjọba níbẹ̀ ni Kàtáláànù tí ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ń sọ (60%) àti èdè faransé. Wọ́n tún ń sọ Kàsìtílíànù ti àwọn Pànyán-àn-àn gan-an fún òwò àgbáyé àti láti fi bá àwọn tí ó bá wá yẹ ìlú wọn wo sọ̀rọ̀ .
Àndórà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2751
2751
Amóráìtì "Amorite" je Èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) kan ni Amóráìtì (Amorite) tí wọ́n ń sọ ní agbègbè àríwá Síríà (Syria) òde òní ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sí ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ ṣáájú ìbí Kírísítì. Díẹ̀ ni a mọ̀ nípa èdè yìí nítorí pé láti inú orúkọ ènìyàn àti àwọn àkọ́sílẹ̀ díẹ̀ tí a rí tí wọ́n opẹ́ sí ara òkúta nìkan ni a mọ̀ nípa èdè yìí
Amóráìtì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2752
2752
Èdè Àmháríkì Amhariki Èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) kan ni eléyìí tí nǹkan bú mílíọ̀nu márùndínlógún ń sọ gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kọ́ ní Ethopia (ìtópíà). Níbẹ̀, wọ́n ń lò ó gẹ́gẹ́ bí tí ìjọba ń mú lò. Àwọn bú mílíọ̀nù márùn-ún ni ó ń sọ èdè yìí ní agbègbè Ethiopia nígbà tí ̣ àwọn ọ̀pọ̀lọpò mílíọ̀nù mìíràn ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì àkọ́kúntẹnu ní Ethiopia àti Sudan (Sùdáànù). Láti nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹrìnlá (14th Century) ni èdè yìí ti ní àkọsílẹ̀. Àkọtọ́ Amharic ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àkọtọ́ yìí ní Kóńsónáǹtì mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ẹ̀dà méjeméje. Ẹ̀dà kóńsónáǹtì tí ènìyàn yóò mú lò dúró lóró fáwẹ̀lì tí kóńsónáǹtì náà yóò bá jẹ yọ. Àbá ti ń wáyé nípa pé kí àtúnṣe wà fún àkọtọ́ yìí. Àwọn kan sì ti kóra wọn jọ fún ìpolongo láti sọ èdè yìí di àjùmọ̀lò (Standardisc).
Èdè Àmháríkì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2753
2753
Àngúíllà Anguilla Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn ènìyàn tó wa ní Anguilla jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún (7,100). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń sọ níbẹ̀. Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni wọ́n ń sọ èdè Kirió tí wọ́n gbé ka èdè Gẹ̀ẹ́sì (English based Creole). Kirió yìí ni ó wọ́pọ̀ jù ní Áńtílẹ́ẹ̀sì (Lesser Antilles)
Àngúíllà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2780
2780
Olódùmarè Olódùmarè Káàkìri àgbáyé ni a ti mò pé olódùmarè wà, eni tí ó dá ayé àti òrùn àti ohun gbogbo ti ń be nínú won òyígíyigí oba àìrí arínú-róde Olùmòràn Òkàn, alèwílèse, alèselèwí, Oba atélè bí eni téní, Oba atésánmo bí eni téso, Oba lónìí, Oba lóla, Oba títí ayé àìnípèkun, Olówó gbogbogbo tí ń yomo rè nínú òfin, Oba Olójú lu kára bí ajere, Oba onínú fúnfún àti béè béè lo. Èyí ni pe oríkì Olódùmarè pọ̀ lọ jáǹtìrẹrẹ, bí a bá sì gbọ́ tí àwọn Yorùbá bá sọ pé ‘orí mi o tàbí olọ́jọ́ ọ̀ní o, Olódùmarè ni wọ́n ń pè ní orí, èyí tí ó dúró fún ẹlẹda orí àti ọlọ́jọ́ òní tí ó dúró fún ẹ̀ni tí ó nì ọjọ́ òní. Tàbí nígbà mìíràn tí àwọn Yorùbá bá rí Ohun tí ó ya ni lẹ́nu wọn á ní ‘Bàbá ò’ èyí tí ó dúró fún Olódùmarè. Àwọn ọmọ ènìyàn gbà wí pé ọlọ́run tóbi ju gbogbo ẹ̀dá lọ ó sì jẹ ẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ má a bọlá fún, èrò ọkàn àwọn Yorùbá ni pé ọlọ́run tàbí olódùmarè tóbi púpọ̀, ó sì ju ẹnikẹ́ni lọ àti nítorí èyí kò yẹ kí wọ́n máa dárúko mọ́ ọ lórí bí wọ́n ti ń ṣe sí ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà wọn, láti bu ọlá fún-un àti láti fi ìtẹríba wọn hàn fún un wọ́n ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ pè é, wọn a ní ẹlẹda, èyí ní ẹni tí ó dá ọ̀run, àti ayé, òyígíyigì, èyí ni ẹni tí ó tóbi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ohun tí a lè fi wé. Ọba àwámárìdí, èyí ni ẹni tí a kò lè rí ìdí iṣẹ́ rẹ̀, Alábàláṣe, èyí ni ẹnì tí ó ni àbá àti àṣẹ, Bàbá, èyí ni baba gbogbo ẹ̀dá inú ayé, Ọ̀gá ògo; èyí ni ẹni tí ó ni ọ̀run èyí tí ó jẹ́ ògo ẹ̀dá tàbí nígbà mìíràn a lè túmọ̀ rẹ̀ sí ẹni tí ògo tàbí ìgbéga ẹ̀dá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, Atẹ́rẹrẹkáríaye, èyí ni ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní gbogbo ayé ní ìkáwọ́ rẹ̀, ẹlẹ́mìí, èyí ni ẹni tí ó ni ẹ̀mí ẹ̀dá. Bí a bá tún gbó nígbà mìíràn tí àwọn àgbàlagbà ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘Èdùàrè tàbí wọ́n ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘olú’ olódùmarè kan náà ni wọn ń tọ́ka sí. Àwọn àgbàlagbà a máa sọ pé: “Àṣegbé ọmọ Èdùàrè. mo ló dàṣegbé Àṣegbé ọmọ Èdùàrè… Ohun tí àkọlé yìí ń tọ́ka sí ni pé ohun tí ọmọ Èdùàrè, èyí tí ó dúró fún olódùmarè bá ti ṣe àṣegbé ni ìgbà gbogbo là ń gbọ́ tí àwọn àgbàlagbà máa ń sọ pé “ẹni olúwa dá kò ṣe é fara wé”. Ohun tí wọn ń tọ́ka sí nínú gbólóhùn yìí nip é ẹni tí Olú, èyí tí ó dúró fún olódùmarè “bá ti dá àyànmọ́ kan mọ́ ẹnìkan, a kò lè fara wé irú ẹ̀nìyàn bẹ́ẹ̀. Àwọn àkíyèsí tí a lè rí tọ́ka sí ni pé ọ̀pọ̀ ìtàn ìwásẹ̀ ni ó sọ bí Olódùmarè ṣe sẹ̀dá ayé àti ọ̀run, Yorùbá gbàgbọ́ pé ọ̀run ni olódùmarè wà, tí ó ti ń ṣe àkóso ayé àti ọ̀run, èrò Yorùbá ni pé kò sí ohun tí a ‘lè fi wé olódùmarè nítorí àwọn àwẹ̀mọ́ tàbí abuda rẹ tó tayọ àwa ẹ̀dá lọ fún àpẹẹrẹ a lè pe olódùmarè báyìí pé ‘Ẹlẹda, Ẹlẹ́mìí, Ọlọ́run Ọba ní í fọ́n èjí iwọ́rọ́ iwọ́rọ̣́, òun ló ni ọ̀sán àti òru dọ́jọ́ òní, òní ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀la ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀tunla ọmọ Ọlọ́fin, ìrènì ọmọ Ọlọ́fin, ọ̀rúnní ọmọ Ọlọ́fin, Yorùbá máa ń sọ pé ìṣẹ́ Ọlọ́run tóbi tàbí àwámárìdí ni iṣẹ́ Ọlọ́run, Ọ̀rúnmìlà fẹ̀yìntì ó wò títí o ní “ẹ̀yín èrò okun, ẹ̀yin èrò ọsa, ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ pé iṣẹ́ Olódùmarè tóbi: A tún lè sọ pé Ọba Ọ̀run ọ̀gá Ògo, atẹ́rẹrẹ káyé ẹlẹ́ní àtẹ́ẹ̀ká, Ọba ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í yẹ̀, alábà láṣẹ̀ á tun le pe ni alágbára láyé àti lọ́run. Adùn ún ṣe bí ohun tí olódùmarè lọ́wọ́ sí, aṣòro o ṣe bí ohun tí olódùmarè kò lọ́wọ́ sí, Alèwílèṣe, Aṣèkanmákù. Ìgbà mìíràn a tún lè sọ pé ọlọ́run nìkan ló gbọ́n, ó rí ohun gbogbo, ó sì lè ṣe ohun gbogbo, Arínúróde Olùmọ̀ràn ọkan, Yorùbá sọ pé “Amòòkùn ṣolè bí Ọba ayé kò ri, Ọba ọ̀run ń wò ó, èyí túmọ̀ sí wí pé kò sí ohun tí a ṣe ní ìkọ̀kọ̀ tí Olódùmarè kò rí, kedere ni lójú Olódùmarè, àwọn òrìṣà ló máa ń jẹ àwọn arúfin ní ìyà ṣùgbọ́n Olódùmarè ló máa ń dájọ́ fún wọn, fún àpẹẹrẹ ní ìgbà kan gbogbo òrìṣa fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú olódùmarè lẹ́yin tí tọ̀tún tòsì wọ́n rojọ́ olódùmarè dá ọ̀rúnmìlà láre, odù ifá kan jẹri sí eléyìí, odù náà lọ báyìí “Ọ̀káńjùa kì í jẹ́ ka mọ nǹkan pínpín, Adíá fun odù. Mẹ́rìndín lógún níjọ́ ti wọn ń jìjà àgbà relé olódùmarè, nígbà tí àwọn ọmọ ìrúnmọlẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún tán ń jìjà ta ni ẹ̀gbọ́n ta ni àbúrò láàárin ara wọn, wọ́n kẹ́jọ́ lọ sódọ̀ olódùmarè, níkẹyìn, olódùmarè dá ẹjọ́ pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn odù yókù. Yorùbá gbàgbọ pé onídàjọ́ òdodo ni olódumarè, ìdí nìyí tí Yorùbá fi ń sọ pé ọlọ́run mú u tàbí ó wà lábẹ́ pàṣán ‘Olódùmarè. Òyígíyigì ọba Ọta àìkú fẹ̀rẹ̀kufẹ̀, a kì í gbọ́kú Olódùmarè. Tí a bá tún wo Ọ̀kànrànsá (odù ìfa) òun náà tún sọ pe olódùmarè kì í ku, fún àpẹẹrẹ, Odù ọ̀kànrànsá yìí sọ pé: Ọ̀dọ́mọdé kì í gbọ́kú asọ yẹyẹyẹ laṣọ ogbó àgbàlagbà kì í gbọ́kù aṣọ yẹyẹyẹ laṣọ ogbó Olódùmarè náà ni Ọba àìrí, àwámárìdí Yorùbá tún gbà pé ó jẹ Ọba mímọ́ tí kò léèérí, alálà funfun òkè. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé bí àwọn áńgẹ́lì tí jẹ́ Olùrànláwọ́ fún Olódùmarè lóde ọ̀run ni àwọn òrìṣà náà jẹ́ aṣojú rẹ̀ lóde ìṣálayé, àwọn òrìṣà wọ̀nyí jẹ́ alágbàwí àwọn ènìyàn níwájú olódùmarè. A gbọ́ wí pé ìbáṣepọ̀ wà láàárin àwọn òrìṣà tàbí òòṣà ilẹ̀ Yorùbá àti Olódùmarè, àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pe òòṣà wọ̀nyí nì wọ́n lè rán sí olódùmarè yálà láti tọrọ nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀ tàbí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ohun ribiribi tí ó ṣe fún wọn. Erò yìí hàn nínú òwe Yorùbá kan pé “ẹni mojú ọwá là ń bẹ̀ sọ́wá, olójú ọwá kan kò sí bíkòṣe ayaba”. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ pé bí a bá fẹ́ kí Ọba ṣe ohun kan fún ni a ó bẹ ayaba sí i, ipò alágbàwí láàárin àwọn abòòṣà àti olódùmarè ni àwọn òòṣà wà.
Olódùmarè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2782
2782
Koisaanu Oju=iwe kiini. ỌLỌFNSAO OLUKEMI M. ÀWỌN ẸBÍ ÈDÈ KHOISAN Ìfáàrà Ẹbí èdè Khoisan yìí ni ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹbí èdè gbogbo tí ó wà ní Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí Greenberg (1963a) ti sọ, ó ní àwọn ni wọ́n dúró fún èyí tí ó kéré jù lọ nínú èdè Áfíríkà. ÌPÌLẸ̀ ORÚKỌ ÈDÈ YÌÍ A mu orúkọ yìí jáde láti ara orúkọ ẹgbẹ́ Khoi-Khoi ti Gusu ilẹ Afirikà (South Africa) àti ẹgbẹ́ san (Bushmen) ti Namibia. A máa ń lo orúkọ yìí fún Oríṣìíríṣìí àwọn ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ pé àwọn gan-an ni wọ́n kọ́kọ́ jẹ́ olùgbé ilẹ̀ south Africa kí awọn Bantu tó wá, kí àwọn òyìnbó ilẹ̀ Gẹẹsi (Europe) sì tó kó wọn lẹ́rù. Oríṣìíríṣìí àwọn onímọ̀ ni wọn ti siṣẹ lórí orúkọ yìí – Khoisan.Tan Gùldemann ati Rainer Vossen ṣàlàyé nínú iṣẹ́ rẹ̀ pé Leonardt Schulze 1928 ni o mu orúkọ yìí jáde láti ara Hottentot’ tí o túmọ̀ sí Khoi ti o sì tún túmọ̀ sí ‘person’ (ènìyàn) àti ‘san’ tí ó túmọ̀ sí ‘forager’. Lẹ́yìn èyí ni onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá àṣà, ìgbàgbọ́ àti ìdàgbàsókè ọmọnìyàn, anthropologist Schapera (1930) tún wá fẹ̀ orúkọ yìí lòjù sẹ́yìn nípasẹ̀ ‘Hottentot’àti ‘Bushman’ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà, (racia) àṣà (cultural) àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè. (Linguistic). Àwọn orúmọ̀ mìíràn tí wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kẹta ti wọ́n tún siṣẹ́ lé orúkọ yìí lórí ni Kolnler (1975, 1981) sands (1998) àti Traill (1980, 1986). Wọn pinnu láti lo orúkọ náà Khoisan gẹ́gẹ́ bí olúborí fún àwọn èdè tí kìí ṣe ti Bantù tí kì í sì í ṣe èdè Cushitic. Àwọn onímọ̀ akíọ́lọ́jì fi han wí pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fa ọdún sẹ́yìn ni awọn ènìyàn Khoisan ti fara hàn. Èyí fi han pé lọ́dọ̀ àwọn àgbà láèláè nìkan ni a ti lè máa gbọ́ èdè Khoisan nìkan báyìí. Bí èdè Khoisan tilẹ̀ farajọra nínú ètò ìró, gírámà tirẹ̀ yàtọ̀ gédégbé. Àìsí àkọ́sìlẹ̀ ìtàn àwọn èdè wọ̀nyí mú kí o nira díẹ̀ láti sọ ìfarajọra awọn èdè yìí sí ara àti sí àwọn èdè adúláwọ̀ tí ó kù. Lóde àní, Ilẹ̀ (South Western Africa) gúsu-ìwọ̀ òòrùn Áfíríkà títí dé àginjù kàlàhárì (Kalaharì Desert), láti Angola de South Africa àti ní apákan ilẹ̀ Tanzania nìkan ní wọ́n ti ń sọ èdè Khoisan. Edè Hadza àti Sandawe ní ilẹ̀ Tanzania ni a sáábà máa ń pè ní Khoisan ṣúgbọ̀n wọ́n yàtọ̀ nípa ibùgbé àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè sí ara wọn. A wá lè sọ pé nínú gbogbo èdè àgbáyé, èdè Khoisan wà lára àwọn èdè tí àwọn onímọ́ èdè kò kọbiara sí tí a kò sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀. ÌPÒ TÍ ÈDÈ YÌÍ WÀ Èdè Khoisan yìí gẹ́gẹ́ bí a ti sọ síwájú ń dín kù síi lójoojúmọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń di ohun ìgbàgbé. Ohun tí ó fa èyí ni pé àwọn tí wọ́n ń sọ àmúlùmálà èdè Khoisan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè mìíràn tí ó gbilẹ̀ ní agbègbè wọn; wọ́n sì dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní èdè abínibí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ní àkọ́silẹ̀ kankan tí ó sì fíhàn pé sísọnù tí àwọn èdè wọ̀nyí sọnù, kò lè ní àtúnṣe. Ó jẹ́ ohun tí ó nira díẹ̀ láti sọ pé iye àwọn ènìyàn kan pàtó ni wọ́n ń sọ èdè Khoisan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí àwọn Òyìnbó tó gòkè bọ̀, a kò sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn Òyìnbó ń ṣètò ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì tún ni pé ìwọ̀nba la lè sọ mọ nípa ohun ti ó ń ṣẹlẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ fi hàn pé, ní bíì ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, iye nọ́nbà tí wọ́n kọ sílẹ̀ kò ṣeé tẹ̀lé mọ́; àkọsílẹ̀ sọ wí pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà Igba (120,000 – 200,000) ni wọn, ṣùgbọ́n èyí ti di ohun àfìsẹ́yìn bí eégún fí aṣọ. Wọn kò tó bẹ́ẹ̀ mọ́. Díẹ̀ lára àwọn èdè khoisan àti iye àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́. EDE, IYE ÀWỌN TI Ń SỌ, ILÚ, Sandare, 40, 000, Tanzania Haillom (San), 16,000, Namibia, Name (Khoekhoegowab) 233,701 Namibia, Botswana, South Africa Suua , 6,000, Botswana Tsoa. 5,000, Botswana //Ani , 1,000, Botswana Gana, 2,000, Botswana Kxoe 10,000, Namibia, Angola, Botswana South Africa, Zambia //Gwi, 2,500 , Botswana Naro, 14,000, Botswana, Namibia =Ikx’aull’ein 2,000, Namibia, Botswana Kung-Ekoka, 6,900, Botswana, Angola, South Africa. Oju-iwe keji. IHUN EDE KHOISAN ÈTÒ ÌRÓ Àwọn èdè Khoisan kò ṣàì ní ìfarajọra nínú ètò ìrò. Ó dá yàtọ̀ gédégbè sí àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà yòókù, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tí ó nira. FAWẸLI Ọ̀pọ̀ àwọn èdè Khoisan wònyí ni ó ń lo fáwẹ́lì márùn ún - /i/, /e/, /a/, /o/, /u/ tí a sì lè pè pẹ̀lú àwọn oríṣìí àbùdá wọ̀nyìí bíi, ìránmú, (nasalization) ìfi káà-ọ̀fun-pè (pharyngealization) ati oríṣìí àmúyẹ ohùn bíi mímí ohun (breathy voice) ati dídún ohùn (Creaky voice) tí yóò sì mú bí i oríṣìí ìró fáwẹ́lì bí i ogójì jáde. KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ:- (Clicks) kílíìkì Kílíìkì ni a ń pe àwọn kọ́ńsónáǹtì wọn; títí kan àwọn àfeyínpè (dential), àfèrìgìpè, (alveolar), afàjàfèrìgìpè (alveo-palatal), afẹ̀gbẹ́-ẹnu-pè (lateral) àti kílíìkì afètèpè (bilabial Chick). Sandawe àti àwọn Hadza tí ilẹ̀ Tanzania ń lo àfeyínpè (dental ) afèrìgìpè (alveolar) àti kílíìkì afẹ̀gbé-ẹnu-pè (lateral clicks). Pẹ̀lú gbogbo àhesọ ọ̀rọ̀ títí di àkókò yìí orísun kílíìkì èdè Khoisan kò tíì yéni. Àpẹẹrẹ:- - Kiliiki Àfeyínpè – A máa ń pe èyí nípa gbígbé ahọ́n sí ẹ̀yìn ẹyín iwájú. “tsk” - Kílíìkì Afèrìgìpè – Ó máa ń dún bí ìgbà tí a bá ṣí ìdérí ìgò nípa gbígbé ahọ́n sí ẹ̀yìn eyín iwájú. - Kílíìkì Afàjàfàrìgìpè – Ó máa ń dún nípa gbígbé ahọ́n sílẹ̀ kúrò lára àjà ẹnu. - Kílíìkì Afègbẹ́-ẹnu-pè – ó máa ń dùn gẹ́gẹ́ bí ìró ti à ń lò lédè Gẹ̀ẹ́sì láti mú kí ẹsin kánjú. - Kílíìkì Afètépè máa ń dún nípa kíkanra ètè méjèèjì, tí a sì tún sí i sílẹ̀ ní kíá, gẹ́gẹ́ bí ìró ìfẹnukonu ni èyí ṣe máa ń dún. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kílíìkì wọ̀nyí ló lè ní Kíkùnyùn-ùn, (Voicing) ríránmú (nasality), “aspiration” ati “ejection”. Láti le mú kí á ní àgbéjáde oríṣìíríṣìí kílíìkì. Àwọn orísìíríṣìí kílíìkì wọnyi ló mú kí èdè Khoisan yàtọ̀. Àpẹẹrẹ nínú èdè Nama, Ogún ni kílíìkì tí wọ́n ń lò nígbà tí wọ́n n lo mẹ́tàlélógọ́rin nínú ède Kxoe tí ó jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khoisan. Ní àfíkún, àádọ́rùn-ún ònírúrú kóńsónáǹtì kílíìkì ni wọ́n n lo ni Gwi tí òhun náà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khosian wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ Kílíìki Nama SÍLÉBÙ Gbogbo àwọn kóńsónáǹtì Kílíìkì àti èyí tí kìí ṣe kílíìkì ló máa ń fara hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tí fáwẹ́lì sì máa ń tẹ̀lé e. Ìwọ̀nba kóńsónáǹtì bí àpẹẹrẹ /b/, /m/, /n/, /r/, àti /l/ ló lè jẹ yọ láàrín fáwẹ́lì, díẹ̀ sì lè farahàn ní ẹ̀yìn ọ̀rọ̀. ÌRÓ OHÙN Àwọn èdè Khosan máa ń sàfihàn oríṣìíríṣìí ìró ohùn, bí àpẹẹrẹ, Jul’hoan ní ipele ohun àárún oríṣìí mẹ́rùn, ó sì ní ipele ohun òkè kan. GIRAMA Ọ̀rọ̀ àti ìhun gbólóhùn àwọn èdè Khoisan yàtọ̀ síra láàrin ara wọn. Ọ̀RỌ̀ ORÚKỌ Ìsọ̀rí mẹ́ta ni ọ̀rọ̀ arúkọ Khoisan pín sí; bí a bá wòó, nípasẹ̀ jẹnda, akọ, abo àti àjọni ni ò pín sí. Nínú Kxoe, fún àpẹẹrẹ, jẹ́ńdà nínú ọ̀rọ̀-orúkọ aláìlẹ́mìí tún máa ń ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìríṣí, bi àpẹẹrẹ, akọ ní í ṣe pẹ̀lú gígùn, tí tò si tóbi, nígbà tí abo ní í ṣe pẹ̀lú nǹken kúkúrú, gbígbòòrò tí kó sì tóbi òríṣìíríṣìí mọ́fíímù ni wọ́n fi ń parí òkọ̀ọ̀kan àwọn jẹ́ńdà wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ láti inú èdè Nama. Khoisan , English, Yoruba , Khoe-b, Man , Ọkùnrin , Khoe-s, Woman, Obinrin , Oríṣìíríṣìí nọ́mbà mẹ́ta ni wọ́n ní, àwọn ní ẹyọ, oníméjì àti ọ̀pọ̀. NỌ́MBÀ Apẹẹrẹ lati inu èdè Naro Male (Akọ), Female (Abo), Common (Ako/Abo) SG, ba , sa _________ Dual , tsara , sara, Khoara PL llua dzi na Ọ̀RỌ̀-ÌṢE Àbùdá gírámà tí ó sáábà máa ń jẹ yọ nínú àwọn èdè Khoisan ni lílo ọ̀rọ̀-iṣe àkànmónúkọ (verb compound) nígbà tí èdè Gẹ̀ẹ́sì ń lo ọ̀rọ̀ atọ́kùn tàbí ọ̀rọ̀-iṣe kan (single verb) Àpẹẹrẹ English, Khoisan, Enter go + enter. Àsìkò (Tense) Ẹ̀rún ni a máa ń lò láti fi àsìko hàn nínú èdè KhoeKhoe àti nípa lílo àfòrò ẹyin nínú ede Kxoe, Buga ati //Ani Ninú àwọn èdè Kalahari East Kxoe, Àfòmọ́ ẹ̀yìn ló ń fi ìṣẹ̀lẹ̀ ti o ti Koja hàn (Past Tense), ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ tí ó lòdì ati jẹ̀rọ́ndì hàn nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ti ọjọ́ iwájú ń lo Ẹ̀rún. Bẹ́ẹ̀ náà lọmọ́ sorí nínú èdè Naro, G//ana, G/ui àti ‡Haba. IBÁ ÌṢẸ̀LẸ̀ Mana nìkan ni ó ń lo ibá ìṣẹ̀lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìṣẹ̀dá (Morphological Category) ó sì ya ibá ìṣẹ̀lẹ̀ aṣetán sọ́tọ̀ sí àìṣetán IYISODI Ẹ̀rún tàbí àfòmọ́ ẹ̀yìn ni wọn n lo fún ìyísódì (Khoekhoe tam; G//ana G/ui àti ‡Haba tàmátema) n lò ẹ̀rún fún ìyísódì nígbà tí (kxoe //Am. Buya-bé) n lo afọmọ ẹyin, nígbà mìíràn wọ́n n lo méjèèjì. Ètò Ọ̀rọ̀ Ètò ọ̀rọ̀ tí àwọn èdè Khoisan ti à ń sọ wọ̀nyí máa ń lò ni (Svo-Subject-Verb-Object) Olùwà ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ tàbí (Sov-Suject-Object-verb). Ọ̀rọ̀ Èdè (Vocabulary) Àfihàn ìgbésí ayé àwọn olùṣọ èdè Khoisan ni ọ̀rọ̀-èdè (Vocabulary) wọn jẹ́. Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn olùṣọ èdè wọ̀nyí ń gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá mìírà, èyí mú kí wọ́n ní àwọn ọ̀rọ̀-èdè tí ó súnmọ́ ọdẹ ṣíṣe, ẹranko, Kóríko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. ÀKỌ́SÍLẸ̀ Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ni àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n Nama ati Naro ni àkọsílẹ̀ àti ohun èlò ìkọ́ni. Nama ní pàtàkì ti wà ní àkọsílẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.
Koisaanu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2811
2811
Nigeria
Nigeria
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2812
2812
Ilorin Ilorin ni olu-ilu Ìpínlẹ̀ Kwara ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Gégé bi abayori ìkà ènìyàn odun 2006 ní Nàìjíríà, ìlú Ilorin ní olùgbé 777,667, èyí mú kí ó jẹ́ ìlú keje tí ó ní olùgbé jùlo ní Nàìjíríà.
Ilorin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2813
2813
Kazimierz Nowak Kazimierzu Nowaki (lati Ọdún 1897 títí di Osu Òwàrà Ọjọ kétàlá Ọdún 1937 je ọmọ Ìuí Polandi ti Ọjẹ arińninajo Oníweroým ati aya woran ti a bi ni ilu Stiryi. Lehin Ogun àgbáyé alakọkọ ogbe ni ilu Poznani lati ọdún 1931 títí di ọdún 1936 Orin, ogun kẹkẹ jake jado ilu Aláẁọ dúdú. Orin irinajo ti oto egberun lọ́na ogoji kilomita (40.000 km). Owun ni eni akọkọ ti okọkọ ṣẹ́iru nkan bayi. O ti kọ iṣẹ yi si inu iwe ti a pe orukọ rẹ ni "Rowerem i pieszo przez Czarny Ląd" (Kẹkẹ ati ẹsẹ jake jado ilẹ aláẁọ dúdú). Oku si ilu Poznani.
Kazimierz Nowak
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2821
2821
Lítíréṣọ̀ Litireso tabi iṣẹ́ọnàmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà OHUN TÍ LÍTÍRÉṢỌ̀ JẸ́ Eléyìí náà kò ṣàì ní orírun tirẹ̀ láti inú èdè Látìn “LITERE” Èyí ni àwọn gẹ́ẹ́sì yá wọ inú èdè wọn tí wọ́n ń pè ni lete rature” Ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ máa ń yípadà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yà ènìyàn kan sí èkejì láti ìgbà dé ìgbà. Lítíréṣọ̀ kò dúró sójú kan. Babalọlá (1986), ṣàpèjúwe lítíréṣọ̀ pé: “Àkójọpọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè kan tàbí òmíràn tó jásí ewì, ìtàn àlọ́, ìyànjú, eré onítàn, ìròyìn àti eré akọ́nilọ́gbọ́n lórí ìtàgé” Tí a bá wo òde òní, ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ tún yàtọ̀, fún àpẹẹrẹ a máa ń ṣàkíyèsí ìlò èdè tí wọ́n fi kọ ìwé kan yàtọ̀ sí èyí, a tún ka lítíréṣọ̀ kùn iṣẹ́ òǹkọ̀wé alátinúdá tàbí iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìlò ojú inú gẹ́gẹ́ bí ewì, ìtàn àròkọ àti eré oníṣe. A ó sì rí i pe awẹ́ tàbí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ tí a mẹ̀nubà wọ̀nyí kó púpọ̀ nínú ìmọ̀ ìgbé ẹ̀dá láwújọ (folklore) mọ́ ara, yálà, a kọ, ọ́ sílẹ̀, a rò ó sọ tàbí a ṣe é léré yàtọ̀ fún àwọn àkọọ́ lẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́. Lítírésọ̀ tún jẹ́ irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ tó ní àbùdá ẹ̀mí gígùn, ó máa ń fi ìṣẹ̀ṣe àti àṣà àgbáríjọ àwọn èèyàn kan hàn. Àwọn míràn tó tún sọ̀rọ̀ lórí lítíréṣọ̀ ni àwọn ọmọ lẹ́yìn Mark: Àwọn Marxist (1977) yìí gbà pé: “Scrutiny of the literature could not be realize without the society” Èyí ni pé: “Lítíréṣọ̀ kò lè ṣe é dá yẹ̀wò láìwo àwùjọ tí a kọ ọ́ fún” Kí òǹkọ̀wé kan tó lè se iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeyanjú, irúfẹ́ oǹkọ̀wé náà gbọ́dọ̀ ni àtinúdá àtinúdá yìí pẹ̀lú ohun gan-an tí ó ń ṣelẹ̀ láwùjọ ni yóò wá sọ di ọ̀kan nínú iṣẹ́ rẹ̀. Lara àwọn tí ó ṣiṣẹ́ lórí ìlànà Marx yìí ni: Trosky ara Russia, Lucas àti Goldmann. Daviguand (1960) ni tíọ́rì sọ pé “Literature enumerate the future thought of an individual (Human being) Èyí ni pé: “Lítíréṣọ̀ wà fún láti máa so èrò ọkàn ènìyàn jáde nípa ọjọ́ iwájú” Nípa yíyẹ lítíréṣọ̀ wò, à ní láti wo ẹ̀hun ìpìlẹ̀ ìtumọ̀, èyí ni wíwo gbogbo nǹkan tí ó wà láwùjọ yẹn olápapọ̀ láì dá ọ̀kan sí.
