url
stringlengths
37
41
id
stringlengths
1
5
text
stringlengths
2
134k
title
stringlengths
1
120
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3174
3174
Yorùbá Yorùbá lè tọ́ka sí:
Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3175
3175
Zulu ! style="background-color: #b0c4de" | Èdè Zulu(many also speak English, Afrikaans, Portuguese, or other indigenous languages such as Xhosa) ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀sìn Christian, African Traditional Religion ! style="background-color: #b0c4de" | Ẹ̀yà abínibí bíbátan Bantu · Nguni · Basotho · Xhosa · Swazi · Matabele · Khoisan Zulu Àwọn ènìyàn Zulu ni ẹ̀yà tó pọ̀jù ni orílè-èdè Gúúsù Áfríkà. A mọ̀ wọ́n mọ́ ìlẹ̀kẹ̀ alárànbàrà àti agbọ̀n pẹ̀lú àwọn ñǹkan gbígbẹ́. Wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn jẹ́ ìran tó sẹ̀ lára olóyè kan láti agbègbè Cóńgò, ni ñǹkan ẹgbẹ̀rún ọdùn mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn ni wọn tẹ̀síwájú sí Gúsú. Àwọn ènìyàn Zulu gbàgbọ́ nínú òrìṣà tó ń jẹ́ Nkulunkulu gẹ̀gẹ́ bí asẹ̀dá wọn òrishà yìí ko ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìfẹ́ sí ìgbé ayé kọ̀ọ̀kan. Awọn ènìyàn Zulu pin sí méjì! àwọn ìlàjì ni inú ìlù nígbà tí àwọn ìlàjì yókù sì wà ní ìgberíko tí wọ́n ń ṣisẹ́ àgbẹ̀. Mílíònù mẹ́sàn-án ènìyàn ló ń sọ èdè Zulu. Èdè yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè ìjọba mọ́kànlá ilẹ̀ South Africa. Àkọtọ Rómàniù ni wọ́n fi ń kọ èdè náà.
Zulu
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3176
3176
Ilẹ̀ Yorùbá Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè ìgbéró àsà ilẹ̀ àwọn ọmọ Yorùbá ní Ìwọ̀òrùn Áfríkà. Ilẹ̀ Yorùbá fẹ̀ láti Nàìjíríà, Benin títídé Togo, agbègbè ilẹ̀ Yorùbá fẹ̀ tó 142,114 km2 106,016 km2 inú rẹ̀ (74.6%) bọ́sí Nàìjíríà, 18.9% bósí orílẹ̀-èdè Benin, àti 6.5% yìókù bósí orílẹ̀-èdè Togo. Ilẹ̀ ìgbéró àsà Yorùbá yìí ní iye àwọn ènìyàn bíi mílíọ́nù 55. Ìtàn Àkọọ́lẹ̀ Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Àtàndá (1980), bí àwọn Yorùbá ṣe dé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àsìkò tí wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀ kíi ṣe ìbéèrè tí ẹnikẹ́ni lè dáhùn ní pàtó nítorí pé àwọn baba nlá wọn kò fi àkọsílẹ̀ ìṣe àti ìtàn wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjogúnbá. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tí a gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá yàtọ̀ sí ara wọn díẹ̀díẹ̀. Ìtàn kan sọ fún wa pé àwọn Yorùbá ti wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀ àti láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé. Ìtàn ọ̀rùn pé kí ó wá ṣẹ̀dá ayé àti àwọn ènìyàn inú rẹ̀. Ìtàn náà sọ fún wa pé Odùduwà sọ̀kalẹ̀ sí Ilé-Ifẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Wọ́n sì ṣe iṣẹ́ tí Olódùmarè rán wọn ní àṣepé. Nípasẹ̀ ìtàn yìí, a lè sọ pé Ilé-Ifẹ̀ ní àwọn Yorùbá ti ṣẹ̀, àti pàápàá gbogbo ènìyàn àgbáyé. Ìtàn mìíràn tí a tún gbọ́ sọ fún wa pé àwọn Yorùbá wá Ilé-Ifẹ̀ láti ilẹ̀ Mẹ́kà lábẹ́ àkóso Odùduwà nígbà tí ìjà kan bẹ́ sílẹ̀ ní ilẹ̀ Arébíà lẹ́yìn tí ẹ̀sìn Islam dé sáàrin àwọn ènìyàn agbègbè náà. Àwọn onímọ̀ kan nípa ìtàn ti yẹ ìtàn yìí wò fínnífínní, wọ́n sì gbà wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe é ṣe kí àwọn Yorùbá ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Mẹ́kà àti agbègbè Arébíà mìíràn kí wọ́n tó ṣí kúrò, ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá gan-an ni íjíbítì tàbí Núbíà. Àwọn onímọ̀ yìí náà gbà pé Odùduwà ni ó jẹ́ olórí fún àwọn ènìyàn yìí. Kókó pàtàkì kan tí a rí dìmú ni pé Odùduwà ni olùdarí àwọn ènìyàn tí ó wá láti tẹ̀dó sí Ilé-Ìfẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn méjéèjì tí a gbọ́ ṣe sọ. Tí a bá yẹ ìtàn méjéèjì wò, a ó rí i pé kò ṣe é ṣe kí Odùduwà méjèèjì jẹ́ ẹnìkan náà nítorí pé àsìkò tàbí ọdún tí ó wà láàrin ìṣẹ̀dá ayé àti àsìkò tí ẹ̀sìn Islam dé jìnna púpọ̀ sí ara wọn. Nítorí ìdí èyí a lè gbà pé nínú ìtàn kejì ni Odùduwà ti kópa. Ìdí mìíràn tí a fi lè fara mọ́ ìtàn kèjì ni pé lẹ́yìn àyẹ̀wò sí ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá fínnífínní, ó hàn gbangba pé Odùduwà bá àwọn ẹ̀dá Olọ́run kan ní Ilé-Ifẹ̀ nígbà tí ó dé ibẹ̀. Àwọn ìtàn kan dárúkọ Àgbọnmìrègún tí Odùduwà bá ní Ilé-Ifẹ̀. Èyí fihàn pé kìí ṣe òfìfò ní ó ba Ilé-Ifẹ̀, bí kò ṣe pé àwọn kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú Àgbọnmìrègún. Èyí sì tọ́ka sí i pé a ti ṣẹ̀dá àwọ̣n ènìyàn kí ọ̀rọ̀ Odùduwà tó jẹ yọ, nítorí náà, kò lè jẹ́ Odùduwà yìí ni Olódùmarè rán wá láti ṣẹ̀dá ayé gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ ọ nínú ìtàn ìṣẹ̀dá. Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, a rí ẹ̀rí nínú ìtàn pé Odùduwà níláti gbé ìjà ko àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan tí ó bá ní Ilé-Ifẹ̀ láti gba ilẹ̀, àti pàápáà láti jẹ́ olórí níbẹ̀. Ìtàn Mọ́remí àjàṣorò tí ó fi ẹ̀tàn àti ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kan ṣoṣo tí ó bí gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìmúnisìn àwọn ẹ̀yà Ùgbò lè jẹ̀ ẹ̀rí tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Odùduwà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun kí wọ́n tó le gba àkóso ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan tí wọ́n bá ní Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn àbáláyé ti sọ. Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ènìyàn Yorùbá wà káàkiri ìpínlẹ̀ bí i mẹ́sàn-án. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Ẹdó, Èkó, Èkìtí, Kogí, Kúwárà, Ògùn, Òndò, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́. Lóde òní, Yorùbá wà káàkiri ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú (Áfíríkà), Amẹ́ríkà àti káàkiri àwọn erékùsù tí ó yí òkun Àtìlántíìkì ká. Ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. A le ríwọn ní Nàìjíríà, Gáná, Orílẹ̀-Olómìnira Bẹ̀nẹ̀, Tógò, Sàró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti àwọn erékùsù káàkiri, a lè rí wọn ní jàmáíkà, Kúbà, Trínídáádì àti Tòbégò pẹ̀lú Bùràsíìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ sí ètò ìjọba olósèlú àwarawa tí ó fi gómìnà jẹ olórí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a tún ní àwọn ọba aládé káàkiri àwọn ìlú nlánlá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Díẹ̀ lára wọn ni Ọba ìbíní, Ọba Èkó, Èwí tí Adó-Èkìtì, Òbáró ti Òkéné, Aláké tí Abẹ́òkúta, Dèji ti Àkúrẹ́, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Àtá-Ója ti Òṣogbo, Sọ̀ún ti Ògbòmọ̀ṣọ́ ati Aláàfin ti Ọ̀yọ́. Baálẹ̀ ní tirẹ̀ jẹ́ olórí ìlú kékeré tàbí abúlé. Ètò ni ó sọ wọ́n di olórí ìlú kéréje nítorí pé Yorùbá gbàgbọ́ pé ìlú kìí kéré kí wọ́n má nìí àgbà tàbí olórí. Aláàfin ni a kọ́kọ́ gbọ́ pé ó sọ àwọn olórí báyìí di olóyè tí a mọ̀ sí baálẹ̀. Lábẹ́ àwọn olórí ìlú wọ̀nyí ni a tún ti rí àwọn olóyè orísìírísìí tí wọ́n ní isẹ́ tí wọ́n ń se láàrín ìlú, ẹgbẹ́, tàbí ìjọ (ẹ̀ṣìn). Lára irú àwọn oyè bẹ́ẹ̀ ni a ti rí oyè àjẹwọ̀, oyè ogun, oyè àfidánilọ́lá, oyè ẹgbẹ́, oyè ẹ̀ṣìn àti oyè ti agboolé bíi Baálé, Ìyáálé, Akéwejẹ̀, Olórí ọmọ-osú, Ìyá Èwe Améréyá, Mọ́gàjí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èdè Yorùbá. Ní báyìí, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní ìwọ̀ oòrùn aláwọ̀ dúdú fún ẹgbẹ̣ẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn tó n sọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà norílẹ̀ èdè Bìní. Tógò àti apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, àti Trinidad. Ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ̀. Àṣà Yorùbá. Ìràn Yorùbá jẹ́ ìran tó ti ní àṣà kí Òyìnbó tó mú àṣà tiwọn dé. Ètò ìsèlú àti ètò àwùjọ wọn mọ́yán lórí. Wọ́n ní ìgbàtbọ́ nínú Ọlọ́run àti òrìṣà, ètò ọrọ̀ ajé wọn múnádóko. Yorùbá ní ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀lé láti fi ọmọ fọ́kọ tàbí gbé ìyàwó. Wọ́n ní ìlànà tó sọ bí a se n sọmọ lórúkọ àti irú orúkọ tí a le sọ ọmọ torí pé ilé là á wò, kí a tó sọmọ lórúkọ. Ìlànà àti ètò wà tí wọ́n ń tẹ̀lé láti sin ara wọn tó papòdà. Oríìsírísìí ni ọ̀nà tí Yorùbá máa ń gbá láti ran wọn lọ́wọ́, èyí sì ni à ń pè àṣà ìràn-ara-ẹni-lọ́wọ́. Àáró, ìgbẹ́ ọdún dídẹ, ìsingbà tàbí oko olówó, Gbàmí-o-ràmí àti Èésú tàbí Èsúsú jẹ́ ọ̀nà ìràn-ara-ẹni-lọ́wọ́. Yorùbá jẹ́ ìran tó kónimọ́ra. Gbogbo nǹkan wọn sì ló létò. Gbogbo ìgbésí ayé wọn ló wà létòlétò, èyí ló mú kí àwùjọ Yorùbá láyé ọjọ́un jẹ́ àwùjọ ìfọ̀kànbalẹ̀, àlàáfíà àti ìtẹ̀síwájú. Àwọn àṣà tó jẹ mọ́ ètò ìbágbépọ̀ láwùjọ Yorùbá ní ẹ̀kọ́-ilé, ètò-ìdílé, ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tàbí irọ̀sírọ̀. Ẹ̀kọ́ abínimọ́, àwòse, erémọdé, ìsírò, ìkini, ìwà ọmọlúàbí, èèwọ̀, òwe Yorùbá, ìtàn àti àlọ́ jẹ́ ẹ̀kọ́-ilé. Nínú ètò mọ̀lẹ́bí lati rí Baálé, ìyáálé Ilé, Ọkùnrin Ilé, Obìnrin Ilé, Ọbàkan, Iyèkan, Ẹrúbílé àti Àràbátan. Oríṣìíríṣìí oúnjẹ tó ń fún ni lókun, èyí tó ń seni lóore àti oúnjẹ amúnidàgbà ni ìràn Odùduwà ní ní ìkáwọ́. Díẹ̀ lára wọn ni iyán, ọkà, ẹ̀kọ, mọ́ínmọ́ín àti gúgúrú. Àwọn Ìwé Ìtókasí. Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá, Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga ti Àwọn Olùkọ́ni Àgbà tí ó jẹ́ ti Ìjọba Àpapọ̀ ní Osíẹ̀lẹ̀, Abẹ́òkúta (2005): Ọgbọ́n Ìkọ́ni, Ìwádìí àti Àṣà Yorùbá.
Ilẹ̀ Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3178
3178
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá Orílẹ̀-Èdè Yorùbá Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ènìyàn Yorùbá wà káàkiri ìpínlẹ̀ bí i mẹ́sàn-án. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Ẹdó, Èkó, Èkìtí, Kogí, Kúwárà, Ògùn, Òndò, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́. Lóde òní, Yorùbá wà káàkiri ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú (Áfíríkà), Amẹ́ríkà àti káàkiri àwọn erékùsù tí ó yí òkun Àtìlántíìkì ká. Ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. A le ríwọn ní Nàìjíríà, Gáná, Orílẹ̀-Olómìnira Bẹ̀nẹ̀, Tógò, Sàró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti àwọn erékùsù káàkiri, a lè rí wọn ní jàmáíkà, Kúbà, Trínídáádì àti Tòbégò pẹ̀lú Bùràsíìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ sí ètò ìjọba olósèlú àwarawa tí ó fi gómìnà jẹ olórí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a tún ní àwọn ọba aládé káàkiri àwọn ìlú nlánlá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Díẹ̀ lára wọn ni Ọba ìbíní, Ọba Èkó, Èwí tí Adó-Èkìtì, Òbáró ti Òkéné, Aláké tí Abẹ́òkúta, Dèji ti Àkúrẹ́, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Àtá-Ója ti Òṣogbo, Sọ̀ún ti Ògbòmọ̀ṣọ́ ati Aláàfin ti Ọ̀yọ́. Baálẹ̀ ní tirẹ̀ jẹ́ olórí ìlú kékeré tàbí abúlé. Ètò ni ó sọ wọ́n di olórí ìlú kéréje nítorí pé Yorùbá gbàgbọ́ pé ìlú kìí kéré kí wọ́n má nìí àgbà tàbí olórí. Aláàfin ni a kọ́kọ́ gbọ́ pé ó sọ àwọn olórí báyìí di olóyè tí a mọ̀ sí baálẹ̀. Lábẹ́ àwọn olórí ìlú wọ̀nyí ni a tún ti rí àwọn olóyè orísìírísìí tí wọ́n ní isẹ́ tí wọ́n ń se láàrín ìlú, ẹgbẹ́, tàbí ìjọ (ẹ̀ṣìn). Lára irú àwọn oyè bẹ́ẹ̀ ni a ti rí oyè àjẹwọ̀, oyè ogun, oyè àfidánilọ́lá, oyè ẹgbẹ́, oyè ẹ̀ṣìn àti oyè ti agboolé bíi Baálé, Ìyáálé, Akéwejẹ̀, Olórí ọmọ-osú, Ìyá Èwe Améréyá, Mọ́gàjí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3182
3182
Ìfitónilétí Informatics (Ifitonileti) OWOLABANI JAMES AHISU ati AKINDIPE OLUWABUNMI TOPE Ètò Gírámà Ìfáàrà “Ní àtètèkọ́sẹ ni ọ̀rọ̀ wà …” (Jọ́ọ̀nù 1:1) Kì í ṣe ohun tó dájú ni pé akẹ́kọ̀ó èdè kọ̀ọ̀kan yóò jiyàn pé ọ̀rọ̀ ni wúnrèn ìpìlẹ̣̀ fún ìtúpalẹ̀ nínú àwọn gírámà. A lè yígbà yígbà kí a wádìí lítítésọ̀ fún àríyànjiyàn lórí mọ́fíìmù, sùgbọ́n léyìn gbogbo atótónu yìí, kí ni a rí? Ṣé ó lẹ́ni tó n sọ mófíìmù tó dáwà tí wọn kìí sìí ṣe ọ̀rò fúnra wọn? kí ni ó wà nínú ọ̀rò–sísọ tó ní ìtumọ̀? Kí ni àwọn ìdánudúró fún gbólóhùn? Ọ̀rọ̀ ni àárín, inú, àti àwọn ìbẹ̀rè ọ̀rọ̣̣̣̀.àjòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀, kódà fóníìmù pẹ̀lú kò lè dá dúró tí kò bá ti lè làdì sí ìtumọ̀ nínú ọ̀rọ̀. Ní àtètèkọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ wà. Ó wà níbẹ̀ láti dá ayé ọfọ̀ sílẹ̀, láti mọ àti láti tún ọ̀rò–sísọ mọ, láti fikún, láti yọ kúrò àti láti mú yẹ ní oríṣìíríṣị ọ̀nà. Ẹ jẹ́ kí á padà kúrò ní àníjẹ́ ìmọ́ wa lọ sí ajúwè nínú gírámà; ètò rẹ̀ ìlànà ìfojú- ààtò-wò àti àlàyé rẹ̀. Fífi ojú gbogbo ayé wo gírámà, a máa ṣe àpèjúwe ètò gírámà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀, ní ìbẹ̀rẹ̀, ní pàtàkì pèlú èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá kí a sì fi àpéjọ àwọn ènìyàn tí n gbọ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ láti dásí ìfihàn nípa títẹríba fún èrò ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún ìtúpalẹ̀ ní èdè tirẹ̣̀, èdè ènìyàn mìíran. Àkíyèsí ni pé tí èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá, àwọn èdè tí kò tàn mọ́ra wọn tó gbilẹ̀, ni a lè tún ṣe àtúnṣe rẹ̀ sí àwọn òfin tí a ti gbìmọ̀ wọn níbí, ó ṣe é ṣe kí àwọn nnkan tí à n rò jẹ́ òtítọ́, kí ó sì sisẹ́ fún èdè mìíràn títí dé àwọn àbùdá àìròtẹ́lẹ̀ àwọn èdè kan. Bí ẹ̀fè yẹn kò bá mú ìbàjẹ́ wá, à á ṣe àtúnwí àbá kan náà pẹ̀lú èyí: àwọn tí wọn kò gba èyí gbọ́dọ̀ mọ̀ nínú wọn pé nígbà tí wón bá n ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn èdè wọn ni àwọn èrò yìí, èrò yìí ni a máa ṣe atótónu wa tí ó kún lórí rẹ̀ fún àpẹẹrẹ èdè Yorùbá, ‘Hausa’, èdè Gẹ̀ẹ́sì, èdè ‘Ibibio’… àwọn èdè tí a kójọ pèlú ìyàtọ̀ ni wọ́n ní ìbáṣepọ̀ kankan nítorí pé wọ́n jẹ́ èdè ènìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, tí a bá fi ọwọ́ gírámà kan náà mú wọn, à n sọ pé wón ní ìjọra, bí ọkùnrin elédè Gẹ̀ẹ́sì ṣe jọ ọkùnrin elédè Yorùbá kan, tí ìyàtọ̀ wọn sì jẹ́ ti àwọ̀ wọn. Ìyókù orí yìí yóò mú wa wà ní ìmúra sílẹ̀ láti rí ìdí tí àwọn onímọ̀ èdè fi n kóòdù àwon ìtúpalẹ̀ wọn bí wọ́n bí wọ́n ṣe n ṣe. 2.1 ỌRO Fífún àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lédè Gẹ̀ẹ́sì: 1. Ọkùnrin, ìwé, kálámù, òòtẹ̀, ife, ̣Olè, ṣíbí, tábìlì, òṣùká, téèpù, ẹni tó rí sọ Gẹ̀ẹ́sì kò ni ní wàhálà nípa ṣíṣẹ̀dá: 2. Àwọn ọkùnrin , àwon ìwé, àwọn kálámù, àwọn òòtè, ̣ àwon ife, Àwọn ṣíbí, àwọn tábìlì, àwọn òṣùká, àwọn téèpù. Ó ti pinu ní ọkàn rẹ̀ láti mọ ìsọdorúkọ àwọn ọ̀rò náà àti àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ (Latin: nomen ‘name’) ̣ni a lè sọ di ọ̀pọ̀ ----- àwọn àpẹẹrẹ pọ̀ nípa àwon nnkan ti a sọ lórúkọ. Nípa ti iye ìtẹ̀sí rẹ̀, a lè fi àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn bí i kan tàbí náà kún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rò náà. Yíyéni láì ṣàlàyé tóbẹ́ ẹ̀ jùbé ẹ̀ lọ gírámà rẹ̀ ni gbìmọ̀ tíórì kan pé kí gbogbo àwọn ọ̀rò orúkọ gba àwọn átíkù kan tàbí náà. Lára àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ni ó jẹ́ pé átíkù wo ni ó síwájú tí ó sì tẹ̀lẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì nínú ìwé tí à n kà lọ́wó láti túmọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó dá yàtọ̀ nípa: 3. ife náà ~ ife kan ṣíbí náà ~ ṣíbí kan Ohùn kan tó tún dìjú ni pé, nígbà tí a bá mú ìkan lára àwọn átíkù wọ̀nyí, ní dandan ọ̀kan lára àwọn tó lè dá dúró tí a pín sí abẹ́ ọ̀rò orúkọ̣ ̣̣̣̣gbọ́dọ̀ tẹ̀le, ṣùgbọ́n kì í ṣe dandan kí sísọ ọ̀rọ̀ jẹ́ òotọ́! Ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀, à n tẹ̀ síwájú láti sọ pé bí a bá ní ọ̀rọ̀ kan, ohun mìíràn, tí ó wá láti ìpín mìíràn, lè tẹ̀le tàbí kí ó máa tẹ̀le, nínú síntáàsì, a máa n lo ọ̀nà mìíràn làti sọ pé: Ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ X ni a pín g̣ẹ́gẹ́ bí Y àti pé ó lè jẹyọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Z, Z jẹ́ ọ̀rò kan tí ó lè wà tàbí kí ó má wà nílé nígbà náà. Tí a bá n fojú iṣẹ́ ọnà wò ó ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ X ni ìpín onítumọ̀ àdámọ̀ (ìsọ̀rí ọ̀rọ̀) Y ní abgègbè tó saajú òrọ̀mìíràn Z, wíwá níbẹ̀ Z jẹ́ wọ̀fún. Àkọsílẹ̀ afòyemọ̀ tí òkè yìí ni à n pè ní àpíntúnpín sí ìsòrí tó múná dóko ni a jíròrò lè lórí nínú Yusuf (1997). Tí a bá padà sí àwọn àpẹẹrẹ (1,2) ti òkẹ̀, ẹni tí n sọ̀rọ̀ lórí bí a ṣe lè mọ àwọn tí ó dá dúró yìí to jẹ́ ọ̀rò orukọ tí o lè wà ní ipò tó ṣe kóko; olùwà àti àbọ̀. Lára àwọn ìmọ̀ rẹ̀ nípa àwon òrò wònyí ni pé a lè fún wón ni àwon ipa kan láti kó; tí a bá ní ká wò ó kí ni ìwúlò wọn tí wọn kò bá kó ipa kankan ní àyíká gbólóhùn tàbí ọfọ̀ wọn. Fún àpẹẹrẹ, olè kan jé ̣òṣèré, olùkópa tí ó bá kópa níhìnìn tàbí òhún láti mú àpíyadà wá. Nígbà tí ó bá n ṣerè, a mọ̀ pé ó lè jalè. Kódà kì í ṣe olè tí a kò bá mọ̀ ọ́ sí ẹni tó jí nnkan kan nítorí nínú gbólóhùn bí i. 5. Olè náà jí kálámù Ọ̀rò náà tó jẹ́ ‘ole’ sọ ohun tó pọ̀. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó mú náà, tójẹ átíkù, ó lè yàtọ̀ fún oye àwọn olè àti pé ó jẹ ÒṢÈRÉ nínú àyè ọfọ̀ tó lè mú ìyípadà bá ìfarasin kálámù náà. Rántí pé ọ̀rọ̀ náà ‘kálámù’ wà ní ìsọ̀rí yìí náà pẹ̀lú; ó máa gba átíkù náà/kan tí a lè gbékalẹ̀ ní ọ̀pọ̀ (àwon kálámù) àti pé a fẹ́ fà á yọ, gẹ́gẹ́ bí àwon ojúgbà rẹ̀, wí pé ó jẹ́ olùkópa ní àyíká gbólóhùn náà sùgbọ́n ní báyìí ó n kó ipa ohun tí wón jí, ipa náà ni a máa pè ni ÀKỌ́SO. Ọpọlọ wa so fún wa pé kálámù kan lè jẹ́ ohun ÈLÒ fún ìbánisọ̀rọ̀. Àwon ipa náà, tí àwon álífábẹ́tì nlá dúró fún ni à n pè ní Àwon ipa aṣekókó, a lè gé e kúrú sí ‘Theta – roles’, tí wón máa n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ‘Ø roles’, bí ìtẹ̀síwájú bá ṣe n bá ìtúpalẹ wa. Ko lè sí ohun ìtọ́kasí tó dúró, àwon olùkópa kan tí a lè tọ̀ka sí, nawọ́ sí, dárúkọ, sọ̀rọ̀ nípa, tí kò ní gba ‘Ø role’ kan. Àwon àjọ̣ni tí a sábà náa n rí ‘Ø roles’ jẹ OLÙṢE, OLÙFARAGBA, (nígbà mìíràn tí a máà n pè ni Àkọ́so), ÒPIN àti ÈLÒ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwon onímọ̀ lìngúísíìkì mọ àwọn mìíràn dájú. Àwọn àbùbá àdámọ́ ọ̀rò wà tí a lè tọ́ka sí báyìí. Àwọn àbùdá mìíràn máa hàn kedere tí a bá gbé èdè tó yàtọ̀ sí èyí tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ỵẹ̀wò. Nítòótọ́, a máa sọ pé ìwúlò wò ni ó wà nínú kí a máa sọ̀rọ̀ nípa àwon ohun tí a kò rí nínú èdè wa! Ìkìlò: À n sọ̀rò nípa àwọn àbùdá tó wà nínú èdè ènìyàn, kì í kan n se nínú ẹ̀dẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tàbí èdè Yorùbá. Rántí ohun tí a rò nípa Gírámà Àgbáyé, Èdè Gẹ̀ésì, èdè Ìgbò, èdè ‘Eskimo’, èdẹ̀ ‘Japan’…….. jẹ́ díẹ̀ lará èdè ènìyàn tí wón sì ní àwọn ìyàtọ̀ wọn, nínú ohun tó ṣe kókó báyìí, fífún àwọn ọ̀rò aṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ asẹ̀dá bí ị Ọ̀PÒ ‘Ø role’, àwon ipò onítumọ̀ gírámạ̀, abbl. Ẹ jé ̣kí á fi àbùdá kan kún àwon àpẹẹrẹ wa. Àwon ọ̀rọ̀ náà ni a lè yí padà. Ní bẹ́è à á ní: 6a. Ọkùnrin alágbára kan b. Ògbójú olè kan d. Igi oaku kan e. Téèpù mímọ́gaara kan ẹ. Ife kan tó kún fún kọfị́ ̣ f. Òṣùká kan fún ìbọ̀sẹ̀ aré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá Àwon wònyí jẹ́ àwọn ẹ̀pọ́n tó jẹ̀ wí pé bí a bá yọ wọ́n kúrò ìtumọ̀ àwon ọ̀rò náa kò ní dínkù (ìsomó)̣. Àwọn àkámọ́ tí a lò nínú àpíntínpín sí ìsọ̀rí tó múná dóko àti àwọn tí a fihàn ní orí kìíní, ni a lè lò báyìí, bí i (T). 7a. ife kan ([tó kún] fún ḳọfí) b. téèpù (mímógaara) kan c. Ọkùnrin (alágbára) kan. Àwon ohun tí a fi sínú àkámọ́ ni à n pè ní àwon ìsomọ́, wọn kò ní apíntúnpín sí ìsọ̀rí, wọn kì í ṣe dandan, wọ́n jẹ ẹ̀pọ́n –ọn wọ̀fún. Nígbà tí àwon wònyí tún wúlò níbò mìíràn, a fẹ yán an pé kìí ṣe gbogbo àwọn ẹ̀pọ́n ló jẹ́ wọ̀fún. Kódà nígbà tí wọn kò bá ní ìtumọ̀ àdámò wọ́n wúlò. Fún àpẹẹrẹ, ọba tàbí olorì kò níyì bí ọba tí wọn kò bá ní ìjọba tiwọn. ní bẹ́ẹ̀ a ní: 8a. Ọba tí Èkó b.̣ ̣ òbí ti Agbor d. Ọba àwon Júù Kódà Ọba bìnrin ‘Elibabeth’ tí ó tó láti ṣe ìtóka ni a mọ̀ pé ó ní agbára lórí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àkíyèsí pé láti sọ pé Oba bìnrin náà, láà jẹ́ pé ènìyàn n gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tàbí tí iyè rẹ̀ sọ pèlú oríle – èdè náà, máà ṣàì nítumọ̀. Orúkọ àbísọ lè tó láti mọ àwọn orí oyè, ṣùgbọ́n ìjọba wọn tí se pàtàkì jù, ẹ̀pọ́n wọ̀fun. Àwọn ẹ̀pọ́n ni à n pè ní Àwọn Àfikún. Ní kúkúrú, àwọn ẹ̀pọ́n PP ti ọba àti ọba àti ọba jẹ wúnrẹ̀n tí a ní lò. 2.2 Àkópọ̀ kúkúrú kan Àwon ọ̀rọ̀, tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí i àwon ọ̀rò orúkọ, gba àwọn nnkan mìíràn mọ́ra dandan, ‘DET’, Àwon ipa aṣekókó, ÌSỌDỌ̀PỌ̀, àwọn kan– npá àti wòfún (ákámọ́), àwon Àfikún àti àwon Ìsomọ́ bákan náà, àti àwon mìíràn tí a kò mẹ́nu bà. Àwon àbùdá àdámọ̀ ti olùsọ èdè rẹ̀ gbọ́dọ̣̀ mọ̀ ni àwon wònyí. Ó jẹ́ dandan pé ó mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀, lára èyí tí a máa sọ tó bá yá ní ìfìwàwẹ̀dá. A fẹ́ jẹ kí àwon akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé àwon nnkan wònyí jẹ́ àìkọ́, lára àwon akówọ̀ó rìn UG nínú àká – ọ̀rò náà (atúmò èdè tí iyè náà). A mẹ́nu bà á pé àwon nnkan wònyí kìí hànde bákan náà, sùgbọ́n ó lè gbọ́n fara sin sínú àwon kóòdù mofọ́lójì nínú ọ̀rò náà, ní àwon àyíká tí a kò funra sí. 2.3 Ọ̀rò náà (2) Àwon àkójọpọ̀ àwon ọ̀rò tó yàtọ̀ sí ti àkọ́kó máa fún wa ni àwon nnkan. Ẹ jẹ kí a mu àwon ọ̀rọ̀ tó n sọ nípa àwon ọ̀rò orúkọ. 1. talk, kill, endure, wait, eat, drink, write, see fún àwon elédè Gẹ̀ẹ́sì, àwon ọ̀rọ̀ wònyí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe (Latin: verbum ‘Word’), won le fi àsìkò ìsẹ̀lẹ̀ hàn nípa gbígba àwon àfòmọ́: 2. talk: talks, talked, talking, ̣̣̣̣̣̣ ̣ kill: kills, killed, killing. X X-s X-ed X-ing. Àwon gẹ́gẹ́ bí àwon òrò orúkọ lè gba àwon àbọ̀ àwon kan wòfún ni (àwon ọ̀rò ise agbàbò) nígbà mìíràn ó jé wọ̀fún nígbà tí wọ́n bá jẹ́ aláìgbàbọ̀ ṣùgbọ́n tí won bá gbà àwọn àbọ̀ tan, tàbí kí won máà gba àwon ìsomó kankan. 3. eat (NP) kill (NP) drink (NP) [+ liquid]. Àwon ìsomọ́ máa n borí àwon àpólà (tí ó lè jẹ eyọ ọ̀rò kan ṣoṣ̣o) sí àwon àpólà orúkọ̀. Níbí ni a ṣe àpèjúwe ránpẹ́ nípa àwọn Àfikún ọ̀rọ̀ ìṣe sí. 4a: eat ([NP an unripe mango]) b. destroy [NP the termitarium] c. said [s. that [s the NBA examination is canceled]] d. put [x [NP salt] [pp in the soap]] e. saw [NP Mọ́remí]. Àwon ọ̀rò ìse aláìgbàbọ̀ ni a máa fihàn nísàlẹ̀, pélù àwon ìsomọ́. 5a Jòkó sórí ẹní b. Sùn síjòkó èyìn ọ̀kọ̀ d. La àlá e. Kú. Nígbà tí àwon yìí kò gba àwon àfikún, wón lè, nípa ìgba àkànṣe gba àwọn àbọ̀ - àwon àbọ̀ àkànse tí a so mọ wọn tàbí tí a sèdá láti ara won. Wón fẹjọ́ Èsù sọ nínú Bíbélì pé ó n gba Éfà níyànjú láti ma bẹ̀rù nípa jíjẹ èso èèwọ̀, tó wí pé, “Èyin kò ní kú kan”. Èṣù kò nílò àti yí ọ̀rọ̀ ìse aláìgbàbò sí agbàbọ̀ Nitóri pé wọ́n n sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rò orúkọ wọ́n fi àwọn nnkan pamọ́ lórí àwọn irú ọ̀rọ̀ orúkọ (kódà yíyípadà) ní àwọn èdè kan. Èdè Gẹ̀ẹ́ṣì kìí ṣe àpẹẹrẹ tó dára nípa bí ọ̀rọ̀ ìṣe ṣe lè yí ọ̀rọ̀ roúkọ tí a bá wẹ̀yìn, ipa aṣekókó ÒṢÈRẸ́, ÀKỌ́SO, ÈLÒ, abbl wá tààrà tàbí àìṣetààrà láti ara ọ̀rọ̀ ìṣẹ. Fún àpẹẹrẹ alè máà ri sùgbón a mọ̀ pé N kan náà (nítòótọ́ NP) ni ó n kú nínú: 6. Olú pa olè náà Olè náà ni olú pa Àti pé kò sí àníàní, NP kan náà tó fa ikú bó tilẹ̀ jé ̣pé ìtò gẹ́gẹ́ ní àwon olùkópa nínú gbólóhùn méjèèjì wà. Fún bẹ́ẹ̀ Olú ni ÒṢÈRÉ nínú gbólóhùn méjèèjì nígbà tí Olè náà jẹ́ Àkọ́so nínú méjèèjì bákan náà. A lè sọ̀rò nípa àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rò mìíràn, tó yàtọ̀ sí Àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ àti àwọn ọ̀rò ìse, sùgbón ẹ jẹ́ kí á padá séyìn láti wo àwon ìjíròrò wa fún ìbáramu. À n sọ pé ọ̀rò kòòkan, bó jé ọ̀rò orúkọ tàbí òrọ̀ ìse, máa ṇ̣̣̣ wá pẹ̀lú àwọn nnkan. Nínú ìbásepò wọn, àwon òrò náà n sisẹ́ lórí ara wọn to fi jẹ́ pé àwon ọ̀wò kan a gbà àwọn mìíràn yóò sì fún wọn ní àwọn àbùdá kan. Ọ̀rò orúkọ náà, tó máa n jé olùkópa, kìí ṣe ÒSÈRÉ tàbí ÀKÓSO tí òrò kò bá fún wọn ní irú ipa béè. Nínú ọ̀rò – èdè tí ayé (tí a gbé wọnú gírámà) òrò ìse tó n darí àbọ̀ APOR rẹ̀ fún ìdí èyí, ọ́ n fún ní isẹ́ (ní báyìí, Ø role nìkan, àmó ó lè se àyànse àwon àwòmọ́ mìị́ràn). Gẹ́gẹ́ bí olùsọ èdè ṣe nu ìmọ̀ nípa àwọn nnkan wònyí láìkọ́ tí ó sì jẹ pé dandan ni ó n tẹ̀lẹ́ àwọn ofin yìí, ṣe a kò lè sọ pé àwon ọgbọ́n ẹ̀tọ̀ yìí jẹ́ abínibí gẹ́gẹ́ bí mímí ṣe jẹ? 2.4 Àwon ibi gígạ̣̣ ̣ ̣ Ìwọ̀n mìíran nì a ti menu bà tẹ́lè, nípa ọ̀rò náà, ohun náà ní pé kìí jẹyọ ní dídáwà. Olè di Olè náà, ògbójú Olè náà, ògbójú alágbára Olè náà pẹ̀lú ìwo, abbl. Àwon àlèpọ̀ òrò náà sí àwọn ọ̀wọ́ tí ó tóbi pẹ̀lú ìrànlówọ́ àwọn ohun tí a pè ní àwon àpólà. Nítorí pé àárín òrò, òrò gangan tí a bá túnṣe nì yóò dúró fún odidi àpólà, a máa n pé irú won ni Ori. Ni a se máa rí i, òrò orúkọ ní ó máa n jé orí fún Apólà orúkọ (APOR), òrò ìse fún Àpólà ìse (APIS), òrò àpèjúwe fún Àpólà àpèjúwe (APAJ)….,X tàbí Y tún àpólà X (XP) àti àpólà Y (YP) bákan náà. Lẹ́èkan sí, ká wò ó pé olùsọ èka –èdè rè mọ púpò nípa rè. Yorùbá máa mọ̀ mọ̀ pé ọmọ ‘child’ ni a lè tó àwon òrò èpón mọ́ bi i ọmọ kékeré ‘small child’̣, ọmọ baba Ìbàdàn ‘the child of the man from Ìbàdàn’ tàbí ọmọ náà “the child” kò di dandan, àti pé kódà, wọn kò tí ì kọ̀ ní àwon àtòpọ̀ yìí rí. Àti wí pé ọpọlọ tí olùsọ ẹ̀ka–èdè yìí n lo ni a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú gírámà, Akitiyan láti mọ ohun tí ó mọ̀ láì kó. Se kò pani lérìn-ín, olùsọ èka – èdè, tàbí ọmọdé kan n kó àwọn orímò èdá–èdè kò ní ìtumọ̀ sùgbọ́n òótọ́ ni. A ṣe àfiikún àwọn àpólà tí a kó tí olùsọ èka–èdè lè lò pé kò ní ẹ̀kun ó sì peléke. Àwon iní ìhun béẹ̀ lè kún fún àwon èròjà wọ̀fún tí ó wọnú ara won. Sùgbón èyí kéyií tó bá ṣẹlè, àpólà gbọ́dọ̀ ní orí, títèlé àwon ohun tí òfin níní orí gbà, tí a pè ní ‘endocentricity requiremrnt’. Nítorí bẹ́ẹ̀tí a bá ní òrọ̀ kan W, ó gbọ́dọ̀ di W max tí a túpalẹ̀ ní síntáàsì gẹ́gẹ́ bí i WP (for W-Phrase) tàbí W” (W- double prime (=bar)).̣̣
Ìfitónilétí
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3183
3183
Ẹ̀kó Ìjìnlẹ̀ nípa Ìfitónilétí OWOLABANI JAMES AHISU Ẹ̀KÓ ÌJÌNLẸ̀ NÍPA ÌFITÓNILÉTÍ (INFORMATICS) Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí n kọ́ nípa ètò, ìṣesí àti ìbáṣepọ̀ àwọn ìlànà adánidá àti ìfi-ọgbọ́n-se, tó n pamọ́, tó sì n ṣe ìyípàdà àti ìkójọ ìfitónilétí. Bákan náà, ní ó n sẹ̀dá àwọn ìpìnlẹ̀ ajẹmérò àti tíórì tirẹ. Láti ìgbà tí àwọn ẹ̀ro kọ̀mpútà, àwọn aládáni àti àwọn onílé-iṣé nlánlá tí n ṣe ìyípadà àwọn abala àwùjọ. Ní ọdún 1957, Karl Steinbush tó jẹ́ orílẹ̀-èdè Germany, tí ó sì tún jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rọ kọ̀mpútà (1917-2005) kọ ìwé kan tí ó pè ní “Informatik: Automatisdie Informationsverarbeitung”) èyí tó túmọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì sí “Informatics: automatic information processing”) ohun ni a túmọ̀ ní èdè Yorùbá bí Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí: ìlànà ìlò ìfitónilétí tí kò yí padà. Ní òde-òní, “Informatik” ni wọ́n n lò dípo “Computerwissescraft” ni orílẹ̀-èdè Germany èyí tó túmọ̀ sí (Computer Science) ní èdè Gẹ̀ésì, tí ó sì túmọ̀ sí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rò kọ̀mpútà ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa èkọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí. Bákan náà oríṣìírisìí àwọn onímọ̀ ìjìnlè nípa ẹ̀ro kọ̀mpútà láti àwọn orilẹ̀-èdè àgbáyé ni ó fún Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí ní oríkì tiwọn pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ oríkì èyí wá láti orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì nípa ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí: ̣̣ Informatics is the discipline of science which investigates the structure and properties (not specific content) of scientific information, as well as the regularities of scientific information activity, its theory, history, methodology and organization. ̣ Èyí tó túmọ̀ sí: Ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí jẹ́ ẹ̀ka kan lára ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó n wádìí nípa ètò àti àwon àkòónú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìfitónilétí, pẹ̀lú àwọn ìṣedédé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, tí ọ́rì rẹ̀, ìtàn rẹ̀, ogbọ́n-`ikọ́ni àti ètò rẹ̀ pẹ̀lú. Oríṣìíríṣi ni ó ti bá ìlò rẹ̀, ọ̀nà mẹ́ta ni wọ́n ti túmọ̀ rẹ̀ sí. Ìkíní ni pé ìyípadà tó bá ìmò, ìjìnlẹ̀ ìfitónilétí ni wọ́n ti yọ kúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí ti ẹ̀kọ́ ìyìnlẹ́ nípa ìfitónilétí tó jẹmọ́ ètò ọrọ-ajé àti òfin ikejì ní, nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pò nínú àwọn ìfitónilétí yìí ni wọ́n ti n kó pamọ́ nílànà tòde-òní, ìdíyelé tí wá jẹ pàtàkì sí ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nipa ìfitónilétí Ìkéta jẹ́ ìlò àti ìbánisọ̀rọ̀ nípa ìfitónilétí tí a rò pọ̀ láti lò fún ìwádìí, nígbà tí ó jé pé wọ́n ti gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì sí ohun kóhun tó bá jẹ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Fún ìdí èyí ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà ní àgbáyé, wọn kò fọwọ́ yẹpẹre mú ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí àti gbogbo ohun tó so mọ́ ọ ̣̣
Ẹ̀kó Ìjìnlẹ̀ nípa Ìfitónilétí
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3205
3205
Omo Yoruba
Omo Yoruba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3208
3208
Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Sàláwù Ìdáyàt Olúwakẹ́mi ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ bí akò bá sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, a jẹ́ pé à ń rólé apá kan nìyẹn. Báwo ni a ó ò ṣe pé orí ajá tí a kò níí pe orí ìkòkò tí a fi ṣè é? ìmọ̀ sáyáǹsì ló bí ìmọ̀ ẹ̀rọ. Sáyáǹsì ni yóò pèsè irinsé tí ìmọ̀ ẹ̀rọ máa lo láti fi se agbára. Ọ̀nà méjì ló yẹ kí á gbé àlàyé wa kà nígbà tí bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ. (1) Ìmọ̀ ẹ̀rọ àbáláyé (Anciant technology) (2) Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé (Modern technology) ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÀBÁLÁYÉ Ní ìgbà àwọn baba ńlá wa, tí ojú sì wà lórúnkún, ọ̀nà láti wá ojútùú sí ìsòro tó wà láwùjọ bóyá nípa ilẹ́ gbígbé, asọ wíwọ̀ oúnjẹ jíjẹ ló fà á tí àwọn baba ńlá wà fi máa ń lo ìmọ̀ sáyéǹsì tiwańtiwa láti sẹ̀dáa àwọn nǹkan àmúsagbára lásìkò náà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbà náà ló di iṣẹ́ ò òjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ń ṣe lásìkò náà. Ẹ jẹ́ ki á mú lọkọ̀ọ̀kan. Oúnjẹ jíjẹ Yorùbá bọ̀ wọ́n ní: “Ohun tá a jẹ́ làgbà ohun táá ṣe. Wọ́n á tún máa sọ pé bí oúnjẹ bá kúrò nínú ìṣẹ́, ìsẹ́ bùṣe”. Ìdí nìyí tí wọ́n fi wá ohun èlò lati máa ṣe àwọn iṣẹ́ òòjọ́ wọ́n bi Isẹ́ àgbẹ̀. Ìṣẹ́ àgbẹ̀ ni isẹ́ ìlè wà. Àwọn baba ńlá wa máa ń lo oríṣìíríṣìí irin ìṣẹ́ láti wá ohun jíjẹ lára wọn ni àdá, ọkọ́, agbọ̀n, akọ́rọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iṣẹ́ Ọdẹ, Iṣẹ́ ọdẹ jẹ́ iṣẹ́ idabọ fún ìran Yorùbá. Ìdí ni péwu ló jẹ́ nígbà náà. Iṣẹ́ àgbẹ̀ gan an ni ojúlówó iṣẹ́ nígbà náà lára àwọn irin-iṣẹ́ tí àwọn ọdẹ máa ń lo ni, ọkọ́, àdá, ìbon, òògùn àti àwọn yòókù. ASỌ WÍWÒ. Nígbà tí a ba jẹun yó tán, nǹkan tó kù láti ronú nípa rẹ̀ ni bí a oo se bo ìhòhò ara. Èyí ló fà á tí àwọn baba ńlá wa fi dọ́gbọ́n aṣọ híhun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, awọ ẹran ni wọ́n ń dà bora lákòókó náà, ṣùgbọ́n wọn ní ọ̀kánjùá ń dàgbà ọgbọ́n ń rewájú ọgbọ́n tó rewájú ló fàá tí àwọn èèyàn fi dọ́gbọ́ aṣọ hihun lára òwú lóko. Láti ara aṣọ òfì, kíjìpá àti sányán ni aṣọ ìgbàlódé ti bẹ̀rẹ̀ ILÉ GBÍGBÉ. Bí a bá bo àsírí ara tán ó yẹ kí á rántí ibi fẹ̀yìn lélẹ̀ si. Inú ihò (Caves) la gbọ́ pé àwọn ẹni àárọ̀ ń fi orí pamọ́ sí í ṣùgbọ́n bí ìdàgbà sókè ṣe bẹ̀rẹ̀, ni àwọn èèyàn ń dá ọgbọ́n láti ara imọ̀ ọ̀pẹ, koríko àti ewéko láti fi kọ́ ilé. IṢẸ ARỌ́ (ALÁGBẸ̀DẸ) Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ láwùjọ Yorùbá bí a kò mẹ́nu bà isẹ́ alágbẹ̀dẹ, a jẹ́ pé àlàyé wa kò kún tó. Iṣẹ́ arọ́ túmọ̀ sí kí a rọ nǹkan tuntun jáde fún ìwúlò ara wa. ọ̀pọ̀ nínú irinṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tí àwọn àgbẹ̀ ńlò ló jẹ́ pé àwọn alágbẹ̀dẹ́ ló máa ń ṣe e. Irinsẹ́ àwọn ọ̀mọ̀lé, ahunsọ, àwọn alágbẹ̀dẹ ni yóò rọ̀ọ́ jáde. Irinse àwọn ọdẹ, àwọn ọ̀mọ̀lé àwọn alágbẹ̀dẹ ló ń rọ gbogbo rẹ̀. Ìmọ̀ ẹ̀rọ gan-an lọ́dọ̀ àwọn alágbẹ̀dẹ ló ti bẹ̀rẹ̀. Tí a bá ṣe àtúpalẹ̀ Ẹ̀RỌ̣ yóò fún wa ni ẹ - mofiimu àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ rọ - ọ̀rọ̀-ìṣe adádúró ẹ + rọ ---- > ẹrọ. Rírọ́ nǹkan ntun jáde ni èrọ ìmọ̀ sáyéǹsì gẹ́gẹ́ bí ń ṣe sọ ṣáájú ló bí ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ó yẹ kí á fi kun un pé, ọpọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ ti sún síwájú báyìí. Ìdí èyí ni pé ìmọ̀ ẹ̀rọ to ti ọ̀dọ̀ àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun wá ti gbalégboko. Àwọn ọ̀nà tí a ń gbà pèsè nǹkan rírọ ti yàtò báyìí. ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ Lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀làjú wọ agbo ilẹ́ Yorùbá ni ọ̀nà tí a ń gba ṣe nǹkan tó yàtọ̀. Ìmọ̀ ẹrọ àtòhúnrìnwá tí mú àyè rọrùn fún tilétoko. Ṣùgbọn ó yẹ kí á rántí pé ki àgbàdo tóó dáyé ohun kan ni adìyẹ ń jẹ. Àwọn nǹkan tí adìẹ ń jẹ náà lati ṣàlàyé nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ àbáláyé. Iṣu ló parade tó diyán, àgbàdo parade ó di ẹ̀kọ. Ìlosíwájú ti dé bá imọ̀ ẹ̀rọ láwùjọ wa. Ẹ jẹ́ kí á wo ìlé kíkọ́ àwọn ohun èlò ìgbàlódé ti wà tí a le fi kọ́ ilé alájàmẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ. Ìmọ̀ ẹ̀rọ náà ló fáà tí àwọn mọ́tọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fi dáyé. Àwọn nǹkan amáyédẹrun gbogbo ni ó ti wà. Ẹ̀rọ móhùnmáwòrán, asọ̀rọ̀mágbèsì, ẹ̀rọ tí ń fẹ́ atẹgun (Fan), ẹ̀rọ to n fẹ́ tútù fẹ́ gbígbóná (air condition) Àpẹẹrẹ mìíràn ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, alagbeeka, ẹ̀rọ kòmpútà, ẹ̀rọ alukálélukako (Internet). Gbogbo àwọn àpẹẹrẹ yìí ni ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé tíì máyé dẹrùn fún mùtúmùwà. Àwọn àléébù ti wọn náà wa, ṣùgbọ́n iṣẹ́ àti ìwúlò wọn kò kéré rárá.
Ìmọ̀ Ẹ̀rọ
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3217
3217
Oduduwa Odùduwà jẹ́ aláṣẹ àti olùdarí ìran Yorùbá, òun tún ni gbòngbò kan pàtàkì tí ó so ilẹ̀ Yorùbá ró láti Ife, títí dé ibi k'íbi tí wọ́n bá ti ń jẹ Ọba káàkàkiri ilẹ̀ Káàrọ̀ -oò -jíire pátá. Lára ìtàn tó fẹsẹ̀ Odùduwà múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọni ìgbà ìwáṣẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá sọ wípé ó jẹ́ ọmọ ọba ti ilẹ̀ Lárúbáwá tí wọ́n f'ogun lé kúrò nílùú baba rẹ̀ nílẹ̀ Mẹ́kà tí ó wá di Saudi Arabia lónìí. Látàrí ogun yìí ló jẹ́ kí ó gbéra ọ́un àti àwón ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ̀n sì fi tẹ̀dó sí ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà títí di òní. Títẹ̀dó rẹ̀ náà kìí ṣe pẹ̀lú ìrọ̀wọ́-rọsẹ̀, bí kọ́ ṣe ogun tó gbóná janjan fún bí ọdún púpọ̀ kí ó tó borí àwọn ẹ̀yà mẹ́tàlá kan tí ó bá ní Ifẹ̀ tí Ọbàtálá jẹ̀ adarí fún, tí ó sì sọ ìlú náà di Ìlú kan ṣoṣo tí ó sì wà ní abẹ́ ìṣàkóso Ọba kan ṣoṣo. Ó gba àwọn ìnagijẹ bí : "Ọlòfin Àdìmúlà," "Ọlòfin Ayé" àti "Olúfẹ̀". Àwọn elédè Yorùbá ma ń pe Orúkọ rẹ̀ báwọ̀nyí: Odùduwà , tì wọ́n sì tún le dàá pè báyìí:" Oòdua" tàbì "Oòduwà" tàbí "Odùduà" nígbà míràn ni ó ń tọ́ka sí akọni náà, tí ó sì ń fi pàtàkì àwọn ilẹ̀ Yorùbá hàn pàápàà jùlọ àwọn Ọba Aládé gẹ́gẹ́ bí àrólé, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni iyì àti àpọnlé. Ohun tì Odùduwà túmọ̀ sí. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Odùduwà ó kúrò láyé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbrẹ̀ ni wọ́n tinfún ká orílẹ̀ kúrò ní Ifẹ̀, tí wọ́n sìbti lààmì -laaka kákiri ìletò tiiwọn nàà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni wọ́n ti dá ìjọba tiwón náà kalẹ̀ nílú tí àwọn náàbtẹ̀dó sí gẹ́gẹ bí Ọba, tí wọ́n sì ń fi yé àwọn ọmọ tiwọn náà wípé Ile-Ife ni àwọn ti wá Ọ́rúntó tí ó jẹ́ ọmọ tí ọ̀kan lára àwọn èrú Odùduwà bí fun ni ó jẹ́ ìyá-ńlá àwọn tí wọ́n ń joyè Ọbalúfẹ̀ tí ó jẹ́ oyè igbá-kejì sí oyè Ọọ̀ni ní Ilé-Ifẹ̀ títí dòní Ọbalùfọ̀n Aláyémore ni ó wà ní orí ìrẹ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn ti ìrìn-àjò dé, tí ó sì pàṣẹ pé kí Ọbalùfọ̀n ó kúrò lórí àpèrè kí òhn sì bọ́ síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ọmọ Odùduwà tí ó lẹ̀tọ̀ọ́ sóróyè baba rẹ̀. Lẹ́yìn Làjàmìsà tí ó jé ọmọ Ọ̀rànmíyàn bi ó ni àwọn ọmọ rẹ̀ ń jẹ Ọọ̀ni nílé-Ifẹ̀ títí dòní. Lápá kan, wọ́n ní ìtàn fiyeni wípé Odùduwà jẹ́ oníṣẹ́ láti ìlú Òkè-Ọrà ìlú tí ó wà ní apá ìlà -Oòrùn é-Ifẹ̀. Wọ́n ní ó rọ̀ láti orí òkè kan pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n, ní èyí tó mú kí wọ́n ma kìí wípé: "Oòduà Ayẹ̀wọ̀nrọ̀" tí ó túmọ̀ sí ( 'one who descends on a chain'). Abala ìtàn yí fi yéwa wípé jagun jagun ni Odùduwà jẹ́ pẹ̀lú bí ó ṣe wọ̀ éwù ogun onírin .Lásìkò tí ó wọ Ilé-Ifẹ̀ wá, àjọṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn wà láàrín àwọn olùgbé ìran mẹ́tàlá(13) Ifẹ̀, tí ìlú kọọ̀kan sì ní Ọba tirẹ̀ bí Ọba Ìjùgbé, Ìwínrín, Ijió, Ìwínrín àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí Odùduwà di aláṣẹ́ Ilé-Ifẹ̀ tán, òun àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ sapá tí wọ́n sì gba àwọn ìlú àti agbègbè mẹ́tàlá tí a mẹ́nu bà wọ̀nyí, tí wọ́n sì ṣí Obatala, nípò gẹ́gẹ́ bí olórí tí wọ́n sì gbé ìjọba titun kalẹ̀ pẹ̀lú ẹtò ìṣèlú tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Látàrí ìdí èyí, ni wọ́n fi ń pèé ní Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó mú ètò àti ìlànà ìṣèjọba aládé wọ ilẹ̀Yorùbá Ìran Òwu gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà. Àkọ́bí Odùduwà tí orúkọ rẹ́ ń jẹ́ Ọ̀kànbí Iyùnadé, ni ó fẹ́ Obatala tí ó sì bí ẹbi tí ó jẹ Olówu àkọ́kọ́. Ìtàn fiblélẹ̀ wìpé Olówu àkọ́kọ́ yìí ni ó ti gorí ìtẹ́ látìgbà tí ó ti wàní òpóǹló. Ìran Alákétu gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà. Ọ̀kan lára àwọn ìyàwó Odùduwà tí ó jẹ́ ààyò tí orúkọ rẹ̀ ǹ jẹ́ Ọmọnidẹ, ni ó bí Sopasan, ẹni tí ó bí ọba Alákétu Sopasan was the first to leave Ile-Ife with his mother and crown. He settled at such temporary sites as Oke-Oyan and Aro. At Aro, Soposan died and was succeeded by Owe. The migrants stayed for a number of generations and broke camp in the reign of the seventh king, Ede, who revived the westward migrations and founded a dynasty at Ketu. Oduduwa and the line of Òràngún. Ajagunlà Fágbàmílà Ọ̀ràngún, tí a lè pè ní ojúlówó ọmó Odùduwà ni ó jẹ́ Ọ̀ràngún ilé Ilé-Ìlála. Odùduwà ni a gbọ́ wípé ó fẹ́ láti bí ọmọ yanturu kí ó lè dẹ́kun àhesọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ifa oracle, he went to a stream, where he found a naked lady by the name of Adetinrin Anasin. She eventually became his wife and the mother of Ifagbamila (which means "Ifa saves me") Ìran Aláàfin ẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà. Ọ̀rànmíyàn ni ó tẹ ìlú Ọyọ́-Ilé dó. Lẹ́yìn tí lára àwọn ọmọ rẹ̀ Àjàká àti Ṣàngó náà darí ìjọba Ọ̀yọ́ lẹ́yìn baba wọn. Ọ̀rànmíyàn. Ọ̀rànmíyàn tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn àwọn ọmọ Odùduwà ni onírìn-àjò jùlọ láàrí àwọn ọmọ bàbá rẹ̀ jùlọ. Òni ẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ jẹ He was the first Ọba ilẹ̀ Ìbìní tí ó sì tún jẹ́ ỌbaAláàfin ti Ìlú Ọ̀yọ́, bákan náàni òun ni Ọba Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ ẹlẹ́kefà nínú ètò. Mọ́remì àti àwọn Ùgbò. Lẹ́yìn tí àwọmọ Odùduwà gbogbo ti túká kúrò ní Ifẹ̀ láti lọ dá ìlú àti ìletò tiwọ̀n sílẹ̀, ó ṣòro láti tukọ̀ ìlú náà fún olórí tó wà níbẹ̀ nígbà náà, fúndìí èyí, àwọn ìpèníjà oríṣiríṣi ni ó dojú kọ Ilé-Ifẹ̀ lásìkò yí. Àwọn ẹmẹ̀wà Ọbàtálá tí ó jẹ́ ẹni tó ti darí Ifẹ̀ ṣáájú Odùduwà ni a gbọ́ wíoé wọ́n sọra wọn di agbọ́n onígàn oró tí wọ́n sì ń gbẹẹ̀mí àwọn ènìyàn lọ́nà àìtọ́, léte àti gbẹ̀san gbígba agbára tí Odùduwà gba agbára lọ́wọ́ Obàtálá. Wọn yóò múra gẹ́gẹ́ bí Th àlùjọ̀nú nígbà tí wọn yóò wọ àwọn kiníkan tó dàbí ewé, lọ́nà tí hóò dẹ́rù ba àwọn ènìyàn gidigidi, wọn yóò ma dáná sunlé tí wọn yóò ja àwọn ọlọ́jà lólẹ láàrín ọjà. Lásìkò yí ni ọmọba bìnrin Mọ́remí Ajasoro, tí ó jẹ́ ọmọba bìnrin ní ìlú Ọ̀fà, tì ó wá láti ìran Ọlálọmí Ọlọ́fà gangan, tí ó jẹ́ ẹni tì ó tẹ Ìlú Ọ̀fà dó tí ó sìbtún jẹ́ adarí pàtàkì fún Ìbọ̀lọ́ ní ìlú Ọ̀yọ́, tí ó sì tún jẹ́ ìbátan Ọ̀rànmíyàn ni a gbọ́ wílé ó dá sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó sì sapá gidi láti pẹ̀tù sí wàhálà náà níoa ṣíṣe alamí àwọn níṣẹ́ búburú náà. Ó fara rẹ̀ sílẹ̀ láti jẹ̀ kí wọ́n fipá kó ọòun lẹ́rú. Nínú ìgbèkùn ẹrú rẹ̀ ni Ọba àwọn Ùgbò náà ti fẹ láti fi ṣaya. Ọba náà gbìyànjú láti ba múfẹ̀ẹ́ lẹyìn tí ó fẹ ytan ṣùgbọ́n Mọ́remí kọ̀ jálẹ̀ ní torí ó ti ládé orí tẹ́lẹ̀, àti wípé iṣẹ́ alamí ló wá ṣe kìí ṣe ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ló kàn. Ó ní bí Ọba náà bá le dọ ìdí abájọ àwọn amòòkùn-sìkà náà fún òun, kíá ni òun yóò gbà fun lát lájọṣepọ̀. Ọba náà kọọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ẹyí, ṣùgbọ́n ó ṣe ìfẹ́ inú Mọ́remi tí ó sì tú àṣírí náà si lọ́wọ́. Ó sọ fún Mọ́remí wí wípé ohun tí àwọn kórìíra jùlọ nígbà tí àwọn bá ti múra bí àlùjọ̀nnú náà bi iná, nítorí iná nìkan ló lè tú wọ́n láṣìírì, bí wọ́n bá sì ríná, àwọn yóọò sá lọ. Lẹ́yìn tí Mọ́remí ti gnọ́ àṣírí yìí tán ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ń dọ́gbọ́n ọ̀nà tí yóò gbà sákúrò níbẹ̀. OnÓ ní kí wọ́n bá òun wá ọsàn tó pọ́ tí ó sì fi ṣe oògùn orun fún gbogbo àwọn olùgbé Ààfin náà. Lẹ́yìn tí wọ́n jí ni wọ́n ri wípé Mọ́eemí ti na pápà bora tí ó sì ti lọ tú àṣírí àwọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Báyìí ni àwọn Ifẹ̀ ṣe múra sílẹ̀ fún àÙgbọ́ lá ti bá wọn bami ìjà wò. Tí wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Àwọn àríwòye mìíràn nípa Ofùduwà. Ipa tí Odùduwà kó nínú ìṣẹ̀dáyé. Àwọb ìtàn ìbílẹ̀ kam di múlẹ̀ wípé Odùduqà jẹ́ ọkan lára àwọn Orisa tí Elédùmarè dẹẹ́ràn jùlọ nígbà ìwáṣẹ̀. Àwọn ìtàn wọ̀yí fi múlẹ̀ wípé Odùduwà ni Elédùmarè rán wá sáyé láti wádá ayé sorí ẹ̀kún omi. Iṣẹ yìí ni a gbọ́ wípé Ọbàtálá kùnà láti jẹ́ lẹ́ni tí a ti fún ní ìkarahun ìgbín, iyẹ̀pẹ̀, àti igi tíyóò fi tàn án ká fún iṣẹ́ pàtàkì náà. Ìtàn yí ni àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Yorùbá gbàgbọ́ tí wọ́n sì fi ṣe ọ̀pákútẹ̀lẹ̀ ì)àgbọ́ wọn nípa ìṣẹ̀dá ayé. Wọ́n ma ń fi igbá àti ṣe àmì Ọbàtálá àti Odùduwà nígbà tí ọnọrí igbá ń rọ́pò Ọbàtálá tí ìyá igbá sì ń dúró fún Odùduwà gẹ́gẹ́ bíese "Ọlọ́fin Ọ̀yẹ́tẹ" tí ó túmọ̀ sí ẹni tí gba igbá ìyè lọ̀dọ̀ Elédùmarè.