Lítíréṣọ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2829
2829
Ìjẹ̀ṣà Àwọn Ìjẹ̀ṣà je iran kan nínú àwọn ọmọ Yorùbá. Ipinle Osun ni Nigeria ni won budo si julo. Ìtàn. Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá ni ilẹ̀ Yorùbá òde-òní ìjẹ̀sa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ojúlówó ọmọ Yorùbá tí kò se fí ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìtàn àwọn Yorùbá. Oríìsíìsí ìtàn ni a sì gbọ́ nípa orírun Ìjẹ̀sà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó Yorùbá kó dà a ti lè gbọ́ wí pé olórí àwọn Ìjẹ̀sà jẹ òkan lára àwọn ọmọ méjèje tí Odùduwà bí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ni a gbọ́ nípa ìsẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ó sì dàbí ẹni pé o sòro díẹ̀ láti sọ pe ọ̀kan ni fìdí múlẹ̀ jùlọ. Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pé ó jẹ́ àsà fún àwọn ènìyàn jàkànjàkàn láti wá bá Ajíbógun ní ibùdó rẹ̀, àwọn ènìyàn wònyí ni à ń pè ní “Ìjọ tí a sà”. Ní ìtẹ̀síwájú, ìtàn sọ fún wa wí pé òjígírí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò bá Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀. Òjígírí yìí kan náà ló jẹ́ ọwá sí ìlú Ìpólé. Bákanna ni ìtàn sọ pé òjígírí ló jẹ Ògbóni sí ìlú ti Ìjẹ̀bú-jẹ̀sà. A sì tún gbọ́ wí pé nígbà tí Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀, ilé-Ìdó ni o kọ́kọ́ dúró sí láti ilè Ìdó yi ló ti lọ sin òkú ọlọ́fin (Odùduwà) ní ilé-ifẹ̀, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ wí pé ìgbàdayé ni Ajíbógun padà sí, tí ó sì kú síbẹ̀. Ọ̀kà-òkìlè tí ó jẹ́ daodu fún Ajíbógun ni ó jẹ Ọwá sí ìlú- Ìlówá ti oun naa si sun ibẹ̀, bakanna ni Ọbarabara tí a mọ̀ sí Olokun. Esin ló je Ọwá sí Ìpólé. Ọwalusẹ ní ẹnití ó jẹ Ọwá àkọ́kọ́ sí ìlú Ilesà ti o nì. Bakanna ni a tún rí ìtàn míràn tó sọ fún wa nípa Ọwá Obòkun ti ilẹ̀-Ìjẹ̀sà wí pé nígbà tí Odùduwà tó n se bàbá fún (Ajíbógun) dàgbà ti ojú rẹ fọ̀ ni ifá Àgbọ̀níregùn ní kí wọn lo bu omi òkun wá kí ojú Odùduwà bàbá wọn lè là. Báyìí ní ó wá pe àwọn ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọkan èjèejì wí pé ki wọn lọ bu omi lókun wá fún ìtọ́jú ojú òhun, sùgbọ́n èyí Ọwá re ló gbà láti lọ bu omi òkun naa wá. Nígbà tí ó ń lọ bàbá rẹ fun ní idà tí á mọ̀ sí idà ìsẹ́gun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára, a gbọ́ wí pé nígbà tí o n lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro àti ìdàmú ló bá pàdé ni ojú ọ̀nà rẹ sùgbọ́n o sẹ́gun wọn pẹ̀lú idà ìsẹ́gun ọwọ́ rẹ, sùgbọ́n kí ó tó dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti sọ ìrètí nù èrò yìí ló mú kí bàbá rẹ gan-an pàápàá sọ ìrètí nù, èrò yìí ló mú kí bàbá pín gbogbo ogún àti àwọn ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ (Owá) Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn àti bàbá wí pé ó lè padà dé mọ́. nígbà tí o dé wọn fi omi òkun fọ ojú bàbá wọn ó sì là padà, lẹ́yìn èyí ló wá bi bàbá lérè wí pé àwọn ẹ̀gbọ́n oun ń kọ́ bàbá sì sàlàyé fún pe ò ń rò pé kò lè padà wá sí ilé mọ́ àti wí pé ò ń ti pín gbogbo ogún fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Ajíbógun bínú gidi, ó wá bèèrè wí pé kí ni ogún ti oun báyìí, bàbá rẹ ni kò sí nkan-kan mọ́ àfi idà Ìsẹ́gun tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nìkan ló kù, inú bí Ajíbógun ó fa idà yọ láti fi ge bàbá rẹ̀, sùgbọ́n idà bá adé ò sí ge jọwọjọwọ ìwájú adé naa, lẹ́yìn èyí ní bàbá rẹ̀ gbé adé naa fún, nítorí pé ó se akin àti akíkanjú ènìyàn, sùgbọ́n bàbá rẹ sọ fun wí pé láti òní lọ kò gbọdọ̀ dé adé tí ó ní jọwọjọẁ létí mọ́, àti ìgbàyí ló ti di èwọ̀ fún gbogbo ọwá tí ó bá jẹ ni ILÉSÀ. Ìtàn míràn ni pé, lẹ́yìn ìgbàtí Ajíbógun ti parí isẹ́ ti bàbá ran tán ni o kúrò ni ilé-ifẹ̀ láti lọ se ìbẹ̀wò sí ìlú àwọn bàbá rẹ. lára àwọn ìlú tí Àjíbógun gba kọ já ni Osu àti àwọn ìlú míràn, a gbọ́ wí pé, Ọ̀kà-òkìle tí ó jẹ́ dáódù fúnAjíbógun ní ó jẹ Owari si ìlú Ìpólé tì wọn ń sì ń pé ni Owari. Ìtàn sọ fún wa wí pé Ìpólé yìí ní Ọ̀kà-òkìle jẹ Owa ti rẹ si sùgbọ́n oun àti àwọn ará ìlú ko gbọ ara wọn yé rárá nítorí agbára tí ó ní, sùgbọ́n o selẹ̀ wí pé ọ̀tẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀sì ni pọ̀ si láàrín àwọn ará ìlú pẹ̀lú ọba, ọ̀tẹ̀ yìí ló fa Ìjà tí ó pín ìlú sí méjì. lára àwọn tí ó kọ́ ara jọ ni wọ́n sọ gbólóhùn kan pé “Ìn jẹ́ asá” tí ó túmọ̀ sí pé “ Ẹjẹ́ ká sá “ èyí ní wọ́n yípadà sí Ìjẹ̀sà, àwọn wọ̀nyí ni wọn lo tẹ ìlú Ilésà gan-gan dó. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìlú Ilésà dó ni àwọn olóyè ti wọ́n kúrò ni ìlú Ìpólé pé ara wọn jọ pé ó yẹ kí àwọn ni ọba, wọ́n wa pa ìmọ̀ pọ̀ pé kí wọn lọ mú Ọwalusẹ ti se àbúrò Ọ̀kà-òkìle kí o jẹ́ ọba wọn, wọ́n se bẹ lọ́ọ̀tọ́ Owálusẹ si jẹ ọba àkọ́kọ́ ní ìlú Ilésà. Ìgbàtí tí Ọ̀kà-òkìle gbọ́ ní Ìpólé o ránsẹ́ sí Owalusẹ pé kí ó wá. Ọwálúsẹ̀ si se bẹ gẹ́gẹ́, ìgbàtí ó dé ọ̀dọ̀ Ọ̀kà-òkìle naa idà si etí Ọwálùsẹ̀, etí kàn si jábọ́, ìgbàtí Ọwálùsẹ padà sí Ilésà oun à ti Ọwá (Ọ̀kà-òkìle) kò rí ara wọ́n, àti ìgbàyí nì Oka- okule tí gẹ́gùn pé gbogbo ọdún tí wọ́n bá fẹ se ni ilésà wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ se ti Ìpólé títí di àsìkò yìí. Lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn yìí ni Ọ̀kà-òkìle (Owá) pinu láti ba gbogbo ará Ìpólé se ìpàdé pọ̀, ohun tí o sẹ lẹ ni Ìpàdé ni pé Ọ̀kà-òkìle se àlàyé pé oun fẹ́ férakù láàrín wọn (fẹ́ kú) ó fún wọn ni osù mẹ́ta, lẹ́yìn osù kan ará ìlú lọ ba pé sé kò fẹ́ wo ilé mọ ilè mọ ni, sùgbọ́n ojú ti fẹ́ ma ti Owari nítorí òrọ̀ òhún ti di yẹ̀yẹ́ láàárín ìgboro. Ìgbà tí ó di ọjọ́ tí ó fẹ́ wọ ilẹ̀ ó jẹ́ àárín òru bí owari se wọ ilẹ̀ ni gbogbo ìgboro dàrú nítorí gbiri gbiri tí wọn gbọ́ wọ́n sáré kiri, kò pé ní àwọn kan ri tí wọn si fi ariwo bọ ẹnu pé owá ti rì ò, Owá ti rì ò, èyí ní wọn yí padà tí ó di Owárì. Àfin tí o rì ni à ń pè ní Ùpàrà Owárì. Ìdí sì ni yìí tí Ọwá kò gbọ́dọ̀ fi dé ibẹ̀ títí di àsìkò yìí. Ìlú mẹ́ta ló kúrò ni Ìpólé, lára wọn ni Ìpólé, Ìjakuro àti Ẹ̀fọ̀n Aláayè. Ìdí nì yí tí wọn má ń sọ pé “Ọ̀pá Ìpólé ku ogun Ọ̀pá ijakuro ku ọgbọ̀n Ọ̀pá Ẹ̀fọ̀n-Aláayè wọ́n ku mẹ́ta gege” Àti ìgbàyí lo ti di òrìsà sí ìlú Ìpólé àti agbègbè Ìjẹ̀sà. Àwọn ìlú Ìjẹ̀ṣà. Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ó wà ní abẹ́ Ìjẹ̀sà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ni a lè rí tọ́kasí lábẹ́ wọn. Lára àwọn ìlú wọ̀nyí ní a tí rí ìlú ńláńlá àti kékeré. Àwọn ìlú naa nì wọ̀nyí (1) Ìpólé (2) Ìrógbó (3) Ìwukùn (4) Ìbòdì (5) Ìtapá (6) Òdò (7) Olówu (8) Ìperindó (9) Ìlokò (10) Ìwárája (11) Ìsè-Ìjẹ̀sà (12) Ìlérín (13) Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà (14) Ìpetu-jẹ̀ṣà (15) Èrìn–Ìjèṣà (16) Ìdómínàà (17) Ìlásè (18) Ìlówá (19) Ìkíyìnwá (20) Ifẹ̀wàrà (21) Èsà-òkè (22) Èsà-odò (23) Ìbòkun (24) Òtan-ilé (25) Ìmèsí-ilé (26) Òsú (27) Ìpetu-ilé (28) Ìlàrè (29) Ìlayè (30) Ìtagúnmodu (31) Mogbàrà (32) Òmò (33) Ìgángán (34) Iléṣà Àwọn oyè pàtàkì ní Ìjẹ̀ṣà. Orísìrísì oyè ló wà ní ilé lólọkàn ò jọ kan. Pàápàá ní ìlú Ilésà gangan, bẹ́ pẹ̀lú ní àwọn oyè míràn tún wà ní ààrín àdúgbò. Bákan náà ni wọ́n ń jẹ àwọn oyè bi baálẹ̀, lọ́jà ni àwọn ìlú kékèké abẹ́ wọn. lára àwọn oyè pàtàkì tí ó wà ní ìlú ilésà gangan ní wọ̀nyí. (1) Léjòfì (2) Àrápaté (3) Risawe (4) Òdolé (5) Lórò (6) Ọbańlá (7) Léjọ̀kà (8) Sàwè (9) Bajimọ (10) sàlórò àti (11) Yèyé ríse Ètò òṣèlú àti ètò ìjọba àwọn Ìjẹ̀ṣà. Tí a bá wo ètò òsèlú tàbí ètò ìse ìjọba ilé ìjẹ̀sà a ó ri wí pé ó jé ètò ìsè ìjọba ti o dára. Nítorí pé, ọba ló jẹ́ olórí fún gbogbo Ìlú ti o maa n pa àsẹ bákan naa ní wọn ní àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìjòyè. Lára àwọn oyè àdúgbò ni tí a rí olórí ọmọ, ọ̀wábùsuwà, lọ́tún, losì, Ìyá-lóbìrin, àti olórí àdúgbò gangan tí wọn maa n fi orúkọ àdúgbò pè bi àpeere:- bàbá lanaye ni àdúgbò Ànáyè, bàbá luroye ni àdúgbò Ìróyè abbl. Àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan yi ló jé olórí fún àwọn ará àdúgbò wọn tí yoo si máà se ìsàkóso àdúgbò naa. Àwọn olórí yìí naa tún ni àwọn àsọmọgbè kọọkan pẹ̀lú isé olúkálukú. Ìyálóbìnrin wà fún ọ̀rọ̀ àwọn obinrin ni àdúgbò, bàbá lórí ọmọ wa fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Ti ọ̀rọ̀ kan ba selè láàrín àwọn ọ̀dọ̀ tàbí làáárín àgbà tí ó wà ní àdúgbò. Wọn á gbé ejó naa lọ si ilé bàbá lórí ọmọ tí bàbá lórí ọmọ bá parí ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n a tari rẹ̀ si olórí-àdúgbò àti àwọn ìjòye rẹ tí àwọn ìjòyè àti olórí àdúgbò naa kò bá rí ọ̀rọ̀ náà yanjú wọ́n a gbé o di ọ̀dọ̀ ọwá (Ọba wọn) àti àwọn Ìjòyè rẹ fún ejò dídá. Ọ̀dọ̀ Ọwá yìí ni ẹjọ́ gbígbé kiri parí sí. Tí a bá wá ri ẹjọ́ tí Ọwá kò le parí wọn a ní kí oníjà méjì naa lọ búra ní ẹ̀yìnkùlé Ọwá, níbíyi ènìyàn kò le se èké kí o lọ búra ní bẹ̀ nítorí kò sí ohun tí a sọ tí kò ní selẹ̀. Àṣà àwọn Ìjẹ̀ṣà. Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àsà ni ilẹ̀ Yorùbá lónìí, a ó ri wí pé kò sí ojùlówó ọmọ Yorùbá tí kò ní àsà, àmọ́ àsà wá le yàtọ̀ láti ibìkan sí ibòmíràn. Lára àwọn ojúlówó ọmọ Yorùbá tí ó ní àsà ni a ti rí àwọn Ìjẹ̀sà. Tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa àsà, àsà jẹ́ ohun tí agbègbè kan ń se yálà nínú Ìwà wọn, ẹ̀sìn wọn, tàbí nínú Ìsesí wọn. Oúnjẹ. Oúńjẹ jẹ́ ohun tí kò sé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní àwùjọ, bẹ si ni àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní àwọn oúńjẹ tí wọ́n fẹ́ràn. Tí a ba sọ̀rọ̀ nípa oúńjẹ tí Ìjẹ̀sà fẹ́ràn jù tàbí oúńjẹ ti o jẹ́ oúńjẹ pàtàkì a o ni sai lai dárúkọ iyán, nítorí iyán ní oúńjẹ pàtàkì tí Ìjẹ̀sà maa n jẹ, bí o tìlẹ́jẹ́ pé wọn tun ni àwọn oúńjẹ míràn bi àmàlà, Ẹ̀bà, Fùfú, ẹ̀wà, Ìrẹsì abbl. Sùgbọ́n iyán ni ọba oúńjẹ wọn .Ìjẹ̀sà le jẹ iyán ni ẹmẹẹta ni ojúmọ́ tàbí ni gbogbo Ìgbà àti àkókò nítorí náà, iyán jẹ oúńjẹ fún Ìjẹ̀sà. Ijó. Nípa ti ijó jíjó kò sí àdúgbò tí kò ní ijó tàbí orin ti wọn, àwọn ondo n ko obitun, Ìlàjẹ àti Ìkálẹ̀ ń kọ bírípo, bẹ́ nì ti àwọn Ìjẹ̀sà pẹlú ilésà ń kọ orin Àdàmọ̀, bẹ́nì wọ́n tun jọ ijó Ìkàngá ati ijó lóye pẹ̀lú Ìlù bẹ̀nbẹ́ àti orin Ìkàngá bákannáà. Onírúrurú orin ni a mọ̀ Ìjẹ̀sà mọ́ sùgbọ́n Ìkàngá àti loye ni o jẹ́ orin Ìpílẹ̀ wọn ti wọn maa ń kọ. Ìwọsọ. Èyí maa tú jẹ ọ̀kan lára àwọn ibi tí a tì lé rì àsà àti èdè Yorùbá bákannáà ni gbogbo àwọn ẹ̀yà kọọkan tún ní àsà ìwọsọ tí wọn. Àwọn obìnrín Ìjẹ̀sà maa nwọ àsọ̀ àfì tó jẹ́ Ìró àti bùbá bẹ́ni àwọn okùnrin wọn máà ń wọ esikí àti sòkòtò ẹlẹ́nu ńlá pẹ̀lú fìlà alabankata. Oge síṣe. Èyí jẹ́ àsà tí o sábà maa ń súyọ láàárín àwọn obìnrin pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́. Àwọn obìnrin Ìjẹ̀sà máà n lo lali, tiro, osùn láti fi soge. Àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀sà. Àwọn Ìjẹ̀sà jẹ́ alákíkánjú àti jagunjagun ènìyàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ní àwọn Ìjẹ̀sà ni pa nínú rẹ̀, ní àkókò ogun kariaye ilè Yorùbá. Lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ìjẹ̀sà ja a ni ogun Ìbàdàn, ogun Jalumu àti ogun Kiriji tàbí ogun Ekìtì parapọ̀. Ogun Èkìtì parapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1877, o sì perí ní ọdún 1886. Ẹni tí ó jẹ́ bí asíwájú ogun pàtàkì yìí ni okùnrin alajagun Ìjẹ̀sà kan ti orúkọ rẹ ń jẹ́ Ògèdèngbé .Ogun Èkìtì parapọ̀ yìí ni ó mú orúkọ Ògèdèngbe dúró sinsin nínú ìtàn Yorùbá ogn náà si ja fún ọdún mẹsan gbáko ọdún 1910 ní ògèdèngbé kú. Ohun kan tí àwọn Ìjẹ̀sà se ni Ìrántí Ògèdèngbé tí ó jẹ́ olórí àwọn Ìjẹ̀sà wà ni eréjà Ilésà ní iwájú ilé Ìfowópamọ́ ti “National Bank of Nigeria Limited” lsẹ́ àwọn Ìjẹ̀sà. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ìyókù ní ilẹ̀ Yorùbá ní wọ́n mọ àwọn Ìjẹ̀sà sí onísòwò paraku idi ni yi tí wọn fi ń pe àwọn Ìjẹ̀sà ni “Òsómàáló”. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí kà nínú ìwé, a gbọ́ pẹ́ àwọn Ìjẹ̀sà ni ó dá àsà san an díẹ̀dị́ẹ̀ sílẹ̀ nínú Ìsòwò. Wọ́n màá n lọ láti ìlú dé ìlú àti ìletò de ìletò láti se isẹ́ ọjà títà wọn, ohun tí wọn si n ta ní pàtàkì ní asọ. Sùgbọ́n lónìí Ìjẹ̀sà ti kúrò ni a n kiri láti Ìlú de ìlú tàbí Ìletò de Ìletò, wọ́n ti wà nínú ilé ìtajà ní àwọn ìlú ńláńlá bíi, Ìbàdàn, Èkó, Ìlọrin, Ògbọ́mọ̀sọ́, Kánò, Kàdùná, òsogbo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́hìn isẹ́ òwò síse ti a mọ si Òsómàló tí wọ́n máa ń kiri, wọ́n tún máa ń se isẹ́ àgbẹ̀ paraku nínú oko wọn, àwọn Ìjẹ̀sà a maa gbin kòkó, obì, isu, àgbàdo, káfé, ìrẹsì, àti orísì́ àwọn ohun jíjẹ míìràn. orísì àwọn isẹ́ míìràn tí àwọn Ìjẹ̀sà n se ni isẹ́ àgbẹ̀dẹ dúdú àti àgbẹ̀de góòlù, isẹ́ gbénàgbénà, asọ híhun, aró dídá àti orísi isẹ́ míràn. Àwọn ilé isẹ́ ti a lè rí ní ilésà ní “ International Breweries Limited Nigeria” ni ibití wọ́n ti ń se ọtí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Trophy Larger Beer” àti àwọn ohun amúlúdùn ti a lè rí ni ilésà lónìí ni iná mọ̀nàmọ́ná, pápá ìseré àti ilé ìtura. Ẹ̀sìn àwọn Ìjẹ̀sà. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, kí àwọn òyìnbó tó kó ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá de orílè-èdè wa, àwọn Yorùbá ti ni ẹ̀́sìn ti wọn. llésà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ilẹ́ Yorùbá maa n sin àwọn òrìsà bii ògún, ọ̀sun, ifá, èsù, ọya àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ti o wá sí orilè - èdè yìí wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà ni nǹkan bíi ọdún mélòó sẹ́hìn ni a mọ̀ sí ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì, ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ó ti àwọn lárúbáwá wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì náà ni a ti rí Ìjọ Àgùdà (Catholic), Ìjọ onítẹ̀bomi (Baptist) Ìjọ Elétò (Methodist) Ajíhìnrere Kírísítì (Christ Apostelic Church) kérúbù àti séráfù (Cherubim and Seraphim) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò Ẹ̀kọ́. Àwọn Ìjẹ̀sà ní Ìmọ̀ tí ó gbámúsé ní pa ètò ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjẹ̀sà ni o di ipò gíga mú ní ilé isẹ́ ìjọba fún àǹfàní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn. tị́tí di àkòkò yìí ó tó nǹkan bí aadọta ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí ó wà ní igboro ilésà, ilé ẹ̀kọ́ girama méjìdínlógún àti ilé ìwé ẹ̀kọ́sẹ́ olùkọ́ onípòkejì méjì. Ni àfikún, ìjọba tún ti dá ilé- ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ olùkóni, fún ilé ẹ̀kọ́ giga sílẹ ni llésà ni ọdún 1977(Osun State College of Education) Àwọn òrìsà ilẹ̀ Ìjẹ̀sà Owari, Owaluse, Oludu, Oluaye, Ajitafa, Ogun, Omi/Osun. Sùgbọ́n àwọn òrìsà kò se bẹ gbilẹ̀ mọ́ ni ilẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ọ̀kan soso lalè ri níbú wọn ti o dàbí ẹni pé wọn sin se ọdún rẹ.
Ìjẹ̀ṣà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2830
2830
Iléṣà Iléṣà jẹ́ ìlú ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀. Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá ni ilẹ̀ Yorùbá òde-òní ìjẹ̀sa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ojúlówó ọmọ Yorùbá tí kò se fí ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìtàn àwọn Yorùbá. Oríìsíìsí ìtàn ni a sì gbọ́ nípa orírun Ìjẹ̀sà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó Yorùbá kó dà a ti lè gbọ́ wí pé olórí àwọn Ìjẹ̀sà jẹ òkan lára àwọn ọmọ méjèje tí Odùduwà bí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ni a gbọ́ nípa ìsẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ó sì dàbí ẹni pé o sòro díẹ̀ láti sọ pe ọ̀kan ni fìdí múlẹ̀ jùlọ. Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pé ó jẹ́ àsà fún àwọn ènìyàn jàkànjàkàn láti wá bá Ajíbógun ní ibùdó rẹ̀, àwọn ènìyàn wònyí ni à ń pè ní “Ìjọ tí a sà”. Ní ìtẹ̀síwájú, ìtàn sọ fún wa wí pé òjígírí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò bá Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀. Òjígírí yìí kan náà ló jẹ́ ọwá sí ìlú Ìpólé. Bákanna ni ìtàn sọ pé òjígírí ló jẹ Ògbóni sí ìlú ti Ìjẹ̀bú-jẹ̀sà. A sì tún gbọ́ wí pé nígbà tí Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀, ilé-Ìdó ni o kọ́kọ́ dúró sí láti ilè Ìdó yi ló ti lọ sin òkú ọlọ́fin (Odùduwà) ní ilé-ifẹ̀, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ wí pé ìgbàdayé ni Ajíbógun padà sí, tí ó sì kú síbẹ̀. Ọ̀kà-òkìlè tí ó jẹ́ daodu fún Ajíbógun ni ó jẹ Ọwá sí ìlú- Ìlówá ti oun naa si sun ibẹ̀, bakanna ni Ọbarabara tí a mọ̀ sí Olokun. Esin ló je Ọwá sí Ìpólé. Ọwalusẹ ní ẹnití ó jẹ Ọwá àkọ́kọ́ sí ìlú Ilesà ti o nì. Bakanna ni a tún rí ìtàn míràn tó sọ fún wa nípa Ọwá Obòkun ti ilẹ̀-Ìjẹ̀sà wí pé nígbà tí Odùduwà tó n se bàbá fún (Ajíbógun) dàgbà ti ojú rẹ fọ̀ ni ifá Àgbọ̀níregùn ní kí wọn lo bu omi òkun wá kí ojú Odùduwà bàbá wọn lè là. Báyìí ní ó wá pe àwọn ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọkan èjèejì wí pé ki wọn lọ bu omi lókun wá fún ìtọ́jú ojú òhun, sùgbọ́n èyí Ọwá re ló gbà láti lọ bu omi òkun naa wá. Nígbà tí ó ń lọ bàbá rẹ fun ní idà tí á mọ̀ sí idà ìsẹ́gun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára, a gbọ́ wí pé nígbà tí o n lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro àti ìdàmú ló bá pàdé ni ojú ọ̀nà rẹ sùgbọ́n o sẹ́gun wọn pẹ̀lú idà ìsẹ́gun ọwọ́ rẹ, sùgbọ́n kí ó tó dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti sọ ìrètí nù èrò yìí ló mú kí bàbá rẹ gan-an pàápàá sọ ìrètí nù, èrò yìí ló mú kí bàbá pín gbogbo ogún àti àwọn ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ (Owá) Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn àti bàbá wí pé ó lè padà dé mọ́. nígbà tí o dé wọn fi omi òkun fọ ojú bàbá wọn ó sì là padà, lẹ́yìn èyí ló wá bi bàbá lérè wí pé àwọn ẹ̀gbọ́n oun ń kọ́ bàbá sì sàlàyé fún pe ò ń rò pé kò lè padà wá sí ilé mọ́ àti wí pé ò ń ti pín gbogbo ogún fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Ajíbógun bínú gidi, ó wá bèèrè wí pé kí ni ogún ti oun báyìí, bàbá rẹ ni kò sí nkan-kan mọ́ àfi idà Ìsẹ́gun tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nìkan ló kù, inú bí Ajíbógun ó fa idà yọ láti fi ge bàbá rẹ̀, sùgbọ́n idà bá adé ò sí ge jọwọjọwọ ìwájú adé naa, lẹ́yìn èyí ní bàbá rẹ̀ gbé adé naa fún, nítorí pé ó se akin àti akíkanjú ènìyàn, sùgbọ́n bàbá rẹ sọ fun wí pé láti òní lọ kò gbọdọ̀ dé adé tí ó ní jọwọjọẁ létí mọ́, àti ìgbàyí ló ti di èwọ̀ fún gbogbo ọwá tí ó bá jẹ ni ILÉSÀ. Ìtàn míràn ni pé, lẹ́yìn ìgbàtí Ajíbógun ti parí isẹ́ ti bàbá ran tán ni o kúrò ni ilé-ifẹ̀ láti lọ se ìbẹ̀wò sí ìlú àwọn bàbá rẹ. lára àwọn ìlú tí Àjíbógun gba kọ já ni Osu àti àwọn ìlú míràn, a gbọ́ wí pé, Ọ̀kà-òkìle tí ó jẹ́ dáódù fúnAjíbógun ní ó jẹ Owari si ìlú Ìpólé tì wọn ń sì ń pé ni Owari. Ìtàn sọ fún wa wí pé Ìpólé yìí ní Ọ̀kà-òkìle jẹ Owa ti rẹ si sùgbọ́n oun àti àwọn ará ìlú ko gbọ ara wọn yé rárá nítorí agbára tí ó ní, sùgbọ́n o selẹ̀ wí pé ọ̀tẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀sì ni pọ̀ si láàrín àwọn ará ìlú pẹ̀lú ọba, ọ̀tẹ̀ yìí ló fa Ìjà tí ó pín ìlú sí méjì. lára àwọn tí ó kọ́ ara jọ ni wọ́n sọ gbólóhùn kan pé “Ìn jẹ́ asá” tí ó túmọ̀ sí pé “ Ẹjẹ́ ká sá “ èyí ní wọ́n yípadà sí Ìjẹ̀sà, àwọn wọ̀nyí ni wọn lo tẹ ìlú Ilésà gan-gan dó. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìlú Ilésà dó ni àwọn olóyè ti wọ́n kúrò ni ìlú Ìpólé pé ara wọn jọ pé ó yẹ kí àwọn ni ọba, wọ́n wa pa ìmọ̀ pọ̀ pé kí wọn lọ mú Ọwalusẹ ti se àbúrò Ọ̀kà-òkìle kí o jẹ́ ọba wọn, wọ́n se bẹ lọ́ọ̀tọ́ Owálusẹ si jẹ ọba àkọ́kọ́ ní ìlú Ilésà. Ìgbàtí tí Ọ̀kà-òkìle gbọ́ ní Ìpólé o ránsẹ́ sí Owalusẹ pé kí ó wá. Ọwálúsẹ̀ si se bẹ gẹ́gẹ́, ìgbàtí ó dé ọ̀dọ̀ Ọ̀kà-òkìle naa idà si etí Ọwálùsẹ̀, etí kàn si jábọ́, ìgbàtí Ọwálùsẹ padà sí Ilésà oun à ti Ọwá (Ọ̀kà-òkìle) kò rí ara wọ́n, àti ìgbàyí nì Oka- okule tí gẹ́gùn pé gbogbo ọdún tí wọ́n bá fẹ se ni ilésà wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ se ti Ìpólé títí di àsìkò yìí. Lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn yìí ni Ọ̀kà-òkìle (Owá) pinu láti ba gbogbo ará Ìpólé se ìpàdé pọ̀, ohun tí o sẹ lẹ ni Ìpàdé ni pé Ọ̀kà-òkìle se àlàyé pé oun fẹ́ férakù láàrín wọn (fẹ́ kú) ó fún wọn ni osù mẹ́ta, lẹ́yìn osù kan ará ìlú lọ ba pé sé kò fẹ́ wo ilé mọ ilè mọ ni, sùgbọ́n ojú ti fẹ́ ma ti Owari nítorí òrọ̀ òhún ti di yẹ̀yẹ́ láàárín ìgboro. Ìgbà tí ó di ọjọ́ tí ó fẹ́ wọ ilẹ̀ ó jẹ́ àárín òru bí owari se wọ ilẹ̀ ni gbogbo ìgboro dàrú nítorí gbiri gbiri tí wọn gbọ́ wọ́n sáré kiri, kò pé ní àwọn kan ri tí wọn si fi ariwo bọ ẹnu pé owá ti rì ò, Owá ti rì ò, èyí ní wọn yí padà tí ó di Owárì. Àfin tí o rì ni à ń pè ní Ùpàrà Owárì. Ìdí sì ni yìí tí Ọwá kò gbọ́dọ̀ fi dé ibẹ̀ títí di àsìkò yìí. Ìlú mẹ́ta ló kúrò ni Ìpólé, lára wọn ni Ìpólé, Ìjakuro àti Ẹ̀fọ̀n Aláayè. Ìdí nì yí tí wọn má ń sọ pé “Ọ̀pá Ìpólé ku ogun Ọ̀pá ijakuro ku ọgbọ̀n Ọ̀pá Ẹ̀fọ̀n-Aláayè wọ́n ku mẹ́ta gege” Àti ìgbàyí lo ti di òrìsà sí ìlú Ìpólé àti agbègbè Ìjẹ̀sà. ÀWỌN ÌLÚ ÌJẸ̀SÀ. Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ó wà ní abẹ́ Ìjẹ̀sà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ni a lè rí tọ́kasí lábẹ́ wọn. Lára àwọn ìlú wọ̀nyí ní a tí rí ìlú ńláńlá àti kékeré. Àwọn ìlú naa nì wọ̀nyí (1) Ìpólé (2) Ìrógbó (3) Ìwukùn (4) Ìbòdì (5) Ìtapá (6) Òdò (7) Olówu (8) Ìperindó (9) Ìlokò (10) Ìwáráya (11) Ìsè-Ìjẹ̀sà (12) Ìlérín (13) Ìjẹ̀bú- Jẹ̀sà (14) Ìpetu- jẹ̀sà (15) Èrìn –Ìjèsà (16) Ìdómínàà (17) Ìlásè (18) Ìlówá (19) Ìkíyìnwá (20) Ifẹ̀wàrà (21) Èsà-òkè (22) Èsà-odò (23) Ìbòkun (24) Òtan-ilé (25) Ìmèsí-ilé (26) Òsú (27) Ìpetu-ilé (28) Ìlàrè (29) Ìlayè (30) Ìtagúnmodu (31) Mogbàrà (32) Òmò (33) Ìgángán (34) Ilésà gan-an (35) Ẹ̀rìnmọ̀ Ìjẹ̀sà ÀWỌN OYÈ PÀTÀKÌ NI ÌJẸ̀SÀ. Orísìrísì oyè ló wà ní ilé lólọkàn ò jọ kan. Pàápàá ní ìlú Ilésà gangan, bẹ́ pẹ̀lú ní àwọn oyè míràn tún wà ní ààrín àdúgbò. Bákan náà ni wọ́n ń jẹ àwọn oyè bi baálẹ̀, lọ́jà ni àwọn ìlú kékèké abẹ́ wọn. lára àwọn oyè pàtàkì tí ó wà ní ìlú ilésà gangan ní wọ̀nyí. (1) Léjòfì (2) Àrápaté (3) Risawe (4) Òdolé (5) Lórò (6) Ọbańlá (7) Léjọ̀kà (8) Sàwè (9) Bajimọ (10) sàlórò àti (11) Yèyé ríse ÈTÒ ÒSÈLÚ ÀTI ÈTÒ ÌJỌBA ÀWON ÌJẸ̀SÀ. Tí a bá wo ètò òsèlú tàbí ètò ìse ìjọba ilé ìjẹ̀sà a ó ri wí pé ó jé ètò ìsè ìjọba ti o dára. Nítorí pé, ọba ló jẹ́ olórí fún gbogbo Ìlú ti o maa n pa àsẹ bákan naa ní wọn ní àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìjòyè. Lára àwọn oyè àdúgbò ni tí a rí olórí ọmọ, ọ̀wábùsuwà, lọ́tún, losì, Ìyá-lóbìrin, àti olórí àdúgbò gangan tí wọn maa n fi orúkọ àdúgbò pè bi àpeere:- bàbá lanaye ni àdúgbò Ànáyè, bàbá luroye ni àdúgbò Ìróyè abbl. Àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan yi ló jé olórí fún àwọn ará àdúgbò wọn tí yoo si máà se ìsàkóso àdúgbò naa. Àwọn olórí yìí naa tún ni àwọn àsọmọgbè kọọkan pẹ̀lú isé olúkálukú. Ìyálóbìnrin wà fún ọ̀rọ̀ àwọn obinrin ni àdúgbò, bàbá lórí ọmọ wa fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Ti ọ̀rọ̀ kan ba selè láàrín àwọn ọ̀dọ̀ tàbí làáárín àgbà tí ó wà ní àdúgbò. Wọn á gbé ejó naa lọ si ilé bàbá lórí ọmọ tí bàbá lórí ọmọ bá parí ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n a tari rẹ̀ si olórí-àdúgbò àti àwọn ìjòye rẹ tí àwọn ìjòyè àti olórí àdúgbò naa kò bá rí ọ̀rọ̀ náà yanjú wọ́n a gbé o di ọ̀dọ̀ ọwá (Ọba wọn) àti àwọn Ìjòyè rẹ fún ejò dídá. Ọ̀dọ̀ Ọwá yìí ni ẹjọ́ gbígbé kiri parí sí. Tí a bá wá ri ẹjọ́ tí Ọwá kò le parí wọn a ní kí oníjà méjì naa lọ búra ní ẹ̀yìnkùlé Ọwá, níbíyi ènìyàn kò le se èké kí o lọ búra ní bẹ̀ nítorí kò sí ohun tí a sọ tí kò ní selẹ̀. ÀSÀ ÀWỌN ÌJẸ̀SÀ. Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àsà ni ilẹ̀ Yorùbá lónìí, a ó ri wí pé kò sí ojùlówó ọmọ Yorùbá tí kò ní àsà, àmọ́ àsà wá le yàtọ̀ láti ibìkan sí ibòmíràn. Lára àwọn ojúlówó ọmọ Yorùbá tí ó ní àsà ni a ti rí àwọn Ìjẹ̀sà. Tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa àsà, àsà jẹ́ ohun tí agbègbè kan ń se yálà nínú Ìwà wọn, ẹ̀sìn wọn, tàbí nínú Ìsesí wọn. Lára àwọn ohun tí a ti le kíyèsí àsà dada ni (1) oúńjẹ (2) oge síse (3) ijó (4) orin (5) Ìwọsọ (1) OÚŃJẸ:-oúńjẹ jẹ́ ohun tí kò sé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní àwùjọ, bẹ si ni àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní àwọn oúńjẹ tí wọ́n fẹ́ràn. Tí a ba sọ̀rọ̀ nípa oúńjẹ tí Ìjẹ̀sà fẹ́ràn jù tàbí oúńjẹ ti o jẹ́ oúńjẹ pàtàkì a o ni sai lai dárúkọ iyán, nítorí iyán ní oúńjẹ pàtàkì tí Ìjẹ̀sà maa n jẹ, bí o tìlẹ́jẹ́ pé wọn tun ni àwọn oúńjẹ míràn bi àmàlà, Ẹ̀bà, Fùfú, ẹ̀wà, Ìrẹsì abbl. Sùgbọ́n iyán ni ọba oúńjẹ wọn .Ìjẹ̀sà le jẹ iyán ni ẹmẹẹta ni ojúmọ́ tàbí ni gbogbo Ìgbà àti àkókò nítorí náà, iyán jẹ oúńjẹ fún Ìjẹ̀sà. (2) IJÓ :- Nípa ti ijó jíjó kò sí àdúgbò tí kò ní ijó tàbí orin ti wọn, àwọn ondo n ko obitun, Ìlàjẹ àti Ìkálẹ̀ ń kọ bírípo, bẹ́ nì ti àwọn Ìjẹ̀sà pẹlú ilésà ń kọ orin Àdàmọ̀, bẹ́nì wọ́n tun jọ ijó Ìkàngá ati ijó lóye pẹ̀lú Ìlù bẹ̀nbẹ́ àti orin Ìkàngá bákannáà. Onírúrurú orin ni a mọ̀ Ìjẹ̀sà mọ́ sùgbọ́n Ìkàngá àti loye ni o jẹ́ orin Ìpílẹ̀ wọn ti wọn maa ń kọ. (3) ÌWỌSỌ:-maa tú jẹ ọ̀kan lára àwọn ibi tí a tì lé rì àsà àti èdè Yorùbá bákannáà ni gbogbo àwọn ẹ̀yà kọọkan tún ní àsà ìwọsọ tí wọn. Àwọn obìnrín Ìjẹ̀sà maa nwọ àsọ̀ àfì tó jẹ́ Ìró àti bùbá bẹ́ni àwọn okùnrin wọn máà ń wọ esikí àti sòkòtò ẹlẹ́nu ńlá pẹ̀lú fìlà alabankata. (4) OGE SÍSE:-jẹ́ àsà tí o sábà maa ń súyọ láàárín àwọn obìnrin pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́. Àwọn obìnrin Ìjẹ̀sà máà n lo lali, tiro, osùn láti fi soge. Àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀sà. Àwọn Ìjẹ̀sà jẹ́ alákíkánjú àti jagunjagun ènìyàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ní àwọn Ìjẹ̀sà ni pa nínú rẹ̀, ní àkókò ogun kariaye ilè Yorùbá. Lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ìjẹ̀sà ja a ni ogun Ìbàdàn, ogun Jalumu àti ogun Kiriji tàbí ogun Ekìtì parapọ̀. Ogun Èkìtì parapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1877, o sì perí ní ọdún 1886. Ẹni tí ó jẹ́ bí asíwájú ogun pàtàkì yìí ni okùnrin alajagun Ìjẹ̀sà kan ti orúkọ rẹ ń jẹ́ Ògèdèngbé .Ogun Èkìtì parapọ̀ yìí ni ó mú orúkọ Ògèdèngbe dúró sinsin nínú ìtàn Yorùbá ogn náà si ja fún ọdún mẹsan gbáko ọdún 1910 ní ògèdèngbé kú. Ohun kan tí àwọn Ìjẹ̀sà se ni Ìrántí Ògèdèngbé tí ó jẹ́ olórí àwọn Ìjẹ̀sà wà ni eréjà Ilésà ní iwájú ilé Ìfowópamọ́ ti “National Bank of Nigeria Limited” lsẹ́ Àwọn Ìjẹ̀sà Gbogbo àwọn ẹ̀yà ìyókù ní ilẹ̀ Yorùbá ní wọ́n mọ àwọn Ìjẹ̀sà sí onísòwò paraku idi ni yi tí wọn fi ń pe àwọn Ìjẹ̀sà ni “Òsómàáló”. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí kà nínú ìwé, a gbọ́ pẹ́ àwọn Ìjẹ̀sà ni ó dá àsà san an díẹ̀dị́ẹ̀ sílẹ̀ nínú Ìsòwò. Wọ́n màá n lọ láti ìlú dé ìlú àti ìletò de ìletò láti se isẹ́ ọjà títà wọn, ohun tí wọn si n ta ní pàtàkì ní asọ. Sùgbọ́n lónìí Ìjẹ̀sà ti kúrò ni a n kiri láti Ìlú de ìlú tàbí Ìletò de Ìletò, wọ́n ti wà nínú ilé ìtajà ní àwọn ìlú ńláńlá bíi, Ìbàdàn, Èkó, Ìlọrin, Ògbómọ̀sọ́, Kano, Kaduna, òṣogbo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́hìn isẹ́ òwò síse ti a mọ si Òsómàló tí wọ́n máa ń kiri, wọ́n tún máa ń se isẹ́ àgbẹ̀ paraku nínú oko wọn, àwọn Ìjẹ̀sà a maa gbin kòkó, obì, isu, àgbàdo, káfé, ìrẹsì, àti orísì́ àwọn ohun jíjẹ míìràn. orísì àwọn isẹ́ míìràn tí àwọn Ìjẹ̀sà n se ni isẹ́ àgbẹ̀dẹ dúdú àti àgbẹ̀de góòlù, isẹ́ gbénàgbénà, asọ híhun, aró dídá àti orísi isẹ́ míràn. Àwọn ilé isẹ́ ti a lè rí ní ilésà ní “ International Breweries Limited Nigeria” ni ibití wọ́n ti ń se ọtí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Trophy Larger Beer” àti àwọn ohun amúlúdùn ti a lè rí ni ilésà lónìí ni iná mọ̀nàmọ́ná, pápá ìseré àti ilé ìtura. Ẹ̀sìn Àwọn Ìjẹ̀sà. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, kí àwọn òyìnbó tó kó ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá de orílè-èdè wa, àwọn Yorùbá ti ni ẹ̀́sìn ti wọn. llésà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ilẹ́ Yorùbá maa n sin àwọn òrìsà bii ògún, ọ̀sun, ifá, èsù, ọya àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ti o wá sí orilè - èdè yìí wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà ni nǹkan bíi ọdún mélòó sẹ́hìn ni a mọ̀ sí ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì, ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ó ti àwọn lárúbáwá wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì náà ni a ti rí Ìjọ Àgùdà (Catholic), Ìjọ onítẹ̀bomi (Baptist) Ìjọ Elétò (Methodist) Ajíhìnrere Kírísítì (Christ Apostelic Church) kérúbù àti séráfù (Cherubim and Seraphim) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìjẹ̀sà ní Ìmọ̀ tí ó gbámúsé ní pa ètò ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjẹ̀sà ni o di ipò gíga mú ní ilé isẹ́ ìjọba fún àǹfàní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn. tị́tí di àkòkò yìí ó tó nǹkan bí aadọta ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí ó wà ní igboro ilésà, ilé ẹ̀kọ́ girama méjìdínlógún àti ilé ìwé ẹ̀kọ́sẹ́ olùkọ́ onípòkejì méjì. Ni àfikún, ìjọba tún ti dá ilé- ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ olùkóni, fún ilé ẹ̀kọ́ giga sílẹ ni llésà ni ọdún 1977(Osun State College of Education) Àwọn òrìsà ilẹ̀ Ìjẹ̀sà Owari, Owaluse, Oludu, Oluaye, Ajitafa, Ogun, Omi/Osun. Sùgbọ́n àwọn òrìsà kò se bẹ gbilẹ̀ mọ́ ni ilẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ọ̀kan soso lalè ri níbú wọn ti o dàbí ẹni pé wọn sin se ọdún rẹ.