Oduduwa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3233
3233
Ojú tí Ifá fi n Wọ́ Obìnrin Ifá jẹ òrìṣà kan pàtàkì láàárín àwọn Yorùbá àwọn Yorúbà gbàgbọ́ wípé Olodumare lo ran ifá wa láti Ode Ọrun láti wa fi Ọgbọ́n rẹ̀ tún ilé ayé se. Ọgbọ́n ìmọ̀ àti Òye tí Olódùmarè fi fún ifá ló fun ifá ní ipò ńlá láàárín àwọn ìbọ ilẹ Yorùbá ….”a kéré-finú-sọgbọ́n”ni oríki ifá. Eleyi lo fi han wa gẹ́gẹ́ bí Abimbọla (1969) ti gbe kala. Nínú isẹ́ àgbékalẹ̀ Ilesanmi ó wa jẹ ki a mọ wípé ifá ni alárínà fún gbogbo ọmọ Oodua oun ni ó dabi agbenuṣọ fún gbogbo àwọn òrìṣà àti Olódùmarè ohùn ṣì la kà ṣí ẹni to ń ṣe àjèwò fún gbogbo mùtúmùwà. Èyí wa fún ni ibò asojú fún gbogbo àwọn Irúnmọlẹ̀ yòókù. Aroko leti ọpọn ifa 1998. Ifa jẹ ẹwi tí ó máà ń lọ láti ilú kan ṣì èkejì láti dífá. Èyí lo ṣe okùnfa bíbá ọ̀pọ̀ obìnrin pàdé ó ṣI fun ni àǹfáàní láti fẹ ìyàwó púpọ̀ torí irúfẹ́ isé ti ifá ń ṣe. Èyí sí lo fa to fi ṣeṣe fún ifá láti mọ ìwà wọn ó wú oniruuru ìwà yìí jáde torí àjọsepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Obìnrin. Ó maa ń ṣawo kiri ní. Gbogbo ibi tí ifá ba ti dé lo ti ń yan ìyàwó, èyí lo mu ifá rí àríṣá àwọn Obìnrín. Obìnrín ní a le pè ni ìdàkejì Ọkùnrin tí a ba wo Tíórì Àbùdá onibeji fún àgbéyèwò lítíréṣọ̀ ifá tí Ilésamí pàjúbà rẹ Tíórì yìí nì ó jẹ kí á mọ pé laisi ọ̀tún osi ko le dádúró. Erongba opilẹkọ yìí ni láti tàn ìmọ́lẹ̀ ṣí ipò tí ifá fi àwọn Obìnrin ṣi Àkíyèsí àwọn ipò wọ̀nyí si han nínú àwọn ẹsẹ ifá. Ojú méjì Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ifá fi wo àwọn Obìnrin (i) Ó rí wọn gẹ́gẹ́ bi ẹni réré ti ko ṣe maniyen to lẹ́wà. (ii) Ifá rì àwọn obìnrin ní ìdàkejì gẹ́gẹ́ bi èsù tàbí olubi ẹ̀dá. Ṣebí tibi tirẹ la dálé ayé. Bẹ́ẹ̀ ṣI ni a kìí dára ka ma kù ṣíbì kan. Àwọn òbinrin la ba máà pè ní ejò gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ ifá. Nítorí ìdí èyí ifá rọ àwọn ọkùnrin láti gbọ́n nínú gbọ́n lode tí ọ̀rọ̀ ba ti di ọ̀rọ̀ obìnrin. OBÌNRIN GẸ́GẸ́ BÌÍ KÒṢÉÉMÀNÍ TÀBÍ ẸNI RERE Nínú ìpín yìí ifá bẹ̀rẹ̀ ṣí ni ṣe àfihàn wọ́n láti òde pé wọ́n tẹwà ó ṣi rí obìnrin gẹ́gẹ́ bi ẹni rere. Ẹwà wọn ṣI maa ń jẹyọ nínú àwọ̀ tí Olódùmarè fit a wọn lọ́rẹ àto ọmu ti ó fi ṣe àfikún ẹwà wọn. Omú tàbí ọyàn obìnrin ní iyì rẹ̀ ohun ṣi ni onfa to ń fa àwọn ọkùnrin to si ààbí èmú to ń mu wọn mọ́lè lára obìnrin òdí méjì, ìjìnlẹ̀ ohun Eleu ifá Apa kinni pg 54-1-3 fìdí èyí mílẹ̀ pé Funfun niyì eyin Egun gadaaga niyi orun Omu sìkì siki niyi obinrin Omu sikisiki niyi obinrin pg 54 1-4 Ohun iyi àti àmúyẹra ní fún ọkọ rẹ bi èyin odi meji Obinrin ba funfun. Bakannaa ni ifá tún fi ye wa pe ki obinrin lómú kọ lopin ẹwa. Ṣùgbọ́n ìmọ́tótó náà tún se pàtàkì láti le e perí ọkùnrin wale ìjìnlẹ̀ ohùn enu ifá láti ọwọ Wade Abimbọla Apa kini pg 51-25-26. Síyínka Súnyinka Baláfúnjú ba ji a sìnyìnká sóko pg. 51 25-26. A ko gbọ́dọ̀ gbàgbé wipe ara ẹwà ita ti òrúnmìlà ri lára Àwòrán ní ó fig be e ni ìyàwó. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pe bi àwòrán tí jọju to ko ìwà àrokò ti ifa ń fi èyí pa ní pe ẹwà kii se ogbo nìkan. Bi a ti ń wo ẹwà ifa ni ó yẹ ki a naa wo ti inú. Ifá wo ẹwà inú àwọn obìnrin ni oríṣìírìṣí ọ̀nà Aabo jẹ ìrànlọ́wọ́ fún òrúnmìlà nigba to lalèjo mẹta Iku, Àrùn àti Èsù. Ààbò lo ko nǹkan ìlò ọkọ rẹ lo ta ni ọjà Ejigbomekan ní owó pọ́ọ́kú ó ra ounjẹ wọn ṣi tójú àwọn àlejò wọn. Ìwa ti Ààbò wù yìí mu kí àwọn àlejò mẹ́ẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí fì ifá sílẹ̀ laipa. Wọn fún Ọ̀rúnmìlà ní ẹ̀bùn ki wọn ó to fí ilé rẹ̀ ṣílẹ̀. Inú Ọ̀rúnmìlà dun nítorí ìwà Ààbò àti ori re tí ó ko ran-an. Èyí ṣi mu kì Òrùnmìlà fẹran Ààbò. Òdá Owo awo kóro Ààbò Obìnrin rẹ̀ - pg 20 1-2 Ifá ó ṣI ní Oọkan a a yọ na Ní Òrúnmìlà ba pé Ààbò obìnrin rẹ̀ pé kí ó kó àwọn nǹkan ìní òun lọ sọ́jà lọ tà. Ìjìnlẹ̀ ohun Ẹnu ifa iwe kinni Ifa fẹ ìwà náà gẹ́gẹ́ bí aya Ọ̀lẹ àti ọ̀bùn ayé ní ìwà jẹ. Èyí mí ki ọ̀rúnmìlà le e lọ ki lọ ṣi nǹkan ò ba gún régé mọ́ àwọn ènìyàn ṣá lọ́dọ̀ rẹ. Àpọ́nlé kò si fún ọ̀rúnmìlà mọ bìí ti tẹ́lẹ̀ ṣebi ko kuku ṣí àpọ́nlé fún ọba tí kò ní olorì. Ká mú rágbá Ká fi ta rágbá Ka mu ràgbà Ka fit a ràgbà Iwa la n wa o, ìwà Alara ó ri ìwà fun mi Ìwà la ń wa o ìwà… Ìwà ni o jẹ gẹ́gẹ́ bí orison áàsikí fún Ọ̀rùnmìlà ṣùgbọ́n ko mọ iyì ìwà àfi ìgbà tí ìwà fi ilé Ọ̀rúnmìlà sílẹ̀. Ẹ̀mí náà jẹ ọkan lára obìnrin ọ̀rúnmìlà. Ifá fi ẹ̀mí hàn gẹ́gẹ́ bi ọ̀pọ́múléró. Ìdí nìyí tí Ọ̀rúnmìlà fí gbé ẹ̀mí ni ìyàwó ko ba le ṣe rere láyé. Á gbọ́dọ̀ mò wípé ẹmi ní ó gbé ìwá ró. LaiṣI èmí ko si àrà tí ènìyàn le da láyé. Aadogun, aadogbọn, ọwọ́ èmí ni gbogbo rẹ wa. Àwọn Yorùbá ṣì gbàgbọ́ wípé ẹ̀mí gígún ni ṣan ìyà Ọ̀rúnmìlà ko le gbàgbé ẹmí nítorí ohun rere ti ẹ̀mí fún Ọ̀rúnmìlà ní ànfààní láti ṣe. Ire gbogbo tí ẹ̀dá ń wa kiri ọwọ́ èmí ní gbogbo rẹ wa. Fun àpẹẹrẹ:- A dia fun Ọ̀rúnmìlà Níjọ́ to ń lọ r’ẹmi ọmọ Olódùmarè s’Obinrin Ó ní àṣé bẹmi ò ba bọ́ Owo ń bẹ Hin hin owo ni bẹ Àṣà bemi o ba bọ̣ Aya ń bẹ Hin hin aya ń bẹ Àsé bẹmi ò bá bọ́ Ọmọ n bẹ Hin hin ọmọ ń bẹ Aṣe bẹmi ò bá bọ̀ Ire gbogbo ń bẹ Hin hin ire gbogbo n bẹ … Wande Abimbọla Ìjìnlẹ̀ ohùn ẹnu ifá Pg 16 (Eji ogbè). Apa kinni Odù náà jẹ ọken nínú àwọn ìyàwó ọ̀rúnmìlà tí o ko orire ràn án. Alátìlẹyìn ni odù jẹ fún Ọ̀rúnmìlà. O dìgbà tọmọ èkọ́sẹ́ ifa ba to fojú ba odù ko to dẹni ara rẹ. Èyí túmọ̀ ṣi pé babaláwo tí kò ba fojú bodù kò tii dangajia. Ẹni bá fojú bodù Yoo ṣi dawo A fojú bodù a rire OBÌNRIN GẸ́GẸ́ BI OLUBI Àbùdá kejì yìí ní yóò tu tìfun tèdọ̀ ihà kejì tí ifá kọ ṣi àwọn obinrin. Ifá ri àwọn Obinrin gẹ́gẹ́ bi ẹni ibi, alásejù, òjòwú àti àjẹ́. Ó fi ìhà yìí hàn tori pe a kìí dara ka ma kù ṣibi kan. Ifá fi wọn wé aláigbọràn ewúrẹ́ tí wọ́n máà ń ṣe àtojúbọ̀ àwọn ohùn tí ko kàn wọ́n. Bi àpẹẹrẹ Yemòó fẹ mọ ìdí agbára Óòsáála ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú èdó tí ó fi ń pa ẹran ohun tójú tíle-túle alaigbọran ń ri ní ojú rẹ rí lọjọ yìí. Òrúnmìlà ṣọ fún àwọn ìyàwó yòókù láti mase yojú wo ọ̀rọ̀mòdìmọ̀dì obìnrin rẹ̀ tuntun. Ìyáálé pé àwọn yòókù láti lọ yojú wo ìyàwó tuntun yìí inú bí ìyàwó tuntu, o si jade. Ó sì fi wọn rẹ́ bayí ni Àjàkálẹ̀ àrùn ṣi wọle tọ wọn. A ko le fí gbogbo ara da ìyaálé àti àwọn ìyàwó yòókù lẹ́bi torí Ọ̀rúnmìlà ti yẹ kì ó fi ìyàwó tuntun han àwọn to ba ní ilé ṣùgbọ́n ó kọ̀ ko ṣe èyí nípa ojú tí ọ̀rúnmìlà fí wo Obìnrin tí a le ṣọ pe Ọ̀rúnmìlà lo fí owọ́ ara rẹ da ilé ara rẹ̀ ru. Ẹni ba wa wàhálà dandan ni ki ori i. Ifá tun fí àwọn obinrin hàn gẹ́gẹ́ bí òjòwú, ti wọn kìí fẹ ki ọkọ wọn fẹ ìyàwó mìíràn le wọn àfi àwọn nìkan. Fún àpẹẹrẹ: Ọ̀kan ṣoṣo péré lobìnrin Dùn mọ lọ́wọ́ ọkọ Bí wọn ba di méjì wọn a dòjòwú Bí wọn ba di mẹta Wọn a dẹta ń túlé Bí wọn bad è mẹrin Wọn a dí iwọ̀ lo rín mi ni mo rin ọ Bi wọn ba dí marun Wọn a di lágbájá ni ó run ọkọ Wa tan lóhùn ṣuṣuusu Bì wọ́n ba dí mẹ́fà Wọn a dìkà Bi wọ́n ba de meje Wọn a d’àjẹ́ Bí wọ́n ba di mẹjọ Wọ́n a di ìyá alátàrí bàmbà… Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá Apá Kìínní pg 29-43 (Òyèkú meji) Wande Abimbọla Ohun tí o jẹ ìjọjú ní wípé Ifá gan-an mọ pé ó sàn fún ọkùnrin láti fẹ ìyàwó kan. Ẹ̀sẹ̀ amọmọda ni èyí ko yẹ ki Ifá maa fẹ ìyàwó lórí ara wọn. Eke àti Ọ̀dàlẹ̀ ni Ifá tún pe àwọn obìnrin. Ohùn tí Ifa ń ṣọ níbí ni pe Obìnrin ko ṣe fi inú hàn ṣùgbọ́n ibeere tí a ba bi Ifá ni pe ṣe ọkúnrin ni o se fi inú hàn. Bi o ti wa ni lìkì ni ó wa ni gbanja Obinrin leke Obinrin lodalẹ Keniyan se pẹlẹ Ki o ma finu han f’oobinrin Ifá tẹ síwájú nìpa pipe àwọn obìnrin ni dọ́kodọ́kọ àti alágbèrè. Èro ifá ni pé àlè yiyan yìí kii jẹ ki wọn tonu lọpọ igba pe ẹni to ba keré sọkọ ni wọn maa ń ba dálè. Àgbìgbọ̀niwọ̀nràn, The unfaithful Ifá priest You have been seeing bad things, Worse things are yet to come; Worse things the father of bad things Ifa divination was performed for Agbigboniworan Who was going to the house of Onkoromebi to perform divination Onikoromebi, husband of an adulterous wife It was because of the incessant adultery Of his wife that oniworonebi Performed divination Igba ti o fìyà jẹ obinrin naa tan O gbe ju, agbala O ṣi de e lokun mọ́lẹ̀ Ni àgbàlá ni onikoromebi fi ìyàwó rẹ ṣI Ti o fì lọ bìfa léèrè Àgbìgbò ní ki Onikoromebi o ṣe ṣùúrù O ní ẹni tí o torii rẹ bi ifa léèré Mbẹ loride nínú àgbàlá Igba ti onikoromebi gbọ Oju ti i Ko lee lo tu ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ mọ Ó ní ki Àgbìgbò o lọ ba òun tu u sílẹ̀ Ìgbà tí Agbìgbo débẹ̀ Dípò ki o tu obìnrin náà sílẹ̀ fefẹ ni ń fẹ ẹ…. (Ifa Divination Poetry pg 87-88) Nígba tí ìyàwó onikoromebi náà yan babalawo ti wọn ni ko ba wọn wo aiṣan agbere lara rẹ. Ṣùgbọ́n ojọ yìí ní ibi wọn wolẹ nítorí bibẹ ní oníkòròmebi bẹ àwọn mejeeji. Babalawo tì wọn ni ko wo aya onikoromebi ko ni ètọ́ lati ṣe èyí. Bí wọ́n ba pe obìnrin ni dokọdọkọ. Obìnrin ko le da ọkọ dó laì ri ọkunrin. Fi obìnrin é yálẹ̀ yàlè alainisuru a ri eleyi nínú Sixteen great poems of Ifa Not long again. They sent for Ọ̀rúnmìlà in the abode of Olokun when Ọ̀rúnmìlà was going he did not take Ọ̀rọ̀ his wife along he promised to return on the seventeenth day. He gave sixteen ọ̀ké measures of cowries to ọ̀rọ̀. He also gave her clothes and plenty of food in the third month that Ọ̀rúmìlà had stayed away. For Example: Ọ̀rọ̀ met Ońdàáró They agreed to be Concubines Ondaaro gave her five oke measures Of cowries He cohabited with her, And he became pregnant. Ọ̀rọ̀ met onigoosun After they had talked together Onìgoosun gave her ten Okẹ measures Of cowries And cohabited with her And again she became pregnant Not long again ọ̀rọ̀ met a man named Olúùkọ́ọlọ́ He gave har tiventy okẹ measures of cowries after they hed fun with each other ọ̀rọ̀ became pregnant again. All together the children of Ọ̀rọ̀ thus became six and they were all boys out of the six children three were children of Concubines. Nínú ẹsẹ̀ Ifá yìí fi hàn wá wípé Owo l’obinrin mọ̀ gbogbo àwọn mẹtẹẹta to ba dálè yìí owó ní wọn fi hàn ọ̀rọ̀. Aritẹnimọọ wi, a fi apadi fẹnfẹ bo tirẹ̀ mọ́lẹ̀ ni Ifá ibeere ti a ba bi ọ̀rúnmìlà nip e ṣe ko ba obinrin kankan ni àjọsepọ̀ ni ìrìn àjò rẹ. Ko ṣi ẹni to mọ iye ọmọ ti o`hun na bi si àjò. The Sixteen Great Poems of Ifa pg 216-221 Wande Abimbọla Ifá rí obinrin han gẹ́gẹ́ bi àjẹ́ Fun àpẹẹrẹ: Bẹ́ẹ̀ ba gbolagbalagba epo òun ewùso Ẹ lo lee ko fún ìyàmi Òsòròngà Apa nimawaagun, Olokiki Orù Ajẹdọ-tútù-mọ-bi Obinrin kukuru regiregi (The 16 Great Poems of Ifa pg 242 Wande Abimbọla) Àwọn obìnrin náà ni Ifá tún fihàn bí aforesunu se. Wọn fore ṣu Ọ̀rúnmìlà nílé ayé pé àwọn o ni sọ̀kalẹ̀ ní ikùn rẹ mọ́ àfìgbà to ba rúbọ. Wọn ní kí ní ń jẹ sisọ kale Wọn ni a tun ṣòkalẹ̀ mọ́ Ọ̀rúnmìlà ti mọ Oko ni oko ikun to gbin èpà síbẹ̀. O mọ pé ìhòhò ní àwọn ẹlẹyẹ wa ko to gbà láti ṣe wọn ní àánú. Kìí ṣe Ọ̀rúnmìlà nikan ní àwọn ẹlẹyẹ bẹ. Ọ̀rúnmìlà tí gbàgbé pe bí ojo oore ba pé asiwèrè a gbàgbé àti pé ìwọ̀n ní oore. Aláwomọ́ àti alakooba ní wọn gẹ́gẹ́ bi ìwà ti ìyá arúgbó tí a fi se àpẹẹrẹ nínú òyèkú méjì wù. Nígbà to fọ̀rọ̀ isú lọ ẹnikan ti ko gba a jẹ o fi ọwọ epo sàmì sìi lára. Ebi kii ṣe ebi ẹni to fi ọwọ́ epo to ọ ni lẹkẹ ẹni to rin ìrìn ìwàsà o di dandan kan fi èkùrọ́ lọ o Fun àpẹẹrẹ: Ó mú ọwọ epo Ó fi to mi lẹ́ẹ̀kẹ́ẹ mi ọ̀tún itọrorọ itọrọrọ Ó mú ọwọ epo Ó fi to mi leẹkẹ mi òsì itọ̀rọ̀rọ̀ itọ̀rọ̀rọ̀ Ìjìnlẹ̀ ohùn ẹnú ifá pg 29-107-110 Òyèkú meji Wande Abimbọla Ifá tún jẹ ka mọ pé ìkà àti òfinràn ni wọn. Nínú méjì Yemoo ìyàwó oriṣà ńlá lo ji omi àwọn ẹlẹyẹ pọn to ṣo tun fọ asọ òdé rẹ ṣínú odò náà The witches asked, Did She stab herself and Èlúlù Replied she did not Stab herself, the blood was From her private part (The 16 Great poem ifá) The witches therefore swallowed both the husband and the wife. Álásejù baba àsetẹ́ tún ní ifá fẹ wọn ohun ti wọn ṣe náà nìyí tí ó je ki nǹkan bọ́tí mọ wọn lọ́wọ́. Wọn kí àsejù bọ ọ̀rọ̀ wọn. Fun àpẹẹrẹ : Igbó etílé t’oun tẹgbin Adapọ owó toun tiyà Iwo o ju mi Ẹmi o ju ọ Lara ile ẹni fi ń fojú di ni Ifá jẹ ka mọ wípé Olódùmarè yan òrìṣà mẹrindinlogun ó fi òbìnrin kan ṣi wípé ki wọ́n maa lọ silẹ́ aye láti maa lọ rúbọ fún àwọn ẹ̀mí airí. Nígbà tí wọn dé ilé ayé ọsun tí ó jẹ obìnrin àárín wọn ní ó maa ń ṣe ìpèsè fún àwọn ẹ̀mí airi yìí. Ní gbobgo ìgbà tí wọn bat i n lọ gbe ẹbọ yìí lọ fún àwọn ẹmí airi yìí oṣun kìí tẹ̀lẹ́ wọn, ti wọn ba ti de ibẹ̀ gbogbo àwọn òrìṣà wọ̀nyí lo maa ń ko gbogbo ìpèsè yìí jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko mọ wípé Olódùmarè tí fun ọṣun ni agbára láàrín wọn nígbà to yá gbogbo nǹken kò gún régé mọ́ wọn ṣa ògùn títí kò jẹ mọ. Bayi ní wọn ṣe pínú láàrín ara wọ́n láti rán òrìṣà ńlá lọ sọdọ Olódùmarè ṣùgbọ́n òrìṣà ńlá kọ láti lọ. Ní ifá bá ní kí wọ́n ran ohùn lọ sọ́dọ̣̀ Olódùmarè nígbà tí Ifá de ibẹ̀ lo ba ṣọ fún Olódùmarè wípé nǹkan ko gún régé mọ̀ o. Olódùmarè ba ni ọṣun ń kọ o ni gbogbo nǹkan te ba ti n ṣe e fi t’obinrin ṣi. Bayí ní gbogbo àwọn òrìṣà yòókù bu lọ ṣi ọ̀dọ̀ ọṣun láti bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀ṣun ko gba ẹ̀bẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo bẹ̀rẹ̀ ṣi ni mu gbogbo wọn bu lẹyọ kọọkan láti orí Oosala, Ọ̀rúnmìlà Ṣungo, ọya obalùfọ̀n àti bebe lọ ó ní nǹkan tí wọn jọ ràn àwọn ń kọ? lo ba sọ fún wọn wípé ọmọ to wà ní ikùn ohùn tí ohun ba fi bí obinrin Olódùmarè yóò fí àwọn ẹlomíran dipo wọn. Ṣùgbọ́n to ba jẹ pe ọkunrin ní ohun fi bi o ni ohun yoo fi wọn silẹ́ wípé ohùn náà ti ni lara wọn niyẹ̀n ni ọṣun ba fi oyin rẹ bi ọkunrin láti ìgbà yìí tí wọn bat í ń lọ̀ ṣI igbó ẹmí airi láti lọ run wọn maa ń lọ gbé ọmọ ọ̀ṣun láti fi ọwọ́ tirẹ̀ náà ṣI gbogbo nǹkan ti wọn ba ń se tan ba se tan wọn à dá pada fún ìyá rẹ̀. Igba yìí lo ti ṣọ pé tó ba jẹ ọkunrin ko ma jẹ Akin osó. Ni ki a Ka kúnlẹ̀ Kí Obìnrin Òbìnrin lo bi wa Ka to di ènìyàn … Ifá jẹ ka mọ̀ wípé alagbará ni àwọn obìnrin Olodumare lọ pin wọn ile agbara yìí. Gbogbo bi àwọn òrìṣà yòókù se ń ko ípèsè yìí jẹ ọ̀ṣun mọ ṣi ṣùgbọ́n ó ṣe bi ènipe ohun ko mọ nǹkan to ń sẹlẹ̀. Alagbara ní wọn bí wọn se le lo agbara wọn lati fi ṣe daradara ni wọn fi le ṣe búburú. (Olóyè Babalọla Fatoogun (Ifá Priest) Ilobu Oṣogbo.) Ifá tún ṣọ ìtàn nipa àwọn obìnrin ajọ àti ìpàdé to maa ń ṣe o fi hàn bo fe lo agbara àwíṣẹ lati fig be ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ni gbogbo ìgbà tí wọn ba ti fẹ ṣe ìpàdé. Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà gbogbo agbara àwísẹ to ba sọ labẹ ge. Nitorí ó dúró gẹ́gẹ́ bi agbára ìtúsílẹ̀ àti agbara Hayese. Bo ṣe dí ojo kan àwọn ọ̀fá wa ọ̀nà láti ji agbara náà gbe wọn ko ri bi wọn ṣe lọ ba ìyàwó ọ̀rúnmìlà pìyí pe to ba juwe ibi ti agbara òhún wa fun àwọn àwọn o fun lówó. Ìyàwó Ọ̀rúnmìlà gba owo, o ṣi gbe agbára náà o lọ bo mọ inú eérú ojú àrò. Nígba tí Ọ̀rúnmìlà fẹ ṣe ìpàdé a kọkọ gbìyànjú làtí bi ifá léèrè lori bi ìpàdé yoo ṣe ri ni wọn ban i ko lọ bọ ṣango ojú eérú tori ke nǹkan ba le ṣenu ire àti pe kí àsírí to farasin le ba hàn sáyé. Ìgbà tí Ọ̀rúnmìlà ti gbe eéru ojú aaro lati bọ Ṣango tan lo ba ri agbara rẹ̀ tí ọ̀tá to ń pè ni ìyàwó bo mọ inú eeru náà. Ìgbà tí ọ̀tá ri pé wọn ko ri Ọ̀rúnmìlà mú náà bá tún lọ ba ìyàwó rẹ láti tún ta ete mìíràn ìyàwó Ọ̀rúnmìlà pẹ̀lú àwọn ọ̀tá náà ba gbìmọ̀ láti lọ ju agbara rẹ sínú odò. Ìgbà ti ọjọ́ àjò ń pe bọ̀ Ọ̀rúnmìlà lọ bi Ifa léèrè bí ọjọ́ àjọ yoo ṣe rí nítorí ó tí mọ bi obinrin se jẹ́. Ṣùgbọ́n ẹbọ to jade ṣí nip é ki o lọ ni eja abori ńlá kan, obi àbàtà, àti iyàn ìlèkẹ̀ ko fi bọ ẹlẹda rẹ. Lílà tí Ọ̀rúnmìlà la inú ẹja lo ba agbára rẹ̀ nínú ẹja. Ó gbà pe obinrin ni òdàlẹ̀ ni wọn. (Lati ẹnu Dro Agbájé ti wọn gba lẹnu Babalawo) Ìtàn kan ti Ifa ṣọ fì Obìnrin hàn gẹ́gẹ́ bi ọ̀dèlè, afẹnimadenu olubi ènìyàn. Ifá ṣọ ìtàn nípa Ọ̀rúnmìlà ENI TÍ MỌ FỌ̀RỌ̀ WÁ LẸ́NU WÒ. Oloye Babalọla Falogun Ifa Priest Ilobu Osogbo.
Ojú tí Ifá fi n Wọ́ Obìnrin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3239
3239
Ìṣírò Isiro Awoyemi, Jolaoluwa AWÓYẸMÍ JỌLÁOLÚWA ÌṢIRÒ Àwọn Yorùbá ní ọ̀nà tí wọn ń gbà ṣe ìsirọ̀, bẹ́ẹ̀ ní àti ọmọkékeré ní àwọn Yorùbá ti ń kọ́ ọmọ wọn ni ìṣirò ní ṣíṣe. Wọn yóò ni kí ó máa fi ení, èjì kọrin, ṣere bíi Ení bí ení ni ọmọde ńkawó Èjì bí èjì ni àgbàlà ń tayò Ẹ̀ta bi ẹta ẹ jẹ́ ka tárawa lọ́rẹ Ayò tí ta náà tún jẹ́ ọ̀nà tí àwọn Yorùbá fi máa ń kọ ìṣirò Yorùbá ni àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi ń ṣe ìsirò wọn fún àpẹẹrẹ “lé”, “dín”, “àádọ́”, “ẹ̀ẹ́dẹ́”, - jẹ́ àwọn ọ̀nà fún ìfilé àti ìyokúrò ìṣirò wọn. Apẹẹrẹ ìṣirò Yorùbá 1 - óókan 10 - ẹ̀wá 20 - ogún 21 - Ọ̀kàn lè lógún (20+1 = ọ̀kan lé ni ogún) 26 - ẹ̀rìndínlọ́gbọ̀n (30-4 = Ọgbọ̀n dín mẹ́rin) 30 - Ọgbọ̀n 40 - Ogójì (20x2 = Ogún méjì) 60 - Ọgọ́ta (20x3 ogún mẹ́ta) 100 - Ọgọ́rùn-ún (20x5) = Ogún lọ́nà márùn-ún) 120 - Ọgọ́fà (20x6 = Ogún lọ́nà mẹ́fà) 50 - àádọ́ta (20 x3 = 10, ẹ́wàá dín nínú ogún mẹ́ta) 200 - Igba 240 - Òjìlélúgba (40+200; Òjì = 40) 300 - Ọ̀ọ́dúnrún 340 - Ọ̀tàdín nírinwó (400-60 = ọ̀tà = 60 lọ́gbọ́ta) 800 - Ẹgbẹ̀rin (igba mẹrin 200x4) 900 - Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (1000-100 = Ọgọ́rùn-ún dín ni Ẹgbẹ̀rún 1000 - Ẹgbẹ̀rún 1600 - Ẹgbẹ̀jọ (200x8 = igba méjọ 2000 - Ẹgbẹ̀wàa (ẹgbàá) (200x10 – igba ní ọ̀nà mẹ́wàá) 4000 - Ẹgbàajì (2000x2) 6000 - Ẹgbàata (2000x3) 7000 - Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (8000-100 = Ọgọ́rùn-ún, dín nínú Ẹgbàárin (800) 10, 000 - Ẹgbàarùn-ún (Ẹgbẹ̀rùn-ún àádọ́ta ẹgbẹ̀rùn-ún - àádọ́ta ọ̀kẹ́).
Ìṣírò
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3241
3241
Ìkọ́ni GBADAMOSI TEMITOPE THOMAS Kíní a mọ̀ sí ìkọ́ni? Ìkọ́ni túmọ̀ si ìlànà ti àhún gbà láti fii òye hàn láti ìran kan dé òmíràn àti láti ènìyàn sí elòmíràn. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ìkọ́ni lèè túmọ̀ sí ìbáwí tàbí ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ ẹnití ó ju ẹni lọ. Àmọ́ ki a máa fi ọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀pọọlọ pa ejò, ìkọ́n tòní dá lórí ti Òye, Ìmọ̀ tàbí Èkó. Tí bá ní kí a woo bi ìtàn ìkọ́ni sé bẹ̀rẹ̀, a máa tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ odún sẹ́yìn. Akòleè sọ pàtó ibi ti ìkóni ti bẹ̀rẹ̀, nítorí pé orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kàn àti àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn níbikíbi lóní ìlànà ti wọ́n ń gbá kọ́ àwọn ènìyàn tiwọn. Ṣùgbọ́n orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀ bíi Gíríìsì (Greece) tí ìsirò ti bẹ̀rẹ̀, ilẹ Lárúbáwá (Arabia), ile isrẹẹli ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, wa nínú àwọn irú ènìyàn tí ó tayọ nínú ètò ìkọ́ni. Àmọ́ ètò ìkọ́ni bí a sè mọ̀ ti di àtọwọ́dọ́wọ́ débi wípé olúkúlùkù lóti gbàá ti wọ́n sì ti fi tún orílẹ̀ èdè wọn tò. Bí a ti se ń kọ́ni se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwùjọ, bí ati se lèe kọ́ ọmọdé yàtọ̀ sí bí ati se lèe kọ́ ọ̀dọ́ lángba bẹ́ẹ̀ ni ti ọ̀dọ́ langba náà yàtọ̀ sí ti àgbàlàgbà. Gbogbo wa lamọ̀ wí pé ọmọdé a máa tètè kọ́ ẹ̀kọ́ láti ibi àwòrán, àwọ̀ àti àfihàn. Nítorí ìdí èyí, àwọn ìwé tí alákọ̀bẹ̀rẹ̀ bíi aláwìíyé dára púpọ̀ fún ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé. Ẹ̀wẹ̀, tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí bá déé ilé ẹ̀kọ́ girama ìlànà kíkọ́ àti mímọ̀ wọn yóò ti yàtọ̀ díẹ̀ sí ti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀. Ní pele yìí, a óò tí máa fi yé wọn bá wọ́n se leè fi ọwọ́ ara wọn see àwọn ohun tí wọ́n ń kó wọn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn oo ti máa gbáradì fún ilé ẹ̀kọ́ gíga. Ní ilé ẹ̀kọ́ girama ẹ̀wẹ̀, àwọn ohun ti àwọn akẹ́kọ̀ óò máa há sórí – àkósórí àwọn akẹ́kọ̀ yóò din kù, yàtọ̀ sí tii ilé ẹ̀kọ́ ‘Jéléósimi’. Ǹjẹ́ tí abá dé ilé ẹ̀kọ́ gíga, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàtọ̀ ni yóò ti wà nínú bi ase ń kọ́ni. Ilé ẹ̀kọ́ gíga ilé ọgbọ́n, ilé ẹ̀kọ́ gíga ilé òmìnira. Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga akẹ́kọ̀ ní àǹfààní lati se ohun tówùú nígbà ti ó bá fẹ́ tí kòsì olùkọ́ tí yóò yẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ wò. Ìkọ́ni nílé ẹ̀kọ̣́ gíga yàtọ̀ gédégédé sí ti ilé ẹ̀kọ́ girama tàbí alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ní ilé ẹ̀kó gíga, akẹ́kọ̀ ló nílò láti se isẹ́ jù, nítorí péé; ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, olùkọ́ yóò kàn wá láti tọ́ akẹ́kọ̀ sọ́nà ni, akẹ́kọ̀ ni yóò se ọ̀pọ̀lọpọ̀ isẹ́ fún ra rẹ̀. Ìkọ́ni ni orílẹ̀-èdè yi ti dojú kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro tí ósì ti ń se àkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé àti ìdàgbà sókè ilẹ̀ yí. Tí abá ni kí áwòó láti ìgbà ìwásẹ̀ fún àpẹẹrẹ, ètò ìkọ́ni dára ni ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀, èdè Yorùbá ni afi hún kọ́ akẹ́kọ̀ láti ilẹ̀ kí àtó kii èdè òmíràn bọ̀ọ́, àmọ́ ni báyìí èdè gẹ̀ẹ́sì ni afi ń kọ́ akẹ́kọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn si ń sọ èdè Yorùbá nílé. Èyí lómú kí ó jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò leè sọ èdè Yorùbá kó já gaara láì má fii èdè gẹ̀ẹ́sì kọ̀ọ̀kan bọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò sì leè sọ èdè gẹ̀ẹ́sì dáradára. Ọ̀rọ̀ wa dàbíi “ẹni tí ófi àdá pa ìkún, ikún sálọ àda tún sọnù”. Kí ń tó fí gègéèmi sílẹ̀, gbogbo wa lamọ̀ wí pé ni àìsí ìkọ́ni kòleè sí ìmọ̀, ni àìsí ìmọ̀ láti ìran kan dé òmíràn; kò leè sí ìdàgbà sókè, ni àìsí ìdàgbà sókè ẹ̀wẹ̀, kò leè sí ìlosíwájú, ìlú tí kò bá sì ní ìlosíwájú ti setán láti parun ni. Fún ìdí èyí a óò ri péé ìkọ́ni jẹ́ ohun kan gbógì tí a kò leè fi seré ní àwùjọọ wa. Ẹ̀kọ́ dára púpọ̀ Ẹ̀kọ́ lóni ayé táawà yi sẹ́ Ẹ̀kọ́ lóhún gbéni dépò gíga Ẹ̀kọ́ lóhún gbéni dépò ọlá Ẹ̀kọ́ dára púpọ Ẹ̀kọ́ lóni ayé tí awà yí sẹ́. ÌTỌ́KASÍ (REFERENCE) i. D.F. Odunjọ - ‘Alawìye Apa keta’ ii. B. Onibonoje – ‘Iwe Ikọni Yorùbá iii. White Shear – ‘ Teaching skills’
Ìkọ́ni
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3244
3244
Ilesha
Ilesha
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3249
3249
Orílẹ̀-èdè Yorùbá ÀKÀNDÉ SAHEED ADÉBÍSÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí Orílẹ̀-Èdè jẹ́ àti-ìran-díran Odùduà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọn ń sin Ọlọrun ni ọ̀nà ti Odùduà ń gbà sìn-ín; ti wọn si bá a jade kúrò ni agbedegbede ìwọ̀ oòrùn nígbà tí ìrúkèrúdò dé nipa ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí. Akikanjú yii pinnu láti lọ tẹ orílẹ̀ èdè miran dó nibi tí wọn yóò gbé ni àǹfàní ati sin Ọlọrun ni ọ̀nà ti wọn gbà pé ó tọ́ ti ó si yẹ. Bí wọn ti ń rìn káàkiri ni Yorùbá, bí Orìlẹ̀-Èdè n gbòòrò síi, ti ó si fi jẹ́ pé l’onii gbogbo àwọn ènìyàn tí wọn ń bá ni gbogbo ibi tí wọn ti ń jagun tí ó di ti wọn àti ibi tí wọn gbé ṣe àtìpó, tí wọn si gbé gba àṣà, ati ìṣe wọn, titi ti ọkunrin Akíkanjú, Akọni, Olùfọkànsìn, Olóógun, Àkàndá ẹ̀dá, yii fi fi Ile-Ifẹ ṣe ibùjókòó ati àmù Yorùbá. Ile-Ifẹ yii si ni àwọn Yorùbá ti fọ́nká kiri si ibi ti wọn gbé wà l’onii ti à ń pè ni ‘Ilẹ̀ K’áàrọ̀, O jí i re’. L’ónìí, kì í ṣe ibi tí a pè ni ‘Ìlẹ̀ k’áàrọ̀, O jí i ré’ yii nìkan ni àwọn Yorùbá wà gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà kan. Wọn fọ́n yíká Ilẹ ènìyàn dudu ni, àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíran l’ábẹ́run ayé. Eyi ni ibi ti àwọn ẹ̀yà ti à ń pè ni Yorùbá wà l’onii: 1. ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ: Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ògún, Èkó, Oǹdó, Kwara, Èkìtì ati Ọṣun. A sì tún ń ri àwọn Yorùbá diẹdiẹ ni àwọn ìpínlẹ̀ wọnyi: (i) Ìpínlẹ̀ Kano: Àwọn ẹ̀yà Yorùbá ti ó wà nibi ni àwọn tí à ń pè ní ‘Báwá Yorúbáwá ati Gogobiri: (ii) Sokoto: Àwọn ìbátan wọn tí ó wà nibi ni à ń pè ni Beriberi. Gẹ́gẹ́ bi òwe ti ó wí pé ‘Oju ni a ti ń mọ dídùn ọbẹ̀. Ilà oju àwọn ẹ̀yà yii fi ìdí ọrọ yii múlẹ̀. (iii) Ìpínlẹ̀ Ilẹ̀ Ìbínní dé etí Odò Ọya: Awọn wọnyi ni àwọn ìlú tí ọmọ Eweka gbé ṣe àtìpó ati ibi tí wọn jẹ oyè sí, àwọn bíi Onìṣà Ugbó, Onìṣà Ọlọ́nà àti Onìṣà Gidi (Onitsha), pàápàá jùlọ àwọn tí wọn ń jẹ oyè tí à ń pè ni Òbí. Àwọn kan sì tún ni ìran Ègùn bíi: Ègùn Ànùmí ni ilẹ Tápà; Ègùn Àwórí ni Ẹ̀gbádò; Ègùn Àgbádárígì ní Ìpínlẹ̀ Èkó. 2. ORÍLẸ́ ÈDÈ BENIN, TOGO, GANA ATI SÀRÓ Awọn ni Ègùn ilẹ Kutonu, Ègùn Ìbàrìbá ilẹ Benin; Aina, Aigbe àti Gaa ni ilẹ Togo ati Gana; àti àwọn Kiriyó (Creoles) ilẹ Sàró (Sierra Leone). 3. ORÍLẸ̀ ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà l’áàrin Amẹ́ríkà ti àríwá àti ti gúúsù (Cuba, Trinidad and Tobago, Jamaica and other Caribbean islands); ati àwọn Ìpínlẹ̀ òkè l’ápá ìlà-oòrùn ti Amẹ́ríkà ti Gúúsù: (Brazil, etc). Bí ó tilẹ jẹ́ pé àwọn ọmọ Odùduà tàn kálẹ̀ bíi èèrùn l’ode oni, ẹ̀rí wa pé orílẹ̀ èdè kan ni wọ́n, ati pé èdè kan náà ni wọn ń sọ nibikibi tí wọn lè wà. Ahọ́n wọn lè lọ́ tàbí kí ó yí pada nínú ìsọ̀rọ̀ síi wọn, ṣùgbọ́n ìṣesí, ìhùwà, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀; gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa sì ti máa ń pa á l’ówe, a mọ̀ a sì gbà pé; Bi ẹrú ba jọ ẹrú, ilé kan náà ni wọn ti wá’. Awọn idi pàtàkì ti ahọ́n àwọn ọmọ Yorùbá fi yí pada díẹ̀ díẹ̀ díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Yorùbá kan náà ni wọn ń sọ niyi: (a) Bí àwọn akọni ti ń jade kúrò ni Ilé-Ifẹ̀ láì pada bọ̀ wá sile mọ́, ni wọn ń gbàgbé díẹ̀ nínú èdè ìbínibí wọn. (b) Ibikibi ti àwọn akọni yii bá sì ṣe àtìpó sí tàbí tẹ̀dó sí ni wọn ti ń ba ènìyàn. Otitọ ni wọn gba orí l’ọ́wọ́ àwọn ti wọn ń bá ti wọn sì ń di ‘Akẹ́hìndé gba ẹ̀gbọ́n’, ṣugbọ́n bi wọn bá ti ń di onile ni ibi ti wọn tẹ̀dó, tàbí ti wọn ṣe àtìpó si yii, ni wọn mú díẹ̀-díẹ̀ lò nínú èdè, àti àṣà wọn nitori pe bi ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ bi kò tilẹ di ọṣẹ yoo dà bí ọṣẹ; àti pé ti ó bá pẹ́ ti Ìjẹ̀ṣà bá ti jẹ iyán, kì í mọ òkèlè ẹ̀ bù mọ́; òkèlè ti ó yẹ kí ó máa bù nlanla yoo di ródóródó. Eyí ni ó sì ń fa ìyàtọ̀ díẹ̀-díẹ̀ nínú ìṣesí àwọn Yorùbá nibikibi ti wọn bá wà l’ónìí. (d) Bi àwọn ọmọ Yorùbá ti ṣe ń rìn jinna sí, sí Ile-Ifẹ ni ahọ́n àwọn ẹ̀yà náà ṣe ń yàtọ̀. Awọn tó gba ọna òkun lọ ń fọ èdè Yorùbá ti ó lami, ti a sì ń dàpè ni ÀNÀGÓ, àwọn ti wọn sì gba ọna igbó àti ọ̀dàn lọ ń sọ ogidi Yorùbá, irú wọn ni a sì ń pè ni ará òkè. Pàtàkì nínú àwọn ẹ̀yà Yorùbá ti ó kúrò ni Ile-Ifẹ ti ó sì gba apá òkè lọ nínú igbó ati ọ̀dàn niyi: Ọ̀yọ̀; Ìjẹ̀ṣà; Àkókó; Èkìtì; Ọ̀wọ̀; Oǹdó; Ìgbómìnà; Ọ̀fà; Ìlọrin; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ti o si gba ẹsẹ̀ odò lọ ni Ẹ̀gbá; Ẹ̀gbádò; Ìjẹ̀bú; Ìlàjẹ; Ikalẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Orílẹ̀-èdè Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3253
3253
Buhari
Buhari
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3254
3254
Ogun Àgbáyé Kìíní ÌJÀ OGUN ÀGBAYÉ KÌÍNÍ Láti ọjọ́ ti aláyé ti dáyé ni àwọn ìwọ̀ búburú bí i: jàgídíjàgan, wàhálà. Rúkèrúdò ti wà nínú ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn. Rògbòdìyàn kò yé sẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ nì làásìgbò kò roko ìgbàgbé. Ìdàrúdàpọ̀ nínú ẹbí, Àríyànjiyàn láàárin ọ̀rẹ́. Gbọ́nmisi, omi ò to kò yé wáyé láàárín ìlú sí ilu, abúléko sí abúléko. Gbogbo àwọn nǹkan ló ń parapọ̀ tí ó sì ń di ogun. Tí a bá fi ojú sùnùkùn wo ogun àgbáyé kìíní, a óò rí wí pé gbogbo rògbòdìyàn, àjàkú akátá tó wáyé, kò sẹ̀yìn ìwà ìgbéraga, owú jíjẹ, èmi ni mo jùọ́ lọ, ìwọ lo jùmí lọ láàárín àwọn ọmọ adáríwurun. Àwọn àgbà sì bọ̀ wọ́n ní “àìfàgbà fẹ́nìkan ni kò jẹ́ káyé ó gún”. Nígbà tí ẹnìkan bá rò pé òun ló mọ nǹkan ṣe jú, èrò tòun ló tọ̀nà jù, kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ ta ko ohun tí òun bá sọ. Àwọn nǹkan wọ̀nyí tó máa ń bí ogun, nígbà tí elòmírà bá ta ko irúfẹ́ èèyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí ó jẹ gàba lé òun lórí. Bí ogun ṣe máa ń sẹlẹ̀ láàárin ìlú sí ìlú ló máa ń sẹlẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè. Ara àwọn nǹkan tí ó sokùn fa ogun àgbáyé àkọ́kọ́ nìyí. Ogun àgbáyé àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ láàárin orílẹ̀-èdè méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Austria-Hungary ati Serbia. Ìlú kékeré kan ní awọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ń jà lé lórí. Orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ló kọ́kọ́ gba ìlú yìí lọ́wọ́ ẹ̀kẹjì nínú ogun kan tó wáyé ní ọdún 1908. Orílẹ̀-èdè kejì wá ń dún kòkò lajà láti gba ìtú yìí padà. Sáájú àsìkò yìí, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ kan sẹ̀lẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé máa ṣe gbún-ùn gbùn-ùn gbún-ùn sí ara wọn. Sáájú ogun àgbàyé kìíní, àwọn orílẹ̀-èdè ló máa ń jẹ gàba lórí àwọ́n orílẹ̀-èdè mìíràn nígbà máà, kò pẹ́ kò jìnnà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní mú sìn yìí bẹ̀rẹ̀ ń jà fún òmìnira. Orílẹ̀-èdè [Belgium] gba òmìnìra ní ọdún 1830, nígbà tí ilẹ̀ [Germany] gba tiwọn ní 1871. Ìjà òmìnìra wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lólogbó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kọ́kọ́ tako èyí, síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò rí nǹkan ṣe si èyí. Gbogbo àwọn tí wọ́n tí wọ́n ti jẹ́ gàba lé lórí bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Gbogbo wọn kóra pọ̀. Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà bẹ̀rẹ̀ sí sẹlẹ̀, àti àwọ́n ìsòro tí ó rọ̀ mọ́ ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sokùnfà rògbòdìyàn ogun nígbà náà yàtọ̀ sí èyí, wíwá àwọn òyìnbó sí ilẹ̀ aláwò dúdú [Africa] wà lára àwọn nǹkan to sokùnfà ogun àgbáyé kìíní. Owó ló gbé àwọn òyìnbó dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, wọ́n wá ri pé yíò rọrùn fún àwọn láti rí nǹkan àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n ń fẹ́ tí àwọn bá mú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú sìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ìjọ̀ bèrè sí wáyé láàárin wọn lórí orílẹ̀-èdè tí oníkálukú wọn yíò mú sìn. Nígbà tí wọ́n ń pín ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn, bí wọn ṣe pin kò tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kan lọ́rùn lórí bí wọ́n ṣe pín àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn nígbà náà Àyọrísí gbogbo wàhálà yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí furá sí ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kó nǹkan ijà olóró jọ. Àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ara wọn sọ̀rẹ́ láti gbógun ti orílẹ̀-èdè mìíràn. Nígbà tí ogun yìí yóò fi bẹ̀rẹ̀, awọn orílẹ̀-èdè alágbára pín ara wọn sí ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Orílẹ̀-èdè [Germany], [Austria-Hungary] ati [Italy] wà ní ẹgbẹ́ kan, nígbà tí orílẹ̀-èdè [Britain], [France] àti [Russia] wà nínú ẹgbẹ́ kejì, Ní ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹfà ọdún 1914 [18/6/1914] ni okùnrin kan tó ń jẹ́ Gavrilo Princip tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Serbia sekú pa ọmọ Ọba orílẹ̀-èdè Astria-Hungary tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Francis Ferdinand ẹni tó yẹ kó di ọba ní orílẹ̀-èdè náà. Èyí kò sẹ̀yìn ìgbìyànjú Serbia láti gba àwọn ẹ̀yà tí Austria-Hungary ti kó sínú ìgbèkùn nínú ogun tí wọ́n ti jà tẹ́lẹ̀. Ikú ọmọ ọba yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé nígbà tí orílẹ̀-èdè Astria-Hungary gbaná jẹ. Wọ́n pinnu láti gbógun ti ilẹ̀ Serbia. Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ilẹ̀ Russia tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ilẹ̀ Serbia kéde pé àwọn yíò gbógun tí ilẹ̀ Austria-Hungary. Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbìyànjù láti pẹ̀tù sí wàhálà yìí. Ilẹ̀ Austria-Hungary fún ilẹ̀ Serbia ní àwọn nǹkan tó le mu ogun yìí wọlè, ṣùgbọ́n ilẹ̀ Serbia kò tẹ̀lé àwọn nǹkan wọ̀nyí. Látàrí èyí, ilẹ̀ Austria-Hungary kéde ogun lé Serbia lórí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù kẹjọ ọdún 1914 [28/8/1914]. Bí ilẹ̀ Austria-Hungary ṣe ṣe èyí tan ni orílẹ̀-èdè Russia náà kéde ogun lé ilẹ̀ Austria-Hungary lórí. Bí ilẹ̀ Russia ṣe ṣe èyí tán ni ilè Germany kìtọ̀ fúnwọ̀n pé tí wọ́n bá danwò, àwọn yíò gbógun tìwọ́n. Nígbà tí ilẹ̀ Austria-Hungary ríbi tí ọ̀rọ̀ yìí ń tọ, wọ́n tẹsẹ̀ dúró fún ìjíròrò pẹ̀lú ilẹ̀ Russia. Ilẹ̀ Germany pàsẹ láti tú àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti kójọ tẹ́lẹ̀ kọ́ fún ogun yìí ká. Ilẹ Russia kọ etí ikún sí àsẹ tí ilẹ̀ Germany lórí àsẹ yìí. Èyí ló mú kí ilẹ̀ Germany kéde ogun lé ilẹ̀ Russia lórí ní ọjọ́ kìíní osù kejọ ọdún 1914 [1/8/1914]. Ní ọjọ́ kejì sí èyí ni ilẹ̀ ni ilẹ̀ France náà kéde ogun lé ilẹ̀ Germany náà lórí. Ní ọjọ́ kẹta ni ilẹ̀ Germany kéde ogun lé ilẹ̀ France lórí padà. Sáájú kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Belgium tí kọ̀wé ránṣẹ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó kù pé tí ogun bá bẹ̀rẹ̀, àwọn kò ní lọ́wọ́ síi. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sì fọwọ́ sí ìwé tí ilẹ̀ Belgium kọ síwọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Germany pinu láti gba ilẹ̀ Belgium kọjá láti kọ lu ilẹ̀ France. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ Belgium kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ti pínú pé àwọn kò ní dá sí ìjà. Èyí mú kí ilẹ̀ Germany bínú, wọ́n sì pínú láti gbógun tí ilẹ̀ Belgium. Ìpin ìlẹ̀ Germany yìí mú kí ilẹ̀ Britain dá sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n kìlọ̀ fún ilẹ̀ Germany láti ro ìpin àti gbógun ti ilẹ̀ Belgium ní ẹ̀ẹ̀mejì nítorí pé gbogbo àwọn ni àwọn fi ọwọ́ si pé ilẹ̀ Belgium kò ní lọ́wọ́ si ogun yìí nítorí náà, kí wọ́n má ṣe gbógun ti ilẹ̀ Belgium. Ilẹ̀ Germany kọ̀ jálẹ̀ láti gba ọrọ yìí yẹ̀wò, èyí sì mú kí orílẹ̀-èdè Britan kéde ogun lé ilẹ̀ Germany lóri ní ọjọ́ kẹrin osù kẹjọ ọdún 1914 [4/8/1914]. Ilẹ̀ Turkey náà dá sí ogun yìí ní osù kẹwàá ọdún 1914. Nígbà tí ilẹ̀ France náà da si ní osù kọkànlá ọdún 1914. Báyìí ni ogun yìí di ogun àgbéyé, tí ó di ìjà àjàràn. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí awọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí ń ṣe àkóso lé lórí tí wọ́n ń mú sìn pàápàá jùlọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ [Africa] àti ilẹ̀ Lárúbáwá ni gbogbo wọn náà múra láti gbè sẹ́yìn àwọn ọ̀gá wọn láti bá àwọn orílẹ̀-èdè yòókù jà tí èyí sì di isu atayán-an yàn-an káàkiri orílẹ̀-èdè àgbáyé. Ní osù kẹrin ọdún 1917 ni ile America náà kéde ogun lé ilẹ̀ Germany lórí látàrí bí wọn ṣe kọlu àwọn ara ilẹ̀ America nínú ọkọ̀ ojú-oni ti èyí si tako ìlànà ogun jìjà. Òfin sì wà wí pé tí orílẹ̀-èdè méjì bá ń jà, àwọn ọmọ ogun ara wọn nìkan ní wọ́n dojú ìjà kọ. Orílẹ̀-èdè Germany rú òfin yìí. Èyí sì bí ilẹ̀ America nínú, ìdí nìyí tí wọ́n fi dá’ sí ogun àgbáyé ní ọdún 1917. Ogun àgbáyé tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù keje ọdún 1914 [28/7/1914] parí ní ọjọ́ kọkànlá osù kọ́kànlá ọdún 1918[11/11/1918] lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, osù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́rìnlá tí ogun ti bẹ̀rẹ̀. Owó tí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ná sí ogun yìí tó Ọgórùn-ún méjì Bílóọ̀nù dọ́là [Two Hundred Billons Dollas] owó ilẹ̀ America láyé ìgbà náà tí owó níyì. Bí i ogójì mílíọ̀nù [Fourty Millions] ọmọ ogun orílẹ̀-èdè àgbáyé ló bá ogun yìí lọ kí á ṣẹ̀ṣẹ̀ má sọ ti àwọn ogun ojú-oun bí i mílíọ̀nù mẹ́wàá [Ten millions] tí ó ará ìlú tá kìí ṣe sọ́jà ló sòfò nínú ogun àgbéyé yìí. Síbẹ̀síbẹ̀, wàhálà tó sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́ tí àwọn èèyàn rò pé yíò yanju tàbí níyanjú. Wàhálà yìí ló tún sokùnfà ogun àgbáyé kejì àti àwọn ogun tó tún wáyé lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní. Ní ìparí, ogun kìí ṣe nǹkan tí ó dára. Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní "ẹni tí ogun ba pa kù ní ń ròyìn ogun". Ogun máa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ èmí àti dúkìẹ́ sòfò. Yorùbá tún bọ̀ wọ́n ní "ẹni tí sàngó bá tojú rẹ̀ jà rí kò ní báwọn bú olúkòso". Ẹnì tí Ogun bá jà lójú rẹ̀ rí, kò ní bẹ ọlọ́run kí ogun tún wáyé ní ojú òun. Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí á ri ogun.
Ogun Àgbáyé Kìíní
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3256
3256
Esin Igbagbo
Esin Igbagbo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3258
3258
Wikipéédíà
Wikipéédíà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3273
3273
Ìyísódì nínú Ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀ ÌYÍSÓDÌ NÍNÚ Ẹ̀KA-ÈDÈ ÌKÁLẸ̀ Ìfáàrà Gẹ́gẹ́ bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ nínu YA, Ìkálẹ̀, tíí ṣe ọ̀kan lára àwọn èka-ède Yorùbá, máa ń ṣe àmúlò oríṣiríṣi wúnrẹ̀n láti fi ìyísódì hàn. Ìyísódì lè jẹ yọ nínú ẹyọ ọ̀rọ̀ kan, ó sì tún lè jẹ yọ nínu ìhun gbólóhùn kan. Ṣíṣe àfihàn àwọn ọ̀nà lóríṣiríṣi tí ìyísódì máa ń gbà wáyé nínu ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀ gan-an ló jẹ wá lógún nínu iṣẹ́ yìí. Ìyísódì Ẹyọ Ọ̀rọ̀ Àkíyèsí fí hàn pé irúfẹ́ ọ̀rọ̀ méjì ló wà: ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ (èyí ti a kò ṣẹ̀dá) àti ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Àwọn ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ kan wà tó jẹ́ wí pé wọ́n ní ìtumọ̀ ìyísódì nínú. Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni rárá. Rárá jẹ́ òdi bẹ́ẹ̀ ni. Ó máa ń dúró gẹ́gẹ́ bíi ìdáhùn gbólóhùn ìbéère 21 (a) (i) Ṣé Adé wúlí? (ii) Ṣé Adé wálé? (b) (i) Rárá (ii) Rárá A ó ṣe àkíyèsí wí pé rárá jẹ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan tó ń ṣiṣé gbólóhùn òdì. Tí a kò bá fé lo rárá fún ìdáhùn (21a), a lè sọ wí pé: (c) (i) Adé éè wúlí (ii) Adé kò wálé. Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ kejì ni ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Àwọn yìí ni ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá tí wọ́n sì ń fún wa ní òye ìyísódì. A pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá, nítorí pé wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ oní-mọ́fíìmù kan. Tí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ yìí, a máa ń lo mọ́fíìmù ìsẹ̀dá mọ́ ọ̀rọ̀ ìpìlè, èyí tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀-ìṣe ló máa ń jẹ; àkànpọ̀ àwọn méjéèjì máa ń yọrí sí ọ̀rọ̀-orúkọ. Fún àpẹẹrẹ: 22 (a) (i) àì- + hùn àìhùn (ii) àì- + sùn àìsùn (b) (i) àì- + gbọ́n àìgbọ́n (ii) àì- + gbọ́n àìgbọ́n (c) (i) àì - + jẹun àìjẹun (ii) àì - + jẹun àìjẹun A ṣe àkíyèsí pé mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá àì- náà ni YA máa ń lọ láti fi yi ọ̀rọ̀-ìṣe sódì. Ìyísódì Fọ́nrán Ìhun Nínu Gbólóhùn Àkíyèsí Alátẹnumọ́ Bí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́, fọ́nrán ìhun tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí sí ni a ó gbé sí iwájú gbólóhùn ìpìlẹ̀. Ọ̀nà tí à ń gbà ṣe èyí ni pé a ó fi ẹ̀rún ní sí èyìn fọ́nrán ìhun náà tí a fẹ́ pe àkíyèsí sí. Àwọn fọ́nrán ìhun tí a lè ṣe bẹ́ẹ̀ gbé sí iwájú ni: òlùwà, àbọ̀, kókó gbólóhùn, ẹ̀yán, àpólà-atọ́kùn. Àwọn fọ́nrán ìhun tí a lè pe àkíyèsí sí yìí ni a lè yí sódì. A ó ṣe àgbéyẹ̀wò wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ìyísódì Olùwà Bí ó ṣe jẹ́ wí pé a lè pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí olùwà nínu gbólóhùn, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè ṣe ìyísódì fún un. Ée ṣe ni wúnrẹ̀n tí ẸI máa ń lò fún ìyísódì Olùwà nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́. Sùgbọ́n nínu YA, ọ̀nà méjì ni a lè gbà ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tí a pẹ àkíyèsí sí. A lè lo atóka ìyísódì kọ́ tàbí kì í se. Fún àpẹẹrẹ: 23 (a)(i) Àwa rín (ii) Àwa ni (b)(i) Ée ṣe àwa (ii) Àwa kọ́ tàbí kì í ṣe àwa. 24 (a)(i) Olú ò ó lọ rín (ii) Olú ni ó lọ (b)(i) Ée ṣe Olú ò ó lọ (ii) Olú kọ́ ni ó lọ tàbí Kì í ṣe Olú ni ó lọ 25 (a)(i) Ọmàn pupa ò ó hun rín (ii) Ọmọ pupa ni ó sùn (b)(ii) Ée ṣe ọmọ pupa ò ó hùn (ii) Ọmọ pupa kọ́ ni ó sùn tàbí Kì í ṣe ọmọ pupa ni ó sùn A ṣe àkíyèsí pé rín ni atọ́ka àkíyèsí alátẹnumọ́ nínu ẸI. Tí a bá sì ti ṣe ìyisódì fọ́nrán ìhun tí a pe àkíyèsí sí, atọ́ka àkíyèsí alátẹnumọ́ náà kì í jẹ yọ mọ́. Ìyísódì Àbọ̀ Pípe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí àbọ̀ nínu gbólóhùn fara jọ ìgbésẹ̀ ti Olùwà. Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbè ni pé tí a bá ti gbé àbọ̀ síwájú, ààye rẹ̀ yóò sófo. Tí a bá fẹ ṣe ìyísódì àbọ̀ inú gbólóhùn, ée ṣe náà ni wúnrẹ̀n tí ẸI máa ń lò. Fún àpẹẹrẹ: 26 (a) (i) Olú nà Adé (ii) Olú na Adé (b) (i) Ée ṣe Adé Olú nà (ii) Adé kọ́ ni Olú nà tàbí kì í ṣe Adé ni Olú nà 27 (a) (i) Kítà á pa ẹran (ii) Ajá pa ẹran (b) (i) Ée ṣe ẹran kítà á pa (ii) Ẹran kọ̀ ni ajá pa tàbí Kì í ṣe ẹran ni ajá pa Ìyísódì Kókó Gbólóhùn Tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí kókó gbólóhùn, a máa ń ṣe àpètúnpè ẹlẹ́bẹ fún ọ̀rọ̀-ìṣe. Bí a ṣe ń ṣe èyí ni pé a ó ṣe àpètúnpè kọ́nsónáǹtì àkọ́kọ́ ti ọ̀rọ̀-ìṣe náà kí a tó wá fi fáwẹ̀lì /i/ Olóhùn òkè sí ààrin kọ́ńsónáǹtì méjéèjì. Fún àpẹẹrẹ: 28 (a) (i) Délé ra bàtà (ii) Délé ra bàtà (b) (i) Rírà babá ra bàtà rín (ii) Rírà ni babá ra bàtà 29 (a) (i) Ìyábọ̀ fọ ọfọ̀ núẹ̀n (ii) Ìyábọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mìíràn (b) (i) Fífọ̀ Ìyábọ̀ fọ ọfọ̀ múẹ̀n rín (ii) Sísọ ni Ìyábò sọ ọ̀rọ̀ mìíràn Ìyísódì (28) (b) ni (30) nígbà tí ìyísódì (29) (b) ni 31) 30 (i) Ée ṣe rírà bàbá ra bàtà (ii) Rírà kọ́ ni bàbá ra bàtà tàbí Kì í ṣe rírà ni bàbá ra bàtà 31 (i) Ée ṣe fífọ̀ Ìyábọ̀ fọ ọfọ̀ múẹ̀n (ii) Sísọ kọ́ ni Ìyábọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mìíràn tàbí Kì í ṣe sísọ ni Ìyábọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mìíràn. Ìyísódì Ẹ̀yán Ọ̀nà tí a ń gbà yí èyán sódì nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ yàtọ̀ díẹ̀ sí tí àwọn fọ́nrán ìhun yòókù. Ìgbésẹ̀ kan wà tí a máa ń ṣe fún èyán tí a pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí nígbà tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì rẹ̀. A lè yíi sódì nínu àpólà-orúkọ tí ó ń yán, a sì tún lè yíi sódì láìbá àpólà-orúkọ tó ń yán rín. Tí èyí bá máa wáyé, a gbọdọ̀ sọ ẹ̀yán náà di awẹ́-gbólóhùn asàpèjúwe, kí á tó yíi sódì. Yí ni atọ́ka awẹ́-gbólóhùn asàpèjúwẹ nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ìyísódì ẹ̀yán tó dá dúró láìba ọ̀rọ̀-orúkọ tó ń yán rìn ni: 32 (i) Ọmàn yí mọ rí, ée ṣe pupa (ii) Ọmọ tí mo rí kì í ṣe pupa tàbí Pupa kó ni ọmọ tí mo rí. 33 (i) Ilẹ̀ yí mọ lọ, ée ṣe Ègùn (ii) Ilẹ̀ tí mo lọ, kì í ṣe Ègùn, tàbí Ègùn kọ́ ni ilè tí lọ Ìyísódì Àpólà-Àpọ́nlé Gẹ́gẹ́ bí àwọn fọ́nrán ìhun yòókù ṣe máa di gbígbe síwájú nígbà tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí wọn, àpólà-àpọ́nlé náà máa ń di gbígbé wá síwájú nígbà tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí i. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni àpọ́là-àpọ́nlé máa ń ṣe nínu gbólóhùn: àwọn kan máa ń sọ ibi tí ìṣe inú gbólóhùn náà ti wáyé; àwọn kan sì máa ń sọ ìdí tí ìṣèlẹ̀ náà fi wáyé. Tí a bá fé ṣe ìyísódì àpólà-àpọ́nlé tó ń sọ ibi tí ìṣe inú gbólóhùn ti wáyé, a ó kọ́kọ́ gbé àpólà-àpọ́nlé náà síwáju, a lè ṣe ìpajẹ ọ̀rọ̀-atọ́kùn tó síwáju rẹ̀, a sì lè dáa sí. Tí a bá ṣe yí, a ó wá fi èrún ti kún àpólà-ìṣe náà. Àpẹẹrẹ ni: 34 (a) (i) Mọ jẹun n’Ọ́ọ̀rẹ̀ (ii) Mo jẹun ní Ọ̀ọ̀rẹ̀ (b) (i) Ée ṣe Ọ̀rẹ̀ mọ ti jẹun (ii) Ọ̀rẹ̀ kọ́ ni mo ti jeun Àpẹẹrẹ ìyísódì àpólà-àpọ́nlé tó ń sọ ìdí tí ìṣe inú gbólóhùn fi wáyé ni 35 (i) Ée ṣe tìtorí àtijẹun àn án bá susẹ́ (ii) Nítorí àtijẹun kọ́ ni wọ́n ṣe ṣiṣẹ́ Ìyísódì Àsìkò, Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ àti Ojúṣe Oríṣiríṣi àríyànjiyàn ló wà lóri pé ède Yorùbá ní àsìkò gẹ́gẹ́ bí ìsọ̀rí gírámà tàbí kò ní. Bámgbóṣé (1990:167) ní tirẹ̀ gbà pé àsìkò àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ wọnú ara wọn Ó ní: Àsìkò àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ máa ń fara kọ́ra nínu ède Yorùbá. Èro Bámgbóṣé yìí ni yóò jẹ́ amọ̀nà fún wa nínu ìsọ̀rí yìí Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àdáwà Àsìkò afànámónìí jẹ mọ́ ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ń sẹlẹ̀, yálà ó ti ṣẹlẹ̀ tán tàbí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lásìkò tí à ń sọ̀rọ rẹ̀. Tí a bá lò ó pẹ̀lú ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà, kò sí wúnrẹ̀n tó máa ń tọ́ka rè. Fún àpẹẹrẹ: 36 (i) Olú ó lọ Oló lọ (ii) Olú lọ Ìyísódì (36) ni: 37 (i) Olú éè lọ Oléè lo ̣ (ii) Olú kò lọ Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Atẹ́rẹrẹ Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán atẹ́rẹrẹ máa ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ nígbà tí Olùsọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ èyí ni: 38 (a) (i) Olú éé rẹ̀n (ii) Olú ń rìn Éé ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán atẹ́rẹrẹ nínu ẸI, ṣùgbọ́n atọ́ka ìyísódì éè ni a fi ń yí i sódì. Àpẹẹrẹ ni: (b) (i) Olú éè rẹ̀n Oléè rẹ̀n (ii) Olú kò rìn Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Bárakú Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán bárakú máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Máa ń àti a máa ló máa ń tọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu YA. Ọ̀nà tí ẸI ń gbà tọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yàtọ̀ gédéńgbé sí ti YA. Atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI ni éé àti a ka. Ìlo rẹ̀ nínu gbólóhùn ni: 39 (i) Olú éé jẹun (ii) Olú ń jẹun 40 (i) Olú a ka kọrin (ii) Olú a máa kọrin Ée ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àpẹẹrẹ ni: 41 (i) Olú ée jẹun (ii) Olú kì í jẹun 42 (i) Olú ée kọrin (ii) Olú kì í kọrin Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìbẹ̀rẹ̀ Stockwell (1977:39) ṣàlàyé ibá-ìsẹ̀lẹ̀ àṣetán gẹ́gẹ́ bí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti parí. Bámgbósé (1990:168) ní tirẹ̀ ṣàlàyé wí pé ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìbẹ̀rẹ̀ nínu àsìkò afànámónìí máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ti parí, ṣùgbọ́n tí ó ṣe é ṣe kí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà má tíì tán. Ti ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI. A máa ń lò ó papọ̀ pẹ̀lú atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ atẹ́rẹrẹ 43 (i) Olú éé ti lọ Oléé ti lọ (ii) Olú ti ń lọ 44 (i) Àn án ti ka kọrin (ii) Wọn á tí máa kọrin Ée ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Fún àpẹẹrẹ: 45 (i) Olú ée ti í lọ Olée ti í lọ (ii) Olú kì í ti í lọ 46 (i) Án àn ti ka korin (ii) Wọn kò tíì máa kọrin Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìparí Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìparí nínu àsìkò afànámónìí máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti parí pátápátá. Ti ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àpẹẹrẹ ìlo rẹ̀ nínu gbólóhùn ni: 47 (i) Ọmàn mi ti hùn (ii) Ọmọ mi ti sùn 48 (i) Mọ ti fọfọ̀ múẹ̀n (ii) Mo ti sọ̀rọ̀ mìíràn Éè ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI. Nígbà tí a bá yíi padà, ohun ààrin to wà bẹ lóri atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò yí padà sí ohùn ìsàlẹ̀. Àpẹẹrẹ ni: 49 (i) Ọmàn mi éè tì hùn (ii) Ọmọ mi kò tíì sùn 50 (i) Méè tì fọfọ̀ múẹ̀n (ii) N kò tíì sọ̀rọ̀ mìíràn Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lè Àdáwà Nígbà tí atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú bá ti jẹ yọ pẹ̀lú ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà, (tí kò ní atọ́ka kankan), àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́ ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà nínu àsìkò ọjọ́-iwájú. Àwọn àpẹẹrẹ ni: 51 (i) Olú a lọ (ii) Olú á lọ 52 Ìyábọ̀ á fọfọ̀ nọọ̀la (ii) Ìyábọ̀ á sọ̀rọ̀ lọ́lá Ìyábọ̀ (51) ni (53), nígbà tí ìyísódì (52) ni (54) 53 (i) Olú éè níí lọ Oléè níí lọ (ii) Olú kò níí lọ 54 (i) Ìyábọ̀ éè níí fọfọ̀ nọọ̀la (ii) Ìyábọ̀ kò níí sọ̀rọ̀ lọ́la. Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Atẹ́rẹrẹ Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí èyí ti jẹ yọ ni: 55 Ìyábọ̀ a ka hunkún (ii) Ìyábọ̀ á máa sunkún Ìyísódì rẹ̀ ni: 56 (i) Ìyábọ̀ éè níí ka hunkún (ii) Ìyábọ̀ kò níí máa sunkún Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Bárakú Ìhun kan náà ni èyí ní pẹ̀lú ìhun àsìkò ọjọ́-iwájú àti ibá-ìṣẹ̀lẹ àìṣetán atẹ́rẹrẹ. Àpẹẹrẹ ni: 57 (a)(i) Àlàdé a ka jẹja ẹri (ii) Àlàdé á máa jẹja odò Ìyísódì gbólóhùn yìí ni: (b)(i) Àlàdé éè níí ka jẹja ẹri (ii) Àlàdé kò níí máa jẹ ẹja odò Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìbẹ̀rẹ̀ Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí èyí ti jẹ yọ ni: 58 (i) A tí a jọ lọ hí oko (ii) A ó tí jọ lọ sí oko Ìyísódì rẹ̀ ni 59 (i) Ẹ́ẹ̀ níí ti a jọ lọ hí oko (ii) A ò níí ti máa jọ lọ sí oko Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìparí Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìparí ti jẹ yọ nínu àsìkò ọjọ́-iwájú ni: 60 (a) (i) Olú a ti rẹ̀n (ii) Olú á ti rìn Ìyísódì gbólóhùn yìí ni: (b) (i) Olú éè tì níí rẹ̀n (ii) Olú kò tíì níí rìn Ìyísódì Atọ́ka Múùdù (Ojúṣe) Adéwọlé (1990:73-80) gbà pé múùdù jé ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀ri gírámà Yorùbá. Ó pín wọn sí oríṣìí mẹ́ta nípa wíwo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jẹ yọ: Ó pe àkọ́kọ́ ni èyí tó ń fi ṣiṣe é ṣe hàn (possibility); ó pe èkejì ní èyí tó ń fi gbígbààyè hàn (permission); ó pe ẹ̀kẹta ni èyí tó pọn dandan. Àwọn múùdù wọ̀nyí ni à ń dá pè ni ojúṣe wọ̀fún, àníyàn àti kànńpá lédè Yorùbá. Fábùnmi (1998:23-24) pè é ní Ojúṣe. Ìyísódì Ojúṣe Wọ̀fún Léè ni atóka ojúse wọ̀fún nínu ẸI. Fún àpẹẹrẹ: 61 (i) Olú léè jọba ùlú rẹ̀ (ii) Olú lè jọba ìlu re. Tí a bá yi atọ́ka ojúṣe yìí sódì, yóò di leè. Ée ni atọ́ka ìyísódì ojúṣe nínu ẸI. 62 (i) Olú éè leè jọba ùlú rẹ̀ (ii) Olú kò lè jọba ìlú rẹ̀ Ìyísódì Ojúṣe Kànńpá Gbẹẹ̀dọ̀ ni atọ́ka ojúṣe kànńpá nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ni: 63 (i) Olú gbẹẹ̀dọ̀ hùn (ii) Olú gbọdọ̀ sùn Ìyísódì rẹ̀ ni: 64 (i) Olú éè gbẹẹ̀dọ̀ hùn (ii) Olú kò gbọdọ̀ sùn Ìyísódì Ojúse Ànìyàn Àríyànjiyàn pọ̀ lóri ìsọ̀ri gírámà tí yóò wà nínu YA.Bámgbóṣé (1990) gbà pé atọ́ka àsìkò ọjọ́ iwájú ni yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀ bíi yó, ó, á. Fábùnmi (2001) ní tirè sàlàyé wí pé ojúse ni yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní Yorùbá tún máa ń lò wón láti fi tọ́ka sí àsìkò ọjọ́-iwájú. Oyèláràn (1982) nínu èro rẹ̀ kò fara mọ́ èro pé yóò jẹ́ atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú. Ó ni yóò máa ń ṣiṣẹ́ ibá-ìṣẹ̀lẹ̀, ò sì tún máa ń ṣiṣẹ́ ojúṣe nígbà mìíràn. Sàláwù (2005) ò gba yóò gẹ́gẹ́ bí atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú tàbí ojúṣe. Ó ní yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀ á, ó àti óó jẹ́ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àníyàn nínu YA. Adéwọlé (1988) ní tirè ṣe òrínkíniwín àlàyé láti fi ìdi rè múlẹ̀ pé atọ́ka múùdù ni yóò. Nítorí náà, a ó lo wúnrẹ̀n yóò gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àníyàn. Nínu ẸI, a ni atọ́ka ojúṣe àníyàn. Fún àpẹẹrẹ: 65 (i) Mà a jẹun nóko (ii) N ó jẹun lóko Ìyísódì rẹ̀ ni: 66 (i) Méè níí jẹun nóko (ii) N kò níí jẹun lóko/N kì yóò jẹun lóko Ìyísódì Odidi Gbòlòhún Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìbẹ̀rẹ iṣẹ́ yìí, a lè ṣe ìyísódì ẹyọ ọ̀rọ̀, a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun gbólóhùn, a sì tún lè ṣe ìyísódì odidi gbólóhùn pẹ̀lú. Bámgbóṣé (1990:217) sàlàyé pé ìyísódì odidi gbólóhùn ni èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ mọ wí pe ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ nínu gbólóhùn náà kò ṣẹlẹ̀ rárá. Ó ní: Tí gbólóhùn kò bá ní ju ẹyọ ọ̀rọ̀-ìṣe kan lọ nínu àpólà-ìṣe…, ìyísódì odidi gbólóhùn nìkan ni a lè ṣe fún un. Ṣùgbọ́n, tí ọ̀rọ̀-ìṣe bá ju ọ̀kan, tàbí tí àpólà-ìṣe bá ní fọ́nrán tí ó ju ọ̀kan lọ, a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tàbí ti odidi gbólóhùn. Ìyísódì Gbólóhùn Àlàyé Gbólóhùn àlàyé ni a máa ń lò láti fi sọ bí nǹkan bá ti rí. Bámgbọ́sé (1990:183) sọ wí pé: Tí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ bá fẹ́ẹ ṣe ìròyìn fún olùgbọ́, gbólóhùn yìí ni yóò lo. Gbólóhùn-kí-gbólóhùn tí kò bá jẹ́ ti ìbéèrè tàbí ti àṣẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ gbólóhùn àlàyé. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn àlàyé ni: 67 (i) Mo fọfọ̀ múẹ̀n naàná (ii) Mo sọ̀rọ̀ mìíràn lánàá 68 (i) Olú gbé uṣu wá í ọja (ii) Olú gbé iṣu wá sí ọjà Ìyísódì (67) ni (69), nígbà tí ìyísódì (68) ni (70) 69 (i) Méè fọfọ̀ múẹ̀n naàná (ii) N kò sọ̀rọ̀ mìíràn lánàá 70 (i) Olú éè gbé usu wá í ọjà (ii) Olú kò gbé iṣu wá sí ọjà Ìyísódì Gbólóhùn Àṣẹ Máà ni wúnrẹ̀n tí ẸI ń lò fún ìyísódì gbólóhùn àṣẹ. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn àṣe ni 71 (i) Háré wá! (ii) Sáré wá! 72 (i) Ka lọ! (ii) Máa lọ! Ìyísódì (71) yóò fún wa ni (73) 73 (i) Máà háré wá (ii) Má sáré wá Tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì (72), a ó yọ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ atẹ́rẹrẹ ka kùrò, a ó sì lo atọ́ka ìyísódì máà dípò rẹ̀. Ìyísódì (72) yóò yọrí sí (74) 74 (i) Máà lọ (ii) Má lọ Ìyísódì Gbólóhùn Ìbéèrè Bámgbóṣé (1990:183-186) ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lóri ọ̀nà tí a máa ń gbà ṣe ìbéèrè nínu ède Yorùbá. Ó ní ọ̀nà tí à ń gbà ṣe èyí ni pé kí á lo wúnrẹ̀n ìbéèrè nínu gbólóhùn. A ó ṣe àgbéyẹ̀wò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan àti bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ pẹ̀lú wọn. Gbólóhùn Ìbéèrè tí ó ń lo Atọ́nà Gbólóhùn Ṣé ni ẸI máa ń lò gẹ́gẹ́ bí atọ́nà gbólóhùn láti fì ṣe ìbéèrè bẹ́ẹ̀-ni-bẹ́ẹ̀-kọ. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn ìbéèrè oní-atọ́nà gbólóhùn ni: ẸI YA 75 (i) Ṣé Olú wúlí? (ii) Sé Olú wálé? 76 (i) Ṣé Dàda ti hanghó? (ii) Ṣé Dàda ti sanwó? Éè ni ẸI ń lò láti fi ṣe ìyísódì ìṣẹ̀lẹ̀ inú gbólóhùn ìbéèrè náà. Fún àpẹẹrẹ 77 (i) Ṣé Olú éè wúlé? (ii) Ṣé Olú kò wálé? 78 (i) Ṣé Dàda éè ti hanghó? (ii) Ṣé Dàda kò tíì sanwó? A ó ṣe àkíyèsí wí pé atọ́ka ìyísódí yìí máa ń jẹ yọ nípa pé kí á fi sí inú gbólóhùn lẹ́yìn Olúwà. Gbólóhùn Ìbéèrè to ní Ọ̀rọ̀-orúkọ Aṣèbéèrè Bámgbósé (1990:184) ṣe àlàyé pé nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ ni a ti máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ aṣèbéèrè. Ó ní a lè dá wọn tò gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí kí á fi wọ́n ṣe ẹ̀yán fún ọ̀rọ̀-orúkọ mìíràn. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn yìí ni: 79 (a) (i) kí àn án jẹẹ? (ii) Kí ni wọ́n jẹ (b) (i) Kíì yi we fẹ́ o? (ii) Èwo lẹ fẹ́ o? (d) (i) Kéèlú àn án gba a? (ii) Èló ni wọ́n gbà? A lè ṣe ìyísódì ìṣẹ̀lẹ̀ inú gbólóhùn ìbéèrè wọ̀nyí. Ìyísódì (79 a-d) ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé ni: 80 (a) (i) Kí án àn jẹ ẹ? (ii) Kí ni wọn ò jẹ? (b) (i) Kíì yi wéè fẹ́ o? (ii) Èwo lẹ ò fẹ́ o? (d) (i) Kéèlú án àn gba a? (ii) Èló ni wọn ò gbà? Gbólóhùn Ìbéèrè Ọlọ́rọ̀ọ̀ṣe Aṣèbéèrè Han àti kẹ ni ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ìlo wọn nínu gbólóhùn ni: ẸI YA 81 (i) Ọmàn mi han? (ii) Ọmọ mi dà? 82 (i) Aṣọ̀ mi kẹ? (ii) Aṣọ mi ńkọ́? A kò le ṣe ìyísódì gbólóhùn ọlọ́ròòṣe aṣèbéèrè. Fún àpẹẹrẹ: ẸI YA 83 (i) *Ọmàn mi éè han? (ii) *Ọmọ mi kò dà? 84 (i) *Aṣọ mi éè kẹ? (ii) *Aṣọ mi kò ńkọ́? Ìyísódì Òǹkà Ẹ̀ka-Èdè Ìkálẹ̀ Ohun tí a fẹ́ ṣe nínu abala yìí ni ṣíṣe àfihàn ipa ti ìyísódì ní lóri òǹkà ẸI. Ohun tó jẹ wá lógún ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí à ń gbà yí àwọn òǹkà sódì. Ọ̀kan lára àwọn àtúnpín-sí-ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ Bámgbóṣé (1990:97) ni ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà. Ó ni ọ̀rọ̀-orúkọ àṣeékà ni èyí tí a lè lò pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òǹkà nítorí pe irú ọ̀rọ̀-orúkọ bẹ́ẹ̀ ṣe é kà. Ní ìbamu pẹ̀lú èro Bámgbóṣé yìí, tí a bá lo ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà pẹ̀lú ọ̀rọ̀-òǹkà papọ̀, yóò fún wa ní àpólà-orúkọ. Àtúpalẹ̀ irúfé àpólà-orúkọ yìí ni orí (tíí ṣe ọ̀rọ̀-orúkọ) àti ẹ̀yan rẹ̀ (ọ̀rọ̀ òǹkà náà). Irúfẹ́ ẹ̀yán yìí ni Bámgbóṣé pè ní ẹ̀yán aṣòǹkà. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ àpólà-orúkọ yìí ni: 85 (a) (i) Ọman mẹ́ẹ̀fà (ii) Ọmọ mẹ́fà (b) (i) Ulí mẹ́ẹ̀tàdínógún (ii) Ilé mẹ́tàdínlógún (d) (i) Bàtà maàdọ́gbọ̀n (ii) Bàtà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n Ìjẹyọ àwọn àpólà-orúkọ yìí nínu gbólóhùn ni: 86 (a) (i) Mọ rí ọman mẹ́ẹ̀fà (ii) Mo rí ọmọ mẹ́fà (b) (i) Mọ kọ́ ulí mẹ́ẹ̀tàdínógún (ii) Mo ko ilé mẹ́tàdínlógún. (d) (i) Mọ ra bàtà maàdọ́gbọ̀n (ii) Mo ra bàtà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣaájú ní 3.3.4, wí pé tí a bá fẹ́ yí ẹ̀yán sódì, nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́, a máa ń sọ ẹ̀yán náà di awẹ́ gbólóhùn asàpèjúwe. Ìgbésè yìí máa ń wáyé nínu ìyísódì òǹkà. Yí ní atọ́ka awẹ́-gbólóhùn-asàpèjúwe nínu ẸI. Ée ṣe ni atọ́ka ìyisódì èyán asòǹka nínu ẸI. Ìyísòdì ẹ̀yán asòǹkà nínu gbólóhùn (86 a-d) yóò fún wa ni (87 a-d) 87 (a) (i) Ọmàn yí mọ rí, ée ṣe mẹ́ẹ̀fà (ii) Mẹ́fà kọ́ ni ọmọ tí mo rí tàbí Ọmọ tì mo rí, kì í ṣe mẹ́fà (b) (i) Ulí yí mọ kọ́, ée ṣe (ii) Mẹ́tàdínlógún kọ́ ni mẹ́ẹ̀tadínógún ilé tí mo kọ́ tàbí Ilé tí mo kọ́ kì í ṣe mẹ́tàdínlógun (d) (i) Bàtà yí mọ rà, ée ṣe (ii) Mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kọ́ ni bàtà tí maàdọ́gbọ̀n mo rà tàbí Bàtà tí mo rà kì í ṣe mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n A ó ṣe àkíyèsí wí pé ọ̀nà méjì ni YA lè gbà ṣe ìyísódì ẹ̀yán àsòǹkà, ṣùgbọ́n ọ̀nà kan ṣoṣo ni ẸI ń gbà ṣe ìyísódì èyí. Bámgbóṣé (1990:129) ṣe àkíyèsí irúfé àpólà-orúkọ kan to pè ní àpólà-orúkọ agérí. Irúfẹ àpólà-orúkọ yìí máa ń sáábà wáyé nínu àpólà-orúkọ tí ọ̀rọ̀ òǹkà jẹ́ ẹ̀yan rẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ àpólà-orúkọ yìí ni àbọ̀ àwọn gbólóhùn ìsàlẹ̀ yìí: 88 (i) Mọ jẹ mẹ́ẹ̀ghwá (ii) Mo jẹ mẹ́wàá 89 (i) Bọ́lá mú ọgọ́ọ̀fà (ii) Bólá mú ọgọ́fà A ó ṣe àkíyèsí pé ẹ̀yán asòǹka nìkan ló dúró gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ gbólóhùn òkè wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n sá, kì í ṣe pé àpólà-orúkọ náà kò ní orí; mọ̀ọ́nú ni orí àpólà náà, ó sì yé àwọn méjéèji tó bá ń tàkurọ̀sọ. Ée ṣe ni a fi máa ń yí irúfẹ́ àpólà-orúkọ agérí wọ̀nyí nínu ẸI. Ìyísódì ọ̀rọ̀ òǹkà nínu gbólóhùn (88) àti (89) ni: 90 (i) Ée ṣe mẹ́ẹ̀ghwá mọ jẹ (ii) Kì í ṣe mẹ́wàá ni mo jẹ tàbí Mẹ́wàá kọ́ ni mo jẹ 91 (i) Ée ṣe ọgọ́ọ̀fà Bọ́lá mu (ii) kì í ṣe ọgọ́fà ni Bólá mú tàbí Ọgọ́fà kọ́ ni Bọ́lá mu Ìgúnlẹ̀ Nínu orí kẹta yìí, a ti gbìyànjú láti ṣe àgbékalẹ̀ bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ nínu ẸI. A ṣe àkíyèsí onírúurú ìhun tí ìyísódì ti ń jẹ yọ nínu ẸI. A jẹ́ kó di mímọ̀ pé a lè ṣe ìyísódì eyọ ọ̀rọ̀; a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun gbólóhùn, a sì lè ṣe ìyísódì odidi gbólóhùn. A tún ṣe àgbéyẹ̀wò ìyísódì àsìkò, ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àti ojúṣe nínu ẸI. Lẹ́yìn èyí, ọwọ́jà iṣẹ́ yìí dé àgbéyẹ̀wò òǹkà ẸI. A ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ òǹkà náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán aṣòǹkà, a sì ṣe àfihàn bí a ṣe ń ṣe ìyísódì òǹkà ẸI.