Iléṣà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2831
2831
Ẹ̀gbá Ẹ̀gbá je eya Yoruba ni Naijiria. Ilẹ̀ Ẹ̀gbá. Ó se pàtàkì láti mọ díẹ̀ nípa ìtàn ilẹ̀ Ẹ̀gbá àti irú ènìyàn tí ń gbé ìlú Ẹ̀gbá. Ìdí èyí ni pé yóò jẹ́ ohun ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó yẹ ní mímọ̀ nínú orin ògódò. Fún ìdí pàtàkì yìí, n ó ò pín àkòrí yìí si ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìtàn Ẹ̀gbá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ onímọ̀ ló ti sọ nípa bí a ti se tẹ ilẹ̀ Ẹ̀gbá dó, tí wọn sí tì gbé àbọ̀ ìwádìí wọn fún aráyé rí. Ara irú àwọn báyìí ni Samuel Johnson, Sàbúrì Bíòbákú, Ajísafẹ́, Délànà àti àwọn mìíràn tó jẹ́ òpìtàn àtẹnudẹ́nu. Johnson gbà pé Ọ̀yọ́ ni àwọn Ẹ̀gbá ti wá. O ní àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbá tòótọ́ lé ti orírun wọn de Ọ̀yọ́. ó tún tẹ̀ síwájú síi pé ọmọ àlè tàbí ẹrú ni Ẹ̀gbá tí kò bá ní orírun láti Ọ̀yọ́. Àwọn olóyè wọn wà lára àwọn Ẹ̀sọ́ Aláàfin láyé àtijọ́, àtipé àwọn olóyè yìí ló sá wá sí Abẹ́òkúta lábẹ́ olórí wọn tó jẹ́ àbúrò ọba Ọ̀yọ́ nígbà náà. Délànà ní tirẹ̀ ní etí ilé-ifẹ̀ ni àwọn Ẹ̀gbá tó kọ́kọ́ dé tẹ̀ dó sí. Àwọn ni ó pè ní Ẹ̀gbá Gbàgùrà. Wọ́n dúró súú sùù súú káàkiri. Olú ìlú wọn sì ni “ÌDDÓ” tí ó wà níbi tí Ọ̀yọ́ wà báyìí. Àwọn ìsí kejì sun mọ ìsàlẹ̀ díẹ̀. Wọ́n kọjá odò ọnà. Àwọn ni Ẹ̀gbá òkè-ọnà. Òsilẹ̀ ni ọba wọn. Òkó ni olú ìlú wọn .Ẹ̀gbá Aké ló dé gbẹ̀yìn. Ajísafẹ́ ní ọ̀tẹ̀ ló lé àwọn Ẹ̀gbá kúrò ni ilé- ifẹ̀ wá Kétu. Láti Kétu ni wọn ti wá sí Igbó- Ẹ̀gbá kí wọn to de Abẹ́òkúta ní 1830. Sàbúrí Bíòbákú náà faramọ́ èyí. Lọ́rọ̀ kan sá, àwọn Ẹ̀gbá ti ilé- ifẹ̀ wá, wọ́n ni ohun i se pẹ̀lú oko Àdágbá, Kétu, àti igbó-Ẹ̀gbá. Ìtàn tún fi yé ni síwájú sii pé ìlú Ẹ̀gbá pọ̀ ní orílẹ̀ olúkúlùkù ló sì ń ní ọba tirẹ̀, fífọ́ tí orílẹ́ Ẹ̀gbá fọ́ lò gbé wọn dé ibi tí wọ́n wà báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Ìtàn ti sọ, 1821 ni Ìjà tó fọ́ gbogbo Ìlú Ẹ̀gbá ti sẹlẹ̀. Ohun kékeré ló dá Ìjà sílẹ̀ láàárín àwọn òwu àti àwọn Ìjẹ̀bú ni ọjà Apòmù, Ogun Ọ̀yọ́ àti tí ifẹ̀ dà pọ̀ mọ́ ogun Ìjẹ̀bú láti bá Òwu jà. Àgbáríjọ ogun yìí dé ìlú àwọn Òwu ní tọ̀ọ̀ọ́tọ́ sùgbọ́n àwọn Òwu lé wọn padà títí wọ́n fi dé àárín àwọn Gbágùrá to wa ni Ìbàdàn. Inú àwọn Gbágùrá kò dùn sí è́yí wọ́n ti lérò pé ogun yóò kó àwọn Òwu. Èyí náà ló sì mú àwọn Gbágùrá tún gbárajọ láti pẹ̀lú ogun Ọ̀yọ́, Ìjẹ̀bú àti ifẹ̀ kí wọn le borí ogun Òwu. Wọ́n sẹ́gun lóòótọ́ sùgbọ́n lánlẹ́yìn, àkàrà Ríyìíkẹ́ ni ọ̀rọ̀ náà dà nígbẹ̀yìn. Òjò ń podídẹrẹ́ ni, àwòko ń yọ̀. Kò pẹ́ ẹ̀ ni ogun Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀sà, Ọ̀yọ́ àti ifẹ̀ rí i mọ́ pé àsé àwọn Ẹ̀gbá kò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ tẹ̀ǹbẹ̀ lẹ̀kun sí àwọn Ẹ̀gbá. Wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo Ìlú wọn tán lọ́kọ̀ọ̀kan. Èyí tí ó wá burú jù níbẹ̀ ni ti IKÚ Ẹ́GẸ́ tó jẹ olóyè ifẹ̀ kan. Lámọ́di asíwájú Ẹ̀gbá kan ló páa nígbà tí ǹ dìtẹ̀ mọ ọn. Sùgbọ́n àwọn ọ̀tá kò sàì pa òun náà sán. Ọ̀tẹ̀ àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun tí wọn ń dí mọ́ àwọn Ẹ̀gbá yìí ló mú wọn pinnu láti kúrò ní ibùjókòó wọ́n. Àwọn babaláwo wọn gbé ọ̀pẹ̀lẹ̀ sánlẹ̀, wọn rí odù òfúnsàá. Wọ́n kifá lọ wọ́n kifá bọ̀, wọ́n ní wọn yóò dé Abẹ́òkúta, àwọn aláwọ̀ funfun yóò sì wá láti bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn babaláwo wọn náà ni Tẹ́jú osó láti Ìkìjà Òjo (a ń-là-lejì- ogbè) ara Ìlúgùn àti Awóbíyìí ará irò. 1830 Sódẹkẹ́ lo sáájú pẹ̀lú àwọn Ẹ̀gbá Aké. Balógun Ìlúgùn kó Ẹ̀gbá òkè-ọnà kẹ́yìn. Wọn kò rántí osù tí wọ́n dé Abẹ́òkúta mọ́ sùgbọ́n àsìkò òjò ni. Nígbà tí wọn kọ́kọ́ dé, wọ́n do sí itòsí Olúmọ, olúkúlùkù ìlú sa ara wọn jọ, wọn do kiri Ẹ̀gbá Aké, Ẹ̀gbá òkè-ọnà àti Ẹ̀gbá Gbágùrá ló kọ́kọ́ dé sí Abẹ́òkúta. Ni 1831 ni àwọn Òwu sẹ̀sẹ̀ wá bá wọn tí àwọn Ẹ̀gbá sì gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Àwọn Ẹ̀gbádò tí wọ́n bá ní Ìbarà ló sọ wọ́n ni Ẹ̀gbá, nínú ọ̀rọ̀ “Ẹ̀GBÁLUGBÓ” ni wọ́n sì tí fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Àwọn òpìtàn ní àwọn Ẹ̀gbádò ni ń gbé ìpadò nígbà tí àwọn Ẹ̀gbá ní gbé ni òkè ilẹ̀. Òpìtàn míìràn tún ní ìtumọ̀ Ẹ̀gbá ni “Ẹ GBÀ Á “ lálejò nítorí pé wọ́n gba àwọn Òwu àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń wá abẹ́ ààbò sá sí mọ́ra. ÀWỌN Ẹ̀YÀ TÓ WÀ NÍLẸ̀ Ẹ̀GBÁ LÓDE ÒNÍ. Ẹ̀yà orísìírísìí tó wà nílẹ̀ Ẹ̀gbá ló jẹ́ kí ó di ìlú ń lá, pẹ̀lú ìjọba àkóso tó lágbára ogun ló sọ ọ́ di kékéré bó ti wàyìÍ. Ní apá Àríwá, ó fẹ̀ dé odò ọbà, ní gúúsù ó gba ilẹ̀ dé Èbúté mẹ́ta, lápá Ìlà Ìwọ̀ oòrùn (Ẹ̀gbádò) Johnson ní ìlú mẹ́tàlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ́ta (503) ló parapọ̀ dé Abẹ́òkúta lonìí yìí. Orísìí mẹ́rin ni àwọn Ẹ̀gbá tó wà ní Abẹ́òkúta lónìí. Kò parí síbẹ̀ àwọn miiran tún wà tí wọn ti di Ẹ̀gbá lónìí. Sé tí ewé bá pẹ́ lára ọsẹ, kò ní sàì di ọsẹ. Èkíní nínú àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbà yìí ni Ẹ̀gbá Aké. Orísìírísìí ìlú ló tẹ̀ ẹ́ dó, ìdí nìyí tí àwọn Ẹ̀gbá tó kù se ń sọ pé “Ẹ̀GBÁ KẸ́GBÁ PỌ̀ LÁKÉ”. Aké ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá Aké ni Ìjokò, Ìjẹùn, Ọ̀bà, Ìgbẹ̀Ìn, Ìjẹmọ̀, Ìtọ̀kú, imọ̀, Emẹ̀rẹ̀, Kéesì, Kéǹta, Ìrò, Erunwọ̀n, Ìtórí, Ìtẹsi, Ìkọpa, Ìpóró ati Ìjákọ. Ẹ̀gbá òkè-ọnà ló tẹ lẹ́ Ẹ̀gbá Aláké. Osìlè ni ọba wọn, oun ni igbákejì Aláké. Òkò ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá òkè -ọnà ni Ejígbo, Ìkìjà, Ìjẹjà, odo, Ìkèrèkú, Ẹ̀runbẹ̀, Ìfọ́tẹ̀, Erinjà, ilogbo àti Ìkànna. Ẹ̀gbá Gbágùrá ni orísìí kẹta. Ìdó ni olórí ìlú wọn. Àgùrá si ni ọba wọn. Àwọn Ìlú to kù ni ọ̀wẹ̀, Ìbàdàn, Ìláwọ̀, Ìwéré, òjé ati àwọn ìlú mọ́kàndínlógoji (39) mìírán.Nígbà tí ogun bẹ sílẹ̀ ni mẹ́sàn-án lara ìlú Gbágùrá sá lọ fi orí balẹ̀ fún Ọlọ́yọ̀ọ́ títí di òní yìí. Àwọn ìlú naa ni Aáwẹ́, Kòjòkú Agéníge, Aràn, Fìdítì, Abẹnà, Akínmọ̀ọ́rìn, Ìlọràá àti Ìròkò. Ẹ̀gbá Òwu ni orísìí kẹrin, Àgó-Òwu ni olú ìlú wọn, Olówu ni ọba wọn, ìlú tó kù lábẹ́ Òwu ni Erùnmu, Òkòlò, Mowó, Àgọ́ ọbà, àti Apòmù. Yàtọ̀ sí àwọn tí a sọ̀rọ̀ rẹ lókè yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà míìràn náà ló pọ̀ ní Ẹ̀gbá tí wọ́n ti di ọmọ onílẹ̀ tipẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn báyìí ni a kó lásìkò ogun tàbí kí wọn wá fúnra wọn nígbà tí wọn ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, tí wọn sì ǹ wá ibi isádi. Irú àwọn báyìí ni Ègùn tí wọn wá ni Àgọ́- Ègùn, Ìjàyè- ni Àgọ́- Ìjàyè, àti àwọn Ìbàràpá ni Ìbẹ̀rẹ̀kòdó àti ni Arínlẹ́sẹ̀. Bákannáà ni àwọn Ẹ̀gbádò wà ní Ìbàrà iléwó, onídà àti oníkólóbó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí sáájú Ẹ̀gbá dó síbẹ̀. ÈTÒ ÌSÈLÚ ÀTI TI ỌRỌ̀ AJÉ ILẸ̀ Ẹ̀GBÁ. Láti ìgbà tí àwọn Ẹ̀gbá ti dó sí Abẹ́òkúta ni ètò ìsèlú wọn ti bẹ̀rẹ̀ si yàtọ̀. Ó di pè wọn ń yan ọba kan gẹ́gẹ́ bí olórí gbogbo gbò. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, kọ́lọ́mú dọ́mú Ìyá rẹ gbé ni. Èyí náà ló sì fìyà jẹ wọ́n. ÀÌrìnpọ̀ ejò ló sá ǹ jẹ ejò níyà.Sé bọ́ká bá síwájú, tí pamọ́lẹ̀ tẹ le e, tí baba wọn òjòlá wá ń wọ́ ruru bọ̀ lẹ́yìn, kò sí baba ẹni tó jẹ dúró. Ọ̀rọ̀ “èmi –ò-gbà ìwọ -ò -gbà” yìí ló jẹ́ kí àwọn alábàágbé Ẹ̀gbá maa pòwe mọ́ wọn pe “Ẹ̀gbá kò lólú, gbogbo wọn ló ń se bí ọba” Ọba wá di púpọ̀. Ìjọba ìlú pín sí ọ̀nà bíi mẹ́rin nígbà tí ọ̀kan wọn balẹ̀ tán ni ibùdó titun yìí. Àkọ́kọ́ nínú wọn ni àwọn Ológbòóni. Ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ẹgbẹ́ yìí fún ra rẹ̀. Lóòtọ́, ọba ló nilẹ̀, òun ló sì ń gbọ́ ẹjọ́ tó bá tóbi jù. Sị́bẹ̀ síbẹ̀, àwọn Ògbóni lágbára ju ọba lọ. Àwọn ni òsèlú gan-an. Àwọn ló ń pàsẹ ìlú. Wọn lágbára láti yọ ọba lóyè. Delanọ ní láti ilé-ifẹ̀ ni Ẹ̀gbá tí mú ètò Ògbóni wá. Wọn tún un se, wọn sì jẹ́ kí o wúlò tóbẹ́ẹ̀ tí ilé-ifẹ̀ pàápàá ń gáárùn wo ògbóni Ẹ̀gbá. Orò ni wọn ń lò láti da sẹ̀ríà fún arúfin ti ẹ̀sẹ̀ rẹ tòbi. Bí orò bá ti ń ké ní oru yóò máa bọ̀ lákọlákọ. Olúwo ni olórí àwọn ògbóni. Àwọn oyè tó kù tó sì se pàtàkì ní Apèènà, Akẹ́rẹ̀, Baàjíkí, Baàlá, Baàjítò, Ọ̀dọ̀fín àti Lísa{. Àwọn olórógun tún ní àwọn ẹgbẹ́ kejì tó ń tún ìlú tò. Láti inú ẹgbẹ́ àáró tí ọkùnrin kan ti n jẹ Lísàbí dá sẹ́lẹ̀, ní ẹgbẹ́ olórógun ti yọ jáde. Ọjọ́ kẹtàdínlógún kẹtàdínlógún ni wọ́n ń se àpèjọ wọn. Àwọn náà ló gba Ẹ̀gbá kalẹ̀ lọ́wọ́ ìyà tí Ọlọ́yọ̀ọ́ àti àwọn Ìlàrí rẹ fi ń jẹ wọn. Ara àwọn oyè tí wọn ń jẹ ni jagùnà (ajagun lójú ọ̀nà) olúkọ̀tún (olú tí Í ko ogun òtún lójú), Akíngbógun, Òsíẹ̀lẹ̀ àti Akílẹ́gun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ni wọn si ti sẹ. Àwọn pàràkòyí náà tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ọrọ ba di ti ọrọ̀ ajé àti ìsèlú. Àwọn ni n parí ìjà lọ́jà, àwọn ló n gbowó ìsọ ̀. Asíwájú àwọn pàràkòyí ni olórí pàràkòyí. Àwọn ọdẹ pàápàá tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn atúnlùútò. Wọ́n ń dá ogun jà nígbà mìíràn. Àwọn ni wọn n sọ ọjà àti gbogbo ìlú lóru. Àwọn olóyè ọdẹ jàǹjàǹkàn naa a maa ba àwọn tó wà ní ìgbìmọ̀ ìlú pésẹ̀ fún àpérò pàtàkì. Díẹ̀ lára oyè tí wọn n jẹ ni Asípa, olúọ́dẹ àti Àró ọdẹ. Bí ọ̀rọ̀ kan ba n di èyí ti apá lé ko ka, o di ọdọ olórí àdúgbò nì yẹn. Bí kò bá tún ni ojútùú níbẹ̀, a jẹ́ pé ó di tìlùú nì yẹn ọba lo maa n dájọ́ irú èyí nígbà náà. Tí a bá ka a ni ẹní , èjì ó di ọba mẹsan an to ti jẹ láti ìgbà ti wọn ti de sí Abẹ́òkúta. Àwọn náà nìwọ̀n yii ORÚKỌ ỌBA ̀ TÍ Ó JẸ . ÀKÓKÒ TÍ Ó KÚ. ÒKÚNKẸ́NÚ 28/08/1854 31/08/1862 ADÉMỌ́LÁ 28/11/1869 30/12/1877 OYÉKÀN 18/01/1878 18/12/1881 OLÚWAÁJÌ 09/02/1885 27/01/1889 SÓKÁLÙ 18/09/1891 11/06/1898 GBÁDÉBỌ̀ 08/08/1898 28/05/1920 ADÉMỌ́LÁ II 10/07/1920 27/12/1962 GBÁDÉBỌII 12/08/1963 26/10/1971 LÍPẸ̀Ẹ́DẸ́ I 10/08 1972 …………… Yàtọ̀ sí ọba Aláké tí a to orúkọ wọn sókè yìí, ọba mẹ́rin míìrán tún sì wà ní Abẹ́òkúta tí wọn ń se olórí ìlú wọn. Sùgbọ́n, gbogbo wọn tún sì wà lábẹ́ aláké gẹ́gẹ́ bii ọba gbogbo gbò ni. Àwọn ọba náà ni, Àgùrà Olówu, Òsilẹ̀ àti olúbarà. Ọba aládé sì ni gbogbo wọn. Ní ti oyè tó kù nílùú, o ní agbára tí wọn fún ìlú kọ̀ọ̀kan láti fi olóyè sílẹ̀. Ẹ̀gbá òkè- ọnà ló ń yan ọ̀tún ọba. Ẹ̀gbá Gbágùrá lo n fi òsì àti Òdọ̀fin sílẹ̀. Ẹ̀gbá Òwu lo si n yan Ẹ̀kẹrin ìlú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jàǹkànjàǹkàn tó ti fi ẹ̀mí wọn wu ewu fún Ẹ̀gbá ni wọ́n máa ń ráńtí nínú gbogbo orin wọn. Wọn a sì máa fi orúkọ wọn búra pàápàá. Irú àwọn báyìí ni Sódẹkẹ́, Lísàbí, Ẹfúnróyè, Tinúubú ati Ògúndìpẹ̀ Alátise. Àwọn Ẹ̀gbá kò kó iyán wọn kéré wọn kò sì yé bu ọlá fún wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú. Orísìí ètò ìjọba mẹ́rin ọtọ̀ọ̀ọ̀tọ̀ ni ó ti kọjá ní ilẹ̀ Ẹ̀gbá kí á tó bọ sí èyí tí a wà lóde òní. Ètò ìbílẹ̀ lábẹ́ àsẹ Ògbóni àti Pàràkòyí 1830-1865 Ẹ̀gbá United Board of Management 1865-1898 Ẹ̀gbá United Government (Ìjọba Ẹ̀gbá) 1898 – 1914 Ẹ̀gbá Native Administration (Ìjọba Ìbílẹ̀) 1914 – 1960 ISẸ́ ÀWỌN Ẹ̀GBÁ. Orísìírìsìí isé ajé ni àwọn Ẹ̀gbá n mú se nínú ìlú. Yàtọ̀ sí isẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ tajá tẹran ló ń seé wọ́n fẹràn láti máa da aró, wọ́n mọ̀ nípa àdìrẹ ẹlẹ́kọ dáadáa. Wọ́n tún nífẹ̀ẹ́ si òwò síse. Àwọn àbọ̀ ilẹ̀ sàró ni ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ òwò síse yìí túbọ̀ gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Kò sí ìlú kan tí kò ní ọjà tirẹ̀, sùgbọ́n àwọn ọjà ń lá kan wà tó ti di ti gbogbo gbo. Irú àwọn ọjà báyìí ni Ìtọ̀kú, Ìta Ẹlẹ́gà, ọjà ọba àti Ìbẹ̀rẹ̀kòdó. Paríparí rẹ̀ àwọn Ẹ̀gbá fẹ́ràn láti máa kọrin lásán.yálà kíkọ tà gẹ́gẹ́ bí alágbe tàbí ìfẹ́ láti máa kọrin lásán. Gbogbo ohun tó sì ti sẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wọn ni wọ́n máa ń mú lò nínú orin wọn pàápàá. ÌBÁSEPỌ̀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN ÀWỌN Ẹ̀YÀ Ẹ̀GBÁ. A ti sọ pé kálukú ẹ̀yà Ẹ̀gbá ló ń da ọmú ìyá rẹ̀ gbé, sị́bẹ̀, kò sàìsí ìbásepọ̀ díẹ̀ láàárín wọn. Lọ́nà kìnní, gbogbo Ẹ̀gbá ló gbà Abẹ́òkúta sí ìlú wọn.Wọn ni ilẹ̀ níbẹ̀, sùgbọ́n wọn a máa lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti lọ múlẹ̀ oko. Ní ìparí ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń wálé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú oko ẹ̀yìn odi ìlú báyìí lo ti di ìlú fún wọn. Abúlé ni wọn n pe àwọn ìletò wọ̀nyí. Kò sí ọmọ Ẹ̀gbá kan tí kò ní abúlé . Ètò abúlé wọ́ pọ̀, ó sì gún régé, Baálẹ̀ tàbí olóróko (olórí oko) ni o wà ní ipò ọ̀wọ̀ jùlọ. Bákan náà ló jẹ́ pé gbogbo wọn lo jọ ń bú ọlá fún àwọn ẹni ńlá wọn. Kò sí pé apá kan kò ka àwọn ẹni àná yìí wọ̀nyìí́ kún. Orò tún jẹ́ ẹ̀sìn kan tó so wọ́n pọ̀. Nílélóko ni wọn ti ń sọdún orò lọ́dọọdún. Àwọn olórò ìlú kan lè mú orò wọn dé ìlú mìíràn láìsí ìjà láìsí ìta. Lóòótọ́, ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní òrìsà tirẹ̀ tó se pàtàkì, fún àpẹẹrẹ, àwọn Òwu ló ni Òtòǹpòrò àti Ẹlúkú. Àwọn Odò ọnà ló ni Agẹmọ, àwọn ìbarà lo ni Gẹ̀lẹ̀dẹ́. Òrìsà Àdáátán, ọ̀tọ̀ ni. O máa ń sẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ìgbà pé tí ìlú kan bá parí ọdún tiwọn lónìí, tí àdúgbò míìràn le bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ keje ẹ̀. Èyí kò sí yi padà láti ọjọ́ pípẹ́ wá. Ọjà kan náà ni wọn jọ́ ń ná, oúnjẹ ti wọn ń jẹ ní Aké ni wọn ń jẹ ní Òkò. Wọn fẹ́ràn àmàlà láfún púpọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń jẹ Sapala kòkò, ewé, awújẹ àti èsúrú. “Mo lérò pé pẹ̀lú gbogbo àlàyé mi òkè yìí ìrànlọ́wọ́ ni yóò jẹ fún àwọn ohun ti a ó ò máa kan nínú orin Ògóló níwájú, àwọn ọ̀rọ̀ tí ìbá si ru ni lójú tẹ́lẹ̀ ni yóò di ohun ti yóò tètè yé ni”.
Ẹ̀gbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2835
2835
Ilẹ̀ Ọba Bakuba Ilẹ̀ọba Bakuba (o tun nje Kuba tabi Bushongo) Ifáárà: Àwọn kúbà náà ló ń jẹ Bushoong. ÀÀYÈ WỌN. Ààrin gbungban gusu (Congo Zaire) ni wọ́n wà IYE WỌN. Ẹgbẹ̀riún mẹ́tà-dún-lóguń ni wọn ÈDÈ WỌN. Ede Bushhoog ló jẹ́ ẹ̀yà Bàǹtú ni wọn ń sọ ALÁGÀÁGBE WỌN. Biombo, lùbà, kasai, lenda, pyaang, àti Ngongo ÌTÀN WỌN. Awọn Bushoog ni ẹ̀yà tó pọ jù ni kńbà.Baba-ńlá wọn ló tẹ ibẹ̀ dó. Abẹ́ Ìṣèjọba Shyaan kan soso bi gbogbo wọn wà. Òun ló ń darí wọn. Apá ìwọ̀-oòrùn ni wọ́n ti wá sí tí wọ́n etí Máńgò wọn bá àwọn ìwa àti kété sì parapọ̀ ṣe ìjoba kúbà. IṢẸ́ ỌNÀ WỌN Àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ọnà tí àwọn adarí ìjọba àti àwọn mẹ̀kúnǹu ń lò bí :- - Ìlù ìbílẹ̀ tí - Ìwo tí wọ́n fi n] mu ọti - Ìjókòó ọba - Idà ọba - Ọ̀pá aṣẹ́ àti - Abẹ̀bẹ̀ ọba ỌRỌ̀ AJÉ WỌN. - Wọ́n ń pẹja - Wọ́n ń hun aṣọ - Wọ́n ń dáko pákí, àgbàdo àti ọka ̀ bàbà - Obiǹrin wọ́n ń ṣòwo ̀ káàkiri agbègbè wọn ÌṢÈLU WỌN. Awọn Bushoog ló ń darí Kuba. Olú ìiú wọn ni Nsheng. Ó le ní ọgọ́ruǹ-ún aṣojú fún ìgbèríko kọ̀ọ̀kan. Òfin ati ìlànà ọba Nyimu wọn ń tẹ̀̀ lé oba shyaam ni ọba àkọ́kọ́. Àwọn ọba mọ́kaǹlélógún ló sì ti jẹ lẹ́yìn rẹ̀. o ti ló iríniwó ọdún ṣẹ́yìn tie ̀tò ìjọba náà ti bẹ̀rẹ. Ẹ̀siǹ WỌN. Bumba ni ẹdá àkọ́kọ́ nínú ìtàn ìgbà ìwáṣẹ̀ won. Òun ló fí awọn Bushoong se asíwájú àti olórí -Ẹ̀sin Baba ńlá wọn ni wọn ń sìn. Ẹ̀sín ọ̀ún ti ń ku lọ díẹ̀díẹ̀. Síbẹ̀, Ìfá tabi Adábigbá ń gbé láàrin wọn. Wọn gbà pè òròṣà ló ko oríre bá wọń. Ère ajá ni wọṅ ń sí ojúbọ òrìsà wọṅ . Ère yìí ló dúró bí olúgbàlà wọn.
Ilẹ̀ Ọba Bakuba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2838
2838
Kuwere KWERE Kuwere ÀÀYÈ WỌN Wọ́n wà ní apa ìwọ-oòrun ààrin gbuǹgbùn Tanzania. IYE WỌN Wọn lè ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta eǹìyàn ÈDÈ WỌN Èdè kikwer (ti Bàǹtú ni wọ́n ń sọ ALÁBÀÁGBÉ Zaramọ, Doe, Zingna, Luguru àti Swahili. ÌTAǸ WỌN Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣẹ́yìn ni baba ńlá Kwere de láti Mozanbique.Nínú ìrìn-àjò wọn ni wọ́n ti bá àwọn eǹìyaǹ Swahili tí wọn di mùslùmí pàdé wọn fìdí tì sí ibẹ̀ pẹ̀lu àwọn alábàágbè wọn bí Zeramo ati Doe ÌṢẸ̀LÚ WỌN Àwọn Kwere ò ni ìjọba àpapọ̀ Ijọba ìletò,ijọba abúlé àti ìjọba ìlú-síluń ní wọ́n ní Àgbà àdúgbò ló ń fi olórí jẹ. Olórí ló ní aṣẹ ilè ìran. Òun si ni ètùtù ìlu wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ọkúnrin ni olórí sáábà ń jẹ́. òun ló ń pàrí ìjà láàrin ẹbi. Agbára ńlá, ọwọ́ rẹ̀ ló wà . Òun náà ló ni agbára tí a fi ń bá èmi àìrí sọ̀rọ̀. ỌRỌ̀ AJÉ WỌN Àgbẹ̀ paraku ni wọ́n. Wọ́n ń gbinsu, gbìngẹ̀, gbìngbàdo. Wọ́n ń gbin òwú àti tábá. wọ́n ń sin ẹranko àti ẹyẹ wọn a sì tún máa ṣe ọ̀sin eja. IṢẸ̀ ỌNA WỌN Awọn KWERE máa ń gbéji rèbété. Ẹ̀sìn WỌN Kwere gba ọlọ́run ńla (MuLUNGU) gbọ́ ọlọ́run ỳí ló ń ròjò ìdíle kọ̀ọ̀kan ló ní òrìṣà tí wọn ń kè pè. Wọ́n gbà pé ọlọ́run nla] ń ran àrùn àti òfò sí wọn. Òkú ọ̀run ló ń gbè ẹ̀bẹ̀ wọn lọ aí ọ̀dọ̀ ọlọ́run ńlá wọn. Òrìṣà-ló ń wo ọjọ́ iwájú fún wọṅ ni MGANGA. Òun ní í sọ ọ̀nà abayọ sí àdánwò tó bà dé bá wọn.