Ìyísódì nínú Ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3276
3276
Ìmò Ìṣírò Oju Ewe Imo Isiro Ìmọ̀ Ìsirì je eyi t'on je mo nipa ọ̀pọ̀iye (quantity), nipa òpó (structure), nipa iyipada (change) ati nipa ààyè (space). Idagbasoke imo Isiro wa nipa lilo àfòyemọ̀ọ́ (abstraction) ati Ọgọ́bn ìrọ̀nú, pelu onka, isesiro, wiwon ati nipa fi fi eto s'agbeyewo bi awon ohun se ri (shapes) ati bi won se n gbera (motion). Eyi ni awon Onimo Isiro n gbeyewo, ero won ni lati wa aba tuntun, ki won o si fi otoo re mule pelu itumo yekeyeke. A n lo Imo Isiro ka kiri agbaye ni opolopo ona ninu Imo Sayensi, Imo Ise Ero, Imo Iwosan, ati Imo Oro Okowo. Bi a se n lo imo Isiro bo si apa eyi ti a n pe ni Imo Isiro Lilo (Applied Mathematics). Apa keji Imo Isiro ni a mo si Imo Isiro Ogidi. Eyi je mo eko imo isiro to ko ti ni ilo kankan bo tileje pe o se se ki a wa ilo fun ni eyinwa ola.
Ìmò Ìṣírò
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3278
3278
Ìmò Ìṣirò Oju Ewe Imo Isiro Ìmọ̀ Ìsirò jẹ́ èyí t'on jẹ mo nipa ọ̀pọ̀iye (quantity), nipa òpó (structure), nipa iyipada (change) ati nipa ààyè (space). Idagbasoke imo Isiro wa nipa lilo àfòyemọ̀ọ́ (abstraction) ati Ọgbọ́n ìrọ̀nú, pelu onka, isesiro, wíwọ̀n ati nipa fi fi eto s'agbeyewo bi awon ohun se ri (shapes) ati bi won se n gbera (motion). Eyi ni awon Onimo Isiro n gbeyewo, ero won ni lati wa aba tuntun, ki won o si fi ootọ́ re mulẹ̀ pelu itumo yekeyeke. A n lo Imo Isiro ka kiri agbaye ni opolopo ona ninu Imo Sayensi, Imo Ise Ero, Imo Iwosan, ati Imo Oro Okowo. Bi a se n lo imo Isiro bo si apa eyi ti a n pe ni Imo Isiro Oníwúlò (Applied Mathematics). Apa keji Imo Isiro ni a mo si Imo Isiro Ogidi. Eyi je mo eko imo isiro to ko ti ni ilo kankan bo tileje pe o se se ki a wa ilo fun ni eyinwa ola. Awon Orisirisi Nomba ti o wa Awon Eka Imo Isiro
Ìmò Ìṣirò
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3279
3279
Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Jeremiah Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tí a bí ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta (Ẹrẹ́nà) ọdún 1909, ti o sí ku lọjọ́ kẹ́sàn-án oṣù karùn-ún (Èbìbí) ọdún 1987, jẹ́ olósèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ẹ̀yà Yorùbá. Awólọ́wọ̀ jẹ́ olórí fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá àti ọ̀kan nínú àwọn olóṣèlú pàtàkì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìgbà èwe. A bí i ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún 1909 ní Ìkẹ́nnẹ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn lónìí. Ọmọ àgbẹ̀ tí ó fi iṣẹ́ àti oògùn ìṣẹ́ sọ ara rẹ̀ di ọ̀mọ̀wé, Awólọ́wọ̀ lọ ilé ẹ̀kọ́ Anglican àti Methodist ní Ìkẹ́nnẹ́ àti sí Baptist Boys' High School ní Abẹ́òkúta. Lẹ́yìn rẹ̀ ó lọ sí Wesley College ní Ìbàdàn tí ó fi ìgbà kan jẹ́ olú-ìlú Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà láti ba di Olùko. Ní ọdún 1934 , ó di olùtajà àti oníròyìn. Ó ṣe olùdarí àti alákòóso Ẹgbẹ́ Olùtajà Àwọn Ọmọ Nàìjíríà (Nigerian Produce Traders Association) àti akọ̀wé gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Àwọn Awakọ̀ Ìgbẹ́rù Ọmọ Ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigerian Motor Transport Union). Awólọ́wọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì gba ìwé ẹ̀rí kékeré ní ọdún 1939, kí ó tó lọ láti gba ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ gíga nínú ìmọ̀ owó ní ọdún 1944. Ìgbà yìí náà ló tún jẹ́ olóòtú fún ìwé ìròyìn Òṣìṣẹ́ Ọmọ Ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigerian Workers). Ní ọdún 1940 ó di akọ̀wé Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigerian Youth Movement) ẹ̀ka Ìbàdàn, ibi ipò yìí ni ó ti ṣolórí ìtiraka láti ṣe àtúnṣe Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Ìdámọ̀ràn Fún Àwọn Ọmọ Ìbàdàn (Ìbàdàn Native Authority Advisory Board) ní ọdún 1942. Ìṣèlú. Ní ọdún 1944 ó lọ sí ìlú Lọ́ńdọ́nù láki kọ́ ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ òfin bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá Ẹgbẹ́ Ọmọ Odùduwà sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1947 ó darí padà wálé láti wá di agbẹjọ́rò àti akọ̀wé àgbà fún Ọmọ Ẹgbẹ́ Odùduwà. Lẹ́yìn ọdún méjì, Awólọ́wọ̀ àti àwọn aṣíwájú Yorùbá yòókù dá ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group sílẹ̀, èyí tí ó borí nínú ìbò ọdún 1951 ní Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà. Láàárín ọdún 1951-54 Awólọ́wọ̀ jẹ́ Alákòóso Fún Iṣẹ́ Ìjọba àti Ìjọba Ìbílẹ̀, ó sì di Olórí Ìjọba Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1954 lẹ́yìn àtúnkọ Ìwé Ìgbépapọ̀ Àti Òfin (constitution).Gẹ́gẹ́ bí Olórí Ìjọba Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà, Awólọ́wọ̀ dá ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ fún gbogbo ọ̀dọ́ láti rí i pé mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà gba le ka. Jàgídíjàgan ní apá ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Nígbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbòmìnira ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá ọdún 1960, Awólọ́wọ̀ di Olórí Ẹgbẹ́ Alátakò (Opposition Leader) sí ìjọba Abubakar Tafawa Balewa àti Ààrẹ Nnamdi Azikiwe ní Ìlú Èkó. Àìṣọ̀kan tó wà láàárín òun àti Samuel Ládòkè Akíntọ́lá tó dípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí fìdí hẹ Olórí Ìjọba ní Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn mú ni ó dá fàá ká ja tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1962. Ní oṣù kọkànlá ọdún yìí, Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà fi ẹ̀sùn kan Awólọ́wọ̀ wí pé ó dìtẹ̀ láti dojú ìjọba bolẹ̀. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ó tó oṣù mọ́kànlá, ilé-ẹjọ́ dá Awólọ́wọ̀ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n lẹ́bi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀, wọ́n sì rán wọn lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Ọdún mẹ́ta péré ni ó lo ní ẹ̀wọ̀n ní ìlú Kàlàbá tí ìjọba ológun Yakubu Gowon fi dá sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 1966. Lẹ́yìn èyí Awólọ́wọ̀ di Alákòóso Ìjọba Àpapọ̀ fún Ọrọ̀ Okòwò. Ní ọdún 1979 Awólọ́wọ̀ dá ẹgbẹ́ òṣèlú kan, Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ìmọ́lẹ̀, sílẹ̀. Aláìsí. Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ṣaláìsí ní ọjọ́ àìkú ọjọ́ kẹsàn-án oṣù karùn-ún ọdún 1987 ní ìlú Ìkẹ́nnẹ́. Lẹ́yìn ikú Awólọ́wọ̀ Ìjọba Àpapọ̀ yí orúkọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ilé-Ifẹ̀ padà sí Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwòrán rẹ̀ wà lórí owó Ọgọ́rùn-ún náírà fún ìṣẹ̀yẹ gbogbo ohun tó ṣe fún ìdàgbàsókè ilẹ̀ Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.
Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3280
3280
Àwọn Ìpínlẹ̀ Nàìjíríà Awon Ìpínlẹ̀ Orile ede Naijiria je merindinlogoji(36): Agbegbe:
Àwọn Ìpínlẹ̀ Nàìjíríà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3282
3282
Awon Nomba Akoko
Awon Nomba Akoko
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3291
3291
28 March 27 March | 28 March | 29 March <ns>10</ns> <id>10812</id> <revision> <id>538182</id> <parentid>122275</parentid> <timestamp>2020-07-24T11:27:09Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <minor /> <comment>Dáàbò bòó "" ([Àtúnṣe=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú) [Ìyípò=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú))</comment> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Ọjọ́ 28 Oṣù Kẹta tabi 28 March jẹ́ ọjọ́
28 March
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3294
3294
Àwọn àdúgbò ìlú Àkúrẹ́ 1. Àdégbọlá :- Ó jẹ́ ibi tí àwọn Ọlọ́lá má gbé jù ní ayé àtijọ́. Ó sí tún jẹ́ orúkọ ènìyàn. 2. Ìkóyí :- Ó jẹ́ ibi tí wọn ti má kó àwọn ìkó jo sí 3. Ayédùn :- Itúmọ̀ rẹ nipé ó jẹ́ orúkọ Akọni kan ní ìlú. Ẹni yìí ní ó má jagun fún nígbà náà 4. Òkè Àró:- Jẹ́ àwọn àdúgbò tí má sé ayẹyẹ Ọdún bí égún àti bẹ́ẹ̀ lọ ní ayé atijó. 5. Ìsólọ̀ :- Ó jẹ́ Ọba ti ogun lẹ́ wá sí Àkúrẹ́ ibi tí ó tẹ́ dó sí ni à pè ní ìsọ́lọ́, 6. Ẹrẹ̀kẹ̀sán:- Ó jẹ́ orukọ́ ọjá Ọba Àkúrẹ́. Ọjá yìí nìkan ni Ọba tí má se ọdún òlósùnta fún ọjọ́ méje. 7. Gbogí:- Ó jẹ ibi tí wọn tí sé orò omi yèyé láyé àtijọ́, ó sí tún jẹ́ aginjù tí àwọn ẹranko búburú má gbé. 8. Ẹringbo:- Ibẹ̀ ní wọn ti má sin orísìíríṣìí àwọn ẹranko tí ó lágbára láwùjọ. 9. Ìjọ̀kà:- Jẹ́ Ọ̀kan lárà àwọn orúkọ̀ ilẹ̀-iwé girama tí ó wá, ìdí níyí tí wọn fí pé orúkọ àdúgbò náà ní ìjọ̀kà 10. Olúwàlúyí :- jẹ́ ibi tí ènìyàn ńlá kan tẹ́dó sí 11. síjúwádé:- Jẹ́ ibi tí ọmọ-ọba Ilé-Ifẹ́ tẹ́dó sí, orúkọ́ rẹ si ni wọn fí pé. 12. Osínlé :- Ibẹ́ jẹ́ ibi tí àwọn òrìṣà sínlẹ̀ sí tàbí tí wọn rí sí. Ibẹ̀ sin i wọn wọlẹ̀ sí 13. Okúntá eléńlá :- Ó jẹ́ ibi tí òkúnta ńlá ńlá pó sí.’ 14. Ìrò – Ó jẹ́ ibi tí wọn tí má sé orò láyé àtijọ́. 15. Òkè ìjẹ́bú:- Ibi tí òkè pọ̀ sí jù ni Àkúrẹ́ ìdí níyí tí wọn fí pé ní ibi tí òkè fi ìdí sí 16. Ìdí àágbá:-jẹ ibi tí wọn má kó goro jọ sí. 17. Ọjà osódí:- jẹ́ ibi tí àwọn àgbààgbà olóyé ìlú má gbé láyé àtijọ́ ibẹ sì ni wọn tí má ṣe ìpàdé fún ètó ìlú. 18. Alágbàká:- jẹ Ibi tí omi ÀKÚRẸ̀ tí pín sí yẹ́lẹ́yẹ́lẹ́, ibẹ̀ ní orirún omi tí sàn lọ si oríṣìíríṣìí ọ̀nà. 19. Ijọmu :- Ó jẹ́ orúkọ́ ibi tí ìjọ kọ́kọ́ tí bẹ́rẹ̀, ìdí nìyí tí wọn fí pé ní ìjọmu. 20. Àrárọ́mì:- Ibẹ̀ ní àrálépó kọ́kọ́ tẹ̀dó sí. Ó sí tún jẹ ibi tí ó gba jù ní Àkúrẹ́. 21. Àlá:- jẹ ibi tí orirún omi ÀKÚRẸ́ ibẹ̀ sí ni omi mejiji Àkúrẹ́ tí pádé. 22. Odò ìjọ́kà:- ò jẹ̀ orúkọ́ àdúgbó tí ó lágbárá, ibẹ̀ sí ní àwọn àkínkánjú alejo ma tẹ̀dó sí 23. Ọba Adésida road:- Jẹ orúkọ ọba Ìlú Àkùrẹ́. 24. Ìlésá garage:- jẹ́ ibi tí ó já sí’ ọ̀nà ilésá. 25. Owódé :- jẹ́ ibi tí ó gbájúmọ́ ibẹ̀ sí ní ọ̀dọ́ ńgbé jù. 26. Isìnkàn:- Jẹ́ ibi tí wọn má sín òkú àwọn olóyé ńlá ńlá sí ní ayé àtijọ́. 27. Ondo road-Ó jẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ondo. 28. Orítáọ́bẹ́lẹ́:- Ó jẹ́ orítá mẹta ó sí tún jásí ibi tí ilé ẹ́rọ gbóhúngbáróyè Àkúré. 29. Iròwò:- Jẹ́ orúkọ Ilú kekéré kan láyé àtijọ ìlú yìí wà lára Àkúrẹ́. 30. Àrákàlẹ́:- Jẹ́ òkìtí Ibẹ̀ ni wọn ti rí àwọn ènìyàn tí ó dí òkìtì láyé àtijọ́. Ibẹ̀ sí ní wọn ti má jẹ́ oyè jù.
Àwọn àdúgbò ìlú Àkúrẹ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3296
3296
Àdúgbò Oyé-Èkìtì 1. Ijisẹ:- Àdúgbò ti a n pen i Ijisẹ ni o fẹ ilu Ọye do lati Ile Ifẹ wa. Wọn pa erin ibi ti ẹrin náà ku si iba ni wọn pe ni atẹba ẹni to pa erin náà ni ọlọta aburo ijise ibi ti wọn pa erin náà si ni wọn pe ni ijisẹ. Ijisẹ lo pa àwọn ara Ọyẹ wa lati ile ifẹ pe wọn ti ri ibi tí wọn magbe. Ijisẹ ni orisu ilu Ọyẹ lati ile-ifẹ wa. 2. Ọgbọ mẹta :- Ọ̀nà mẹta ni àwọn ara ọgbọ mẹta ti si wa ki wọn to tẹ̀dó si ilu Ọyẹ. 3. Ọmọdọwa:- Ibi jẹ agbegbe ti ọba ilu maa n gbe. 4. Ire:- Aburo Oloye ni Àdúgbò to wa ni Iyeni, Ọde ni se idi ti o fi ń de ade ogun 5. Ulọdo:- Ibe ni wọn ti se ọdẹ 6. Ilẹsẹ:- Àdúgbò yi kọ de igọsi ko si de ilu Ọyẹ wọn wa ni arin meji. 7. Ilẹdara:- Orukọ ti àdúgbò yi jẹ wa lati ile-ifẹ wa ni wọn tun jẹ ni ìgba ti wọn de ilu Ọyẹ. 8. Odo:- ibi ti àdúgbò yi deto si je egbe odọ. 9. Iwaro:- Oni imọlẹ kan ti wọn máa ń jo ni ibẹ ìdí ti wọn fi pe ni ìwarọ ni yẹn. 10. Ijagun:- Awọn ti on jagun ni wọn gbe ni àdúgbò yìi. 11. Oke-Ọfa:- Apa oke ni àdúgbo naa wa 12. Ayegbaju:- Wọn tun pe àdúgbò yi ni odo-oje nitori pe ẹgbẹ odo ni ilu náà wa. 13. Ẹgbẹ:- Ọ̀nà mẹta ni àwọn ara ẹgbẹ ti si wa ki wọn to wa si mọ àwọn ara ijisẹ. 14. Ijagẹmọ:- Àwọn ara àdúgbò yin i a mọ si ologun tàbí onija láti ìle-ifẹ wa. Igbati wọn de ilu Ọyẹ wọn sit un pe wọn ni ijagẹmọ nitorí ija wọn. 15. Ilogbo:- àdúgbo yi jẹ pàtàkì ni ìlú Ọye, Ijalọ po púpọ̀ si arin wọn itorí náà ni wọn ni ọmọ orin yọyọ ilugbo. 16. Ilupeju:- Ireko ilu Ọyẹ ni, àwọn ni wọn máa ń sin ọba Ọyẹ wọn máa ń pe jọ si ilu Ọyẹ láti ba ọba ji roro, ìdí ti wọn fi pe wọn ni ilupeju. 17. Orisunmíbare:- Wọn jẹ àdúgbò ti o ko owo ati oríṣìíríṣìí dukiya wa si ilu Ọyẹ, àwọn ara Ọyẹ ri pe ọlọrọ ni wọn jẹ ni wọn se pe wọn ni orísunmibare. 18. Esọ sin :- àdúgbò yi ti wọn pe ni esọ sin jẹ ara àwọn ti ogun ko wa lati ile- ifẹ. 19. Ile ya o :- Ogun ko wọn láti Iyao wa si ìlú Ọyẹ ti wọn wa ya ile gbe ni ilu Ọyẹ ni wọn fi ń pe ni ile-yao. 20. Ileesa:- Wọn jẹ àdúgbò to ji náà si ìlú nitorí wọn ko ogùn ba ilu púpọ̀. 21. Ilẹmọ:- O wa lati ile-ifẹ wa si ilu Ọyẹ wọn si kin jẹ iyọ ni àdúgbọ̀ yi. 22. Ipamọ:- wọn jẹ ọmọ ìya si ilẹmọ, wọn jẹ ara ilẹmọ ìdí ti wọn fi ń pe ni ilẹmọ ni yen. 23. Idọfin:- Ọ̀nà mẹrin ni àwọn ara àdúgbò yi ti si wa kì wọn to para po wa si Ijisẹ. 24. Irare:- Ilare ni wọn jẹ ni ilẹ-Ifẹ wọn wa ń jẹ́ irare ni ìgbati wọn de ilu Ọyẹ. 25. Oke ìyin-Araroni:- Ọ̀nà mẹta ni wọn ti si wa 26. Iyeni:- jẹ àdúgbò ti wọn ti jẹ orogun ni ilu Ọyé. 27. Asara:- àdúgbò yìí jẹ ibi àwọn ìransẹ ọba ń gbe. 28. Oloyagba:- Iya gba ni ogun tí ki wọn wa sí ilu Ọyẹ ni wọn se ń jẹ oloyagbe. 29. Ibẹru:- Ọlota ni aburo Ijise lati ile ifẹ wa nígbati wọn de Ọyẹ iberu ati Ijisẹ wa yapa o sit un jẹ àdúgbò ti o bẹru ogun tàbí ija púpọ̀. 30. Imijẹ:- Àdúgbò yii wa láti ilu Itapu iṣẹ ọdẹ ni baba ń la wa n se. Iṣẹ yii lo se wa si ilu Ọyẹ ìdí ti wọn fi tẹ̀dó si ìlú Ọyẹ ni èyí.
Àdúgbò Oyé-Èkìtì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3298
3298
Àdúgbò Àgọ́-Ìwòyè 1. Ìsámùró:- Babaláwo kan wà ní àdúgbò yì tí orúkọ rẹ ń jẹ́ ìsà, ó má rń gba àwọn Àbíkú ọmọ, o máa ń mú wọn dúró láti má lè jẹ́ kí wọ́n kú. Orúkọ Bàbá yì ni wọ́n fi wá ń pé àdúgbó yí ní ìsámùró. 2. Ìdóbì:- A má ń ta ọbà ní àdúgbò yí. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ún pè ní ìdóbì. 3. Àyégbàmí:- Ọmọ ọkùnrin kan tí ó kọ́kọ́ dé àdúgbò yí ní ó ń jẹ́ àyégbàmí. Ìdí nìyí tí a fi n pè bẹ́ 4. Òshọ́ òsì:- Orúkọ olóyè ìlú ni òshóòsì, oyè osì ìlú ni ó jẹ, ìdí nìyí tí a fi ń pè àgbolé yì ní òshóòsì 5. Olóòlù:- Aṣọ òkè ni wọ́n máa ń lù ní agbolé yìí, ìdí nì yí tí wọ́n fi ń pe agbolé yìí ní olóòlù. 6. Akadi eredo:- Agbolé yìí ni agbolé ẹni tí ó kọ́kọ́ jẹ oyẹ (èbùmàrè) ní ìlú Àgó ìwòyè, ìdí nì yí tí a fi ń pe agbolé yìí ní Akádì eredò. 7. Ẹdùwẹ:- Agbolé yì jẹ́ agbolé alágẹmọ, ẹni tí ó sì má ń gbé agẹmọ yì má ń dirun sórí bí ogbe orí àkùkọ adìẹ. Ìdí nìyí tí a fi ń pe agbolé yì ní Edùwe. 8. Bàtàdìran:- Ẹni tí o kọkọ tẹ̀dó si agbo-ile yi aso bata ni o n se pẹ̀lú ẹbi rẹ titi di asiko yi, ìdí niyi ti a fi pe agbole yii ni Batadiran. 9. Agbélékalè bí ère:- Agbolé yìí lati kọ́kọ́ kó ilé tó lẹ́rà jùlọ ní ìlú yìí, ìdí nì yí tí a fí ń pe agbolé yì ní Agbélékalẹ̀ bí ère. 10. Onàbámiró:- Ọ̀gbẹ́ni ọ̀nàbámiró jẹ́ ọ̀mọ̀wé, ó wà lárà àwọn tí ó gbé Àgó-Ìwòyè sókè de ini tí ó wà lónì yìí. Ìdí nì yí tí a fi ń fi orúkọ rẹ̀ pe Agbolé yìí. 11. Dòdùnmú:- Okunrin olukọ kan (teacher) ni o kọkọ wa si àdúgbò yi, ìdí níyi ti a fi ń pe ni dosunmu. 12. Olówó Iranrìn:- Okùnrin kan wà tí óun tá Ianrin ní àdúgbò yí láti bí ọdún pípẹ́ sẹ́yìn, ó sì ti se nkan rere ní ìdí isẹ́ yìí, ìdí nìyí tí a fí ń pé olówó iranrìn. 13. Olópò mérin:- Òpó mẹ́rin kan wà ní àdúgbò yí láti ọdun pípẹ́ wá títí di òní, ìdí nì yí tí a se ń fi orúkọ rẹ̀ pe àdúgbò yí bayi olópò mẹ́rin. 14. Ìmosù:- Osù ni isé tí àwọn ara àdúgbò yí yàn láye láti ọdún pípẹ́ wá títí di òní olónì, ìdí nìyí tí a fi ń pe àdúgbò yí ní Ìmosù. 15. Orogunebi:- Ọkùnrin kan tí ó ní ta ògùn tí ó sì kó ilé ni a n fí ilé rẹ̀ pe àdúgbò yí. 16. Oyinkìńkorò:- Ilé olóyè agẹmọ kan ni ó wà ní agbolé yìí, orúkọ rẹ̀ ni wọ́n sì fi ń pe agbolé yìí. 17. Obamijasi:- Àwọn agbo ilé méjì jà du oyè ọba, agbolé baálẹ̀ ato àti agbo ilé odùdányà, oyè yí wá jámọ́. 18. Bámè ato:- Agbolé èyí ní wọ́n ti kọ́kọ́ jẹ baálè ní ìlú Àgọ́ Ìwòyè (Baálè ató), Orúkọ Baálè yí nì asì fí ń pé agbolé yìí títí di òní olónìí. 19. Opopona ọja:- Inu agbole yi ni o ja ńlá kan wa ìdí niyi ti a fi n pe agbole náà ni opopona ọjà. 20. okenugbo:- Àdúgbò òkènúgbó jẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú kan tí à ń pè ní òkénúgbọ́n láti inú ìlú Àgó ìwòyè. Ọ̀nà yí ni wọ́n fi pe àdúgbò. 21. Ajọbì láwé:- Orúkọ àwọn ẹbi kan nìyí wọ́n kó ilé papọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn, wọ́n àsi ń pe àdúgbò náà ní ajọbì láre. 22. Pàsedà:- Ògbẹ́ni passedà ní ilé-ìwé kan ní àdúgbò yí orúkọ ilé ìwé yìí ni “ọmọ-Edumare Model School” inú àdúgbò pàsedà lọ́nà. 23. Ìtamẹ́rin:- Ilé ìwé kan wà ní àdúgbò yí tí à ń pé ni Ìta mẹ́rin high school. Ìdí nìyí tí a fi ń pé àdúgbò yí ní ìtamẹ́rin. 24. Ìdodẹ̀:- Àgbolè yìí jẹ́ bi tí igi obì wà ìdí èyí ni wọ́n fi pè ní ìdobì.
Àdúgbò Àgọ́-Ìwòyè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3302
3302
29 March 28 March | 29 March | 30 March <ns>10</ns> <id>10812</id> <revision> <id>538182</id> <parentid>122275</parentid> <timestamp>2020-07-24T11:27:09Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <minor /> <comment>Dáàbò bòó "" ([Àtúnṣe=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú) [Ìyípò=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú))</comment> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Ọjọ́ 29 Oṣù Kẹta tabi 29 March jẹ́ ọjọ́
29 March
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3317
3317
31 March 30 March | 31 March | 1 April <ns>10</ns> <id>10812</id> <revision> <id>538182</id> <parentid>122275</parentid> <timestamp>2020-07-24T11:27:09Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <minor /> <comment>Dáàbò bòó "" ([Àtúnṣe=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú) [Ìyípò=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú))</comment> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Ọjọ́ 31 Oṣù Kẹta tabi 31 March jẹ́ ọjọ́
31 March
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3321
3321
1 April 31 March | 1 April | 2 April <ns>10</ns> <id>10812</id> <revision> <id>538182</id> <parentid>122275</parentid> <timestamp>2020-07-24T11:27:09Z</timestamp> <contributor> <username>Demmy</username> <id>193</id> </contributor> <minor /> <comment>Dáàbò bòó "" ([Àtúnṣe=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú) [Ìyípò=Gba àwọn alámùójútó nìkan láyè] (kòdájú))</comment> <model>wikitext</model> <format>text/x-wiki</format> Ọjọ́ 1 Oṣù Kẹrin tabi 1 April jẹ́ ọjọ́
1 April
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3322
3322
Oṣù Kẹrin Osù kerin odun ni April je. Ọgbọ̀n ọjọ́ ni o wa ninu osu April.
Oṣù Kẹrin
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3325
3325
Oṣù Ṣẹ̀rẹ́ Oṣù Ṣẹ̀rẹ́ tàbí oṣù Kìíní jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ nínú Kàlẹ́ńdà Gregory. Ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni ó wà nínú osù yìí. Ọjọ́ kìíní ti oṣù Ṣẹ̀rẹ́ ni a ṣe ayẹyẹ ọdún títun. Ní ìpíndọ́gba, oṣù yìí sì jẹ́ oṣù tí ó máa ń tutú jù lọ ní ìdajì ayé àríwá (nítorí pé ó jẹ́ oṣù kejì ti ìgbà òtútù níbẹ̀); ó sì jẹ́ oṣù tí ooru máa ń mú jù lọ ní ìdajì ayé gúúsù (nítorí pé ó jẹ́ oṣù kejì ti ìgbà sọ́mà níbẹ̀). Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n pè é ní "January"; orúkọ yìí wá láti ọ̀rọ̀ èdè Látínì "iānuārius" (osù ti Janus). Nítorí èyí, ní èdè Yorùbá náà a sì máa ń pe oṣù yìí ní "oṣù Jánúárì" ní ìgbà mìíràn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń wí pé kò yẹ́ kí a lò ó nítorí jíjẹ́ ọ̀rọ̀-àyálò tí ó jẹ́.
Oṣù Ṣẹ̀rẹ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3326
3326
Oṣù Kejì Osù Keji ni February je ninu Kalenda Gregory. Ojo mejidinlogbon tabi mokandinlogbon ni o wa ninu February.
Oṣù Kejì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3327
3327
Oṣù Kẹta Osù keta (tí àwọn Yorùbá mọ̀ sí Oṣù Ẹrẹ̀nà) jẹ́ oṣù kẹta odun kalenda Gìrẹ́górì àti Julian. Ọjọ́ mokanlelogbon ni o wa ninu Oṣù Ẹrẹ̀nà. Òun ni oṣù kẹ́jì nínú àwọn oṣù méje tí ó ní ọjọ́ mókanlélogún.
Oṣù Kẹta
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3328
3328
Oṣù Kàrún Osù karun ni May je ninu Kalenda Gregory. Ojo mokanlelogbon ni o wa ninu osu May.
Oṣù Kàrún
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3330
3330
Abubakar Tafawa Balewa Abubakar Tafawa Balewa (December 1912 – January 15, 1966) je omo orile ede Nàìjíríà, lati apa ariwa ile Nàìjíríà. Balewa je Alakoso Agba (prime minister) akoko fun ile Nàìjíríà ni Igba Oselu Akoko ile Nàìjíríà leyin igba ti Nàìjíríà gba ominira ni odun 1960. Eni ayesi ni kariaye, o gba owo ni orile Afrika gege bi ikan lara awon ti won daba idasile Akojoegbe Okan ara Afrika (Organization of African Unity, OAU). Itokasi.
Abubakar Tafawa Balewa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3331
3331
Oṣù Kẹfà Osu kefa ni June je ninu odun. Ogbon ojo ni o wa ninu osu June.
Oṣù Kẹfà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3332
3332
Oṣù Keje Osu keje ni July je ninu odun. Ojo mokanlelogbon ni o wa ninu osu July.
Oṣù Keje
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3333
3333
Oṣù Kẹjọ Osù kẹjọ ni August jẹ́ nínú ọdún. Ọjọ́ mọ́kànlélógbọ̀n ni ó wà nínú osù August.
Oṣù Kẹjọ
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3334
3334
Oṣù Kẹ̀sán Osù kẹsàán ni September jẹ́ nínú Kàlẹ́ndà Gregory. Ọgbọ̀n ọjọ́ ni ó wà nínú osù September.
Oṣù Kẹ̀sán
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3336
3336
Oṣù Ọwàrà Osù kewa ni October je ninu Kalenda Gregory. Ojo mokanlelogbon ni o wa ninu osu October.
Oṣù Ọwàrà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3337
3337
Oṣù Kọkànlá Osù kokanla ni November je ninu Kalenda Gregory. Ogbon ojo ni o wa ninu osu November.
Oṣù Kọkànlá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3338
3338
Oṣù Kejìlá Osù Ọ̀pẹ nínú ònkà oṣù ojú ọ̀run Yorùbá ni ó jẹ́ oṣù Kejìlá nínú ònkà oṣù ojú ọ̀run ti àwọn (Gẹ̀ẹ́sì) tí wọ́n pè ní December Ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni ó wà nínú oṣù yí. Osù December ni awọn gẹ̀ẹ́sì fa orúkọ rẹ̀ yọ látara ọ̀rọ̀ ""decem" (tí ó túmọ̀ sí ten) nítorí wípé òun gaan ni oṣù kẹwàá ọdún nínú kalẹ̀dà tí àwọn calendar of Romulus c. 750 BC tí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tiwọn sì bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹta ọdún. Àwọn oṣù tókù kò ti sí tẹ́lẹ̀, amọ́ wọ́n ṣàfikún oṣú kínní ati oṣù kejì kun tí December sì dá dúró ní tirẹ̀.