Kuwere
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2839
2839
Kiwahu KWAHU Kiwahu ÀÁYÈ WỌN Wọ́n wà ní apá Àríwá Ghana IYE WỌN Wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún márún –lé lọ́gọ́ta. ÈDÈ WỌN Ède Akàn ti ẹ̀yà Twini wọn ń fọ̀ ALÁBÀÁGBÉ WỌN ANYI, Asante àti Fante ÍTÀN WỌN Ẹ̀yà Akan tó ń gbé Àríwá Ghana ni Kwahu. Ìjọba ńlá Akàn bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí sẹ́ńtúrì mẹ́tàla] sẹ́yìn. Àsìkò yìí ni ìjọba ńlá Asanti bẹ̀rè òwò góòlù Àwọn ìpi]nlẹ̀ kéékèèke díde láti gba òmìnira lábẹ́ Denkyira lábẹ aláẹẹ Kumasi Àgbáríjọ Akàn sí lágbára ìsèlú àti ọrọ̀ aje. ÌṢÈLÚ WỌN Ìdílé kọọ̀kan ló ní ètò ìṣèlú àti òfin wọn. Olórí okó wà, olórí àdúgbò wà, olori agbègbè wà, mọ́gàjí náà sì wà tó fi dorí ńla Asante. Agbàra ńlá jẹ̀ orírun rẹ̀ dà Asante nìkan tó le jẹ olórí agbègbè tábí ìlú. Títí di àsìkò yìí ni àwọn Asante ń kópa nínú etò ìSèlú Ghana IṢẸ̀ ỌNÀ WỌN - Wọ́n máa ń ṣe Bojì lósọ̀ọ́ - Wọ́n ń gbégi lére. (wọ́n ń ìjòkó obínrin - Wọ́n ń ṣe ìlèkùn tí a mọ̀ Akuaba - Wọ̀n ń mọ ìkòkò - Wọ́n ń hun aṣọ̣(Aṣọ kéúté tó gbajúmọ̀ jù ní ilẹ̀ Àfírikà ẸSIN WỌN - Ìtàn ìgbà ìwáṣẹ̀ wọn kan sọ pè ọlọ́ru ńlá wọn sún mọ wọn. Ó sì ń bá wọn ṣeré. porporo gígún odó tí àwọn arígnṕ wọn ń gún ló ń han ọlọ́run-ńlá wọ́n létí tó fi bínú fi òrin ṣe ibújókòó. Àwon Akan ń bá ọlọ́run-ńlá wọn sọ̀rọ̀ tààràtà. Oríṣíríṣòí (Abosom) Òrìṣà ni wọ́n mó pèlú wọ́n mó ọ̀run wọn òrìṣa obìrin náà wà nídìí ìgbèbí.
Kiwahu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2841
2841
Laka LAKA Laka. ÀÀYÈ WỌN Grúsù ìls̀ oòrùn chad ni wọ́n wà IYÈ WỌN Ẹgbèrún lọ́nà ọgóruǹún ÈDÈ WỌN Lake àti Mbonu (Niger-Congo) ni wọ́n ń ṣo ALÁBÀÁGBÉ WỌN Sára, Èèyan Cameroon àti Fúlaní ni múlé tí wọ́n ITAN WỌN Àríwá ìlà oòruń oko chad ni wọ́n ti ṣẹ. Ijọba ńlá tí Fúlàní ló wọn dèbi wọ́n wà yìí. Èdè àti aṣa wọn àti ti Cameroon tó jẹ́ bákan náà. ÈTÒ ÌṢÈLÚ WỌN Eto ìṣè ijọba abúlè wọ́n jẹ́ ti ẹlẹ́bí baba. Olórí febí wọn gbọ́dọ́ le tan orírun wọn sí ọ̀dọ̀ baba ńlá Laka. Olórí yìí ló sì ń ṣe ìfilọ̀ ètò àgbẹ̀ ỌRỌ̀ AJÉ Owú ni wọ́n fi ń sọwó sókè òkun. Agbàdo, bàbà àti ohun ẹnu ń jẹ ló pọ̀ lọ́dọ̀ wọn Àsíkò òjọ nikan ni wọn le ṣe ògbìn nǹkan wòńyi. IṢẸ́ ỌNÀ WỌN Àwọn ló ń ṣọnà sí ara. Èyí ni wọn ń lò nígbà aápọ̀n tabi obitan Ẹ̀SÍN WỌN Ẹbi wọn sì ń pèṣè fún àwon òkú ọ̀run wọn lójoojúmọ́. B. LAKA Orúkọ èdè yìí ni a mọ̀ sí Lákà; tí orúkọ rẹ̀ mìíràn a tún máa jẹ́ Kabba Laka. Èdè adugbo wọn ni a mọ̀ sí Bemour Goula, Mang Maingao pai. Aarin gbungbun ilẹ Chad ni wọn ti n sọ o; wọ́n sì jẹ́ ibatan pẹ̀lú Nilo-Saharan. LAP ni ami tí wọn kọ́kọ́ ń lò dípò èdè Ganda. Àwọn àmì ẹka wọn la mọ̀ sí N S B B A C B A..
Laka
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2843
2843
Luba LUBA ÀÀYÈ WON Àríwa iwọ oòrùn Congo (Zaire) IYE WỌṄ Mìlíonù kan ÈDÈ WỌṄ CILUBE (Ààrin gbùngbùn Bantu) ALÁBÀÁGBÉ WỌN Chowe, Ndembu, Kaonde, Benba, Tabwa, Songye, Lunda. ITAN WỌṄ Ijọba ńlá Luba ti bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ọdún sẹ́yin 1,500. Ìjọba yìí ń gbòòrò láti Upemba tí Í ṣe ààrin gbuńgbún Lube. Wọn fẹ̀ dé iòkè Tangayika lábẹ́ llnngh Sungu tí í ṣe olorí wọṅ ní 1760-1840. Ó gbòòrò de apá àríwá àtiu gusu ní 1840 lábẹ́ iiungo kablee. Igbà tí olórí yà papòdà ni awọṅ Láíubáwó amúnilérú àti àwọn òyìbó anúnisìn sọ ìjọba ńlá wọn di yẹpẹrẹ. ÌṢẸ̀LU WỌṄ Ìjọba àpapọ̀ ni wọṅ ń ṣe Aláyèlúwà (Mulopwe) ni olórí wọn. Awọṅ ìlú kèkerè ń wárì fún Mulopwr. Òun ìlú àti olórí ẹgbẹ́ Bambulye ỌRỌ̀ AJE WỌN Iṣẹ òwò iyò àti iru ni àwọṅ ọlọlá wọn tún ń ṣe àgbe iṣẹ ọdẹ ẹran àti ti ẹja tún wó pọ̀ láàrin wọn. IṢẸ́ ỌNA WỌṄ Iṣẹ́ agbẹ̀gilére ni iṣẹ] wọn. Ère ló ń ṣègbè fún abọ ni wọṅ ń gbẹ̀. Wọ́n tún ń gbẹ̀ ère àgba tí a mọ̀ sí (Mboko) Ẹ̀SÌN WỌN Àwọṅ baba ńlá wọn ni wọṅ ń bọ. Ọba wọṅ gan0an ló ní òriṣà.
Luba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2846
2846
Bangubangu Bangubangu je eya kan ni Afrika. Èdè wọn ni wọn ń pè ni Bantu, wọ́n tún lè pè é ni kiban gubangu, èdè, yìí pin si ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ede méjìlá nínú èdè bantu ni ògọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tó lè ni mílíọ́ọ́nù márùn-ún ń sọ, lára àwọn tí ó ń sọ èdè Bantu ni Rundi, Rwanda, Shona, Xhosa àti Zulu, Swalili. Èdè Olóhùn ni èdè yìí fún àpẹẹrẹ ní Zulu, íyàngà túmọ̀ si dókítà, nígbà tí ìyángá túmọ sí òṣùpá.
Bangubangu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2849
2849
Baule Baule tabi Baoule je eya eniyan ni Afrika. Baule jẹ́ àwọn ènìyàn Akan tí a lè rí ní Ghana àti Cote d'Ivoire, èdè wọn ni kwa tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú èdè tí ó wà ẹ̀yà Niger Congo, èdè kwa jẹ́ èdè àdúgbò àwọn Akan, àwọn baule náà máa ń sin àwọn òrìṣà, iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ wọn.
Baule
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2851
2851
Beembe Beembe Àwọn beembe ń gbé ni àríwá Zaire ni Congo (Brazzaville) ọ̀nà méjì ni wọ́n ti wá sí beembe, àwọn kan ti ń gbe ibẹ̀ láti ọdún 1485, nígbà tí àwọn yapa láti Congo nígbà ogun Portuguese ni Ọdun 1665.
Beembe
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2853
2853
Betsileo Àwọn Betsileo jẹ ẹ̀yà ará àwon Àfíríkà tí wọ́n ń gbe ní Madagascar, àgbẹ̀ ni wọn, wọ́n máa ń gbé nínú ahéré ti wọ́n fi ewé ṣe, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, ó jẹ́ ìkan nínú àwọn èdè Malagasy.
Betsileo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2854
2854
Betsimisaraka Betisimisaraka je eya Malagasy. Ó jẹ́ èdè kan lára èdè Malagasy, iṣẹ àgbẹ̀ ni àti iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi wiwa (Sailor) àti olè ojú omi (Pirate). Láàrin ẹ̀yà Madagascar àwọn ẹ̀yà Betsimisaraka jẹ́ ẹ̀yà kejì tí ó tóbi jù.
Betsimisaraka
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2858
2858
Sadiiki Chadic Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ New man (1992:253) ó ṣọ́ pe o to nǹkan bi ogóje èdè Chadic gẹ́gẹ́ bí maapu ṣeṣe àfihàn ó tanka èka mẹ́fa nínú ajúwe lati adagun odo Chad nibi tí orúkọ ìdílé ti sẹ̀ wa ti a ṣi ń sọ ni apá kan nìjìríà, Chad Cameroon orílẹ̀ èdè Arìngbùngbùn ilẹ́ Áfíríkà olómìnira àti Niger. Èyí tí ó dára ju tí ó si tan káàkiri ti á ń ṣọ ní èdè Chadic tí a mo si Hausa, tí ó jẹ pe ti á ba fi mìlọnu àwọn tí wọn ń ṣọ èdè kejì ti a ba wo ìgbéléwọ̀n náà a ó ri gẹ́gẹ́ bí èyí to tóbi jù nínú àwọn adúláwọ̀ to n ṣọ èdè náà tì ó sì je pé à yọ Arabiki kúrò ninú rè. Àwọn yòókù tí wọn ń sọ èdè Chadic kò jú ẹgbẹ̀rún kan nìgbà tó o jẹ́ pé àwọn yòókù ko ju perete lọ Newman(1977) wọn pin àwọn Chadic si mẹrin (2) Bio-Manchaca ni èdè tí wọ́n ń ṣọ ni agbègbè Àríwá Cameroon àti Àríwá ìlà Òòrùn Nígiria pẹlu Chad àwọn ẹka mẹta nígbà tí ìkan jẹ mẹjọ, ti a si ṣe àfihàn rẹ lati Ọwọ Tera (50) Bura (250), Kanwe (300), Lamang (40), Mafa 9138), Sukur (15), Daba (36) àti BaChama-Bata 300. Àwọn méjì nínú ẹ̀ka méjì a le ṣe àfihàn wọn láti Ọwọ Buduma (59) ati Musgu (75) Ìpele Kẹta kun fún èdè ẹyọ kan Gudar (66) (3) Èdè Chadic ní wọn ń ṣọ ní Chad Gusu àti diẹ lára Cameroon àti àringbìngbìn ilé Áfíríkà olómìnira. Èdè náà ní ẹ̀ka méjì tí ó kún fún ẹgbẹ́ ìṣọ̀rí mẹta mẹta tí ó ni ẹka a ṣe àfihàn iṣupọ lórísìíríṣí Ọwọ Kera *51) púpọ̀ nínú àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí a le ṣe àfihàn rẹ lati Ọwọ Dangaleat (27) ati Mokulu (12), àti lowo Sokoro (5) (4) Masa jẹ èyí tí ó gba Ominra tí ó ṣi kún fún orísi, mẹ́san láti ìwọ̀ Òòrùn Gúsù Chad àti Àrìíwá Cameroon. Ní àfikún Masana (212) Musey 120 èyí tí ó sún mọ́ ní Zumaya
Sadiiki
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2860
2860
Sẹ̀mítíìkì Semitic Semitiiki Semitic ni àwọn ènìyàn ka ju ti o ṣi ye wọn jù síbẹ̀ àwọn èdè kan wa ti wọn kò mọ rárá nipá ṣiṣe arópò extant ati extinet kan. Semitic ṣe ipatẹ adọọfa lorisiirisi. Nípa ìṣàkóṣo ti ìbílẹ̀ wọn ṣùgbọ́n dọsini kan àbọ̀ lo wà lábẹ́ ìṣàkóṣo àwọn Arabiki, ṣùgbọ́n àwọn kan rò wípé ko ba ojú mu lati ṣe bẹ. Àwọn Oludari kan gba pe Semitic a le ri orukọ wọn ni àríwá ìlà Oòrùn, àríwá Iwọ Òòrun àti Guṣu lábẹ́ ipin ẹka ìdílé kan ṣùgbọ́n aríyanjiyan wa lórí pe bóyá Arabiki wa ni ariwa ìlà Oòrun tàbí pẹ̀lú ẹ̀ka ìdílé Gúṣù. Arákùnrin tí Orúkọ rẹ̀ ń jẹ Hetzron (1972: 15-16)5 ṣe àríyànjiyàn lórí ipò (1) Ẹka ìdílé àríwá ila Òòrun wa láti Akkadian, nítorí èdè to ti paré tó jẹ́ ayé òlàjú tó ti kọjá lọ ti àwọn Assyrians àti Babylonians nígbà to ṣi jẹ pé Akkadian wà ní lílò fún nǹkan bi Ọdún meji miliniọnu títí di àkókò ayé jésù Hetzron pin àríwá ìwọ̀ Oòrùn Semitiki si àringbùngbùn àti Gúṣù àríwá ṣi ẹ̀ka. Ti àwọn Ìsáájú dúró fún Aramaic ní àṣìkò ìgbà ayé àtijọ́ ati tí ode òní orisiirisi Aramaic ni wọ́n ń ṣọ lati nǹkan bí Centiuri mẹwa BC. Ṣẹ́yìn. nǹkan bì Centiuri mẹ́fà sẹ́yìn àwọn kirisitẹni Aramaic nìkan ní ó jẹ́ èdè to gbalè nígbà náà bi ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn èdè tí á ń ṣọ ni ìlètò ti tàn Kariaye ìwọ̀ Òòrùn Aramaic /ma’lula(15) Turoyo (70) èdè tí á ń pe láàrín àwọn Olùṣo èdè ní Assyrian (200). 2. Ẹka arìngbùngbùn Guṣu ní èyà Canani tí a pín ti ó dúró fún èdè to tí parẹ́ legbẹ èdè ìlà Òòrun gẹ́gẹ́ bi Phonecian ati (Biblical) Hebrew. Àwọn phonecian, ni tòótó wọn ń sọ̀rọ̀ nipa Lebanon, nígbà to yá o ń tàn ká nípa gbígba Òmìnira, nígbà to ya ó di èdè àwọn keteji (Carthage) níbi tí á tí mọ hàn-án bí puniki. Èdè ìgbàlódé ti àwọn Hébérù ń ṣọ ni Isrealis lo ṣe àtúnṣe rẹ (4, 510). Èdè tí àwọn Ras Shamra àti Uguritic ń sọ kàyéfì lo jẹ́. Èdè to ti pẹ́ tí àwọn Quran ń lò láti Centiuri kẹrin AD, lo wà ṣùgbọ́n nígbà tó yá wọ́n padà ṣí tí Centiuri karun BC; ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n ko ṣọ mọ́. Loni Orísìírìsí ìpínlẹ̀ Arábìkì tí wọ́n ń so ní tí gbogbogbo ní àrín ìlà Òòrùn àti àríwá adúláwọ̀ Afíríkà. Ní Áfíríkà àwọn èdè tó hàn gbegedé wọn ṣi pegedé Egyptian (42,500), hassaniya (2, 230), ti wọn ń ṣọ ní Mauritania àti díẹ̀ lápá Mali Senegal àti Niger, Morocan (19,542); Shua (1,031), wọn ń ṣọ díẹ̀ ní Chad, Cameroon, Nigeria Niger; Sudanese (16,000-19,000) ohun nìkan ni wọ́n ń sọ ní Àríwá Sudan ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn Olùṣọ èdè ni Egypt àti Eritrea; Algerian Colloquial (22,400), tì wọ́n ń sọ Tunisia; àti Sulaimitoan (4,500) ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣọ èdè yìí díẹ̀ ní Libya àti Egypt. Ó dá hàn yàtọ̀ ṣí ẹ̀dá ọ̀rọ̀ aláwomọ èdè oni ti Arabiki ṣùgbọ́n èdè Arabiki ní a ń lò fún ẹ̀kọ́ Ìṣàkóṣo àti Ìgbòòrò Ìbánisòrọ̀ bakan náà a ń lo gẹ́gẹ́ bi èdè kejì ó si jẹ́ èdè ìpìnlẹ̀ àkọ́kọ fún èdè Arábìkì. Ìyàtọ̀ ẹ̀dá Ìgbẹ́dègbẹ́yọ̀ wúni lórí nítorípé àpèjúwe àkọ́kọ́ Ferguson (1959) Maltese (330) wọn ń sọ̀rọ̀ nìpa ilè ti omi yíká ti Malta ati níbikíbi ohun ní ìpìlẹ̀ èdá ti Àríwá Afíríkà Arabiki ṣùgbọ́n tí ó tí tàn ka láàrín àwọn Italiàni. (3) Sémítìkì to wa ní Guṣu kún fún àwọn Arabiki Guṣu àti Ethic Semitic Ṣùgbọ́n àwọn ti tẹ́lẹ̀ kún fún Orísìíríṣí bi Hadrami Mineah Ontabanian ati Sebaean, Òhun nìkan ni a mọ̀ láti ìwọ̀ Òòrùn Guṣu Arábìkì àkọsílè rè tí wà láti Centiuri méjọ BC pẹ̀lú Arábìkì ti Guṣu Soqotri (70), Mehri (77), Jibbali (25) àti Harsusi (700) Ṣùgbọ́n ki i se gbogbo àwọn Òmòwé to gboye nínú koko isẹ kan lo fara mọ̀. Ethic-Semitic kún fún àwọn ará Àríwá Eghiopic àti ẹ̀ka ọ̀rọ̀ aláwòmọ́ àti Liturgical G I’ IZ Ùqre (683) àti Tigrinya (6, 060) àti Ethiopia tí ó wa ní ẹ̀ka Guṣu to wa láàrin ita tì kò sí ní pínpín. Amharic (20, 000) èdè Ethopia jẹ tí gbogbo gbo ó wà lára ti tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Harari (26), O jé ẹni ti ahọ́n rẹ̀ fanimọ́ra tí ó si jẹ tí ìbìlẹ̀ ṣi gbogbo ìlú Harari gbogbo àwọn ẹgbẹ́ atòdefimọ̀ gbárajọ pẹ̀lú àwọn ará Àrìwá tí Gurage l’orisiirisi gẹ́gẹ́ bí Soddo (104) yàtọ̀ si tí àringbùngbùn tí ìwọ̀ Òòrùn pẹ̀lú Chaha, Masqan, e.t.c. tí wọ́n jẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ (1,856) Orísìírírìsí nǹkan tí Gurage fi kun ni silti (493) a ṣi ṣe àpínsowoó rẹ̀ ṣi ẹgbé èyí ti o wa láàrín. Ó ṣe pàtàkì kí á ka “Gurage” ká á ṣi fi hàn gẹ́gẹ́ bi èdè kan.
Sẹ̀mítíìkì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2861
2861
Kusitiiki Cushtic Kusitiiki Kí á to lè ri Chustic gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan ó ní ṣe pé kí á pápọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ìsọ̀rí èdè yòókù, díẹ̀ nínú wọn dá hàn yàtọ̀ láàrín ara wọn; Àwọn kan ṣe àfihàn tí ó dádúró tí ó ṣi yàtò láàrín ẹ̀ka egbẹ́. Ó ṣì ṣúnmọ́ atodefimọ èdè. Díẹ̀ laarin àwọn àgbà ẹgbẹ́ odẹ ni Kenya lo ń ṣọ Yaaku. Àwọn ẹgbẹ́ mééfèfà jo ni nǹkan kan to jọ jẹ àjọni lórí ẹ̀kọ́ nípa ayé to dúró lórí aṣàmì tí ó wa ní ìsàlẹ̀, ìlà Òòrùn Cushitic to wà lórí òkè ati èyí to wa ní ìlà Òòrùn to wa nílẹ̀, Dullay àti Yaakuni nǹkan tí wọn fi se àárin dipo kí a ka lábẹ́ ìlà Òòrùn ẹwọ́n Cushitic. (1) Cushitic to wa ní Àríwá kún fún èdè eyọkan, Badawi/Beja (1,148), tí á ń ṣọ ní agbègbè to farapẹ́ ìpín ti Sudan, Egypt àti Eriterea. (2) Cushitic to wa ní àringbùngbùn jẹ mọ èdè Àgaw, ó jẹ ẹgbẹ́ ti a ṣe atúnmọ̀ rẹ̀ lórísìírìsí ni Àríwá ìlà Òòrùn Ethiopia àti Kwara lápapọ̀ 1,000), Xamtunga (80), Awngi (490), àti díẹ̀ lórìṣìírìsí tó rún (3) Ai ba ìgbà mu fún Burji, Cushitic tó wà ní ìlà òòrùn tún mún ìpàdé ìṣùpọ̀ àhánnupè. Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀sọ̀ ń gbé ní orí òkè tí wọn ń ṣọ Burji wa ní Àríwá Kenya àwọn ẹgbẹ́ náà ní Burji (87) Sidamo (1,500) àti Kambata Halìyya ẹgbẹ̀rún kan. Àwọn Cushitic ìlà Òòrùn ní ẹka ẹgbẹ́ mẹta. (i) Àwọn ẹ̀ka ẹgbẹ́ Àríwá wọn dúró fún saho (144) àti Afari (1,200) (iii) Àwọn ọmọ Tana wọn jẹ mo ìlà Òòrùn àti ìwọ̀ Òòrùn ti ìpààlà wa láàrìn wọn. Àwọn ará tẹ́lẹ̀ kún fún Àríwá ni Kenyan Rendille (32) Boni(5) Lapapọ iye ti àwọn Somali jẹ (8,335) Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní Somalia, Djiboute, Ila Òòrùn Ethiopia, ati Aríwá ìlà Òòrùn Kẹnya. Ti ìwọ̀ Òòrùn pín tó ṣí ní Daasenech (30) Arbore (1,000-500) àti bóyá èdè Elmọlo. Èkọ́ nípa ìmọ̀ ayé tí ó da wà ní Bayso (500) òhun ní wọ́n ń ṣọ ní agbègbè Abàjà adágún nínú Ethopian Rift Valley tí ó pin ẹya kan pẹlu ìlà Òòrùn atí ìwọ̀ Òòrùn. (4) Dually dúró fún gẹ́gẹ́ bi okùn ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ní àgbègbè Wayto Valley ṣí ìwọ̀ òòrùn ti Konsout (of 4(n) soke) èyí to yàtọ̀ l’orisiirisi ni Gusu Tsmay (7) pípàdé ẹgbẹ́ onihun ìsùpọ̀ lójúpọ̀ parapọ̀ ní Ethnologue gẹ́gẹ́ bi Gwwada (65-76). (5) Èdè Cushitic ni Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ń sọ ni Tanzania, níbi ti wọn ti dúró fún iraqw gẹ́gẹ́ bí ìsùpọ̀ fún apẹẹrẹ (365), Gorowa (30) Burunge (31) Mbugu/Mana (32) ní wọn ṣábà maa ń lò gẹ́gẹ́ bi ojúlówó àpẹ̀ẹrẹ èdè àmúlùmálà àti alaisi Asax àti fún kw’adza ọmọ ẹgbẹ ti i ki i ṣe ọmọ ìlú Tan zania tó jẹ dahalo (3,000) ó sọ̀rọ̀ ní ìletò to ṣúnmọ́ ẹnu ìlú odò Tana ní Kenya.
Kusitiiki
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2874
2874
Àwọn èdè Niger-Kóngò Àkójọpọ̀ èdè tí a mọ̀ sí Niger-Congo dín mẹ́rin ni òjì-lé-légbéje. Grimes (1996) ríi gẹ́gẹ́ bíi èyí tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé àti wí pé àwọn èèyàn tí ó ń sọ ọ̀kan tàbí èkejì nínú. àwọn èdè yìí fọ́n ká orílẹ̀ ayé ju àwọn ìyókù akẹgbẹ wọn lọ. Ní orílè èdè Afíríkà, àwọn èdè tí ó ní èèyàn tí ó pọ̀ jùlọ ni wọ́n jẹ́ èyí tí a lè rí ní abẹ́ àkójọpọ̀ èdè Niger-Congo. Bí àpẹẹrẹ, èdè tí ó tóbi jùlọ ni Senegal, Wolof jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè Niger-Congo; Fulfude tí ó tàn káàkirí ìwọ̀ oòrùn àti àárín gbùngùn Afíríkà, ọkan níbẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ náà ni èdè Manding tí ó gbajú gbajà ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onikaluku ni ó ní orúkọ tí ó ń pe èdè yìí, oun náà sì ni a mọ̀ ṣí Bambara tí ó jẹ́ èdè orílè èdè àti ìjọba Mali àti Dyala, èdè Okòwò gbalé-gboko. A kò gbọdọ̀ gbàgbé Akan ní orílẹ̀ èdè Ghana. Yorùbá àti Igbo náà kò gbẹ́yìn níbẹ̀, èdè pàtàkì ni méjèèjì yìí ní orílẹ̀ èdè Nàìjiria. Ní àárín gbùngbùn Áfíríkà, èdè Sango ni wọ́n ń sọ. Àwọn èdè Bantu bíi Ganda, Gikuyu, Kongo, Lingala, Luba-Kasari, Luyia, Mbundu (Luanda), Northern Sotho, Sukuma, Swahili, Tsonga, Tswana, Umbundu, Xhosa ati Zulu. Ó tó èèyàn bíi Mílíọ̀nù lọ́nà ọtà-lé-lọ́ọ̀dúnrún sí Mílíònù irínwó tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ń sọ èdè Niger Congo ní Áfíríkà, gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe sọ. IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ LÓRÍ ÌPÍN ÈDÈ NIGER-CONGO Ọkan gbòógì lára àwọn èdè tí a rí lára ìpín èdè Niger-Congo ni àkójọpọ̀ èdè Bantu jẹ́. Àwọn èdè yìí gbalẹ tààrà ní ilẹ̀ Áfíríkà, wọ́n sì jọra gidi. Ní abẹ́ gírámà rẹ, a ríi wí pé àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ inú àwọn èdè yìí jọra gan-an, èyí ni ó sì mú àwọn onímọ̀ tí ó jẹ́ aláwọ̀ funfun fi ara balẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìwádìí ní orí àwọn èdè wọ̀nyí. Koelle àti Bleek sọ wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà èdè tí àwọn ènìyàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ń sọ ni ó ní ọ̀rọ̀ orúkọ tí a sẹ̀dá nípa àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀. Nínú ìwádìí tirẹ̀, Meinhof sa awọn èdè kan jọ tí wọ́n fi ara pẹ́ ara wọn láti ara ọ̀rọ̀ orúkọ wọn ṣùgbọ́n tí gírámà wọn yàtọ̀ díẹ̀. Èyí ni òún pè ní ‘Semi-Bantu’. Westerman ṣe iṣẹ́ tí ó jọ mọ́ ti Meinhof díẹ̀. Ní tirẹ̀, ó se ìpìnyà láàrin àwọn èdè tí ó farahàn ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Sudan. Ó ṣe àkíyèsi àwọn èdè kan tí a rí ní apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sudan; àwọn náà ni ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́fà: Kwa, Benue-Cross, Togo, Gur, Mandingo, àti ti ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sílébù nínú àwọn èdè wọ̀nyí ni wọ́n jé ‘CV’. Greenberg yapa díẹ̀ nínú èrò ti rẹ̀. Ó ṣe àtúnpín àwọn èdè wọ̀nyí láàrín ọdún 1949 sí 1954. Ní tirẹ̀, ó pín Bàntú àti ìwọ̀ oòrùn Sudan sí ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó pè ní Niger-Congo, ó sì ṣe àdáyanrí ìlà oòrùn Sudan sí ìsọ̀rí mìíràn ọ̀tọ̀, ó pè é ni Nilo-Saharan. Iṣẹ́ rẹ̀ sì fi ara pẹ́ ti Westerman tààrà ní abẹ́ ìsọ̀rí yìí. Àwọn kókó inú iṣẹ́ Greenberg ni ìwọ̀nyí: (a) Orúkọ Mandigo yí padà sí Mande (b) Àárín gbùngbùn Togo di ara Kwa (d) Benue-Cross yí padè di Benue-Congo (e) Bantu di ìsọ̀rí kan lábẹ́ Benue-Congo (ẹ) Fulfude di ara ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì; Serer àti Wolof sì di ara kan náà pẹ̀lú fulfude. (f) Adamawa kún àkójọpọ̀ èdè yìí (g) Ní ọdún 1963, Kordofanian kúrò ní èdè Kòtó-ǹ-kan ó di ọ̀gbà kan náà pẹ̀lú Niger-Congo. Orúkọ wá yí padà, ó di Niger-Kordofanian (tàbí Congo-Kordofanian). Greenberg fura sí ipe èdè àwọn èdè wọ̀nyí, ó sì tọ́ka síi wí pé /ףּ/. Kordofanian ati /m/ Niger-Congo jọ ara wọn. Èyí sì máa ń jẹyọ dáadáa nínú àwọn àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ Kòsemánìí kan nínú àwọn èdè yìí. Lẹ́yìn Greenberg ni Mukarovsky ṣe àtúpalẹ̀ àti àtúnpín àwọn èdè yìí, Ó yọ Kordofanian, Mande, Wolof-Serer-Fulfulde, Ijoid àti Adamawa kúrò níbẹ̀; àwọn ìyókù ni ó sì pè ní ‘Western Nigritic’. Ayé sí tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí gan-an ni láàrín àwọn olùwádìí ìjìnlẹ̀. Àtúnṣe gbòógì wáyé láti ọwọ Bennett àti Sterk (1977), Wọ́n fi ojú lámèyítọ́ wo àwọn ọ̀rọ̣̀ orúkọ tí ó fara jọ ara wọn nínú àwọn èdè wọ̀nyí. Ìgbàgbọ́ wọn ni wí pé Kordofanian àti Mande ti yà kúrò lara wọn. Lẹ́yìn èyí ni ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì yà kúrò lára ìsọ̀rí èdè yìí tí a sì fún àwọn tí ó kù ní orúkọ ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Ara àwọn wọ̀nyí ni Ila-oòrùn Adamawa, Gur, Kru àti Ijọ wà. Ọ̀kan gbòógì iṣẹ́ lórí ìwádìí yìí ni The Niger-Cong Languages (Bender – Samuel 1989) jẹ́. Àgbékalẹ̀ ìsọ̀rí èdè Niger-Congo gẹ́gẹ́ bí a ti mọ lónìí ni a ṣe àtẹ rẹ̀ sí ìṣàlẹ̀ yìí (Boyd 1989) nípa lílò àlàyé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Nínú atẹ yìí a rí, ‘Proto-Niger-Congo’ nínú èyí tó jẹ́ wí pé ‘Kordofanian’ ni ìsọ̀rí àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ yapa. Mande àti iwọ oòrùn Atlantic ni ìsọ̀rí kejì tí ó tún yapa bẹ́ẹ̀, èyí tí wọ́n fi hàn wá lábẹ́ ‘Proto-Mande-Atlantic-Congo’. Àwọn èyí tí ó tún dàbí rẹ̀ ni àwọn tí wọ́n pín sí abẹ́ ìsọ̀rí ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Láti ara ‘Proto-Ijo-Congo’ ni ‘Ijoid’ ti yapa, lábẹ́ rẹ̀ ni a tí rí Ijọ ati Defaka. Lábẹ́ ‘Proto-Ijọ-Congo’, a rí ‘Proto-Dogon-Congo’ èyí tí Dogon yapa láti ara rẹ̀. Lábẹ́ ‘Proto-Dogon-Congo’, a rí ‘Proto-Volta-Congo’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn Vota-Congo àti ìlà oòrùn Volta Congo (Proto-Benue-Kwa). Ní a pá ìwọ̀ oòrùn Volta-Congo ni a ti wá rí Kru, Pre, Senufo; ààrin gbùngbùn Gur àti Adawawa (Bikirin, Day, Kam ati Ubangi). A lè pè é ní Gur-Adamawa. Ní apá ìlà oòrùn, ni a ti rí ààrín gbùngbùn orílè èdè Nìjíríà tí òhun náà tún yapa, a sì rí Bantoid Cross lábẹ́ Ìlà oòrùn yìí. Lára Bantoid Cross yìí ni Cross River ti yapa, nígbà tí a wa rí Bantoid lábẹ́ Bantoid Cross. KORDOFANIAN Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kordofanian’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Heiban, Tahodi, Rashad, Katla. Heiban pín sí Ìlà Oòrùn (Ko, Warnang); ààrín gbùngbùn (Koalib, Logol, Laru, Ebang, Utoro); lààrín ‘Central àti west’ a rí shirumba; Ní ìwọ̀ oòrùn (Tiro àti Moro). Talodi: lábẹ́ Tolodi, a rí Ngile (Masakin) àti Dengbebu, Tocho, Jomang, Nding, Tegem. Rashad: lábẹ́ rẹ̀ ni Tagoi àti Tagali wà. Katla: lábẹ́ rẹ̀ ni kalak (Katla) àti Lomorik (Tima). MANDE Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè yìí Sodo sí jùlọ. Àwọn ìhú tí a sì ti rí àwọn tí èdè wọn pẹ̀ka láti ara orí èdè yìí ni Mali, Cote d’Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Senegal, Gambia, Guinea Bissan, Mauretania, Banin, Ghana, Togo ati Nigeria (Dwyer 1989; Kastenholz 1991/2). Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá sí méjìlá tí wọ́n ń sọ ọ́. Nínú àtẹ yìíu a rí ‘Proto-Mande’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. A wá rí ìwọ̀ oòrùn fúnrarẹ̀ tí ó tún wá pín sí ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti Àríwá ìwọ̀ oòrùn. Láti ara ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí: Mandaing ati Koranko, Vai àti Kono, Jogo (Ligbi, Nnmu, Atumfuor, Wela) àti Jeri, Sooso àti Yalunka, Kpelle, Loomu, Bandi, Mande ati Loko. Láti ara àríwá-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí Sorogama àti Tieyaxo, Tiema Cewe, hainyaxo, Soninke (Azer), Bobo (Sya), Dzuun (Samogo-Guan) àti Sembia, Jo (Samogo-Don). Ní ìlà Oòrùn a rí : Mano, Dan (Yakuba, Gio) àti Tura (Wen), Guro (Kweni) àti Yanre, Mwa àti Wan (Nwa), Gban àti Beng (Gan). Bákan náà, ni a rí: Bisa, Sane (Samogo-Tongan, Maya) àti San(South Samo, Maka), Busa (Bisa, Boko), Shanga àti Tyenga. Oju-iwe Keji. ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi ara hàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, ní ẹ̀bá òkun Àtìláńtíìkì ni èdè yìí sodo sí jùlo. Ó fọ́nká láti ẹnu odò Senegal títí dé orílẹ̀ èdè Liberia. Díẹ̀ lára àwọn èdè tí ó pẹ̀ka sí abẹ́ orí èdè yìí ni a ti rí: Fulfulde, Wolof, Diola, Serer àti Remne. Sapir (1971) ni ó ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí: Fig 2.4. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Atlantic’ tí ó pín sí Àríwá àti Gunsu. Ní àríwá ni a ti rí Fulfulde àti Wolof, Serer, Cangin, Diola ati Pupel, Balanta, Bassari/Bedik ati Konyagi, Biafada/Pajade, Kobiana/Kasanga àti Banyin, Nalu, Bijago(Proto-Atlantic), Sua, Temne, Sherbro àti Gola, Limba. IJOID Apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria ni a ti rí àwọn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Èdè náà ni a mọ̀ sí Defaka àti Ijọ. Jenewari àti Williamson (1989) ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ isálẹ̀ yìí Fig 2.5. Nínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto-Ijoid’ tí ó pín sí Defaka ati Ijọ. Ijọ pín Ìlà-oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn. Lábé ìlà-oòrùn ni a ti rí: Nkọrọ, Ibani, Kalabari, Kirike (Okrika), Nembe ati Akaha(Akassa). Lábẹ́ ìwọ̀-oòrùn ni a ti rí : Izon, Biseni, Akita (Okordia), Oruma. DOGON Àwọn ènìyàn bíi ìdajì mílíọ̀nù tí a bá pàdé ní ilẹ̀ Mali àti Burkina Faso ni wọ́n n sọ èdè yìí. Bendor-Samuel àti àwọn ìyókù (1989) ni ó gbé àtẹ yìí kalẹ̀. Fig 2.6. Ínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto Dogon’ ti o pín ṣi ìsọ̀rí mẹfa. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí (a) Plain - Jamsay tegu, Toro teju, Tene ka, Tomo ka (b) Escarpment - Toro sọọ, Tombaco sọọ, Kamba sọọ (d) West - Dulerí dom, Ẹjẹngẹ dó (e) North west - Bangeri Me (ẹ) North Platean - Bondum dom. Dogul dom (f) Ìsọ̀rí kẹfà ni Yanda dom, Oru yille àti Naya tegu. ARIWA VOLTA-CONGO Kru, Gur àti Adamawa-Ubangi ni àwọn ẹ̀ka èdè tí a lè rí ní abẹ́ ìsọ̀rí ‘ARIWA VOLTA-CONGO’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn èdè yìí ti fọ́nká orílẹ̀ KRU Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire àti Liberia ni a ti lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù kan sí méjì tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Tí a bá wo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí, a ó ṣe alábápàdé àwọn èdè bíi Kuwaa, Tiegba, Seme àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lára orí èdè ‘Kru’. Fig 2.7. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kru’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí (a) Ìlà-oòrùn - Godie àti Kouya, Dida, Kwadia, Bakwe ati Wane. (b) Ìwọ̀-oòrùn - Grebo complex, Guere complex, Bassa, Klao (d) Ìsọ̀rí kẹ́ta ni àwọn bíi Kuwaa, Tiegba, Abrako, Seme. GUR Èdè yìí gbajú gbajà dáadáa àti wí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ń sọ èdè yìí ní orílẹ̀ ayé. A lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè náà ní orílẹ̀ èdè bíi Cote d’Ivoire Ghana, Togo, Benin, Burkina Faso àti Nigeria. Ó tó èèyàn bíi mílíọ̀nù márùn-ún ati àbàbọ̀ tí wọ́n ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí Manessy 91978) ti ṣe ìwádìí rẹ̀. Fig 2.8. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto Gur’. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ó pín sí:- Ààrin gbùngbùn Proto; Kulango àti Loron (Proto-Gur); Viemo, Tyefo, Wara-Natioro, Baatonum, Win (Toussian). Ààrin gbùngbùn Proto: eléyìí tún wà pín sí ìsọ̀rí meji pere: Àríwá àti Gúúsù. Lábẹ́ àríwá, a rí : Kurumfe, Bwamu Buli-Konni, Ìlà-oòrùn Oti-Volta, Iwọ̀-oòrùn Oti Volta, Gurma, Yom-Nawdm. Lábẹ́ gúúsù, a rí: Lobi àti Dyan, Kirma àti Tyurama, Ìwọ̀-oòrùn Gurunsi, ààrin gbùngbùn Guruusì àti Ìlà-oòrùn Guruusi, Dogose àti Gan. ADAMAWA-UBANGI Èdè tí ó gbòòrò ni èdè Adamawa-Ubangi. Ipẹ̀ka rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti apá Gúsù-Ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà títí dé Àríwá-Ìwọ̀ oòrùn Sudan. Àpapọ̀ iye àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa tó mílíọ̀nù kan àti ààbọ̀-Crozier àti Blench (1992); Grimes (1996). Mílíọ̀nù méjì lé lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ni Barreteau àti monino (1978) tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń sọ èdè Ubangi. Èyí túmọ̀ sí pé àpapọ̀ àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa-Ubangi ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rindín ní ẹgbàá lọ́nà ọgọ́rùn-ún láì ka àwọ̣n tí ó ń sọ èdè Sango mọ́ ọ. Fig 2.9. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Adamawa-Ubangi’ tí ó pín sí ọ̀nà méjì ní ìbẹ̀rẹ̀ àpẹẹrẹ̀. (a) Adamawa (b) Ubangi Adamawa - eléyìí tún pín sí àwọn àwọn ìsọ̀rí mìíràn bíi: Leko, Duru, Mumuye/Yendang ati Nimbari; Ubum, Bua, Kim, Day; Waja, Longuda, Jen, Bikwin, Yungur. Bákan náà ni a rí: Ba (Kwa), Kam, Fali. Ubangi - Gbaya; Banda, Ngbandi, Sere, Ngbaka àti Mba; Zande. SOUTH VOLTA-CONGO Bennett ati Sterk (1977) pe ‘South Volta-Congo ni ààrin gbùngbùn àríwí Niger-Congo. Atọ́tọ́nu wáyé nípa yíyapa tí ó wá yé láàrin Kwa àti Benue Congo nítorí pé wọ́n sún mọ́ ara wọn pékípẹ́kí-Greenberg (1963). Pàápàá jùlọ yíyapa láàrin èdè kwa, Gbe àti Benue –Congo: Bennett àti Sterk (1977) àti síse àtúnṣe. Kranse (1895) ni ó ṣe ìfihàn orúkọ ‘Kwa’ fún ayé. Bíi mílíọ̀nù lọ́nà ogún ni Grimes (1996) fi yé wa wí pé ó ń sọ èdè náà. Greenbery (1963a) pín-in sí ìsọ̀rí mẹ́jọ, ó sì so àwọn èdè ààrin gbùngbùn Togo pọ mọ ìsọ̀rí tirẹ̀. Stewart 1994 ni o ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí. Fig 2.10. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kwa’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́fà ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí: (a) Ega, Avikan ati Alladian, Ajukru, Abidji, Abbey, Attie (b) Potou Tano (d) Ga ati Dangme (Proto-Kwa) (e) Na – Togo (ẹ) Ka – Togo (f) Gbe Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí wọ̀nyí ni o tún jẹ́ àtúnpín sí ìsọ̀rí mìíran bí àpẹẹrẹ :- Potou-Tano, Na-Togo, Ka-Togo, Gbe. Potou-Tano: èléyìí pín sí Potou àti Tano. Lábẹ Potou ni a ti rí Ebríe àti Mbatto Tano – eléyìí pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin. (a) Krobu (b) Ìwọ̀-oòrùn Tano: Abure, Eotilé (d) Ààrin gbùngbùn Tano: Akan, Bia (Nzema-Ahanta) àti (Anyi, Banle, Anufo). (e) Guan – O tun pín si Gúúsù níbi ti a ti rí Efutu –Awutu ati Larten-Cherepong-Anum. Bákan náà ni Àríwá Guang. Na-Togo:- Ó pín sí Lelémi – Lefana, Akapatu-Lolobi, Likpe, Santrokofi; Logba (Na Togo); Basila, Adele. Ka-Togo ;- Ìsọ̀rí eléyìí pín sí Avatime, Nyangbo-Tafi; Kposo, Ahlo, Bowiri (Ka-Togo); Kebu, Animere. Gbe :- Lábẹ́ èyí ni a ti rí: Ewe ati Gen/Aja, Fon-Phla-Phera BENUE CONGO Ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èdè yìí ni: Ìwọ̀-oòrùn àti Ìlà oòrùn Benue-Congo. Àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ ni ó ní àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí, ó sì sodo sí apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìlú bíi Cameroon, Congo, CAR, DRC, Tonzania, Uganda, Kenya, Mozambique, Angola, Rwanda, Burundi, Namibia, Zambia, Malawi, Zimbabwe, Gabon, Lesotho, Samalia àti àwọn èdè yìí kalẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe wádìí rẹ̀, èdè Yorùbá àti Igbo ni ó tóbi jùlọ nínú ẹ̀ka èdè tí a pè ní Benue-Congo, ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Benue-Congo ni ó sì pín àwọn èdè wọ̀nyí sí. Àtẹ náà nìyí. Fig 2.11. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Benue-Congo’ ti o pín sí ìsọ̀rí meji pàtàkì. (a) Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo (b) Ìlà oòrùn Benue Congo Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo:- Ó pín sí YEAI (Yoruboid, Edoid, Akokoid, Igboid); Akpes; Ayere-Ahan; NOI (Nupoid, Ọkọ, Idomoid). Ìlà oòrùn Benue Congo :- Ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta pàtó. (a) Àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíráà:- Ó pín sí: Kainji, Àríwá-Ìwọ̀ Plateane, Beromic, Àárín gbùngbùn Plateane, Ìlà-oòrùn Gúúsù Plateane, Tarok, Jukunoid. (b) Ukaan (d) Bantoid-Cross:- Lábẹ́ èyí ni Bantoid ti yapa. Nígbà tí a sì rí Cross River ní abẹ́ Bantoid-Cross. Láti ara Cross River ni Bandi ti wá yapa. Nígbà tí a wá rí Delta-Cross lábẹ́ Cross River. Ní ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílẹ̀ èdè Áfíríkà ni ó pẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó gbalẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a rí lára wọn tí ìgbà ti fẹ́rẹ̀ tan lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni èdè mìíràn ti fẹ́ máa gba saa mọ lọwọ Àwọn ìdí bíi, òṣèlú, ogun, òlàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sì ṣe okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlọ, gbogbo èdè yìí náà kọ́ ni àwọn Lámèyítọ́ èdè fi ohùn ṣe ọ̀kan lé lórí lábẹ́ ìsòrí tí wọ́n wa ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ‘ẹbí’ rẹ fi ojú hàn gbangba. Ní ìparí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n ààyè sì tún sí sílẹ̀ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ túlẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí àti lámèyítọ́ lórí ẹ̀kà èdè Niger-Congo.
Àwọn èdè Niger-Kóngò
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2875
2875
Kodofanianu KORDOFANIAN Kodofanianu Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kordofanian’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Heiban, Tahodi, Rashad, Katla. Heiban pín sí Ìlà Oòrùn (Ko, Warnang); ààrín gbùngbùn (Koalib, Logol, Laru, Ebang, Utoro); lààrín ‘Central àti west’ a rí shirumba; Ní ìwọ̀ oòrùn (Tiro àti Moro). Talodi: lábẹ́ Tolodi, a rí Ngile (Masakin) àti Dengbebu, Tocho, Jomang, Nding, Tegem. Rashad: lábẹ́ rẹ̀ ni Tagoi àti Tagali wà. Katla: lábẹ́ rẹ̀ ni kalak (Katla) àti Lomorik (Tima).
Kodofanianu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2876
2876
Mande Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè yìí Sodo sí jùlọ. Àwọn ìhú tí a sì ti rí àwọn tí èdè wọn pẹ̀ka láti ara orí èdè yìí ni Mali, Cote d’Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Senegal, Gambia, Guinea Bissau, Mauritania, Banin, Ghana, Togo ati Nigeria (Dwyer 1989; Kastenholz 1991/2). Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá sí méjìlá tí wọ́n ń sọ ọ́. Ẹ yẹ àtẹ ìsọ̀rí yìí wò. Nínú àtẹ yìíu a rí ‘Proto-Mande’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. A wá rí ìwọ̀ oòrùn fúnrarẹ̀ tí ó tún wá pín sí ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti Àríwá ìwọ̀ oòrùn. Láti ara ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí: Mandaing ati Koranko, Vai àti Kono, Jogo (Ligbi, Nnmu, Atumfuor, Wela) àti Jeri, Sooso àti Yalunka, Kpelle, Loomu, Bandi, Mande ati Loko. Láti ara àríwá-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí Sorogama àti Tieyaxo, Tiema Cewe, hainyaxo, Soninke (Azer), Bobo (Sya), Dzuun (Samogo-Guan) àti Sembia, Jo (Samogo-Don). Ní ìlà Oòrùn a rí : Mano, Dan (Yakuba, Gio) àti Tura (Wen), Guro (Kweni) àti Yanre, Mwa àti Wan (Nwa), Gban àti Beng (Gan). Bákan náà, ni a rí: Bisa, Sane (Samogo-Tongan, Maya) àti San (South Samo, Maka), Busa (Bisa, Boko), Shanga àti Tyenga
Mande
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2877
2877
Àtìláńtíìkì ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ Atlantic Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi ara hàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, ní ẹ̀bá òkun Àtìláńtíìkì ni èdè yìí sodo sí jùlo. Ó fọ́nká láti ẹnu odò Senegal títí dé orílẹ̀ èdè Liberia. Díẹ̀ lára àwọn èdè tí ó pẹ̀ka sí abẹ́ orí èdè yìí ni a ti rí: Fulfulde, Wolof, Diola, Serer àti Remne. Sapir (1971) ni ó ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí: Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Atlantic’ tí ó pín sí Àríwá àti Gunsu. Ní àríwá ni a ti rí Fulfulde àti Wolof, Serer, Cangin, Diola ati Pupel, Balanta, Bassari/Bedik ati Konyagi, Biafada/Pajade, Kobiana/Kasanga àti Banyin, Nalu, Bijago(Proto-Atlantic), Sua, Temne, Sherbro àti Gola, Limba
Àtìláńtíìkì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2878
2878
Ijọidi Apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria ni a ti rí àwọn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Èdè náà ni a mọ̀ sí Defaka àti Ijọ. Jenewari àti Williamson (1989) ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ isálẹ̀ yìí Nínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto-Ijoid’ tí ó pín sí Defaka ati Ijọ. Ijọ pín Ìlà-oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn. Lábé ìlà-oòrùn ni a ti rí: Nkọrọ, Ibani, Kalabari, Kirike (Okrika), Nembe ati Akaha(Akassa). Lábẹ́ ìwọ̀-oòrùn ni a ti rí : Izon, Biseni, Akita (Okordia), Oruma
Ijọidi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2879
2879
Dogon ! style="background-color: #b0c4de" | Èdè Dogon languages Dogon Àwọn ènìyàn bíi ìdajì mílíọ̀nù tí a bá pàdé ní ilẹ̀ Mali àti Burkina Faso ni wọ́n n sọ èdè yìí. Bendor-Samuel àti àwọn ìyókù (1989) ni ó gbé àtẹ yìí kalẹ̀. Ínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto Dogon’ ti o pín ṣi ìsọ̀rí mẹfa. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí (a) Plain - Jamsay tegu, Toro teju, Tene ka, Tomo ka (b) Escarpment Toro sọọ, Tombaco sọọ, Kamba sọọ (d) West - Dulerí dom, Ẹjẹngẹ dó (e) North west - Bangeri Me (ẹ) North Platean - Bondum dom. Dogul dom (f) Ìsọ̀rí kẹfà ni Yanda dom, Oru yille àti Naya tegu. Iye àwọn tí ó ń sọ èdè yìí jẹ 100,000. (Ọ̀kẹ́márùn-ún) Orílẹ̀ èdè tí wọn tí ń sọ èdè yìí ni Mali, ati Burkina Faso
Dogon
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2881
2881
Krumen Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire àti Liberia ni a ti lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù kan sí méjì tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Tí a bá wo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí, a ó ṣe alábápàdé àwọn èdè bíi Kuwaa, Tiegba, Seme àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lára orí èdè ‘Kru’. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kru’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí (a) Ìlà-oòrùn - Godie àti Kouya, Dida, Kwadia, Bakwe ati Wane. (b) Ìwọ̀-oòrùn - Grebo complex, Guere complex, Bassa, Klao (d) Ìsọ̀rí kẹ́ta ni àwọn bíi Kuwaa, Tiegba, Abrako, Seme.
Krumen
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2883
2883
Adámáwá-Ubangi I Èdè tí ó gbòòrò ni èdè Adamawa-Ubangi. Ipẹ̀ka rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti apá Gúsù-Ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà títí dé Àríwá-Ìwọ̀ oòrùn Sudan. Àpapọ̀ iye àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa tó mílíọ̀nù kan àti ààbọ̀-Crozier àti Blench (1992); Grimes (1996). Mílíọ̀nù méjì lé lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ni Barreteau àti monino (1978) tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń sọ èdè Ubangi. Èyí túmọ̀ sí pé àpapọ̀ àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa-Ubangi ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rindín ní ẹgbàá lọ́nà ọgọ́rùn-ún láì ka àwọ̣n tí ó ń sọ èdè Sango mọ́ ọ. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Adamawa-Ubangi’ tí ó pín sí ọ̀nà méjì ní ìbẹ̀rẹ̀ àpẹẹrẹ̀. (a) Adamawa (b) Ubangi Adamawa - eléyìí tún pín sí àwọn àwọn ìsọ̀rí mìíràn bíi: Leko, Duru, Mumuye/Yendang ati Nimbari; Ubum, Bua, Kim, Day; Waja, Longuda, Jen, Bikwin, Yungur. Bákan náà ni a rí: Ba (Kwa), Kam, Fali. Ubangi - Gbaya; Banda, Ngbandi, Sere, Ngbaka àti Mba; Zande.
Adámáwá-Ubangi I
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2885
2885
Àwọn èdè Bẹ́núé-Kóngò Ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èdè yìí ni: Ìwọ̀-oòrùn àti Ìlà oòrùn Benue-Congo. Àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ ni ó ní àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí, ó sì sodo sí apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìlú bíi Cameroon, Congo, CAR, DRC, Tonzania, Uganda, Kenya, Mozambique, Angola, Rwanda, Burundi, Namibia, Zambia, Malawi, Zimbabwe, Gabon, Lesotho, Samalia àti àwọn èdè yìí kalẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe wádìí rẹ̀, èdè Yorùbá àti Igbo ni ó tóbi jùlọ nínú ẹ̀ka èdè tí a pè ní Benue-Congo, ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Benue-Congo ni ó sì pín àwọn èdè wọ̀nyí sí. Àtẹ náà nìyí. Fig 2.11. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Benue-Congo’ ti o pín sí ìsọ̀rí meji pàtàkì. (a) Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo (b) Ìlà oòrùn Benue Congo Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo:- Ó pín sí YEAI (Yoruboid, Edoid, Akokoid, Igboid); Akpes; Ayere-Ahan; NOI (Nupoid, Ọkọ, Idomoid). Ìlà oòrùn Benue Congo :- Ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta pàtó. (a) Àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíráà:- Ó pín sí: Kainji, Àríwá-Ìwọ̀ Plateane, Beromic, Àárín gbùngbùn Plateane, Ìlà-oòrùn Gúúsù Plateane, Tarok, Jukunoid. (b) Ukaan (d) Bantoid-Cross:- Lábẹ́ èyí ni Bantoid ti yapa. Nígbà tí a sì rí Cross River ní abẹ́ Bantoid-Cross. Láti ara Cross River ni Bandi ti wá yapa. Nígbà tí a wá rí Delta-Cross lábẹ́ Cross River. Ní ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílẹ̀ èdè Áfíríkà ni ó pẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó gbalẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a rí lára wọn tí ìgbà ti fẹ́rẹ̀ tan lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni èdè mìíràn ti fẹ́ máa gba saa mọ lọwọ Àwọn ìdí bíi, òṣèlú, ogun, òlàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sì ṣe okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlọ, gbogbo èdè yìí náà kọ́ ni àwọn Lámèyítọ́ èdè fi ohùn ṣe ọ̀kan lé lórí lábẹ́ ìsòrí tí wọ́n wa ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ‘ẹbí’ rẹ fi ojú hàn gbangba. Ní ìparí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n ààyè sì tún sí sílẹ̀ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ túlẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí àti lámèyítọ́ lórí ẹ̀kà èdè Niger-Congo.
Àwọn èdè Bẹ́núé-Kóngò
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2888
2888
Asa Yoruba
Asa Yoruba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2892
2892
Mangbetu Mangbetu Àwọn ènìyàn yìí wà ní abala àríwá Congo, wọ́n sì tó ọ̀kẹ́ méjì ni iye. Èdè mangbetuti ni wọ́n ń sọ, wọ́n sì múlé gbe àwọn Azande, Mbuti àti Momvu. Ọ́ jọ pé orílẹ̀ èdè Sundan ni wọ́n ti sẹ̀ wá; àgbẹ̀, ọdẹ àti apẹja sì ni wọ́n. Òrìṣà Kilima tàbí Noro ni wọ́n ń bọ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́dàá, wọn a sì máa bọ Ara náà.
Mangbetu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2897
2897
Lunda Àwọn ẹ̀yà yìí wà ní orílẹ̀ èdè Congo, Zambia àti Angola, èdè wọn sì jẹ́ ẹ̀yà ti Bantu. Wọ́n dín díẹ̀ ní ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án wọ́n sì múlé gbe ẹ̀yà Yaka, Suku, Chokwe abbl. A rí àgbẹ̀, apẹja àti onísòwò tààrà ni orílẹ̀ èdè yìí. Mwaat Yaav ni ọba wọn, àwọn ìjòyè náà sì wà. Baálẹ̀ kọ̀ọ̀kan náà sì sà ṣùgbọ́n ìsákọ́lẹ̀ pọn dandan. Wọ́n máa ń dífá alágbọ̀n ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbọ́ nínú nzambi.
Lunda
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2899
2899
Luwaluwa (Lwalwa) LWALWA Luwaluwa Àwọn ènìyàn yìí tó bíi ọ̀kẹ́ kan ní iye, ẹ̀yà èdè Bantu sì ni wọ́n ń sọ. Àdúgbò Congo ni wọ́n wà, wọ́n sì múlé gbe Salampasu, Mbagani, Kete, Lunda, Luba àti Chokwe. Wọn a máa ṣe àgbẹ̀ àti ọdẹ wọn a sì máa ṣe iṣẹ́ ọnà. Wọ́n ní ìgbàgbọ́n nínú Olódùmarè (Mvidie Mukulu) àti ẹlẹ́dàá (Nzambi) ṣùgbọ́n wọ́n máa ń wárí fún àwọn alálẹ̀.
Luwaluwa (Lwalwa)
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2900
2900
Maasai ! style="background-color: #b0c4de" | Èdè Maa (ɔl Maa) ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀sìn Monotheismincluding Christianity ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀yà abínibí bíbátan Samburu Maasai je eya awon eniyan ni Apailaoorun Afrika. Wọ́n wà ní àdúgbò orílẹ̀ èdè Tanzania àti Kenya, wọ́n sì fẹ́ẹ̀ tó ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún ààbọ̀ ní iye. Èdè wọn ni OI Maa wọ́n sì múlé gbe Samburu, Kikuyu, Kamba, Chaga, Meru abbl. Darandaran tààrà ni wọ́n. wọn a sì máa sín ìlẹ̀kẹ̀ gan-an. Ọjọ́ orí ni wọ́n máa fi ń ṣe ìjọba ní ilẹ̀ yìí, obìnrin wọn kìí sìí pẹ́ ní ọkọ ṣùgbọ́n ọkùnrin gbọ́dọ̀ ní owó lọ́wọ́ kí ó tó fẹ́ aya. Ní àsìkò ayẹyẹ pàtàkì, màálù ni wọ́n máa ń fi rúbọ.
Maasai
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2901
2901
Mahafali Mahafali Àwọn ènìyàn yìí lé ní mílíọ̀nù kan àti ààbọ̀, wọ́n ń gbé ní apá Gúúsù ìwọ̀ oòrùn Madagascar. Àgbẹ̀ àti darandaran sì ni wọ́n; wọ́n gbajú gbajà fún fínfín àti kíkun ibojì/sàréè. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, asòdì sí ẹ̀kó kristiẹni ni ìjọba wọn tẹ́lẹ̀, wọn kò ní àǹfààní láti gbọ́ nípa orúkọ Jesu. Nísisìyí ẹ̀sìn òmìnira ti wà ṣùgbọ́n ojú ọ̀nà tí kò dára ń pa ìtànkálẹ̀ ìhìnrere lára.
Mahafali
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2903
2903
Makonde Makonde Èdè Bàntú ni wón ń so, wón sì wà ní Tanzania àti Mozambique. Àwon Mwera, Makua àti Mabia ni àwon alámùúlégbé won. Isé won sì ni àgbè, ode àti igbá fínfín. Abúlé kòòkan ni ó sì ní baálè tirè, àwon alálè ni wón sì máa ń bo bíi Olórun ti won.
Makonde
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2904
2904
Mambila Mambila Àwọn ènìyàn yìí wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ati Kamẹrúùnù, wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́na mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, wọ́n sì múlé ti àwọn ènìyàn bíi kaka, Tikong àti Bafum. Èdè Mambila, ẹ̀yà Bantu ni wọ́n sì ń sọ. Àgbẹ, ọde,̣ apẹja àti ọ̀ṣìn ẹran ni ìṣe wọn. Ẹ̀sìn Mùsùlùmí àti ti ìbílẹ̀ ni wọ́n ń ṣe papọ̀. Àwọn wọnyi wa ni Orílẹ́ èdè Nàìjíríà àti Kamẹrúùnù. wọn jẹ ẹya Bantu. Àwọn kaka, Tikong ati Bafun ni wọn jọ pààlà. Ẹsin ibilẹ ati ẹsin musulumi ni wọn n sin.
Mambila
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2905
2905
Murtala Muhammad Murtala Ramat Mohammed tí a bí ní November 8, 1938–February 13, 1976) je olori ijoba Nigeria gege bi ologun lati odun 1975 si 1976. Igba ti awon ologun egbe re fe gba ijoba ni won pa. Ogagun Obasanjo ti o je igbakeji re ni o bo si ori oye gege olori ijoba lati 1976 si 1979. Igbesi aye. A bí ògágun Murtala Ramat Muhammed ni ojó kéjo, osù kejì odún 1938 (8/2/1938). Olórí ológun ní ó jé. Ó di alákòso ológun orílè èdè Nàígíríà ní 1975 títí di odún Feb 13, 1976 Murtala Mohammed jé elésìn Mùsùlùmí, Hausa ni pèlú láti (òkè oya apá gúúsù. Ó kékò ológun ní British Academy, Sandhurst. Murtala kò faramó ìjoba ológun Johnson Aguiyi Ironsi tí ó fipá gbà joba ni osù kìíní odún 1966 nínú èyí tí wón pa òpòlopò olórí Nàíjíríà tó jé omo apá gúúsù lónà tó burú jáì! Fún ìdí èyí ó kópà nínú ìfipá - gbà ijòba tó wáyé ni July 21, 1966. Wón fipá gba papakò òfurufú ìkejà; èyí tí wón ti yí orúko rè sí Murtala Mohammed International Airport làti fi yé. Ó kókó fé fi ìfipá gbà ijoba yìí gégé bíi igbésè fún àwon ara gúúsù láti ya kúrò lára Nàíjíríà sùgbón ó da àbá yìí nù nígbèyìn. Ìfipá gbajoba yìí ló mú ògagún (lieutenant-colonel) Yakubu Gowon jé alákòso orílè èdè Nàígíríà. Ní July/29/1975 àwon ologun tó jé òdò fi ògágun Murtala je alákoso orílè èdè yìí láti jé kí Nàígíríà padà sí ìjoba alágbádá Democracy. Omo odún méjìdínlógójì ni Murtala Ramat Muhammed nígbà tí àwon ológun fi je alákoso rópò Gowon. Murtala kó pa pàtàkì nínú ogun abélé. Ó jé òkan nínú adarí omo ogun Nàígíríà nígbà tí ogun náà dójú iná tán po. Òun ló fà á tí ikojá òdò oya (River Niger) àwon omo ogun Biyafira Biafra se já sí pàbó. Murtala ò lówó sí bí ìfipá-gbà-joba tó mu gorí oyè. Lógán tí Murtala gbàjòba, ara ohun tó kókó se ni; ó pa ètò ìkani Census ti odún 1973 re, eléyìí tó jé pé ó fì jù sí òdò àwon gúúsù nípa ti ànfàní. Ó padà sí ti odún 1963 fún lílò nínú isé. Murtala Mohammed yo òpòlopò àwon ògá ise ijoba tí ó ti wà níbè láti ìgbà ìjoba Gowon. Ó tún mú kí àwon ará ìlú ni ìgbèkèlé nínú ìjòba alápapò. Ó lé ni egbàárùn (10,000) òsísé ìjoba tí Murtala yo lénu isé nítorí àìsòótó lénu isé, àbètélè, jegúdú-jerá, síse ohun ìní ìjoba básubàsu, àìlèsisé-lónà-tó ye tàbí ojó orí láìfún won ní nkankan. Fífòmó Murtala kan gbogbo isé ìjoba pátápátá, bí àwon olópàá, amòfin, ìgbìmò tó n mójútó ètò ìléra, ológun, àti Unifásitì. Àwon olórí isé ìjòba kan ni wón tún fi èsùn jegúdú jerá kàn, tí wón sì báwon dé ilé ejó. Murtala tún fó egbàárùn owo-ogun sí wéwé. Ó fún àwon alágbádá ni méjìlá nínú ipò méèdógbòn ti amojútó ìgbìmò isé ìjoba. Ìjoba àpapò gba àkóso ilé isé ìròyìn méjì tí ó tóbi jù lo lórílè èdé yìí. Ó jé kí gbígbé ìròyìn jade wa làbé ìjoba àpapò nìkan. Murtala mú gbogbo Yunifasiti tó wà lábé ìjoba ìpínlè sí abé àkoso ìjoba àpapò. Mélòó lafé kà nínú eyín adépèlé ni òrò àwon ohun ribi-ribi tí Murtala gbése nígbà ti re. Ara won tún ni dídá ìpínlè méje mó méjìlá tó wà tèlé láti di mókàndínlógún. Murtala se àtúnyèwò ètò ìdàgbàsókè elekéta orílè èdè. Ó rí ìgbówólórí (inflation) gégé bí ìdàmú nlá tó n se jàmbá fún òrò ajé e wa. Fún ìdí èyí, ó pinnu láti dín owó tó wà lode pàápàá èyí tí wón n ná le isé ìjoba lórí ku. Ó tún gba àwon onísé àdáni níyànjú láti máa sesé tí àwon òsìsé gbogbo-o-gbo ti je gàba lé lórí. Murtala tún se àtúnyèwò òye ise ìtójú ìlú tó ní se pèlú ìlú mìíràn tí àwon egbé ìlú tí ó n sèdá epo ròbì lágbàáyé (OPEC). Ó jé kí Nàíjíríà je ohun kìíní tí ó kà sí nípa ti ànfàní àti iye tí wón dálé epo ròbì. Láìrò télè, ògágun Murtala dèrò òrun ni ojó ketàlá osù kejì, odún 1976. Wón da lónà nínú mótò rè, nígbà tí òun ti mósálásí bò nínú ìfipá-gbà-joba tí ó jé ìjákulè nígbèyìn. Owó te àwon òlòtè tó pa á, sùgbón kì lé tó pa òsìkà ohun rere á tí bà jé. Murtala Ramat Mohammed ti fayé sílè. Èpa kò bóró mó. Ká tó rérin ó digbó, ká tó rèfon ó dò dàn, ká tó réye bí òkín Murtala Ramat Mohammed ìyén di gbére.
Murtala Muhammad
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2906
2906
Muhammadu Buhari Nigeria current president Muhammadu Buhari (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ ketàdínlógún, Oṣù Kejìlá Odún 1942) olóṣèlú tí ó jẹ́ Ààrẹ orílè-èdè Nàíjíríà láàrin ọdún 2015 sí ọdún 2023. Ó lo ṣáà àkọ́kọ́ rẹ̀ láàrin odún 2015 sí 2019 àti kejì láàrin ọdún 2019 sí 2023. Buhari tí fìgbà kan jẹ́ ogágun Méjọ̀ Gẹ́nẹ́rà àti pé ó j̣e olórí orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lati 31st Oṣù kejìlá odún 1983 sí Oṣù kẹjó odún 1985, léyìn tí ó fi kúùpù ológun gbàjọba. Igbesi aye tete. A bí Muhammadu Buhari sí ìdílé Fulani ní ọjọ 17 Kejìlá 1942, ní Daura, Ìpínlè Katsina, baba rẹ ni Hardo Adamu, ẹni tí ó jẹ́ olori Fulani, orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Zulaihat, ẹni tí ó Hausa. Òun ni ọmọ kẹtalelogun bàbá rẹ̀. Ìyá Buhari ni ó tọ dàgbà, bàbá rẹ̀ fi ayé sílè nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rinrin. Ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Ológun. Buhari dara pò mó Nigerian Military Training College (NMTC) ní ọdun 1962, ó jẹ́ omo odun kan dínlógún nígbà náà. Ní oṣù kejì ọdún 1964, a yí orúkọ ilé-ìwé ológun náà padà sí Nigerian Defence Academy (NDA). Ní àárín 1962 sí 1963, Buhari kó nípa ìmò ogun ní Mons Officer Cadet School ní ìlú Aldershot, England. Ní oṣù kínní ọdún 1963, nígbà tí Buhari jẹ́ ọmọ ọdún ogún, a sọ́ di lieutenanti kejì.