Oṣù Kejìlá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3345
3345
Nọ́mbà àkọ́kọ́ Ninu Ìmọ̀ Ìṣirò nọ́mbà àkọ́kọ́ (prime numbers) ni a si àwọn nomba adabaye (natural numbers) tí wọn ní nọmba ádábá méjí péreé tí a lè fí pín wọn dọ́gba, éyí ní nọmbaa 1 atí nọmba ákọkọ fún árá rẹ. Áwọn nọmba ákọkọ pọ tó bẹẹ tó fí jẹ wípé wọn kò lòpin gẹgẹe bí Efklidi ṣé fihàn ní ọdúnn 300 K.J (kia to bi Jesu, K.J). Nọmba ódò 0 ati ọ̀kan 1 kì ṣé nọmba akọkọ. Bí àwọnon nọmba akọkọ ṣé ẹètárá wọn wí íi yi : 2, 3, 5, 7, 11, 13, 17, 19, 23, 29, 31, 37, 41, 43, 47, 53, 59, 61, 67, 71, 73, 79, 83, 89, 97, 101, 103, 107, àtí, and 113 Nọmba 2 (íkèji) í i íó ẹ Nomba Akoko gege bi baba awon ááoíba ọdabÁ. ọIpóleùse ẹAbagbo Isesiro la kale pe gbogbo nọ́mbà odidi (integers) apa otun ti won tobi ju 1 lo se ko sile gege bi isodipupo nomba akoko kan tabi jubelo ni ona kan pato. Fun apere a le ko: formula_1 Gbogbo Awon Nomba Akoko. Awon nomba akoko ko ni ye. Eyi ti je fifihan lopolopo ona. Eni akoko to koko fi eyi han ni Efklidi. Bi o se fi han ni yi: E je ki a so pe awon nomba akoko to l'opin (finite) kan wa. E je ki a pe awon nomba wonyi ni "m". Se isodipupo gbogbo m, ki o si se aropo re pelu okan (nomba Efklidi). Nomba esi ti ri ko se pin pelu ikojopo number akoko kankan t'olopin, nitoripe bi a ba se pin to okan yio seku, be sini okan ko se pin pelu nomba akoko. Nipa bayi, tabi ki o je nomba akoko fun ra ara re tabi ki o se pin pelu nomba akoko miran ti ko si ninu ikojopo to l'opin. Botiwulekaje, a gbudo ni nomba akoko ti yio je "m" + 1.
Nọ́mbà àkọ́kọ́
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3346
3346
Nọ́mbà àdábáyé Nínú mathematiki, àwon nọ́mbà àdábáyé, tàbí nọ́mbà àdábá (Natural number) lé jé òkan nínú àkójopò {1, 2, 3...} (èyun nọ́mbà odidi rere) tàbí òkan nínú àkójopò {0, 1, 2, 3, ...} (èyun gbogbo nọ́mbà tí kí se tí òdì). A n ló nọ́mbà àdàbà fún kíkà ("Ọsàn mefa lowa ninu apẹ̀rè yị); bé ni á sí tún n ló won fún sisé ètò elésèsè ("Ipo keji ni Bùkọ́lá mu ninu ìdíje sàyẹ̀nsì odun yi").
Nọ́mbà àdábáyé
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3350
3350
Mathimátíkì Mathematiki tabi Ìmọ̀ Ìsirò jẹ́ èyí t'on jẹ mo nipa ọ̀pọ̀iye (quantity), nipa òpó (structure), nipa iyipada (change) ati nipa ààyè (space). Idagbasoke imo Isiro wa nipa lilo àfòyemọ̀ọ́ (abstraction) ati Ọgbọ́n ìrọ̀nú, pelu onka, isesiro, wíwọ̀n ati nipa fi fi eto s'agbeyewo bi awon ohun se ri (shapes) ati bi won se n gbera (motion). E ni awon Onimo Isiro n gbeyewo, ero won ni lati wa aba tuntun, ki won o si fi ootọ́ re mulẹ̀ pelu itumo yekeyeke. A n lo Imo Isiro ka kiri agbaye ni opolopo ona ninu Imo Sayensi, Imo Ise Ero, Imo Iwosan, ati Imo Oro Okowo. Eyi je mo eko imo isiro to ko ti ni ilo kankan bo tileje pe o se se ki a wa ilo fun ni eyinwa ola.
Mathimátíkì
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3360
3360
Nọ́mbà adọ́gba àti aṣẹ́kù Ninu Imo mathematiki, gbogbo nọ́mbà odidi le je nomba adogba (even number) tabi nomba aseku (odd number) lona yi: ti o ba je odidi nomba ni opolopo meji, nomba na je nomba adogba bibeko yio je nomba aseku. Fun apere 4, 0, 8, 16 je nomba adogba bee si ni 1, 3, 7, 9, 11 je nomba aseku. Akojopo awon nomba adogba se ko bayi: Adọ́gba = 2Z = {..., −6, −4, −2, 0, 2, 4, 6, ...}. Akojopo awon nomba toseku se ko bayi: Aṣẹ́kù = 2Z + 1 = {..., −5, −3, −1, 1, 3, 5, ...}. Isirosise pelu awon nomba adogba ati nomba aseku. Isodipupo. adogba * adogba = adogba adogba * aseku = adogba aseku * aseku = aseku Isepinpin. Ti a ba sepinpin odidi nomba ki se dandan pe yio fun wa ni nomba odidi pada. Fun apere ti a ba sepinpin 1 pelu 4, esi re yio je 1/4 ti ki se nomba adogba tabi nomba aseku nitoripe awon nọ́mbà odidi nikan ni won le je adogba tabi aseku. Sugbon ti ipin ba je odidi nomba, yio je adogba ti afi ti nomba ti a pin (dividend) ni opolopo iye (factor) meji ju nomba ti a fi pin (divisor) lo.
Nọ́mbà adọ́gba àti aṣẹ́kù
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3361
3361
Nọ́mbà odidi Nomba odidi (integer) je gbogbo awon nọ́mbà àdábáyé alapaotun {1, 2, 3...} ati ti awon alapaosi won (−1, −2, −3, ...) pelu nomba òdo. Ami ti a fi n tokasi akojopo awon nomba odidi ni Z (tabi formula_1, tabi Unicode ℤ) ti o duro fun "Zahlen" (ti o tumosi nomba ni ede Germani)
Nọ́mbà odidi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3372
3372
Àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá Onjo ti Okeho Deji ti ilu Akure
Àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3399
3399
Bọ́lá Ìgè James Ajibọ́lá Adégòkè Ìgè (September 13, 1930 - December 23, 2001) jẹ́ ọmọ Yorùbá, agbẹjọ́rò ati olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní apá ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. A bí Ìgè ní ọjọ́ kẹtàlá oṣu kẹsàán ọdún 1930, ó di olóògbé ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣu kejìlá ọdún 2001. Ìgè di Alákòóso (mínísítà) ìjọba àpapọ̀ fún ẹ̀ka ètò ìdájọ́ àti Agbẹjọ́rò-Àgbà ìjọba àpapọ̀̀ láàrín ọdún 2000 títí di ọdún 2001 tí wọ́n fi fipá gba ẹ̀mí rẹ̀ nínú oṣù Kejìlá ọdún 2001. Ìgè jẹ gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti osù kẹwàá ọdún 1979 títí dé osù kẹwàá ọdún 2003. Lẹ́yìn ìgbàtí ìjọ̀ba olósèlú padà dé ní ọdún 1999.̣̣̣̣̣̣̣̣̣́́́́́́́ Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀. Wọ́n bí ní James Ajíbọ́lá Ìdòwú Adégòkè Ìgè ìlú Zaria ni ìpínlẹ̀ Ìpínlẹ̀ Kaduna ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàn án ọdún 1930 bí tiḷẹ̀ jẹ́ pé ọmọ bíbí ìlú Ẹ̀sà Òkè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni àwọn òbí rẹ̀. Ìgè gbéra lọ sí ìlú Ìbàdàn ní dédé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá láti lọ kẹ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Ibadan Grammar School ní àárín ọdún 1943 sí 1948. Ó sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ fàfitì ti Ìbàdàn, lẹ́yìn èyí ni ó gbéra lọ sí ilé eré ẹ̀kọ́ University College London níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ọdún 1961. Bọ́lá Ìgè da ilé iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó pe ní Bola Ige & Co ní ọdún 1961, tí ó sì padà di Agbẹjọ́rò Àgbà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìgè di ìlú-mòọ́ká agbẹjọ́rò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà látàrí ìṣọwọ́sọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mú béré béré ati akitiyan rẹ̀ lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó fi mọ́ ìṣèjọba awa arawa. Bákan náà, Ìgè jẹ́ onígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn kìrìstẹ́nì. Bọ́lá Ìgè tún mọ èdè mẹ́ta tó gbajúgbà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn èdè Yorùbá, Igbo àti èdè Hausa lásọ yanrantí. He wrote several books, and an anthology of articles and tributes about him was published shortly after his death. Ibẹ̀rẹ̀ ìṣèlú rẹ̀. Lásìkò ìṣèjọba àwa arawa alákọ́kọ́, láàrín ọdún 1963 sí 1966 ní déédé ọmọ ọdún mẹ́tàlélọgbọ̀n, ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Action Group tí ó kópa nínú rògbòdìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú AG láàrín olóyè Obafemi Awolowo ati olóyè Samuel Ladoke Akintola Bo la Ìgè di ọ̀tá pẹ̀lú Olusola Olaosebikan fún ìwà ìgbẹ̀yìn-gbẹbọjẹ́ fún Olóyè Obafemi Awolowo. Ìgè di kọmíṣọ́nà fún ètò ọ̀gbìn fún agbègbè Western Region nígbà náà láàrín ọdún 1967 sí 1970 lásìkò ìṣèjọba ọ̀gàgunYakubu Gowon. Ní ọdún 1967, Bọ́lá Ìgè di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú olóyè Olusegun Obasanjo tí ó jẹ́ adarí ikọ̀ ọmọ ogun ní bárékè ìlú Ìbàdàn lásìkò náà. Lásìkò ìṣèjọba ológun akọ́kọ́ ní ọdún 1970, Bọ́lá Ìgè gbógun tako ìpolongo ẹlẹ́yàmẹyà tí àwọn World Council of Churches gbé ìgbésẹ̀ rẹ̀ nígbà náà. Ọdún 1970 ń pari lọ ni ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Unity Party of Nigeria (UPN), ẹgbẹ́ tí ó rọ́pọ̀ ẹgbẹ́ ìṣèlú Action Group. Nígbà tí ọ̀gágun Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ gbé ìjọba kalẹ̀ fún alágbádá ní ọdún 1979, wọ́n dìbò yan Bọ́lá Ìgè gẹ́gẹ́ bí gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàrín ọdún 1979 sí 1983. Adebisi Akande, tí ó padà di gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ó jẹ igbékejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà nínú ẹgbẹ́ ìṣèlú UPN nígbà náà. Ní inú ìdìbò ọdún 1983, tí Bọ́lá tún díje láti padà sípò gómìnà lábẹ́ abùradà UPN, ọ̀mọ̀wé Victor Omololu Olunloyo ló fẹ́yìn rẹ̀ balẹ̀ nínú ìdíje ìbò sípò gómìnà náà. Bọ̀lá Ìgè gbé abájáde èsì ìdìbò náà lọ sílé ẹjọ, àmọ́ Olunloyo kò ló ju oṣù mẹ́ta lọ lórí alééfà gómìnà kí ọ̀gágun Muhammadu Buhari àti Tunde Idiagbon tí wọ́n jẹ́ ológun tó tún dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ alágbádá. Ìjọba ológun gbé Ìgè ju sátìmọ́lé pẹ̀lú ẹ̀sùn wípé ó fi owó ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ṣara rindin, àmọ́ wọ́n tu sílẹ̀ ní ọdún 1985 lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tí ọ̀gágun Ibrahim Babangida ṣe, ó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ òjòọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amòfin, agbẹjọ́rò ati ònkọ̀wé. Ó gbé ìwé kan jáde ní ọdún 1990 tí ó pe ní "People, Politics And Politicians of Nigeria: 1940–1979", ìwé tí ó ti ń kọ ṣáájú kí wọ́n tó gbe jù sátìmọ́lé. Ó jẹ́ ìkan pàtàkì lára àwọn péréte tí wọ́n da ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ọ̀gágunSani Abacha wà lórí àlééfà, ó sì ń ṣoro bí agbọ́n lásìkò ìṣèjọba tìrẹ, Bọ́lá Ìgè gbìyànjú láti má da sí ohunkóhun tí ó níṣe pẹ̀lú ìṣèlú lásìkò náà. Ìjọba alágbádá ìkẹrin. Lẹ́yìn tí ọ̀gágun Sani Abacha papò dà tán tí ìjọba sì padà sọ́wọ́ alágbádá lẹ́ẹ̀kẹrin ní ọdún 1999 ni Bọ́lá Ìgè yọjú wípé òun nífẹ́ láti di Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Alliance for Democracy, àmọ́ wọ́n kò mu. Lẹ́yin tí Olúṣẹ́gun Obásanjọ́ di ààrẹ tán ni ó fi Bọ́lá Ìgè jẹ Mínísítà fún ohun àlùmọ́nì àti agbára. Ó wà ní ipò yí láàrín ọdún 1999 sí 2000. Ipá Bọ́lá kò fi bẹ́ẹ̀ kájú ipò yí látàrí àwọn ayídáyidà kan tí ó wà nídí ina Ọba. Lẹ́yìn èyí ni Ààrẹ bá tun fi jẹ Mínísítà fún ẹ̀ka ètò Ìdájọ́ àti Adájọ́ Àgbà fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láàrín ọdún 2000 sí 2001 Nínú osù kẹsàán ọdún 2001 ni Bọ́lá Ìgè sọ wípé ìjọba apápọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìṣàtúntò ìwé òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti wípé wọn yóò g e sí ojú-òpó ẹ̀rọ ayélujára fún gbogbo ènìyàn kí wọ́n lè lánfàní si níbi gbogbo. Bọ́lá ṣe ìpolongo tako lílo òfin Ṣàríà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àwọn ìpínlẹ̀ apá òkè ọya . Nínú osù kọkànlá ọdún 2001, Bọ́lá sọ wípé ìjọba àpapọ̀ kò ní fàyè gba ìjọba Ìpínlẹ̀ Sokoto láàyè láti sọ̀kò pa arabìnrin kan tí wọ́n fi ẹ̀sùn àgbèrè kàn, tí wọ́n sì dájọ́ nílé ẹjọ́ Gwadabawa wípé kí wọn lọ sọ̀kò pàá gẹ́gẹ́ bí òfin ṣàríà ti gbe kalẹ̀. Adájọ́ tí ó da ẹjọ́ náà ni adájọ́ Safiya Hussaini. Ó ku diẹ̀ kí wọ́n fi Ìgè sí ipò ńlá kan nínú àjọ United Nations International Law Commission ni wọ́n fi ìbọn gé okùn ẹ̀mí rẹ̀ kúrú ní Ìbàdan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ikú rẹ̀. Ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù Kejìlá ọdún 2001, wọ́n yìnbọn pa Bọ́lá Ìgè ní ìlú Ìbàdàn, ṣáájú kí wọ́n tó pàá, òun ati àwọn kan ti ní fàá-kája nínú ẹgbẹ́ ìṣèlú wọn ní Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun. Ní nkan bí ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ṣáájú ikú rẹ̀ ni àwọn kan tí a wọn kò mọ̀ ṣekú pa aṣòfin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odunayo Olagnaju tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú AD, wọ́n fura wípé ìjà tí ó ń ṣẹlẹ̀ láàrín gómìnà Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ìyẹn olóyè Bisi Akande ati igbákejì rẹ̀ Iyiola Omisore ti ó ṣokùnfà iku olóògbé náà. Ní kété tí Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọba sàn ńọ́ gbọ́ ìró iku Bọ́lá Ìgè ni ó da Àwọn ṣọ́jà sígboro wípé kí wọ́n ó wà lójú lalákàn fi ń ṣọ́rí kí rògbòdìyàn ó má ba bẹ́ sílẹ̀ látàrí iku akọni olóògbé Bọ́lá Ìgè látàrí bí àwọn kan ṣe gbẹ̀mí rẹ̀ ní fọná-fọnsu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ògọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ni wọ́n fòfin mú lórí iku Bọ́lá Ìgè, tí ó fi mọ́ Iyìọlá Omisore, àmọ́ wọ́n padà yọ̀nda wọn náà ni. Títí di àsìkò yí, wọn kò mọ ẹni tí ṣekú pa Bọ́lá Ìgè. Wọ́n sìnkú rẹ̀ sí ulẹ́ rẹ̀ tí ó wà ní Ẹ̀sà-Òkè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti sọ sílẹ̀ nínú àwọn ìwé rẹ̀ ni ó ti sọ wípé " Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dùn ńgbé, àmọ̀ òun kò mọ́ bóyá ó yẹ láti kú fún" .
Bọ́lá Ìgè
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3400
3400
Wọlé Sóyinká Akínwándé Olúwọlé Babátúndé Ṣóyínká (ọjọ́ìbí 13 July 1934) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) nínú Ìmọ̀ Lítíréṣọ̀ (literature), alákọsílẹ̀, eré orí ìtàgé (playwright) àti akéwì (poet). Wọlé Sóyinká jẹ́ ògidì ọmọ Yorùbá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gba Ẹ̀bùn Nobel ní ọdún 1986 fún iṣẹ́ ọwọ́ ọ rẹ̀ lórí i ìgbéga ìmọ̀ ìkọ̀wé.. Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Wọ́n bí Wọlé Sóyinká ní ìlú Abẹ́òkúta, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà àti United Kingdom tán, Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Theatre Royal Court ni ìlú Loọ́ńdọ̀nù (London). Ó tẹ̀ síwájú láti kọ àwọn eré oníṣe lorílẹ̀ èdè méjèèjì ní tíátà àti orí ẹ̀rọ Asọ̀rọ̀-mágbèsì. Ó kó ipa pàtàkì nínú ètò ìṣèlú àti akitiyan lópọ̀lọpọ̀ nínú ìjàǹgbara òmìnira orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn Great Britain. Wole Soyinka de ko ere ti won te ni Nàìjíríà ati oke okun ,ire itagbe ati ire olori redio.Wole je eniyan paataki ninu ija ominira Naijira lati owo awon Ilu Oba. Àwọn Ìtọ́kasí. 4. Open Country Magazine. https://opencountrymag.com/52-books-in-64-years-your-guide-to-all-work-by-wole-soyinka/
Wọlé Sóyinká
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3401
3401
Chinua Achebe Chinua Achebe (, oruko abiso Albert Chinualumogu Achebe, 16 November 1930 – 21 March 2013) jẹ́ ọmọ orile ede Naijiria lati eya Igbo ni apa ila oorun Naijiria. Ojogbon ninu imo ikowe (literature) ni Achebe je, opo ni ile Afrika ni won si mo Achebe gege bi okan ninu awon omowe (intellectual) pataki ti a jade ni ile Afrika. Iwe re Igbesiaye Okonkwo (Things fall apart) ni o je eyi ti o gbajumo julo ni ile Afrika leyi igba ti a ti seyipada re si ogun logo ede ka kiri aye. Igbèsi Àyè Àràkunrin naa. Chinua Achebe ni a bini óṣu November ni ọdun 1930 si church ti Saint Simon, Nneobi ti wọn si wẹ si mimọ gẹgẹbi Albert Chinualumogu Achebe. Baba rẹ̀ Isaiah Okafo Achebe jẹ ólúkọ ati evangelist ti Iya rẹ Janet Anaenechi Iloegbunam jẹ àgbẹ ati ólóri ijọ awọn óbinrin ninu church. Achebe fẹ Christie ni ọjọ kẹwa óṣu September ọdun 1961 ni Chapel of Resurrection ni ilè iwè giga ti ibadan ti wọn si bi ọmọ óbinrin kan Chinelo (a bini óṣu July, ọdun 1962) ati ọmọ ọkunrin mèji Ikechukwu (à bini óṣu December, ọdun 1964) ati Chidi (a bini óṣu May, ọdun 1967). Achebe ku ni óṣu March, ọdun 2013 si Boston, Massachusetts, US ti wọn sin si ilú rẹ ni ogidi. Ẹkọ. Ni ọdun 1936, Achebe lọsi ilè iwè St Philips ti apapọ ni Akpakaogwe lẹyin naa lo lọsi Ilè iwè ti ijọba ni Umuahia ni ipinlẹ Abia. Ni ọdun 1942, Achebe lọsi Ilè iwè ti Nekede apapọ. Ni ọdun 1948, Achebe lọsi ilè iwè giga ti ilú ibadan lati kẹẹkọ lóri imọ iṣègun ṣugbọn o fi silẹ lati kẹẹkọ lori imọ èdè gẹẹsi, itan ati theology.
Chinua Achebe
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3407
3407
Nọ́mbà gidi Nínú Ìmọ̀ Ìṣirò nọ́mbà gidi (real number) ni a mọ̀ sí àwọn nọ́mbà tí a Ko lè gé, gẹ́gẹ́ bí nọ́mbà oníyemẹ́wàá (decimals) tí kò lópin. Fún àpẹẹrẹ 2.4871773339…. Àwọn nọ́mbà gidi jẹ́ nọ́mbà oníìpín, nọ́mbà bí 42 àti −23/129, àti nọ́mbà aláìníìpín, nọ́mbà gbòngbò alágbára-méjì]] 2 (square root) tí wọ́n sì ṣeé fihàn gẹ́gẹ́ bí ojúàmì (point) ní orí ìlà nọ́mbà tó gùn ní àìlópin. A ń pe àwọn nọ́mbà gidi bẹ́ẹ̀ láti lè ṣèyàtọ̀ sí àwon nọ́mbà tósòro (complex number). Ní ayé àtijọ́ àwọn onímọ̀ ìṣirò mọ nọ́mbà tó rújú gẹ́gẹ́ bí nọ́mbà afòyemọ̀ (imaginary number). Bí a ṣe lè dá nọ́mbà gidi mọ̀. Nọ́mbà gidi lè jẹ́ onípìín tàbí aláìnípìín; Ó lè jẹ́ nọ́mbà Ọ̀jíbírà tàbí nọ́mbà t tí kò ní ònkà (transcendental number); bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n lè jẹ́ nọ́mbà tódájú, ni odi tàbí kí wọ́n jẹ́ òdo. A n fi nomba gidi se iwon awon opoiye to je wiwapapo (continuous). O se se ka fi won han gege bi nombamewa to ni itelentele (sequence) eyonomba (digit) ti ko lopin lapa otun ojuami nombamewa (decimal point); a le fi won han bayi 324.823211247…. Awon ami bintin meta to wa leyin nomba yi tumosi pe awon eyonomba miran si n bo leyin. Bakanna, awon nomba gidi tun ni idamo meji ti papa elesese (ordered field) ni, be ni won si ni idamo ti a mo si ipari l'oke tokerejulo (least upper bound). Akoko so fun wa pe awon nomba gidi ni papa kan, pelu aropo, isodipupo ati isepinpin pelu awon nomba ti ki se odo ti won le je elesese lapapo ni ori ila nomba lona to ni ibamu po mo aropo ati isodipupo. Ekeji so fun wa pe ti akojopo nomba gidi ti ki se ofo (empty) ba ni ipari l'oke (upper bound), o gbudo ni ipari l'oke tokerejulo. Awon mejeji yi lapapo ni won se'tumo nomba gidi patapata. Lati inu won ni awon idamo nomba gidi yioku ti jade wa. Fun apere a le fihan pe gbogbo polynomial (alamipupo) alagbara nomba siseku pelu nomba ibamulo (coefficient) gidi yio ni gbongbo gidi; ati pe ti a ba s'aropo gbongbo alagbarameji idin okan (minus one) po mo nomba gidi lati fun wa ni nomba tosoro, esi yi ni a n so pe o je titi ninu aljebra. Iwulo awon nomba gidi. A n se iwon ninu Imo Sayensi Alagbamu (physical science) gege bi won ba n sunmo nomba gidi to. Bo tile je pe awon nomba ti a n lo fun eyi je ida nombamewa (decimal fraction) ti won duro fun awon nomba oniipin, nipa kiko won sile gege bi nombamewa fihan pe won n sunmo nomba gidi kan. A n so pe nomba gidi se sesiro ti igbese isiro ti a mo si Algorithm ba wa ti yio mu eyonomba re wa. Nitoripe bo tile wu ki awon algorithm re o po to, won niye pato (countable), sugbon awon nomba gidi ko niye (uncountable), nitori eyi opo ninu awon nomba gidi ni won ko se sesiro. Ero onka Komputa le sunmo nomba gidi nikan. L'apapo won le s'oju fun awon inuakojopo (subset) awon nomba oniipin pato kan, nipa lilo nomba ojuami tonlefo (floating point) tabi nomba ojuami soso (fixed point), be sini awon nomba oniipin yi n je lilo lati sunmo awon iye gidi ti won sunmo won. Awon onimo isiro n lo ami R (tabi formula_1 tabi Unicode ℝ) lati se'duro fun akojopo gbogbo nomba gidi. Ami ikosile R"n" n tokasi aaye elegbe-"n" pelu ipoidojuko (coordinate) gidi won. Fun apere awon iye R3 je nomba gidi meta ti won tokasi ipo kookan ninu aaye elegbe meta (3 dimension) Amuwa lati inu awon nomba oniipin. A lé mú nomba gidí wa gégé bí àkótán àwon nomba oniìpín ni ònà tó jé pé ìtèntèle nomba kan se fẹsíwájú pèlú nombámèwa tàbí nombáméjì (binary) báyí {3, 3.1, 3.14, 3.141, 3.1415...} f'enuko sí nomba pàtò gidí kan. Agbagbo (Axiom). E je ki R ki o duro fun akojopo gbogbo nomba gidi. Nitorie: Idamo to gbeyin yi lo seyato larin nomba gidi ati nomba oniipin. Fun apere akojopo awon nomba oniipin ti alagbarameji won din si 2 ni nomba oniipin ipari l'oke (apere 1.5) sugbon won ko ni nomba onipin ipari l'oke tokerejulo, nitoripe gbongbo alagbarameji 2 ko se pin Awon Idamo. Titan Idi pataki ti a tun se seyato awon nomba gidi ni pe won ni gbogbo opin (limit). A le so pe won ""tan". Eyi tumosi bawonyi: Itelentele kan ("x""n") nomba gidi ni a n pe ni ìtẹ̀léntẹ̀lé Cauchy to je pe fun ε > 0, nomba odidi "N" kan wa to je pe ijinnasi (distance) |"x""n" − "x""m"| kere ju ε eyun to ba je pe "n" ati "m" tobi ju "N" lo. Ni ede mi, itelentele je itelentele Cauchy ti awon afida (element) "x""n" re ba sunmo ara won gbagba. Itelentele ("x""n") foriko po si opin "x" to ba je pe fun ε > 0, nomba odidi "N" kan wa to je pe ijinnasi |"x""n" − "x"| kere ju ε lo, to ba je pe "n" tobi ju "N" lo. Ni ede miran, itelentele kan ni opin "x" ti awon afida (element) re ba sunmo "x" gbagbagba. A ri bayi pe gbogbo itelentele ti o n foriko si oju kanna ni itelentele Cauchy. Gbogbo itelentele Cauchy fun nomba gidi je eyi to n foriko si oju kanna. Bayi wipe awon nomba gidi "tan". S'akiyesi pe awon nomba onipin ko lo tan o. Fun apere itelentele 1, 1.4, 1.41, 1.414, 1.4142, 1.41421, …) je ti Cauchy sugbon won ko foriko si nomba oniipin. (Eyi yatosi nomba gidi ti won foriko si gbongbo alagbarameji 2). Nitoripe awon opin wa fun awon itelentele Cauchy ni isiro Kalkulosi fi se e se, ti o si wulo. Ona kan ti a fi le sewadi boya itelentele kan ni opin ni ki a yewo boya o je itelentele Cauchy, nitoripe a ko le mo opin yi tele. Fun apere etonomba (series) fun igbega alabase (exponential function) formula_2 foriko si nomba gidi kan, nitoripe fun gbogbo "x" awon aropo formula_3 le kere gan ti a ba je ki "N" o tobi daada. Eyi fihan pe itelentele Cauchy ni o je. A ti mo bayi pe itenlentele ohun foriko si opin kan bi a ko ba ti e le so opin ibi ti o foriko si.
Nọ́mbà gidi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3416
3416
Àwọn Ẹ̀ka-èdè Yorùbá Awon Eka-ede Yoruba Tèmítọ́pẹ́ Olúmúyìwá (1994), Àwọn Ẹ̀ka-Èdè Yorùbá 1Akúrẹ́: Ìbàdàn, Montem Paperbacks. ISBN 978-3297-3-3. Ojú-ìwé = 58. Ọ̀RỌ̀-ÌṢÁÁJÚ Èdè Yorùbá àjùmọ̀lò ni ó pa gbogbo ẹ̀yà Yorùbá pọ. Ṣùgbọ́n ẹ̀ka-èdè tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ń sọ yàtọ̀ láti ilú kan sí èkeji. Ìyàtọ́ yìí le hàn ketekete tàbí kí ó farasin. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìwádii ni àwọn onímọ̀-èdè ti ṣe lórí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá wọ̀nyí. Púpọ̀ nínú àbájáde ìwádìí wọn ni kò sí ní àrọ́wọ́tó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá. Níbi ti irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ bá jàjà bọ́ sí ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́, èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọn fi ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ yóò mú ìfàsẹ́yìn bá iṣẹ́ wọn nítorí wọ́n ní láti kọ́kọ́ túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Yorùbá kí wọn tó le ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀ka-èdè bẹ́ẹ̀ finnífínní. Títí di bi mo ṣe ń sọ yìí, kò sí ìwé kankan nípa àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá lórí àtẹ. Ohun àsọmórọ̀ ni àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá jẹ́ nínú àwọn ìwé gírámà Yorùbá tí ó wà lórí àtẹ. Púpọ̀ àbájáde ìwádìí àwọn onímọ̀-èdè tí ó wà ní àrọ́wọ́tó ni ó dálé ìpín-sí-ìsọ̀rí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Ohun tí ó jẹ àwọn aṣèwádìí mìíràn lógún ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀ka-èdè ìlú kan tí wọ́n yàn láàyò. Ṣùgbọ́n nínú ìwé yìí mo ṣe àyẹ̀wò púpọ̀ àwọn ẹ̀ka-ède Yorùbá léte àti pe àkíyèsí sí fonẹ́tíìkì àti fonọ́lọ́jì ẹ̀ka-èdè wọ̀nyí. Ìwé yìí yóò wúlò púpọ̀ fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti wọ́n ń kọ́ nípa àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Yóò si ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọnolùkọ̀ọ́ pẹ̀lú. Bákan náà ni ìwé yìío yóò jẹ́ ìpèníjà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀-èdè Yorùbá láti túbọ̀ kọ ibi ara sí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ wọ̀nyí tí wọ́n tẹ̀ mí nífá ẹ̀ka-èdè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò fojú rí púpọ̀ nínú wọn rí. Àwọn ni Ọ̀mọ̀wé Jíbọ́lá Abíọ́dún, Ọ̀gọ̀gbọ́n Ọládélé Awóbùlúyì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyèlárán, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Bámgbóṣé, Ọ̀mọ̀wé Adétùgbọ́, Ọ̀mọ̀wé Akínkúgbé àti Ọ̀mọ̀wé Olúrẹ̀mi Bámiṣilẹ̀. Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀mọ̀wé Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé àti Ọ̀mọ̀wé Jíbọ́lá Abíọ́dún tí wọ́n fu àkókò sílẹ̀ láti bá mi ka ìwé yìí pẹ̀lú àtúnṣe tí ó yẹ nígbà tí mo fí ọwọ́ kọ ọ́ tán. ìmọ̀ràn wọn ni àwọn ohun tí ó dára nínú ìwé yìí, èmi ni mo ni gbogbo àléébù ibẹ́. Mo gbé òṣùbà ọpẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí fún ìrànlọ́wọ́ wọn. Àwọn ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Bísí Ògúnṣíná, Arábìnrin Comfort Ògúnmọ́lá, Arábìnrin Àrìnpé Adéjùmọ̀, Olóyè Olúfẹ́mi Afọlábí, Arábìnrin Ọláyinká Afọlábí, Lékan Agboọlá, Ọjádélé Àjàyí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí mo kọ́ ní àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá láàárín ọdún 1991-1994 àti àwọn aláṣẹ ilé-iṣẹ́ aṣèwétà Montem Paperbacks. Ní ìparí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Arábìnrin Tèmítọ́pẹ́ Olúmúyìwá, ìyàwó mi àpé àti Mòńjọlá, ọmọ mi, fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn lásìkò ti mo kọ́ ìwé yìí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, bi Ọlọ́run kò bá kọ́ ilé náà, àwọn ti ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán. Ìdí nìyí tí mo fi yíkàá níwájú Ọlọ́run ayérayé.
Àwọn Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3440
3440
Ilu Ijebu-Jesa
Ilu Ijebu-Jesa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3441
3441
Ìsèdálẹ̀ Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ÌTÀN ÌSÈDÁLẸ̀ ÌLÚ ÌJẸ̀LÚ-JÈSÀ Oríṣìíríṣìí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a ti gbọ́ nípa ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé yóò dín. Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn náà sọ pé; Ọwà Iléṣà kìíní Ajíbógun àti Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà kìíni, Agígírí jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò. Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ẹ̀gbọ́n tí Ọwá sì jẹ́ àbúrò. Bákan náà, tẹ̀gbón tàbúrò ni ìyá tí ó bí wọn. Láti ọmọ omún ni ìyá Ajíbógun Ọwá Iléṣà ti kú ìyá Agígírì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ló wò ó dàgbà, ọmún rẹ̀ ló sì mún dàgbà. Èyí ló mú kí wọn di kòrí-kòsùn ara wọn láti kékeré wá, wọn kì í sìí yara wọn bí ó ti wù kí ó rí. Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji – Agírírí àti Ajíbógun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọ́n wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà láti dó sí kí wọn lè ni àyè ìjọba tiwọn. Ajíbógun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónií yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírí rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbúrò òun kò mọ̀ wí pé nǹkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín. Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbùrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọ́dọ̀ jìnnà sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé agìnjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pé ibi tí òun ti rìn ti nasẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí. Kì wọn tó kúrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fùn un ní ọgbọ̀n nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n, òun lè dáàbò bo ara òun ó sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé; “Ijẹ̀ṣà ọgbọ̀n Ìjẹ̀bú ogún É sìí bó ṣe a rí Kógún a parẹ́ mọ́gbọ̀n lára” Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírí àti Ajíbógun ni Ìlé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lé ríran padà. Ó lọ, ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohùn ìní bàbá wọn láìfi nǹkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran. Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. Bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀ bàbá rẹ̀. Ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fún un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú ìrin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lóri àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀. Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyá yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrè pọ̀. Láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn si wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn. Itán sọ pé Ìbòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì gba Ilékété lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró. Agóró yìí ló dúro sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan pàtàkì nínú wọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sí iwájú díẹ̀ kí lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ran Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Ìgbà ti Agígírí kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí bóyà ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fún ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti ń wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí yìí. Ìyàlẹ́nu ńláńlá lọ́ jẹ́ fún Agígírí láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lú àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí tí ibẹ̀ dùn mọ́ ọn fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọḍẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì ó sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n ìsàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkènísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayé”. Agbo ilée Bajimọn ni Òkè - Ọjà ni Agígírí kọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́hin èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gvà ọ̀tẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè ni Agígírí kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ìlédè náà ní ibi tí ààfin Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí i wọ́n múra láti gbé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Níkẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rè ati àwọn ọmọ - ogun rẹ̀. “Ojù iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu ti ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ̀ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n. Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbá tí wọ́n dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀sí í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mú ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n. Ìgà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ làti máa tọ́jú egbò náà, wọ́n sì dúró pẹ́ díẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wón fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ibẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilẹ̣́. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn – Agígírí sọ ibẹ̀ ni ÌJẸ̀BÚ nítorí pe ÌJẸ ni Ìjẹ̀ṣà máa ń pe Ẹ̀JẸ́. Nígbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ́bú tí wọ́n ti ń pè é tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà títí di òní. Ṣùgbọ́n Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́ tí ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa. A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀bù – Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè xxxxxx pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè máa sí láàárin wọn nígbà kan tí rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu ọ̀gbọ́ni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú – Òde lọ. Ibẹ̀ ló ti mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó. Nínú àwọn ìtán òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ìjẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfé èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mu díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ọ̀gbọ́ni. Ìtán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀. Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyèwò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ òótọ́ jù lọ nínú wọn. Nípa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ọjọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nǹkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a tẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì ken náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti a já tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárín wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nǹkan kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn. Tí Owá bá fẹ́ fi ènìyàn bọrẹ̀ láyé àtijọ́, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀. Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilèṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Iléṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Iléṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọn ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀. Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé; “ Kàí bi an kọlíjẹ̀bú Níbi an tọ̀nà Ìjẹ̀sàá bọ̀ Ọtáforíjọja ọ̀nà ni an kọlijẹ̀bú Ọmọ Egbùrùkòyàkẹ̀” Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sìń jẹ́ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. A rí Ọ̀gbọ́ni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara ìwàrẹ̀fà mẹfà ni Ọ̀gbọ́ni méjèejì yí wa ni Iléṣà ṣùgbọ́n Ọ̀gbọ́n Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. a rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jèṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà. Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí tí orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún àpẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní Iléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú méjèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ̀lú. Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀sà, èdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ. Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán. Tí ọ̀kan nínú wọn bá sì wàjà, óun ni ogún ti wọ́n máa ń jẹ lọ́dọ̀ ara wọn bí aya, ẹrú àti ẹrù Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀ná tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. Nígbà tí ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́un, àrìmọ-kùnrin ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójú ráyè, kí ó tó tàbà tuṣẹ. Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà àti Ọwá Ilẹ́ṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá ati Ọ̀gbọ́ni Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn”.
Ìsèdálẹ̀ Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3442
3442
Àgàdá ní Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà Ìtàn bí Àgàdá ṣendé ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà Ìtàn méjì ló rọ̀ mọ́ bi Àgàdá ṣe dé Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ìtàn kìíní. sọ fún wa pé ìlú Ìlayè ni wọ́n tí gbé e wá sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà. Ìlú Ìlayè yí ti wà lásìkò kan ní ayé àtijọ́ ṣùgbọ́n ìwádìí fi hàn wá pé kò sí i mọ́ lóde òní. Ìtàn sọ pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà jẹ́ jagunjagun didi tí ó lágbára púpọ̀. Ó jà títí ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kan dé ìlú Ìlayè, ṣùgọ́n kí ó tó dé ìlú yìí, àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti ránsẹ́ sí àwọn ènìyàn wọn ní ìlú tiwọn pé ki wọn wá pàdé wọn láti fi agbára kún agbára fún wọn nítorí pé ìdè ń ta wọ́n lápá. Báyìí ni àwọn ènìyàn ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà gbéra láti wà gbèjà Ọba wọn. Ìlù Ìlayè yí ni wọ́n ti pàdé Ọba ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà, ogún sì wá gbónà janjan. Nítorí pé agbára ti kún agbára Ọba ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà yí, ó wá dàbí ọwọ́ fẹ́ tẹ Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun náà bá sá tọ Ọba Ìlú Ìlayè lọ fún ìrànlọ́wọ́. Lọ́gán ni onítọ̀hún náà fún Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ní òrìṣà kan nínú òrìṣà wọn tí ó lágbára gidi láti gbèjà Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ó si sẹ́gun ọ̀tà rẹ̀. Bayìí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ṣe bèèrè fún òrìṣà yí ó sì tọrọ rẹ̀ láti gbé e wá sí ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nítorí pé ó ti ran án lọ́wọ́ lọ́pọ̀: ṣe òrìṣà tí ó bá san ni là ń sìn. Ṣùgbọ́n Ọba yìí kò gbé e fún un, Ìlú rẹ̀ tí ń jẹ́ ÀGÀDÁ ló gbé fún un láti máa gbé lọ ní rántí òrìṣà olùgbèjà yí. Ìgbà tí ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà dé ìlú rẹ̀ ni ó bá kọ́lè kan fún ìránti òrìṣà yí ó sì fi Ọkùnrin kan tì í pé kí ó màa bá òun rántí òrìṣà náà pé òun yóò sì wá máa fún un ní ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún fún ìrántí oore tí ó ṣe fún wọn. Báyìí ni ó ṣe di ọdún Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní, ìgbàkugbà tí wọ́n bá sì fẹ́ rántí rẹ̀ tàbí bọ ọ́, ìlú Àgàdá yìí ni wọ́n máa ń lù fún un, ilù ogun sì ni ìlù náà. Láti ọjọ́ náà tí ogun kan bá wọ ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ìlú náà ni wọ́n máa ń lù, tí wọ́n bá sì ti ń lù ú, gbogbo ọmọ -ogun ìlú ni yóò máa fi gbogbo agbára wọn jà nítorí pé orí wọn yóò máa yá, agbára sì túnbọ̀ máa kún agbára fún wọn. Ìtàn kejì. sọ fún wa pé Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ni wọ́n bí i àti pé alágbára gidi ni, ó fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kà fim ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn ó kú gẹ́gẹ́ bí alágbára, wọ́n sì sin ín gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọkùnrin. Wọ́n sọ ọ́ di òrìṣà kan pàtàkì ní ìlú gẹ́gẹ́ bí àwọn alágbára ayé ọjọ́un tí wọ́n ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà fún àwọn ènìyàn wọn, tí wọ́n kú tán tí wọ́n sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di òriṣà àti ẹn ìbọ lóníì àwọn òrìṣà bí ògún, ọ̀ṣun, ṣàngó, ọbàtálá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí a ń gbọ́ orúkọ wọn jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá lóde òní. Nígbà tí ó wà láyé, ó fẹ́ràn ìlù Àgàdá púpọ̀. Tí ogun bá sì wà, tí wọ́n bá ti ń lu ìlù náà, kí ó máa jà lọ láìwo ẹ̀nìyàn ni. Kò sì sí ìgbà tí wọ́n bá ń lu ìlù yí tí ogun bá wà tí kò ní ṣẹ́gun. Ìgbà tí ó sí kú, ìlù yí náà ni àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń lú tí ogun bá wà, ó sì di dandan kí àwọn áà borí irú ogun bẹ́ẹ̀. Orúkọ̀ míràn fún Àgàdá tún ni Dígunmọ́dò nítorí pé tí ogún bá ti ń bọ̀ láti wọ̀lú, ibi Ẹrẹ́jà ni ọkùnrin akíkanjú náà yóò ti lọ pàdé rẹ̀, kò sì ní jẹ́ kí ó wọ ìlú dé apá Ọ̀kèniṣà ti a ń pe ní orí ayé tí àwọn ènìyàn wà nígba náà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè é ní DÍGUNMÓDÒ –DÍ OGUN MỌ́ ODÒ. Títí di oní yìí, Ẹrẹ́jà náà ni wọ́n ti ń bọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ojúbọ rẹ̀. Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní “ẹjọ́ kì í ṣe tara ẹni ká má mọ̀ ọ́n dá” èyí ló jẹ́ kí n ronú dáadáa sí àwọn ìtàn méjì yí láti lè mọ eléyìí tí ó jẹ́ òótọ́ tí a sì lè fara mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìtán àtẹnudẹ́nu, àwọn olùsọ̀tàn ìtàn méjèèjì yí ló ń gbìyànjú láti sọ pé epó dun ẹ̀fọ́ wọn nítorí pé oníkálùkù ló ń gbé ìtàn tirẹ̀ lárugẹ. Ṣùgbọ́n ìgbà tí a wo ìsàlẹ̀ láti rí gùdùgbú ìgbá mo gba ìtàn tàkọ́kọ́ tí ó sọ pé ìlú Ilayè ni wọ́n ti mú un wá gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jẹ́ òótọ́ jù lọ nítorí pé wọ́n máa ń ki òrìṣà náà bayìí pé Oríkì. Jó jẹ̀gi Ìlayè” Nínú orin rẹ̀ náà, ọ̀kan sọ pé: Èlè: Oriṣà Òrìṣà Ègbè: Jẹ kéèrín peyín ò Èlé: Bàbá ulé Aláyè Ègbè: Jẹ́ kéèrín pe yín ò Èlé: Oriṣà òrìsà Ègbè: Jẹ́ kéèrín peyín ò Ṣùgbọ́n kì í ṣe òrìṣà yí nìkan ni ìtàn sọ fún wa pé ó ń gbèjà Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lákòókó ogun; ìrókò náà jẹ́ ọ̀kan. Akíkanjú ni òun náà tí kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kó má tatí were” ni tirẹ̀. Nígbà kan rí, a gbọ́ wí pé òrìṣà ìlú Ejíkú3 ni ìrókò jẹ́ ṣùgbọ́n ìgbà gbogbo ni ogún máa ń yọ ìlú yìí lẹ́nu tí wọ́n sí máa ń kó wọn lọ́mọ lọ. Nígẹ̀hìn, wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ wá sí ọ̀dọ̀ Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ò sì ràn wọnm lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí Èkíjú rójú ráyè tán ni wọ́n bá kúkú kó wá sí ilú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà láti sá fún ogun àti pé ẹni tí ó ran ni lọ́wọ́ yìí tó sá tọ̀ ìgbà tí ìlú méjì yí di ọ̀kan ni òrìṣà tí ó ti jẹ́ tí Èjíkú tẹ́lẹ̀ bá di ti Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nítorí pé ìgbà tí Èjíkú ń bọ̀ wá sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà, wọ́n gbé òrìṣà wọn yìí lọ́wọ́. Gbogbo ìgbà tí ogun bá dìde sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà náà ni ìrókò yí máa ń dìde láti sa gbogbo ipá ọwọ́ rẹ̀ láti gbèjà ìlú náà. Ológun gidi ni ìtàn sì sọ fún wa pé òun náà jẹ́ látàárọ ọjọ́ wá. Ṣé ẹni tí ó ṣe fún ni là ń ṣe é fún; èyí ni ìrókò náà ṣe máa ń gbé ọ̀rọ̀ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà karí tí nǹkan bá dé sí i láti fi ìwà ìmoore hàn tún ìlú náà. Ìdílé kan pàtàkì ni Èjíkú tí a ń sòrọ̀ rẹ̀ yí jẹ́ nílùú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí, àwọn sì ni ìran tí ń sin tàbí bọ òrìṣà ìrókò yí. Olórí tàbí Ọba Èjíkú sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwàrẹ̀fà mẹfà ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí. Àwọn tínqọ́n ń ṣe ọdún yìí. Lẹ́hìn ìgbà tí òrìṣà yí tit i ìlú Ìlayè dé Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà tí Ọba sì ti gbé e kalẹ̀ sí Ẹrẹ́jà, ló ti fi olùtọ́jù tì í. Ọbalórìṣà ni orúkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ agbátẹrù òrìṣà náà. “Ẹni tí ó ṣe fú ni là ń ṣe é fún” “ẹni tí a sì ṣe lóore tí kò mọ̀ ón bí a ṣe é ní ibi kò búrú”kí àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà má bà a jẹ́ abara – í móore - jẹ ni gbogbo wọn ṣe gba òrìṣà yí bí Ọlọ́run wọn tí wọ́n sì ń bọ́ ọ́ lọ́dọọdún. Àwọn tó ń bọ́ ọ́ pín sí mẹ́rin. Olórí àwòrò òrìṣà àgàdá ni Ọbalórìṣà tí ó jẹ́ agbàtẹrù òrìṣà náà. Aṣojú ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ló jẹ́ fún òrìṣà náà “Omi ni a sì ń tẹ̀ ká tó tẹ iyanrìn” bí ọbá bá fẹ́ bọ Àgàdá, ọbalórìṣà ni yóò rìí. Bí àwọn ọmọ ìlú ló fẹ́ bọ ọ́, Ọbalòrìṣà náà ni wọn yóò rí pẹ̀lú. Ìsọ̀ngbè ọbalórìṣà nínú bíbọ Àgàdá ni àwọn olórí ọmọ ìlú. Àwọn olórí-ọmọ yìí ló máa ń kó àwọn ọmọ ìlú lẹ́hìn lákòókó ọdún Àgàdá náà láti jó yí ìlú káákiri àti láti máa ṣàdúrà fún ìlọsíwájú ni gbobgo ìkóríta ìlú. Ọba ìlú náà ní ipa pàtàkì tirẹ̀ làti kó. Òun ló ń pèsè ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lódọọdún láti fí bọ òrìṣà náà èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn rẹ̀ ní ìgbà tó gba òrìṣà náà òun yóò máa fún un ní ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún títí dòní ló sì ń ṣe ìràntí ìlérí rẹ̀ ọjọ́ kìíní. Wàyí o, gbogbo ìlú ni wọ́n ka ọdún díde láti ṣe ọdún náà tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà tí ó wà ní ìdálẹ̀ ni yóò wálé fún ọdún náà. Gbogbo ìlú ló sì máa ń dùn yùngbà tí wọ́n bá ń ṣe ọdún náà lọ́wọ́.
Àgàdá ní Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3485
3485
Egbe Omo Oduduwa
Egbe Omo Oduduwa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3486
3486
Samuel Ladoke Akintola Samuel Ladoke Akintola (July 6, 1906 - January 15, 1966) je oloselu omo orile ede Naijiria lati eya Yoruba ni apa ila oorun. A bi ni ojo kefa osu keje odun 1906 ni ilu Ogbomosho. Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀. Wọ́n bí Sámúẹ̀lì sínú ìdílé Akíntọ̀lá ní ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, bàbá rẹ̀ ni Akíntọ̀lá Akínbọ́lá nígba tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Àkànkẹ́ Akíntọ̀lá. Bàbá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò tí ó jáde wá láti inú ẹbí oníṣòwò. Nígbà tí ó kéré jọjọ, àwọn ẹbí rẹ̀ kó lọ sí ìlú Minna tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Naija lónìí. Ó kàwé léréfèé nílé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ́rẹ̀ Church Missionary Society. Ní ọdún 1922, ó padà wá sí Ògbómọ̀ṣọ́ láti wá bá bàbá bàbá rẹ̀ gbé tí ó tún tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Oníyẹ̀tọmi ṣáájú kí ó tún tó tẹ̀ síwájú ní ilé-ẹ̀kọ́ Kọlẹ́ẹ̀jì ti onítẹ̀bọmi ní ọdún 1925. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Akádẹmì Onítẹ̀bọmi láàrín ọdún 1930 sí 1942, lẹ́yìn èyí ni ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ àjọ tó mójú tó ìrìnà Rélùwéè ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Lásìkò yí, ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú H.O. Davies, tí ó jẹ́ agbẹjọ́rò àti olóṣèlú, ó tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Nigerian Youth Movement níbi tí ó ti ṣàtìlẹyìn fún Ikoli láti di ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣojú Ìpínlẹ̀ Èkò tako yíyàn tí wọ́n yan Samuel Akisanya, ẹni tí Nnamdi Azikiwe fara mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò dépò náà. Akíntọ́lá tún dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́, tí ó sì di olóòtú fún.iwé ìròyìn náà ní ọdún 1953 pẹ̀lú àtìlẹyìn Akinọlá Májà tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olówó ìwé-ìròyìn náà tí ó sì rọ́pò Ernest Ikoli gẹ́gẹ́ olóòtú. Akíntọ̀lá náà sì dá Ìwé-ìròyìn Yorùbá tí wọ́n ń fi èdè Yorùbá gbé kalẹ̀ ní ojojúmọ́. Ní ọdún 1945, ó tako ìgbésẹ̀ ìdaṣẹ́ sílẹ̀ tí ẹ́gbẹ́ òṣèlú NCNC tí Azikiwe àti Michael Imoudu, fẹ́ gùn lé, èyí sì mu kí ó di ọ̀dàlẹ̀ lójú àwọn olóṣèlú bíi Anthony Enahoro. Ní ọdún 1946, Akíntọ̀lá rí ìrànwọ́ ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ gbà láti kàwé ọ̀fẹ́ ní U.K, níbi tí ó ti parí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ìmọ̀ òfin, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò lórí òfin tí ó jẹ mọ́ ìlú. Ní ọdún 1952, òun àti Chris Ògúnbanjọ,olóyè Bọ̀dé Thomas àti Michael Ọdẹ́sànyà kóra jọ pọ̀ di ọ̀kan.
Samuel Ladoke Akintola
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=3487
3487
Nọ́mbà oníìpín Ninu imo Mathematiki, nomba oniipin (rational number) ni nomba ti a le ko le gege be ipin nọ́mbà odidi meji. Nomba bi formula_1, to je pe "b" ki se odo. A le ko awon nomba oniipin ni opolopo ona, fun apere formula_2, sugbon o d'ero julo nigbati "a" ati "b" ko ba ni nomba kanna ti a le fi pin won a fi 1.
Nọ́mbà oníìpín
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73720
73720
VFD Microfinance Bank VFD Microfinance Bank jẹ́ báǹkì oní nọ́ḿbà ni kikun pẹlu olu ni ipinle Eko, Naijiria. Gẹgẹbi banki oni nọmba o funni ni awọn iṣẹ ifowopamọ ọfẹ si awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria. Gbenga Omolokun ni olori banki naa gẹgẹbi oludari alakoso. VFD Microfinance Bank jẹ oniranlọwọ ti Ẹgbẹ VFD ile-iṣẹ idoko-owo ohun-ini pẹlu Nonso Okpala gẹgẹbi Alakoso . Vbank. VBank (V by VFD tabi V) jẹ banki foju ati pẹpẹ ti o ni agbara nipasẹ VFD Microfinance Bank ati pe o ṣe ifilọlẹ ni Oṣu Kẹta Ọjọ 25, Ọdun 2020. A ṣẹda rẹ lati funni ni ile-ifowopamọ ori ayelujara ọfẹ. Lọwọlọwọ, VBank ti wọ diẹ sii ju 500,000 awọn eniyan ti nṣiṣe lọwọ ati awọn iṣowo lori pẹpẹ ile-ifowopamọ alagbeka rẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria.
VFD Microfinance Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73721
73721
Jaiz Bank Commercial Institute in NigeriaJaiz Bank Plc, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn bánkìì tí ó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ bánkìì ìsìlámù tí kò rọ̀gbọ̀kú lé ìjọba. Ó jẹ́ bánkíì àkọ́kọ́ fún ìdínwó ní orílé-èdè Nigeria tí olú ìyá ilé iṣẹ́ wọn wà ní Abuja, olú ìlú Nigeria. Ní December ọdún 2012, bánkíì yìí jẹ́ elétò ìsúná alábọ́dé ní Nigeria. Ní ìgbà yí, gbogbo owó inú àsùnwọ̀n wọn jẹ́ US$88.8 million (NGN:14.1 billion) léyìí tí àwọn alága ìgbìmọ̀ máa ń pín owó tó tó US$63.6 million (NGN:10.1billion). Bánkìì yí ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ mẹ́ta dín lọ́ gbọ̀n. Tí wọ́n sì ní káàdi ATM àti èto Bánkìì ayélujára, ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ alátẹ̀jíṣẹ́. Ìtàn. Wọ́n dáa ṣílẹ̀ ní 2003, gẹ́gẹ́ bí JAIZ International Pls. Ní ọjọ́ kọkànlá November 2011, Jaiz gba ìwé eri ẹ̀rí láti ọwọ́ Central Bánkìì ilẹ̀ Nàìjíríà. Láti máa sise gẹ́gẹ́ bí Bánkìì tí ó wà ní àrówótò. Ní ọjọ́ kẹfà January 2012, ilé ìṣe Bánkìì yí bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ilé ìṣe aladani JAIZ Bank pls ni ọ́fíìsì ní Abuja, Kaduna àti Kano. In 2013, Jaiz Bank tàn kálẹ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà, àti láàrin àwọn ìlú kéréje kéréje ilẹ̀ náà.
Jaiz Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73722
73722
Citibank Citibank, NA (NA dúró fún “ Association Orilẹ-ede ”) jẹ́ onírànlọ́wọ́ ilé-ìfowópamọ́ AMÉRÍKÀ àkọ́kọ́ tí àwọn iṣẹ́ ìnáwó ti ìlú ìlú Citigroup . Citybank tí a dá ní 1812 bí City Bank of New York, àti kí ó tó di First National City Bank of New York. Báńǹkì náà ní àwọn ẹ̀ka 2,649 ní àwọn orílẹ̀-èdè 19, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka 723 ní Amẹ́ríkà àti àwọn ẹ̀ka 1,494 ní ìlú Meksiko tí ó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ Banamex onírànlọ́wọ́ rẹ̀ wá ní ògidì ní àwọn agbègbè ìlú mẹ́fà: New York, Chicago, Los Angeles, San Francisco, Washington, DC, àti Miami. Ó jẹ́ ìpìlẹ̀ bí Ìlú Bank ti New York ó sì di National City Bank of New York . Ó ti ní ipa pàtàkì nínú àwọn ìfúnmọ́ ogun. Ó ti ní ipa nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbáyé pẹ̀lú ìkọlù AMẸ́RÍKÀ ti Haiti.
Citibank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73723
73723
Heritage Banking Company Limited Nigerian financial services institutionHeritage Bank Plc., tí a tún n pè ní Heritage Bank, jé̩ ilé ìfowopamọ. O jẹ ọkan lara awọn ile ifowopamọ ti gbogbo-gbo ti Ile Ifowopamọ apapọ ti Naijiria fi ọwọ si, tii ṣe akoso ọrọ ifowopamọ ni Naijiria, pẹlu aṣẹ iṣiṣẹ, lati ṣe iduna dura eto ifowopamọ, eto ifowopamọ ti ayelujara, eto ifowopamọ onidokowo ati amojuto nkan ini; olu ile iṣẹ wọn wa ni 292B Ajose Adeogun Street, Victoria Island, Ẹ̀kọ́, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà.
Heritage Banking Company Limited
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73724
73724
Stanbic IBTC holdings Stanbic IBTC Holdings, ti gbogbo aye mo si Stanbic IBTC, ile-ise ti o pese eto owo ati inowo ni orile ede Naijiria. Olu ilese I.B.T.C. wa ni Walter Carrington Crescent, Victoria Island, Lagos. Stanbic IBTC Holdings wa lara Standard Bank Group,ileese isuwo nla ti o kale si orile-ede South Africa. Standard Bank o je ileese ifowopamo ti o tobi ju ni ileese ogun ni ile African ati ilu metala ti ki i se ilu adulawo. Àwọn ilé-iṣẹ́ tó jẹ́ ẹgbẹ́ Stanbic Bank. Àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n jọ papọ̀ di Stanbic IBTC bank ni: Ohun ìní. Gbogbo ìdókòwò Stanbic IBTC Holdings wà lórí NSE, ní ó sì ń ṣọrọ̀ ajé rẹ̀ lábẹ́ àmì STANBIC Shareholding. Àwọ ìdókòwò wọn ní a kọ sísàlẹ̀ yìí;
Stanbic IBTC holdings
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73725
73725
Moniepoint Microfinance Bank Moniepoint Inc, (tí a mọ tẹ́lẹ̀ sí TeamApt Inc) jẹ́ ilé-iṣẹ fintech tí Tosin Eniolorunda jẹ́ Oludasilẹ iléṣẹ náà ní ọdún 2015 tí o dálé lórí wí wá ọ̀nàbáyọ sí ètò ìsúnná. Àmì-ẹ̀yẹ. Moniepoint ti wà lára àwọn ilé-ìfowópamọ́ tó ti lórúkọ lórí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn tí wọ́n da sílẹ̀ ní ọdún 2022 láti ọwọ́ CB Insights. Moniepoint tún gbàmì ẹ̀yẹ Financial Inclusion Award láti ọwọ́ ilé-ìfowópamọ́ gbogboogbò ti ilẹ̀ Nàìjíríà níbi àpérò àgbááyé ti Financial Inclusion ní ọdún 2022.
Moniepoint Microfinance Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73726
73726
Guaranty Trust Bank Guaranty Trust Holding Company PLC tÍ a tún mọ̀ sí GTCO PLC jẹ́ ilé iṣẹ ìfowópamọ́ káàkiri àgbáyé, tí ó ń ṣe Ìdókòwọ̀ ìṣàkóso owó ìfẹ̀hìntì, ìṣàkóso dúkìá, àti àwọn iṣẹ́ tó ń rísí owó sísan. Olú ilé-iṣẹ́ wọ́n wà ní Victoria Island, Ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A dá GTCO Plc sílẹ̀ ní oṣù keje ọdún 2021 léyìn àtúntò ilé-iṣẹ́ Guaranty Trust Bank PLC (tàbí GTBank) sínú ilé-iṣẹ́ kan. Àtúntò GTCO Plc túmọ̀ sí pé yóò pèsè àwọn iṣẹ́ mìíràn ju iṣẹ́ ìfowópamó si pe yoo pese awọn iṣẹ diẹ sii ju ile-ifowopamọ lọ; pẹlu kan owo sisan owo jije oke ti okan fun awọn ẹgbẹ. Labẹ igbekalẹ atijọ rẹ, ko le ṣe awọn iṣowo ti kii ṣe ayanilowo nitori ilana 2010 nipasẹ Central Bank of Nigeria (CBN) ti paṣẹ fun awọn banki lati da iṣẹ awọn ẹka ti kii ṣe ile-ifowopamọ duro. Wọn boya ni lati yọkuro lati iṣẹ awin ti kii ṣe pataki tabi tunto bi ile-iṣẹ didimu kan. Awọn iṣowo tuntun rẹ pẹlu awọn sisanwo, iṣakoso owo ifẹhinti, iṣakoso dukia, ati iṣowo ile-ifowopamọ ti o wa. Ẹka ile-ifowopamọ GTCO ni orilẹ-ede Naijiria, Guaranty Trust Bank Limited jẹ banki ti o niyelori julọ ni Nigeria nipasẹ iye ọja pẹlu idiyele ọja to ṣẹṣẹ julọ ni N840.26 bilionu. Guaranty Trust Bank Plc ti dasilẹ ni ọdun 1990 gẹgẹbi ile-iṣẹ layabiliti to lopin (LLC) ti a ṣe ilana nipasẹ Central Bank of Nigeria lati pese awọn iṣẹ iṣowo ati awọn iṣẹ banki miiran fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria. Ile-ifowopamọ bẹrẹ iṣẹ bi banki iṣowo ni ọdun 1991. Banki naa ṣe ifilọlẹ Ile-iṣẹ akọkọ rẹ ni Oṣu kejila ọjọ 11, ọdun 1991, ni The Plaza, Adeyemo Alakija, Victoria Island, Lagos. Ni ọdun 1992, Banki ṣii awọn ẹka meji ni Lagos (Ikeja ati Broad Street), bakannaa ẹka akọkọ ti oke ni Kano, ati ẹka Port-Harcourt ni ọdun 1993.
Guaranty Trust Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73727
73727
First City Monument Bank First City Monument Bank (FCMB), ẹgbẹ tí FCMB Group Plc, ó jẹ́ ilé ìṣe tí ìnáwó a dání tí headquartered ní Lagos. FCMB Group Plc ní ẹ̀ka mẹsan tí a pín wọn sì ìṣe owó mẹ́ta: commercial and retail banking, investment banking, and asset and wealth management. Ní Oṣu December 2020,iye tí dúkìá wọ́n ní yé lórí ní US $5 billion (NGN: 2 trillion). Ìtàn. Ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ dá ilé-ìfowópamọ́ yìí sílẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni City Securities Limited (CSL), ọdún 1977 sì ni wọ́n dá a sílẹ̀, láti ọwọ́ Oloye Subomi Balogun, ẹni tó jẹ́ ọ̀túnba Tunwashe ti ìlú Ìjẹ̀bú, tó jẹ́ olórí ìlú Yoruba kan. Ọdún 1982 ni wọ́n dá báǹkì yìí sílẹ̀, pẹ̀lú èso ìdókòwò láti CSL. Wọ́n sọ ọ di ilé-iṣẹ́ aládàáni ní ọjọ́ 20 oṣù April, ọdún 1982, wọ́n sì gba ìwé àṣẹ láti máa siṣẹ́ ní ọjọ́ 11 oṣù August, ọdún1983. Ó jẹ́ báǹkì àkọ́kọ́ tí wọ́n máa dá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ ìjọba tàbí láti òkè òkun. Ní ọjọ́ 15 oṣù July, ọdún 2004, wọ́n yi padà kúrò láti ilé-iṣẹ́ aláàdíni sí ilé-iṣẹ́ ìjọba, wọ́n sí fi sábẹ̀ Nigerian Stock Exchange (NSE) ní ọjọ́ 21 oṣù December, ọdún 2004.
First City Monument Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73728
73728
Ecobank Nigeria Ecobank Nigeria Limited, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ dáadáa sí Ecobank Nigeria, jẹ́ báǹkì gbogbogbò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn báǹkì tó gbàwé àṣẹ lọ́wọ́ báǹkì gbogbo gbò Nàìjíríà, báǹkì apàṣẹ fún orílẹ̀-èdè. Ìsọníṣókí. Báǹkì náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1989. Ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi báǹkì àgbáyé, nípa pípèsè ìdúnàádúrà lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan fún àwọn tí bá wọn ná ní ọjà Nàìjíríà. Báǹkì náà pín iṣẹ́ rẹ̀ sí ipele mẹ́ta: (a) Báǹkì oníṣòwò kéékèèké, (b) Báǹkì ìṣọ̀wọ́ ńláǹlà àti (c) Ilé ìṣura àti ètò ìṣúná. Báǹkì yìí máa ń pèsè àyè owó yíyá àti ètò ìdókòwò. Nígbà ìpín kẹ́rin ọdún 2011, ilé-iṣẹ́ Ecobank Nigeria nípasẹ̀ ilé-iṣẹ́ àgbà rẹ̀, Ecobank Transnational Inc (ETI) gba ìdá ọgọ́rùn-ún owó ìbábádòwò ní Oceanic Bank, dídá Ecobank Nigeria Limited tí ó fẹjú sílẹ̀. Nìpa fífẹjú Ecobank Nigeria, ó darí ohun ìní tí ó tó US$8.1 billion (NGN:1.32 trillion),èyí tí ó sọ ọ́ di ọ̀kan lára báǹkì ńlá márùn-ún Nàìjíríà nígbà náà. Nígbà náà,báǹkì yìí ní ẹ̀ka ìṣiṣẹ́ tó dá dúró mẹ́wàá lé ní ẹgbẹ̀ta, tí ó sọ ọ́ di báǹkì ńlá kejì ní orílẹ̀èdè nípa níní ẹ̀ka ìṣiṣẹ́ tó pọ̀jù. Ohun tí Ecobank lọ́wọ́ sí. Ecobank Nigeria jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ecobank, báǹkì Olómìnira ti àkójọpọ̀ ọmọ Áfíríkà,tí olú ilé-iṣẹ́ rẹ̀ wà ní Lomé, Togo, pẹ̀lú àwọn alábáṣiṣẹ́pọ̀ ní ìwọ̀-oòrùn, ọ̀gangan àti ìlà-oòrùn Áfíríkà. Ecobank, tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1985, ti ní ẹ̀ka tó lé ní ẹgbẹ̀rún, gbígba ènìyàn tó lé ní ẹgbààrún pẹ̀lú ọ́fíìsì ní orílẹ̀-èdè méjìlélọ́gbọ̀n bíi Benin, Burkina Faso, Burundi, Cameroon, Cape Verde, the Central African Republic, Chad, the Republic of Congo, the Democratic Republic of Congo, Côte d'Ivoire, Gambia, Ghana, Guinea, Guinea Bissau, Kenya, Liberia, Mali, Malawi, Niger, Nigeria, Rwanda, Sao Tome, Senegal, Sierra Leone, Togo, Uganda, Zambia àti Zimbabwe. Ecobank tún ń ṣe alámòjútó ẹ̀ka ìfowópamọ́ ní Paris àti ọ́fíìsì aṣojú ní Johannesburg, Dubai àti London. Ilé-iṣẹ́ àgbà. Ecobank Transnational Inc. (ETI) ni ilé-iṣẹ́ àgbà fún àwọn Ecobank Group, lára àwọn ilé-iṣẹ́ tí Wọ́n ń darí ni: ETI máa ń ta ìṣura wọn ní ibi mẹ́ta tí wón ti ń ṣe pàṣípààrọ̀ ìṣúra ní Áfíríkà tí bíi: the Ghana Stock Exchange (GSE), the Nigerian Stock Exchange (NSE) àti the BRVM stock exchange ní Abidjan, Ivory Coast. Ẹ̀ka ìṣiṣẹ́. Ní oṣù Kejìlá, ọdún 2011, Ecobank Nigeria Limited tí a fẹ̀ lójú ni a rí pé ó ní ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ tó tọ́ ẹgbẹ̀ta,ní gbogbo àgbègbè Federal Republic of Nigeria, títẹ̀lé àgbékalẹ́ Oceanic Bank.
Ecobank Nigeria
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73729
73729
Zenith bank Nigerian commercial financial services companyZenith Bank Plc jẹ́ ẹ̀ka ìfowópamọ ní ìlú Nìgíríà àti Anglophone apá iwọ̀ oòrùn Afíríkà . Ilé ìfowópamọ àpapọ̀ tí ìlú Nìgíríà tí fòǹtẹ̀ lu gẹ́gẹ́ bí ilé ìfowópamọ kéékèèké ,àjọ fún ètò ìfowópamọ ní ọjọ́ ọ́kànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 ní $16.1bn ni àkójọpọ̀ ìní wọn. Ilé Iṣẹ́ yìí wà lára Nigeria Stock Exchange àti London stock Exchange.
Zenith bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73730
73730
First Bank of Nigeria First Bank of Nigeria Limited jẹ́ ilé-ìfowópamọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ilé- iṣẹ́ ètò iṣúná ni ìpínlẹ̀ Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Ó jẹ́ báǹkì àkọ́kọ́ ní Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà. First Bank of Nigeria Limited ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òbí ilé-iṣẹ́ fún àwọn 'FBN Bank" ni orílẹ̀-èdè Congo, Ghana, Gambia, Guinea, Sierra-Leone ati Senegal ; FBN Bank UK Limited ní United Kingdom pẹ̀lú ẹ̀ka kan ní Paris; Ọ́fììsì Aṣojú First Bank ní Ìlú Beijing láti mú ìṣòwò tí ó ní ìbátan sí ìṣòwò láàárin àwọn agbèègbè. First Bank tún tukò First Pension Custodian Nigeria Limited, ilé-iṣẹ́ ètò ọ̀rọ̀ ifehinti àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà. Àwọn oníbàárà ti First Bank Group jẹ́ iṣẹ lati inu nẹtiwọọki ti o ju awọn ipo iṣowo 700 kọja Afirika. Láti ṣe ìgbélárugẹ àti ìpolongo ètò-iṣúná dé ọ̀dọ̀ àwọn ti kò mọ̀ nípa báǹkì, First Bank ní nẹ́tíwọọ̀kì Ilé-ìfowópamọ́ Aṣojú lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ipo tó ju 200,000 lọ káààkiri Nàìjíríà. Ọ̀gá ni wọn jẹ́ nínu ètò-iṣúná wọn sì ní àwọn oníbàárà tí o tóbi jù ni ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà pẹ̀lú àwọn oníbàárà tó lé ní mílíọ̀nù 18. Fún ọdún mẹ́jọ (2011 - 2018) ni First Bank Nigeria fi gba ami ẹ̀yẹ Best Retail Bank ní Nàìjíríà láti ọwọ́ The Asian Banker First Bank gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ kan gba àwọn òṣìṣẹ́ tó ju 16,000 lọ, àti pé ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ 'Ibi Ti o dara julọ lati Ṣiṣẹ'. O ń ṣiṣẹ́ mẹrin pàtàkì nínu ètò ìṣòwò tó gbọgbón (Strategic Business Units) SBU - Ilé-ìfowópamọ́ ṣọ́ọ̀bù, Ilé-ìfowópamọ́ Ilé-iṣẹ́, Ilé-ìfowópamọ́ Ìṣòwò, àti Ilé-ìfowópamọ́ Àpapọ̀ ti gbogbo ènìyàn. Ó ti ṣe ìṣetò tẹ́lẹ̀ bí ilé-iṣẹ́ ìdádúró ṣiṣiṣẹ ṣaaju imuse ti eto ile-iṣẹ Holding ti kii ṣiṣẹ (FBN Holdings) ni ọdun 2011/2012.