Muhammadu Buhari
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2907
2907
Chuba Okadigbo Chuba Okadigbo (17 December, 1941 - 25 September, 2003) je oloselu omo ile Naijiria lati eya Igbo ti a bi ni odun 1941 ti o si ku ni odun 2003. Okadigbo je Aare awon Alagba ile Igbimo Asofin Naijiria lati 1999 titi de 2000. Itokasi. <ns>10</ns> <id>19502</id> <revision> <id>216362</id> <parentid>166404</parentid> <timestamp>2011-07-02T11:03:18Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format>
Chuba Okadigbo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2925
2925
Èdè Oríṣìíríṣìí àwọn onímọ̀ ní ó ti gbìnyànjú láti fún èdè ní oríkì kan tàbí òmíràn, ṣùgbọ́n kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn oríkì wònyìí, kí èdè túmọ̀ sí? Èdè níí ṣe pẹ̀lú ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń lò ní àwùjọ yálà fún ìpolówó ọjà, ìbáraẹni sọ̀rọ̀ ojoojúmó, ètò ìdílé tàbí mọ̀lẹ́bí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ó ní: "Èdè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìrú kan gbòógì tí àwùjọ àwọn ènìyàn ń lò láti fi bá ara ẹni sọ̀rọ̀". Raji (1993:2) pàápàá ṣe àgbékalẹ̀ oríkì èdè ó ṣàlàyé wípé; “Èdè ni ariwo tí ń ti ẹnu ènìyàn jáde tó ní ìlànà. Ìkíní lè ní ìtumọ̀ kí èkeji maa ní. Èdè máa ń yàtọ̀ láti ibìkan sí òmíràn. Ohun tó fà á ni pé èdè kọ̀ọ̀kan ló ní ìwọ̀nba ìrú tó ń mú lò. Èdè kankan ló sì ní ìlànà tirẹ̀ to ń tèlé.” Wardlaugh sọ nínú Ogusiji et al (2001:10) wí pé: “Èdè ni ni àwọn àmì ìsọgbà tí ó ní ìtumọ̀ tí o yàtọ̀ tí àwọn ènìyàn ń lò láti fi bá ara wọn sọ̀ọ̀.” Àwọn Oríkì yìí àti ọ̀pọ̀lọpọ oríkì mìíràn ni àwọn Onímọ̀ ti gbìyànju láti fún èdè, kí a tó lè pe nǹkan ní èdè, ó gbọ́dọ̀ ní àwọn èròja wọ̀nyí: èdè gbọ́dọ̀ jẹ́: 1. Ohun tí a lè fi gbé ìrònú wa jáde 2. Ariwo tí ó ń ti ẹnu ènìyàn jáde 3. Ariwo yìí gbọ́dọ̀ ní ìtumọ̀ 4. Aríwo yìí gbọ́dọ̀ ní ìlànà ìlò tí yóò ní bí a ti ṣe ń lò ó. 5. Kókó ni á ń kó ọ, kì í ṣe àmútọ̀runwá 6. nǹkan elémú-ín tó lè dàgbà sí i, tó sì lè kú ikú àìtọ́jọ́ ni èdè. 7. A lè so èdè lẹ́nu, a sì le kọ́ sìlè. Síwájú sí í, a ní àwọn àbùdá ti èdè ènìyàn gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ (1) Ìdóhùa yàtọ̀ sí ìtumọ̀ (Ar’bitransess) (2) Àtagbà Àṣà (Cultural transmission) (3) Agbára Ìbísí (Productivity) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo. Gbogbo Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn yàtọ̀ láàrín èdè ènìyàn àti ti ẹranko kì í ṣe ohun tí ó rorùn rárá. Nǹkan àkọ́kọ́ nip é a gbọ́dọ̀ wá oríkì èdè tó ń ṣiṣé lórí èyí tí a ó gbé ìpìnlè àfiwé wa lè. Ṣùgbọ́n ṣá, kò sí oríkì tí ó dàbí ẹni pé ó ṣàlàyé oríkì èdè tàbí tí ó jẹ́ ìtéwógbà fún gbogbo ènìyàn. Charles hocket ṣe àlàyé nínú Nick Cipollone eds 1994 wípé: Ọ̀nà kan gbòógì tí a fi lè borí ìṣòro yìí nip é, kí a gbìnyànjú láti ṣe ìdámọ̀ ìtúpalẹ̀ àwọn àbùdá èdè ju kí a máa gbìnyànjú láti fún ẹ̀dá rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì ní oríkì. Torí náà, a lè pinu bóyá èdè ẹranko pàápàá ni àwọn abida yìí pẹ̀lú… Ohun tí a mọ̀ nípa èdè ẹranko ni pé, kò só èdè ẹranko kọ̀ọ̀kan tí ó ní àwọn àbùdá èdè ènìyàn tí a ti sọ síwájú. Èyí ni ó mú kí á fẹnukò wípé àwọn èdà tí kìí ṣe àwọn ènìyàn kì í lo èdè. Dípò èdè, wọn a máa bá ara wịn sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ń pè ní ẹ̀nà, àpẹẹrẹ ìfiyèsí (Signal Cocle). Gbogbo ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn yàtọ̀ sí èyí kì í ṣe èdè. Àwọn ọ̀nà náà ní: (1) Ìfé sísú (2) Ojú ṣíṣẹ́ (3) Èjìká sísọ (4) Igbe ọmọdé (5) Imú yínyín (6) Kíkùn ẹlẹ́dẹ̀ (7) Bíbú ti kìnnìún bú (8) Gbígbó tí ájá ń gbó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo ariwo ti a kà sílẹ̀ wọ̀nyí kì í ṣe èdè nítorí pé; (1) Wọ́n kò ṣe é fọ́ sí wẹ́wẹ́ (2) Wọn kì í yí padà (3) Wọn kì í sì í ní Ìtumọ̀ Pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí mo ti sọ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàrín èdè ènìyàn àti ẹranko, Ó hàn gbangba wípé a kò le è fi èdè ẹranko àti ti ènìyàn wé ara wọn. Yorùbá bì wọ́n ní “igi ímú jìnà sí ojú, bẹ́ẹ̀ a kò leè fi ikú wé oorun. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èdè ènìyàn àti ẹranko rí. Nínú èdè ènìyàn lati rí gbólóhùn tí ènìyàn so jáde tí a sì leè fi ìmò ẹ̀dá èdè fó sí wéwé. Àtiwípé àǹfàní káfi èdè lu èdè kò sí ní àwùjọ ẹranko gẹ́gẹ́ bí i ti ènìyàn. Fún bí àpẹẹrẹ. Olu ra ìṣu Olú nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀-Orúkọ ní ipò Olùwá, rà jẹ́ Ọ̀rọ̀-ìṣe nígbà tí ísu jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ ní ipò ààbọ̀. A kò le rí àpẹẹrẹ yìí nínú gbígbó ajá, kike ẹyẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà èdè ènìyàn yàtọ̀ sí enà apẹẹrẹ, ìfiyèsí (Siganl Code) àwọn ẹranko. Àwọn Ìwé àmúlò. Fatusin, S.A (2001), An Introduction to the Phonetics and Phonology of English. Green-Field Publishers, Lagos. Rájí, S.M (1993), Ìtúpalẹ̀ èdè àṣà lítíréṣọ̀ Yorùbá. Fountan Publications, Ibadan. Ogunsiji, A and Akinpẹlu O (2001), Reading in English Languag and Communication Skills. Immaculate-City Publishers, Oyo. Nic Cipollone eds (1998), Language files Ohio State University Press, Columbus.
Èdè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2933
2933
Merina MERINA Àwọn ti won n so ede wọ̀nyí jẹ́ ará Malayo-Indonesian. Wọ́n ní ìtàn tó gbọ̀ọ̀rìn nípa ìsẹ̀dá wọn ati nipa àṣà àtí ètò òsèlú won láàrin orisi awọn ènìyàn Madagascar. Ẹsin kiriyo ati ẹ̀sìn eranko ni wọn ni sìn
Merina
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2934
2934
Mende Ede Mende jọ ede awọn Mande. Àwọn wọ̀nyí wá lati Sudan si apá àríwá. Eya Menda jẹ ẹ̀yà ti o tobi ni Afirika wọn lé ni ọ̀kẹ́ méjì.
Mende
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2935
2935
Mossi Mossi (tabi Moaaga) Àwọn ènìyàn Mossi jẹ jagunjagun. Olóyè Moro Naba ni Olórí wọn. Àwọn tó kọ́kọ́ da Mossi àkọ́kọ́ sílẹ̀ wá lati Gbana. Awọn ló tóbi ju ni Burkina Faso
Mossi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2937
2937
Ngbaka Eya Ngbaka tabi M'Baka je eya eniyan ni Orile-ede Olominira Arin ile Afrika. Awọn wọnyi jẹ awon to ń gbé ìlú Ngbaka, kò sì sí agbára kan to da wọn pọ, ńṣe ni olukuluku n se bi o ti fẹ láàrin ìlú. Awọn ẹya náà ń gbe Ubangi.
Ngbaka
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2952
2952
Ìtàn àkọọ́lẹ̀ Yorùbá THOMAS PETER TAIWO ṣẹ Ìtàn bi ede Yorùbá ṣe di kíko sí lè (Yorùbá Orthography) Láti ayébáyé, èdè Yorùbá wa lábé ìpínsí sòrí tí ọ̀gbẹ́nì thamstrong (1964) se fún àwọn èdè gbogbo èdè Yorùbá bọ́ sí abẹ́ ìpín èdè “KWA”. Èyí sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé èdè olóhùn (tonalanguage) ni Yorùbá jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí a se mọ̀ pé tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀ rí, a kì í kọ èdè Yorùbá sí lẹ̀, sí sọ nìkan ni a ń sọ ọ́ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun dé tí òwò ẹrú si bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹ wọ́n bèrè sí ní í kó àwọn ọmọ bíbí ilẹ́ Yorùbá lẹ́rú lọ sí òkè-òkun. Èyí tẹ̀síwájú fún ìgbà pípẹ́ kán-fin-kése títí di àsìkò tí ìjọba àpapọ̀ àgbáyé gbìmọ̀ pọ̀ ti òpin sí òwò ẹrú yìí. Fún ìdí eléyìí, ó di òranyàn kí á dá àwọn ẹrú wònyí padà sí ibi tí wọ́n ti sẹ̀ wá. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹní tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá padà sí ilẹ̀ wọn. ṣùgbọ́n ní ọwọ́ àsìkò ti wọ́n fi wà ní oko ẹrú yíì ni wọ́n ti ń se ẹ̀sìn jíjẹ́-ọmọ-lẹ́yìn-kírísítì (chiristanity) Àwọn òyìnbó amúnsìn yìí sí rí i ní ọ̀ranyàn pẹ̀lú láti se agbára lórí i bí ẹ̀sìn yí yóò se máa tẹ̀síwájú láàrin wọn. Ẹ̀yí gan-an ló mú kí wọn se akitiyan lórí bí wọn yóò se se àyípaà ìwé-mímọ́ nì –Bíbélì sí èdè Yorùbá. Nínú sí se eléyìí ó se pàtàkì láti rí i dájú pé ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá tó sì jẹ́ gbédè-gbijọ̀ èdè náà wà ní bẹ̀ àti kí ó sì kó ipa takuntakun nínú sí se àyẹ̀wò, àfikún, àyokúrò àti afótónu tó yaarantí ló rí iṣẹ́ náà. Àwọn ènìyàn bíi Humnah Kilham (1891) John Rahar, Gollmer and Bowdich (1817) àti Àjàyí Growther (1815) ló bẹ̀rẹ̀ isẹ́ lórí kí kó lẹ́tà àti àwọn òǹkà jọ. Okùnrin kan tí ń jẹ́ Bowdich ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ si ṣẹ́ lórí i àwọn òǹkà Yorùbá bí i, óókan, ééjì, ẹ́ẹ́ta títío do ri i ẹ́ẹ́wà-á ó sì se àwọn isẹ́ yìí í ní odún (1817). Hamah Kilhar ní (1828) náà sísẹ́ lórí kíkọ sí lẹ̀ èdè tí à ń mẹ́nu bà yìí. Ó fún wa ní ìlànà méjì tí ó se pàtàkì jù nínú isẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn Crowther, a ò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn yeekan-yeekan bi, Henny Venn (ijo CMS), Àlùfáà Charle Andrew Gollmer (German), Alufa Heny. Townsend, Samuel Johnson abbl. Tí wọ́n se akanse iṣẹ takun-takun lórí bí èdè Yorùbá se di kí ko sèle. Akiyesi pàtàkì kan ti a lee se nínú gbogbo atotonu lórí bi èdè Yorùbá se di kiko silẹ yin i pe nínú gbogbo àwọn to siṣe yi ti wọn jẹ àwọn oyinbo atohun rinwa alawọ dúdú kan ni a timenu ba, ṣùgbọ́n èyí ko fi bẹ́ẹ ri bẹ. Àwọn dúdú ti wọn ko pa nínú iṣe yìí naa po jojo ṣùgbọ́n fún ìdí kan tàbí òmíràn ti a ko ni lee sòro nípa wọn. Ìwọ̀nba kéréje tí a leè mẹ́nu bà nínú ìtàn bí èdè Yorùbá ṣe di kíko sílẹ̀ nì yí.
Ìtàn àkọọ́lẹ̀ Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2960
2960
Àyàn Ayan (Drummer) Iṣẹ́ Àyàn Iṣẹ́ ìlù lílú ni a n pe ni ìṣẹ́ àyàn, àwọn ti o n sẹ iṣẹ yii ni a n pe ni “Aláyàn tàbí ‘Àyàn’. Iṣe àtìrandíran ni èyi, nitori iṣẹ afilọmọlọwọ ni. Gbogbo ọmọ ti Onílù bá bí sí ìdi Àyàn Agalú ni o ni láti kọ ìlù lílù, paapaa akọbi onílù. Dandan ni ki àkọ́bí onílù kọ iṣẹ ìlù, ko si maa ṣe e nitori àwọn onìlu ko fẹ ki iṣẹ́ náà parun. Yàtọ̀ si àwọn ti a bì ni ìdile onìlu tabi awọn o ọmọde ti a mu wọ agbo ifa, Ọbàtálá, Eégún tàbí Ṣàngó ti wọn si n ti pa bẹ́ẹ̀ mọ oriṣiiriṣii ìlù wọn a maa n rì awọn to ti ìdílé miíran wa láti kọ ìlù lìlú lọwọ awọn onìlu. Àwọn Yorùbá bọ wọn ni “àtọmọde dé ibi orò ń wò fínní-fínní, àtàgbà dé ibi orò ń wò ranran” Òwe yìi tọka si i pe ko si ohun ti a fi ọmọdé kọ ti a si dàgbà sínú rẹ̀ ti a ko ni le se dáadáa. Láti kékeré làwọn Yorùbá ti n kọ orìṣiiriṣi ìlù lìlú. Nígba ti ọmọde ba ti to ọmọ ọdún mẹ́wàá sí méjìlá ni yóò ti máa bá baba rẹ ti o jẹ onílù lọ òde aré. Láti kékeré yìí wá ni yóò ti máa foju àti ọkàn si bi a ti n lu ìlù. Àwọn ọmọdékùnrin tí ń bẹ nínú agbo àwọn tí ń bọ̀ Ọbàtálá yóò máa fojú síi bi a ti ń lu ìgbìn, àwọn tí n bẹ lágbo àwọn onífá yóò máa kọ bi a ti ńlu Ìpèsè. Ọ̀nà kan náà yii làwọn tí ń bẹ lágbo àwọn Eléégún àti onísàngó ń gbà kọ́ bi a ti ńlu Bàtá. Àwọn ọmọdé mìíran máa ń gbé tó ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lẹ́nu iṣẹ́ ìlù kíkọ́ yìí.
Àyàn
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2962
2962
Ìpèsè Ipese Drum ÌPÈSÈ:- Ìlù tí àwọn babaláwo ńlù lọjọ ọdún ifá ni Ìpèsè. Awọn mìíran npe e ni Ìpẹ̀sì. Yatọ̀ si ọjọ ọdun ifa, a tun nlù Ipese lọjọ̀ ti a ba n ṣe isinku tabi ijade oku ọkan nínú àwọn asaaju nibi Ifa. Mẹrin ni ọ̀wọ́ ìlù ti a papọ se Ìpèsè:- (a) Ìpèsè:- Ìlù yi funra rẹ lo tóbi jù nínú mẹ́rèẹ̣́rin. Igi la fi n gbẹ ẹ. Ó sì gbà tó ẹsẹ bata ti a fi bo o loju mọ ara igi ti a gbẹ ti a si da ìho sinu rẹ. (b) Àféré:- Ìlù yìí lo tobi tẹle Ipese. Igi la fi n gbẹ àféré, ṣùgbọ́n o lẹgbẹ ti o fẹ jù ipese ko ga to ipese, ẹsẹ mẹta ni o fi dúró nilẹ. (d) Àràn: Ìlù yìí kò tobi to Aféré, bẹẹ ni ko ga to o. Òun náà ni ẹsẹ̀ mẹ́ta to fi dúró (e) Agogo:- Ohun kẹ́rin ti a n lù si Ìpese ni agogo. Irin la fi ńrọ agogo. Abala ìrìn meji ti a papọ, ṣùgbọ́n ti a da ẹnu rẹ si lapa kan ni agogo.
Ìpèsè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2963
2963
Àgèrè Agere Drum ÀGẸ̀RẸ̀:- A nlù agẹrẹ lọjọ ọdun awọn ọdẹ. Idi niyi ti a fi n pe Agẹrẹ ni ìlù ogun. Bi ọlọ́ọ́dẹ tàbí olórí ọdẹ kan bá ku ni a n lù agẹrẹ. Ọ̀wọ́ ìlù mẹta la papọ̀ se àgẹ̀rẹ̀ ògún. (a) Àgẹ̀rẹ̀:- Eyí ni ìlù to tobi ju pátápátá. Igi la fi ngbẹ agẹrẹ. Oju meji Ọgbọọgba lo sì nì. Ìlù yi dabi ìbẹ̀mbẹ́. Awọ la fin bòó lójú ọ̀nà méjèèjì, okun la si nfi wa awọ ojú rẹ lọ́nà méjèèjì ki o le dún. (b) Fééré:- Ìlù yii kere jù agẹrẹ lọ. Igi naa la fi gbẹ ẹ, ṣùgbọ́n ko fẹ to agẹrẹ. (d) Aféré: Ìlù yii lo kere jù awọn meji ìsáájú lọ.
Àgèrè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2964
2964
Gbẹ̀du Pàtàkì ni Gbẹ̀du jẹ̀ nínú àwọn ìlù ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìlù yii kan naa lawọn kan n pen i àgbà. Ìyàńgèdè ni ìlẹ̀ Yorùbá. Ìlù mẹta la le tọkasi nínú ọwọ ìlù Gbẹ̀du. (a) Aféré:- Ìlù nla ni afẹrẹ. Ó ga tó iwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin ó sì gùn gbọọgì. Géńdé ti ko ba dara rẹ loju ko le gbe nìlẹ. Oùn rẹ̀ máa n rìnlẹ dòdò. Ìkeke ni a fi maa nlù. (b) Apéré tabi Opéré: Ìlù yii lo tobi tẹle afẹrẹ labẹ ọmọ ìlù ti a n pe ni Gbẹdu. Igi la fi gbẹẹ, ṣùgbọ́n ko ga, ko si fẹ lẹnu to aféré. (d) Ọbadan: Ìlù yii lo kere ju nínú ọ̀wọ́ ìlù Gbẹdu. Igi la fi gbẹẹ bi ti awọn yooku. Ko sit obi to apẹẹrẹ rara. Gbẹdu se patakì pupọ nitori pe o jẹ ìlù ọba. A kii dede n lu u. Ìlù yi wa fun ìyẹ̀sì awọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá. Bi ọba ba gbesẹ tabi ijoye nla kan tẹri gbaso wọn n lù Gbẹdu lati fi tufọ.
Gbẹ̀du
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2965
2965
Ìgbìn Ìlù Ìgbìn Ìlù oriṣà Ọbàtálá ni ìlù yii ọjọ̀ àjọ̀dún Ọbàtálá ni àwọn olóòṣà yìí ńkó ijó Ìgbìn sóde. Oriṣii ìlù mẹ́rin la le tọ́ka sí lábẹ́ ọ̀wọ́ ìgbìn. (a) Ìyá-nlá: Igi la fi n gbẹ́ ìlù yìí. Ihò ìnu ìgi naa si dọ́gba jálẹ̀. Awọ lafi ńbo oju ìgi ìlù yi lójù kan. (b) Ìyá-gan: Ìlù yii lo tẹle iya-nla. Òun ló sì dàbí omele tàbí emele ìyá-ńlá, (d) Keke: Ìlù yìi lo tẹle Iya-gan. Ó kó ìpa pàtàkì nínú ìgbin. (e) Aféré: Ìlù yii lo kere jù nínú awọ ìlù mẹrẹẹrin ti a le tọka si nínú ọwọ ìlù igbin. Igi náà ni a fi n gbẹ ẹ bi i ti awọn mẹta yooku. Awọn ti n gbẹ ìlù yii máa n sojú àti ìmú sára ìgi ìlù yii.
Ìgbìn
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2969
2969
Gangan Gangan (Drum) Gangan: Ìlù yii lo tẹle kẹrikẹri. Ó kéré ju àwọn méjèèjì ìsaájú lọ. Igi la fi ń gbẹ́ òun náà bí i ti àwọn tóókù. Kò sí ohun ti kẹríkẹrì ní tì gangan ò ní.
Gangan
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2971
2971
Kànnà-n-gó Kanna-n-go (Drum) Kànnàngó: - Igi ti a fi se kànnàngó kéré jù igi ti a fi se ìsaaju. Ṣùgbọ́n gbogbo ohun ti ìsaájú ni náà ni kannango ni. Bì a ba tẹ kọ̀ngọ́ bọ kànnàngó, o n dun leti kerekere ju ìsaájú.
Kànnà-n-gó
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2972
2972
Gúdúgúdú Gúdúgúdú Ìlù yi gan an là bá máa pè ní omele dùndún. Igi la fi n gbẹ́ ẹ, ṣùgbọ́n ojù kansoso lo nì. O fi èyí yatọ si awọn bi ìyá-ìlù, kẹrikẹri, Gangan, ìsaájú ati kànnàngó ti wọn ni ojù méjìméjì. Ìlù yìí kò se gbé kọ́ apá bi ti àwọn yòókù ọrùn la máa ń gbé e kọ́ nígbà tí a bá ń lùú. Bí o ti kéré tó ipa tí ó ń kó nínú ìlù dùndún kò kéré. Kerekere ní ń dún nígbà gbogbo nítorí pé awọ ojú ìlù náà kò dẹ̀ rárá.
Gúdúgúdú
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2974
2974
Àpíntí Apinti (Drum) Àpíntí: Ọkan nínú àwọn ìlù ti a nlu nibi aseyẹ ni apinti. Ẹya ìlù mẹta la papọ ti a n pen i àpíntí. (a) Iya-ìlù: Igi ti a gbẹ ti a si da iho sìnu rẹ la fi nṣe ìya-ìlù. Oju kan ṣoṣo lo ni. Oju kan ṣoṣo yi la n fi awọ bo. Iho ìnu ìgi yi jade si isalẹ rẹ, ko si ni awọ. Iya-ìlù yi ni okun tẹẹrẹ ti a so mọ ara rẹ. Okun náà la fi ngbe e kọpa. (b) Omele tabi Emele: Igi ni a fi n gbe oun náà, ṣùgbọ́n o kere pupọ̀ ju iya-ìlù lọ. (d) Agogo: Irìn la fi nṣe agogo ti a n lu si apinti. Awọn alagbẹdẹ lo n see.
Àpíntí
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2975
2975
Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun èlò amúlùúdùn ní ilẹ̀ Yorùbá. Jákè jádò ìlẹ Yorùbá la ti ń lù sẹ̀kẹ̀rẹ̀, pàá pàá jùlọ níbí àṣeyẹ oríṣiríṣi. "Sèkèrè" jé òkan. làra oh un tí ó n mú ìdàgbàsókè àti ìdánilárayá wá fún àwon ènìyàn ní àwùjo .Sèkèrè yi jé òkan lára ohun ìlù tí wón n lòní apá ìwò oòrùn nd orílè èdè Nàìjíríà tí a so ìlèkè mó lára igbá tí a sì fi àwòn so ara rè. Sèkèrè jé irinsé ìlù tí ó wópò níìwò oòrùn Áfíríkà àti láàárín àwon aláwò funfun. Nígbàtí a bá n korin ni a máa n mìí. Orísirísi ònà ni àwon ìlú kankam n pe sèkèrè ìlú Cuba n peé ní "chekere" wón sì tún pèé ní "aggué(abwe). Bákan náà Brazil n pèé ní"xequerê". Àwọn ìlù akọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lu Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Kósó: Kósó ni ìlù tí a fi igi ṣe. Awọ la fi ń bo orí igi tí a gbẹ́ náà. O gùn gbọọrọ tó ìwọ̀n ẹṣẹ̀ bàtà méjì àbọ̀. Ó sì tóbi lórí níbí tí a fi awọ bò ju ìsàlẹ̀ lọ, ó ní ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ tí a lè fi gbé e kọ́ apá. Bẹ́mbẹ́: jẹ́ ìlù tí a fi awọ bo lójú méjèèjì, tí wọ́n sì tún fi awọ tẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí Òkun ṣòkòtò kọ lójú kí ohùn rẹ̀ ó lè dun yàtọ̀ létí. Awọ tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn ṣòkótò yí náà ni wọ́n fi ma ń fà tí wọ́n sì ń fọwọ́ kan ojú ìlù náà kí olè mú Ohun tí onílù náà bá fẹ́ jáde lásìkò tí ó bá ń lùú. Aro: Ìlù kẹrin tí a ń lù sí sẹ̀kẹ̣̀rẹ̀ ni aro. Irin la fi ń ṣe aro, àwọn alágbẹ̀dẹ ló sì ń ṣe é.
Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2976
2976
Àpíìrì Apiiri Àpíìrì tàbí sẹkẹrẹ: Aré yi wọ́pọ̀ lágbègbẹ̀ Èkìtì. Ó yàtọ̀ sí ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti a kọ́kọ̣́ sàlàyé rẹ̀ nítorí pé a kìí lu aro, koso, àti bẹ̀mbẹ́ síi. Kìkì ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ là ń lù nìbi ti a ba nsere apíìri. Orìṣii ṣẹ̀kẹ̣̀rẹ̀ mẹ́ta là ń lù si apiiri. (a) Ìya-àjẹ́: Àgbe to tobi díẹ̀ la fi n ṣe Iya-aje. E so igi kan bayi la n ṣe sara owu ti a ran. Bi a ba ti seetan, a o fi owu ti a se eso si yi kọ ara agbe náà lọwọọwọ titi de ọrun rẹ̀. Eso ara agbe yi ni n dun lara rẹ nìgba ti a ba n luu. (b) Emele-ajè: Emele-aje meji la n lu si apiiri. Agbe la fi n ṣe e bi ti iya-aje. Agbe ti a fi n se emele-aje ko tobi to eyi ti a fi n se iya-aje. Ìdi niyi ti didun wọn ko fi fẹ dodo bi ti Ìya-aje.
Àpíìrì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2979
2979
Bwa ! style="background-color: #b0c4de" | Èdè Buamu ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀sìn Animism (85%)<br>Christianity (10%)<br>Islam (5%) Bwa tabi Bwaba (lọ́pọ̀) je eya kan ni arin ile The places left unconquered were raided by the Bamana, which led to a weakening of the Bwa social and political systems. Burkina Faso ati Mali. Iye àwon ènìyàn eya yi je je 300,000 lapapo.
Bwa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2980
2980
Ṣókúwé Ṣókúwé je eya eniyan ni Apa Arin Afrika. Ìran àwọn tí o ń sọ èdè yìí wá ní orílẹ̀ èdè olómìnira Congo àti Portuguese. Àwọn alábàgbéé wọn ni Luba-Lunda. Orílẹ̀ èdè Angola ni á tí ń sọ èdè yìí. Iye àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè yìí jé 455, 88. Lára ẹbí Niger-Cong0 ni èdè yìí wa, ẹka rẹ si ni Bantu.
Ṣókúwé
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2983
2983
Ekeeti Ekeeti (Eket) Eket:- Èdè Bantu ni èdè yìí. Gusu Ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Nigeria ni wọn ti ń sọ èdè yìí. Ẹya àwọn ti ó ń sọ èdè Ibibio ni wọn, wọ́ wà ní Ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom ni orílẹ̀ èdè Nigeria. Wọn ń sọ èdè yí náà ni Benue Congo.
Ekeeti
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2987
2987
Kongo
Kongo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2988
2988
Èdè Bijago Èdè Bijago tabi Bidyogo jẹ́ ọkan pàtàkì lára àwọn orisìírísìí èdè bí i mẹ́ẹ́dógbọ̀n tí wọ́n ń sọ láti ilẹ Guinea-Bissau, orúkọ mìíràn tí a tún mọ èdè yìí sí ni: Bigogo, Byougout. Bijuga, Budjago, Bugago. Bákan náà ni a mò wọ́n mọ àwọn. Ẹ̀ka Èdè bíi: Anhaki, kagbaaga, Kajoko, Kamọna àti Orango wọ́pọ̀ nínú èdè Bidgogo. Gbogbo àwọn èdè náà ni wọn sì tì ń sọ títí di àkókò yìí. Àwọn Niger-Congo tó jẹ́ ẹya Bijago ló máa ń ṣọ èdè náà.
Èdè Bijago
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2989
2989
Bobo Madare Bobo Madare BOBO MADARE Èdè yìí jẹ mọ́ èyí tí wọ́n máa ń sọ ní ìwọ̀ oòrùn Africa. Orúkọ mìíràn tí a tún mọ èdè yìí sí ní: Balck bobo, Bobo Bobo Bobo fing. Àwọn èdè Adugbo wọn ni Benge Bobo, Dioula Bobo, Jula Sogokire Sya Syabere voré Zara. Ile Burkina. Faso ni wọ́n ti ń sọ ọ́. Nígbà tí wọn sijẹ̣ ẹ̀yẹ̀ ti Niger-Congo pẹ̀lú àwọn ẹya Bobo. Àwọn àmì ẹ̀ka wọn ni N.C. B B A B A. A tun rí èdè Bobo mìíràn tó jẹ mo ti Gusu ní: Burkina Faso, Mali. Wọ́n sì tì ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí titi di òní.
Bobo Madare
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2990
2990
Busoogi Busoogi (Bushoog) BUSHOOG Bushoog ni a mọ èdè yìí sí. Bákan náà ni wọ́n tún ń jẹ́. Bamong, Bushong, Bushongo, Busoong, Ganga, Kuba Mbale, Mongo Shongo. Wọ́n jẹ mọ ẹka èdè ti Djeenbe, Ngende, Ngombe, Ngombia, Ngongo, panga, Pianga, Shoba, Shobuia ìsobwa. Èdè náà tì wà títí dí oni lápá ijọba onimira ilẹ Congo. Bakan náà ni wọ́n jẹ́ ẹbi Niger-Congo ní ọ̀wọ́ ti Bushong. Awọn èèyàn tó n ṣọ wọ́n sì ju ẹgbàágbèje lọ.
Busoogi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=2991
2991
Ìdomà Èdè Idoma A lè rí Ìdomà ní ààrin gùngùn orílẹ̀ èdè Náígíríà. Àwọn tí wọ́n ń sọ èdè yìí jẹ́ igba méjì ati àádọ́ta ẹgbẹ̀rún. Àwọn aládùgbóò rẹ̀ ni Ibibo, Igbo, Mama àti Mumuye. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Idoma ni wọ́n jẹ agbẹ. Wọ́n si máa ń se àpọ́nlé àwọn baba ńlá wọn tí wọ́n ti kú.
Ìdomà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3016
3016
Mumuye MUMUYE. Àwọn wọ̀nyí jẹ ara ènìyàn Naijiria, wọn kere niye, wọn si da dúró tẹlẹ ni. Ipinle Taraba ni wọn n gbe ni Jalingo. Wọn le lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà irínwó. Isẹ́ Lagalagana ni wọn ń ṣe.
Mumuye
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3017
3017
Àṣà Nok Àṣà Nok yo jade ni arin ile Naijiria ni bi odun 1000 SK o si pare lai nidi ni bi odun 200 LK. A ko mo ohun ti awon ènìyàn náà pe ara won, nitori náà oruko àsà náà ni won fi so ilu won. Àsà Nok wa lati ariwa Afrika ni ipinlè Niger.
Àṣà Nok
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3052
3052
Èdè Ìgbìrà Èdè Igbìrà tàbí Ebira tàbí Egbira jẹ́ èdè ní Nàìjíríà (ní àwọn Ìpínlẹ̀ Kwárà àti Ẹdó àti Násáráwá). Èdè Igbìrà Èdè yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè Naìjírìà. Àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù kan. Wọn wà ní àgbègbè Èbìrà ní ìpínlè Kogi, Kwara, Edo, àti béè béè lo. Àwon èka èdè tí ó wà ní abẹ́ rẹ̀ ni Okene (Hima, Ihima) ìgbàrà (Etunno) Èbìrà ní ìsupò èka èdè, wón ń lò ó ní ilé ìwé.
Èdè Ìgbìrà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3053
3053
Ìgbìrà ! style="background-color: #b0c4de" | Èdè Ebira language ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀sìn Christianity and Islam Igbìrà tàbí Ebira je eya eniyan ni Naijiria. Èdè yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè Náíjíríà. Àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù kan. Wọn wà ni àgbègbè Ebira ní ìpínlẹ̀ Kwara, Edo, Okene àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ẹ̀ka èdè tí ó wà ní abẹ́ rẹ̀ ni Okene (Hima, Ihima) igbara (Etunno) Ebira ní ìsupọ̀ ẹ̀ka èdè, wọ́n ń lò ó ní ilé ìwé.
Ìgbìrà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3054
3054
Igbo E le ka ayoka ni Yoruba lori "Igbo":
Igbo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3055
3055
Ibo
Ibo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3056
3056
Èdè Ijọ
Èdè Ijọ
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3058
3058
Koin Koin Èdè koin Orúkọ àdúgbò tí wọ́n ń pè é ni Itajikan. Àwọn ènìyàn koin ní wọ́n sì ń sọ ọ́. Ó kún fún àlàyé kíkún lórí gírámà èdè. Ilè Cameroon ni wọ́n ti ń sọ ọ́. Àwọn ti wọ́n ń sọ èdè yìí jẹ́ àádọ́jọ ẹgbẹ̀rún. Àwọn mọ̀lẹ́bí èdè koin ni Niger-Congo, Atlántic-Congo, Volta-Congo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Koin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3059
3059
Èdè Kóngò Kikongo tabi ede Kongo je ede Bantu ti awon eya Bakongo ati Bandundu n so. A. Èdè tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ ni Kitumba, òun ta ń pè ní Kongó ní n ǹkan ṣe pẹ̀lú àpapọ̀ àwọn èdè Bantu. Àwọn ibi tí ati n sọ èdè yìí ni: Angola, Congo, Crabon ati Zoure. Ní àarin odún (1960) sí Ọdún (1996) àwọn tí ó n sọ èdè yìí dín díẹ̀ ni mílíọ̀nù mọ́kànlá. Àkọtọ́ èdè wọn muná dóko; ṣùgbọ́n wọn kìí lo àmì ohùn lórí gbogbo ọ̀rọ̀ wọn. Àkọtọ wọn tó wuyì yìí lo mú kí ohun èdè wọn dín kù ní lílò. B. Èdè Kongo Kongo tàbí Kikongo – ó jẹ́ èdè Bantu, àwọn ènìyàn Bakongo ni wọn ń sọ ọ́. Ààrin ilẹ̀ Afíríkà ni ó wà. Àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù méje ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n kó ní ẹrú ní ilẹ̀ Afíríkà tí wọ́n sì tà wọ́n fún America ni wọ́n ń sọ èdè yìí. Àwọn bí i mílíọ̀nù ni wọ́n ń lo èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè méjì. Kongo language
Èdè Kóngò
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3061
3061
Sínńtààsì Èdè Aafíríka AKANDE TITILAYO C. Sintaasi ede Aafirika SYNTAX- JOHN R. WATTERS. John R. Watters túmọ̀ sínńtààsì sí bí ìró àti ọ̀rọ̀ se ń so papọ̀ di gbólóhùn, àti bí àwọn ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan se hun ara wọn papọ̀ ní ìpele, ìpele di gbólóhùn. Gbogbo èdè ni wọ́n ní ju ọ̀nà kan lọ ti wọn ń gba hun ọ̀rọ̀ wọn. tí a bá ń kọ nípa èdè kan, àfojúsùn wa ni láti se àfìwé ìdí tí ìhun wọn fi pé orísìírísìí. Ní ilẹ̀ Afirika, ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èdè ni wọn ń lo Olùwà, àbò àti ọ̀rọ̀ ìṣe. A tún máa ń lo “less common word orders” nínú gbogbo èdè, láti sèdá gbólóhùn àyísódì. (SENTENCES WITH SINGLE CLAUSES) GBÓLÓHÙN ALÁWẸ̀ KAN. Ètò ọ̀rọ̀ (Word categories) Àwọn ọ̀rọ̀ tí a máa ń tò pọ̀ di gbólóhùn ni OR, IS, Apọnle, Eyan àti Atókùn. Iwájú ọ̀rọ̀ orúkọ ni atọ́kùn máa ń wà Post Position máa ń wa lẹ́yìn ọ̀rọ̀ orúkọ. Nínú èdè Afirika, OR ati Is se iyebíye. Àwọn èdè Africa máa ń lo Is dáadáa ju àwọn èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè àwọn European. Fún àpẹẹrẹ: Aghem, Bantu, Benu-Congo, Niger-Congo -(i) fi - baףּà – The bird is red. Ọ̀rọ̀ Ise ni wọ́n lo red fún nínú gbólóhùn yìí. - Ngiti, Lendu, Central Sudanic, Nilo-Sohare -(ii) mà m-àndi we are ill Ẹ̀wẹ̀, a lè lo ọrọ ìṣe ní ibi tí àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì bá ti ń lo àpọ́nlé (e.g. frequently, not yet, still, again) ati ọ̀rọ̀ àsopọ̀ (Conjunction) e.g. and, their’ - Yorùbá, Defoid, Benue – Congo, Niger- Congo (i) Ó tún ń lọ. He is going again. - Ejapham, Ekoid Bantu, benue-Congo – Niger-Congo (ii) à-njánà à-Chòr-á She is still talking Àwọn Èdè Africa kò ní Atókà púpọ̀ bí Europeans. Èdè Afíríka jẹ́ èdè olóhùn, èyí ni a sì fi máa ń dá wọn mọ̀ yàtọ̀. - Babungo, Bantu, Benu- Congo ati Niger-Congo (i) ףּwá báy làa bàà He was very, very red (ii) ףּwá nyiףּ máa tátátә He ran quickly and Continuosly Gbólóhùn oní pọ́nónna (Simple Sentence) Àwọn wọ̀nyí: Subject (s) verb (v) obuject (o) ni a máa ń lò láti sàlàyé gbólóhùn Svo ni o gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Afroasiatic àti ní Niger-Congo yàtọ̀ sí Mande, Senufo àti Ijo, Ní ilè Khoisan – Khoe náà yàtọ̀ fún àpẹẹrẹ: Hausa, Chadic, Afroasiatic (i) S V O Obdun yaa ci na amaaa Swahili, Bantu, Benu – Congo, Niger-Congo (ii) S V O Halima a-na-pika ugali Halima is cooking porridge Nínú àwọn èdè wọ̀nyí: - Bari, Eastern Nilotic, Nilo – Saharan, S V O Adv ló gbajúmọ̀. (iii) S V O Adv teleme a kop kene ‘de’ de ‘The monkey Caught the branch quickly Ìkejì tí ó tùn gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Afirika ni SOV. A lè rí i ní Ethio-Semitic, Cushitic àti Omotic láàrin Afroasiatic ní senufo : Bí àpẹẹrẹ: (i) Silt’e, Ethio – Semitic, Afroasiatic S O V isaam ciitañe gilgil Ceeñeet (ii) Supyire, Senufo, Gur, Niger-Congo S O V Kile ù kùni pwọ ‘May God sweep the path. (iii) Aiki, Maban, Nilo-Saharan S O V gòףּ yàףּ sám tare ‘The farmer occupies a fiertile plot. Ìkẹta ni VSO, òhun kò gbajúmọ̀ ní ilè Afirika. A máa ń rí i ní Berber Chadic ni Afroasiatic, Nilotic Surmic ní ilẹ̀ Eastern Sudamic. Fún àpẹẹrẹ: (i) Maasai, Eastern Nilotic Eastern Sudamic, àti Nilo-Saharan. V S O édól oltúףּání eףּkolìí The person sees a gazelle. Nínú àwọn èdè tí ń lo V S O àbọ̀ kìíní àti ìkejì máa ń tẹ̀lé Is á wá fùn wa ní VSOO Turkana bí àpẹẹrẹ: V S O O à-in-a-kin-i ayòףּ ףּide akimui Nínú èdè SOV, adjuncts (afikun) maa ń síwájú Is, a wá fún wa ni SXOV tàbí SOXV bí ó se hàn ni – (1) Aiki, Maban, Nilo-Saharan. S O LOC V Kàikàì ti tiףּíףּ gá tàk gán tàndàrkÈ The child joined its mother at the pound “X” yìí dùró fún ìkan lára àwọn àfìkún. Àfikún (adujunct) ni Location post positional phrase “tak g∂n Àwọn èdè SOV lè lo SOVX fun afikun (adjuncts) bí a se ríi ní Menade, pẹ̀lú atọ́kún Instrumental prepositional a bó a ti o túmọ̀ sí with a knife. Mende, Western, Mande, Niger – Congo S O V INST è wúru tèe à bóa hé stick cut with knife He cut the stick with a knife. Gbólóhùn Àsẹ àti ìbèèrè (commands and questions) Ohun mẹ́ta ni a máa gbé yèwò. Èyí ibeere ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ (i) (Yes or no question) (2) Information word question (3) Indirect question. Nínú èdè Africa Yes/no question most commonly involve only a question marker or morpheme at the end or the beginning of the sentences. Nínú èdè Africa ìbéèrè oní bẹẹni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ máa ń ni àmì ìbéèrè ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ìparí Linda is typical of many Niger-Congo and other langs, that use a question marker at the edge of the sentence. Linden i Ogidi nínú àwọn Niger Congo ti o n lo ìbéèrè alámì ni opìn gbólóhùn. Linda, Banda, Adamawa –Ubangi, Niger-Congo (a) `ce gú he/she arrived she arrived (b) cè gú à he/she arrived Qm Did she arrive? Nínú èdè bíi silte wọ́n máa ń lo ohùn gbigbe sókè ní ìparí gbólóhùn, á lè lò ó gẹ́gẹ́ bíi yes/no question. Fun àpẹẹrẹ: Silt’e, Ethio – Semitic, Afroasiatic akkum tisiikbińaas way Qm ó máa ń wáyé nínú èdè Haúsá náà. Ohùn àwọn èdè wọ́nyí: Wande, Gur àti Kwa máa ń lọ sí ilẹ̀ ni. Nínú èdè àwọn konni, Gur ní ilè Ghana, vowel or nasal is lengthened and has a slow fall in pitch. Èyí túmọ̀ sí pé nínú èdè Konni fáwẹ̀lì tàbí aránmúpè wọn máa ń falẹ̀. Àpẹẹrẹ nì díè saabú-u Are you (pi) eating porridge? Yes/no question tún máa ń wáyé nípa lilo negation (Ayisodi) “Didn’t he go to Accra? Nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a bá dáhùn bẹ́ẹ̀ni, ohun tí à ń sọ ni pé ò lọ sí Accra. Ìdàkejì rẹ̀ ni ó tọ̀nà ní ilẹ̀ Africa. Ṣùgbọ́n ní ilẹ̀: Ejagbam, Ekoid Bant Benue – Congo àti Niger-Congo (a) Ó – kà – jí ògàm à (Didn’t you go to the Qm market) (b) nńǹ, (ń-kà-ji) Yes, (I didn’t go) ÌYÓSÓDÌ Twó different kinds of negation should be distinguishes. Túmọ̀ sí pé orísìí àyísódì méjì ni a máa gbé yèwò. Àkọ́kọ́, A lè yí gbogbo gbólóhùn sí òdì. Ìkejì, ó sì lè jẹ́ àpólà kan nínú gbólóhùn bí àpólà orukọ ni a máa yí sódì. VERBAL AFFIXES Ọ̀nà tí ó gbajúmọ̀ tí wọ́n fi máa ń yi gbólóhùn sódì ni síse àtúnrọ àwọn ọ̀rọ̀ ìse. A yi kúrò ni ipò ìṣe lọ sí ìse aláyìísódì. Gbogbo ilẹ Benue-Congo ni wọn tí máa ń lò ó. Fún àpẹẹrẹ. - Aghem, Grassfield, Banu, Benue-Congo, Niger-Congo ò bò fí – ghGm He has hit the mat. ò kà bó gbam-fò he has not hit the mat Compound and complex sentences (Gbólóhùn ọlọ́pọ̀ awẹ́) Compound sentewes-ni síse awẹ́ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pọ̀, ó máa ń jẹ́ odidi awẹ́ àti àfarahẹ. Emphasis or focus’Àfojúsùn, Àfojúsùn jẹ́ ohun pàtàkì tàbí information abẹ́nú nínú gbólóhùn. Ó jẹ́ ohun ti olùsọ gbà pé Oùgbọ́ kò gbọdọ̀ bá òun sọ. Èdè Africa máa ń lo ohùn nígbà mìíràn. Ṣùgbọ́n ohun ti wọ́n sabàá máa ń lò ni (i) yíyí padà kúrò ni ọ̀rọ̀ ìse tàbí kí wọ́n lo AUX àsèrànwọ́ ìṣe (2) use of special words (particles) (3) use of cleft-types constructions fún àpẹẹrẹ nínú èdè Ejaghan. (a) à – nam bì-yù buy yam “She bought yams” (b) à – nàm-é jén Focus what What did she buy (c) à – nam-é bì-yù She bought yams Èdè A ghem ni àfojúsùn tó le (complex focus) In some cases it uses a focus particle ñ (a) fù kí mò nyiףּ nõ á kí-bé The rat ran in the compound. (b) Fú kí mọ nyiףּ no á kí-bé The rat ran (did not walk) in the compound (c) Fù kí mọ nyiףּ á kí-bé no The rat ran inside the conpound (not inside the house) Àwọn èdè mìíràn lè lo àpepọ̀ verb changes and particles, gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú èdè Vute. (a) mvèìn yi Gwáb-na tí ףּgé cene The chief bought him a chicken (b) Mvèìn yi Gwab-na-á ףּgé cene já The Chief bought him a chicken.
Sínńtààsì Èdè Aafíríka
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3070
3070
Zosso ‘ZOSSO’ ‘Zosso’ jẹ Òrìṣà àdáyé bá, tó jẹ pé tí wọ́n bá tí bí ọmọ Àjara-Tọpá, ìyá ọmọ náà kò ní jẹ iyọ̀ títí oṣù afi yọ lókè. Tí oṣù yìí bá ti yọ, wọn á gbé ọmọ náa bọ́ sí ìta láti fi osù han ọmọ náà wí pé kí ọmọ náà wo oṣù tí ó wá sáyé. Ní ọjọ́ náà ìyá ọmọ náà yòó gbé ọmọ náà bó sí ìta láìwọ aṣo àti ọmọ náà pàápàá tí òun àti ọmọ rẹ̀ yóò sì jẹ iyọ̀ pèlú ẹja, wọn yóò sì tún fọ́ èkùrọ́ sórí ẹ̀wà láti fún ìyá ọmọ náà jẹ nígbà méje tó bájẹ́ obìnrin, ẹ̀mẹ́sàn-án to ba jẹ ọkùnrin. Léyìn tí wón bá ti se èyí tán, ìyá ọmọ yóò gbé ọmọ rẹ̀ lọ sí ìdí Òrìsà ‘Zosso’ láìwọ asọ ní ọjọ́ kejì, tí yóò sì ra otí dání láti sure fún ọmọ náà gẹ́gẹ́ bí àṣà. Wọn á sì padà sílé. Nígbà tí ìyá ọmọ náà bá dé ilé yoò fá irun orí ọmọ rè, yóò sì lọ ra igbá àti ìkòkò tuntun. Igbá yìí ni yóò fi bo ìkòkò náà lọ sí odò ‘Zosso’. Omi odò yìí ni ìyá àti ọmọ yóò fi wẹ̀ títí omi yóò fi tàn. Òrìsà yìí máà n dáàbò bo àwọn ọmọde lọ́wọ́ aburú.
Zosso
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3085
3085
Zangbetọ Zangbeto jẹ́ Òrìṣà àwọn ẹ̀yà Ògù ní Àgbádárìgì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Badagry, tí wọ́n gbàgbọ́ pé ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṢẸ̀ wá láti orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin àti orílẹ̀-èdè Togo. Zángbétọ́ lè jade nígbà kúgbàà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ọdún Òrìsà tàbí aỵẹyẹ ìbílẹ̀. ‘Zangbetọ’ jẹ́ Òrìsà tó mò n pa idán ní ọjọ́ ayẹyẹ láti yẹ́ àwọn ènìyàn sì. ‘Zangbetọ’ sì tún jẹ ààbò fún ìlú kí àwọn ọlọ́sà máa ba wọ̀lú ní òru. Tí ọ̀rọ̀ kan bá sí se pàtàkì, ‘Zangbetọ’ kan náà ni wọn yóò ran láti lọ jẹ́ irú isẹ́ bẹ́è. Tí ẹnìkan bà sì sẹ̀ tàbí lódí sí ofin ìlú, àrokò ‘Zangbetọ’ ni wọn yóò fí síwájú ilé e rẹ̀. Ẹníkẹ́ni tí wọ́n bá sì fi irú àrokò yìí síwájú ilé rẹ̀ yóò ní láti dé aàfin Ọba kí ó sì san ohun kóhun tí wọn bá ni kò san ki ó to lè wo ilé rẹ̀. Àgbálo gbábọ̀ ọ̀rọ̀ nii ni pé àwọn ẹ̀sìn àtọ̀hunrìnwá wà ṣùgbọ́n ẹ̀sìn àbáláyé kò lè parun, nítorí pe, gbogbo àwọn Òrìsà wọ̀nyí ṣì wà síbẹ̀.
Zangbetọ
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3086
3086
Ìrìnàjò lọ sínú Òṣùpá ÌDÒWÚ OLUWASEUN ADẸ́SAYỌ̀ ÌRÌNÀJÒ LỌ SÍNÚ ÒṢÙPÁ Osupa Aye mẹ́jọ míràn bíi’rú ti wa lo n yi po káàkiri òòrùn. Àwa la ṣìkẹta táa jìnà sóòrùn, awọn méjì wà níwájú. Àwọn mẹ́fà wà lẹ́yìn wa. Mo ni òòrùn tí à ń wò lókè taa rò pé ó kéré mo ló tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ju gbogbo ilé ayé lọ báyé yìí ṣẹ́ ń yípo òòrùn, bẹ́ẹ̀ náà lòsùpá ń yípó ayé Mo tún sọ fún wa wípé jínjìn ilé ayé sí òṣùpá tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ọ̀rún mẹta, ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún kìlómítà 320, 000 kin. Bíi kéèyàn ó máa rin Èkó sí Ìbàdàn bíi ọ̀nà ẹgbẹ̀rún méjì bẹ́ẹ̀ náà lòṣùpá ṣe jìn sílé ayé tó téèyàn bá kúrò lórí ilẹ̀ ayé àlàfo tí ń bẹ láàrin Ilé-ayé àti òṣùpá, láàrin ilé ayé àti òòrùn láàrin ilé-ayé àti àwọn ayé mẹ́jọ tó kù lèèyàn ó kàn o, téèyàn bá ń fò lọ sókè sínú òfurufú àlàfo yìí làwọn olóyìnbó ń pè ní space ṣee mọ̀ pé bí ìgbà téèyàn bá to ǹkan ka lẹ̀ tálàfo wá wà níbẹ̀, bí Olódùmarè ṣe tàlàfo sáàrin ilé ayé àtàwọn ayé tókù, àtòòrìn àtòṣùpá rèé. Àlàfo tí à ń sọ yìí, bíi ojú sánmọ̀, ojú òfurufú ló ṣe rí ṣùgbọ́n ǹkan tí ó fi yàtọ̀ díẹ̀ ni pé kò sí atẹ́gùn nínú àlàfo yìí, kò sí kùrukùru òfuru jágédo lásán ni. Àjá ni wọ́n kọ́kọ́ rán sínú àlàfo tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí lọ́dún 1957 Làíkà lórúkọ tájá yìn ń jẹ́, nigba tájá yi padà tí ò kú ní wọ́n bá rán ẹnìkan ta n pe ni Yuri Gagarin lọ sínu àlàfo yìí, láti orílẹ̀èdè Russia láti mọ̀ bálàfo yì sẹ rí Yuri Gagarin lẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ fò kúrò lórí ilẹ̀-àyé pátápátá lọ sinu àlàfo ta n pe ni space to wà láàrin Ilé ayé àtòṣùpá. Lẹ́yìn èyí orílẹ̀ èdè America náà bẹ̀rẹ̀ sí ní rìnrìnàjò yii Ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín orílẹ̀èdè America lọ́ sínú òṣùpá lọ́dún 1969 Neil Armstrong ati Edwin Aldrin si lẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ wọnú ọ̀sùpá. Mo sọ fun wa wipe òǹfà kan nbẹ́ ninú ilé ayé tó má n fa gbobgo ǹkan tó bá ti wà lórí ilé-ayé tàbí súnmọ́ ilé ayé mọ́ra, Téèyàn á bá wá kúrò lórí ilẹ̀-ayé pátápátá èàyàn gbọdọ̀ jára rẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ òǹfà yìí, mọ́to téèyàn á bá lọ ó gbọ́dọ́ lágbára gidi kò sì tún lè sáré láti bori agbára ̣ òǹfà yìí, tóò ọkọ̀ tí wọ́n gbé lọ inú òṣùpá, Rọ́kẹ́ẹ̀tì ló ń jẹ́ o, Aeroplane, ò lè rin irú ìrìnàjò yí o, e wòó iṣẹ́ ọpọlọ ni wọ́n fi se rọ́rẹ́ẹ̀tì yìí, Ìpéle mẹ́ta ni wọ́n ṣe éńjínnì mọ́to yí o, Ìpéle kínní, ìpéle kejì, ìpóle kẹta lọ sókè ibi tí àwọn èèyàn dúró sí núnú rẹ̀, ó wà lórí ìpéle kẹta lókè téńté bí wọ́n ṣe to àwọn éńjìnnì yìí bíi àgbá rìbìtì léra wọn rèé tó dúró lóòró tó wá kọjú da sánmọ̀ wọ́n tún wá jẹ́ ki ọkọ yìí ṣẹnu ṣómu ṣómú ko le máa wọnú atẹ́gùn lọ sọ̀ọ̀, Orúkọ tí wọ́n fún rọ́kẹ́ẹ̀tì yìí ni wọn n pè ni Apollo 11, Apollo 11 yìí ga lọ sókè ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà ọgọ́run mẹ́ta Ààbọ̀ ó lé díẹ̀, bíi ká sọ pé ilé alája ogóji epo tí ọkọ yìí ń jẹ kèrémí kọ́ o. Kò ṣéé fẹnu sọ. Bíi ìgbà tèèyàn bá yin ọta ìbọn, bi wọ́ń ṣé, má n yìn-ín nuu torí ó gbọdọ̀ le sáré dáadáa kío le jára rẹ̀ gbà kúro lọ́wọ́ ̣ òǹfà tí ń bẹ lórí ilẹ̀ aye, tí wọn á bá si yin mọ́to yìí kìí séèyàn kankan ní sàkání ibẹ̀, torí ooru, èéfín àti iná nló má ń jáde ní ìdí Rọ́kẹ̀ẹ̀tì yìí. Àwọn tó lọ inú òṣùpá, ti wọ́n wà nínú mọ́to yìí. wọ́n dera wọn mọ́ àgá ni Àwọn tó yin rọ́kéẹ̀tí yìí sókè, wọ́n jìnnà pátápátá sí ibi tí Rọ́kẹ̀tì yìí wà, ẹ̀rọ̀ kọ̀mpútà ni wọ́n fí yìn ín bi wọ́n sẹ gbéná lé Rókẹ́ẹ̀tí yìí tí à ń pè ní Apollo 11 ni 1969 dó bá dún gbòà? lọkọ̀ bá ṣí, Ó dòkè lójú sán mọ̀ Eré burúkú kí ọkọ̀ máa sáré ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá kìlómítà láàrín wákàtí kan. 10,000km/hr irú eré tí àwọn móto má ń sá lọ́nà ẹ́spùrẹ̀sì irú eré yìí lọ́nà ẹgbẹ̀rún kan leré tí rọ́kẹ́ẹ̀tì yìí bá lọ sínú òfurufú lọhun. Láàrin ìṣẹ́jú méjì ààbọ, éńjìnnì tìpéle àkọ́kọ́ ti gbé ọkọ̀ yìí rin kìlómità ọgọrun mẹ́fà 600km. lọ sínú òfunrufú. Lẹ́yìn iṣẹ́jú méjì ààbọ̀ éńjìnnì tó wà ní ìpéle àkọ́kọ́ ti jó tán ó jábọ́ kúrò lára ọkọ̀ yìí, éńjìnnì tì péle kejì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ó sì gbé wọn rin ẹgbẹ̀rún méji, ó lé ni ọgọrun mẹta kìlómítà 2,300 kilometres láàrin ìṣẹ́jú mẹ́fà lọ́ sí nú òfururú lọ́ùnlọ́ùn, ẹńjìnnì ìpéle kejì jó tán òhun náà jábọ́, tipéle kẹta bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ẹ́njìnnì tìpéle kẹta ló wá jáwọn gbà kúrò lọ́wọ́ òǹfà tí ń bẹ nínú ayé pátápátá, wọ́n sì bọ́ sínú àlàfo tí ń bẹ láàrin ilé-ayé àtoṣùpá. Nínú àlàfo yìí, ̣ òǹfà ayé ò ní pa púpọ̀ mọ́ lórí wọn Wọ́n wá sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ni rìnrìnàjò wọn lọ́ sínú òṣùpá ní ìrowọ́ ìrọsẹ̀. Nínú àlàfo tí a ńpè ní space yìí, béèyàn bá ju ̣ ǹkan ókè kìí padà wá lẹ̀ yíó dúró pa sókè ni, kó dà gan béèyàn gan fò sókè èèyàn ò ní tètè padà wálẹ̀ tórí kò sí ̣ òǹfà kan tí ó fààyàn padà nínú àlàfo yìí ṣùgbọ́n béèyàn bá dẹ́nú òṣùpá, ̣ òǹfà ń bẹ nínú òṣúpá ṣùgbọ́n àmẹ́ kò tó tayé béèyàn bá ju ǹkan sókè nínú òṣùpá naa kìí tètè padà walẹ, ẹ má gbàgbé àti nínú àfìfo tí ń bẹ láàrin ilé-ayé àtọ̀ṣùpá àti nínú òṣùpa gan-an kò sí atẹ́gùn níbẹ̀ o báwo wá làwọn tí wọ́n ń lọ inú òṣùpá ṣé má ń mí, wọ́n má ń gbé atẹ́gùn pamọ́ sínú àpò kan ni, kí wọn o le rátẹ́gùn fi mí. Tòò wọ́n dénú òṣùpá lógúnjọ́ oṣù kẹfà lọ́dún 1969 lọ́jọ̀ Sunday ọjọ ìsinmi ló bọ́ sí ẹ̀yin tẹ́ẹbá ní kàlẹ́ńdà 1969 lọ́wọ́ ẹ wòó ọjọ́ márùn-ún ni wọ́n fi rin ìrìn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun mẹ́ta , ó lé ní ọgọrun lọ́nà ogún kìlómítà 320,000km lọ sí nú òṣùpá, Neil Armstrong lórukọ fẹẹ̀ ẹní tó kọkọ fi ẹsẹ tẹnú òṣùpá bó sẹ́ ń sòkalẹ̀ láti inú ọkọ̀ tí wọ́n gbé lọ óní bí ó ti lẹ̀ jẹ́pé ìgbéṣẹ̀ ti òhun gbé wọnú òṣùpá ó kéré óní ìgbésẹ̀ ńlá ni fún ìran ọmọ ènìyàn. Edwin Aldrin tí wọ́n dìjọ lọ náà sọ̀kalẹ̀ sínú òṣùpá wọ́n bá ààrẹ oríléèdè Amerika Nígbànáà ààrẹ Richard Nixon sọ̀rọ̀ pé tò àwọn tí dé nú òṣùpá o. Àwọn méjéèjì bẹ̀rẹ̀ ìwádí ti wọ́n bá lọ sínú òṣùpá wọ́n fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé erùpè, òkúta àtàwọn òkè ń bẹ nínú òṣùpá ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀dá alàyè tàbí ohun abẹ̀mí kan níbẹ̀. Inu òṣùpa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ọjọ́ méjì ti è oṣù kan ti wa ni ọ̀ sẹ̀ méjì gbáko lòòrùn á fi ràn. Tí gbogbo ǹkan á sì gbóná lọ́nà méjì ju omi tó ń hó lọ, ọ̀sẹ̀ méjì ni lẹ̀ tún fí má ń ṣú, gbogbo ǹkan á tún tutu lọ́nà méjì ju ice block yìnyín lọ. Àsìkò ìgbà tóòrùn ń ràn ni wọ́n dé bẹ̀ àmọ́ aṣọ tiwọ́n wọ̀ dábòbò wọn tóoru ò fi mú wọn pa torí wọ́n dọ́gbọ́n éńjìnnì amára tutu sínú aṣọ yìí, àwọn méjéèjì lo wákàtí méjì àtìṣẹ́jú mẹ́ta dínláàádọ́ta nínú òṣùpá wọ́n ṣàwọn ìwáàdí kéèkèè ké wọ́n ri àsìá orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà síbẹ̀, wọ́n bu yèèpè inú òṣùpá àtòkúta díẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì padà, tòò àti lọ sínú òṣùpá ló le àti kúrò níbẹ̀ ò le, wọn yin ra wọn kúrò níbẹ̀ ni bi wọ́n ṣe yin ra wọn kúrò lórí ìlẹ̀ aye. Ọjọ́ méjì ààbò ni wọ́n fi rìn padà sórílẹ̀ ayé bi wọ́n tún ṣe súnmọ́ ilé-ayẹ́ lòǹfà inú ayé bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ní fàwọ́n, eré ni awọ́n si n bá bo láti inú òṣùpá tẹ́lè leré yìí bá tún pọ̀ si, báwo lọkọ̀ se fẹ́ bà sórí ilẹ̀ pẹ̀lú eré burúkú yìí íápọọ̀tì òtì wo ló fẹ́ bà sí wọ́n sá ṣètò kí mọ́tò yí balẹ̀ sínú òkun alagbalúgbú omi ṣẹẹ mọ̀ pé okún jìn lọ ìsàlẹ̀, omi inú òkun tún dá mọ́tò yìí dúró bíi búrèkì, tòò bi wọ́n se lọ sínú òṣùpá rèé o. Lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 1969 16-7-1969 tí wọ́n sì padà sórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kẹrìnlélógún, oṣù keje kannáà lọ́dún 1969, 24-7-1969.
Ìrìnàjò lọ sínú Òṣùpá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3096
3096
Andora
Andora
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3102
3102
Ijo Jesu l’otito
Ijo Jesu l’otito
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3150
3150
Baṣọ̀run Gáà Baṣọ̀run Gáà jẹ́ ìwé ìtàn eré-oníṣe tí gbajúmọ̀ oǹkọ̀wé nì, Adébáyọ̀ Fàlétí kọ. Ó dá lórí ìtàn olóyè Baṣọ̀run tí ìlú Ọ̀yọ́ tí wọ́n ń pè ní Baṣọ̀run Gáà. Ó jẹ́ afọbajẹ ní ìlú Ọ̀yọ́ láyé àtijó. Kókó inú ìwé ìtàn eré oníṣe yìí ni wípé kí a má ṣe ìkà. Ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ni ònkọ̀wé náà fi kọ ìwé náà, tí ó sì gbé ìtàn rẹ̀ lé orí ìtàn gidi tí ó sì jẹ́ ojúlówó ìtàn ilé Yorùbá. ìtàn Igbesiaye Baṣọ̀run Gáà. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan ni BBC, ìtàn fi ye wa pe, Basọrun Gaa ni olori igbimọ Ọyọmesi, eyi to dabi Olootu ijọba laye ode oni, lẹyin Alaafin, tii se oriade ilu Ọyọ́, Basọrun Gaa lo tun ku. Ko si sẹni to le e sọ pe ti Basọrun Gaa ko jẹ eeyan gidi, wọn yoo fi jẹ oye Basọrun, to jẹ olori igbimọ lọbalọba fun Alaafin, tii se Ọyọmesi. Ni bayii, o wa yẹ ka mọ itan igbe aye akọni yii ati ipa to ko ni ilu rẹ, boya rere ni abi buburu. Basọrun Gaa ni olori ogun Ọyọ ile ati gbajumọ ilu ni saa onka ẹgbẹrun ọdun kẹtadinlogun si ikejidnlogun, 17th/18th century Basọrun Gaa se gudugudu meje ati ya a ya mẹfa lati rii daju pe Ọyọ ile akọkọ di ilu nla, o lagbara, to si fẹ de ọpọ ilu ati orilẹ-ede lode oni Lọdun 1750 ni Alaafin Labisi yan Gaa gẹgẹ bii Basọrun, olootu ijọba ati olori igbimọ lọbalọba ẹlẹni meje fun Alaafin nilu Ọyọ ile, ti agbara si n pa Gaa bi ọti Ilu Ọyọ ile roju, o tuba, o tusẹ lasiko ti Basọrun Gaa joye, ti Ọyọ si maa n gba isakọlẹ lati ọpọ ilu àmọ́nà to wa labẹ rẹ Tọmọde-tagba nilu Ọyọ lo n bẹru, ti wọn si n bọwọ fun Basọrun Gaa, tori pe o ni oogun abẹnu gọngọ, ti asẹ rẹ si mulẹ ni aarin ilu ju Alaafin Labisi to yan an sipo lọ Itan sọ pe Basọrun Gaa ni oogun pupọ, to si maa n parada di ẹranko to ba wu u, to fi mọ Ẹkun, Kiniun, Igala, Ọya ati bẹẹ bẹẹ lọ Ni kete ti Gaa di Basọrun ni Ọyọ ile lo pa meji ninu awọn ọrẹ imulẹ Alaafin Labisi, eyi to dun ọba naa de egungun, to si gba ẹmi ara rẹ lọdun 1750 naa Alaafin Awọnbioju lo jẹ Alaafin lẹyin Labisi, sugbọn niwọn igba toun naa kọ lati gba itọni lọdọ Basọrun Gaa, aadoje ọjọ pere lo lo lori itẹ ti Gaa fi ni ki wọn yẹju rẹ Alaafin Agboluaje to jẹ lẹyin Awọnbioju tiẹ ri ijọba se n tiẹ, tori o n gbọrọ si Basọrun Gaa lẹnu, sugbọn ọwọ Basọrun Gaa naa ni ẹmi rẹ papa bọ si Alaafin Majẹogbe tiẹ lo dun kan soso pere lori itẹ, ki Basọrun Gaa to ran sọrun ọsan gangan Lọdun 1774 ni Alaafin Abiọdun gori itẹ, to si n wọna bi yoo se rẹyin Basọrun Gaa, ko lee roju se aye, sugbọn Gaa pa ọmọbinrin Alaafin Abiọdun, Agbọrin, nigba to nilo ẹranko Agbọnrin, to si ni orukọ wọn jọra Ọrọ naa dun Abiọdun to bẹẹ, to si beere fun atilẹyin Onikoyi, ati aarẹ Ọna Kakanfo to jẹ nigba naa, Ọyalabi lati ilu Ajasẹ ipo, ki wọn lee tete rẹyin Basọrun Gaa Alaafin Abọdun kọkọ yọ ibẹru Gaa kuro lọkan awọn araalu, to si jẹ ki ibinu rẹ maa ru jade ni inu wọn, titi ti Basọrun Gaa fi rọ lapa, rọ lẹsẹ Lọdun 1774, ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan Ọyọ ile ya bo agboole Basọrun Gaa, ti wọn si wọ ọ lọ si ọja Akẹsan, ki wọn to sun un nina gburugburu, bẹẹ ni wọn pa a tọmọtọmọ, wọn jẹ ile Gaa run patapata Sugbọn ori ko akọbi rẹ, Ojo Aburumaku yọ ninu wahala yii, to si sa lọ si ilẹ Ibariba, eyi to fopin si aye fami lete ki n tutọ ti Basọrun Gaa ati idile rẹ n jẹ Idi ree ti awọn eeyan se maa n pa asamọ pe ‘Bo laya ko sika, to ba ri iku Gaa, ko sootọ’ Sugbọn iku Basọrun Gaa se akoba nla fun ijọba Ọyọ akọkọ, tori lẹyin iku Gaa ni ẹdinku ba bi awọn ọmọ ogun rẹ ti dangajia si ati agbara ilu naa, tawọn ilu kan si n sa kuro labẹ rẹ, titi ti Ọyọ ile akọkọ fi tu lọdun 1836.