First Bank of Nigeria
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73733
73733
Keystone Bank Limited Nigerian commercial bankKeystone Bank Limited,ni ile ifowopamo kan ni Nigeria. O je lara ile ifowopamo ti o gba iwe ofin lowo Ile ifowopamo olu ilu ile Nigeria, the national banking regulator. Overview. Keystone Bank ma n fun eto gbigba Owo ati ti toju Owo fun awón kopirason nla, Ile-ise Ijoba, Ile-ise kekere ati awon eeyan. Ile-ise ifowopamo nla ni Keystone Bank je ti o n fun awón eeyan ni awon nnkan ti o ni se pelu Owo ni ilu Nigeria. , gbogbo Owo ninu isunwon ile ifowopamo naa je US$1.916 billion (NGN:307.5 billion), pelu Owo inu isunwon awón shareholders ti o je US$213.3 million (NGN:34.23 billion). Itan. Ni ojo Eti, ojo karun-un osu kejo odun 2011, ni a fun Keystone Bank Limited ni iwe ofin lati Ile- ifowopamo olu ilu Nigeria (Central Bank of Nigeria (CBN)). On the same day, CBN revoked the banking license of Bank PHB. Keystone Bank assumed the assets and some liabilities of the now defunct Bank PHB. On 22 March 2017, Asset Management Company of Nigeria announced that Keystone bank had been sold to investors for 25 billion naira ($81.5 million). It was sold to Sigma Golf-Riverbank consortium. Ownership. The bank was previously owned by the Asset Management Corporation of Nigeria (AMCON), an arm of the Federal Government of Nigeria. The bank is currently owned by Sigma Golf River Bank Consortium after being acquired from the Asset Management Corporation of Nigeria (AMCON) in March 2017. Keystone Bank Group. The bank together with its onshore and offshore subsidiaries, constitute the Keystone Bank Group. The bank's subsidiaries include the following: Branch network. According to its website, the bank maintains a network of over 150 business offices and locations in all the states of Nigeria. Some of its products offered to the public includes; QuickSave/ QuickSave Plus, Paytime Accounts, Partner Plus, Active Dom/Dom Extra, Growbiz Account, Future Account, NIDA etc. Governance. After the sale of the bank by AMCON, the bank is now governed by a substantive Board of Directors. The Chairman of the Board of Keystone Bank Limited is Alhaji Umaru H. Modibbo. The managing director and chief executive officer of the bank is Olaniran Olayinka who was appointed in March 2020 shortly after the exit of the acting MD/CEO, Mr. Abubakar Danlami Sule. The current executive directors of the bank include; Messrs Tijjani Aliyu, Adeyemi Odusaya and Lawal Jibrin Ahmed. Other sources. Nigerian commercial bank Keystone Bank Limited, is a commercial bank in Nigeria. The bank is one of the commercial banks licensed by the Central Bank of Nigeria, the national banking regulator. Overview. Keystone Bank offers banking services to large corporations, public institutions, small to medium enterprises (SMEs) and individuals. The bank is a large financial services provider in Nigeria. , the bank's total assets were valued at US$1.916 billion (NGN:307.5 billion), with shareholders' equity valued at about US$213.3 million (NGN:34.23 billion). History. On Friday 5 August 2011, Keystone Bank Limited was issued a commercial banking license by the Central Bank of Nigeria (CBN). On the same day, CBN revoked the banking license of Bank PHB. Keystone Bank assumed the assets and some liabilities of the now defunct Bank PHB. On 22 March 2017, Asset Management Company of Nigeria announced that Keystone bank had been sold to investors for 25 billion naira ($81.5 million). It was sold to Sigma Golf-Riverbank consortium. Ownership. The bank was previously owned by the Asset Management Corporation of Nigeria (AMCON), an arm of the Federal Government of Nigeria. The bank is currently owned by Sigma Golf River Bank Consortium after being acquired from the Asset Management Corporation of Nigeria (AMCON) in March 2017. Keystone Bank Group. The bank together with its onshore and offshore subsidiaries, constitute the Keystone Bank Group. The bank's subsidiaries include the following: Branch network. According to its website, the bank maintains a network of over 150 business offices and locations in all the states of Nigeria. Some of its products offered to the public includes; QuickSave/ QuickSave Plus, Paytime Accounts, Partner Plus, Active Dom/Dom Extra, Growbiz Account, Future Account, NIDA etc. Governance. After the sale of the bank by AMCON, the bank is now governed by a substantive Board of Directors. The Chairman of the Board of Keystone Bank Limited is Alhaji Umaru H. Modibbo. The managing director and chief executive officer of the bank is Olaniran Olayinka who was appointed in March 2020 shortly after the exit of the acting MD/CEO, Mr. Abubakar Danlami Sule. The current executive directors of the bank include; Messrs Tijjani Aliyu, Adeyemi Odusaya and Lawal Jibrin Ahmed.
Keystone Bank Limited
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73738
73738
Kuda Bank Kuda,tí a tún mọ̀ sí Kuda Technologies, jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ tó níṣe pẹ̀lú ètò ìṣúná ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti U.K. Babs Ogundeyi àti Musty Mustapha ni ó dáa sílẹ̀ ní ọdún 2019. Kuda wà lára ọ̀kan nínú méje àwọn ilé-iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ ìbẹ̀rẹ̀pèpẹ̀ Áfíríkà WEF ní ọdún 2021. Iye ìwọ̀n ìfowópamọ́ Kuda ni $500 million, ó sì ti lé kọja $90 million láti ọwọ́ olùdókòwò bí i Target Global àti Valar Ventures.
Kuda Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73739
73739
Access Bank   Access Bank plc, tí a mọ̀ sí Access Bank, jẹ́ ilé-ìfowópamọ́ gbogboogbò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà; ó sì jẹ́ ohun-ìní Access Bank Group . Ó ní ìwé-àṣẹ nípasẹ̀ Central Bank of Nigeria, olùṣàkóso ilé-ìfowópamọ́ orílẹ̀-èdè. Ní àkọ́kọ́, wọ́n jẹ́ báńkì ilé-iṣẹ́ kan; ní ọdún 2012, wọ́n gbòòrò sí báńkì ti ara-ẹni àti ilé-ìfowópamọ́ ìṣòwò. Access Bank àti Diamond Bank dàpọ̀ ní Ọjọ́ kìn-ín-ní, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2019. Ní ìparí ìdàpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìfowópamọ́ ti Diamond, Access Bank ṣe àfihàn ààmì ìdánimọ̀ tuntun rẹ̀, èyí tí ń ṣe àfihàn ìbẹ̀rẹ̀ ti ilé-ìfowópamọ́ tuntun ńlá kan. Ilé-ìfowópamọ́ yìí gba àwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní 28, 000 ní ọdún 2021. Lẹ́yìn ìṣọpọ̀ yìí, Access Bank plc di báǹkì tí ó tóbi jùlọ ní Áfíríkà lágbọn ti oníbàárà, pẹ̀lú àwọn oníbàárà tó ju mílíọ̀nù méjìlélógójì lọ, àti báńkì tí ó tó tóbi jùlọ ní Nàìjíríà lágbọn ti dúkíà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2021, Access Bank kéde pé ó ti ṣe ìdánimọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà tuntun mẹ́jọ fún ìfẹ̀lójú tó lọ́ọ̀rìn, pẹ̀lú èróńgbà láti je àǹfàní láti inú àdéhùn ìṣòwò ọ̀fẹ́ jákèjádò kọ́ńtìnẹ́ẹtì kan. Awọn ìlú tó jẹ́ ọjà àfojúsùn wọn ni Morocco, Algeria, Egypt, Côte d'Ivoire, Senegal, Angola, Namibia àti Etiopia, èyítí yóò ṣe ìfẹ̀lójú mímọ̀-lágbàáyé báńkì náà sí àwọn orílẹ̀-èdè méjìdínlógún. Access Bank ni a nírètí láti ṣètò àwọn ọ́fíìsì sí àwọn orílẹ̀-èdè, ṣe alábàáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-ìfowópamọ́ tó wà, àti kí ó lo àwọn ẹ̀rọ agbagbe rẹ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn oníbàárà.
Access Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73740
73740
Unity Bank plc Unity Bank, ti a mo si Unity Bank plc, je ile ifowopamo kan ni orike ede Naijriaje owo ise nla kan to won se ni orile ede Naijiria. Won wa ni ile eko ni Naijria.Unity itoju ise kan ni Abuja, olu-ilu Naijiria. Ni December 2012,ile ifowopamo akojopo ohuni wo US$2.45 billion (NGN:396 billion), pelu aeon shareholders' equity of approximately wo US$322 million (NGN:51.5 billion ). Ẹgbẹ́ Unity Bank. Unity Bank plc, wà lábẹ́ àsíá Unity Bank Group. Àwọn ẹgbé yòókù tó wà lábé ẹgbé náà ni:
Unity Bank plc
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73742
73742
Sterling Bank Sterling Bank Plc, tó jẹ́ ilé-ifowópamọ́ iṣowo orilẹ-ede ti o ni kikun ti ni iwe-aṣẹ nipasẹ Central Bank of Nigeria . Lori awọn ebute Reuters ati Bloomberg, o jẹ idanimọ bi STERLNB. LG ati STERLNBA: NL lẹsẹsẹ. Ilé-ifowópamọ́ máa ń pese àwọn iṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kọọkan, àwọn iṣowo kékeré (SMEs) àti àwọn ilé-iṣẹ́ nlá. Titi di Oṣù kéjìlá ọdún 2021, iye nẹtiwọọki ẹ̀ká ilé-ifowopamọ jẹ 141, wọn pin kaakiri orílè-èdè Naijiria pẹ̀lú gbogbo ohun tó níye tí ó sì ju NGN 1.6 trillion). Itan. Ní oṣù kínní, ọdún 2006, gẹgẹbi apakan ti isọdọkan ile-iṣẹ ile-ifowopamọ Naijiria, NAL Bank pari iṣiṣẹpọ pẹlu awọn ilé-ifowopamọ Nàìjíríà mẹ́rin mìíràn tí ó jẹ́, Magnum Trust Bank, NBM Bank, Trust Bank of Africa àti Indo-Nigeria Merchant Bank (INMB) ó sì gba orúkọ 'Sterling Bank'. Àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó dapọ ni a ṣepọ ni aṣeyọri ati pe wọn ti ṣiṣẹ gẹgẹbi ẹgbẹ ti o ni iṣọkan lati igba naa. Ni ibamu pẹ̀lú ifagile ti Central Bank of Nigeria ti ile-ifowopamọ agbaye, Sterling Bank nṣiṣẹ bayi gẹgẹbi banki iṣowo ti orilẹ-ede, ti npa awọn ohun-ini ni awọn ile-iṣẹ ati awọn ile-iṣẹ alafaramo. Ni aarin ọdun 2011, Sterling Bank Plc gba ẹtọ ẹtọ ti Banki Trust Equatorial ti iṣaaju. Awọn iṣẹ ṣiṣe. Awọn iṣẹ ti ilé- ati awọn ọja jẹ akojọpọ si awọn iṣupọ mẹrin: Soobu & Ifowopamọ Onibara, Ile-ifowopamọ Iṣowo, Ile-ifowopamọ ile-iṣẹ ati Ile-ifowopamọ Ajọ. Sterling ti ṣe ifilọlẹ ọpọlọpọ awọn ipilẹṣẹ labẹ Ile-ifowopamọ Soobu & Olumulo gẹgẹbi Ile-ifowopamọ Aṣoju (ti a ṣe apẹrẹ lati fa ifamọra labẹ banki/aiṣe-ifowopamosi), Micro-kirẹditi fun awọn ọdọ ati Specta (ipilẹ awin soobu adaṣe adaṣe). Awọn iṣowo ile-ifowopamọ Iṣowo rẹ ni awọn apakan pupọ pẹlu Iṣẹ-ogbin fun eyiti ile-ifowopamọ ti gba ọpọlọpọ awọn ẹbun lakoko ti Ile-ifowopamọ Ile-iṣẹ nfunni ni iye fifi imọran & awọn iṣẹ ikojọpọ fun awọn parastatals ijọba. Ile-ifowopamọ ile-iṣẹ Sterling bo ọpọlọpọ awọn apa pẹlu Awọn ibaraẹnisọrọ, Agbara ati Irin, Ounjẹ ati Awọn ohun mimu laarin awọn miiran. Awọn iṣẹ pataki. Ile-ifowopamọ tun ṣaajo si awọn ẹni-kọọkan Nẹtiwọọki Nẹtiwọọki giga nipasẹ Ile-ifowopamọ Aladani ati apa iṣakoso Oro ti nfunni awọn ọja bii Igbẹkẹle ati Awọn iṣẹ Fiduciary, Isakoso Philanthropy, Advisory Idoko, laarin awọn miiran.
Sterling Bank
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73745
73745
First Lady of Nigeria Informal title held by the spouse of the president of Nigeria Arábìnrin ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ àkọ́lé gbẹ̀fẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ àtéwógbà, tí ìyàwó ti Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mú dání. Ìyàwó ààrẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Aisha Buhari tí ó ti di àkọ́lé náà láti ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015. Òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò ṣẹ̀dá ọ́fíìsì fún arábìnrin sí ààrẹ àkọ́kọ́ ti orílẹ̀-èdè tàbí okùnrin alákọbẹ̀rẹ̀ àkọ́kọ́.[1] Síbẹ̀síbẹ̀, ìnáwó òṣíṣẹ́ àti òṣìṣẹ́ ti pín sí arábìnrin àkọ́kọ́ ti Nàìjíríà láti ìgbà òmìnira orílẹ̀-èdè náà. Arábìnrin àkọ́kọ́ ni a kojú nípasẹ̀ àkọ́lé 'Her Excellency'. Ìtàn. Stella Obasanjo ni ìyàwó ààrẹ Nàìjíríà nìkan tí ó ti kú ní ọ́fíìsì.
First Lady of Nigeria
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73746
73746
Audrey Ajose Nigerian lawyer and writer Audrey Olatokunbo Ajose (ọjọ́-ìbí c. 1937) jẹ́ Àgbẹjọ́rò àti Akòwé ọmọ Nàìjíríà. Ó ṣiṣẹ́ bí aṣojú orílẹ̀-èdè rẹ̀ sí Scandinavia láti ọdún 1987 sí 1991. Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀ Àti Ẹ̀kọ́. Ọmọbìnrin Ọmọba Oladele Ajose àti Beatrice Spencer Roberts. Audrey Ajose jẹ́ ọmọ obìnrin ilẹ̀ òkèèrè kan tí ó fẹ́ ọmọ Nàìjíríà. Ó kọ ẹ̀kọ́ ìròyìn ní Regent Polytechnic. Ọ́ kọ ẹ̀kọ́ àti àdaṣe òfin ṣùgbọ́n tún tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ ní ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́. Ó tún kọ ẹ̀kọ́ nípa'theology' ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa 'theology' ní ilé ìjọsìn Lutheran.
Audrey Ajose
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73747
73747
Emily Nkanga Emily Nkanga jẹ́ ayàwòrán ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan, ó tún ń ṣe fíìmù jáde. Nkanga gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olórin bi Koker, Aramide, Boj, Olamide, Jidenna, Not3s, Mr Eazi, Mayorkun, Adekunle Gold, Sarz, òṣèré Adesola Osakalumi, agbábọ́ọ̀lù Tammy Abraham àti Femi Kuti. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwòrán Nkanga jẹ́ nípa àwọn ènìyàn tí wón ti pàdánù ilé àti ọ̀nà wọn ní àríwá Nàìjíríà nítorí ogun Boko Haram. Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n bí Nkanga ní ìpínlẹ̀ Èkó sínú ìdílé Idongesit àti Mosunsola Nkanga, Ìpínlẹ̀ Èkó náà ni wọ́n ti tọ dàgbà. Ó lọ ilé-ìwé Air Force Girls Comprehensive School, Jos, Ìpínlẹ̀ Plateau, lẹyìn náà, ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní American University of Nigeria, Yola, Ìpínlẹ̀ Adamawa, ní Àríwá Nàìjirià. Ó ni àmì ẹyẹ masters of art nínú ṣíṣe àgbéjáde láti Yunifásitì Goldsmiths ti London.
Emily Nkanga
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73749
73749
Lepacious Bose Bose Ogunboye (tí a bí ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹrin ọdún 1976) tí ọ̀pọ̀lopọ̀ mọ̀ sí Lepacious Bose jẹ́ aláwadà àti òṣèrébìnrin ní ilé isé Nollywood. Ní ọdún 2014, ó gba àmì-ẹ̀yẹ 2014 Golden Icons Academy Movie Awards fún eré àwàdà rẹ̀ nínú fíìmù “Being Mrs Elliot”.
Lepacious Bose
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73752
73752
Biola Adebayo Biola Adebayo jẹ́ òṣèrébìnrin tí ó ṣeré nínú "àwọn eré bi Jade's cross", "Tori Owo" àti àwọn eré mìíràn. Òṣèrébìnrin náà, Eniola Badmus àti Banky W ṣe ìpòlongo nípa àwọn ọ̀nà láti kọjú ààrùn coronavirus nípa tí ààrùn náà ń jà fitafita ní Nàìjíríà, wọ́n rọ àwọn ènìyàn láti dúró sínú ilé àti láti lọ àwọn èlò ìfowọ́. Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀. Biola gba àmì-ẹ̀yẹ Master degree nínú ìmọ̀ Public Administration ní Yunifásítì ìlú Èkó.
Biola Adebayo
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73753
73753
Jamilah Tangaza Jamilah Tangaza níkejì Jamilah Tangaza) jẹ́ àkọ̀ròyìn àti ìmọ-ẹ̀rọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ àkọ̀ròyìn BBC tẹ́lẹ̀, níbi tí ó ti ṣisẹ́ ní onírúurú àwọn ìpò ko tó di olórí Hausa service. Tangaza jẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ tí Reuters institute fún ikẹ́kọ ti ìwé ìròyìn, university of Oxford àti ọmọ ẹgbẹ́ ti chatered management institute ti united kingdom
Jamilah Tangaza
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73754
73754
Toluwani Obayan Nigerian writer Toluwani Obayan jẹ́ Akọ̀wé ìbojú ara Nàìjíríà, olókìkí jùlọ fún kíkọ àwọn fíìmù bíi 'Ponzi', 'This Lady Called Life'. Ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìwé tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ 'Becoming A Spectacular Woman'.
Toluwani Obayan
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73755
73755
Tokunbo Abiru Nigerian politician and banker (born 1964)Mukhail Adetokunbo Abiru FCA (tí a bí ní 15th March ọdún 1964) jẹ́ òṣìṣẹ́ báǹkì àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni sẹ́nátọ̀ tó ń sojú àgbègbè senatorial Lagos east ní ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ Olùdarí àti alákòso àgbà ilé ìfowópamọ́ Polaris bank limited, Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí. Ó lọ sí ètò ìṣàkóso ìlọsíwájú ti ilé-ìwé ìṣòwò Harvard tí ó wáyé fún òsẹ̀ mẹ́fà. Ó gba òye B.Sc (Economics) ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ipínlẹ̀ èkó. Ó jẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ tí institute of chartered accountants of Nigeria (ICAN) àti olùkọ́ni ọlà ti chartered institute of bankers of Nigeria (CIBN). Ní ọjọ́ 24th oṣù kẹ́jọ̀ ọ̀dún 2020, Abiru fi ìpò sílẹ ní báǹkì Polaris láti dijé du ìpò ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní èkó east lábẹ́ ìpìlẹ ẹgbẹ́ All Progressives Congress. Ọnà Iṣẹ́. Òun ni ó jẹ́ Olùdarí àgbà ilé ìfọwópamọ́ First bank Nigeria Ltd láàrin ọdún 2013 sí 2016, ó sì tún jẹ́ kọmísónà fún ètò ìnáwó ní ìpìnlẹ̀ èkó láárín ọdún 2011 sí 2013 lábẹ́ ìdarí Babatunde R. Fashola (SAN) gẹ́gẹ́ bí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó. Central Bank of Nigeria (CBN) yàn án ní òṣù kèje ọdún 2016 gẹ́gẹ́ bí alákòso ẹgbẹ́ kan láti ran ilé ìfowópamọ́ Skye Bank nínú ewu tí ó ń báwọn fínra. Àṣeyọrí ẹgbẹ́ yìí ni ó jẹ́ kí ilé ìfowópamọ́ Polaris wà ní òní Tokunbo tún ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ pẹ̀lú Airtel Mobile Networks Limited, (báyìí FBN Quest Merchant Bank Limited); FBN bank sierra-leone limited; àti Nigeria inter-bank settlement system PLC(NIBBS). Lákọkọ́ àjàkáyé àrùn covid 19, ó ti ṣètorẹ̀ àwọn ìbojú ìparada 150,000 sí àwọn ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè rẹ̀. Àkọsílẹ Aladani. Lásìkò Abiru gẹ́gẹ́ bí kọmísónà fún ètò ìnáwó nípìnlẹ̀ èkó, ìpínlẹ̀ náà fi owo 80 billion naira, eléyìí tí ó gbà àmi ẹyẹ EMEA finance best local currency bond award fún 2012. Ó ṣí àwọn ijiroro lórí owó-orí ní ìpínlẹ̀ èkó lẹ́hìn tí ìsawárí tí àwọn ènìyàn tí ó gbà owó-orí tí ó jù 5.5 million ní ọdún 2013. Ìgbìyànjú rẹ̀ tún yọrí sí àlekùn àwọn ìrànwọ́ owo-wíwọlé lílò ile-ile sí ohun tí N6.2bn. Abiru tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti Lagos HOMs committee, tí ó wà ní alábojuto Lagos state home ownership mortgage scheme (HOMs) tí á ṣe láti dínkù àìpé ilé ní ìpínlẹ̀ náà. W Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí sẹ́nétọ̀ ti Lagos East senatorial district nínú ìdìbò a ọjọ́ karùn-ún December, ọdún 2020
Tokunbo Abiru
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73756
73756
Funke Adesiyan Funke Adesiyan jẹ́ òṣèrébìnrin, Olóṣèlú àti olùrànlọ́wọ́ Aisha Buhari, ìyàwó ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àṣà àti àwùjọ. Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀. Adesiyan jẹ́ ọmọ bíbí Ìlú Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó lọ ilé-ìwé Time and Tide International School, Ibadan City academy, Saint Anne's School, àti Oriwu College Ikorodu fún ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti Sẹ́kọ́ndírì rẹ̀. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ nínú ìmò òfin ní Yunifásítì Olabisi Onabanjo. Adesiyan kọ́ nípa ṣíṣe fíìmù ní ilé-ìwé New York Film Academy.
Funke Adesiyan
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73757
73757
The 48 Laws of Power 1998 non-fiction New York Times bestseller book by Robert Greene Òfin Méjìdínláàádọ́ta Agbára' (The 48 Laws of Power) (1998) jẹ́ ìwé àpilẹ̀kọ oníṣìípayá tí oǹkọ̀wé America, Robert Greene kọ ọdún 1998. Ìwé yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tí "New York Timee" tà wàràwàrà, wọ́n ta igba kan lé ní mílíọ̀nù kan ìwé náà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà; it is popular with prison inmates and celebrities.
The 48 Laws of Power
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73758
73758
Robert Greene (American author) American author (born 1959) Robert Greene (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù karùn-ún ọdún 1959) jẹ́ oǹkọ̀wé ọmọ Amẹ́ríkà tí ó kọ ìwé nípa strategy, power, àti seduction. Ó ti kọ oríṣiríṣi ìwé tí wọ́n tà wàràwàrà káàkiri àgbáyé, lára wọn ni "Òfin Méjìdínláàádọ́ta Agbára", "The Art of Seduction", "The 33 Strategies of War", "The 50th Law" (with rapper 50 Cent), "Mastery", àti "The Laws of Human Nature". Greene fìgbà kan sọ wípé òun kì í tẹ́lẹ̀ gbogbo ìmọ̀ràn tí wọ́n bá gba òun, wípé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba òun ní ìmọ̀ràn lè banújẹ́ lọ́dọ̀ òun."
Robert Greene (American author)
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73759
73759
Shola Adewusi Shola Adewusi (tí a bí ní ọdún 1963) jẹ́ òṣèrébìnrin Òṣerébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àpẹrẹ awọn iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ìmóhùn máwòrán ni "Little Miss Jocelyn", BBC comedy sketch show series tí Jocelyn Jee Esien kọ, Òun ni ó ń kó ipa Auntie Olu lọ́wọ́ lọ́wọ́ nínú fíìmù CBS; "Bob Hearts Abishola"
Shola Adewusi
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73760
73760
Igbo Biseni Igbó Biseni igbó omi tàbí igbó irà tí ó fìkàlẹ̀ láàárín ìlú Ahoada àti apá òkè igbó Orashi ní agbègbè Niger Delta. Igbó náà tóbi tó ìwọ̀n kìlómítà 219 ní ìbú àti Òró tí ó kún fún ilẹ̀ omi. Àwọn koríko rẹ̀. Igbó Biseni jẹ́ inú irà tí ó kún fún àwọn igi gẹdú àti àwọn koríko mìíràn tí wọ́n sáàbà máa ń gbẹ lásìkò ẹrùn tí ó sì máa ń kún fún omi rọ́rọ́ nígbà òjò. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Igi agbe àti àwọn igi mìíràn tí wọ́n fẹ́ràn omi ni wọ́n wọ́pọ̀ nínú igbó Biseni. Bákan náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn koríko omi bíi òṣíbàtà àti àwọn koríko mìíràn ló kún fọnfọn sí ibẹ̀, pàápàá jùlọ lẹ́bàá igbó náà. Àwọn ẹranko. Igbó Biseni kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹyẹ àti àwọn ẹranko-afọ́mọlọ́yàn tí wọ́n ṣọ̀wọ́n.
Igbo Biseni
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73762
73762
JAIZ
JAIZ
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73763
73763
Diamond bank plc
Diamond bank plc
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73764
73764
Sambisa Forest Sambisa Forest jẹ́ igbó kan ní Ìpínlẹ̀ Bọ̀rnó, àríwá apá ìlà oòrùn Nàìjíríà. Ó wà ní gúúsù apá ìwọ oòrùn Chad Basin National Park, ó sì tó bí kilometer ọgọ́ta láti gúúsù ìlà-oòrùn Maiduguri, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Bọ̀rnó. Ilé Sambisa forest tó kilometer èjì dín ní okòó-lé-ní-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta(518). Ilẹ̀ Sambisa. Sambisa forest wà ní àríwá apá ilà-oòrùn ti ìwọ oòrùn Sudanian Savanna àti ní gúúsù Sahel Savannah àti bi kilometer ọgọ́ta láti gúúsù ìlà-oòrùn Maiduguri, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Borno. Ilẹ̀ rẹ̀ gba díẹ̀ nínú àwọn Ìpínlẹ̀ Borno, Yobe, Gombe, Bauchi, lára ilẹ̀ Darazo, Jigawa, àti ara ilẹ̀ àríwá Ipinle Kano. Ó wà lábẹ́ ìdarí Àwọn Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Nàìjíríà ti Askira/Uba ní apá gúúsù rẹ̀, Damboa ní apá ìwọ̀ oòrùn gúúsù rẹ̀, àti Konduga òun Jere ní apá ìwọ̀ òórùn rẹ̀. Àwọn ènìyàn so igbó náà ní Sambisa forest nítorí pé ìlú kan wà ní ẹgbẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Sambisa. Ìkọ̀ Boko Haram. Igbó Sambisa, pàápàá jùlọ ibi ilẹ̀ àpáta tí ó wà ní Gwoza lẹ́gbẹ àlà Cameroon, jẹ́ ibi tí àwọn Ìkọ̀ Boko Haram fi ń ṣelẹ́, ìdánilójú sì wà pé ibè ni wọ́n kó àwọn ọmọ tí wọ́n jí gbé ní Chibok ní oṣù kẹrin ọdún 2014. Ní ọdún 2015, àwọn ọmọ ológun Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ sí ń dójú ìjà kọ Boko Haram nínú igbó náà, ṣùgbọ́n wọ́n rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí wọ́n ri pé àwọn Ikọ̀ Boko Haram ti gbin àwọn àdá olóró síbẹ̀ àti pé àwọn ikọ̀ Boko Haram mo bí ilẹ̀ náà ṣe rí ju àwọn ọmọ ológun Nàìjíríà lọ. Pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo èyí, ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2015, àwọn ibùdó Boko Haram mẹ́rin ní igbó Sambisa ni àwọn ọmọ ológun gbà tí wón sì tú àwọn obìnrin tí ó fèrè tó ọ́ọ̀dúnrún sílẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn yìí kìí se àwọn ọmọ Chibok tí Boko Haram jí gbé.
Sambisa Forest
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73765
73765
Jos Plateau Jos Plateau jẹ́ ilẹ̀ òkè kan tí ó sún mọ́ àárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n fún ilẹ̀ náà ní orúkọ rẹ̀ nítorí pé ó wà ní Ìpínlẹ̀ Plateau, àti nítorí Jos, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Plateau. Ilẹ̀ òkè náà jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pẹ̀lú oríṣi àṣà àti èdè. Ilẹ̀ Jos Plateau. Jos Plateau ní ilẹ̀ tí ó tó 8600 km². Gígún rẹ̀ kọjá òkun sì tó kìlómítà kan, òun ni ó tóbi jù nínú àwọn ilẹ̀ tí ó fi kìlómítà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kọjá òkun ni Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ odò ní orísun wọn láti Jos plateau. Àwọn odò bi Odò Kaduna, Odò Gongola. Àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ibẹ̀. Jos Plateau súnmọ́ àárín Nàìjíríà, ó sì tó àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà ọgọ́ta tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ jẹ́ àwọn èdè tí ó jọ mọ́ èdè Chad. Méjì nínú àwọn èdè tí wọ́n ń sọ jù níbẹ̀ ni èdè Berom àti èdè Ngas. Àwọn èdè míràn ni Mwaghavul, Pyem, Ron, Afizere, Anaguta, Aten, Irigwe, Chokfem, Kofyar, Kulere, Miship, Mupun àti Montol.
Jos Plateau
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73766
73766
Charles Ndukuba
Charles Ndukuba
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73767
73767
Masoja Msiza Masoja Josiah Msiza (ti a bi ni Oṣu Kẹwa 5, 1964) jẹ oṣere South Africa kan, akewi ati akọrin. O je olokiki julọ fun iṣafihan “Nkunzi Mhlongo” ni telenovela Uzalo ti o gba ami-eye. Tete aye. Wan bi Msiza ni Kwa-Thema, ilu kan to wa ni agbegbe South Africa ti Gauteng. Ifẹ rẹ fun iṣere bẹrẹ nigbati o jẹ ọmọ ọdun 9 ati pe o gbadun kopa ninu iṣẹre ati awọn kilasi ere. Ni ọmọ ọdun 14 o kopa ninu idije ere-idaraya ni ile-iwe rẹ eyiti o bori. Lẹ́yìn tí ó parí ilé ẹ̀kọ́, ó rí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí awakùsà, ó sì wá parí rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ pẹ̀lú àwọn awakùsà mìíràn tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìkọlù . Lẹhin iyokuro rẹ, o pinnu lati lepa ala rẹ lati di oṣere kan ati pe gigi akọkọ rẹ jẹ ifihan ninu ere kan ti a pe ni “Mfowethu” eyi ti Gibson Kente je oludari. Iṣẹ. Msiza bẹrẹ iṣẹ rẹ bi akewi osi tun di ipele ati oṣere tẹlifisiọnu, akọrin ati aroso itan. O ti farahan ni ọpọlọpọ awọn fiimu olokiki bi Kalushi: Itan ti Solomon Mahlangu ati Awọn awọ Milionu kan . Bibẹẹkọ, ipa ti o ṣe pataki julọ ni iṣafihan ti oluwa ilufin aibikita Nkunzebomvu “Nkunzi” Mhlongo lori ifihan tẹlifisiọnu ti a wo julọ ni South Africa Uzalo . O tun si farahan ni ọpọlọpọ awọn jara TV gẹgẹbi Scandal!, Shreads ati Dreams, Rhythm City, Intersexions, Sokhulu & Partners, ati Ṣiṣe awọn senti pẹlu Sitholes. Ni ọdun 2016, o gba kikopa ipa akọkọ rẹ ni tẹlifisiọnu ni telenovela kan ti wan pe ni “ring of Lies”. Ni odun 2004, o kọ awọn oriki fun awon Ẹgbẹ Bọọlu Orilẹ-ede South Africa no gba ti wan Se figagbaga AFCON ni Tunisia . O tun kọ ati ṣe awọn oriki igbega fun redio ibudo ti o tobi julọ ni South Africa Ukhozi FM . Ni Oṣu Kẹfa ọjọ 22, Ọdun 2019, Masoja Msiza pelu Dudu Khoza ṣe igbekale Awọn ẹbun Orin Cothoza Ọdọọdun akọkọ ti o gbalejo nipasẹ ẹgbẹ agbabọọlu A cappella ti o bori pupọ Ladysmith Black Mambazo . Igbesi aye ara re. Msiza jẹ baba ọmọ mẹta, ọmọkunrin kan ati awon ọmọbinrin meji.
Masoja Msiza
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73769
73769
Gígé igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà Gígé igi láti ṣe pákó, gígé igi lulẹ̀ láti gbin irúgbìn àti gígé igi lulẹ̀ láti fi dánọ́ jẹ́ gbòógì jùlọ nínú àwọn ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń gé igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà. Láàrín ọdún 2000 sí 2005, Nàìjíríà jẹ́ rílẹ̀-èdè tí ó gé igi lulẹ̀ jùlọ ní àgbáyé, gẹ́gẹ́ bí àjọ the Food and Agriculture Organization ti United Nations (FAO) ṣe sọ. Ní àwọn ọdún 1950s, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ni wọ́n fi òfin dè pé kí ẹnikẹ́ni má gégi níbẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n ti gé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn igi tí ó wà ní àwọn ilẹ̀ yìí lulẹ̀, ọkàn lára àwọn ìdí tí eléyìí fi ṣẹlẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni àwọn ènìyàn ń ṣe lónìí tí ó nílò kí wọ́n lo igi. Àwọn ìdí tí wọ́n fi ń gégi lulẹ̀. Ọ̀pọ̀lopọ̀ ǹkan ní òun fa gígé igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà. Iṣẹ́ àgbẹ̀. Ilẹ̀ tí àwọn àgbè nílò fún gbí gbin ǹkan ọ̀gbìn ń posi nítorí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń pò si lólojúmọ́, èyí mú kí àwọn àgbẹ̀ ma gé àwọn igi inú igbó lẹ̀ láti fi àwọn ilẹ̀ náà ṣe oko. Àwọn àgbẹ̀ míràn tún féràn kí wọ́n ma gbin ọ̀gbìn sí àwọn ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọdọọdún Wíwá epo. Wíwá epo ti fa kí wọ́n gé ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà. Lílo igi dáná. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ń ta epo. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Nàìjíríà sì ń lọ igi dáná, pàápàá jùlọ, àwọn tí ó ń dáná níbi ìnáwó, èyí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma gé igi lulẹ̀ láì gbin òmíràn. Ọ̀làjú. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ń kó lọ àwọn ìlú ńlá, ó jẹ́ dandan fún àwọn inú igbó àwọn ìlú yìí láti gé àwọn igi inú igbó wọn kalẹ̀ láti kọ́ ojú ọ̀nà, ilé-ìwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. railways, bridges, schools, in these parts of the country which are now threats to the forests areas as trees and vegetations are cut down or burnt to achieve these development plans. For instance, most first generation and second generation universities like University of Calabar were highly forested areas but the need to establish these schools made way for the destruction of these areas.
Gígé igi lulẹ̀ ní Nàìjíríà
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73770
73770
Shalewa Ashafa Shalewa Ashafa (tí a bí ní ọjọ́ Kejìlá oṣù keje ọdún 1995) tí ọ̀pọ̀lopọ̀ mọ̀ sí ShallyStar jẹ́ òṣèrébìnrin Nollywood tí ọ̀pọ̀lopọ̀ mọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú eré Ajoche àti The Razz Guy. Ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. Shalewa Ashafa jẹ́ àbíkẹ́yìn àwọn òbí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun . Ó lọ ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní Christ the Cornerstone Nursery àti Primary School, GRA Ikeja, Èkó ó sì lọ ilé-ìwé Sẹ́kọ́ndírì rẹ̀ ní Iloko Model College ní ìpínlẹ̀ Osun. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ nínú ìpolongo ọjà ní Yunifásítì ìlú Èkó. Àtòjọ àwọn fíìmù tí ó ti ṣe. "Evol (2017)," "There is Something," "The Razz Guy," "Blood Covenant."
Shalewa Ashafa
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73772
73772
Niger Delta Niger Delta jẹ́ ilẹ̀ àti iyẹ̀pẹ̀ tí ó sàn láti Odò Ọya tí ó sì wà ni Gulf of Guinea ti Atlantic Ocean, Nàìjíríà. Ó wà lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà. Ọ̀pọ̀lopọ̀ lọ ń gbé lórí Niger Delta, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì mọ ibè sí Oil Rivers nítorí ibè ni wọ́n ti ń ṣe epo Pupa ní Nàìjíríà. Ibẹ̀ náà sì jẹ́ ibi tí ọ̀pọ̀lopọ̀ epo rọ̀bì. Ilẹ̀ Niger Delta. Niger Delta ní ilẹ̀ tí ó tó , ó sì gbà tó 7.5% gbogbo ilẹ̀ Nàìjíríà. Àwọn Ìpínlẹ̀ tí ilẹ̀ náà dé ni Bayelsa, Delta, àti Ìpínlẹ̀ Rivers. Niger Delta ló pín Bight of Benin àti Bight of Bonny níyà nínú Gulf of Guinea. Àwọn ènìyàn Niger Delta. Àwọn ènìyàn tí ó tó mílíọ̀nù ókànlélógbọ̀n ni ó gbé ní Niger Delta àwọn ẹ̀yà tí ó wà níbè sì tó ogójì, àwọn ẹ̀yà bi Ukwuani, Abua, Bini, Ohaji/Egbema, Itsekiri, Efik, Esan, Ibibio, Annang, Oron, Ijaw, Igbo, Isoko, Urhobo, Kalabari, Yoruba, Okrika, Ogoni, Ogba–Egbema–Ndoni, Epie-Atissa àti Obolo, wọ́n sì ń sọ èdè tí ó tó ọ́ta-din-lẹwá-lé-nígba(250). Díè nínú àwọn èdè yìí ni èdè Ijaw, Ibibio-Efik, Igboid, Itsekiri, Central Delta, Edoid, àti Àwọn èdè irú Yorùbá,
Niger Delta
https://yo.wikipedia.org/wiki?curid=73773
73773
Upper Orashi Forest Reserve Upper Urashi Forest Reserve jẹ́ ibi ìpamọ́ ohun àdáyébá ní Ìpínlẹ̀ Rivers, Nàìjíríà tí ó wà ní òkè òkè ti Odò Urashi, nítòsí abúlé Ikodi ní Ahoada West. Ìfipamọ́ náà ní agbègbè 25,165 ha (97.163 sq mi). Ó jẹ́ ìyasọ́tọ̀ ilẹ̀ olómi tí ó ṣe pàtàkì káríayé lábẹ́ Àpéjọ Ramsar ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù Kẹrin ọdún 2008.
Upper Orashi Forest Reserve