Baṣọ̀run Gáà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3157
3157
Nàìjíríà Nàìjíríà ( <ns>10</ns> <id>16731</id> <redirect title="Àdàkọ:Pron-en" /> <revision> <id>68360</id> <timestamp>2009-12-25T19:26:44Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <comment>Redirected page to </comment> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìtàn fífẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀rí ìmọ̀-aíyejọ́un fihàn pé àwọn ìgbé ènìyàn ní agbègbè ibẹ̀ lọ sẹ́yìn dé kéré pátápátá ọdún 9000 kJ. Agbegbe Benue-Cross River jẹ́ rírò gẹ́gẹ́ bí ile àkókó àwọn Bantu arókèrè ti wón fán káàkiri òpó ààrin àti apágúúsù Áfríkà bí irú omi ní ààrin ẹgbẹ̀rúndún akoko àti ẹgbẹ̀rúndún kejì. Orúkọ Nàìjíríà wá láti Odò Ọya, tí a tún mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi "Odò Náíjà", èyí tó sàn gba Nàìjíríà kọjá. Flora Shaw, tí yíò jẹ́ ìyàwó lọ́jọ́ wájú fún Baron Lugard ará Britan tó jẹ́ alámójútó àmúsìn, ló sẹ̀dá orúkọ yìí ní òpin ọdún 1897. Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè tó ní èèyàn púpò jùlọ ní Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú, ikejo ni agbaye, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ní àwọn eniyan alawodudu jùlọ láyé. Ó wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí a ń pè ní "Next Eleven" nítorí okòwò wọn, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú Ajoni àwọn Ibinibi. Okòwò ilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èyí tó ń dàgbà kíákíá jùlọ lágbàáyé pẹ̀lú IMF tó ń gbèrò ìdàgbàsókè 9% fún 2008 àti 8.3% fún 2009. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 2000 sókè, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà gbé pẹ̀lú iye tó dín ní US$ 1.25 (PPP) lójúmọ́. Nàìjíríà ní okòwò rẹ̀ tóbi jùlọ ní Áfíríkà, ati alágbára ní agbègbè Iwoorun Afirika. Ìtàn. <ns>10</ns> <id>16733</id> <revision> <id>534273</id> <parentid>122075</parentid> <timestamp>2020-05-17T15:21:13Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Ìtàn Ìṣẹ̀ǹbáyé. Àwọn ará Nok ní ààrin Nàìjíríà se ẹ̀re gbígbẹ alámọ̀ tí àwọn onímọ̀ ayéejọ́un tí wárí. Ère Nok tó wà ní Minneapolis Institute of Arts, júwè é ẹni pàtàkì kan mú "Ọ̀pá idaran" dání ní owó ọ̀tún àti igi ní owó òsì. Ìwònyì ní àmì-ìdámọ̀ aláse tó jẹ́ bíbásepọ̀ mò àwọn fáráò ilè Egypti ayéejọ́un àti òrìṣà, Oṣíriṣ, èyí lo n so pé irú àwùjọ, idimule, bóyá àti ẹ̀sìn ilè Egypti ayeijoun wà ní agbẹ̀gbẹ̀ ibi tí Nàìjíríà wà lónìí ní ìgbà àwọn Fáráò.         Ní apá àríwá, Kano àti Katsina ní ìtàn Àkọsílè tí ọjọ́ wón dẹ́yìn tó bí ọdún 999 kJ. Àwọn ìlú-ọba Haúsá àti Ilé-ọba Kanem-Bornu gbòòrò gẹ́gẹ́ bí ibùdó ajẹ́ láàrin Àríwá àti Ìwọ̀ọòrùn Áfríkà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún 19sa lábé Usman dan Fodio àwọn ará Fúlàní di àwọn olórí Ilé-ọba Fúlàní lójúkan èyí tó dúró bayi títí di 1903 nígbàtí wọn jẹ́ pínpín láàrin àwọn àlámùúsìn ará Europe. Láàrin 1750 àti 1900, ìdá kan sí ìdá méjì nínú meta àwọn oníbùgbẹ́ àwọn ìlù Fúlàní jẹ́ eru nítorí ogun. Àwọn Yorùbá ka ọjọ́ tí wọ́n ti wà ní agbègbè Nàìjíríà, Benin àti Togo ayéòdeòní sẹ́yìn dé bí ọdún 8500 kJ. Àwọn Ìlú-ọba Ifẹ̀ àti Ọ̀yọ́ ní apá Ìwòòrùn Nàìjíríà gbalẹ̀ ní 700-900 àti 1400 ní sísẹntẹ̀lé. Síbẹ̀síbẹ̀, ìtàn àríso Yorùbá gbàgbọ́ pé Ilé-Ifẹ̀ ni orísun ẹ̀dá ènìyàn pe bẹ́ẹ̀ sì ni ó síwájú àsà-ọ̀làjú míìràn. Ifẹ̀ sẹ̀sọ́ ère alámọ̀ àti onítánganran, Ìlú-ọba Ọ̀yọ́ si fẹ̀ de ibi tí Togo wà loni. Ìlú-ọba míìràn tó tún gbalẹ̀ ní gúúsù apáìwòọ̀rùn Nàìjíríà ní Ìlú-ọba Benin láti ọ̀rúndún 15ru 19sa. Ìjọba wọn dé Ìlú Èkó kí àwọn ara Portugal ó tó wá sọ ibẹ̀ di "Lagos." Ní apá gúúsù ìlà-oòrùn Nàìjíríà, Ìlú-ọba Nri tí àwọn Igbo gbòòrò láàrin ọ̀rúndún 10wa títí de 1911. Eze Nri ni ó jọba Ìlú-ọba Nri. Ilu Nri jẹ́ gbígbà gẹ́gẹ́ bí ìpilèsè àsà ígbò. Nri àti Aguleri, níbi ti ìtàn àrísọ ìdá Igbo ti bẹ̀rẹ̀, wà ní agbẹ̀gbẹ̀ ìran Umueri, àwọn tí wọ́n sọ pé ìran àwọn dé ilẹ̀–ọba Eri fúnra rẹ̀. Ìgbà Àmúsìn. <ns>10</ns> <id>16733</id> <revision> <id>534273</id> <parentid>122075</parentid> <timestamp>2020-05-17T15:21:13Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Àwọn Portuguese Empire ni wọ́n jẹ́ ará Europe àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ ìsòwò ní Nàìjíríà tí wọ́n sì sọ èbúté Eko di Lagos tí wọ́n mú látara orúkọ ìlú Lagos ní Algarve. Orúkọ yìí lẹ̀ mọ́bẹ̀ bí àwọn ará Europe míìràn náà ṣe bẹ̀rẹ̀ síní sòwò níbẹ̀. Àwọn ará Europe ṣòwò pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà abínibí ní ẹ̀bá–odò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ owo eru níbẹ̀, èyí tó pa ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀yà abínibí Nàìjíríà lára. Lẹ́yìn tí ogun Napoleon bẹ̀rẹ̀, àwọn ará Britani fẹ ìsòwò dé àárín Nàìjíríà. Ni 1885, ìgbẹ́sẹ̀lé Ìwọ̀oòrùn Áfríkà látọ́wọ́ àwọn ará Britain gba ìdámọ̀ káríayé. Nígbà tó sì di ọdún tó tẹ̀lé e, ilé-iṣẹ́ Royal Niger Company jẹ́ híháyà lábẹ́ Sir George Taubman Goldie. Ní 1900, àwọn ilẹ̀ tí ilé-iṣẹ́ yìí ní di ti ìjọba Britain. Ni January 1901, Nàìjíríà di sísọ–di–ọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi ìlànà àláàbò. Nàìjíríà sì di ara Ilẹ̀–ọbalúayé Britain tó wà lára alágbára nígbà náà. Ní 1914, àgbègbè náà di sísọ-di-ọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi Ìmúsìn àti Aláàbò ilẹ̀ Nàìjíríà ("Colony and Protectorate of Nigeria"). Fún àmójútó, Nàìjíríà di pínpín sí ìgbèríko apá-àríwá, apá-gúúsù àti Ìmúsìn Èkó. Okòwò ayé òde òní tẹ̀̀ síwájú ní wàrànsesà ní gúúsù ju ní àríwá lọ, ipa èyí hàn nínú ayé olóṣèlú Nàìjíríà òde òní. Ní ọdún 1936 ni òwò ẹrú ṣẹ̀ṣẹ̀ di fífòfin lù. Lẹ́yìn Ogun Agbaye Eleekeji gẹ́gẹ́ bíi èsì fún ìdàgbà isonibinibi Nàìjíríà àti bíbéèrè fún òmìnira, àwọn ìlànà–ìbágbépọ̀ tó rọ́pò ara wọn tí wọ́n jẹ́ sísọdòfin látowọ́ Ìjọba Britain mú Nàìjíríà súnmọ́ Ijoba-ara-ẹni tó dúró lórí aṣojú àti àpapọ̀. Nígbà tó fi di àárín ọ̀rúndún 20ji, ìjàgbara fún òmìnira jà káàkiri Áfríkà. Lẹ́yìn Òmìnira. Ní ọjọ́ kìíní, oṣù Ọ̀wàrà, ọdún un 1960, Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ orílè-èdè Sisodokan Ilu-oba. Ilẹ̀ Olómìnira tuntun yìí mú kí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ orílè-èdè kí ẹ̀yà tiwọn ó jẹ́ èyí tó lágbára jù lọ. Ìsèjọba àwa-ara-wa Nàìjíríà tuntun jẹ́ àjọ̀sepọ̀ àwọn ẹgbẹ́. Nigerian People's Congress ni ẹgbẹ́ tí àwọn ará Àríwá tí wọ́n tún jẹ́ Mùsùlùmí ń darí.smi ti Ahmadu àello ati Abubakar Tafawa Bewa to di Alakosoàkọ́kọ́ ẹ́yì òmìnira. Àti ẹgbẹ́ èyítiAlákòóso Àgbà ti awon tíỌmọ Ígbòwọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Kìrìstẹ́nì ń jẹ́ ìdarí National Council of Nigeria and the Cameroons , NíNC) ti Nnamdi Aie, to di Gomina-bínibíaàkọ́kọ́ ní ko ni 1960,órí olí i.òNi átakòlataẹgbẹ́iìlọsíwájúsiwaju Action Groupwà,Ati àwọn Yorùbá ti Obafemi Awṣe woórí olori. Ìpinnu ọdún 1961 fún Apáagúúsù Kameroon láti darapọ̀ mọ́ orílè-èdè Kameroon nígbàtí Apáàríwá Kameroon dúró sí Nàìjíríà fa àìdọ́gba nítorí pé apá àríwá wá tóbi ju Apáagúúsù lọ gidigidi. Nàìjíríà pínyà lọ́dọ̀ Britani pátápátá ní 1963 nípa sísọ ara rẹ̀ di ilẹ̀ Apapo Olominira, pẹ̀lú Azikiwe gẹ́gẹ́ bi Aare àkọ́kọ́. Rògbòdìyàn ṣẹlẹ̀ ní Agbegbe Apaiwoorun lẹ́yìn ìbò 1965 nígbà tí i Nigerian National Democratic Party gba ìjọba ibẹ̀ lọ́wọ́ ọ AG. Ìjọba Ológun Àkọ́kọ́. Àìdọ́gba yìí àti ìbàjẹ́ ètò ìdìbòyàn tí olóṣèlú fà ní 1966 dé àwọn ìfipágbajọba ológun léraléra. Àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ní Oṣù Ṣẹrẹ ti àwọn ọ̀dọ́ olóṣèlú alápáòsì lábẹ́ ẹ Major Emmanuel Ifeajuna àti Chukwuma Kaduna Nzeogwu. Ó kù díẹ̀ kó yọrí sí rere - àwọn olùfipágbàjọba pa Alákòóso Àgbà, Sir Abubakar Tafawa Balewa, Asolórí Agbègbè Apáàríwá Nàìjíríà, Sir Ahmadu Bello, ati Asolórí Agbègbè Apáìwọ̀oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, Sir Ladoke Akintola. Bó tilẹ̀ jẹ́ báyìí, síbẹ̀síbẹ̀, àwọn olùfipágbàjọba náà kò le bẹ̀rẹ̀ síní ṣe ìjọba nítorí ìṣòro bí wọn yíó ti ṣé, nítorí èyí Nwafor Orizu, adelédè Ààrẹ jẹ́ mímú dandan láti gbé ìjọba fún Ile-ise Ologun Adigun Naijiria lábẹ́ ẹ Apàṣẹ Ọ̀gágun JTY Aguyi-Ironsi. Ìjọba àti Ìṣèlú. boilerplate seealso">Ẹ tún wo: Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà Òfin. Irúfẹ́ òfin mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà ní Nàìjíríà. Nàìjíríà ní ẹ̀ka ìdájọ́ ọ ti Ilé-Ẹjọ́ Gíga jùlo ilẹ̀ Nàìjíríà, ó jẹ́ èyí tó lágbára jù lọ. Ìbásepọ̀ Òkèrè. Ní kété tí ó gba òmìnira ní 1960, Nàìjíríà sọ Ìsọ̀kan Áfríkà di ààrin-gbùngbùn òfin òkèèrè rẹ̀, Ó sì kópa ńlá nínú u ìgbógun ti ìjọba Ìyàsọ́tọ̀-Ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa. Ìyapa kan kúrò ni ìbáṣepọ̀ pẹ́kípẹ́kí tí Nàìjíríà bá Israel ṣe yípo gbogbo 1960s. Israel sonígbọ̀wọ́ àti àmójútó fún kíkọ́ àwọn ilé asòfin Nàìjíríà. Òfin Òkèère Nàìjíríà rí ìdánwò ní 1970s lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè náà jáde kúrò nínú Ogun Abẹ́lé nísọ̀kan. Ó dúró ti àwọn akitiyan tó lòdì sí ìjọba àwọn òyìnbó péréte ní ẹkùn Gúúsù Áfríkà. Nàìjíríà dúró ti ẹgbẹ́ ẹ African National Congress pẹ̀lú u bó ṣe pọkàn pọ̀ nínú ìpinnu rẹ̀ nípa ìjọba South Africa àti àwọn ipa ológun wọn ní Gúúsù Áfríkà. Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀dádáálẹ̀ ẹgbẹ́ ẹ Organisation for African Unity (tó di African Union) Ó sì ti ní ipa tó kàmọ̀nmọ̀ ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà àti ní Áfríkà lápapọ̀. Nàìjíríà ṣe akitiyan ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà, ó sì tún ṣe aṣáájú fún Economic Community of West African States (ECOWAS) àti ECOMOG (pàápàá nígbà ogun abẹ́lé ní Liberia àti Sierra Leone) – tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ ọrọ̀-ajé àti ti ológun ní sísẹntẹ̀lé. Pẹ̀lú ìdúró tó so mọ́ Áfríkà yí, Nàìjíríà rán àwọn ikọ̀ lọ sí Congo ní ìtẹ̀lé àṣẹ Àjọ àwọn Orílẹ̀-èdè kété lẹ́yìn òmìnira (ó sì ti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ láti ìgbà náà). Nàìjíríà tún ṣe ìtìlẹyìn fún orísìírísìí ẹgbẹ́ ẹ Áfríkà àti àwọn ìdìde fún ìjọba tiwa-n-tiwa ní àwọn 1970s, tó fi mọ́ kíkó ìtìlẹyìn jọ fún MPLA ní Angola àti SWAPO ní Namibia, àti ṣíṣe ìtìlẹyìn fún àtakò sí àwọn ìjọba eléèyan pérété ti àwọn Potogí ní Mozambique àti Rhodesia. Nàìjíríà sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Non-Aligned Movement. Ní ìparí oṣù Belu ní 2006, Nàìjíríà ṣe àkójọ ìpàdé e Áfríkà àti Gúúsù Amẹ́ríkà ní Abuja láti fi gbé nǹkan tí àwọn olùkópa kan pè ní ìbáṣepọ̀ "Gúúsù–Gúúsù" lórísirísìí ọ̀nà lárugẹ. Nàìjíríà tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ilé-Ẹjọ́ Ìwàọ̀daràn Káríayé àti Àjọni àwọn Orílẹ̀-èdè . Wọ́n yọọ́ kúrò nínú u tàsọgbẹ̀yìn fún ìgbà díẹ̀ ní 1995 nígbà ìṣèjọba Abacha. Nàìjíríà ti jẹ́ olùkópa takuntakun nínú ọjà epo àgbáyé láti 1970s,ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹ OPEC, èyí tó darapọ̀ mọ́ ní 1971. Ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òǹtà epo gbòógì jẹyọ nínú àwọn ìbáṣepọ̀ mímì pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó ti dàgbà sókè, pàápàá Amẹ́ríkà, àti pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣì ń dàgbà sókè. Láti 2000, ìsòwò láàrin Ṣáínà-Nàìjíríà ti ga sókè sí i. Ìpọ̀síi nínú u òwò ti lé ní mílíọ̀nù 10,384 dọ́là láàrin orílẹ̀-èdè méjèèjì láàrin 2000 sí 2016. Àmọ́, òwò láàrin Sáínà àti Nàìjíríà ti di ọ̀rọ̀ òṣèlú ńlá fún Nàìjíríà. Èyí jẹyọ nínú u pé ìtàjáde àwọn Sáínà jẹ́ ọgọ́rin nínú u ọgọ́rùn-ún gbogbo òwò. Èyí mú àìdọ́gba wá, pẹ̀lú u bí Nàìjíríà ṣe ń kó ọjà ìlọ́po mẹ́wàá wọlé ju ti Sáínà lọ. Bẹ́ẹ̀, ọrọ̀-ajé Nàìjíríà ti ń farati àwọn ìkówọlé ọjà olówó-pọ́ọ́kú láti fi gbéra, èyí sì mú ìdínkù wá nínú u Ìsòwò Nàìjíríà lábẹ́ irú ètò bẹ́ẹ̀. Ní ìtẹ̀síwájú pẹ̀lú u òfin òkèèrè tó so mọ́ Áfríkà, Nàìjíríà mú àbá wá fún níná owó kan náà ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà tí á máa jẹ́ "Eco" lábẹ́ ẹ èrò pé náírà ló máa wò ó dàgbà ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Ọ̀pẹ, 2019; Ààrẹ Alassane Ouattara ti Ivory Coast pẹ̀lú u Emmanuel Macron àti púpọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè UEMOA, kéde pé àwọn kàn máa yí orúkọ CFA franc padà ní kàkà kí àwọn rọ́pò rẹ̀ bí wọ́n ṣe rò tẹ́lẹ̀. Ní 2020, wọ́n ti gbé ètò owó o "Eco" náà tì di 2025. Iṣẹ́ Ológun. boilerplate seealso">Ẹ tún wo: Ile-ise Ologun ile Naijiria Ojúṣe àwọn ológun Olómìnira Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà ni láti dáàbò bo ilẹ̀ Nàìjíríà, gbígbésókè ìjẹlógún àbò Nàìjíríà àti ìtìlẹyìn ìtiraka ìgbèrò àlàáfíà àgàgà ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà. Iṣẹ́ ológun Nàìjíríà ní Ilé-Isẹ́ Ológun Akogun,Ilé-Isẹ́ Ológun Ojú Omi, àti Ilé-Isẹ́ Ológun Ojú Afẹ́fẹ́. Lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà,Ilé-Isẹ́ Ológun Nàìjíríà ti kópa nínú Ìgbèrò Àlàáfíà ní Áfríkà. Ilé-Isẹ́ Ológun Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí i ìkan nínú ECOMOG ti kópa gẹ́gẹ́ bí i olùfbèrò àlàáfíà ní Liberia ní 1990, Sierra Leone ní 1995, Ivory Coast àti Sudan. Jíógíráfì. Nàìjíríà wà ní apá Ìwọ̀oòrùn Áfríkà ní Ikun-omi Guinea, àpapọ̀ ilẹ̀ ẹ rẹ̀ sì fẹ̀ níwọ̀n 923,768 km2 (356,669 sq mi), èyí jẹ́ kó jẹ́ orílẹ̀-èdè 32ji tó tóbi jù lọ lágbàáyé lẹ́yìn in Tanzania. Ibodè rẹ̀ pẹ̀lú Benin tó 773 km, ti Niger tó 1497 km, ti Chad tó 87 km àti ti Kamẹrúùnù tó 1690 km; bákan náà àlà etí-odò rẹ̀ tó 853 km. Ibi tó ga jù lọ ní Nàìjíríà ni Chappal Waddi ní 2419 m (7936 ft). Àwọn odò gbangba ibẹ̀ ni Odo Oya àti Odo Benue tí wọ́n já pọ̀ ní Lokoja, láti ibi tí wọ́n ti sàn lọ sínú Okun Atlantiki láti Delta Naija. Bákan náà, Nàìjíríà jẹ́ gbọ̀ngán pàtàkì fún orísìírísìí ẹranko àti nǹkan abẹ̀mí pàtàkì. Agbègbè tó ní àwọn orísìírísìí labalaba jùlọ láyé ni agbègbè Calabar ní Ipinle Cross River. Àwọn ọ̀bọ agbélẹ̀ ń gbé ní Gúúsù-Ìlà-oòrùn Nàìjíríà àti Kamẹrúùnù nìkan. Ojúilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ orísìírísìí. Ní Gúúsù, ojú-ọjọ́ jẹ́ ti ojoinuigbo amuooru níbi tí òjò ọdọọdún tó 60-80 inches (1,524 — 2,032 mm) lọ́dún. Ní apá gúúsù-ìlà-oòrùn ní Àwọn Ìwúlẹ́ Obudu wà. Àwọn Ìpínlẹ̀. Nàìjíríà jẹ́ pípín sí mẹ́rìndínlógójì ipinle 36 pọ̀mọ́ Agbègbè Olúìlú Àpapọ̀ kan; àwọn wọ̀nyí náà jẹ́ pípín sí agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ 774. Ìlú mẹ́fà ní Nàìjíríà ni àwọn oníbùgbé tó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún kan tàbí púpọ̀ jùlọ: Èkó, Kano, Ibadan, Kaduna, Port Harcourt àti Benin. Awon Ipinle: Agbegbe: Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀ Okòòwò. Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan láàrin àwọn ọjà tó ń gbéra sókè nítorí àwọn nǹkan àlùmọ́ọ́nì púpọ̀ tó ní, ìnáwó, ìbánisọ̀rọ̀, òfin àti ìrìnnà àti pàsípàrọ̀ ìpínwó (Ilée-pàsípàrọ̀ Ìpínwó Nàìjíríà) tó jẹ́ èkejì tó tóbi jù lọ ní Áfríkà. Nàìjíríà ní 2007 jẹ́ 37th lágbàáyé ní Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè. Gẹ́gẹ́ bí Economic Intelligence Unit àti Ilé-Ìfowópamọ́ Àgbáyé ṣe sọ. Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè tí Nàìjíríà fún ìpín agbára ìrajà tí jẹ ìlọ́po méjì láti $170.7 legbegberunkeji ní 2005 dé $292.6 legbegberunkeji ní 2007. Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ti fò láti $692 fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní 2006 dé $1,754 fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní 2007. Nígbà ọ̀pọ̀ epo àwọn ọdún 1970s, Nàìjíríà dá gbèsè òkèèrè tó tóbi gidi láti ṣe ìnáwó ìdè-ajé-mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí iye owó epo dín ní àwọn ọdún 1980s, ó ṣòro fún Nàìjíríà láti san àwọn gbèsè rẹ̀ padà, èyí fa kó fi owó tó yá sílẹ̀ láìsan kó le ba à kọjú sí bí yíò ṣe san èlé orí owó tó yá nìkan. Lẹ́yìn ìjíròrò ìjọba Nàìjíríà ní October 2005, Nàìjíríà àti àwọn aṣínilówó Paris Club fi ẹnu kò pé Nàìjíríà le ra gbèsè rẹ̀ padà pẹ̀lú ìdínwó tó tó 60%. Nàìjíríà lo èrè tó jẹ níbi epo láti san gbèsè 40% tó kù, èyí jẹ́ kí $1.15 lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún kejì ó lé sílẹ̀ lọ́dún láti ṣe ètò ìdín àìní. Nàìjíríà di orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ní Áfríkà láti san gbogbo gbèsè (tí ìdíye rẹ̀ jẹ́ $30 lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún kejì) tó jẹ Paris Club padà ní April 2006. Apá Okòòwò. Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè 8th tó ń ta epo pẹtiró láyé, bẹ́ẹ̀ sì ni òun ni ìkẹẹ̀wà tó ní ìpamọ́ epo pẹtiró. Nàìjíríà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹ OPEC. Epo petroleomu kó ipa pàtàkì nínú u okòòwò Nàìjíríà tó ṣírò fún 40% Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè (GIO) àti 80% iye owó tí ìjọba ń pa. Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọjà fún Ìbánisọ̀rọ̀-ọ̀ọ́kán tó ń dàgbà sókè kíákíá jù láyé, àwọn ilé-isẹ́ ìbánisọ̀rọ̀-ọ̀ọ́kán bí i MTN, Etisalat, Airtel àti Globacom ni ibùjókòó tó tóbi jù lọ tó sì lérè jù lọ ní Nàìjíríà. Nàìjíríà ní apá okòòwò ìṣefúnni oní-ìnáwó dídàgbà gidi, pẹ̀lú àdàlù àwọn ilé-ìfowópamọ́ abẹ́le àti káríayé, àwọn ilé-isẹ́ ìmójútó ohun ìní, Ilé-isẹ́ Adíyelófò, àwọn ilé-isẹ́ "brokerage", àwọn àjọ aládàáni "equity" àti àwọn ilé-ìfowópamọ́ ìnáwọlé. Bákan náà, Nàìjíríà tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan àlùmọ́ọ́nì àti ìmúlò bíi ẹ̀fúùfù aládàánidá, èédú, bauxite, tantalite, wúrà, tin, irin inú-ilẹ̀, òkúta dídán, niobiomu, òjé, ati sinki. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ wọ̀nyí pọ̀ dáadáa, àwọn ilé-isẹ́ akó-àlùmọ́ọ́nì tí ó mú wọn jáde ò sí. Iṣẹ́ Àgbẹ̀ jẹ́ èyí tó ń mú owó òkèèrè wọlé fún Nàìjíríà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ . Nígbà kan, Nàìjíríà ló ń ta Ẹ̀pà, Kòkó àti Epo Ọ̀pẹ tó pọ̀ jùlọ sí òkè-òkun àti olùpèsè pàtàkì Coconut, Èso ọsàn, Àgbàdo, Ọkà Bàbà, Ẹ̀gẹ́, Iṣu àti Ìrèké. Bí i 60% àwọn ará a Nàìjíríà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ilẹ̀ tó ṣe é dáko sì wà ṣùgbọ́n tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ gidi . Nàìjíríà ní àwọn ilé-isẹ́ àgbẹ̀ṣe bí i Leather àti Ìhun Aṣọ ní Kano, Abeokuta, Onitsha àti Èkó. Ilé-isẹ́ Ato-ọkọ̀-pọ̀ bí i Peugeot láti Fransi àti Bedford láti Britani tó jẹ́ apá kan lára ilé-isẹ́ ọkọ̀ láti orílẹ̀-èdè Amerika, General Motors;nísìn-ín, àwọn ẹ̀wù t-shirt, ike àti oúnjẹ alágolo. Dẹmógíráfíìkì. Ìsùpọ̀ Iye Àwọn Èèyàn. Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè tí èèyàn pọ̀sí jùlọ ní Áfríkà bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tó jẹ́ gangan kò ì jẹ́ mímọ̀. Àjọ Ìṣọ̀kan Àwọn Orílẹ̀-èdè díye pé iye àwọn èèyàn tó wà ní Nàìjíríà ní 2009 jẹ́ 154,729,000, tí 51.7% nínú u wọn ń gbé ní ìgbèríko tí 48.3% sì ń gbé ní ìlú-ńlá ;àti iye ènìyàn 167.5 ní agbègbè ìlọ́po méjì kìlómítà kan. Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè kẹjọ tí ó ní àwọn ènìyàn tó pọ̀ jùlọ láyé. Òǹkà ní 2006 fi hàn pé iye ènìyàn tí ọjọ́-orí wọn wà láàrin ọdún 0-14 jẹ́ 42.3%; láàrin ọdún 15-65 sì jẹ́ 54.6%. Òṣùwọ̀n ìbímọ pọ̀ gidi ju òṣùwọ̀n ikú lọ, wọ́n jẹ́ 40.4% àti 16.9% nínú ènìyàn ẹgbẹ̀rún (1000) ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Nàìjíríà ní bí i ẹ̀ya 250 pẹ̀lú orísìírísìí èdè pẹ̀lú àṣà àti ìṣe orísìírísìí. Àwọn ẹ̀yà ènìyàn tó tóbi jùlọ ni Hausa/Fulani, Yoruba ati Igbo ti àpapọ̀ wọn jẹ́ 68% nígbàtí Edo, Ijaw, Kanuri, Ibibio, Ebira, Nupe àti Tiv jẹ́ 27%,tí àwọn yòókù jẹ́ 7%.Ó jẹ́ mímọ̀ pé Ààrin ìbàdí Nàìjíríà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà bí i Pyem, Goemai, àti Kofyar.
Nàìjíríà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3164
3164
Tutsi Tutsi jé eya kan lárà àwon olùgbé mẹta àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Rwanda and Burundi ni apa arin Afrika. Ìyàtọ̀ díẹ̀ ló wà láàrìn àsà àwọn ará Tutsi àti Hutu. Àgbẹ̀ àti Olùsìn maalu ni isẹ́ àárò abínibí àwọn ara Tutsi. Maálù jẹ́ ohun tí àwọn ará Tutsi fi máa ń fi agbára àti Ọlà wọn han, èyí ló sì mú àwọn ará Tutsi jẹ́ Olúborí nínú isẹ́ àgbẹ̀. Fun bí ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta ọdún sẹ́yin ni Tutsi ti ń se ìjọba lórí àwọn tókù.
Tutsi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3165
3165
Twa Twa tabi Batwa jé àwon èyà ènìyàn kúkuru (pigmy) tí a le pè ní àràrá. Àwọn ni Olùgbé tí a ní àkọsílẹ̀ pé ó pẹ́ jù ní àarin gbùngbùn ìlẹ Afíríka nibi tí a ti rí àwọn orílẹ̀-èdè bí Rwanda, burunidi ati Ilẹ̀ olomìnira ti Congo lóde òní. Àwọn ará Hutu tó sẹ̀ wá láti àwọn ara Bantu jọba lé Twa lori nígbà tí wọ́n dé agbègbè náà ṣùgbọ́n nígbà tó di bí ẹgbẹ̀rún ọdun ìkẹẹ̀dógún (15th century AD) ni Tustsi fó jẹ́ ara ẹ̀yà Bantu dé sí agbègbè náà ti wọ́n sì jẹ ọba lórí Twa àti Hutu ti wọ́n ba lórí ìlẹ náà. Àwọn ènìyàn Twa ń sọ èdè Kwyarwanda èyí ti àwọn ènìyàn Tutsi ati Hutu n sọ.
Twa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3169
3169
Èdè Wolof Ede Wolof jẹ èdè tí à ń sọ ni atí bèbè Senegal Mílíọ̀nù méjì-àbọ̀ niye àwọn tó ń sọ. Awọn Olùbágbè wọn ni Mandika ati Fulaní. Awọn isẹ́ ọna wọn màa ń rewà tó sì ma ń ní àmìn àti àwòràn àwọn asáájú nínú ẹ̀sìn musulumi. Ìtan Wolof ti wà láti bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjìlá tàbí métàlá sẹ́yìn. Ìtàn ẹbí alátẹnudẹ́nu wọn sọ pé ọ̀kan lára àwọn tó kọkọ tẹ̀dó síbí yìí jẹ́ awọn to wa láti orífun Fulbe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn Wolof ni a le rí nínú àwọn orin oríkì èyí ti a ma ń gbọ́ láti ẹnu àwọn ‘Griots’ àwọn akéwì. Mùsùlùmí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọnm ará Wolof.
Èdè Wolof
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3170
3170
Woyo Woyo Ní agbègbè Congo (Zaire) ni a tin í àwọn ẹ̀yàn Woyo. A kò le sọ pàtó iye àwọn tó ń gbé agbègbè yìí. Kiwoyo (Bantu) ni èdè àwọn ẹ̀yà yìí. Solongo, Kongo, Vili àti Yombe jẹ́ àwọn Olùbágbé. Ní ñǹkan ẹgbẹ̀rún ọdún kẹ̀ẹdógún (prior 15th century) ìtàn se akọ̀sílẹ rẹ pe ọmọọba bìnrin Nwe kò àwọn ènìyàn rẹ tọ́ yẹ kan dí Woyo sodí lo sí ojù gbangba níbi tí wọ́n gbé wà bayìí. A pa ìlu wọn àkọ́kọ́ run nígbà tí Ọba Kikongo tó jẹ́ olùbágbè wọn Kógun jàwọ́n. Arábìnrìn Kongo la gbọ́ pó dá ilú Woyo kejì silẹ̀. Isẹ́ àgbẹ̀de adẹ́mu apẹja ati ode jẹ́ àwọn isẹ́ ọkùnrin Woyo
Woyo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3171
3171
Wum Wum je ilu ni Kamẹroon Apa ariwa Cameroon ni ibùgbé àwọn ènìyàn Wum. Wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn níye. Àwọn alábágbé wọn ni Esu, kom àti Bafut. Èdè Wum (macro-Bantu) ni wọ́n n sọ. Nítori ìgbàgbọ̀ wọn nipa orí, kò fẹ̣́si nínú isẹ́ ọnà wọn tí a kì í rì àwòrán ori. Àgbè ọlọ́gìn àgbàdo, isu, ati ewébe ni àwọn ará Wum. Wọn tún jẹ́ olùsìn adìẹ ati ewúrẹ́ èyí sì kó ìpa tó jọjú nínú àtijẹ wọn lójojúmọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Fulani ló di mùsùlùmí ni òpin ẹgbẹru ọdun méjìdínlógún. Akitiyan wọn nínú ẹ̀sìn yìí láti tàn-án ka ló mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Wum dí ẹlẹ́sìn mùsùlùmí.
Wum
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3172
3172
Yaka Yaka Ní gúsu apa iwo oòrùn Congo ti Zaire àti ní Angola ni àwon ènìyàn Yaka wà. òké méjìdínlógún (300.000) ni wón tó níye. Lára àwon aládúgbò won ni Suku, Teke àti Nkanu.’ Itan àtenudénu fìdí rè múlè pé àwon ènìyàn Yaka pèlú Suku jé ara àwon tí ó kógun ja ìlú ńlá Kongo ni egbèrún odún kerìndínlógún. Suku ti je òkan lára kéréjé èyà tó wà lábé Yakà rí./ Nípa síse ode ni ònà tí àwon okùnrin Yaka n gbà sapé won láti gbe ètò orò ajé. ‘Ajá ode sì jé ohun ìní pàtàkì láàrin àwon Yaka. Àgbe ni àwon obìnrin Yaka, wón si ma ń gbìn ègé, ànànmó, èwà àti erèé míràn.
Yaka